ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | MÁTÍÙ 12-13
Àkàwé Àlìkámà àti Èpò
Jésù lo àlìkámà àti èpò láti ṣàpèjúwe bí òun ṣe máa yan àwọn ẹni àmì òróró tó dúró fún àlìkámà láti ara aráyé, bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 33 Sànmàní Kristẹni.
‘Ọkùnrin kan fún irúgbìn àtàtà sínú pápá rẹ̀’
Afúnrúgbìn: Jésù Kristi
Ó fún irúgbìn àtàtà: Ó fi ẹ̀mí mímọ́ yan àwọn ọmọ ẹ̀yìn
Pápá: Ayé
“Nígbà tí àwọn ènìyàn ń sùn, ọ̀tá wá fún èpò sínú pápá”
Ọ̀tá: Èṣù
Àwọn èèyàn ń sùn: Ikú àwọn àpọ́sítélì
“Ẹ jẹ́ kí àwọn méjèèjì dàgbà pa pọ̀ títí di ìkórè”
Àlìkámà: Àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró
Èpò: Àwọn Kristẹni afàwọ̀rajà
“Ẹ kọ́kọ́ kó àwọn èpò jọ . . . ; lẹ́yìn náà ẹ lọ kó àlìkámà jọ”
Àwọn ẹrú tàbí akárúgbìn: Àwọn áńgẹ́lì
Èpò tí wọ́n kó jọ: Wọ́n ya àwọn Kristẹni afàwọ̀rajà kúrò lára àwọn ẹni àmì òróró
Kíkójọ sínú ilé ìtọ́jú-nǹkan-pa-mọ́: Wọ́n kó àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró jọ sínú ìjọ tá a mú pa dà bọ̀ sípò
Nígbà tí ìkórè bẹ̀rẹ̀, kí ló mú kí àwọn Kristẹni tòótọ́ yàtọ̀ sí àwọn Kristẹni afàwọ̀rajà?
Àǹfààní wo ni mo rí nínú ìtumọ̀ àkàwé yìí?