Ẹyin Alagba—Ẹ Mu Awọn Ẹlomiran Bọsipo Ninu Ẹmi Iwatutu
ỌKÀN-ÀYÀ ojulowo Kristian kan ni a lè fiwe ọgbà tẹmi kan ti ń so eso ti ó dara. Ifẹ, ayọ, alaafia, ipamọra, iwapẹlẹ, iṣoore, igbagbọ, iwatutu, ati ikora-ẹni-nijaanu ni o sábà maa ń dagba nibẹ. Kò ṣe ní rí bẹẹ? O ṣetan, iwọnyi ni eso ẹmi mimọ tí Jehofa Ọlọrun fifun awọn iranṣẹ rẹ̀ oluṣeyasimimọ. (Galatia 5:22, 23) Sibẹ, olukuluku Kristian tí ń fẹ lati mu ki ọgbà ọkàn-àyà rẹ̀ maa baa lọ lati jẹ ibikan ti ń tẹ́ Baba rẹ̀ ọrun lọ́rùn gbọdọ bá awọn èpò ti ẹ̀ṣẹ̀ ajogunba jagun kikankikan, lọna ti ń baa lọ laidawọduro.—Romu 5:5, 12.
Lẹẹkọọkan, ohun kan ti a kò fẹ a maa bẹrẹsii ruyọ ninu ọkan-aya alaipe ti ẹni oniwa-bi-Ọlọrun kan. Oun lọkunrin tabi lobinrin ti lè ni awọn akọsilẹ iṣe titayọlọla nipa tẹmi. Ṣugbọn lẹhin naa awọn iṣoro diẹ dide, boya ti gbòǹgbò rẹ̀ wá lati inu ẹgbẹkẹgbẹ, tabi ipinnu kan ti kò bọ́gbọ́n mu. Bawo ni awọn alagba ijọ ṣe lè ṣeranwọ fun iru ẹni bẹẹ nipa tẹmi?
Imọran Awọn Aposteli
Ni ríran Kristian kan ti o ti ṣàṣìṣẹ̀ lọwọ, awọn alagba nilati tẹle imọran aposteli Paulu pe: “Ará, bi a tilẹ mú eniyan ninu iṣubu kan, ki ẹyin tii ṣe ti ẹmi ki o mú iru ẹni bẹẹ bọsipo ni ẹmi iwatutu; ki iwọ tikaraarẹ maa kiyesara, ki a má baa dán iwọ naa wò pẹlu.” (Galatia 6:1) Nigba ti a bá “mú” onigbagbọ ẹlẹgbẹ ẹni kan “ninu iṣubu,” awọn alagba ni ẹrù-iṣẹ́ lati nawọ iranlọwọ si i bi o bá ti le ṣeẹṣe ki o yá tó.
Paulu tọka si “eniyan” ka gẹgẹ bi ẹni ti a mú ninu iṣubu. Bi o ti wu ki o ri, ọ̀rọ̀ Griki naa (anʹthro·pos) ti a lò nihin in lè tọka si ọkunrin tabi obinrin kan. Ki sì ni o tumọsi lati “mú” ẹnikan “bọsipo”? Èdè-ọ̀rọ̀ Griki yii (ka·tar·tiʹzo) tumọsi lati “mú wá si òpó ìlà titọ.” Ọ̀rọ̀ kan-naa ni a ń lò fun títún àwọ̀n ṣe. (Matteu 4:21) Ó tun nii ṣe pẹlu títo ẹsẹ̀ ẹnikan ti o ti dá. Dokita kan maa ń fi tiṣọratiṣọra ṣe eyi lati yẹra fun fífa irora ti kò yẹ fun olùgbàtọ́jú rẹ̀. Bakan naa, ríran arakunrin tabi arabinrin kan lọwọ lati wá si òpó ìlà titọ tẹmi gba iṣọra, ọgbọ́n-ẹ̀wẹ́, ati ìyọ́nú.
