ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w95 8/1 ojú ìwé 14-19
  • A Ń kọ́ Wa Láti Ọ̀dọ̀ Jehofa Títí Dòní

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • A Ń kọ́ Wa Láti Ọ̀dọ̀ Jehofa Títí Dòní
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àpẹẹrẹ Pípé ti Ipò-Ìbátan Olùkọ́ni Pẹ̀lú Akẹ́kọ̀ọ́
  • Ètò Ẹ̀kọ́ Tí A Mú Gbòòrò Síi
  • A Ń Kọ́ Wa Ní Àwọn Ìpàdé Ìjọ
  • A Ń Kọ́ Wa Ní Àwọn Ìpàdé Ńláńlá
  • A Ń Kọ́ Wa Láti Ọ̀dọ̀ Ọlọrun Kí A Baà Lè Kọ́ Ẹlòmíràn
  • A Ń kọ́ Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Inú Jèhófà
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Jehofa—Ọlọrun Tí Ń Kọ́ni
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Awọn Apejọpọ Agbegbe “Ẹ̀kọ́ Atọrunwa”
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Gbádùn Àwọn Àǹfààni̇́ Ẹ̀kọ́ Àtọ̀runwá
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
w95 8/1 ojú ìwé 14-19

A Ń kọ́ Wa Láti Ọ̀dọ̀ Jehofa Títí Dòní

“Jehofa fi ahọ́n akẹ́kọ̀ọ́ fún mi.”—ISAIAH 50:4.

1, 2. (a) Kí ni Jehofa múra akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ tí ó yàn láàyò sílẹ̀ fún, kí sì ni ìyọrísí rẹ̀? (b) Báwo ní Jesu ṣe jẹ́wọ́ Orísun àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀?

JEHOFA ỌLỌRUN ti jẹ́ Olùkọ́ni láti ìgbà tí ó ti di Bàbá. Nígbà kan lẹ́yìn tí àwọn kan lára àwọn ọmọ rẹ̀ dìtẹ̀, ó múra akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ tí ó yàn láàyò sílẹ̀, Àkọ́bí rẹ̀, fún iṣẹ́-òjíṣẹ́ kan lórí ilẹ̀-ayé. (Owe 8:30) Isaiah orí 50 lọ́nà àsọtẹ́lẹ̀ fi akẹ́kọ̀ọ́ náà hàn gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ń sọ pé: “Oluwa Jehofa ti fi ahọ́n akẹ́kọ̀ọ́ fún mi, kí èmi kí ó lè mọ̀ bí a tíí sọ̀rọ̀ ní àkókò fún aláàárẹ̀.” (Isaiah 50:4) Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí fífi ẹ̀kọ́ Bàbá rẹ̀ sílò nígbà tí ó wà lórí ilẹ̀-ayé, Jesu jẹ́ orísun ìtura fún gbogbo àwọn wọnnì tí ‘ó ti rẹ̀ tí a sì di ẹrù wọ̀ lọ́rùn.’—Matteu 11:28-30.

2 Jesu ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́-ìyanu ní ọ̀rúndún kìn-ínní. Ó la ojú afọ́jú ó tilẹ̀ tún jí òkú dìde, síbẹ̀ ní pàtàkì àwọn alájọgbáyé rẹ̀ mọ̀ ọ́n sí olùkọ́ni. Àwọn ọmọlẹ́yìn àti àwọn alátakò rẹ̀ pẹ̀lú pè é bẹ́ẹ̀. (Matteu 8:19; 9:11; 12:38; 19:16; Johannu 3:2) Jesu kò fìgbà kankan rí gba iyì fún ara rẹ̀ nítorí ohun tí ó kọ́ni ṣùgbọ́n ó fi tìrẹ̀lẹ̀ tìrẹ̀lẹ̀ jẹ́wọ́ pé: “Ohun tí mo fi ń kọ́ni kì í ṣe tèmi, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ti ẹni tí ó rán mi.” “Gẹ́gẹ́ bí Baba ti kọ́ mi ni mo ń sọ nǹkan wọ̀nyí.”—Johannu 7:16; 8:28; 12:49.

Àpẹẹrẹ Pípé ti Ipò-Ìbátan Olùkọ́ni Pẹ̀lú Akẹ́kọ̀ọ́

3. Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ Isaiah ṣe fi ọkàn-ìfẹ́ Jehofa nínú àwọn wọnnì tí òun ń kọ́ hàn?

