Irisi Ìran Lati Ilẹ Ileri
Jẹ Ounjẹ Kan Jẹ Burẹdi
NI AKOKO iṣẹlẹ kan nigba ti Jesu ati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wà ninu ile kan, “wọn kò tilẹ lè jẹ ounjẹ” nitori ọpọ ero naa. (Marku 3:20) Ni akoko miiran Jesu wọle Farisi kan “lati jẹun.” (Luku 14:1) Iru ounjẹ wo ni o wá sí ọkàn rẹ?
Awọn ọmọ Israeli igbaani ni o ṣeeṣe ki wọn ronu nipa burẹdi nitori pe ọ̀rọ̀ Hebreu ati Griki fun “jẹ ounjẹ” tumọ ni olowuuru si “jẹ burẹdi.” Eyi ṣee loye, niwọn bi burẹdi ti a fi alikama tabi ọkà barle ṣe ti jẹ́ apa ṣiṣe pataki julọ ninu ounjẹ wọn.
Ọpọlọpọ lonii maa ń ronu pe awọn babanla Heberu je oluṣọ agutan, pe awọn ọmọ-ẹhin Jesu jẹ́ apẹja. Awọn kan ṣe iru iṣẹ yẹn ṣugbọn ó daju ṣáká pe kì í ṣe gbogbo wọn. Alikama gbígbìn jẹ́ igbesi-aye ọpọlọpọ. Lọna híhàn gbangba iyẹn jẹ bẹẹ pẹlu Isaaki ati Jakọbu nigba miiran, gẹgẹ bi a ti lè loye rẹ̀ lati inu Genesisi 26:12; 27:37; ati 37:7. Niwọn bi o sì ti jẹ pe iṣẹ àgbẹ̀ ni iṣẹ amuṣe ṣiṣe pataki julọ ni Galili ni akoko Jesu, o ha ṣeeṣe ki diẹ lara awọn ti o di aposteli ti jẹ olùgbin alikama tẹlẹri bi?
Siṣeeṣe naa wà, nitori ṣiṣe ọgbin alikama wọ́pọ̀ ni Ilẹ Ileri, itọka Bibeli sí i sì pọ̀. (Deuteronomi 8:7-9; 1 Samueli 6:13) Ki ni ohun ti ó mú lọwọ?
Lẹhin ti òjò àkọ́rọ̀ ni October ati November bá ti mu kì ílẹ dẹ, àgbẹ̀ alalikama yoo túlẹ ti yoo sì gbin eso rẹ̀. Òjò àrọ̀kẹ́hìn yoo sì ṣeranwọ lati mu ki ọgbin rẹ̀ dagba ati lẹhin naa, ni April ati May, yoo di pípọ̀n bii àwọ̀ rẹ́súrẹ́sú ṣaaju ooru ìgbà ẹ̀rùn. Kikore alikama jẹ́ ohun ti a mọ daradara tobẹẹ ti iwọ kà nipa rẹ̀ gẹgẹ bi atọka ìgbà. (Genesisi 30:14; Onidajọ 15:1) Iwọ ha lè pinnu ìgbà wo ninu ọdun ni yaworan fọto ti o wà ni apá-òsì bi?a Ìgbà wo ni o sì jẹ́ nigba ti awọn ọmọ-ẹhin fi já awọn hóró alikama ti a kò sè?—Matteu 12:1.
Kikore alikama tumọsi ọpọlọpọ iṣẹ fun awọn àgbẹ̀. Awọn olùkórè yoo gé pòròpórò naa pẹlu dòjé ti wọn yoo sì dì wọn ni ìtì, gẹgẹ bi o ti lè rí i nisalẹ yii. Niti gidi awọn pòròpórò kan ni a lè foju foda tabi wọn lè gbọ̀n silẹ, eyi sì ni idi rẹ̀ ti Rutu fi lè pèéṣẹ́ lọna alaṣeyọrisirere. (Rutu 2:2, 7, 23; Marku 4:28, 29) Awon ìtì alikama ni a kó lọ si ilẹ ìpakà lẹhin naa, bii ti Araunna. Ki ni o ṣẹlẹ nibẹ? Bibeli mẹnuba “ohun eelo ìpakà ati ohun eelo miiran ti maluu fun igi.” (2 Samueli 24:18-22; 1 Kronika 21:23) Awọn ìtí ni a ń tẹ́ silẹ lori agbegbe ori okuta titẹju tabi ilẹ lile paali. Maluu tabi ẹranko miiran yoo lọ yipo-yipo, ni gígún alikama naa mọlẹ. Ẹrankọ naa lè maa fa olùgbóńgbó onigi kan ti yoo ṣeranwọ lati fọ́ pòròpórò gbigbẹ naa ki awọn wóró alikama sì yọ jade.—Isaiah 41:15.
Nigba naa o ti ṣetan fun fífẹ́, eyi ti a ń ṣe nipasẹ fifi ṣọ́bìrì tabi àmúga fẹ́ẹ soke ninu afẹfẹ gẹgẹ bi a ti lè rí i loke yii. (Matteu 3:12) Àgbẹ̀ naa lè fẹ́ ni alẹ́ nigba ti ìgbì afẹfẹ yoo gba iyangbo (eepo ẹhin hóró) ati pòròpórò naa sẹgbẹẹkan. Gbàrà ti a bá ti kó hóró irugbin jọ ti a sì fi ajọ̀ jọ̀ ọ́ lati mu awọn okuta keekeeke eyikeyi kuro, o ti wa ni sẹpẹ́ fun titọju pamọ—tabi fun sise ounjẹ ṣiṣe pataki gidi yẹn, burẹdi.—Matteu 6:11.
Bi iwọ bá jẹ́ iyawo ile pẹlu iru iṣẹ-opo yẹn, ni ojumọ kọọkan iwọ yoo lo odó ati ọmọrí-odó lati gún hóró alikama naa si iyẹfun, boya iyẹfun alikama ti kò fi bẹẹ kúná. Tabi boya iwọ nilati gun “iyẹfun daradara,” bii iru eyi ti Sara lo lati fi ṣe “akara” fun awọn angẹli ti wọn gbé ara wọ̀ tabi eyi ti awọn ọmọ Israeli lò ninu ọrẹ-ẹbọ ohun jijẹ si Jehofa. (Genesisi 18:6; Eksodu 29:2; Lefitiku 2:1-5; Numeri 28:12) Sara fi omi si iyẹfun alikama naa ó sì pò ó di iyẹfun pípò.
Nisalẹ yii, iwọ lè rí awọn ìṣù rìbìtì iyẹfun pípò ati ọ̀kan fẹlẹfẹlẹ pẹlẹbẹ ti a tò silẹ fun sísè. Iru awọn akara titobi roboto bẹẹ ni a lè dín lori awọn okuta tabi agbada, gẹgẹ bi obinrin naa ti ń ṣe. Eyi ha ràn ọ́ lọwọ lati foju inu wo ohun ti Sara ṣe fun awọn angẹli alejo naa ati ohun ti idile Loti ṣe lẹhin naa bi? Awa kà pe: “[Awọn angẹli] sì yà tọ̀ ọ́, wọn sì wọ inu ilẹ rẹ̀; ó sì se àsè fun wọn, ó sì dín akara alaiwu fun wọn, wọn si jẹ.”—Genesisi 19:3.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fiwe 1992 Calendar of Jehovah’s Witnesses.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 24]
Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 24]
Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 25]
Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 25]
Garo Nalbandian