Awọn alagba ń fi ẹ̀rí jijẹ ẹni tẹmi wọn hàn nipa fifi ẹmi iwatutu hàn nigba ti wọn ba ń gbiyanju lati mú ẹnikan bọsipo. Dajudaju, Jesu oniwatutu yoo bojuto iru awọn ọ̀ràn bẹẹ pẹlu iwatutu. (Matteu 11:29) O yẹ ki awọn alagba fi animọ yii hàn si iranṣẹ Jehofa kan ti a mú ninu iṣubu nitori pe awọn funraawọn kò rekọja didi ẹni ti ẹ̀ṣẹ̀ kan lè lébá, lodisi ète ọkan-aya wọn. Eyi le ṣẹlẹ lọjọ iwaju bi kò bá tii ṣẹlẹ sẹhin.
Awọn ọkunrin ti wọn tootun nipa tẹmi wọnyi nilati fi tifẹtifẹ ‘ru ẹrù-ìnira’ awọn olujọsin ẹlẹgbẹ wọn. Nitootọ, awọn alagba nii lọkan wọn lati ran arakunrin kan tabi arabinrin kan lọwọ lati jijakadi lodisi Satani, awọn idẹwo, ailera ti ẹran-ara, ati ipọnju ti ẹ̀ṣẹ̀. Dajudaju eyi ni ọ̀nà kan fun awọn Kristian alaboojuto lati “mu ofin Kristi ṣẹ.”—Galatia 6:2.
Awọn ọkunrin ti wọn ni ẹ̀rí-ìtóótun tootọ nipa tẹmi jẹ onirẹlẹ, ní mímọ̀ pe “bi eniyan kan bá ń ro araarẹ̀ si ẹnikan, nigba ti kò jẹ nǹkan, o ń tan araarẹ̀ jẹ.” (Galatia 6:3) Laika bi awọn alagba ti lè gbiyanju gidigidi tó lati ṣe ohun ti o tọ́ ti o si ṣeranwọ sí, wọn kì yoo lè doju ìlà ti Ọmọkunrin Ọlọrun, Jesu Kristi ti o pé ti o sì fi tifẹtifẹ jẹ oníyọ̀ọ́nú. Ṣugbọn iyẹn kìí ṣe idi fun wọn lati máṣe ṣe gbogbo isapa ti wọn lè ṣe.
Awọn alagba mọ̀ pe ki yoo tọna fun wọn lati bu ẹnu-àtẹ́ lu olujọsin ẹlẹgbẹ wọn lọna onigbeeraga, pẹlu iṣarasihuwa mo-jẹ́-ẹni-mímọ́-jù-ọ́-lọ! Dajudaju Jesu ki yoo ṣe eyiini. Họwu, oun fi iwalaaye rẹ̀ lelẹ kìí ṣe nititori awọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ nikan ṣugbọn fun awọn ọ̀tá rẹ̀ paapaa! Awọn alagba ń sapa lati fi iru ifẹ kan-naa hàn nigba ti wọn ba ń gbiyanju lati ṣeranwọ fun awọn arakunrin tabi arabinrin wọn kuro ninu iṣoro ki wọn si mu wọn sunmọ Baba wọn ọrun ati awọn ọ̀pá idiwọn ododo rẹ̀. Ki ni awọn igbesẹ diẹ ti yoo ṣeranwọ fun awọn alagba lati mú awọn olujọsin ẹlẹgbẹ wọn bọsipo?
