Ìrìn Àjò Síbi Tí Wọ́n Ti Ń ṣe Òwò Ẹrú
LÁTI ọdún 1600 sí 1800, ìlú Ouidah jẹ́ ìlú tó gbajúmọ̀ tó bá dọ̀rọ̀ ṣíṣòwò ẹrú, ní ìwọ̀ oòrùn Áfíríkà. Lóde òní, ìlú yìí wà ní orílẹ̀-èdè Republic of Benin. Àwọn ẹrú tí wọ́n kó láti ibẹ̀ ju mílíọ̀nù kan lọ. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Áfíríkà máa kó ọmọ ilẹ̀ Áfíríkà bíi tiwọn fáwọn tó ń ra ẹrú, wọ́n á sì fi wọ́n ṣe pàṣípààrọ̀ fún ọtí, aṣọ, ẹ̀gbà ọwọ́, ọ̀bẹ, idà, àti ní pàtàkì ìbọn, tó jẹ́ nǹkan tí ọ̀pọ̀ èèyàn fẹ́ láti ní nítorí ogun kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà tó máa ń ṣẹlẹ̀ nígbà yẹn.
Wọ́n fojú bù ú pé láàárín ọdún 1500 sí 1800, ó tó mílíọ̀nù méjìlá àwọn ọmọ ilẹ̀ Áfíríkà tí wọ́n kó lẹ́rú gba orí okun Àtìláńtíìkì láti lọ fi wọ́n ṣe iṣẹ́ àṣekára nínú àwọn oko ọ̀gbìn ńlá, tí wọ́n sì tún fi wọ́n wa kùsà ní Ìwọ̀ Oòrùn Ìlàjì Ayé. Ìwé kan tó ń jẹ́ American Slavery —1619-1877, sọ pé, nǹkan bí ìdá márùn-dín-láàádọ́rùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ẹrú náà “ni wọ́n kó lọ sí orílẹ̀-èdè Brazil àti àwọn àgbègbè àdádó kan táwọn ará Caribbean tẹ̀ dó sí ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, Faransé, Sípéènì àti Dutch.” Wọ́n tún fojú bù ú pé nǹkan bí ìdá mẹ́fà nínú ọgọ́rùn-ún ló tẹ̀ dó sáwọn ibòmíì tó wá di ara ilẹ̀ Amẹ́ríkà nígbà tó yá.a
Nígbà tí wọ́n fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí í kó àwọn ẹrú yẹn lọ, ọ̀pọ̀ nínú wọn ni wọ́n fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ dè, wọ́n ti lù wọ́n ní àlùbami, wọ́n sì ti sàmì sí wọn lára. Lẹ́yìn náà, wọ́n á wá rin ìrìn kìlómítà mẹ́rin láti ibi tí wọ́n ń pé ní ibi ìkóhun-ìṣẹ̀ǹbáyé-sí ti ìlú Ouidah lóde òní, ìyẹn Ouidah Museum of History, tó jẹ́ ọgbà ológun kan tí wọ́n ti tún kọ́, títí dé ibi kan tí wọ́n ń pè ní Ẹnú Ọ̀nà Àrèmábọ̀, tó wà létí òkun. Ẹnu ọ̀nà yẹn ló dúró fún bí wọ́n ṣe kó àwọn ẹrú jáde pátápátá níbi tí wọ́n ti ń ṣe Òwò Ẹrú náà. Àmọ́ ṣá o, ìyẹn kàn jẹ́ lọ́nà àpẹẹrẹ ni, torí pé kì í ṣe ojú ọ̀nà kan ṣoṣo yẹn ni wọ́n gbà kó gbogbo àwọn ẹrú náà jáde. Báwo gan-an ni òwò ẹrú ṣe bẹ̀rẹ̀?
