ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w92 9/1 ojú ìwé 3-4
  • Ohun Ti Kristẹndọm Ti Fúnrúgbìn ní Africa

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ohun Ti Kristẹndọm Ti Fúnrúgbìn ní Africa
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Awọn Eso Ojihin-Iṣẹ-Ọlọrun Ni Ilẹ Ajeji
  • Ìkórè ti Kristẹndọm ní Africa
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Àwọn Míṣọ́nnárì Ń Wàásù ní “Ibi Tó Jìnnà Jù Lọ ní Ayé”
    Bá A Ṣe Ń Ná Owó Tẹ́ Ẹ Fi Ń Ṣètọrẹ
  • Àrùn Aids Ní Áfíríkà—Báwo Ni Kirisẹ́ńdọ̀mù Ṣe Jẹ̀bi Rẹ̀ Tó?
    Jí!—1996
  • Kristẹndọm Ati Òwò Ẹrú
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
w92 9/1 ojú ìwé 3-4

Ohun Ti Kristẹndọm Ti Fúnrúgbìn ní Africa

NI 1867, Charles Lavigerie, ará France onisin Katoliki kan, wá si Africa gẹgẹ bi biṣọọbu àgbà titun ti a ṣẹṣẹ yàn fun Algiers. “Ọlọrun ti yan France,” ni ó sọ, “lati sọ Algeria di ìpìlẹ̀ orilẹ-ede ńlá ati orilẹ-ede Kristian.”

Àlá Lavigerie gbooro kọja Algeria. Nitootọ, ó rán awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji rekọja aṣálẹ̀ pẹlu gongo “síso Aarin-gbùngbùn ati Ìhà-Ariwa Africa pọ̀ mọ́ igbesi-aye ti Kristẹndọm ń ṣajọpin rẹ̀ ni gbogbogboo.”

Laaarin akoko naa, ní awọn apá ìhà iwọ-oorun, guusu, ati ila-oorun àgbáálá-ilẹ̀ naa, awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji Protẹs- tant ti wà lẹnu iṣẹ ní pẹrẹwu. Wọn fàyàrán ọpọlọpọ inira, iru bii ìkọlù àrùn ibà láti-ìgbà-dé-ìgbà, pẹlu àmì rẹ̀ ti gbígbọ̀n, lílàágùn, ati ìrànrán. Ọpọlọpọ kú laipẹ lẹhin ti wọn dé bi awọn aisan ilẹ olooru ti tètè sọ wọn di alailera. Ṣugbọn awọn miiran dé sii laidawọduro. Adlai Stevenson sọ pe, “Ẹnikẹni ti ó bá rinrin-ajo ni Africa, ni a ń ran létí lemọlemo nipa ìwà akọni awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji. . . . Wọn bá ibà-pọ́njú, ìgbẹ́-ọ̀rìn, aisan ti aràn ń fà jà . . . mo sì rí . . . awọn okuta-iboji wọn—jakejado gbogbo Africa.”

Awọn Eso Ojihin-Iṣẹ-Ọlọrun Ni Ilẹ Ajeji

Bi awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji ti wọnu Africa, wọn rí i pe ọpọ julọ awọn ẹ̀yà ni wọn jẹ́ alaimọọkọ-mọọka. “Ninu iye ti ó fẹrẹẹ jẹ́ ẹgbẹrin èdè [Africa],” ni Ram Desai ṣalaye ninu iwe rẹ̀ Christianity in Africa as Seen by Africans, “mẹrin pere ni ó wà ní kíkọ ṣaaju dídé awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji.” Nitori naa awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji hùmọ̀ ọ̀nà kíkọ awọn èdè ti a kò kọ wọnyi. Lẹhin naa wọn ṣe awọn ìwé-ẹ̀kọ́ wọn sì bẹrẹ sii kọ́ awọn eniyan bí a tií kàwé. Fun ète yẹn wọn kọ́ awọn ilé-ẹ̀kọ́ jakejado Africa.

Awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji naa tún kọ́ awọn ile-iwosan. “Kò sí eto awujọ miiran ti ó lè bá akọsilẹ iṣẹ afẹ́nifẹ́re wọn dọgba,” ni Ram Desai jẹwọgba. Yatọ si abojuto iṣegun, awọn ará Africa lepa awọn ohun títà lati Europe. Awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji kan dá ìsọ̀ òwò silẹ, bi wọn ti gbagbọ pe eyi yoo fa awọn ti a yí lọkan pada mọra. Fun apẹẹrẹ, Basel Mission lati Switzerland fidii ile-iṣẹ òwò kan mulẹ ni Ghana. Wọn ṣawari pe igi kòkó ń dagba daradara nibẹ, ati lonii Ghana ni olùgbìn kòkó ti ó pọ julọ kẹta ni ayé.

Aṣeyọri titayọ kan ti awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilẹ ajeji ti Kristẹndọm ni ṣiṣe tí wọn ṣe itumọ Bibeli. Sibẹ títan ihin-iṣẹ Bibeli kalẹ mú ẹrù-iṣẹ́ pataki siwaju sii dani. Kris­tian aposteli Paulu fi eyi hàn nipa bibeere pe: “Ǹjẹ́ iwọ ti o ń kọ́ ẹlomiran, iwọ kò kọ́ ara rẹ? iwọ ti o ń waasu ki eniyan ki ó má jale, iwọ ń jale?” Bibeli kilọ pe awọn wọnni ti wọn ń kọni ni isin Kristian gbọdọ doju ìlà awọn ilana rere ti a lana wọn ninu Ọ̀rọ̀ Ọlọrun funraawọn.—Romu 2:21, 24.

Ki ni nipa ti iṣẹ ijihin-isin Kristẹndọm si Africa? Ó ha ti bọla fun Ọlọrun Bibeli, tabi ṣèké si awọn ẹ̀kọ́ Kristian bi?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́