Jehofa Bojuto Wa Labẹ Ifofinde—Apa 2
LAKOOKO Ogun Agbaye II, irin pàǹpà ti ń so bẹ́líìtì mú lara aṣọ ọmọ-ogun Nazi mi ní ami ikọwe naa “Ọlọrun Wà Pẹlu Wa.” Fun mi eyi wulẹ ti jẹ́ apẹẹrẹ miiran nipa lilọwọ ṣọọṣi ninu ogun ati itajẹsilẹ. Ó ti sú mi. Nitori naa ni akoko ti meji lara Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa mú mi wọnu ibanisọrọpọ ni Limbach-Oberfrohna, Ila-oorun Germany, mo ní ikoriira lilagbara fun isin mo sì ti di alaigbọlọrungbọ ati onigbagbọ ninu efoluṣọn kan.
“Ẹ maṣe lero pe emi yoo di Kristẹni kan,” ni mo sọ fun Awọn Ẹlẹ́rìí naa ti wọn ṣebẹwo. Ṣugbọn awọn àlàyé ọ̀rọ̀ wọn mú un dá mi loju pe Ọlọrun kan wà. Bi mo ti fẹ́ lati ṣòfintótó, mo ra Bibeli kan mo sì bẹrẹ sii kẹkọọ rẹ̀ pẹlu wọn laipẹ. Iyẹn jẹ́ ni ìgbà ìrúwé 1953, nigba ti igbokegbodo Awọn Ẹlẹ́rìí ni Ila-oorun Germany ti wà labẹ ifofinde Kọmunisti fun ohun ti o sunmọ ọdun mẹta sẹhin.
Ilé-Ìṣọ́nà ti August 15, 1953, ṣapejuwe ipo Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa nigba naa, ni wiwi pe: “Bi o tilẹ jẹ pe a ń yọ́ wọn wò lemọlemọ ti a sì ń halẹ mọ wọn, bi o tilẹ jẹ pe wọn kò lè ké si araawọn laikọkọ rí i daju pe a kò tẹle wọn, bi o tilẹ jẹ pe didi ẹni ti a rí pẹlu iwe ikẹkọọ Ilé-Iṣónà ni ìkáwọ́ ẹni tumọsi ọdun meji tabi mẹta ninu ẹ̀wọ̀n fun ‘pínpín iwe ikẹkọọ arunisókè’ kiri, bi o sì tilẹ jẹ pe ọgọrọọrun awọn arakunrin ti wọn tubọ dàgbàdénú, awọn wọnni ti wọn ti ń mú ipo iwaju, ti wà ninu ẹ̀wọ̀n, sibẹ awọn iranṣẹ Jehofa ni Ila-oorun Germany ń ba a lọ ni wiwaasu.”
Ni 1955 Regina, aya mi, ati emi lọ si apejọpọ agbaye ti Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni Nuremberg, Iwọ-oorun Germany, ati ni ọdun ti ó tẹle e awa mejeeji gba iribọmi ni Iwọ-oorun Berlin. Iyẹn, dajudaju, jẹ́ ṣaaju ki wọn tó mọ Ogiri Berlin ni 1961, ní gígé Ila-oorun Germany kuro lara Iwọ-oorun Berlin. Ṣugbọn ṣaaju ki ń tó gba iribọmi paapaa, iduroṣinṣin mi si Jehofa ni a fi sinu idanwo.
Titẹwọgba Ẹru-Iṣẹ
Ìjọ Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti a ti bẹrẹ sii lọ ni Limbach-Oberfrohna nilo ẹnikan ti ó lè lọ kó iwe ikẹkọọ Bibeli ni Iwọ-oorun Berlin. A ni iṣẹ-aje kekere kan ati awọn ọdọmọde kekere meji, ṣugbọn ṣiṣiṣẹsin Jehofa ti di gongo ifojusun ninu igbesi-aye wa ṣaaju akoko yii. A tun ogbologboo ọkọ ayọkẹlẹ wa ṣe, eyi ti ó mú ki o ṣeeṣe lati tọju 60 iwe pamọ nikọkọ. Jíjẹ́ afìwéjíṣẹ́ kan jẹ́ iṣẹ ti o léwu, ṣugbọn ó kọ́ mi lati gbarale Jehofa.
Fifi ọkọ ayọkẹlẹ mi sọda lati apá ìpín Ila-oorun Berlin si Iwọ-oorun Berlin kò rọrun, mo sì maa ń ṣe kayefi nigba gbogbo nipa bi a ti ṣe ń dọgbọn sii. Nigbakan rí ni apá ìpín ti ó wà lominira, a kó awọn iwe ikẹkọọ naa a sì tọju awọn iwe naa sinu ọkọ ṣaaju ki a tó sọda ibode pada lọ si Ila-oorun Germany.