Ìtàn Kan Tó Bani Nínú Jẹ́
Nígbà àtijọ́, àwọn aláṣẹ ilẹ̀ Áfíríkà máa ń ta àwọn tí wọ́n bá kó bọ̀ láti ogun fún àwọn Lárúbáwá oníṣòwò. Nígbà tó yá, àwọn orílẹ̀-èdè alágbára nílẹ̀ Yúróòpù náà bẹ̀rẹ̀ sí í ṣòwò ẹrú, pàápàá jù lọ lẹ́yìn tí wọ́n ti tẹ àwọn ibì kan dó nílẹ̀ Amẹ́ríkà. Láyé ìgbà yẹn, àwọn ogun kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà máa ń jẹ́ káwọn tó lọ jagun rí ọ̀pọ̀ èèyàn kó lẹ́rú, ogún wá di iṣẹ́ tó ń mówó rẹpẹtẹ wọlé fún àwọn tó bá ṣẹ́gun àtàwọn oníwọra tó ń ṣòwò ẹrú. Bákan náà, wọ́n tún máa ń rí àwọn èèyàn tí wọ́n á fi ṣe ẹrú kó nípa jíjí àwọn èèyàn gbé tàbí kí wọ́n rà wọ́n lọ́wọ́ àwọn oníṣòwò ọmọ ilẹ̀ Áfíríkà tí wọ́n ń kó wọn wá láti àwọn àrọko kan nílẹ̀ Áfíríkà. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí ẹni tí wọn kò lè tà gẹ́gẹ́ bí ẹrú, kódà, wọ́n lè ta ọmọ ọba, tó bá ṣẹlẹ̀ pé kò rí ojú rere ọba mọ́.
Ọ̀kan lára àwọn oníṣòwò ẹrú tó gbajúmọ̀ ni ọmọ orílẹ̀-èdè Brazil kan tó ń jẹ́ Francisco Félix de Souza. Lọ́dún 1788, ọ̀gbẹ́ni yìí gba ibi tí wọ́n fi ṣe ọjà tí wọ́n ti ń ta ẹrú nílùú Ouidah, ní etíkun orílẹ̀-èdè Republic of Benin. Nígbà yẹn, ìlú Ouidah wà lábẹ́ Ìjọba Dahomey. Àmọ́, ìjà kan ṣẹlẹ̀ láàárín De Souza àti Ọba ìlú Dahomey, ìyẹn Adandozan. Ó jọ pé nígbà tí De Souza, fi wà ní ẹ̀wọ̀n, ó lẹ̀dí àpò pọ̀ pẹ̀lú àbúrò ọba, bí wọ́n ṣe pawọ́ pọ̀ lé ọba kúrò lórí oyè lọ́dún 1818 nìyẹn. Bí ọba tuntun náà, Ghezo àti De Souza ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í ṣòwò pa pọ̀ nìyẹn, ó sì ní kí De Souza máa ṣe kòkáárí òwò ẹrú.b
Ó wu Ghezo gan-an láti mú kí ìjọba rẹ̀ gbòòrò dáadáa, ó sì nílò àwọn ohun ìjà ogun látọ̀dọ̀ àwọn ará Yúróòpù. Torí náà, ó fi De Souza ṣe gómìnà tó ń ṣojú ọba nílùú Ouidah kó bàa lè máa bójú tó òwò náà pẹ̀lú àwọn ará Yúróòpù. Ní báyìí tí De Souza sì ti ní àṣẹ lórí òwò ẹrú lápá ibẹ̀ yẹn nílùú Áfíríkà, kò pẹ́ tó fi rí towó ṣe gan-an, ọjà tí wọ́n ti ń ta ẹrú tó wà nítòsí ilé rẹ̀ wá di ibi tó gbajúmọ̀ tí àwọn ará Áfíríkà àtàwọn tó wá láti òkè òkun ti wá ń ra ẹrú.
