Awọn Apejọpọ Agbegbe “Ẹ̀kọ́ Atọrunwa”
GBOGBO awọn wọnni ti wọn ń fẹ́ lati di ẹni ti Jehofa kọ́ ń fi ìháragàgà wọna fun awọn Apejọpọ Agbegbe “Ẹ̀kọ́ Atọrunwa.” Itolẹsẹẹsẹ ọlọjọ mẹrin naa yoo tẹnumọ awọn ìhà pataki ninu ẹ̀kọ́ ti ó bá Iwe Mimọ mu tí ń daabobo awọn Kristian ni awọn akoko iṣoro ti ara-ẹni ati irukerudo ayé ti ń ga sii wọnyi. Itolẹsẹẹsẹ naa yoo ràn wọ́n lọwọ lati duro gbọnyingbọnyin lodisi ‘ohun yoowu ti ó wà ni atako si ẹ̀kọ́ afunni ni ilera.’ (1 Timoteu 1:10) Yoo tun fun gbogbo awọn ti wọn bá wá niṣiiri lati tubọ di olùkọ́ didara sii ninu Ọ̀rọ̀ Ọlọrun.
Ẹ wo iru awọn apẹẹrẹ rere ti a ní lati ṣafarawe! Olùkọ́ Titobi Julọ naa kìí ṣe ẹlomiran bikoṣe Jehofa Ọlọrun funraarẹ! Nipa bayii, Elihu fi ẹ̀tọ́ sọ fun Jobu pe Jehofa ni Ẹni ti ń “kọ́ wa ni ẹ̀kọ́ ju awọn ẹranko ayé lọ, ti ó sì mú wa gbọ́n ju awọn ẹyẹ oju ọrun lọ.” Ó tun beere nipa Jehofa pe: “Ta ni jẹ́ olùkọ́ni bi oun?” (Jobu 35:11; 36:22) Ọlọrun ni a tọka si ni Isaiah 30:20 (NW) gẹgẹ bi “Atobilọla Olùkọ́ni.”
Jesu Kristi ni ẹnikanṣoṣo ti ó wà ni ipo keji si Jehofa gẹgẹ bi olùkọ́. Oun ni a mọ gẹgẹ bi “Olùkọ́” ati gẹgẹ bi “Olùkọ́ni,” ti a sì tọka sii lọna bẹẹ ni nǹkan bii 50 ìgbà ninu awọn Ihinrere. Laika awọn imunilarada agbayanu ati awọn iṣẹ-iyanu miiran rẹ̀ sí, Jesu ni a kò mọ gẹgẹ bi Oniṣegun ṣugbọn gẹgẹ bi Olùkọ́, Olùkọ́ni naa.—Matteu 8:19; Luku 5:5; Johannu 13:13.
Lọna ti ó yẹ wẹ́kú julọ, Jesu kọ́ awọn ọmọ-ẹhin ati aposteli rẹ̀ lati di olùkọ́ gẹgẹ bi oun ti jẹ́. A lè rí eyi lati inu Matteu 10:5 si 11:1 ati Luku 10:1-11. Ni kété ṣaaju gigoke re ọrun, Jesu fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ni iṣẹ-aṣẹ kíkọ́ni ti a mọ̀ bi ẹni mowó ti a ṣe akọsilẹ rẹ̀ ni Matteu 28:19, 20 pe: “Ẹ lọ, ẹ maa kọ́ orilẹ-ede gbogbo, ki ẹ sì maa baptisi wọn ni orukọ Baba, ati ni ti Ọmọ, ati ni ti ẹmi mimọ; ki ẹ maa kọ́ wọn lati maa kiyesi ohun gbogbo, ohunkohun ti mo ti pa ni àṣẹ fun yin.” Iwe Iṣe, ati awọn lẹta onimiisi ti ó tẹle e ninu awọn Iwe Mimọ Lede Griki bakan naa, rohin bi awọn ọmọlẹhin Jesu ti ijimiji ti fi titaratitara, lọna ijafafa, ati pẹlu iṣotitọ mú iṣẹ-aṣẹ ìkọ́ni yii ṣẹ.
Iṣẹ ìkọ́ni yii tubọ jẹ́ kanjukanju lonii ju ti igbakigba ri lọ. A ń gbé ni awọn ọjọ ikẹhin ti eto-igbekalẹ awọn nǹkan, ati nitori iyẹn, iwalaaye wémọ́ ọn. Fun awọn eniyan lati maṣe ṣajọpin ninu ẹṣẹ Babiloni Nla ki wọn sì gba apakan ìyọnu rẹ̀, wọn gbọdọ di ẹni ti a kọ́ ti a sì ràn lọwọ lati jade kuro ninu Babiloni ki wọn sì mú iduro wọn fun Jehofa ati Ijọba rẹ̀.—Ìfihàn 18:4.
Lati ran gbogbo awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa lọwọ ninu iṣapa wọn lati mú iṣẹ-aṣẹ ìkọ́ni wọn ṣẹ, Jehofa nipasẹ eto-ajọ rẹ̀ ti pese awọn Apejọpọ Agbegbe “Ẹ̀kọ́ Atọrunwa” naa. Awọn Apejọpọ ọlọjọ mẹrin wọnyi yoo bẹrẹ ni Nigeria ni November. Ǹjẹ́ ki iranṣẹ oluṣeyasimimọ kọọkan ti Jehofa rí i daju pe oun pesẹ sí ó keretan ọ̀kan lara awọn apejọpọ wọnyi, ní wíwà nibẹ ki wọn sì tẹ́tísílẹ̀ lati orin ati adura ibẹrẹ ni ọ̀sán ọjọ Thursday titi di adura ipari ni ọ̀sán ọjọ Sunday.