3 Olùkọ́ni kan tí ó ga lọ́lá ń ní ọkàn-ìfẹ́, tí ń fi ẹ̀mí ìbìkítà, àti ìfẹ́ hàn sí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ lẹ́nìkọ̀ọ̀kan. Isaiah orí 50 ṣípayá pé Jehofa Ọlọrun ní irú ọkàn-ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ sí àwọn wọnnì tí ó ń kọ́. Àsọtẹ́lẹ̀ náà sọ pé: “Ó ń jí ní òròòwúrọ̀, ó ṣí mi ní etí láti gbọ́ bí akẹ́kọ̀ọ́.” (Isaiah 50:4) Èdè tí a lò níhìn-ín tọ́ka sí olùfúnni ní ìtọ́ni tí ó ń jí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ ní òwúrọ̀ kùtùkùtù láti lè kọ́ wọn. Nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ lórí ìfisílò àsọtẹ́lẹ̀ náà, ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan nínú Bibeli ṣàkíyèsí pé: “Èrò náà ni pé, Olùràpadà náà yóò jẹ́ . . . ẹni tí ó wà, ní ilé-ẹ̀kọ́ Ọlọrun, kí a sọ ọ́ lọ́nà bẹ́ẹ̀; ẹni tí yóò sì tóótun láti fún àwọn ẹlòmíràn ní ìtọ́ni. . . . Messia náà yóò tóótun lọ́nà gíga lọ́lá, nípasẹ̀ ẹ̀kọ́ Àtọ̀runwá, láti jẹ́ olùfún aráyé ní ìtọ́ni.”

4. Báwo ni Jesu ṣe dáhùnpadà sí ẹ̀kọ́ Bàbá rẹ̀?

4 Bí a bá fojú ti alápẹẹrẹ pípé wò ó, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ máa ń dáhùn padà sí ẹ̀kọ́ ẹni tí ń fún wọn ní ìtọ́ni. Báwo ní Jesu ṣe dáhùnpadà sí ẹ̀kọ́ Bàbá rẹ̀? Ìdáhùnpadà rẹ̀ wà ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí a kà ní Isaiah 50:5 pé: “Oluwa Jehofa ti ṣí mi ní etí, èmi kò sì ṣe àìgbọràn, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò yípadà.” Bẹ́ẹ̀ni, Jesu háragàgà láti kẹ́kọ̀ọ́. Ó jẹ́ elétí ìgbọ́. Ju bẹ́ẹ̀ lọ, ó múratán láti ṣe ohun yòówù tí Bàbá rẹ̀ bá ní kí ó ṣe. Òun kò dìtẹ̀; kàkà bẹ́ẹ̀, ó wí pé: “Kì í ṣe ìfẹ́-inú mi ni kí ó ṣẹ, bíkòṣe tìrẹ.”—Luku 22:42.

5. (a) Kí ni ó fi hàn pé Jesu ti mọ àwọn àdánwò tí òun yóò jìyà rẹ̀ lórí ilẹ̀-ayé ṣáájú? (b) Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ Isaiah 50:6 ṣe ní ìmúṣẹ?

5 Àsọtẹ́lẹ̀ náà fi hàn pé a ti fi ohun tí ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ àbájáde ṣíṣe ìfẹ́-inú Ọlọrun tó Ọmọkùnrin náà létí. Èyí ni a fi hàn nínú ohun tí ẹni tí a kọ́ náà sọ pé: “Mo fi ẹ̀yìn mi fún àwọn aluni, àti ẹ̀rẹ̀kẹ́ mi fún àwọn tí ń tu irun: èmi kò pa ojú mi mọ́ kúrò nínú ìtìjú àti ìtutọ́ sí.” (Isaiah 50:6) Gẹ́gẹ́ bí àsọtẹ́lẹ̀ náà ti fi hàn, a hùwà ìkà sí Jesu lórí ilẹ̀-ayé. Aposteli Matteu kọ̀wé pé: “Wọ́n tutọ́ sí ojú rẹ̀. . . . Awọn mìíràn gbá a lójú.” (Matteu 26:67) Èyí ṣẹlẹ̀ látọwọ́ àwọn aṣáájú ìsìn ní alẹ́ ọjọ́ Àjọ Ìrékọjá ti 33 C.E. Ní ọjọ́ kejì Jesu fi ẹ̀yìn rẹ̀ fún àwọn aluni, bí àwọn ọmọ-ogun Romu ṣe lù ú lọ́nà tí kò fi àánú hàn ṣáájú gbígbé e kọ́ sórí igi láti kú.—Johannu 19:1-3, 16-23.

