ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w96 5/1 ojú ìwé 31
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Fílípì 4:13—“Mo Lè Ṣe Ohun Gbogbo Nínú Kristi”
    Àlàyé Àwọn Ẹsẹ Bíbélì
  • Ẹ Má Ṣe Wo “Àwọn Ohun Tí Ń bẹ Lẹ́yìn”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Ọkunrin Ọ̀mọ̀wé Kan
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • “A Kò Juwọ́ Sílẹ̀”!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2019
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
w96 5/1 ojú ìwé 31

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Kí ni aposteli Paulu ní lọ́kàn nígbà tí ó wí pé òun ń ‘gbàgbé awọn ohun tí ń bẹ lẹ́yìn tí òun sì ń nàgà sí awọn ohun tí ń bẹ níwájú’? (Filippi 3:13) Ẹnì kan ha lè mọ̀ọ́mọ̀ gbàgbé ohun kan bí?

Rárá o, nínú àwọn ọ̀ràn tí ó pọ̀ jù lọ a kò lè mọ̀ọ́mọ̀ mú ìrántí kan kúrò ní ọkàn wa. Òkodoro òtítọ́ náà ni pé, ọ̀pọ̀ ohun tí a ń fẹ́ láti rántí ni a ń gbàgbé, tí a sì ń rántí ọ̀pọ̀ ohun tí a fẹ́ láti gbàgbé. Nígbà náà, kí ni Paulu wá ní lọ́kàn nígbà tí ó kọ àwọn ọ̀rọ̀ tí ó wà ní Filippi 3:13? Àyíká ọ̀rọ̀ náà ràn wá lọ́wọ́ láti lóye rẹ̀.

Nínú Filippi orí 3, Paulu ṣàpèjúwe “awọn ìdí” rẹ̀ “fún ìgbọ́kànlé ninu ẹran-ara.” Ó sọ̀rọ̀ nípa ipò àtilẹ̀wá rẹ̀ tí kò ní àbàwọ́n gẹ́gẹ́ bíi Júù àti ìtara rẹ̀ fún Òfin—àwọn ohun tí ì bá ti fún un ní ọ̀pọ̀ àǹfààní ní orílẹ̀-èdè Israeli. (Filippi 3:4-6; Ìṣe 22:3-5) Síbẹ̀, ó kọ irú àwọn àǹfààní bẹ́ẹ̀ sílẹ̀, ó gbàgbé wọn, kí a sọ ọ́ lọ́nà bẹ́ẹ̀. Èé ṣe? Nítorí pé ó ti rí ohun kan tí ó sàn jù—“ìníyelórí títayọlọ́lá ìmọ̀ nipa Kristi Jesu.”—Filippi 3:7, 8.

Olórí góńgó Paulu kì í ṣe kí ọwọ́ rẹ̀ lè tẹ ipò kan nínú ayé yìí, bí kò ṣe “àjíǹde àkọ́kọ́ kúrò ninu òkú.” (Filippi 3:11, 12) Nípa báyìí, ó kọ̀wé pé: “Ní gbígbàgbé awọn ohun tí ń bẹ lẹ́yìn ati nínàgà sí awọn ohun tí ń bẹ níwájú, mo ń lépa góńgó naa nìṣó fún ẹ̀bùn eré ìje ti ìpè Ọlọrun sí òkè nípasẹ̀ Kristi Jesu.” (Filippi 3:13, 14) Nígbà tí Paulu sọ pé òun ń “gbàgbé awọn ohun tí ń bẹ lẹ́yìn,” òun kò ní in lọ́kàn pé, lọ́nà kan, ohun tí pa “awọn ohun tí ń bẹ lẹ́yìn” rẹ́ kúrò nínú ọkàn rẹ̀. Ó hàn gbangba pé ó ṣì rántí wọn, níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé ó ṣẹ̀ṣẹ̀ tò wọ́n lẹ́sẹẹsẹ ni. Yàtọ̀ sí ìyẹn, nínú èdè Gíríìkì ìpilẹ̀ṣẹ̀, ó lo irú ọ̀rọ̀ ìṣe kan tí ń fi hàn pé ìgbésẹ̀ kan ń bá a lọ, kò tí ì parí. Ó sọ pé “ní gbígbàgbé,” kò sọ pé “bí mo ti gbàgbé.”

Ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà tí a túmọ̀ sí “gbàgbé” (e·pi·lan·thaʹno·mai) ní onírúurú ìtumọ̀, ọ̀kan nínú rẹ̀ ni “ṣíṣàìṣàníyàn nípa nǹkan,” tàbí “ṣíṣàìnáání.” Gẹ́gẹ́ bí ìwé atúmọ̀ èdè Exegetical Dictionary of the New Testament (tí Horst Balz àti Gerhard Schneider ṣàyẹ̀wò rẹ̀) ti sọ, ohun tí “ní gbígbàgbé” túmọ̀ sí nínú Filippi 3:13 nìyí. Paulu kì í fi ìgbà gbogbo ronú lórí àwọn nǹkan tí ó ti fi sílẹ̀. Ó ti kọ́ láti kà wọ́n sí ohun tí kò ṣe pàtàkì. Wọ́n dà bí “ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ pàǹtírí” ní ìfiwéra pẹ̀lú ìrètí ti ọ̀run.—Filippi 3:8.

