Ipade Ọdọọdun—October 5, 1991
IPADE ỌDỌỌDUN ti mẹmba Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania ni a o ṣe ni October 5, 1991, ni Gbọngan Apejọ ti awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, 2932 Kennedy Boulevard, Jersey City, New Jersey. Ipade àṣeṣaájú ti kiki awọn mẹmba ni a o pe apejọpọ rẹ ni 9:30 a.m., ti ipade ọdọọdun ti gbogbogboo yoo si tẹle e ni 10:00 a.m.
Awọn mẹmba Ajọ-ẹgbẹ nilati fi tó Ọfiisi Akọwe leti nisinsinyi nipa iyipada eyikeyii ninu awọn adirẹsi ifiweranṣẹ wọn ti ọdun ti o kọja ki awọn lẹta ìfitónilétí ati iwe aṣẹ ìṣojúfúnni ba lè dé ọdọ wọn kété lẹhin August 1.
Awọn iwe aṣẹ ìṣojúfúnni naa, ti a o fi ranṣẹ si awọn mẹmba pẹlu ìfitónilétí nipa ipade ọdọọdun, ni a nilati dá pada ki o ba le dé Ọfiisi Akọwe Society laipẹ ju August 15. Mẹmba kọọkan nilati kọ ọrọ kun iwe aṣẹ ìsọfúnni tirẹ ni kíámọ́sá ki o sì dá a pada ki o sọ yala oun yoo wà ni ibi ipade naa funraarẹ tabi bẹẹkọ. Ìsọfúnni ti a fifunni lori iwe aṣẹ ìsojúfúnni kọọkan nilati ṣe pàtó lori kókó yii, niwọn bi a o ti gbarale eyi ni pipinnu awọn wo ni yoo wà nibẹ funraawọn.
A fojusọna pe gbogbo akoko ijokoo naa, titi kan awọn ipade iṣẹ àmójútó eleto aṣa ati awọn irohin, ni a o pari rẹ ni 1:00 p.m. tabi kété lẹhin naa. Ki yoo si akoko ijokoo ọsan. Nitori aye ti o mọniwọn, igbawọle yoo jẹ nipasẹ tikẹẹti nikanṣoso. Ko si iṣeto kankan ti a o ṣe fun siso ipade ọdọọdun naa pọ mọ waya tẹlifoonu lọ si awọn gbọngan awujọ miiran.