ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 7/11 ojú ìwé 13-15
  • Bí Mo Ṣe Jáwọ́ Nínú Ìwà Jàgídíjàgan

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bí Mo Ṣe Jáwọ́ Nínú Ìwà Jàgídíjàgan
  • Jí!—2011
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Mò Ń Wá Nǹkan Amóríyá
  • Mo Ṣe Iṣẹ́ Bòókẹ́lẹ́ Kan
  • Kò Rọrùn Láti Fi Ìwàkíwà Sílẹ̀
  • “Mo Di Ọmọọ̀ta”
    Bíbélì Máa Ń Yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà
  • ‘Níwọ̀n Bí A Ti Ní Iṣẹ́-òjíṣẹ́ Yìí, Àwa Kò Juwọ́sílẹ̀’
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Inú Mi Kì Í Dùn, Mo Sì Máa Ń Hùwà Ìpáǹle
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2016
  • Ó Ha Yẹ Kí Ọmọ Rẹ Lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Onílé Gbígbé Bí?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
Àwọn Míì
Jí!—2011
g 7/11 ojú ìwé 13-15

Bí Mo Ṣe Jáwọ́ Nínú Ìwà Jàgídíjàgan

Gẹ́gẹ́ bí Jose Antonio Nebrera ṣe sọ ọ́

KÍ LÓ mú kí ọkùnrin kan di oníjàgídíjàgan? Ìgbà tí mo ti wà lọ́mọdé ni mo ti kọ ohun púpọ̀ nípa ìwà jàgídíjàgan. Ọmọ ẹgbẹ́ Spanish civil guard ni bàbá mi, ìyẹn ẹgbẹ́ àwọn ọmọ ogun tó roro gan-an. Bàbá tó bí bàbá mi sábà máa ń fi ẹgba na bàbá mi, bàbá mi sì máa ń na èmi náà. Wọ́n máa ń fi bẹ́líìtì wọn tó nípọn lù mí. Yàtọ̀ sí lílù tí wọ́n máa ń lù mí, wọ́n tún máa ń pè mí ní ọ̀dẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì rèé, wọ́n fẹ́ràn àbúrò mi obìnrin gan-an. Màmá mi kì í fẹ́ rí ìbínú bàbá mi, àwọn náà ò sì ṣe nǹkan kan láti mú kí ìwà àìdáa tí bàbá mi ń hù sí mi yìí dín kù tàbí kí wọ́n tiẹ̀ fìfẹ́ hàn sí mi bí mo ṣe fẹ́.

Bí mo bá wà níléèwé pẹ̀lú àwọn ọmọ yòókù, mo máa ń fojú inú wò ó pé mo ń gbé nínú ayé kan tí mo ti láyọ̀ gan-an. Lójú àwọn èèyàn, ọmọ tó lọ́yàyà tó sì gbà pé nǹkan ń bọ̀ wá dáa ni mí. Àmọ́, ojú lásán nìyẹn. Ńṣe ni mo máa ń fi ẹ̀rù tó ń bà mí àti ìbínú mi pa mọ́. Àmọ́, tá a bá ti jáde iléèwé tí mo sì ń pa dà sílé, ẹ̀rù á tún bẹ̀rẹ̀ sí í bà mí, ṣé ti èébú ni ká sọ, àbí ti lílù tí wọ́n máa lù mí.

Nígbà tí mo pé ọmọ ọdún mẹ́tàlá, mo kúrò nínú ilé tí wọn ò ti fẹ́ràn mi yìí, mo sì lọ sílé ìwé àwọn àlùfáà Kátólíìkì tó ní ibùgbé fún àwọn ọmọléèwé. Ìgbà kan tiẹ̀ wà tí mo ronú pé kí n di àlùfáà. Àmọ́, irú ìgbésí ayé tá à gbé níléèwé yẹn, kò jẹ́ kí ìgbésí ayé mi dáa. A ní láti dìde ni aago márùn-ún àárọ̀, omi tútù la sì máa ń fi wẹ̀. Lẹ́yìn náà, á wá bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ látàárọ̀ ṣúlẹ̀, a óò gbàdúrà, a óò sì ṣe ìsìn, àkókò díẹ̀ la sì máa ń fi sinmi.

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ máa ń kà ìtàn àwọn “ẹni mímọ́,” kò sí Bíbélì nínú ìwé tá à ń kà. Inú gíláàsì kan ní wọ́n tọ́jú Bíbélì kan ṣoṣo tó wà sí, a sì ní láti gbàṣẹ ká tó lè kà á.