6. Kí ni ó fi hàn pé Jesu kò fìgbà kan rí sọ ìgbọ́kànlé nù nínú Olùkọ́ rẹ̀, báwo sì ni a ṣe san èrè fún ìgbọ́kànlé rẹ̀?

6 Ọmọkùnrin náà, tí ó kẹ́kọ̀ọ́ ṣáájú dáradára, kò fìgbà kan sọ ìgbọ́kànlé nù nínú Olùkọ́ rẹ̀. Èyí ni ó hàn nínú ohun tí ó sọ tẹ̀lé e gẹ́gẹ́ bí àsọtẹ́lẹ̀ náà ti sọ pé: “Oluwa Jehofa yóò ràn mí lọ́wọ́: nítorí náà èmi kì yóò dààmú.” (Isaiah 50:7) A san èrè jìngbìnnì fún ìgbọ́kànlé Jesu nínú Olùkọ́ rẹ̀. Bàbá rẹ̀ gbé e ga, ní fífi ipò tí ó ga ju ti gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun yòókù lọ bùkún fún un. (Filippi 2:5-11) Ìbùkún pípabambarì ń bẹ ní ìpamọ́ fún àwa náà pẹ̀lú bí a bá fi tìgbọràn tìgbọràn rọ̀ mọ́ ẹ̀kọ́ Jehofa tí a kò sì “yípadà sí òdìkejì.” Ẹ jẹ́ kí a ṣàgbéyẹ̀wò bí a ti ṣe mú ẹ̀kọ́ náà wà lárọ̀ọ́wọ́tó títí di ọjọ́ wa.

Ètò Ẹ̀kọ́ Tí A Mú Gbòòrò Síi

7. Báwo ni Jehofa ṣe ń bá ẹ̀kọ́ rẹ̀ lọ lórí ilẹ̀-ayé?

7 Gẹ́gẹ́ bí a ti ṣàkíyèsí ṣaájú, Jehofa lo Aṣojú rẹ̀ orí ilẹ̀-ayé, Jesu Kristi, láti fúnni ní ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá ní ọ̀rúndún kìn-ínní. (Johannu 16:27, 28) Ìgbà gbogbo ni Jesu tọ́ka sí Ọ̀rọ̀ Ọlọrun gẹ́gẹ́ bí ọlá-àṣẹ fún ẹ̀kọ́ rẹ̀, ní fífi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fún àwọn wọnnì tí òun ti kọ́. (Matteu 4:4, 7, 10; 21:13; 26:24, 31) Lẹ́yìn náà, ẹ̀kọ́ Jehofa ń bá a lọ lórí ilẹ̀-ayé nípasẹ̀ iṣẹ́-òjíṣẹ́ irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ tí a kọ́. Rántí pé Jesu pàṣẹ fún wọn pé: “Nitori naa ẹ lọ kí ẹ sì máa sọ awọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ-ẹ̀yìn, . . . ẹ máa kọ́ wọn lati máa pa gbogbo ohun tí mo ti paláṣẹ fún yín mọ́.” (Matteu 28:19, 20) Nígbà tí wọ́n sọ àwọn ènìyàn di ọmọ-ẹ̀yìn, àwọn wọ̀nyí di apá kan “agbo ilé Ọlọrun, . . . ìjọ Ọlọrun alààyè.” (1 Timoteu 3:15) A tún pín wọn sí ìjọ kọ̀ọ̀kan nínú èyí tí Jehofa ti ń kọ́ wọn. (Ìṣe 14:23; 15:41; 16:5; 1 Korinti 11:16) Ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá ha ti ń bá a nìṣó ní ọ̀nà yẹn títí di ọjọ́ wa bí?

8. Báwo ni Jesu ṣe fi hàn pé a óò darí iṣẹ́ ìwàásù náà lórí ilẹ̀-ayé ṣáájú kí òpin kí ó tó dé?

8 Nítòótọ́, ó ti ṣe bẹ́ẹ̀! Ọjọ́ mẹ́ta ṣáájú ikú rẹ̀, Jesu sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé ṣáájú òpin ètò-ìgbékalẹ̀ nǹkan ìsinsìnyí, iṣẹ́ ìwàásù ńláǹlà kan yóò wáyé. Ó wí pé: “A óò . . . wàásù ìhìnrere ìjọba yii ní gbogbo ilẹ̀-ayé tí a ń gbé lati ṣe ẹ̀rí fún gbogbo awọn orílẹ̀-èdè; nígbà naa ni òpin yoo sì dé.” Jesu tẹ̀síwájú láti ṣàpèjúwe ọ̀nà tí a óò gba darí ìwàásù àti ètò ẹ̀kọ́ kárí-ayé yìí. Ó sọ̀rọ̀ nípa “olùṣòtítọ́ ati ọlọ́gbọ́n-inú ẹrú” tí yóò ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà, tàbí irin-iṣẹ́, láti pèsè oúnjẹ tẹ̀mí fún àwọn ìránṣẹ́ Rẹ̀. (Matteu 24:14, 45-47) Jehofa Ọlọrun ti lo “ẹrú” yìí láti ṣàbójútó ire Ìjọba jákèjádò ilẹ̀-ayé.

