ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w92 9/1 ojú ìwé 5-9
  • Ìkórè ti Kristẹndọm ní Africa

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìkórè ti Kristẹndọm ní Africa
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Gbígbin Awọn Irugbin Àìsí Ìṣọ̀kan
  • Ǹjẹ́ Kristian Ni Wọn Tabi Elérò Ẹ̀yà-Tèmi-Lọ̀gá Lati Europe?
  • Wọn Ṣakoso Gẹgẹ bi Ọba ni Africa
  • Awọn Ogun Agbaye
  • Igbagbọ Africa Ninu Awọn Babanla
  • Ohun Ti Kristẹndọm Ti Fúnrúgbìn ní Africa
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Àwọn Míṣọ́nnárì Ń Wàásù ní “Ibi Tó Jìnnà Jù Lọ ní Ayé”
    Bá A Ṣe Ń Ná Owó Tẹ́ Ẹ Fi Ń Ṣètọrẹ
  • Àrùn Aids Ní Áfíríkà—Báwo Ni Kirisẹ́ńdọ̀mù Ṣe Jẹ̀bi Rẹ̀ Tó?
    Jí!—1996
  • Kristẹndọm Ati Òwò Ẹrú
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
w92 9/1 ojú ìwé 5-9

Ìkórè ti Kristẹndọm ní Africa

ÀLÁ CHARLES Lavigerie ti yíyí Algeria pada di “orilẹ-ede Kristian” kan jásí bẹẹ gan-an—àlá kan. Lonii, ipin 99 ninu ọgọrun-un awọn olùgbé Algeria jẹ́ Musulumi, Kristẹndọm sì ti tubọ di alailagbara ni apa ti ó pọ julọ ni Ariwa Africa. Ṣugbọn ki ni nipa iyooku àgbáálá-ilẹ̀ naa?

”Isin Kristian,” ni Dr. J. H. Kane sọ, ninu A Concise History of the Christian World Mission, “ti yí awọn eniyan yii lọkan pada ni ilẹ Africa Adúláwọ̀ ju ni gbogbo iyooku Ayé Kẹta lapapọ.” Bi o ti wu ki o ri, ǹjẹ́ awọn ti a yí lọkan pada wọnyi jẹ́ Kristian nitootọ bi? Dr. Kane gbà pe, “Ewu ńlá kan ninu ṣọọṣi Africa jẹ́ lílú awọn èrò ati àṣà Kristian pọ̀ mọ́ ti abọriṣa.” Pẹlupẹlu, gbólóhùn-ọ̀rọ̀ rẹ̀ “ṣọọṣi Africa” jẹ́ orukọ tí kò yẹ kan. Ẹgbẹẹgbẹrun awọn ṣọọṣi Africa ni wọn wà niti gidi, olukuluku pẹlu ọ̀nà ìgbàjọ́sìn rẹ̀. Eeṣe?

Gbígbin Awọn Irugbin Àìsí Ìṣọ̀kan

Awọn irugbin àìsí ìṣọ̀kan ni a gbìn àní ṣaaju ki awọn ojihin-iṣẹ- Ọlọrun ni ilẹ ajeji tó bẹrẹ sii rinrin-ajo loju òkun wá si Africa. Ẹgbẹ́ Ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji ti London gba awọn mẹmba lati oriṣiriṣi awọn ṣọọṣi, ìjà gbigbona nipa ẹ̀kọ́ igbagbọ laaarin awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji sì wáyé loju ọ̀nà irin-ajo oju-omi si ibi ayanfunni wọn. Iforigbari ni ó daju pe yoo tubọ buru sii lẹhin ti wọn bá ti fidi kalẹ ni ibùdó iṣẹ ijihin-isin wọn.

Ọjọgbọn Robert Rotberg kọwe ninu iwe rẹ̀ Christian Missionaries and the Creation of Northern Rhodesia 1880 si 1924 pe, “Awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji bá araawọn ati awọn adarí wọn lókè òkun jà kíkankíkan, niye ìgbà sí ìwuléwu ète ti wọn ń jihinrere fun. . . . Awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji jọbii pe wọn ń lo iye akoko ati okun ti ó pọ̀ tó eyi ti wọn fi ń wá awọn ti a yí lọkanpada lati fi kọwe nipa awọn ìjà wọnyi.”

Nigba miiran, ìjà awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji yọrisi idasilẹ awọn eto isin abánidíje. Awọn ile-iṣẹ akanṣe ti Katoliki ati Protẹstant dije kíkankíkan fun awọn ti a yí lọkanpada. Àìsí iṣọkan kan-naa yii ni ó daju pe yoo farahan laaarin awọn ti wọn yí lọkan pada. Bi akoko ti ń lọ araadọta-ọkẹ awọn ará Africa fi awọn ṣọọṣi oniṣẹ ijihin-isin silẹ ti wọn sì dá ṣọọṣi tiwọn funraawọn silẹ.