Ní ọdún kẹta tí mo lò ní iléèwé yìí, fífi ìyà jẹ ara wa wà lára ohun tá a máa ń ṣe, èyí tí wọ́n pè ní “eré ìmárale tẹ̀mí” a sì máa ń ṣe é déédéé. Mo gbìyànjú láti sáré jẹ oúnjẹ tó pọ̀ gan-an, kí n lè ṣàìsàn, kí n bàa lè bọ́ lọ́wọ́ fífi ìyà jẹ ara mi. Àmọ́, ọgbọ́n tí mo ta yìí kò ṣiṣẹ́. Lẹ́yìn nǹkan bí ọdún mẹ́ta tí mo délé ìwé yìí, ara mi ò gbà á mọ́. Mo sá kúrò ní iléèwé náà, mo sì pa dà sílé. Ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún ni mí nígbà yẹn.

Mò Ń Wá Nǹkan Amóríyá

Nígbà tí mo pa dà sílé, mo bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ẹ̀ṣẹ́ kíkàn àti ìjàkadì. Àṣeyọrí tí mo ṣe nídìí àwọn eré ìdárayá oníwà ipá yìí mú kí n rò pé èèyàn pàtàkì ni mí, torí pé mo jẹ́ akọni, tipátipá ni mo fi máa ń mú kí ọwọ́ mi tẹ ohunkóhun tí mo bá fẹ́, bí bàbá mi ti máa ń ṣe.

Àmọ́ nígbà tí mo pé ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún, ohun kan ṣẹlẹ̀ tó wá jẹ́ kí n dí èèyàn jẹ́jẹ́. Mo pàdé ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Encarnita, tí mo gbé níyàwó lẹ́yìn oṣù mẹ́sàn-án tá a mọra. Ó rí bí mo ṣe máa ń ṣọ́ra, tí mo jẹ́ onínúure tí mo sì máa ń láyọ̀. Kò mọ ìbànújẹ́ tó wà lọ́kàn mi lọ́hùn-ún. Ìbànújẹ́ yìí wá hàn síta gan-an, nígbà tí wọ́n fipá mú mi pé kí n wá wọṣẹ́ ológún lẹ́yìn tá a bí ọmọ wa àkọ́bí.

Nítorí pé mi ò fẹ́ gẹ irú irun táwọn ológun máa ń gẹ̀, kí n sì lè máa rìnrìn àjò káàkiri, mo gbà láti wọ ẹgbẹ́ ológún orílẹ̀-èdè Sípéènì tó wà nílẹ̀ òkèèrè, ìyẹn Spanish Foreign Legion. Gbogbo èrò mi ni pé máa ní òmìnira tí mo bá dé aṣálẹ̀ orílẹ̀-èdè Mòrókò, tí mo sì ń kópa nínú iṣẹ́ tó lè ṣekú pani. Bákan náà, ó jọ pé èyí jẹ́ kí n lè bọ́ lọ́wọ́ ojúṣe mi fún ìyàwó àti ọmọ mi. Àmọ́, lásẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, ńṣe ló wá sọ mí dìdàkudà.

Kò pẹ́ tí mo fi kó sí wàhálà lọ́dọ̀ àwọn ọ̀gágun tí wọ́n fẹ́ràn láti máa fìyà jẹ àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dẹ́nu iṣẹ́, òǹrorò ẹ̀dá ni wọ́n, wọ́n sì ṣe fìrìgbọ̀n. Mò kórìíra ìwà ìrẹ́jẹ, mo sì máa ń múra tán láti jà, tí wọ́n bá fi ẹ̀tọ́ mi dù mí. Láàárọ̀ ọjọ́ kan tí wọ́n ń pè wá jáde, mo dápàárá kan, àmọ́ ọ̀gá wa ṣì mí lóye. Bó ṣe gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè láti fi lù mí, mó yára gbá ọwọ́ náà mú, mo lọ́ ọ sẹ́yìn, mo sì ṣá a bálẹ̀. Mo tẹ ọwọ́ rẹ̀ mọ́lẹ̀ síbẹ̀, torí ẹ̀rù ń bà mí pé tí mo bá jẹ́ kó dìde ó máa yin ìbọn fún mi.

Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí mú kí wọ́n fìyà jẹ mí fún oṣù mẹ́ta. Inú yàrá kékeré kan tí kò sí ohunkóhun nínú rẹ̀ lèmi àtàwọn ọkùnrin tó tó nǹkan bí ọgbọ̀n ń gbé. Ní gbogbo àkókò yẹn, mi ò pààrọ̀ aṣọ mi. Ọ̀gá kan wà níbẹ̀ tó fẹ́ràn kó máa fi kòbókò na àwọn ọkùnrin náà. Àmọ́ lọ́jọ́ kan nígbà tí mo halẹ̀ mọ́ ọn pé màá pa á tó bá fọwọ́ kàn mí, ó wá dín ẹgba tèmi kù láti ọgbọ̀n sí mẹ́ta. Mo ti wá di ògbójú bíi tàwọn tó ń fìyà jẹ mí.