9. Àwọn wo ni ó parapọ̀ jẹ́ olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n-inú ẹrú?

9 Lónìí, àwọn ajogún Ìjọba ni ó parapọ̀ jẹ́ olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n-inú ẹrú náà. Àwọn wọ̀nyí ni àwọn Kristian ẹni-àmì-òróró, àwọn àṣẹ́kù lára àwọn 144,000, tí “í ṣe ti Kristi” tí wọ́n jẹ́ apá kan “irú-ọmọ Abrahamu.” (Galatia 3:16, 29; Ìṣípayá 14:1-3) Báwo ni o ṣe lè dá olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n-inú ẹrú náà mọ̀? Ní pàtàkì nípa isẹ́ tí wọ́n ń ṣe àti nípa rírọ̀ tímọ́tímọ́ wọn mọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, Bibeli.

10. Àwọn irin-iṣẹ́ wo ni ẹgbẹ́ ẹrú náà lò láti gbé ẹ̀kọ́ Jehofa lárugẹ?

10 Jehofa ń lo “ẹrú” yìí gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà láti kọ́ àwọn ènìyàn lónìí. Àwọn wọnnì tí wọ́n jẹ́ ti ẹgbẹ́ ẹrú náà bẹ́rẹ̀ síí lo orúkọ náà Ẹlẹ́rìí Jehofa ní 1931. Láti ìgbà náà àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ti darapọ̀ mọ́ wọn, wọ́n sì ti tẹ́wọ́gba orúkọ náà wọ́n sì darapọ̀ nínú pípòkìkí Ìjọba Ọlọrun. Ìwé ìròyìn yìí, Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa, ni olórí irin-iṣẹ́ tí “ẹrú” náà ń lò nínú iṣẹ́ ìkọ́ni náà. Bí ó ti wù kí ó rí, wọ́n tún ń lo àwọn ìtẹ̀jáde mìíràn, títí kan àwọn ìwé ńlá, ìwé kékeré, ìwé pẹlẹbẹ, ìwé àṣàrò kúkúrú, àti ìwé ìròyìn Jí!

11. Àwọn ilé-ẹ̀kọ́ wo ni “ẹrú” náà ti ṣonígbọ̀wọ́ rẹ̀, ète wo sì ni ìkọ̀ọ̀kan ilé-ẹ̀kọ́ wọ̀nyí ń ṣiṣẹ́ fún?

11 Ní àfikún síi, “ẹrú” náà ń ṣonígbọ̀wọ́ onírúurú ilé-ẹ̀kọ́. Èyí ní nínú Watchtower Bible School of Gilead, tí ó jẹ́ ìdánilẹ́kọ̀ọ́ olóṣù márùn-ún tí ń múra àwọn ọ̀dọ́ òjíṣẹ́ sílẹ̀ fun iṣẹ́-ìsìn míṣọ́nnárì ní ilẹ̀ òkèèrè, àti ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ti Ilé-Ẹ̀kọ́ Ìdánilẹ̀kọ̀ọ́ Iṣẹ́-Òjíṣẹ́ olóṣù méjì, tí ń ṣe ìdálẹ́kọ̀ọ́ fún àwọn alàgbà àti ìránṣẹ́ iṣẹ́-òjíṣẹ́ tí wọ́n jẹ́ àpọ́n fún àkànṣe iṣẹ́-àyànfúnni ti ìṣàkóso Ọlọrun. Ilé-Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́-Òjíṣẹ́ Ìjọba tún wà níbẹ̀, nínú èyí tí a ti ń fún àwọn Kristian alàgbà àti ìránṣẹ́ iṣẹ́-òjíṣẹ́ ní ìtọ́ni lóòrèkóòrè nípa ẹrù-iṣẹ́ wọn nínú ìjọ, àti Ilé-Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́-Ìsìn Aṣáájú-Ọ̀nà, tí ń mú àwọn ajíhìnrere alákòókò kíkún gbaradì láti túbọ̀ gbéṣẹ́ síi nínú ìgbòkègbodò ìwàásù wọn.