Ìrìn Àjò Tó Nira Gan-an
Bó bá jẹ́ pé àlejò ni ẹ́, tó o sì fẹ́ rìn yí ká ibi tí wọ́n ti ń ṣòwò ẹrú nílùú Ouidah, ìrìn náà bẹ̀rẹ̀ láti ọgbà ológun táwọn ará Portugal tún kọ́. Ọdún 1721 ni wọ́n kọ́kọ́ kọ́ ọ̀gbà yìí, ibẹ̀ ló sì wá di ibi ìkóhun-ìṣẹ̀ǹbáyé-sí tá a sọ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí. Inú ọgbà ńlá náà ni wọ́n máa ń kó àwọn tí wọ́n fẹ́ fi ṣe ẹrú sí. Ọ̀pọ̀ nínú wọn ló ti rìnrìn-àjò fún ọ̀pọ̀ ọjọ́, tí wọ́n fi ẹ̀wọ̀n dè wọ́n pọ̀, alẹ́ sì ni wọ́n máa ń rìnrìn-àjò náà. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé alẹ́ ni wọ́n máa ń rìnrìn àjò? Ìdí ni pé tí wọ́n bá ń rìn nínú òkùnkùn, nǹkan á dàrú mọ́ wọn lójú, èyí á sì mú kó ṣòro fún àwọn tó bá sá mọ́ wọn lọ́wọ́ láti pa dà sílé.
Tí wọ́n bá ti kó àwọn ẹrú kan dé, àwọn oníbàárà á dúnàádúrà, lẹ́yìn náà, kálukú á wá sàmì sí àwọn ẹrú tirẹ̀. Wọ́n á kó àwọn ẹrú tí wọ́n bá fẹ́ kó lọ sókè òkun lọ sí etíkun, wọ́n á wá fi ọkọ̀ ọ̀pẹẹrẹ kó wọn lọ́ sínú ọkọ̀ òkun.
Ibòmíì tó tún gbàfiyèsí níbi tí wọ́n ti ń ṣe Òwò Ẹrú náà ni ibi tí igi kan tí wọ́n ń pè ní Igi Ìgbàgbé wà nígbà yẹn. Lóde òní, wọ́n ti kọ́ ohun ìrántí kan síbi tí igi náà wà, ìtàn fi yé wa pé, àwọn tó ń ṣòwò ẹrú máa ń fipá mú àwọn ẹrú láti rìn yí po igi náà, àwọn ọkùnrin á rìn yí po ní ìgbà mẹ́sàn-án, àwọn obìnrin á rìn yí po ní ìgbà méje. Wọ́n sọ pé ohun tí wọ́n ṣe fún àwọn ẹrú yìí máa ń ra wọ́n níyè, kí wọ́n máa bàa rántí ilé mọ́, èyí kò sì ní jẹ́ kí wọ́n gbéjà ko àwọn tó rà wọ́n.
Wọ́n tún ṣe ohun ìrántí kan tí wọ́n fi ń rántí ahéré Zomaï, àmọ́ ahéré náà kò sí níbẹ̀ mọ́. Ohun tí Zomaï túmọ̀ sí ni òkùnkùn biribiri tó máa ń wà nínú ahéré tí wọ́n máa ń kó àwọn ẹrú sí, èyí tó má ń jẹ́ kí ipò táwọn ẹrú náà máa wà nínú ọkọ̀ òkun ti mọ́ wọn lára, níbi tí wọ́n á ti fún wọ́n pọ̀ mọ́ra, tó jẹ́ pé agbára káká ni wọ́n á fi lè yíra pa dà. Kódà, wọ́n ti lè kó wọn sínú ahéré yẹn fún ọ̀pọ̀ oṣù títí dìgbà tí ọkọ̀ tó máa kó wọn á fi dé. Ojú kan náà ni wọ́n máa ń da gbogbo àwọn tó bá kú sínú ipò ìnira náà sí.
Wọ́n ṣe ohun ìrántí kan síbẹ̀ tó ṣeni láàánú púpọ̀. Zomachi ni wọ́n ń pe ohun ìrántí náà, ohun tó sì dúró fún ni ìrònúpìwàdà àti ìpadàrẹ́. Ní oṣù January, lọ́dọọdún, àwọn àtọmọdọ́mọ àwọn ẹrú àti tàwọn tó ń ṣòwò ẹrú máa ń wá tọrọ ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ fún àwọn tó hu irú ìwà ìrẹ́jẹ burúkú yẹn.