Ni akoko kan, a ṣẹṣẹ pari fifi awọn iwe naa pamọ nikọkọ ni nigba ti àjòjì kan jade wa lati inu ile àdágbé kan. Ó pariwo pe, “ẹyin ti ẹ wà nibẹyẹn.” Àyà mi là gàrà. Ó ha ti ń kiyesi wa bi? “Yoo sàn ki ẹ gba ibomiran lọ nigbamiran. Ọkọ ayọkẹlẹ oniredio ti awọn ọlọpaa Ila-oorun Germany duro sẹgbẹẹ ibẹyẹn, wọn sì lè gbá yin mú.” Mo mí kanlẹ hẹ̀n-ẹ̀n. Sisọda ẹnu ibode lọ ni ìrọwọ́rọsẹ̀, awa mẹrẹẹrin ninu ọkọ sì kọrin titi ti a fi dé ile.
Imurasilẹ fun Àdádó
Ni awọn ọdun 1950 awọn ará ni Ila-oorun Germany gbarale awọn wọnni ti wọn wà ni Iwọ-oorun fun iwe ikẹkọọ ati itọsọna. Ṣugbọn ni 1960 awọn itunṣebọsipo ni a ṣe ti ó ran Ẹlẹ́rìí kọọkan ni Ila-oorun Germany lọwọ lati tubọ ni ifarakanra pẹkipẹki sii pẹlu Awọn Ẹlẹ́rìí ẹlẹgbẹ wọn ni agbegbe ibi ti wọn ń gbé. Lẹhin naa ni June 1961 kilaasi akọkọ ti Ile-Ẹkọ Iṣẹ-Ojiṣẹ Ọlọrun fun awọn alagba ni a ṣe ni Berlin. Mo lọ si eto idanilẹkọọ ọlọsẹ mẹrin akọkọ. Ni ohun ti ó fẹrẹẹ má tó ọsẹ mẹfa lẹhin naa, awa ni a deede ké kuro ni Iwọ-oorun nigba ti a mọ Ogiri Berlin. Iṣẹ wa nisinsinyi kì í ṣe kìkì abẹlẹ ṣugbọn ó tún jẹ àdádó.
Awọn kan bẹru pe igbokegbodo Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni Ila-oorun Germany yoo wá si opin patapata ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀. Bi o ti wu ki o ri, awọn itunṣebọsipo ninu eto-ajọ ti a ti bẹrẹ ní eyi ti kò tó ọdun kan ṣaaju ràn wa lọwọ lati pa iṣọkan ati okun tẹmi mọ́. Ni afikun, idalẹkọọ ti wọn rígbà lati ọwọ awọn alagba ti wọn lọ si kilaasi akọkọ ti Ile-Ẹkọ Iṣẹ-Ojiṣẹ Ijọba naa mu wọn gbaradi lati fi idalẹkọọ yii fun awọn alagba miiran. Nitori naa Jehofa mura wa silẹ fun àdádó wa, ani bi oun ti mura wa silẹ fun ifofinde ni 1950 pẹlu awọn apejọpọ agbegbe 1949.
Bi a ti ké wa kuro lara Iwọ-oorun, ó ṣe kedere pe a nilati lo idanuṣe lati maa jẹ́ ki eto-ajọ naa tẹsiwaju. A kọwe si awọn Kristẹni arakunrin wa ni Iwọ-oorun Berlin a sì damọran pipade pẹlu wọn ni oju opopona márosẹ̀ ni Ila-oorun ti ó ṣee tọ̀ fun awọn arinrin-ajo lati Iwọ-oorun. A dọgbọn ṣe bi ẹni pe ọkọ wa yọnu ni ibi ti a ti pinnu lati pade. Ni ọpọ iṣẹju lẹhin naa awọn arakunrin wa ọkọ̀ dé, ni kíkó iwe ikẹkọọ Bibeli wá fun wa. Lọna ti o muni layọ, wọn tun mú iwe ìdálẹ́kọ̀ọ́ Ile-Ẹkọ Iṣẹ-Ojiṣẹ Ijọba mi wá, awọn akọsilẹ ti mo ti ṣe, ati Bibeli ti mo ti fi silẹ sẹhin ni Berlin fun awọn idi ti o jẹ mọ́ aabo. Ó ti dun mọ mi tó lati ri wọn gbà pada! Diẹ ni mo mọ̀ nipa bi emi yoo ti nilo iwọnyi lọpọlọpọ tó ni iwọnba awọn ọdun diẹ ti o tẹle e.