12. Kí ni apá ẹ̀ka ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ti ètò ẹ̀kọ́ yìí?

12 Apá ẹ̀ka mìíràn ti ètò ẹ̀kọ́ náà ni àwọn ìpàdé márùn-ún ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ tí a ń ṣe ní àwọn ìjọ tí ó lé ní 75,500 ti àwọn ènìyàn Jehofa kárí-ayé. O ha ń jàǹfààní lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ bí ó ti lè ṣeé ṣe tó láti inú àwọn ìpàdé wọ̀nyí bí? Nípa títẹ́tísílẹ̀ rẹ sí ìtọ́ni tí a ń fúnni, o ha ń fi hàn pé o gbàgbọ́ nítòótọ́, kí a sọ ọ́ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, pé ilé-ẹ̀kọ́ Ọlọrun ni o wà bí? Ìtẹ̀síwájú rẹ nípa tẹ̀mí ha mú un ṣe kedere sí àwọn mìíràn pé o ní “ahọ́n akẹ́kọ̀ọ́” bí?—Isaiah 50:4; 1 Timoteu 4:15, 16.

A Ń Kọ́ Wa Ní Àwọn Ìpàdé Ìjọ

13. (a) Ọ̀nà pàtàkì wo ni Jehofa gbà ń kọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀ lónìí? (b) Báwo ni a ṣe lè fi ìmọrírì wa hàn fún Ilé-Ìṣọ́nà?

13 Ní pàtàkì Jehofa ń kọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀ nípasẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀, ní lílo Ilé-Ìṣọ́nà gẹ́gẹ́ bí àrànṣe ìkẹ́kọ̀ọ́. O ha ka ìpàdé yìí sí ibi tí Jehofa ti lè kọ́ ọ bí? Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Isaiah 50:4 tọ́ka sí Jesu ní pàtàkì, ó tún lè tọ́ka sí àwọn wọnnì tí wọ́n fi ara wọn fún àwọn ìpèsè Ọlọrun láti gba “ahọ́n akẹ́kọ̀ọ́.” Ọ̀nà kan tí o gbà lè fi hàn pé o ka Ilé-Ìṣọ́nà sí ìṣúra ni nípa kíka ìtẹ̀jáde kọ̀ọ̀kan bí ó bá ti lè tètè yá tó lẹ́yìn tí o ti rí i gbà. Lẹ́yìn náà, nígbà tí a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Ilé-Ìṣọ́nà nínú ìjọ, o lè fi ìmọrírì rẹ hàn fún Jehofa nípa pípésẹ̀ síbẹ̀ àti nípa mímúrasílẹ̀ láti ṣe ìpolongo ìrètí rẹ̀ ní gbangba.—Heberu 10:23.

14. (a) Èéṣe tí sísọ̀rọ̀ ìlóhùnsí ní àwọn ìpàdé fi jẹ́ àǹfààní tí ó ṣe pàtàkì tóbẹ́ẹ̀? (b) Àwọn ọ̀rọ̀-ìlóhùnsí tí àwọn ìpẹ́ẹ̀rẹ̀ ń sọ wo ni ó ń fúnni ní ìṣírí jùlọ?

14 O ha mọrírì rẹ̀ pé nípasẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀-ìlóhùnsí rẹ ní àwọn ìpàdé, o lè lọ́wọ́ nínú ètò ẹ̀kọ́ pípabambarì ti Jehofa bí? Dájúdájú, sísọ̀rọ̀ ìlóhùnsí ní àwọn ìpàdé jẹ́ ọ̀nà kan tí ó ṣe pàtàkì láti lè ru ara wa lẹ́nìkínní kejì sókè “sí ìfẹ́ ati awọn iṣẹ́ àtàtà.” (Heberu 10:24, 25) Àwọn ọmọdé ha lè kópa nínú ètò ìtọ́ni yìí bí? Bẹ́ẹ̀ni, wọ́n lè ṣe bẹ́ẹ̀. Ọ̀rọ̀-ìlóhùnsí àtọkànwá láti ẹnu àwọn ògowẹẹrẹ sábà máa ń jẹ́ èyí tí ń fún àwọn àgbàlagbà ní ìṣírí. Nígbà mìíràn, ọ̀rọ̀-ìlóhùnsí àwọn ọmọdé ti sún àwọn ẹni titun ní àwọn ìpàdé wa láti ní ọkàn-ìfẹ́ tí ó mọ́yánlórí nínú òtítọ́ Bibeli. Àwọn ìpẹ́ẹ̀rẹ̀ kan sábà máa ń sọ ọ́ di àṣà láti ka àwọn ọ̀rọ̀-ìlóhùnsí wọn jáde tààràtà láti inú ìpínrọ̀ tàbí láti sọ ohun tí àgbàlagbà kan sọ wúyẹ́wúyẹ́ sí wọn létí. Bí ó ti wù kí ó rí, ó jẹ́ ohun tí ń fúnni ní ìṣírí jùlọ bí àwọn ọ̀rọ̀ ìlóhùnsí wọn bá jẹ́ èyí tí a múrasílẹ̀ dáradára. Irú ọ̀rọ̀-ìlóhùnsí bẹ́ẹ̀ ń mú ọlá wá fún Atóbilọ́lá Olùfúnni-Ní-Ìtọ́ni wa nítòótọ́ àti ètò ẹ̀kọ́ rẹ̀ tí a ti gbéga.—Isaiah 30:20, 21.

