A Ń kọ́ Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Inú Jèhófà
“Kọ́ mi láti ṣe ìfẹ́ inú rẹ, nítorí ìwọ ni Ọlọ́run mi.”—ORIN DÁFÍDÌ 143:10, NW.
1, 2. (a) Nígbà wo ni ó yẹ kí a kọ́ wa, ìfojúsọ́nà gidi wo sì ni ó yẹ kí a ní? (b) Èé ṣe tí jíjẹ́ ẹni tí Jèhófà kọ́ fi ṣe pàtàkì?
OJOOJÚMỌ́ tí ẹnì kan fi wà láàyè, tí ara rẹ̀ sì le ni a fi lè kọ́ ọ ní ohun kan tí ó ṣeyebíye. Ìyẹn jẹ́ òtítọ́ nínú ọ̀ràn tìrẹ, bẹ́ẹ̀ sì ni ó rí nínú ọ̀ràn àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú. Ṣùgbọ́n kí ní ń ṣẹlẹ̀ nígbà ikú? Kò ṣeé ṣe láti kọ́ni ní ohunkóhun tàbí láti kẹ́kọ̀ọ́ nínú ipò yẹn. Bíbélì sọ ní kedere pé àwọn òkú “kò mọ ohun kan.” Kò sí ìmọ̀ kankan ní Ṣìọ́ọ̀lù, isà òkú aráyé. (Oníwàásù 9:5, 10) Èyí ha túmọ̀ sí pé asán ni kíkọ́ tí a ń kọ́ wa, kíkó tí a ń kó ìmọ̀ jọ, já sí bí? Ìyẹn sinmi lórí ohun tí a bá kọ́ wa àti bí a ṣe lo ìmọ̀ yẹn.
2 Bí a bá kọ́ wa ní kìkì ohun ti ayé, a kò ní ọjọ́ ọ̀la pípẹ́ títí. Ṣùgbọ́n, ó dùn mọ́ni pé, a ti ń kọ́ àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn ní ìfẹ́ inú Ọlọ́run pẹ̀lú ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun. Ìpìlẹ̀ ìrètí yìí sinmi lórí jíjẹ́ ẹni tí Jèhófà, Orísun ìmọ̀ tí ń fúnni ní ìyè, kọ́.—Orin Dáfídì 94:9-12.
3. (a) Èé ṣe tí a fi lè sọ pé Jésù ni ẹni tí Ọlọ́run kọ́kọ́ kọ́? (b) Ìdánilójú wo ni a ni pé Jèhófà yóò kọ́ àwọn ẹ̀dá ènìyàn, ìyọrísí wo sì ni yóò ní?
3 A kọ́ Ọmọkùnrin Ọlọ́run, àkọ́bí rẹ̀, ẹni tí ó kọ́kọ́ jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ Rẹ̀, láti ṣe ìfẹ́ inú Bàbá rẹ̀. (Òwe 8:22-30; Jòhánù 8:28) Ní òdì kejì ẹ̀wẹ̀, Jésù fi hàn pé ẹgbàágbèje ẹ̀dá ènìyàn ni Bàbá òun yóò kọ́. Kí ni ìrètí tí ó wà fún àwa tí a kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ Ọlọ́run? Jésù wí pé: “A kọ̀wé rẹ̀ nínú àwọn Wòlíì pé, ‘A óò sì kọ́ gbogbo wọn láti ọ̀dọ̀ Jèhófà.’ Gbogbo ẹni tí ó bá ti gbọ́ láti ọ̀dọ̀ Bàbá tí ó sì ti kẹ́kọ̀ọ́ ń wá sọ́dọ̀ mi. . . . Ní òótọ́ dájúdájú ni mo wí fún yín, Ẹni tí ó bá gbà gbọ́ ní ìyè àìnípẹ̀kun.”—Jòhánù 6:45-47.
4. Báwo ni ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá ṣe ń nípa lórí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn, ìfojúsọ́nà wo sì ni wọ́n ní?
