ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w92 7/15 ojú ìwé 22
  • Ipade Ọdọọdun—October 3, 1992

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ipade Ọdọọdun—October 3, 1992
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ipade Ọdọọdun—October 3, 1992
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Ipade Ọdọọdun—October 5, 1991
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ipade Ọdọọdun—October 5, 1991
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ipade Ọdọọdun
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
w92 7/15 ojú ìwé 22

Ipade Ọdọọdun​—October 3, 1992

IPADE ỌDỌỌDUN ti mẹmba Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania ni a o ṣe ni October 3, 1992, ni Gbọngan Apejọ ti Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, 2932 Kennedy Boulevard, Jersey City, New Jersey. Ipade àṣeṣaájú ti kìkì awọn mẹmba ni a o pe apejọpọ rẹ̀ ni 9:30 òwúrọ̀, ti ipade ọdọọdun ti gbogbogboo yoo sì tẹle e ni 10:00 òwúrọ̀.

Awọn mẹmba Ajọ-ẹgbẹ nilati fi tó Ọfiisi Akọwe leti nisinsinyi nipa iyipada eyikeyii ninu awọn adirẹsi ifiweranṣẹ wọn ni aarin ọdun ti o kọja ki awọn lẹta ìfitónilétí ti a ń lo deedee ati iwe aṣẹ ìṣojúfúnni ba lè dé ọdọ wọn kété lẹhin August 1.

Awọn iwe aṣẹ ìṣojúfúnni naa, ti a o fi ranṣẹ si awọn mẹmba pẹlu ìfitónilétí nipa ipade ọdọọdun, ni a nilati dá pada ki o baa lè dé Ọfiisi Akọwe Society laipẹ ju August 15 lọ. Mẹmba kọọkan nilati kọ ọrọ kun iwe aṣẹ ìsọfúnni tirẹ̀ ni kíámọ́sá ki ó sì dá a pada ni sisọ yala oun yoo wà ni ibi ipade naa fúnraarẹ̀ tabi bẹẹkọ. Ìsọfúnni ti a fifunni lori iwe aṣẹ ìsọfúnni kọọkan nilati ṣe pàtó lori kókó yii, niwọn bi a o ti gbarale e ni pipinnu awọn wo ni yoo wà nibẹ funraawọn.

A reti pe gbogbo akoko ijokoo naa, titi kan awọn ipade iṣẹ àmójútó eleto àṣà ati awọn irohin, ni a o pari rẹ̀ ni 1:00 ọ̀sán tabi kété lẹhin naa. Kì yoo sí akoko ijokoo ọ̀sán. Nitori ààyè ti o mọniwọn, igbawọle yoo jẹ́ nipasẹ tikẹẹti nikanṣoṣo. Kò sí iṣeto kankan ti a o ṣe fun siso ipade ọdọọdun naa pọ mọ wáyà tẹlifoonu lọ si awọn gbọngan awujọ miiran.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́