Awọn Igbesẹ Kan Ti Ó Ṣeranwọ
Fi taduratadura gbarale Jehofa bí o ti ń sọrọ tabi huwa lọna oniwatutu. Jesu jẹ oniwatutu, ó gbadura kíkankíkan si Baba rẹ̀ ọrun fun itọsọna, o sì ń figba gbogbo ṣe awọn ohun ti o wu Ú. (Matteu 21:5; Johannu 8:29) Awọn alagba kò nilati ṣe ohun ti o dinku si eyi nigba ti wọn bá ń gbiyanju lati tún ẹnikan ti a ti mú ninu iṣubu ṣe bọsipo. Gẹgẹ bi oluṣọ-agutan ọmọ-abẹ oniwatutu, alagba kan yoo jẹ afunni ni ìṣírí ati agbeniro ninu ọ̀rọ̀ sisọ, kìí ṣe ahalẹmọni. Nigba ijiroro naa, oun yoo gbiyanju lati ṣe sàkáání ayika kan ninu eyi ti yoo fi lè ṣeeṣe fun Kristian ti o nilo iranlọwọ lati wà ni itura tó bi o bá ti le ṣeeṣe tó fun un lati lè sọ awọn èrò rẹ̀ jade. Ki eyi lè ṣeeṣe, adura atọkanwa ni ibẹrẹ yoo ṣeranlọwọ pupọ. Ẹni naa ti ń gba imọran ti a funni pẹlu iwatutu yoo tubọ muratan lati ṣí ọkan-aya rẹ̀ silẹ sii bi oun bá mọ̀ pe, gẹgẹ bii Jesu, olugbani ní imọran naa ń fẹ ṣe ohun ti ó tẹ́ Ọlọrun lọ́rùn. Adura ipari ṣeeṣe ki o mu ki ó yé ẹni naa idi ti o fi yẹ ki o fi imọran ti a fun un ni iru ọ̀nà onifẹẹ, oniwa tutu bẹẹ sílò.
Lẹhin adura, funni ni ìgbóríyìn olotitọ-inu. O lè tan mọ́ awọn animọ rere ti ẹni naa, iru bii inurere, ṣiṣee gbẹkẹle tabi jijẹ alaapọn. A lè tọkasi akọsilẹ iṣẹ-isin iṣotitọ rẹ̀ si Jehofa, boya lati ọdun pupọ wá. Ni ọ̀nà yii, a ń fihàn pe a bikita a sì ní ìkanisí bii ti-Kristi fun ẹni naa. Jesu bẹrẹ ihin-iṣẹ rẹ̀ si ijọ Tiatira pẹlu igboriyin funni, ni wiwi pe: “Emi mọ iṣẹ rẹ, ati ifẹ rẹ, ati igbagbọ, ati isin, ati suuru rẹ; ati pe iṣẹ rẹ ikẹhin ju ti iṣaaju lọ.” (Ìfihàn 2:19) Awọn ọ̀rọ̀ wọnni mú un dá awọn mẹmba ijọ naa loju pe Jesu mọ̀ nipa iṣẹ rere ti wọn ń ṣe. Bi o tilẹ jẹ pe ijọ naa ni awọn aṣiṣe tirẹ̀—agbara-idari ti “Jesebeli” ni a ti fayegba—o ń ṣe daradara ni awọn ibomiran, Jesu si fẹ ki awọn ará wọnyẹn mọ̀ pe igbokegbodo wọn onitara ni a kò gbojufoda rara. (Ìfihàn 2:20) Lọna kan-naa, awọn alagba nilati gbóríyìn funni nibi ti o ba ti yẹ fun un.