4 Jésù ń ṣàyọlò láti inú Aísáyà 54:13, èyí tí ó sọ̀rọ̀ nípa obìnrin ìṣàpẹẹrẹ ti Ọlọ́run, Síónì ti ọ̀run. Àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ní ìmúṣẹ pàtàkì sí àwọn ọmọ rẹ̀, 144,000 ọmọ ẹ̀yìn Jésù Kristi tí a fẹ̀mí bí. Àṣẹ́kù àwọn ọmọ wọ̀nyẹn nípa tẹ̀mí ṣì jẹ́ ògbóṣáṣá lónìí, ní mímú ipò iwájú nínú ètò ẹ̀kọ́ tí ń lọ kárí ayé. Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí rẹ̀, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ mìíràn ti wọ́n para pọ̀ jẹ́ “ogunlọ́gọ̀ ńlá” tún jàǹfààní láti inú jíjẹ́ ẹni tí Jèhófà kọ́. Wọ́n ní ìrètí aláìlẹ́gbẹ́ ti kíkẹ́kọ̀ọ́ láìjẹ́ pé ikú fòpin sí i. Báwo ni ìyẹn yóò ṣe ṣeé ṣe? Tóò, wọ́n ń fojú sọ́nà fún líla “ìpọ́njú ńlá” tí ń yára sún mọ́lé já àti láti gbádùn ìyè àìnípẹ̀kun lórí párádísè ilẹ̀ ayé kan.—Ìṣípayá 7:9, 10, 13-17.
Ìtẹnumọ́ Gíga Lórí Ṣíṣe Ìfẹ́ Inú Ọlọ́run
5. (a) Kí ni ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ọdún 1997? (b) Kí ni ó yẹ kí ó jẹ́ ìmọ̀lára wa nípa lílọ sí àwọn ìpàdé Kristẹni?
5 Ní 1997, ní èyí tí ó lé ní 80,000 ìjọ kárí ayé, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò fi àwọn ọ̀rọ̀ ìṣáájú nínú Orin Dáfídì 143:10 (NW) sọ́kàn pé: “Kọ́ mi láti ṣe ìfẹ́ inú rẹ.” Ìyẹn ni yóò jẹ́ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ọdún 1997. Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn, tí a gbé sí ojútáyé nínú àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba, yóò máa rán wa létí pé, àwọn ìpàdé ìjọ ní ibi títayọ lọ́lá tí a ti lè gba ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá, níbi tí a ti lè ṣàjọpín nínú ètò ìtọ́ni tí ń lọ lọ́wọ́. Nígbà tí a bá ń dara pọ̀ mọ́ àwọn ará wa ní ìpàdé kí Atóbilọ́lá Olùfúnni-Nítọ̀ọ́ni wa baà lè kọ́ wa, a lè nímọ̀lára bíi ti onísáàmù náà, ẹni tí ó kọ̀wé pé: “Inú mi dùn nígbà tí wọ́n wí fún mi pé, Ẹ jẹ́ kí a lọ sí ilé Olúwa.”—Orin Dáfídì 122:1; Aísáyà 30:20.
6. Nínú àwọn ọ̀rọ̀ Dáfídì, kí ni a jẹ́wọ́?
6 Bẹ́ẹ̀ ni, a fẹ́ kí a kọ́ wa láti ṣe ìfẹ́ inú Ọlọ́run dípò ìfẹ́ inú elénìní wa, Èṣù, tàbí ìfẹ́ inú àwọn ẹ̀dá ènìyàn aláìpé. Nítorí náà, bíi Dáfídì, a jẹ́wọ́ Ọlọ́run tí a ń jọ́sìn, tí a sì ń ṣiṣẹ́ sìn pé: “Nítorí ìwọ ni Ọlọ́run mi: jẹ́ kí ẹ̀mí rẹ dídára fà mí lọ ní ilẹ̀ tí ó tẹ́jú.” (Orin Dáfídì 143:10) Dípò fífẹ́ láti máa dara pọ̀ mọ́ àwọn oníbékebèke, Dáfídì yàn láti wà níbi tí ìjọsìn Jèhófà ti ń lọ lọ́wọ́. (Orin Dáfídì 26:4-6) Níwọ̀n bí ó ti ní ẹ̀mí Ọlọ́run láti darí ìṣísẹ̀ rẹ̀, Dáfídì lè rìn ní ipa ọ̀nà òdodo.—Orin Dáfídì 17:5; 23:3.
