Ibeere Lati Ọwọ́ Awọn Òǹkàwé
Ki ni Kristian kan lè ṣe nigba ti oun lọkunrin tabi lobinrin kò ba ri olubaṣegbeyawo ti o yẹ wẹ́kú?
Bi o tilẹ jẹ pe Kristian olufọkansin ni wá, a ṣì lè di ẹni ti a kó idaamu bá sibẹ nigba ti a bá fi tọkantara wọ̀nà fun ohun kan ṣugbọn ti kò ṣẹlẹ. Imọlara wa ni a sọ daradara ninu Owe 13:12, ti o wi pe: “Ireti pipẹ mú ọkàn ṣaisan.” Bayii ni awọn Kristian kan ti nimọlara nigba ti wọn bá ti nifẹẹ-ọkan lati gbeyawo ṣugbọn ti wọn kò lè rí ẹnikeji ti o yẹ wẹ́kú. Eyi ri bẹẹ ni pataki nipa awọn wọnni ti aposteli Paulu ṣapejuwe gẹgẹ bi awọn ti wọn ‘kun fun ifẹkufẹẹ.’—1 Korinti 7:9.
Jehofa fi ìfẹ́-ọkàn lati ri aṣekun tootọ kan ninu ẹnikan ti o jẹ ẹya odikeji sinu eniyan. Nititori eyi, kò yanilẹnu pe iru ero-imọlara bẹẹ ń korajọpọ ninu ọpọlọpọ awọn Kristian àpọ́n. (Genesisi 2:18) Imọlara ti o wà deedee yii ni a lè nu ẹnu mọ́ ninu awọn aṣa-iṣẹdalẹ eyi ti o fi itẹnumọ ti o ga sori gbigbeyawo (tabi gbigbeyawo ni ọjọ ori pato kan) tabi nigba ti a bá yí awọn Kristian apọn ká pẹlu awọn tọkọtaya alayọ ninu ijọ. Bi o ti wu ki o ri, kò tọ́ lati fààyè gba aniyan lati maa baa lọ fun akoko gigun kan. Nitori naa bawo ni awọn Kristian olotiitọ-inu ṣe lè koju ipo naa laijẹ pe wọn di ẹni ti a dalaamu ju bi o ṣe yẹ lọ?
Kò rọrun, awọn miiran kò si gbọdọ ka aniyan-ọkan yii si ohun aṣeju tabi airọgbọ ti kò jámọ́ nǹkan lasan. Ṣugbọn dé iwọn ààyè ti o ga, agbara naa lati lè koju tabi yanju ipo naa sinmi lori awọn igbesẹ ti apọn eniyan naa lè gbé.
A ri kọkọrọ kan ninu ilana Bibeli ti o gbeṣẹ yii: “Ati funni o ni ibukun ju ati gbà lọ.” (Iṣe 20:35) Iyẹn ni a sọ lati ẹnu ọkunrin apọn naa Jesu Kristi, o si mọ ohun ti oun ń sọ. Ṣiṣe nǹkan fun awọn ẹlomiran pẹlu ète alainimọtara-ẹni-nikan jẹ́ ọ̀nà iṣe ti o dara lati ran eyikeyii ninu wa lọwọ lati bori awọn imọlara ti ń jẹyọ lati inú ireti pipẹ. Ki ni eyi tumọsi ninu ọ̀ràn ti Kristian apọn kan?
Nàgà lati ṣe awọn iṣẹ oninuure fun idile rẹ ati fun awọn miiran ninu ijọ, ki o sì mu ki igbokegbodo rẹ pọ sii ninu iṣẹ-isin. Imọran yii kìí wulẹ ṣe ọ̀nà kan lati sọ pe, ‘Ṣaa jẹ ki ọwọ́ rẹ di, iwọ yoo si gbagbe ohun ti o níí ṣe pẹlu fifẹ lati ṣegbeyawo.’ Bẹẹkọ. Ni jijẹ ẹni ti ọwọ rẹ̀ di ninu awọn ilepa amesojade ti Kristian wọnyi, iwọ lè ri pe o di ‘ẹni ti o duroṣinṣin ni ọkàn rẹ̀, tí o ní agbara lori ifẹ araarẹ,’ ti o si lè lo ipo-ayika rẹ ti isinsinyi ni ọ̀nà ti o tubọ ṣanfaani.—1 Korinti 7:37.
Awọn diẹ ti wọn ti ni ọkàn-ìfẹ́ ti o gadabu lati ṣegbeyawo ti fayegba eyi lati di ohun ti o gbà wọn lọ́kàn kankankan. Wọn tilẹ ti lọ jinna paapaa debi fifi olubaṣegbeyawo wẹ́lọ̀ ninu awọn iwe-irohin. Bi o ti wu ki o ri, o ti sanju tó, lati fi itẹnumọ ti o pọ sii sori mimọriri awọn anfaani ti a lè jèrè lati inu akoko wíwà ni apọn.—Jọwọ wo ọrọ-ẹkọ naa “Láìṣègbeyàwó Ṣugbọn Pé Pérépéré fun Iṣẹ-Isin Ọlọrun” ati “Wíwà Ní Àpọ́n—Ọ̀nà Igbesi-Aye Kan Tí Ó Lérè-Ẹ̀san” ninu Ilé-Ìṣọ́nà ti November 15, 1987, ati “Igbeyawo Ha Ni Kọkọrọ Kanṣoṣo Naa Si Ayọ Bi?” ninu Ilé-Ìṣọ́nà May 15, 1992.
Gbadura si Jehofa fun iranlọwọ lati farada a ninu ipo apọn. (Filippi 4:6, 7, 13) Ọpọ awọn Kristian alaigbeyawo ti rii pe nipa lilo akoko wọn lati kẹkọọ ati lati ṣàṣàrò lori Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ati lati lọ ki wọn si nipin-in ninu awọn ipade Kristian, wọn ti gbadun afikun ‘isinmi fun ọkàn wọn,’ gẹgẹ bi Jesu ti ṣeleri fun awọn wọnni ti wọn ń tẹle e. (Matteu 11:28-30) Eyi ti ràn wọ́n lọwọ lati mu ipo tẹmi dagba, ki wọn baa lè jẹ́ ọkọ tabi aya ti o sànjù bi wọn bá ri olubaṣegbeyawo kan ti o yẹ wẹ́kú nigba ti o bá yá.
Maṣe gbagbe lae pe Jehofa loye ipo gbogbo awọn apọn eniyan ti wọn ń ṣiṣẹsin in. Oun mọ pe iwọ lè má ni imọlara pe ipo-ayika rẹ ti isinsinyi ni ohun ti iwọ ìbá ti yàn. Bakan naa ni Baba wa ọrun onifẹẹ mọ̀ ohun ti o lè jẹ ire rẹ pipẹtiti ti o dara julọ, nipa tẹmi ati nipa ti ero-imọlara. Ni ọwọ keji iwọ lè mọ eyi pẹlu idaniloju: Nipa fifi suuru duro de Jehofa ati nipa fifi awọn ilana Ọ̀rọ̀ rẹ̀ silo ninu igbesi-aye ojoojumọ, iwọ lè ni idaniloju pe oun yoo tẹ́ awọn aini rẹ ti o ṣepataki julọ lọrun ni ọ̀nà kan ti o jẹ fun ire rẹ ayeraye.—Fiwe Orin Dafidi 145:16.