Máṣe bojuto iṣubu lọna ti o wuwo rekọja bi ipo naa ti beere fun lọ. Awọn alagba gbọdọ daabobo agbo Ọlọrun ki wọn sì mu ki eto-ajọ rẹ̀ wà ni mímọ́. Ṣugbọn awọn iṣisẹ gbe kan nipa tẹmi ti o beere imọran lilagbara ni a le bojuto pẹlu idanuṣe ti alagba kan tabi meji laisi igbẹjọ onidaajọ kan. Ninu ọpọlọpọ ọ̀ràn, ailera ti ẹ̀dá dipoo imọọmọ huwa buruku ni okunfa iṣubu Kristian kan. Awọn alagba nilati ba agbo lò pẹlu jẹlẹnkẹ ki wọn sì ranti eyi pe: “Ẹni ti kò ṣaanu, ni a o ṣe idajọ fun laisi aanu; aanu ń ṣogo lori idajọ.” (Jakọbu 2:13; Iṣe 20:28-30) Kàkà ti à bá fi maa fẹ ọ̀ràn loju, nigba naa, awọn alagba nilati bá ẹni ti ń kẹdun ẹ̀ṣẹ̀ naa lò lọna pẹ̀lẹ́tù, bii ti Jehofa, Ọlọrun wa oníyọ̀ọ́nú ati alaaanu.—Efesu 4:32.
Fi òye hàn nipa awọn kókó ipilẹ ti o ti lè ṣamọna si iṣubu naa. O yẹ ki awọn alagba fetisilẹ daradara bi onigbagbọ ẹlẹgbẹ wọn ti ń tú ọkàn rẹ̀ jade. Niwọn bi ‘Ọlọrun kìí tií gan irobinujẹ ọkàn,’ awọn pẹlu kò gbọdọ ṣe bẹẹ. (Orin Dafidi 51:17) Boya àìkòsí itilẹhin alabaaṣegbeyawo kan niti ero-imọlara ni gbòǹgbò iṣoro naa. Isorikọ ti ọpọlọ lilekoko ti o sì ń baa lọ fun ìgbà pipẹ le ti mú ki diẹ lara okun ero-imọlara ẹni naa ti o ti jẹ alagbara tẹlẹtẹlẹ di eyi ti ó joro tabi ki o ti jẹ ki o nira rekọja àlà fun un lati ṣe awọn ipinnu ọlọgbọn. Awọn alagba onifẹẹ yoo gbe iru awọn kókó abájọ bẹẹ yẹwo, nitori pe bi o tilẹ jẹ pe Paulu gba awọn arakunrin rẹ̀ niyanju lati “kilọ fun awọn ti ń ṣe aigbọran,” o tun rọni pe: “Ẹ maa tu awọn aláìlọ́kàn ninu, ẹ maa ran awọn alailera lọwọ, ẹ maa mu suuru fun gbogbo eniyan.” (1 Tessalonika 5:14) Nigba ti awọn alagba kò nilati sọ agbara awọn ọ̀pá-ìdiwọ̀n ododo Ọlọrun di yẹpẹrẹ, wọn nilati gba awọn kókó abájọ amọranfuyẹ yẹwo, àní gẹgẹ bi Ọlọrun ti ṣe.—Orin Dafidi 103:10-14; 130:3.
Yẹra fun fifi oju tín-ínrín iyì ara-ẹni awọn Kristian ẹlẹgbẹ rẹ. A kò fẹ lae lati du arakunrin tabi arabinrin eyikeyii ni ipo ọlá rẹ̀ tabi funni ni èrò-ọkàn pe oun kò wulo. Kàkà bẹẹ, idaniloju pe a ni igbarale ninu awọn animọ Kristian ati ifẹ fun Ọlọrun ẹni naa yoo ṣiṣẹ gẹgẹ bi ìṣírí fun ṣiṣe atunṣe aṣiṣe kan. Boya, awọn ara Korinti ni a fun ni ìṣírí lati jẹ ọ̀làwọ́ nigba ti Paulu sọ fun wọn pe oun ti fi “imuratẹlẹ” ati “itara” wọn ṣogo fun awọn ẹlomiran lori ọ̀ràn yii.—2 Korinti 9:1-3.