7. Báwo ni ẹ̀mí Ọlọ́run ṣe ṣiṣẹ́ lórí ìjọ Kristẹni?
7 Dáfídì Títóbi Jù, Jésù Kristi, mú un dá àwọn àpọ́sítélì lójú pé, ẹ̀mí mímọ́ yóò kọ́ wọn ní ohun gbogbo, yóò sì mú kí wọ́n rántí gbogbo ohun tí òun ti kọ́ wọn. (Jòhánù 14:26) Láti ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì lọ, Jèhófà ti ṣí “àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run” tí ó wà nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí a kọ sílẹ̀ payá ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀-lé. (Kọ́ríńtì Kìíní 2:10-13) Èyí ni òun ti ṣe nípasẹ̀ ọ̀nà kan tí a lè fojú rí, tí Jésù pè ní “olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n-inú ẹrú.” Ó ń pèsè oúnjẹ tẹ̀mí tí a ń gbé yẹ̀ wò nínú ètò ẹ̀kọ́ tí ó wà fún ìjọ àwọn ènìyàn Ọlọ́run kárí ayé.—Mátíù 24:45-47.
A Ń Kọ́ Wa Ní Ìfẹ́ Inú Jèhófà ní Àwọn Ìpàdé Wa
8. Èé ṣe tí ṣíṣàjọpín nínú Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ fi ṣe pàtàkì?
8 Ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ nínú Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ tí a ń ṣe lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ nínú ìjọ sábà máa ń sọ̀rọ̀ lórí fífi àwọn ìlànà Bíbélì sílò. Dájúdájú, èyí ń ràn wá lọ́wọ́ láti kojú àwọn àníyàn ìgbésí ayé. Nínú àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ mìíràn, a ń gbé àwọn òtítọ́ tí ó jinlẹ̀ nípa tẹ̀mí tàbí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì yẹ̀ wò. Ẹ wo bí a ṣe ń kọ́ wa tó nínú irú àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ bẹ́ẹ̀! Ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀, àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba máa ń kún fọ́fọ́ nítorí àwọn ìpàdé wọ̀nyí. Síbẹ̀ ní àwọn orílẹ̀-èdè kan, iye àwọn tí ń wá sí ìpàdé ti dín kù. Kí ni o rò pé ó fà á? Ó ha lè jẹ́ pé àwọn kan ti yọ̀ọ̀da kí iṣẹ́ àmúṣe wọn forí gbárí pẹ̀lú pípàdé pọ̀ wọn déédéé láti ‘runi lọ́kàn sókè sí ìfẹ́ àti sí àwọn iṣẹ́ àtàtà’? Àbí ó ha lè jẹ́ pé a ń lo ọ̀pọ̀ wákàtí nínú ìgbòkègbodò ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà tàbí ní wíwo tẹlifísọ̀n, èyí tí ó mú kí ó dà bíi pé ìtòlẹ́sẹẹsẹ kún fọ́fọ́ jù láti lè ráyè lọ sí àwọn ìpàdé? Rántí ìṣílétí tí a mí sí náà nínú Hébérù 10:23-25. Pípàdé pọ̀ fún ìtọ́ni àtọ̀runwá kò ha ṣe pàtàkì nísinsìnyí pàápàá ‘bí a ti rí ọjọ́ náà tí ń sún mọ́lé bí’?
9. (a) Báwo ni Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn ṣe ń mú wa gbára dì fún iṣẹ́ òjíṣẹ́? (b) Kí ni ó yẹ kí ó jẹ́ ìṣarasíhùwà wa nípa ìjẹ́rìí?