Ibi tó gbẹ̀yìn ní ibi tí wọ́n ti ń ṣòwò ẹrú náà ni, Ẹnu Ọ̀nà Àrèmábọ̀, ohun ìrántí yìí dúró fún ìgbà táwọn ẹrú lò kẹ́yìn lórí ilẹ̀ Áfíríkà, kó tó di pé wọ́n kó wọn lọ sí òkè òkun. Àwòrán tí wọ́n mọ sára ẹnu ọ̀nà ńlá olóbìrìkìtì yìí ni, àwọn ọmọ ilẹ̀ Áfíríkà tí wọ́n fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ dè pa pọ̀, tí wọ́n wà ní ìlà méjì ní etí òkun Àtìláńtíìkì. Nígbà tí wọ́n kó àwọn ẹrú dé ẹnú ọ̀nà yìí, ipò àìnírètí tí wọ́n wà yìí mú kí àwọn kan lára wọn bu erùpẹ̀ sẹ́nu tí wọ́n sì jẹ ẹ́, kí wọ́n lè máa rántí ìlú ìbílẹ̀ wọn. Ńṣe ni àwọn míì dìídì fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ tí wọ́n fi dè wọn fún ara wọn lọ́rùn, tí wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀ gbẹ̀mí ara wọn.
Òmìnira Dé!
Láti ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1800, àwọn èèyàn sapá gidigidi láti fòpin sí òwò ẹrú. Ọkọ̀ tó gbẹ̀yìn tí wọ́n fi kó àwọn ẹrú gbéra láti ìlú Ouidah lọ sí orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ó sì gúnlẹ̀ sí ìlú Mobile, ní ìpílẹ̀ Alabama, ní July 1860. Àmọ́, kò pẹ́ táwọn ẹrú wọ̀nyí fi dòmìnira, torí pé ní ọdún 1863, ìjọba orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà kéde pé kí wọ́n dá àwọn ẹrú sílẹ̀. Ọdún 1888 ni òwò ẹrú dópin ní Ìwọ̀ Oòrùn Ìlàjì Ayé, nígbà tí orílẹ̀-èdè Brazil fòpin sí fífi àwọn àwọn èèyàn ṣe ẹrú.c
Ohun kan tí kò ṣeé gbàgbé nípa òwò ẹrú ni bí àwọn ọmọ ilẹ̀ Áfíríkà ṣe tú ká sí àwọn orílẹ̀-èdè míì káàkiri, èyí tó mú kí iye àwọn tó ń gbé ní àwọn orílẹ̀-èdè náà pọ̀ sí i, tí èyí sì tún ní ipa lórí àwọn àṣà ìbílẹ̀ ọ̀pọ̀ ilú lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríka. Ohun míì tí òwò ẹrú dá sílẹ̀ ni ẹ̀sìn voodoo, ìyẹn ẹ̀sìn kan tí wọ́n ti máa ń pidán tí wọ́n sì máa ń fi èèdì dini, èyí tó wọ́pọ̀ gan-an lórílẹ̀-èdè Haiti. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, Encyclopædia Britannica, sọ pé: “Ọ̀rọ̀ náà voodoo, wá látinú vodun, èyí tó túmọ̀ sí ọlọ́run, tàbí ẹ̀mí, ní èdè tí wọ́n ń pè ní, Fon táwọn kan ń sọ ní orílẹ̀-èdè Republic of Benin (ìyẹn ìlú Dahomey nígbà kan).”
