Kristẹndọm Ati Òwò Ẹrú
NÍ ỌRUNDUN 19, awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji ti Katoliki ati ti Protẹstant wà ni iṣọkan ninu atako wọn sí òwò ẹrú. Bi o ti wu ki o ri, iyẹn kì í tií fi gbogbo ìgbà jẹ́ ipo wọn. Ni awọn ọrundun ti ó ṣaaju, wọn fọwọsi, wọn sì Iọwọ ninu òwò ẹrú laika ijiya ẹlẹ́rù-jẹ̀njẹ̀n ti eyi mú jade.
Awọn ojihin-iṣe-Ọlọrun ni ilẹ ajeji bẹrẹ sii wá sí etíkun ila-oorun ati etíkun iwọ-oorun Africa bakan-naa nigba ti wọn ṣawari ipa-ọna òwò lori òkun ni ayika Cape of Good Hope ni ọrundun 15. Bi o ti wu ki o ri, Iẹhin ọrundun mẹta, iṣẹ ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji ni Africa ti fẹrẹẹ wá sí opin. Iwọnba awọn ará Africa ti a yí Iọkan pada ni wọn wà. Idi kan fun ìkùnà yii jẹ́ kíkó tí Kristẹndọm kówọnu òwò ẹrú. C. P. Groves ṣalaye ninu iwe The Planting of Christianity in Africa pe:
”llepa òwò-ẹrú lójú mejeeji bá iṣẹ ijihin-isin Kristian rìn a kò sì ronu pe ó ṣaitọ. Nitootọ, ẹ̀ka iṣẹ ijihin-isin gan-an ní awọn ẹrú tirẹ fúnraarẹ̀; ile awọn ọkunrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàndágbé Jesuit kan ni Loanda [ti i ṣe Luanda nisinsinyi, olu-ilu Angola] ni a fun ni 12,000. Nigba ti òwò-ẹrú gbèrú laaarin Angola ati Brazil, biṣọọbu Loanda, lori àga olókùúta lẹbaa etíkun, rọ̀jò ibukun biṣọọbu sori awọn ẹrú ti a kó sọ́kọ̀ ti ó ń mura àti ṣí, ni ṣiṣeleri ayọ ọjọ-ọla fun wọn nigba ti awọn adanwo oníjì ti igbesi ayé bá pari.”
Awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji ti wọn jẹ Jesuit kò “tako sísọ awọn adúláwọ̀ dẹrú,” ni C. R. Boxer sọ gẹgẹ bi a ti ṣayọlo rẹ̀ ninu iwe naa Africa From Early Times to 1800. Ni Luanda, ṣaaju ki awọn ẹrú tó wọnu ọkọ oju-omi ti ń lọ si awọn ilẹ tí Spain ati Portugal tẹ̀dó, ni Boxer fikun un, “a ń kó wọn lọ si ṣọọṣi ti o wà nitosi. . . nibẹ ni alufaa ṣọọṣi kan yoo sì ti baptisi wọn ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ ọgọrọọrun lẹẹkan.” Lẹhin naa, bi a bá ti wọ́n “omi mímọ́” si wọn lara tán, awọn ẹrú naa ni a sọ fun pe: “Ẹ wo ẹyin wọnyi ti di ọmọ Ọlọrun ná; ẹ ń lọ si ilẹ awọn ará Spain nibi ti ẹyin yoo ti mọ awọn ohun Igbagbọ. Ẹ maṣe ronu nipa ibi ti ẹ ti wá mọ́ . . . ẹ lọ pẹlu ọkàn rere.”
Niti tootọ, awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji ti Kristẹndọm kò danikan wà ninu fifọwọsi òwò ẹrú. “Titi di apá ilaji ti o kẹhin ọrundun kejidinlogun, ó jẹ́ iṣarasihuwa ọpọ julọ eniyan” ni Geoffrey Moorhouse ṣalaye ninu iwe rẹ̀ The Missionaries. Moorhouse tọka si apẹẹrẹ ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji ti Protẹstant ti ọrundun 18 kan, Thomas Thompson, ẹni ti o kọ iwe ìléwọ́ kan ti ó ni akori naa The African Trade for Negro Slaves Shown to Be Consistent With the Principles of Humanity and With the Laws of Revealed Religion.
Sibẹ, nipasẹ ìkópa rẹ̀ Kristẹndọm ṣajọpin ìjíhìn fun ijiya buburu ti a múwá sori araadọta-ọkẹ awọn ẹrú Africa. “Laifi awọn ẹrú ti wọn kú ṣaaju ki wọn tó tukọ̀ lati kuro ni Africa kun un,” ni The Encyclopaedia Britannica sọ, “ipin 121/2 ninu ọgọrun-un ni a padanu lakooko ìsọdá wọn si Iwọ-oorun Indies; ni Jamaica ipin 41/2 ninu ọgọrun-un kú nigba ti wọn wà ni etikun tabi ṣaaju ki a tó tà wọn ati ìdámẹ́ta sii ninu ‘imurasilẹ ti a ń ṣe fun awọn ẹrú titun lati mú wọn jẹ́ ẹrú titootun.’”
Laipẹ Jehofa Ọlọrun yoo pe Kristẹndọm ati iru awọn isin èké miiran wá fun ìjíhìn fun gbogbo iṣe buburu jai ẹlẹ́bi-ẹ̀jẹ̀ ti wọn ti fàyègbà ti wọn tilẹ ṣadura sí paapaa.—Ìfihàn 18:8, 24.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an.)
Aworan ọ̀nà ti a gbà ń sín awọn ẹrú sinu ọkọ oju-omi tí ń kó ẹrú kan
[Credit Line]
Schomburg Center for Research in Black Culture / The New York Public Library / Astor, Lenox and Tilden Foundations