Báwo ni a ṣe lè fi àwọn ọ̀rọ̀ Paulu sílò lónìí? Toò, Kristian kan ti lè ṣe ìrúbọ láti ṣiṣẹ́ sin Ọlọrun, gẹ́gẹ́ bí Paulu ti ṣe. Ó ti lè fi àwọn iṣẹ́ ìgbésí ayé kan tí ń mówó wọlé sílẹ̀ nítorí àtiṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. Tàbí ó lè wá láti inú ìdílé ọlọ́rọ̀ tí wọn kò dá sí ọ̀ràn rẹ̀ ní ti ìṣúnná owó mọ́, nítorí pé wọn kò fara mọ́ òtítọ́. Irú àwọn ìrúbọ bẹ́ẹ̀ yẹ ní gbígbóríyìn fún, ṣùgbọ́n wọn kì í ṣe ohun kan tí a ní láti máa ronú lé lórí nígbà gbogbo. Kristian kan ‘ń gbàgbé,’ ó ń dẹ́kun ṣíṣàníyàn nípa, “awọn ohun tí ń bẹ lẹ́yìn” lójú ìwòye ọjọ́ ọ̀la ológo tí ń dúró dè é.—Luku 9:62.

Bóyá a lè fi ìlànà tí àwọn ọ̀rọ̀ Paulu ní nínú sílò ní ọ̀nà míràn. Kristian kan tí ó lọ́wọ́ nínú ìwà àìtọ́ ṣáájú kíkẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọrun ńkọ́? (Kolosse 3:5-7) Tàbí kí a sọ pé lẹ́yìn tí ó di Kristian, ó dá ẹ̀sẹ̀ wíwúwo kan, tí ìjọ sì bá a wí. (2 Korinti 7:8-13; Jakọbu 5:15-20) Toò, bí ó bá ronú pìwà dà ní tòótọ́, tí ó sì yí àwọn ọ̀nà rẹ̀ padà, a ti ‘sọ ọ́ di mímọ́.’ (1 Korinti 6:9-11) Ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ti kọjá. Ó lè má gbàgbé ohun tí ó ṣe ní ti gidi láé—ní tòótọ́, yóò dára kí ó kẹ́kọ̀ọ́ láti inú ìrírí náà kí ó má baà padà dá ẹ̀ṣẹ̀ náà mọ́. Síbẹ̀, ó ‘gbàgbé’ ní èrò pé kò ní máa dá ara rẹ̀ lẹ́bi lọ́nà líle koko nígbà gbogbo. (Fi wé Isaiah 65:17.) Níwọ̀n bí a ti dárí jì í lórí ìpìlẹ̀ ẹbọ Jesu, òun yóò tiraka láti máà ṣàníyàn púpọ̀ jù lórí ohun àtẹ̀yìnwá.

Ní Filippi 3:13, 14, Paulu ṣàpèjúwe ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ń sáré nínú eré ìje, ‘ẹni tí ń nàgà síwájú’ kí ọwọ́ rẹ̀ lè tẹ góńgó náà. Iwájú ni eléré ìje máa ń wò, kì í ṣe ẹ̀yìn. Bákan náà, ó yẹ kí Kristian kan máa wo àwọn ìbùkún tí ń bẹ níwájú, kì í ṣe àwọn ohun tí ó fi sílẹ̀ sẹ́yìn. Paulu tún sọ pé: “Bí ẹ bá . . . ní èrò-orí tí ó tẹ̀ sí ibòmíràn lọ́nà èyíkéyìí, Ọlọrun yoo ṣí ẹ̀mí ìrònú tí ó wà lókè yii payá fún yín.” (Filippi 3:15) Nítorí náà, gbàdúrà sí Ọlọrun pé kí ó ràn ọ́ lọ́wọ́ láti lè mú ojú ìwòye yìí dàgbà. Fi àwọn èrò Ọlọrun kún èrò inú rẹ, gẹ́gẹ́ bí ó ti wà nínú Bibeli. (Filippi 4:6-9) Ṣàṣàrò lórí ìfẹ́ tí Jehofa ní sí ọ àti lórí àwọn ìbùkún tí o ń gbádùn nítorí rẹ̀. (1 Johannu 4:9, 10, 17-19) Lẹ́yìn náà, Jehofa yóò fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ ràn ọ́ lọ́wọ́ kí o má baà ṣàníyàn nípa ohun tí o ti fi sílẹ̀ sẹ́yìn. Kàkà bẹ́ẹ̀, bíi Paulu, ìwọ yóò máa fojú sọ́nà fún ọjọ́ ọ̀la ológo tí ń bẹ níwájú.—Filippi 3:17.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́