Ile-Ẹkọ Abẹ́lẹ̀
Ni iwọnba ọjọ diẹ lẹhin naa, a fun wa nitọọni lati ṣeto fun awọn kilaasi Ile-Ẹkọ Iṣẹ-Ojiṣẹ Ijọba ni gbogbo apa Ila-oorun Germany. Awọn olukọ mẹrin ni a yàn, ti ó ní mi ninu. Ṣugbọn fun mi ó dabi iṣẹ ti kò ṣeeṣe kan lati kọ́ gbogbo awọn alagba nigba ti iṣẹ wa wà labẹ ifofinde. Lati dọgbọn ohun ti a ń ṣe, mo pinnu lati ṣeto awọn kilaasi naa gẹgẹ bi ìpàgọ́ akoko isinmi.
Kilaasi kọọkan ni ninu akẹkọọ mẹrin ati emi gẹgẹ bi olukọ, ati arakunrin kẹfa ti ó ṣiṣẹ gẹgẹ bi alásè. Awọn aya ati ọmọ wa wà nibẹ pẹlu. Nitori naa ni gbogbogboo a ni awujọ eniyan lati ori 15 si 20. Ibi àyè ìpàgọ́ ti ó wà deedee ni kò ṣeeṣe, nitori naa emi ati idile mi jade lọ lati wá awọn ọgangan àyè ti ó bojumu.
Ni akoko kan, nigba ti a ń rinrin-ajo la abule kan lọ, a ṣakiyesi ọ̀nà tóóró kan ti o lọ jásí abẹ́ awọn igi ti wọn jinna diẹ si ojú ọ̀nà tààrà. Ó jọ bi eyi ti ó dara, nitori naa mo lọ bá baalẹ ilu naa. “A ń wa ibi kan lati lo ọsẹ melookan lati pàgọ́ pẹlu awọn idile miiran,” ni mo ṣalaye. “A fẹ́ danikan wà ki awọn ọmọ baa lè rin yika falala. Ǹjẹ́ a lè lo abẹ awọn igi ti ó wà nibẹyẹn?” Ó faramọ ọn, nitori naa a ṣe awọn ètò.
Ni ibi àyè naa, a gbé awọn àgọ́ naa ati ile àgbérìn mi kalẹ ki o baa lè láàyè onigun mẹrin ti o farasin si ẹhin-ode ni àárín. Ile àgbérìn naa ni a lo gẹgẹ bii iyàrá ikawe. A pade nibẹ fun ikẹkọọ kúnnákúnná oniwakati 8 loojọ fun ọjọ 14. Ni agbegbe ti a kámọ́ naa ni awọn aga ati tabili kan wà, ti a tò kalẹ boya o lè ṣẹlẹ ki a ni àlejò ti a kò reti tẹlẹ. A sì ni wọn! Ni iru awọn akoko bẹẹ a mọriri itilẹhin onifẹẹ ti awọn idile wa gidigidi.
Nigba ti a ń ní akoko ikẹkọọ lọwọ, awọn idile wa ń ṣọna. Ni akoko pataki yii, baalẹ naa, ti o tun jẹ́ akọwe Ẹgbẹ Kọmunisti adugbo, ni a gán-ánní ti ń bọ̀ loju ọ̀nà tóóró naa siha abẹ́ igi wa. Awọn aṣọna naa tẹ ago ti a ta okun rẹ̀ mọ inu ile àgbérìn naa. Lọgan a bẹ́ jade kuro ninu ile àgbérìn naa a sì jokoo lori awọn awọn ibi ti a ti ṣeto silẹ ṣaaju yika tabili naa a sì bẹrẹ sii ta kaadi. Igo ṣìnáàbù kan tilẹ wà lati mú ki iran naa jọ otitọ gidi. Baalẹ naa ṣe ibẹwo oniwa bi ọ̀rẹ́ sọdọ wa ó sì pada sile laisi ifura eyikeyii nipa ohun ti ń ṣẹlẹ niti gidi.
Awọn kilaasi Ile-Ẹkọ Iṣẹ-Ojiṣẹ Ijọba ni a ṣe jakejado orilẹ-ede naa lati ìgbà ìrúwé 1962 titi di ipari 1965. Idalẹkọọ kúnnákúnná ti a gbà nibẹ, eyi ti ó ni isọfunni lori bi a ṣe lè koju ipo ti a wa gan-an ni pataki ni Ila-oorun Germany ninu, mura awọn alagba silẹ fun iṣabojuto iṣẹ iwaasu. Ki wọn baa lè lọ si awọn kilaasi naa, kì í ṣe pe awọn alagba fi akoko isinmi wọn nikan rúbọ ṣugbọn wọn tun dagbale ewu ifisẹwọn bakan naa.