“Awọn Ṣọọṣi Africa Adádúrólómìnira,” ni opitan ti o jẹ́ ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji Dr. Kane kọwe, “ni a lè rí ni gbogbo Africa . . . Lapapọ nǹkan bii ẹgbẹrun meje awujọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọn wà ninu awujọ idasilẹ yii.” Ibaradije laaarin awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji ti wọn ni igbagbọ ti ó takora kọ́ ni kìkì okunfa eyi. Ninu iwe rẹ̀ The Missionaries, Geoffrey Moorhouse ṣalaye pe okunfa miiran fun “ẹgbẹ́ alatun-un-ṣe adúláwọ̀” ni “ikunsinu lodisi ìlọ́lájù awọn oyinbo.”

Ǹjẹ́ Kristian Ni Wọn Tabi Elérò Ẹ̀yà-Tèmi-Lọ̀gá Lati Europe?

“Awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji ní ẹmi mo-lọ́lá-jù-ọ́-lọ,” ni Dr. Kane gbà. Wọn “gbagbọ pe isin Kristian gbọdọ lọ pẹlu aṣa ati ipo aṣiwaju ti Europe,” ni Adrian Hastings sọ ninu iwe rẹ̀ African Christianity.

Ọkunrin ará France naa Charles Lavigerie jẹ́ aṣaaju ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji kan ti o ní oju-iwoye yẹn. Ẹlomiran ni John Philip, alaboojuto awọn ẹ̀ka iṣẹ ijihin-isin ti Lon­don Missionary Society ni ìhà guusu Africa. Ó fọ́nnu ni 1828 pe, “Awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji wa ń mú . . . awọn ire Britain, agbara idari Britain, ati ilẹ-ọba Britain gbooro siwaju. Nibi yoowu ti ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji bá ti ń wá awọn ti wọn yoo yí lọkan pada laaarin awọn ẹ̀yà tí kò lajú, ẹ̀tanú wọn lodisi ijọba agbókèèrè ṣakoso ni yoo dawọduro; igbarale ijọba okeere wọn ni a mú pọ sii nipa dídá aini awúrúju silẹ; ile-iṣẹ ẹ̀rọ, ìṣòwò, ati àgbẹ̀ á rúyọ lojiji; olukululu ojulowo ẹni ti a yí lọkan pada laraawọn . . . yoo sì di alájọṣepọ̀ ati ọ̀rẹ́ ijọba agbókèèrè ṣakoso.”

Ó ha yanilẹnu rárá pe awọn ijọba Europe rí iru awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji bẹẹ gẹgẹ bi aṣoju ti ó wulo fun imugbooro ijọba agbókèèrè ṣakoso bi? Ni ìhà tiwọn, awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji tẹwọgba ijagunmolu ijọba agbókèèrè ṣakoso lori Africa. Gẹgẹ bi wọn ti polongo ni Àpérò Ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji Agbaye ti 1910 ni Edinburgh: Kì yoo . . . ṣeeṣe nigba gbogbo lati fi iyatọ saaarin ète ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ aje­ji ati ète ti Ijọba.”

Wọn Ṣakoso Gẹgẹ bi Ọba ni Africa

Lati jẹwọ ọla-aṣẹ wọn, awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji kan gbarale agbara ológun ti ijọba agbókèèrè ṣakoso. Awọn ìlú etí òkun ni awọn ọkọ̀ oju-omi ológun ti o ru ìbọn ti Britain maa ń wó lulẹ nigba miiran nitori pe awọn ará abúlé naa ti kọ̀ lati tẹwọgba ọla-aṣẹ ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji. Ni 1898, Den­nis Kemp, ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji ti isin Methodist kan si Iwọ-oorun Africa, sọ “idaniloju gbọnyingbọyin” rẹ̀ “pe Ọmọ-ogun ori-ilẹ ati ti oju-omi ti Britain ni Ọlọrun ń lò lonii fun ṣiṣaṣepari ète Rẹ̀.”

Lẹhin fifidii araawọn mulẹ, awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji ni ìgbà miiran a maa gba ipo agbara awọn olóyè ibilẹ ti ayé. “Awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji ti London,” ni Ọjọgbọn Rotberg kọwe “sábà maa ń lo ipá lati mú ki ofin atọrunwa tiwọn maa baa lọ. Ohun eelo àyànláàyò julọ nipasẹ eyi ti wọn gbà ń fi ìlòdìsíni wọn hàn ni cikoti, pàṣán gigun ti a fi awọ erinmi ṣe. Awọn ará Africa ni a ń nà pẹlu rẹ̀ laijafara lori ohun ti o fẹrẹẹ jẹ́ idi eyikeyii.” “Ará Africa kan ti a yí lọkan pada,” ni David Lamb sọ ninu iwe rẹ̀ The Africans, “sọyeranti ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji ti Anglika kan ni Uganda ti a mọ̀ si Bwana [Ọ̀gá] Botri ẹni ti ó sábà maa ń sọkalẹ lati ori apoti iwaasu nigba isin lati na awọn ará Africa ti wọn pẹ́lẹ́hìn.”

