Iniyelori Nash Papyrus
BAWO ni a ti ṣeé mọjọ́-orí iwe-afọwọkọ Bibeli Lede Heberu lọna pipeye? Iyẹn ni isoro ti ń dojukọ Dokita John C. Trever ní 1948 nigba ti o kọkọ ri Ìwé-kíká Òkun Òkú ti Isaiah. Irisi awọn lẹ́tà Heberu naa ru itọpinpin rẹ̀ soke. O mọ̀ pe ninu awọn lẹ́tà naa ni ojútùú si ọjọ́-orí ìwé-kíká naa wà, ṣugbọn ki ni o lè fi wọn wé? Lọna titọna, o pari ero si pe: Nash Papyrus nikanṣoṣo ni. Eeṣe? Ki ni iwe-afọwọkọ yii, nibo ni o sì ti wá?
Nash Papyrus wulẹ ní awọn àjákù mẹrin ti ó ní ìlà 24 ninu ẹsẹ-ìwé Heberu ninu, ni wíwọn nǹkan bii íǹṣì mẹta níbùú ati íǹṣì marun-un lóòró. A fi orukọ W. L. Nash, akọwe Ẹgbẹ́ Awalẹpitan Bibeli, ẹni ti o rà á lọ́wọ́ awọn oniṣowo ọmọ ilẹ̀ Egipti kan ní 1902 pè é. S. A. Cooke tẹ̀ ẹ́ jade ni ọdun ti o tẹ̀lé e ninu iwe ẹgbẹ́ yẹn Proceedings ti a sì fifun Ilé-àkójọ-ìwé-kíkà Yunifasiti Cambridge, England, nibi ti o wà di isinsinyi. Iniyelori àjákù papyrus yii ni a sopọ mọ́ ọjọ-ori rẹ̀. Awọn ọmọwe akẹkọọ jinlẹ fi ọjọ rẹ̀ si ọrundun kìn-ín-ní tabi ikeji B.C.E., nitori naa o jẹ abala iwe-afọwọkọ Lede Heberu ti ijimiji julọ ti a tii rí rí.
Nigba ti Dokita Trever ṣefiwera aworan ara ogiri oloriṣiriṣi àwọ̀ ti Nash Papyrus naa pẹlu ìwé-kíká ti o wà niwaju rẹ̀, o fi tiṣọratiṣọra wo irisi ati bi awọn lẹ́tà kọọkan ṣe rí. Laisi iyemeji, wọn jọra gidigidi. Bi o tilẹ ri bẹẹ, o dabi alaiṣeegbagbọ fun un pe iwe-afọwọkọ nla, ti a ṣẹṣẹ rí naa ni o ṣeeṣe ki ọjọ rẹ̀ jẹ́ ti ijimiji bii ti Papyrus Nash. Bi o ti wu ki o ri, bi akoko ti ń lọ, ọ̀nà igbaronu rẹ̀ jásí eyi ti o tọna. Ìwé-kíká Òkun Òkú ti Isaiah jẹ ti ọrundun keji B.C.E.!
Awọn Ọ̀rọ̀ Inú Nash Papyrus
Ayẹwo kulẹkulẹ ẹsẹ-ìwé Nash Papyrus ṣipaya pe gbogbo awọn ìlà 24 rẹ̀ ni kò pé, pẹlu ọ̀rọ̀ kan tabi lẹ́tà kan ti o sọnu ni ẹ̀gbẹ́ mejeeji. O ní awọn apakan Ofin Mẹwaa lati Eksodu ori 20 nínú, pẹlu awọn ẹsẹ melookan lati inu Deuteronomi ori 5 ati 6. Nitori naa eyi kìí ṣe iwe afọwọkọ Bibeli gidi kan ṣugbọn àkọ́pọ̀ awọn ẹsẹ-ìwé pẹlu akanṣe ète kan. O farahan pe o jẹ́ apakan àkópọ̀ onítọ̀ọ́ni kan lati rán Ju kan létí ẹrù-iṣẹ́ rẹ̀ si Ọlọrun. Apakan ẹsẹ ti o bẹrẹ pẹlu Deuteronomi 6:4 (NW), ti a pè ní Shema, ni a túnsọ leralara. Ẹsẹ yẹn kà pé: “Fetisilẹ, Óò Israeli: Jehofa Ọlọrun wa Jehofa kan ni.”
Tetragrammaton [lẹta mẹrn ti Heberu fun orukọ Ọlọrun], YHWH, “Jehofa,” ninu ẹsẹ yii farahan nigba meji lori ìlà ti o kẹhin papyrus naa, o si tun farahan nibi marun-un miiran. O tun farahan lẹẹkan pẹlu lẹ́tà rẹ̀ akọkọ ti o sọnu.
Shema naa ni pataki ni a pete lati tẹnumọ “ànímọ́ jijẹ ọkanṣoṣo ti Ọlọrun.” Gẹgẹ bi Talmud ti Ju (Berakoth 19a) ṣe sọ, ọ̀rọ̀ ipari naa, ʼE·chadʹ (“Ọ̀kan”), “ni a nilati tẹnumọ ni pataki nigba ti a ń fi tiṣọratiṣọra pè é nipa pipe sílébù ọ̀rọ̀ kọọkan soke.” (W. O. E. Oesterley ati G. H. Box) Ni itọkasi Ọlọrun, ʼE·chadʹ ti a fàgùn yii tun polongo jijẹ alailẹgbẹ rẹ̀.
Lonii, Nash Papyrus ní ọpọlọpọ awọn ojúgbà, ni pataki laaarin awọn ìwé-kíká ti a rí ninu awọn hòrò lẹ́bàá etikun Òkun Òkú ti kò jinna sí Qumran. Awọn ayẹwo ti a ṣe ní kulẹkulẹ ti fidi rẹ̀ mulẹ pe ọpọ ninu awọn iwe afwọkọ wọnyi ni ọjọ wọn tó ọrundun kìn-ín-ní ati ikeji B.C.E.a Bi o tilẹ jẹ pe kìí tún ṣe awọn iwe afọwọkọ Lede Heberu ti a mọ̀ ti o jẹ ti ijimiji julọ mọ́. Nash Papyrus sibẹ ṣì jẹ́ eyi ti a lọkan-ifẹ si gidigidi. O ṣì jẹ́ kiki iwe afọwọkọ Bibeli Lede Heberu ti o jẹ́ ti ijimiji bẹẹ ti a rí ní Egipti.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo Ilé-Ìṣọ́nà ti April 15, 1991, oju-iwe 10 si 13.