15. Kí ni àwọn òbí lè ṣe láti ran àwọn ọmọ lọ́wọ́ láti túbọ̀ jáfáfá síi?

15 Ìdùnnú-ayọ̀ ni ó jẹ́ láti rí àwọn ọmọdé tí ń fẹ́ láti nípìn-ín nínú yíyin Ọlọrun wa. Jesu mọrírì àwọn ọ̀rọ̀ ìyìn láti ẹnu àwọn ògowẹẹrẹ. (Matteu 21:15, 16) Kristian alàgbà kan sọ pé: “Nígbà ti mo wà ní ọmọdé, mo fẹ́ láti sọ̀rọ̀ ìlóhùnsí ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé-Ìṣọ́nà. Lẹ́yìn tí wọ́n ti bá mi múra ọ̀rọ̀-ìlóhùnsí kan sílẹ̀, bàbá mi yóò ní kí n fi ọ̀rọ̀-ìlóhùnsí náà dánrawò fún ìgbà méje ó kéré tán.” Bí ó bá ṣeé ṣe nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli ìdílé tiyín, ẹ̀yin òbí lè ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti múra àwọn ọ̀rọ̀-ìlóhùnsí sílẹ̀ ní ọ̀rọ̀ ara wọn lórí àwọn ìpínrọ̀ kan tí a ṣàyàn nínú Ilé-Ìṣọ́nà. Ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mọrírì àǹfààní ńláǹlà tí wọ́n ní láti máa nípìn-ín nínú ètò ẹ̀kọ́ Jehofa.

16. Kí ni ó ti jẹ́ àǹfààní Ilé-Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́-Òjíṣẹ́ Ìsàkóso Ọlọrun, àwọn wo ni ó sì lè forúkọ sílẹ̀ ní ilé-ẹ̀kọ́ náà?

16 Ẹ̀kọ́ ní àwọn ìpàdé Kristian mìíràn ni a tún níláti gbéyẹ̀wò gidigidi, láti ọ̀dọ̀ àwọn tí wọ́n ní àǹfààní láti gbé ìsọfúnni náà kalẹ̀ àti àwọn wọnnì tí ń tẹ́tísílẹ̀ sí ìtọ́ni tí a gbé kalẹ̀. Fún ohun tí ó lé ní 50 ọdún nísinsìnyí, Jehofa ti lo Ilé-Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́-Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọrun tí a ń ṣe lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ láti ṣe ìdálẹ́kọ̀ọ́ fún àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ọkùnrin àti obìnrin láti gbé ìhìn-iṣẹ́ Ìjọba náà kalẹ̀ lọ́nà gbígbéṣẹ́ síi. Àwọn wọnnì tí wọ́n ń darapọ̀ taápọn taápọn pẹ̀lú ìjọ lè forúkọ sílẹ̀, títí kan àwọn ènìyàn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí wá sí àwọn ìpàdé láìpẹ́ yìí, níwọ̀n bí wọ́n bá ti ń gbé ìgbésí-ayé tí ó wà ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà Kristian.

17. (a) Fún ète wo ní pàtàkì ni a fi dá Ìpàdé fún Gbogbo Ènìyàn sílẹ̀? (b) Àwọn ọ̀ràn wo ni àwọn tí ń bá gbogbo ènìyàn sọ̀rọ̀ níláti fi sọ́kàn?

17 Apá ẹ̀ka ọlọ́jọ́ pípẹ́ mìíràn ti ètò ẹ̀kọ́ náà ni Ìpàdé fún Gbogbo Ènìyàn. Bí orúkọ rẹ̀ ti fi hàn, ìpàdé yìí ni a dá sílẹ̀ ní pàtàkì láti lè fi ojú àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí mọ àwọn ìpìlẹ̀ ẹ̀kọ́ Bibeli. Nípa bẹ́ẹ̀, ẹni náà tí ń sọ ọ̀rọ̀-àsọyé náà gbọ́dọ̀ gbé ìsọfúnni náà kalẹ̀ kí àwọn wọnnì tí ń gbọ́ ìhìn-iṣẹ́ náà fún ìgbà àkọ́kọ́ baà lè lóye rẹ̀. Èyí túmọ̀ sí ṣíṣàlàyé àwọn ọ̀rọ̀ àkànṣe irú bí “awọn àgùtàn mìíràn,” “awọn arákùnrin,” àti “àwọn àṣẹ́kù,” àwọn ọ̀rọ̀ àkànṣe tí àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí lè má lóye. Níwọ̀n bí àwọn ènìyàn tí ń wá sí Ìpàdé fún Gbogbo Ènìyàn ti lè ní àwọn èrò-ìgbàgbọ́ tàbí ọ̀nà ìgbésí-ayé tí ó lòdì pátápátá sí Ìwé Mímọ́—bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹgbẹ́ àwùjọ òde-òní tẹ́wọ́gbà á—olùbánisọ̀rọ̀ náà níláti lo ọgbọ́n-ẹ̀wẹ́ kí ó má sì ṣe fi irú èrò-ìgbàgbọ́ tàbí ọ̀nà ìgbésí-ayé bẹ́ẹ̀ ṣe yẹ̀yẹ́.—Fiwé 1 Korinti 9:19-23.