9 Ọ̀kan lára àwọn ẹrù iṣẹ́ wa tí ó ṣe pàtàkì jù lọ ni ṣíṣiṣẹ́sìn gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ Ọlọ́run. A ṣètò Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn láti kọ́ wa bí a ṣe lè ṣàṣeparí èyí lọ́nà tí ó gbéṣẹ́. A ń kọ́ bí a ṣe ń bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀, ohun tí a óò sọ, bí ó ṣe yẹ kí a hùwà padà nígbà tí a bá dáhùn padà lọ́nà rere, àti ohun tí ó yẹ kí a ṣe nígbà tí àwọn ènìyàn bá kọ́ ìhìn iṣẹ́ wa pàápàá. (Lúùkù 10:1-11) Bí a ṣe ń jíròrò àwọn ọ̀nà gbígbéṣẹ́, tí a sì ń ṣàṣefihàn wọn nínú ìpàdé ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ yìí, a túbọ̀ ń múra wa sílẹ̀ láti lè dé ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn kì í ṣe kìkì nígbà tí a bá ń lọ láti ilé dé ilé nìkan ṣùgbọ́n nígbà tí a bá ń wàásù ní òpópónà pẹ̀lú, ní ibi ìgbọ́kọ̀sí, nínú ọkọ̀ èrò, ní pápákọ̀ òfuurufú, níbi okòwò, tàbí ní ilé ẹ̀kọ́. Ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀bẹ̀ wa pé, “Kọ́ mi láti ṣe ìfẹ́ inú rẹ,” àwa yóò fẹ́ láti lo gbogbo àǹfààní tí a bá ní láti ṣe gẹ́gẹ́ bí Ọ̀gá wa ti rọ̀ wá pé: “Kí ìmọ́lẹ̀ yín máa tàn níwájú àwọn ènìyàn, kí wọ́n lè . . . fi ògo fún Bàbá yín tí ń bẹ ní àwọn ọ̀run.”—Mátíù 5:16.
10. Báwo ni a ṣe lè ran ‘àwọn ẹni yíyẹ’ ní tòótọ́ lọ́wọ́?
10 Nínú irú àwọn ìpàdé ìjọ bẹ́ẹ̀, a tún ń kọ́ wa láti sọ àwọn ẹlòmíràn di ọmọ ẹ̀yìn. Gbàrà tí a bá ti rí i pé ẹnì kan fi ìfẹ́ hàn tàbí pé a fi ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ síta, olórí ète wa nígbà tí a bá ń ṣe ìpadàbẹ̀wò ni láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé. Lọ́nà kan, èyí bá bí àwọn ọmọ ẹ̀yìn ‘ṣe dúró ti àwọn ẹni yíyẹ’ mú, kí wọn baà lè kọ́ wọn ní àwọn ohun tí Jésù ti pa láṣẹ. (Mátíù 10:11; 28:19, 20) Níní àwọn àrànṣe gbígbámúṣé, irú bí ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun, a ti mú wa gbára dì dáradára láti ṣàṣeparí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa kúnnákúnná. (Tímótì Kejì 4:5) Lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, bí o ṣe ń lọ sí Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn àti Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run, sakun láti lóye àwọn kókó arannilọ́wọ́ tí yóò fi ọ́ hàn gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan nínú àwọn òjíṣẹ́ Ọlọ́run tí ó tóótun dáradára, tí ń ṣe ìfẹ́ inú rẹ̀, kí o sì lo àwọn kókó arannilọ́wọ́ náà.—Kọ́ríńtì Kejì 3:3, 5; 4:1, 2.
11. Báwo ni àwọn kan ti ṣe fi ìgbàgbọ́ hàn nínú àwọn ọ̀rọ̀ tí a rí nínú Mátíù 6:33?
11 Ó jẹ́ ìfẹ́ inú Ọlọ́run pé kí a “máa bá a nìṣó, . . . ní wíwá ìjọba náà àti òdodo rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́.” (Mátíù 6:33) Béèrè lọ́wọ́ ara rẹ, ‘Báwo ni ń óò ṣe fi ìlànà yìí sílò bí ohun tí iṣẹ́ àmúṣe mi [tàbí ti alábàáṣègbéyàwó mi] ń béèrè bá forí gbárí pẹ̀lú lílọ sí ìpàdé?’ Ọ̀pọ̀ àwọn tí ó dàgbà dénú nípa tẹ̀mí yóò gbé ìgbésẹ̀ láti bá àwọn agbanisíṣẹ́ wọn sọ̀rọ̀ nípa ọ̀ràn náà. Òjíṣẹ́ alákòókò kíkún kan jẹ́ kí agbanisíṣẹ́ rẹ̀ mọ́ pé òún ní láti gba àkókò kúrò lẹ́nu iṣẹ́ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ láti baà lè máa lọ sí àwọn ìpàdé ìjọ. Ó fọwọ́ sí ìbéèrè tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ náà. Ṣùgbọ́n nítorí pé ó fẹ́ mọ ohun tí ń ṣẹlẹ̀ ní àwọn ìpàdé náà, ó ni òún fẹ́ lọ síbẹ̀. Níbẹ̀ ni ó ti gbọ́ ìfilọ̀ nípa àpéjọpọ̀ àgbègbè kan tí ń bọ̀. Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí rẹ̀, agbanisíṣẹ́ náà ṣètò láti lo odindi ọjọ́ kan ní àpéjọpọ̀ náà. Ẹ̀kọ́ wo ni èyí kọ́ ọ?
