ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w92 11/1 ojú ìwé 21-22
  • Ọkunrin Ọ̀mọ̀wé Kan

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọkunrin Ọ̀mọ̀wé Kan
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ọmọ-ibilẹ Tarsu
  • Ọlọ̀tọ̀ Romu
  • Oju-iwoye Titọna Kan
  • Àwọn Ìbùkún Ìjọba náà Lè Jẹ́ Tìrẹ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • “Ẹ Gbọ́ Ẹjọ́ Tí Mo Fẹ́ Rò fún Yín”
    “Jẹ́rìí Kúnnákúnná Nípa Ìjọba Ọlọ́run”
  • À Ń Gbèjà Ìhìn Rere Níwájú Àwọn Aláṣẹ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2016
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
w92 11/1 ojú ìwé 21-22

Ọkunrin Ọ̀mọ̀wé Kan

“ẸSA wo ìpè yin, ará, bi o ti ṣe pe kìí ṣe ọpọ awọn ọlọgbọn eniyan nipa ti ara, kìí ṣe ọpọ awọn alagbara, kìí ṣe ọpọ awọn ọlọla ni a pe.” (1 Korinti 1:26) Gẹgẹ bi awọn ọ̀rọ̀ wọnyi ti fihàn, ewu wà ninu didi ẹni ti ó rì wọ́nú ọgbọn ti ayé tabi níní ipo ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà giga. Iru awọn nǹkan bẹẹ lè jẹ́ ìdènà fun titẹwọgba ti ẹnikan yoo tẹwọgba ihinrere.—Owe 16:5; Marku 10:25.

Sibẹ, ni ọjọ Paulu awọn kan ti wọn jẹ́ ọlọgbọn ni ọ̀nà ti ara tẹwọgba otitọ, ọkàn lara awọn wọnyi sì ni Paulu funraarẹ. Bi o ti jẹ́ ọmọwe tí ó yááyì ti ó sì dabi ẹni pe ó wá lati inu idile ti ó yọri-ọla, Paulu jẹ́ ajihinrere onitara. Ó tipa bayii fihàn pe awọn ti wọn lanfaani ni ayé yii lè ṣiṣẹsin Jehofa bi ọkan-aya wọn bá tọ́. Wọn tilẹ lè lo òye ti ayé ti wọn ni ninu iṣẹ-isin Jehofa.—Luku 16:9.

Ọmọ-ibilẹ Tarsu

Paulu ni a bi ni Tarsu, “ilu ti kìí ṣe ilu lasan kan,” gẹgẹ bi oun ti ṣapejuwe rẹ̀ lẹhin naa. (Iṣe 21:39) Ó ṣeeṣe kí ó jẹ́ pe ibẹ ni oun ti jere ìmọ̀ èdè—ni pataki mímọ èdè Griki sọ—ti ó ṣeyebiye ninu iṣẹ ijihin-iṣẹ-Ọlọrun rẹ̀. Igbesi-aye ni Tarsu yoo ti ṣí oju Paulu payá si kìí ṣe kìkì ọ̀nà awọn Ju bikoṣe si aṣa Keferi pẹlu, iriri ti ó lò ni awọn ọdun ẹhin ìgbà naa gẹgẹ bi aposteli fun awọn orilẹ-ede. Ó mọ bi oun ṣe lè ṣalaye otitọ ni ọ̀nà ti yoo gbà yé wọn. (1 Korinti 9:21) Gẹgẹ bi apẹẹrẹ kan, gbé ọ̀rọ̀ sisọ rẹ̀ fun awọn ará Ateni ti a rohin ni Iṣe ori 17 yẹwo. Nibẹ, oun fi ìjáfáfá wé awọn itọka sí isin ilu Ateni ati ọ̀rọ̀ kan ti ó fayọ lati inu iwe eléwì wọn kan mọ́ igbekalẹ-ọrọ otitọ rẹ̀.

Ọlọ̀tọ̀ Romu

Paulu ní anfaani ti ayé miiran. Ó jẹ́ ọlọ̀tọ̀ Romu, ó sì lo eyi pẹlu fun mimu ihinrere naa tẹsiwaju. Ni ilu Filippi, oun ati awọn ẹlẹgbẹ rẹ̀ ni a nà ti a sì sọ sẹ́wọ̀n láìgbẹ́jọ́. Kò bá ofin mu lati ṣe eyi fun ọlọ̀tọ̀ Romu, nigba ti Paulu sì mú otitọ yii wá sí afiyesi awọn alaṣẹ, wọn fun un láàyè lati duro ki ó sì ṣe ojiṣẹ fun ijọ ṣaaju ki ó tó lọ si ibi tí ó kàn.—Iṣe 16:37-40.

Lẹhin naa, nigba ti ó ń farahan niwaju Gomina Festu, Paulu lo anfaani ipo ọlọ̀tọ̀ Romu rẹ̀ lati pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn rẹ̀ si Kesari. Nipa bayii, ó gbeja ihinrere niwaju alaṣẹ ti o ga julọ ni Ilẹ-ọba Romu.—Iṣe 25:11, 12; Filippi 1:7.