Fihàn pe a lè bori iṣoro naa nipa gbigbẹkẹle Jehofa. Bẹẹni, fi taratara gbiyanju lati ran ẹni naa lọwọ lati ríi pe gbigbẹkẹle Ọlọrun ati lilo imọran Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ yoo ṣeranwọ lati mu ipadabọsipo ti a nilo wá. Lati le ṣe eyi, awọn gbólóhùn ọ̀rọ̀ wa ni a gbọdọ gbekari Iwe Mimọ ati lori awọn itẹjade ti a gbekari Bibeli. Gongo wa jẹ onilọọpo meji: (1) lati ṣeranwọ fun ẹni naa ti ń fẹ iranlọwọ lati rí ki o si loye oju-iwoye Jehofa ati (2) lati fihàn ẹni naa bí oun de ààyè ipo kan ti gbojufo tabi kùnà lati tẹle awọn ilana atọrunwa wọnyi.
Pa imọran ti o ba Iwe Mimọ mu pọ̀ pẹlu awọn ibeere oninuure ṣugbọn ti wọn soju-abẹ-nikoo. Eyi lè wulo daradara ni dide inu ọkan-aya. Nipasẹ wolii rẹ̀ Malaki, Jehofa lo ibeere kan lati mú ki awọn eniyan Rẹ̀ loye bi wọn ti ṣe ṣìnà lọ. “Eniyan yoo ha ja Ọlọrun ni olè? ni oun beere, ni fifi kun un pe: “Ṣugbọn ẹyin ṣa ti jà mi ni olè.” (Malaki 3:8) Ìkùnà Israeli lati dá idamẹwaa ninu irugbin wọn bi Ofin Mose ti beere fun un ṣe deedee pẹlu jija Jehofa ni olè. Lati wa atunṣe si ipo yii, o ń beere pe ki awọn ọmọ Israeli mu ẹrù-iṣẹ́ wọn siha ijọsin mimọ gaara ṣẹ pẹlu igbagbọ pe Ọlọrun yoo bukun wọn lọpọ yanturu. Nipasẹ awọn ibeere amunironu jinlẹ̀ ati agbatẹniro, awọn alagba le tẹnumọ ọn pe ṣiṣe ohun ti o tọ́ lonii ní ninu gbigbẹkẹle Baba wa ọrun ati ṣiṣegbọran sii. (Malaki 3:10) Mimu ki èrò yẹn dé inu ọkan-aya yoo lọ jìnnà ni ṣiṣeranwọ fun arakunrin wa lati ‘ṣe ipa-ọna ti o tọ́ fun ẹsẹ̀ rẹ̀.’—Heberu 12:13.
Tẹnumọ anfaani ti o wà ninu titẹwọgba imọran naa. Imọran ti o gbeṣẹ ní ninu lapapọ ikilọ nipa awọn abajade lilepa ipa-ọna ti o lòdì ati awọn irannileti nipa awọn anfaani ti a ń rí gbà lati inu títún awọn ọ̀ràn ṣe bọsipo. Lẹhin ikilọ ti o bọsi akoko, Jesu mú un dá awọn ará ijọ Laodikea wọnni ti wọn ni ẹmi idagunla nipa tẹmi loju pe bi wọn bá ronupiwada kuro ninu ipa-ọna wọn atẹhinwa ti wọn si di awọn ọmọ-ẹhin onitara, wọn yoo gbadun awọn anfaani alailẹgbẹ, papọ pẹlu ifojusọna fun ṣiṣakoso pẹlu rẹ̀ ninu awọn ọrun.—Ìfihàn 3:14-21.