18. Àwọn ìpàdé ìjọ ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ mìíràn wo ni ó wà, ète wo ni wọ́n sì ṣiṣẹ́ fún?

18 Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ jẹ́ ìpàdé kan níbi tí a ti ń kẹ́kọ̀ọ́ àwọn ìtẹ̀jáde tí a pèsè lábẹ́ ìdarí olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n-inú ẹrú náà lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ papọ̀ pẹ̀lú Bibeli. Ìwé náà Revelation—Its Grand Climax At Hand! ni èyí tí a ń kẹ́kọ̀ọ́ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilẹ̀ ní lọ́ọ́lọ́ọ́. Ìpàdé Iṣẹ́-Ìsìn ni a ṣètò láti mú àwọn ènìyàn Jehofa gbaradì láti ní ìpín kíkún rẹ́rẹ́ nínú ìwàásù ìhìnrere Ìjọba náà kí wọ́n sì sọni di ọmọ-ẹ̀yìn.—Matteu 28:19, 20; Marku 13:10.

A Ń Kọ́ Wa Ní Àwọn Ìpàdé Ńláńlá

19. Àwọn ìpéjọpọ̀ ńláńlá mìíràn wo ni “ẹrú” náà ṣètò lọ́dọọdún?

19 Fún ohun tí ó lé ní ọgọ́rùn-ún ọdún, ‘olùṣòtítọ́ ẹrú’ náà ti ṣètò àwọn àpéjọpọ̀ àti àpéjọ fún kíkọ́ àwọn Kristian tòótọ́ àti fífún wọn ní àkànṣe ìṣírí. Mẹ́ta irú àwọn ìpàdé ńláńlá bẹ́ẹ̀ ni a ń ṣe lọ́dọọdún báyìí. Àpéjọ ọlọ́jọ́ kan ń bẹ tí ẹgbẹ́ àwùjọ àwọn ìjọ tí ó parapọ̀ jẹ́ àyíká kan ń pésẹ̀ sí. Láàárín ọdún náà, àyíká kọ̀ọ̀kan tún ń ní ìpéjọpọ̀ ọlọ́jọ́ méjì tí a ń pè ní àpéjọ àyíká. Ní àfikún síi, ìpéjọpọ̀ kan ń bẹ tí a ń pè ní àpéjọpọ̀ àgbègbè, tí iye àwọn àyíká díẹ̀ ń pésẹ̀ sí. Lóòrèkóòrè àwọn àpéjọpọ̀ àgbáyé lè wà. Àwọn ìpéjọpọ̀ ńlá wọ̀nyí pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n jẹ́ àlejò láti orílẹ̀-èdè púpọ̀ máa ń jẹ́ èyí tí ń fún ìgbàgbọ́ lókun nítòótọ́ fún àwọn ènìyàn Jehofa!—Fiwé Deuteronomi 16:16.

20. Kí ni a ti ń fìgbà gbogbo tẹnumọ́ ní ìpéjọpọ̀ ńláńlá ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa?

20 Ní 1922, nígbà tí nǹkan bí 10,000 àwọn ènìyàn pàdé ní Cedar Point, Ohio, U.S.A., ọ̀rọ̀ ìṣírí olùbánisọ̀rọ̀ náà ru àwọn àyànṣaṣojú sókè pé: “Ọjọ́ gbogbo àwọn ọjọ́ ni èyí. Kíyèsíi, Ọba náà ń ṣàkóso! Ẹ̀yin ni aṣojú rẹ̀ fùn gbogbo ènìyàn. Nítorí náà ẹ fọnrere, ẹ fọnrere, ẹ fọnrere, Ọba náà àti ìjọba rẹ̀.” Irú àwọn àpéjọpọ̀ ńlá bẹ́ẹ̀ ti fìgbà gbogbo gbé ìtẹnumọ́ karí iṣẹ́ ìwàásù. Fún àpẹẹrẹ, ní àpéjọpọ̀ àgbáyé ní New York City ní 1953, a ṣe ìfilọ̀ nípa dídá ètò ìdánilẹ́kọ̀ọ́ nípa iṣẹ́ ilé-dé-ilé sílẹ̀ ní gbogbo ìjọ. Ṣíṣàmúlò rẹ̀ ti ní ipa tí ó dára lórí ìwàásù Ìjọba náà ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilẹ̀.