Paulu gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ lọna iṣẹ ṣiṣe ti ó wá jasi eyi ti ó wulo lẹhin naa. Oun ni a kọ́ ni àgọ́-pípa, ó ṣeeṣe ki ó jẹ́ baba rẹ̀ ni o kọ́ ọ. Ọpẹlọpẹ eyi, oun lè tọju araarẹ̀ ninu iṣẹ-ojiṣẹ naa nigba ti owó-àkànlò bá fẹ́ri. (Iṣe 18:1-3) Ó tun gba ẹkọ-iwe isin lojumejeeji. Oun ni a tọ́ dagba gẹgẹ bii “Farisi . . ., ọmọ Farisi.” (Iṣe 23:6) Nitootọ, ó kẹkọọ ni ẹsẹ Gamalieli, ọ̀kan lara awọn olukọ Ju ti ó lokiki julọ. (Iṣe 22:3) Iru ẹkọ-iwe bẹẹ, boya ni afiwe pẹlu ẹkọ-iwe yunifasiti lonii, tumọsi pe idile rẹ̀ yọri-ọla daadaa.

Oju-iwoye Titọna Kan

Ipilẹ igbesi-aye Paulu ati ìdánilẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ pese ọjọ-ọla dídán yanran kan ninu isin awọn Ju. Oun ìbá ti lọ jinna. Bi o ti wu ki o ri, gbàrà ti o gbà pe Jesu ni Messia naa, gongo ilepa Paulu yipada. Nigba ti ó ń kọwe si awọn ará Filippi, ó ṣe itolẹsẹẹsẹ diẹ lara awọn anfaani ti ó ni tẹlẹ ninu ayé ó sì wi pe: “Ohunkohun ti o ti jasi èrè fun mi, awọn ni mo ti kà sí òfo nitori Kristi. Nitootọ laiṣe àní-àní mo sì ka ohun gbogbo si òfo nitori itayọ ìmọ̀ Kristi Jesu Oluwa mi.”—Filippi 3:7, 8.

Ọkunrin ọmọwe yii kò fi ìyánhànhàn bojuwẹhin wo ohun ti oun ìbá ti ṣe pẹlu ẹkọ-iwe ti ayé rẹ̀; bẹẹ ni oun kò lo “ẹ̀kọ́ àkọ́jù” lati kó awọn ẹlomiran láyà jẹ. (Iṣe 26:24; 1 Korinti 2:1-4) Dipo bẹẹ, ni fifi igbagbọ kikun sinu Jehofa Ọlọrun, ó tọka si ifojusọna rẹ̀ iṣaaju, ni wiwi pe: “Emi ń gbagbe awọn nǹkan ti o wà lẹhin, mo sì ń nọ̀gà wo awọn nǹkan ti o wà niwaju. Emi ń lépa lati de opin ire-ije nì fun èrè ìpè giga Ọlọrun ninu Kristi Jesu.” (Filippi 3:13, 14) Paulu ka awọn nǹkan tẹmi si iyebiye.

Sibẹ, Paulu lo ìdánilẹ́kọ̀ọ́ iṣaaju yẹn ninu iṣẹ-isin Jehofa. Nigba ti ó sọ nipa awọn Ju pe, “Mo gba ẹ̀rí wọn jẹ́ pe, wọn ni ìtara fun Ọlọrun,” ó sọrọ lati inu iriri ara-ẹni. (Romu 10:2) Gẹgẹ bii Farisi paraku, oun dajudaju ní ìtara fun Ọlọrun ati Iwe Mimọ. Lẹhin ti Paulu di Kristian, ìtara rẹ̀ ni a mú dẹrùn nipa ìmọ̀ pipeye, ó sì lè lo ẹkọ-iwe ti o ti ní tẹlẹ fun ète ododo. Ninu iwe Heberu, fun apẹẹrẹ, ó lo ìmọ̀ jijinlẹ rẹ̀ nipa ìtàn awọn ọmọ Israeli ati ijọsin tẹmpili lati ṣapejuwe ipo giga ju ti eto-igbekalẹ Kristian.

Lonii awọn kan ti wọn jẹ́ ọlọgbọn ni ọ̀nà ti ara tun ń dahunpada si ihinrere. Awọn eniyan pẹlu gbogbo iru itootun ẹkọ-iwe, ati mẹmba gbogbo iru iṣẹ́-àkọ́mọ̀ọ́ṣe ati iṣẹ́-òwò, ti tẹwọgba otitọ ti wọn sì ti lo ìdánilẹ́kọ̀ọ́ wọn iṣaaju ninu iṣẹ-isin Jehofa. Sibẹ, ohun yoowu ki ẹkọ-iwe ayé wọn lè jẹ́, awọn Kristian kò tíì sọ oju-iwoye otitọ naa nù pe awọn itootun ṣíṣekókó jẹ́ tẹmi. Iwọnyi ni “awọn ohun ti wọn ṣe pataki jù” nitori pe wọn lè ṣamọna wa si ìyè ainipẹkun.—Filippi 1:10, NW.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́