Àwọn Òbí Oníwà-bí-Ọlọ́run Ń Kọ́ Wa Ní Ìfẹ́ Inú Jèhófà
12. Kí a lè kọ́ àwọn ọmọ ní ìfẹ́ inú Jèhófà, kí ni ó yẹ kí àwọn Kristẹni òbí fi sùúrù àti ìdúró gbọn-in ṣe?
12 Ṣùgbọ́n kì í ṣe àwọn ìpàdé ìjọ àti àpéjọpọ̀ nìkan ni ìpèsè tí a fi ń kọ́ wa láti ṣe ìfẹ́ inú Ọlọ́run. A pàṣẹ fún àwọn òbí oníwà-bí-Ọlọ́run láti tọ́ àwọn ọmọ wọn, láti bá wọn wí, kí wọ́n sì tọ́ wọn dàgbà láti yin Jèhófà àti láti ṣe ìfẹ́ inú rẹ̀. (Orin Dáfídì 148:12, 13; Òwe 22:6, 15) Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ béèrè pé kí a mú “àwọn ògo wẹẹrẹ” wa lọ sí àwọn ìpàdé níbi tí wọ́n ti lè ‘gbọ́, kí wọ́n sì kẹ́kọ̀ọ́,’ ṣùgbọ́n nípa ti kíkọ́ wọn láti inú Ìwé Mímọ́ nínú ilé ńkọ́? (Diutarónómì 31:12, NW; Tímótì Kejì 3:15) Ọ̀pọ̀ ìdílé ti bẹ̀rẹ̀ ètò ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ìdílé tí a ń ṣe déédéé tọkàntọkàn, ṣùgbọ́n kò pẹ́ kò jìnnà wọ́n yọ̀ǹda kí ó di ségesège tàbí tí wọn tilẹ̀ pa á tì. Ìwọ́ ha ti ní irú ìrírí yẹn bí? Ìwọ yóò ha parí èrò sí pé àbá náà láti ní irú ìkẹ́kọ̀ọ́ déédéé bẹ́ẹ̀ kò tọ́ tàbí pé ìdílé tìrẹ yàtọ̀ débi pé àbá náà kò lè ṣiṣẹ́ nínú ọ̀ràn tìrẹ? Ohun yòó wù kí ipò náà jẹ́, ẹ̀yin òbí, ẹ jọ̀wọ́, ẹ ṣàyẹ̀wò àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ àtàtà náà “Ogún Wa Nípa Tẹ̀mí Tí Ó Dọ́ṣọ̀” àti “Èrè Ìtẹpẹlẹmọ́” nínú Ilé-Ìṣọ́nà ti August 1, 1995.
13. Báwo ni àwọn ìdílé ṣe lè jàǹfààní láti inú gbígbé ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ojoojúmọ́ yẹ̀ wò?
13 A rọ àwọn ìdílé láti sọ ọ di àṣà láti máa ṣàyẹ̀wò ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ojoojúmọ́ láti inú ìwé Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́. Kíka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ náà àti àlàyé rẹ̀ dára, ṣùgbọ́n jíjíròrò ẹsẹ Ìwé Mímọ́ náà àti fífi í sílò tún ṣàǹfààní. Fún àpẹẹrẹ, bí o bá ń gbé Éfésù 5:15-17 yẹ̀ wò, àwọn mẹ́ńbà ìdílé lè ronú nípa bí ‘wọ́n ṣe lè ra àkókò rírọgbọ padà’ fún ìdákẹ́kọ̀ọ́, láti ṣàjọpín nínú irú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún kan, àti láti bójú tó àwọn iṣẹ́ àyànfúnni yòó kù ti ìṣàkóso Ọlọ́run. Bẹ́ẹ̀ ni, ìjíròrò ìdílé lórí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ojoojúmọ́ lè sún ẹnì kan tàbí ọ̀pọ̀lọpọ̀ láti “máa bá a lọ ní ríróye [ní kíkún sí i] ohun tí ìfẹ́ inú Jèhófà jẹ́.”