A Ń Kọ́ Wa Láti Ọ̀dọ̀ Ọlọrun Kí A Baà Lè Kọ́ Ẹlòmíràn

21. Àǹfààní wo ni a fẹ́ láti tẹ́wọ́gbà, kí a má baà pàdánù ète rẹ̀?

21 Dájúdájú, Jehofa ní ètò ẹ̀kọ́ àgbàyanu lórí ilẹ̀-ayé lónìí! Gbogbo àwọn tí ń lo àǹfààní náà ni Ọlọrun lè kọ́ lẹ́kọ̀ọ́, bẹ́ẹ̀ni, wọ́n lè wà lára àwọn wọnnì tí a ti fún ní “ahọ́n akẹ́kọ̀ọ́.” Ẹ wo irú àǹfààní tí ó jẹ́, bí ó ti rí gan-an, láti wà ní ilé-ẹ̀kọ́ Ọlọrun! Síbẹ̀, nígbà tí a bá ń tẹ́wọ́gba àǹfààní yìí, a kò níláti pàdánù ète rẹ̀. Jehofa kọ́ Jesu kí ó baà lè kọ́ àwọn mìíràn, Jesu sì kọ́ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ kí wọ́n baà lè ṣe irú iṣẹ́ kan náà bí òun ti ń ṣe ṣùgbọ́n lọ́nà tí ó tilẹ̀ túbọ̀ gbòòrò síi. Bákan náà, a dá wa lẹ́kọ̀ọ́ nínú ètò ẹ̀kọ́ pípabambarì ti Jehofa fún ète àtikọ́ àwọn mìíràn.—Johannu 6:45; 14:12; 2 Korinti 5:20, 21; 6:1; 2 Timoteu 2:2.

22. (a) Ìṣòro wo ni Mose àti Jeremiah ní, ṣùgbọ́n báwo ni a ṣe yanjú rẹ̀? (b) Ìdánilójú wo ni a lè ní pé Ọlọrun yóò rí síi pé a ṣàṣeparí ìwàásù Ìjọba náà?

22 O ha ń sọ bí Mose ṣe sọ pé, “Èmi kì í ṣe ẹni ọ̀rọ̀-sísọ,” tàbí bí Jeremiah ṣe sọ pé, “Èmi kò mọ ọ̀rọ̀ í sọ”? Jehofa yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ bí ó ti ṣe ràn wọ́n lọ́wọ́. Ó sọ fún Mose pé: “Èmi óò sì pẹ̀lú ẹnu rẹ.” Ó sì wí fún Jeremiah pé: “Má bẹ̀rù . . . èmi wà pẹ̀lú rẹ.” (Eksodu 4:10-12; Jeremiah 1:6-8) Nígbà tí àwọn aṣáájú ìsìn fẹ́ pa àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ lẹ́nu mọ́, Jesu wí pé: “Bí awọn wọnyi bá dákẹ́, awọn òkúta yoo ké jáde.” (Luku 19:40) Ṣùgbọ́n kò sí ìdí fún àwọn òkúta láti ké jáde nígbà náà lọ́hùn-ún, bẹ́ẹ̀ sì ni kò sí ìdí láti ṣe bẹ́ẹ̀ nísinsìnyí nítorí pé Jehofa ń lo ahọ́n àwọn akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ láti jẹ́ ìhìn-iṣẹ́ Ìjọba rẹ̀.

O Ha Lè Dáhùn Bí?

◻ Àpẹẹrẹ pípé ti ipò-ìbátan Olùkọ́ni pẹ̀lú akẹ́kọ̀ọ́ wo ni a gbé yọ ní Isaiah orí 50?

◻ Báwo ni Jehofa ti ṣe ń bá ètò ẹ̀kọ́ gbígbòòrò lọ?

◻ Kí ni àwọn apá díẹ̀ nínú ètò ẹ̀kọ́ Jehofa?

◻ Èéṣe tí ó fi jẹ́ àǹfààní pípabambarì láti nípìn-ín nínú ètò ẹ̀kọ́ Jehofa?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Ọ̀rọ̀ ìlóhùnsí àtọkànwá láti ẹnu àwọn ògowẹẹrẹ sábà máa ń fún àwọn àgbàlagbà ní ìṣírí

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́