Mo Ṣe Iṣẹ́ Bòókẹ́lẹ́ Kan

Láàárín àkókò tí mo fi ń gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ láti di ara ẹgbẹ́ ọmọ ogun ilẹ̀-òkèèrè, mo fi ìwàǹwára yọ̀ǹda láti ṣe ohun tí mo ronú pé ó máa mú mi lórí yá. Bí èyí tí mo kọ́kọ́ ṣe, mi ò mọ ibi tí ìgbésẹ̀ yìí má yọrí sí fún mi. Mo gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ àkànṣe kan tí wọ́n máa ń fún àwọn ọmọ ogun, wọ́n kọ́ mi bí màá ṣe máa lo onírúurú ohun ìjà tó fi mọ́ àwọn àdó olóró. Nígbà tí ìdálẹ́kọ̀ọ́ náà parí, wọ́n rán mi lọ sí ìlú Langley, ní ìpínlẹ̀ Virginia, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, mo sì gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú àjọ àwọn ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ kan tí wọ́n ń pè ní CIA.

Kò pẹ́ tí mo fi di ara ẹgbẹ́ àwọn ọmọ ogun tó ń ṣiṣẹ́ ní bòókẹ́lẹ́. Láàárín ọdún 1960 sí 1969, mo lọ́wọ́ nínú ọ̀pọ̀ àwọn iṣẹ́ kan tá a ṣe ní bòókẹ́lẹ́. Mo wà lára àwọn tó lọ mú àwọn tó ń ṣe fàyàwọ́ oògùn olóró àti àwọn ohun ìjà ní Amẹ́ríkà Àárín àti Amẹ́ríkà ti Gúúsù. Nígbà tá a rí àwọn èèyàn yìí, wọ́n sọ fún wa pé ńṣe ni ká pa wọ́n. Ó tì mí lójú láti sọ pé mo lọ́wọ́ nínú irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀. Gbogbo àwọn tá a bá jà la pa dà nù, àyàfi àwọn díẹ̀ tá a mú láti fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò.

Nígbà tó yá, wọ́n yàn mí láti lọ ṣe amí àwọn ọmọ ogun Sípéènì, ká lè mọ àwọn tí kò sí lẹ́yìn ìjọba apàṣẹwàá tí Ọ̀gágun Franco ń ṣe. A tún ṣe amí àwọn alátakò ìjọba Franco tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Faransé. Ìdí tá a fi ń ṣe èyí ni pé ká lè jí àwọn alágbára tó wà láàárín wọn gbé, ká mú wọn lọ sí orílẹ̀-èdè Sípéènì, ká sì pa wọ́n dà nù.

Iṣẹ́ tí mo ṣe gbẹ̀yìn gba pé kí n ṣètò àwọn ẹgbẹ́ àwọn ọmọ ogun kan tó máa lọ fipá gbàjọba lórílẹ̀-èdè kékeré kan nílẹ̀ Áfíríkà. Wọ́n sọ fún wa pé ká ya wọ báráàkì àwọn ọmọ ogun tó wà ní olú ìlú náà lójijì, lẹ́yìn náà ká lọ gba ààfin ààrẹ orílẹ̀-èdè náà. Bá a ṣe gbèrò rẹ̀, a ya wọ orílẹ̀-èdè náà láàárín òru, a sì parí iṣẹ́ náà láàárín wákàtí mẹ́rin péré. Mẹ́ta lára àwọn tá a jọ lọ ló kú nínú ìjà náà, a sì pa ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn ọmọ ogun “ọ̀tá.” Èmi fúnra mi lọ́wọ́ nínú pípa àwọn ọmọ ogun náà.

Ìṣẹ̀lẹ̀ aburú yìí da ẹ̀rí ọkàn mi láàmú. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í lá àlákálàá, mo máa ń lálàá pé mò ń fọwọ́ ara mi pa àwọn ọmọ ogun ọ̀tá níbi tá a ti ń jà, mi ò sì ní lè sùn mọ́. Lójú àlá mi, mo máa ń rí bí ẹ̀rù ṣe máa ń ba àwọn èèyàn tí mo fẹ́ pa.