Fi ọkàn-ìfẹ́ hàn ninu boya a fi imọran naa silo. Gẹgẹ bi dokita daradara kan ṣe ń ṣayẹwo lati igba-de-igba lati rí boya egungun kan ti oun ti tò bá ṣì wà loju ipò rẹ̀ títọ́, bẹẹ ni awọn alagba ṣe nilati gbiyanju lati ríi mọ̀ boya imọran inu Iwe Mimọ ni a fi silo. Wọn le bi araawọn leere pe: Iranlọwọ sii ha yẹ bi? A ha nilati tún imọran naa sọ, boya ni ọ̀nà miiran bi? Imọran leralera ni Jesu nilati fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ lori aini naa fun iwa irẹlẹ. Fun ìgbà gigun kan, oun fi suuru wá ọ̀nà lati tún ironu wọn ṣe nipasẹ imọran, awọn apejuwe, ati awọn awokọṣẹ ti o ṣee fojuri. (Matteu 20:20-28; Marku 9:33-37; Luku 22:24-27; Johannu 13:5-17) Ni ifiwera, awọn alagba lè ṣeranwọ lati mu ipadabọsipo patapata ti arakunrin tabi arabinrin kan daju nipa ṣiṣeto tẹle e fun awọn ijiroro ti a gbekari Iwe Mimọ eyi ti a wewee lati fun itẹsiwaju ẹni naa sipo ilera kikun nipa tẹmi niṣiiri.
Gboriyin funni fun itẹsiwaju eyikeyii ti a ti ṣe. Bi ẹni naa ti a mú ninu iṣubu ba ń sapa tọkantọkan lati fi imọran ti a gbekari Iwe Mimọ silo, yin ín daradara. Eyi yoo fun imọran akọkọ lagbara sii ti o si ṣeeṣe ki o jẹ iṣiri fun itẹsiwaju sii. Ninu lẹta Paulu akọkọ si awọn ara Korinti, a sun un lati fun wọn ni imọran alagbara lori awọn ọ̀ràn melookan. Laipẹ lẹhin ti Titu ti sọ fun aposteli naa nipa idahunpada ti o dara gidigidi si lẹta rẹ̀, Paulu kọwe lati yìn wọn. “Emi yọ̀ nisinsinyi,” ni oun wi, “kìí ṣe nitori ti a mu inu yin bajẹ, ṣugbọn nitori ti a mu inu yin bajẹ si ironupiwada: nitori ti a mu inu yin bajẹ bi ẹni iwa-bi-Ọlọrun.”—2 Korinti 7:9.
Idi kan fun Yíyọ̀
Bẹẹni, Paulu yọ̀ nigba ti o gbọ pe imọran oun ti ran awọn ara Korinti lọwọ. Bakan naa, awọn alagba ode-oni ni ayọ nla nigba ti olujọsin ẹlẹgbẹ wọn kan bá padabọsipo lati inu iṣubu kan nititori didahunpada daradara si iranlọwọ onifẹẹ wọn. Awọn niti tootọ lè ri itẹlọrun ninu ríran Kristian kan ti ń kẹdun fun ẹ̀ṣẹ̀ lọwọ lati fa gbòǹgbò èpò ẹlẹ́gùn-ún ẹ̀ṣẹ̀ tu kuro ni ọkàn rẹ̀ ki eso oniwa-bi-Ọlọrun baa le gbilẹ nibẹ lọpọ yanturu.
Bi awọn alagba bá ṣaṣeyọri ni títún ẹnikan ti o ti ṣubu ṣe bọsipo, oun lọkunrin tabi lobinrin ni a lè yipada kuro ni ọ̀nà ti yoo jẹ ti onijamba patapata gbaa nipa tẹmi. (Fiwe Jakọbu 5:19, 20.) Fun iru iranlọwọ bẹẹ, ẹni ti ń gba iranwọ naa nilati fi imoore rẹ̀ hàn fun Jehofa Ọlọrun. Awọn ọ̀rọ̀ imọriri tootọ fun iranlọwọ onifẹẹ, ìyọ́nú, ati ìfòye hàn ti awọn alagba yoo jẹ́ ohun yiyẹ pẹlu. Nigba ti pípadàbọsipo nipa tẹmi ba sì pari tán patapata, gbogbo awọn ti ọ̀ràn kàn lè yọ̀ pe ìtúnpadàbọsipo yẹn ni a ti ṣaṣeyọri rẹ̀ pẹlu ẹmi iwatutu.