Bi iru awọn iṣe bẹẹ ti mú un wárìrì, ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji kan, James Mackay, fi ẹ̀sùn sùn lọdọ adari Ẹgbẹ́ Awujọ Ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji ti London. “Dipo ki wọn kà wá sí awọn ọkunrin alawọ funfun ti wọn mú ihinrere nipa ifẹ Ọlọrun wá fun wọn,” ni ó kilọ, “awa ni wọn mọ̀ ti wọn sì bẹru.”

Awọn Ogun Agbaye

Iwe naa The Missionaries sọ pe, “Fun ọrundun kan ati ju bẹẹ lọ, [Awọn ará Africa] ni a ti sọ fun lemọlemọ ati pẹlu agbara pe jíjà ati gbogbo ọgbọ́n inu oníka ti ó ń gbejade papọ jẹ́ alaileso ati ibi.” Lẹhin naa, ni 1914, Ogun Agbaye I bẹ́ silẹ laaarin awọn orilẹ-ede ti a ń fẹnu lasan pe ni Kristian ti Europe.

“Awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji ti eyi tí ó fẹrẹẹ jẹ́ ti gbogbo orilẹ-ede ni a yí lero pada lati kowọnu Ogun Ńlá naa,” ni Moorhouse ṣalaye. Sí itiju wọn, awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji rọ awọn ará Africa ti wọn yí lọkàn pada lati gbeja. Awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji kan tilẹ ṣaaju awọn ọ̀wọ́-ogun Africa wọnu ija-ogun. Iyọrisi ogun naa ni a sọ daradara lati ẹnu Ọjọgbọn Stephen Neill ninu iwe rẹ̀ History of Christian Mis­sions: “Awọn orilẹ-ede Europe, pẹlu ifigberara wọn jẹwọ níní àdáni lori isin Kristian ati ọ̀làjú, ti fi ìkùgbù ati pẹlu idarudapọ kówọnú ogun abẹ́lé kan eyi ti yoo sọ wọn di alaini niti iṣunna-owo ati laisi ìwà-ẹni-abíire ti ó kere jù.” Neill ń baa lọ pe, “Ogun Agbaye Keji wulẹ pari ohun ti èkìnní ti ṣaṣepari rẹ̀ ni. Ìdíbọ́n iwarere ti iwọ-oorun ni a fihàn pe ó jẹ́ ẹ̀tàn; ‘Kristẹndọm’ ni a túfó gẹgẹ bi eyi ti kò ju àlọ́ kan lọ. Kò ṣeeṣe mọ́ lati sọrọ nipa ‘Iwọ-oorun ti ó jẹ́ ti Kristian.’”

Lọna tí ó ṣee yéni, ẹgbẹ́ alátùn-ún-ṣe adúláwọ̀ tẹsiwaju lẹhin Ogun Agbaye I. Ṣugbọn ki ni nipa awọn ará Africa ti wọn dìrọ̀ mọ awọn ṣọọṣi Kristẹndọm? A ha fi otitọ lati inu Bibeli kọ́ wọn lẹhin ìgbà naa bi?

Igbagbọ Africa Ninu Awọn Babanla

Awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji ti Kristẹndọm bu ẹnu àtẹ́ lu awọn iṣe-aṣa onisin ti Africa, iru bii lilọ sọdọ adáhunṣe lati tu awọn babanla ti ó ti kú loju. Lakooko kan-naa, awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji naa tẹnumọ ọn pe gbogbo eniyan ní aileku ọkàn kan. Wọn tun gbé ìkúnlẹ̀bọ Maria ati “awọn ẹni mimọ” larugẹ. Awọn ẹ̀kọ́ wọnyi jẹ́rìí si igbagbọ Africa pe awọn babanla ti wọn ti kú walaaye. Pẹlupẹlu, nipa kíkúnlẹ̀bọ awọn ere onisin, iru bii agbelebu, awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji dá lílo awọn ońdè gẹgẹ bi aabo kuro lọwọ awọn ẹmi buburu láre.

Ọjọgbọn C. G. Baëta ṣalaye ninu iwe rẹ̀ Christianity in Tropical Africa pe: “Ó ṣeeṣe fun ọmọ Africa kan lati fi ìtara kọ orin ‘Ibi ìsádi miiran ni emi kò ni,’ ninu Ṣọọṣi, nigba ti ó ṣì ń so ońdè kan mọ́ra, tabi ki ó jade taarata kuro ninu Ṣọọṣi lọ sọdọ adáhunṣe rẹ̀, laini imọlara pe oun ṣe aiṣootọ si ilana kankan.”—Fiwe Deuteronomi 18:10-12 ati 1 Johannu 5:21.