14. Irú olùkọ́ wo ni Diutarónómì 6:6, 7 fi hàn pé ó yẹ kí àwọn òbí jẹ́, kí ni èyí sì ń béèrè?
14 Àwọn òbí gbọ́dọ̀ jẹ́ olùkọ́ aláápọn fún àwọn ọmọ wọn. (Diutarónómì 6:6, 7) Ṣùgbọ́n kì í wulẹ̀ ṣe ọ̀ràn sísọ̀rọ̀ ṣáá tàbí pípàṣẹ fún àwọn ọmọ wọn. Bàbá àti màmá tún ní láti fetí sílẹ̀, lọ́nà yẹn, wọn yóò lè mọ ohun tí ó yẹ kí wọ́n ṣàlàyé, kí wọ́n mú ṣe kedere, kí wọ́n ṣàpèjúwe, tàbí kí wọ́n tún sọ. Nínú ìdílé Kristẹni kan, àwọn òbí ru ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ fàlàlà sókè nípa fífún àwọn ọmọ wọn níṣìírí láti béèrè ìbéèrè nípa àwọn nǹkan tí wọn kò lóye tàbí tí ń dà wọ́n láàmú. Wọ́n tipa báyìí lóye pé, ọ̀dọ́langba kan ní ìṣòro lílóye pé Jèhófà kò ní ìbẹ̀rẹ̀. Ó ṣeé ṣe fún àwọn òbí náà láti lo ìsọfúnni láti inú àwọn ìtẹ̀jáde Watch Tower Society tí ń fi hàn pé àkókò àti gbalasa òfuurufú ni a gbà pé kò lópin. Ìyẹn ṣèrànwọ́ láti mú kókó náà ṣe kedere, ó sì tẹ́ ọmọkùnrin náà lọ́rùn. Nítorí náà, fi sùúrù dáhùn ìbéèrè àwọn ọmọ rẹ lọ́nà tí ó ṣe kedere àti láti inú Ìwé Mímọ́, ní ríràn wọ́n lọ́wọ́ láti rí i pé kíkọ́ láti ṣe ìfẹ́ inú Ọlọ́run lè mú ìtẹ́lọ́rùn gidigidi wá. Kí tún ni ohun mìíràn tí a ń kọ́ àwọn ènìyàn Ọlọ́run—lọ́mọdé lágbà—lónìí?
A Ń Kọ́ Wa Láti Nífẹ̀ẹ́ àti Láti Jagun
15. Nígbà wo ni a lè dán ìjójúlówó ìfẹ́ ará wa wò?
15 Ní ìbámu pẹ̀lú àṣẹ tuntun tí Jésù pa, ‘Ọlọ́run kọ́ wa láti nífẹ̀ẹ́ ara wa lẹ́nì kíní kejì.’ (Tẹsalóníkà Kíní 4:9) Nígbà tí nǹkan bá rọgbọ, tí ó sì ń dùn yùngbà, a lè rò pé a nífẹ̀ẹ́ gbogbo àwọn ará wa. Síbẹ̀, kí ni ń ṣẹlẹ̀ nígbà tí èdè àìyedè bá ṣẹlẹ̀ tàbí nígbà tí inú bá bí wa nítorí ohun tí Kristẹni kan sọ tàbí ṣe? Níbi tí ọ̀ràn dé yìí a lè dán bí ìfẹ́ wa ṣe jẹ́ ojúlówó tó wò. (Fi wé Kọ́ríńtì Kejì 8:8.) Kí ni Bíbélì kọ́ wa láti ṣe nínú irú ipò bẹ́ẹ̀? Ọ̀kan nínú rẹ̀ ni láti làkàkà láti fi ìfẹ́ hàn lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́. (Pétérù Kìíní 4:8) Kàkà tí a óò fi máa wá ire ara wa, nípa bíbínú nítorí àwọn ọ̀ràn tí kò tó nǹkan, tàbí kíkọ àkọsílẹ̀ ìṣeniléṣe, a gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìfẹ́ bo ọ̀pọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀. (Kọ́ríńtì Kìíní 13:5) A mọ̀ pé èyí ni ìfẹ́ inú Ọlọ́run, nítorí ohun tí Ọ̀rọ̀ rẹ̀ fi ń kọ́ni nìyẹn.