Mo wá pinnu pé mi ò tún ní lọ́wọ́ nínú ìjà míì mọ́. Torí náà, mo dá gbogbo ìwé mi pa dà fún àwọn ológun, mo sì ní kí wọ́n yọ̀ǹda mi. Oṣù mẹ́ta lẹ́yìn náà, ọ̀gá mi pè mí pé kí n wá báwọn ṣe amí àwọn ọ̀tá. Mo sá lọ sí orílẹ̀-èdè Switzerland, lóṣù mélòó kan lẹ́yìn náà, Encarnita, ìyàwó mi wá bá mi ní ìlú Basel, kò sì mọ ohunkóhun nípa iṣẹ́ ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ tí mò ń ṣe.

Kò Rọrùn Láti Fi Ìwàkíwà Sílẹ̀

Láàárín ọdún mẹ́ta tí mo fi wà lẹ́nu iṣẹ́ ológun, Encarnita, ìyàwó mi ti bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Sípéènì. Ó sọ fún mi pé òun ti mọ ohun tó jẹ́ òótọ́ nípa Ọlọ́run, ìtara rẹ̀ sì ran èmi náà. A yára wá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Switzerland, a sì bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pa pọ̀.

Inú mi dùn gan-an nígbà tí mo kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn láti ṣe. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo fẹ́ máa gbé ìgbé ayé tó bá ìlànà Bíbélì mu, ó ṣòro gan-an fún mi láti ṣe àwọn àyípadà tó yẹ, ní pàtàkì jù lọ lórí ti inú tó máa ń bí mi. Síbẹ̀, mo nífẹ̀ẹ́ sí ohun tí mò ń kọ́. Nígbà tí mo ti kẹ́kọ̀ọ́ fún nǹkan bí oṣù mélòó kan, mo yarí pé mo fẹ́ máa bá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ wàásù láti ilé dé ilé.

Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, mo wá dẹni tó ní ìkóra-ẹni-ní ìjánu, nígbà tó yá, èmi àti ìyàwó mi ṣe ìrìbọmi. Nígbà tí mo pé ọmọ ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n, wọ́n yàn mí láti jẹ́ alábòójútó nínú ìjọ.

Lọ́dún 1975, a pa dà sórílẹ̀-èdè Sípéènì. Àmọ́, àwọn ológun kò tíì gbàgbé mi, wọ́n tún pè mí pé kí n wá lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ àkànṣe kan. Kí n lè yẹra fún wàhálà, kò pẹ́ tí mo tún fi sá pa dà sí orílẹ̀-èdè Switzerland. Ibẹ̀ ni ìdílé wa ń gbé títí fi di ọdún 1996, tá a tún fi wá pa dà sí orílẹ̀-èdè Sípéènì.

Ní báyìí mo ni ọmọkùnrin kan àti ọmọbìnrin kan tí wọ́n ti ṣègbéyàwó àti ọmọ ọmọ méjì, gbogbo wọn ló ń sin Jèhófà. Síwájú sí i, mo ti láǹfààní láti ran àwọn èèyàn mẹ́rìndínlógún lọ́wọ́ láti mọ Jèhófà, tó fi mọ́ ọmọkùnrin kan tó ti lọ́wọ́ nínú ìjà ìgboro ní àríwá orílẹ̀-èdè Sípéènì. Èyí ti fún mi ní ìtẹ́lọ́rùn tí kò lẹ́gbẹ́.

Mo ti gbàdúrà sí Ọlọ́run lọ́pọ̀ ìgbà pé kò ràn mí lọ́wọ́ kí n lè mú ìwà jàgídíjàgan tí mo ti hù sẹ́yìn àti àlákálàá tí mo máa ń lá kúrò lọ́kàn. Bí mo ti ń sapá láti máa ṣe ohun tó tọ́, mo ti fi ìmọ̀ràn tó wà nínú Sáàmù 37:5 sílò, ó sọ pé: “Yí ọ̀nà rẹ lọ sọ́dọ̀ Jèhófà, kí o sì gbójú lé e, òun yóò sì gbé ìgbésẹ̀.” Jèhófà sì ti mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Ó ti ràn mí lọ́wọ́ láti jáwọ́ nínú ìwà jàgídíjàgan mi. Ìbùkún ńlá lèyí sì ti jẹ́ fún èmi àti ìdílé mi.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Èmi rèé lọ́mọ ọdún mẹ́tàlá nígbà ti mo lọ forúkọ sílẹ̀ nílé ìwé àwọn àlùfáà Kátólíìkì tó ní ibùgbé fún àwọn ọmọléèwé

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Mo fi ọ́fíìsì ẹgbẹ́ tó ń rí sí ọ̀ràn ilẹ̀ òkèèrè sílẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n yọ̀ǹda mi lọ́dún 1968

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Èmi àti ìyàwó mi Encarnita rèé ní báyìí

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́