Ipade Ọdọọdun—October 3, 1992
IPADE ỌDỌỌDUN ti mẹmba Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania ni a o ṣe ni October 3, 1992, ni Gbọngan Apejọ ti Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, 2932 Kennedy Boulevard, Jersey City, New Jersey. Ipade àṣeṣaájú ti kìkì awọn mẹmba ni a o pe apejọpọ rẹ̀ ni 9:30 òwúrọ̀, ti ipade ọdọọdun ti gbogbogboo yoo sì tẹle e ni 10:00 òwúrọ̀.
Awọn mẹmba Ajọ-ẹgbẹ nilati fi tó Ọfiisi Akọwe leti nisinsinyi nipa iyipada eyikeyii ninu awọn adirẹsi ifiweranṣẹ wọn ni aarin ọdun ti o kọja ki awọn lẹta ìfitónilétí ti a ń lo deedee ati iwe aṣẹ ìṣojúfúnni ba lè dé ọdọ wọn kété lẹhin August 1.
Awọn iwe aṣẹ ìṣojúfúnni naa, ti a o fi ranṣẹ si awọn mẹmba pẹlu ìfitónilétí nipa ipade ọdọọdun, ni a nilati dá pada ki o baa lè dé Ọfiisi Akọwe Society laipẹ ju August 15 lọ. Mẹmba kọọkan nilati kọ ọrọ kun iwe aṣẹ ìsọfúnni tirẹ̀ ni kíámọ́sá ki ó sì dá a pada ni sisọ yala oun yoo wà ni ibi ipade naa fúnraarẹ̀ tabi bẹẹkọ. Ìsọfúnni ti a fifunni lori iwe aṣẹ ìsọfúnni kọọkan nilati ṣe pàtó lori kókó yii, niwọn bi a o ti gbarale e ni pipinnu awọn wo ni yoo wà nibẹ funraawọn.
A reti pe gbogbo akoko ijokoo naa, titi kan awọn ipade iṣẹ àmójútó eleto àṣà ati awọn irohin, ni a o pari rẹ̀ ni 1:00 ọ̀sán tabi kété lẹhin naa. Kì yoo sí akoko ijokoo ọ̀sán. Nitori ààyè ti o mọniwọn, igbawọle yoo jẹ́ nipasẹ tikẹẹti nikanṣoṣo. Kò sí iṣeto kankan ti a o ṣe fun siso ipade ọdọọdun naa pọ mọ wáyà tẹlifoonu lọ si awọn gbọngan awujọ miiran.