16. (a) Irú ogun wo ni a kọ́ àwọn Kristẹni láti lọ́wọ́ nínú rẹ̀? (b) Báwo ni a ṣe mú wa gbára dì?
16 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ kì yóò so ìfẹ́ pọ̀ mọ́ ogun, èyí tí ó kẹ́yìn yìí ni ohun tí a ń kọ́ wa, ṣùgbọ́n ó jẹ́ irú ogun kan tí ó yàtọ̀ pátápátá. Dáfídì mọ̀ pé Jèhófà ni òún gbára lé láti kọ́ òun ní bí òun yóò ṣe lè jagun, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ní àkókò tirẹ̀, ìyẹn ní bíbá àwọn ọ̀tá Ísírẹ́lì jagun gidi nínú. (Sámúẹ́lì Kìíní 17:45-51; 19:8; Àwọn Ọba Kìíní 5:3; Orin Dáfídì 144:1) Ogun tiwa lónìí ńkọ́? Àwọn ohun ìjà wa kì í ṣe ti ẹran ara. (Kọ́ríńtì Kejì 10:4) Ogun tiwa jẹ́ ogun nípa tẹ̀mí, nítorí èyí ni ó sì ṣe yẹ kí a gbé ìhámọ́ra tẹ̀mí wọ̀. (Éfésù 6:10-13) Nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti àwọn ènìyàn rẹ̀ tí ó kó jọ, Jèhófà ń kọ́ wa láti ja ogun àjàyè nípa tẹ̀mí.
17. (a) Àwọn ọgbọ́n àyínìke wo ni Èṣù ń lò láti dárí wa síhà ọ̀dọ̀ rẹ̀? (b) Kí sì ni ó yẹ kí a fọgbọ́n yẹra fún?
17 Ní àwọn ọ̀nà ẹ̀tàn àti àyínìke, Èṣù sábà máa ń lo àwọn ohun ti ayé, àwọn apẹ̀yìndà, àti àwọn alátakò òtítọ́ mìíràn láti lè darí wa sí àwọn ọ̀ràn tí kò níláárí. (Tímótì Kìíní 6:3-5, 11; Títù 3:9-11) Ó dà bí ẹni pé ó rí i pé òun kò ní agbára tó láti borí wa nípasẹ̀ lílo ìgbéjàkò ojúkoojú, ní tààràtà, nítorí náà, ó ń gbìyànjú láti mú wa kọsẹ̀ nípa mímú kí a sọ àwọn ìráhùn wa àti ìbéèrè òmùgọ̀ jáde, àwọn ohun tí kò ní ìníyelórí tẹ̀mí kankan. Gẹ́gẹ́ bí jagunjagun tí ó wà lójúfò, ó yẹ kí a wà lójúfò sí irú àwọn ewu bẹ́ẹ̀ bí a ṣe wà lójúfò sí àwọn ìgbéjàkò ojúkoojú.—Tímótì Kìíní 1:3, 4.