Awọn Anfaani Ile-Ẹkọ Naa
Awọn alaṣẹ ń fi tiṣọratiṣọra ṣakiyesi awọn igbokegbodo wa, ati ni apá ipari 1965, lẹhin ti ọpọ julọ awọn alagba ti lọ si ile-ẹkọ naa, wọn gbiyanju lati fopin si igbokegbodo eto-ajọ wa. Wọn faṣẹ ọba mu Awọn Ẹlẹ́rìí 15 ti wọn kà sí awọn ti ń mú ipo iwaju ninu iṣẹ naa. Igbesẹ ti a murasilẹ daradara ni, ti o lọ taara kọja ilẹ naa. Lẹẹkan sii, ọpọlọpọ ro pe Awọn Ẹlẹ́rìí yoo dawọ iṣẹ ṣiṣe duro. Ṣugbọn pẹlu iranlọwọ Jehofa a mu araawa bá ipo naa mu a sì ń bá iṣẹ wa lọ bii ti iṣaaju.
Ohun ti o mu eyi ṣeeṣe ni pataki ni idalẹkọọ ti awọn alagba naa ti rígbà ni Ile-Ẹkọ Iṣẹ-Ojiṣẹ Ijọba ati awọn ìdè igbẹkẹle ti ibakẹgbẹpọ tí wọn gbadun ni akoko awọn ikọnilẹkọọ wọnyi ti mú ki o wà. Nipa bayii, eto-ajọ naa fi animọ ifarada rẹ̀ han. Ó ti ṣe pataki tó pe a ti fi igbọran tẹle awọn itọni eto-ajọ naa timọtimọ!—Aisaya 48:17.
Ó hàn kedere ni awọn oṣu ti o tẹle e pe ọpọlọpọ ilekoko mọni nipasẹ awọn alaṣẹ ijọba ti ni ipa buburu ti kò tó nǹkan lori igbokegbodo wa. Lẹhin akoko kekere, ó ṣeeṣe fun wa lati tun bẹrẹ awọn kilaasi Ile-Ẹkọ Iṣẹ-Ojiṣẹ Ijọba. Gbàrà ti awọn alaṣẹ ṣakiyesi ìrújáde wa, a fi ipá mú wọn lati yí awọn ọgbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yí wọn pada. Ayọ iṣẹgun wo ni ó jẹ́ fun Jehofa!
Onitara Ninu Iṣẹ-Ojiṣẹ
Ni akoko yẹn awujọ Ikẹkọọ Iwe Ijọ wa ni nǹkan bii ẹni marun-un ninu. Ẹnikọọkan wa gba iwe ikẹkọọ Bibeli rẹ̀ nipasẹ iṣeto ikẹkọọ iwe ijọ yii, iṣẹ iwaasu ni a sì ṣe kòkáárí rẹ̀ lati inu awọn awujọ ikẹkọọ kekere wọnyi. Lati ibẹrẹ Jehofa bukun emi ati Regina pẹlu ọpọlọpọ awọn eniyan ti wọn fẹ́ lati kẹkọọ Bibeli.
Iṣẹ-isin ile-de-ile ni a yí pada lọna kan ṣá lati daabobo wa kuro lọwọ didi ẹni ti a wá rí ti a sì faṣẹ ọba mú. Awa yoo ṣe ikesini sí ile kan, lẹhin naa a o fo awọn ile bii melookan dá ki a tó kan ilẹkun miiran. Ni ile kan iyaafin kan pe emi ati Regina wọle. A ń jiroro ẹṣin-ọrọ ti ó bá Iwe Mimọ mu pẹlu rẹ̀ nigba ti ọmọkunrin rẹ̀ rin wọle. Ọrọ rẹ̀ ṣe ṣàkó.
“Iwọ ha ti rí Ọlọrun rẹ ri bi?” ni ó beere. “Gan-an gẹgẹ bi o ti mọ̀, mo gba kìkì ohun ti mo lè rí gbọ́. Gbogbo ohun ti ó kù jẹ́ alaiwulo.”
“Emi kò lè gba iyẹn gbọ́,” ni mo fesi pada. “Iwọ ha ti ri ọpọlọ rẹ rí bi? Gbogbo ohun ti o ń ṣe fihan pe iwọ ni ọ̀kan.”