Ó bani nínú jẹ́ pé, ìsìnrú tó burú gan-an ṣì ń ṣẹlẹ̀ lóde òní, bó tiẹ̀ jẹ́ pé irú ìsìnrú tá à ń sọ yìí tún yàtọ̀. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn ló ń ṣiṣẹ́ bí ẹrú nítorí àtirí ìwọ̀nba owó díẹ̀ gbọ́ bùkátà. Àwọ́n míì ń jìyà nítorí pé àwọn olóṣèlú tó ń ṣe ìjọba ń fi ayé ni wọ́n lára. (Oníwàásù 8:9) Ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn ló sì tún jẹ́ pé àwọn ẹ̀kọ́ èké àti ìgbàgbọ́ nínú ohun asán táwọn onísìn ń kọ́ wọ́n ni wọ́n fi mú wọn lẹ́rú. Ǹjẹ́ ìjọba èèyàn lè gba aráyé lọ́wọ́ irú àwọn ìsìnrú wọ̀nyí? Rárá o. Jèhófà Ọlọ́run nìkan ló lè ṣe é, ó sì máa ṣe bẹ́ẹ̀! Kódà, Ọlọ́run ṣèlérí nínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé, lọ́jọ́ kan, gbogbo àwọn tó bá ń sin òun lọ́nà tó bá àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì mu, ìyẹn òtítọ́ tó ń sọni dòmìnira, máa ní “òmìnira ológo ti àwọn ọmọ Ọlọ́run.”—Róòmù 8:21; Jòhánù 8:32.
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, iye àwọn ẹrú tó wà lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà bẹ̀rẹ̀ sí í pọ̀ sí i, nítorí pé, àwọn ẹrú náà bẹ̀rẹ̀ sí í bímọ.
b Oríṣiríṣi ọ̀nà ni wọ́n ń gbà kọ orúkọ náà, “Ghezo.”
c A ṣàlàyé ohun tí Bíbélì sọ nípa òwò ẹrú nínú àpilẹ̀kọ náà, “Ojú ìwòye Bíbélì: Ǹjẹ́ Ọlọ́run Fara Mọ́ Ṣíṣe Òwò Ẹrú?” nínú Jí! September 8, 2001.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
“ÈNÌYÀN TI JỌBA LÓRÍ ÈNÌYÀN SÍ ÌṢELÉṢE RẸ̀”
Ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà gbọ́ pé ńṣe làwọn tó ṣòwò ẹrú máa ń ya wọ àwọn abúlé tí wọ́n á sì jí ẹnikẹ́ni tí ọwọ́ wọn bá tẹ̀ gbé. Ó lè jẹ́ bẹ́ẹ̀ lóòótọ́ o, àmọ́ ọ̀jọ̀gbọ́n kan nípa ìtàn àwọn adúláwọ̀, Ọ̀mọ̀wé Robert Harms sọ nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan tó wáyé lórí rédíò pé, kò dájú pé àwọn tó ń ṣòwò ẹrú á lè kó ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn lẹ́rú “tí kì í bá ṣe pé àwọn aláṣẹ àtàwọn oníṣòwò kan pawọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn tó ń ṣòwò ẹrú náà.” Ẹ ò rí i pé òótọ́ pọ́ńbélé ni ohun tí Bíbélì sọ pé: “ènìyàn ti jọba lórí ènìyàn sí ìṣeléṣe rẹ̀.”—Oníwàásù 8:9.
[Credit Line]
© Réunion des Musées Nationaux/Art Resource, NY
[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 16]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
Wọ́n fojú bù ú pé, ó tó mílíọ̀nù méjìlá àwọn ọmọ ilẹ̀ Áfíríkà tí wọ́n kó lẹ́rú gba orí òkun Àtìláńtíìkì láti lọ fi ṣe iṣẹ́ àṣekára
ÁFÍRÍKÀ
BENIN
Ouidah
Etíkun tí wọ́n ti ń ṣòwò ẹrú
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]
Ọdún 1721 ni wọ́n kọ́ ọgbà àwọn ológun àwọn ara Portugal yìí, òun ló sì wá di ibi ìkóhun-ìṣẹ̀ǹbáyé-sí nílùú Ouidah lẹ́yìn tí wọ́n tún un kọ́
[Credit Line]
© Gary Cook/Alamy
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Ère ẹrú kan tí wọ́n fi okùn dè tí wọ́n sì fi nǹkan bò lẹ́nu
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Ẹnu Ọ̀nà Àrèmábọ̀—ohun ìrántí yìí dúró fún ìgbà táwọn ẹrú lò kẹ̀yìn lórí ilẹ̀ Áfíríkà
[Credit Line]
© Danita Delimont/Alamy