18. Kí ni ṣíṣàìwà láàyè fún ara wa mọ́ ní nínú?
18 A kò gbé ìfẹ́ ọkàn ènìyàn tàbí ìfẹ́ inú àwọn orílẹ̀-èdè lárugẹ. Jèhófà ti fi àpẹẹrẹ Jésù kọ́ wa pé, a kò gbọdọ̀ wà láàyè fún ara wa mọ́; kàkà bẹ́ẹ̀, a ní láti dìhámọ́ra pẹ̀lú irú ìtẹ̀sí èrò kan náà tí Kristi Jésù ní, kí a sì wà láàyè fún ṣíṣe ìfẹ́ inú Ọlọ́run. (Kọ́ríńtì Kejì 5:14, 15) Nígbà àtijọ́, a ti lè gbé ìgbésí ayé aláṣerégèé, aláìníkòóra-ẹni-níjàánu, ní fífi àkókò ṣíṣeyebíye ṣòfò. Àríyá aláriwo, ìfagagbága ọtí mímu, àti ìwà pálapàla ni a fi ń dá ayé búburú yìí mọ̀. Nísinsìnyí tí a ti kọ́ wa ní ìfẹ́ inú Ọlọ́run, a kò ha kún fún ìmoore pé a ti yà wá sọ́tọ̀ kúrò nínú ayé oníwà ìbàjẹ́ yìí? Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a ja ìjà tí ó gbóná janjan nípa tẹ̀mí láti yẹra fún lílọ́wọ́ nínú àwọn ìṣe ayé tí ń sọni di ẹlẹ́gbin.—Pétérù Kìíní 4:1-3.
Kíkọ́ Wa Láti Ṣe Ara Wa Láǹfààní
19. Jíjẹ́ ẹni tí Jèhófà kọ́ ní ìfẹ́ inú rẹ̀ àti ṣíṣe é yóò yọrí sí àwọn àǹfààní wo?
19 Ó ṣe pàtàkì láti mọ̀ pé, kíkọ́ wa láti ṣe ìfẹ́ inú Jèhófà yóò ṣe wá láǹfààní gidigidi. Lọ́nà tí ó yéni, a gbọ́dọ̀ ṣe ipa tiwa nípa fífún ohun tí a ń kọ́ ní àfiyèsí gidigidi, kí a baà lè kọ́ àwọn ìtọ́ni tí a ń rí gbà nípasẹ̀ Ọmọkùnrin rẹ̀ àti Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti nípasẹ̀ àwọn ènìyàn tí òún kó jọ, kí a sì lè tẹ̀ lé e. (Aísáyà 48:17, 18; Hébérù 2:1) Bí a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, a óò fún wa lókun láti dúró gbọn-in ní àwọn àkókò alájàálù wọ̀nyí, a óò sì lè la ẹ̀fúùfù tí ń bẹ níwájú já. (Mátíù 7:24-27) Àní nísinsìnyí pàápàá, a óò mú inú Ọlọ́run dùn nípa ṣíṣe ìfẹ́ inú rẹ̀, a óò sì máa ní ìdánilójú pé a ti dáhùn àwọn àdúrà wa. (Jòhánù 9:31; Jòhánù Kìíní 3:22) A óò sì gbádùn ojúlówó ayọ̀.—Jòhánù 13:17.
20. Kí ni yóò dára kí o máa ṣàṣàrò lé lórí bí o ṣe ń rí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ọdún jálẹ̀ 1997?
20 Jálẹ̀ ọdún 1997, a óò fìgbà gbogbo ní àǹfààní láti ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ọdún àti láti gbé e yẹ̀ wò, Orin Dáfídì 143:10 (NW): “Kọ́ mi láti ṣe ìfẹ́ inú rẹ.” Bí a ti ń ṣe èyí, ẹ jẹ́ kí a lo díẹ̀ nínú àwọn àkókò náà láti ronú lórí àwọn ohun tí Ọlọ́run ti pèsè fún wa láti lè kọ́ wa, gẹ́gẹ́ bí a ṣe fi hàn lókè yìí. Ẹ sì jẹ́ kí a lo irú ṣíṣàṣàrò lórí àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn gẹ́gẹ́ bí ohun ìsúnniṣe láti gbégbèésẹ̀ lọ́nà tí ó bá àrọwà yẹn mu, ní mímọ̀ pé “ẹni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ inú Ọlọ́run ni yóò dúró títí láé.”—Jòhánù Kìíní 2:17.
Báwo Ni Ìwọ Yóò Ṣe Dáhùn?
◻ Àwọn wo ni a ń kọ́ lónìí láti ṣe ìfẹ́ inú Jèhófà?
◻ Báwo ni Orin Dáfídì 143:10 ṣe yẹ kí ó nípa lórí wa ní 1997?
◻ Báwo ni a ti ṣe kọ́ wa láti ṣe ìfẹ́ inú Jèhófà?
◻ Kí ni a ń béèrè lọ́wọ́ àwọn òbí Kristẹni nínú kíkọ́ àwọn ọmọ wọn?