Emi ati Regina pese apẹẹrẹ awọn ohun miiran ti a gbà lai ri wọn, iru bii iná mànàmáná. Ọdọmọkunrin naa fetisilẹ yekeyeke, ikẹkọọ Bibeli inu ile kan ni a sì bẹrẹ pẹlu oun ati iya rẹ̀. Awọn mejeeji di Ẹlẹ́rìí. Nitootọ, awọn ẹni 14 ti emi ati aya mi bá kẹkọọ di Ẹlẹ́rìí. Ìlàjì iye yii ni a bá pade ni akoko awọn ibẹwo ile-de-ile wa, ìlàjì ti ó sì kù ni a kọkọ pade ni akoko ijẹrii àìjẹ́-bí-àṣà.
Gbàrà ti a ba ti ń dari ikẹkọọ Bibeli deedee kan ti a sì ka ẹni naa si ẹni ti o ṣee fọkàntẹ̀, a o ké sí ẹni yẹn si awọn ipade wa. Bi o ti wu ki o ri, igbeyẹwo pataki kan ni boya akẹkọọ naa lè fi aabo awọn eniyan Ọlọrun si inu ewu jẹ́. Nipa bayii, ó maa ń tó ọdun kan nigbamiran ki a tó ké si akẹkọọ kan si ipade, ati ni akoko miiran ó ń pẹ́ ju iyẹn lọ. Mo níran ọkunrin kan ti ó gbadun ìwọ̀n iyọri-ọla kan; ó wà ninu awọn sànmànrí ìjòyè oṣiṣẹ lóókọlóókọ ninu Ẹgbẹ́ Kọmunisti. Ó ṣe ikẹkọọ Bibeli fun ọdun mẹsan-an ki a tó fun un lanfaani lati wá si awọn ipade! Lonii ọkunrin yii jẹ Kristẹni arakunrin wa.
Awọn Alaṣẹ Ń Lépa Wa Sibẹ
Lẹhin 1965 a kò niriiri ifaṣẹ ọba muni lọpọlọpọ mọ́, ṣugbọn bẹẹ ni a kò fi wá silẹ lalaafia. Awọn alaṣẹ ṣì ń fi imu fínlẹ̀. Ni nǹkan bi akoko yii mo di ẹni ti ó kó wọnu iṣẹ ṣiṣe timọtimọ pẹlu eto-ajọ wa, nitori naa mo di ẹni ti awọn ìjòyè oṣiṣẹ ń pe afiyesi akanṣe sí. Laimọye ìgbà ni wọn wá gbé mi fun bibeere ọrọ, ni wíwà mi lọ si àgọ́ ọlọpaa ti wọn yoo sì maa beere ibeere lọwọ mi. “Iwọ lè sọ pe odigbooṣe fun ominira rẹ nisinsinyi,” ni wọn yoo sọ. “Ẹ̀wọ̀n yá ọ.” Ṣugbọn wọn sábà maa ń jẹ́ ki ń lọ lẹhin-ọ-rẹhin.
Ni 1972 awọn ìjòyè oṣiṣẹ meji bẹ̀ mi wò wọn sì sọ ọrọ iyin rere fun eto-ajọ wa láìmọ̀. Wọn ti ń fetisilẹ si Ikẹkọọ Ilé-Ìṣọ́nà ninu ìjọ wa. “Ọrọ-ẹkọ naa kò dùn mọ́ wa” ni wọn ráhùn. Ni kedere wọn daniyan nipa ohun ti awọn ẹlomiran lè rò nipa èrò Kọmunisti bi wọn bá ka ọrọ-ẹkọ ti a ń gbeyẹwo, “Ó ṣetan,” ni wọn sọ, “Ilé-Ìṣọ́nà ni ipinkiri million marun-un tabi mẹfa, a sì ń kà á ni awọn orilẹ-ede tí ń dìdelẹ̀. Ki i wulẹ ṣe iwe irohin yẹpẹrẹ.” Mo rò ó sinu araami pe, ‘O ti tọna tó!’
Nigba ti o fi di 1972 a ti wà labẹ ifofinde fun ọdun 22, Jehofa sì ti tọ́ wa sọna tifẹtifẹ ati pẹlu ọgbọn. A ti tẹle awọn itọni rẹ̀ tiṣọratiṣọra, ṣugbọn yoo jẹ́ ọdun 18 miiran sii ki a tó yọnda mímọ̀ labẹ ofin fun Awọn Ẹlẹ́rìí ni Ila-oorun Germany. A tun kún fun imooore fun awọn ominira agbayanu ti a ń gbadun nisinsinyi lati jọsin Ọlọrun wa, Jehofa!—Gẹgẹ bi Helmut Martin ti sọ ọ́.