Ọpọlọpọ ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji sọ fun awọn ọmọ Africa pe awọn babanla wọn alaigbagbọ ni a ń daloro ninu hell onina ati pe kadara kan-naa yoo ṣẹlẹ si wọn bi wọn bá kọ̀ lati tẹwọgba ẹ̀kọ́ awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji. Ṣugbọn ẹ̀kọ́ idaloro ayeraye forigbari pẹlu awọn gbolohun-ọrọ kedere ti o wà ninu Bibeli gan-an tí awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji ti lo iru isapa ti o pọ tobẹẹ lati tumọ si awọn èdè Africa.—Genesisi 3:19; Jeremiah 19:5; Romu 6:23.

Nitootọ, Bibeli wi pe awọn ọkàn eniyan ẹlẹṣẹ ń kú ati pe “awọn òkú kò mọ ohun kan.” (Oniwasu 9:5, 10; Esekieli 18:4) Niti awọn ará Africa ti wọn kò ni anfaani lati gbọ́ otitọ Bibeli, wọn ni ifojusọna ti níní ìpín ninu “ajinde . . . ati ti oloootọ, ati ti alaiṣootọ” ti ń bọ̀. (Iṣe 24:15) Iru awọn ẹni ti a jí dide bẹẹ ni a o kọ́ nipa ipese Ọlọrun fun igbala. Lẹhin naa, bi wọn bá dahunpada lọna onimọriri si ifẹ Ọlọrun, awọn ni a o san ẹsan ìyè ainipẹkun lori paradise ilẹ̀-ayé fun.—Orin Dafidi 37:29; Luku 23:43; Johannu 3:16.

Dipo kikọni ni awọn ẹ̀kọ́ agbayanu otitọ Bibeli wọnyi, Kristẹndọm ti ṣi awọn ará Af­rica lọ́nà nipa awọn ẹ̀kọ́ èké ati agabagebe ti isin. Dajudaju, ipa ti awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji ti Kristẹndọm kó ninu ijagunmolu ti ijọba agbókèèrè ṣakoso lori Africa kò rí itilẹhin kankan ninu Bibeli. Ni odikeji, Jesu sọ pe Ijọba oun “kì í ṣe ti ayé yii” ati pe awọn ọmọlẹhin oun tootọ kì yoo jẹ́ “apakan ayé” bakan-naa. (Johannu 15:19; 18:36) Awọn Kristian ijimiji jẹ́ ikọ̀ fun Jesu Kristi, kì í ṣe fun ijọba ayé.—2 Korinti 5:20.

Fun idi yii, ìkórè ti Kristẹndọm ní Africa lodindi jẹ́ onibanujẹ kan, tí a mọ̀ fun àìsí ìṣọ̀kan, àìsí ìfọkàntán, ati “Lílú awọn èrò ati àṣà Kristian pọ̀ mọ́ ti abọriṣa” buburu jai. Ìwà-ipá ti ó ti sàmì sí ọpọlọpọ apá ti ó jẹ́ ti “Kristian” ni Africa ni kò wà ni ibamu pẹlu awọn ẹ̀kọ́ “Ọmọ-Alade Alaafia.” (Isaiah 9:6) Awọn eso iṣẹ Kristẹndọm ní Africa jẹ́ odikeji patapata gbáà si awọn ọ̀rọ̀ Jesu nipa awọn ọmọlẹhin rẹ̀ tootọ. Ninu adura si Baba rẹ̀ ọ̀run, Jesu beere pe ki “á lè ṣe wọn pe ni ọ̀kan; ki ayé ki o lè mọ̀ pe, iwọ ni ó rán mi.”—Johannu 17:20, 23; 1 Korinti 1:10.

Eyi ha tumọsi pe gbogbo iṣẹ ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji ni Africa ni ó ti jasi pàbó bi? Kí a má rí i. Àwọn eso rere iṣẹ ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji ti Kristian tootọ ni Africa ati jakejado ayé ni a jiroro ninu awọn ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ ti yoo bẹrẹ ni oju-iwe 10.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

Awọn aṣaaju ojihin-iṣẹ Ọlọrun ti ọrundun ti ó kọja, iru bii John Philip, gbagbọ pe ọ̀làjú Europe ati isin Kristian jẹ́ nǹkankan-naa

[Credit Line]

Cape Archives M450

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji ti Kristẹndọm fun igbagbọ Africa ninu awọn babanla niṣiiri nipa titan awọn ẹ̀kọ́ ti kò bá Bibeli mu, iru bii aileku ọkàn kalẹ

[Credit Line]

Courtesy Africana Museum, Johannesburg

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́