Jehofa—Ọlọrun Tí Ń Kọ́ni
“A óò sì kọ́ gbogbo wọn lati ọ̀dọ̀ Jehofa.”—JOHANNU 6:45.
1. Níbo ní Jesu ti ṣe iṣẹ́-ìyanu, kí ni ó sì ń ṣe níbẹ̀ nísinsìnyí?
JESU KRISTI ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe àwọn iṣẹ́-ìyanu tán ni, a sì rí i nísinsìnyí tí ń kọ́ni nínú sinagogu ní Kapernaumu, lẹ́bàá Òkun Galili. (Johannu 6:1-21, 59) Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ṣiyèméjì nígbà tí ó sọ pé: “Èmi ti sọ̀kalẹ̀ wá lati ọ̀run.” Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í kùn pé: “Jesu ọmọkùnrin Josefu ha kọ́ yii, ẹni tí awa mọ baba ati ìyá rẹ̀? Bawo ni ó ṣe jẹ́ tí ó wá ń wí nísinsìnyí pé, ‘Emi ti sọ̀kalẹ̀ wá lati ọ̀run’?” (Johannu 6:38, 42) Ní bíbá wọn wí, Jesu polongo pé: “Kò sí ènìyàn kankan tí ó lè wá sọ́dọ̀ mi láìjẹ́ pé Baba, tí ó rán mi, fà á; dájúdájú emi yoo sì jí i dìde ní ìkẹyìn ọjọ́.”—Johannu 6:44.
2. Ìpìlẹ̀ wo ni ó wà fún gbígba ìlérí Jesu nípa àjíǹde gbọ́?
2 Ẹ wo irú ìlérí àgbàyanu tí ó jẹ́—láti jí dìde ní ìkẹyìn ọjọ́, nígbà tí Ìjọba Ọlọrun bá ń ṣàkóso! A lè gba ìlérí yìí gbọ́ nítorí pé Bàbá náà, Jehofa Ọlọrun, mú un dá wa lójú. (Jobu 14:13-15; Isaiah 26:19) Níti tòótọ́, Jehofa, ẹni tí ó kọ́ni pé àwọn òkú yóò jí dìde, ni “olùkọ́ tí ó ju gbogbo olùkọ́ lọ.” (Jobu 36:22, Today’s English Version) Ní dídarí àfiyèsí sí ẹ̀kọ́ Bàbá náà, Jesu sọ lẹ́yìn náà pé: “A kọ̀wé rẹ̀ ninu awọn Wòlíì pé, ‘A óò sì kọ́ gbogbo wọn lati ọ̀dọ̀ Jehofa.’”—Johannu 6:45.
3. Àwọn ìbéèrè wo ni a óò gbé yẹ̀wò?
3 Dájúdájú, àǹfààní ni yóò jẹ́ láti wà lára àwọn wọnnì tí wòlíì Isaiah kọ̀wé nípa wọn pé: “A óò sì kọ́ gbogbo àwọn ọmọ rẹ láti ọ̀dọ̀ Oluwa.” (Isaiah 54:13) A ha lè wà lára wọn bí? Àwọn wo ni ó ti dàbí ọmọ fún un tí wọ́n sì ti gba àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀? Kí ni àwọn ẹ̀kọ́ Jehofa tí ó ṣe pàtàkì tí a gbọ́dọ̀ mọ̀ kí a sì ṣiṣẹ́ lé lórí láti lè rí ìbùkún rẹ̀ gbà? Báwo ni Jehofa ṣe kọ́ni ní ìgbà àtijọ́, ó ha sì ń kọ́ni lọ́nà kan náà lónìí bí? Àwọn ìbéèrè wọ̀nyí ni a óò gbé yẹ̀wò.
Bàbá, Olùkọ́, Ọkọ
4. Àwọn wo ni ọmọkùnrin Jehofa tí wọ́n kọ́kọ́ gba ẹ̀kọ́ rẹ̀?
4 Jehofa kọ́kọ́ di Bàbá àti Olùkọ́ nígbà tí ó dá Ọmọkùnrin bíbí rẹ̀ kanṣoṣo, Jesu ṣáájú kí ó tó di ènìyàn. Ẹni yìí ni a pè ní “Ọ̀rọ̀” nítorí pé òun ni Olórí Agbọ̀rọ̀sọ fún Jehofa. (Johannu 1:1, 14; 3:16) Ọ̀rọ̀ náà ṣiṣẹ́sìn “lọ́dọ̀ [Bàbá náà] gẹ́gẹ́ bí ọ̀gá òṣìṣẹ́,” ó sì kẹ́kọ̀ọ́ dáradára láti inú ẹ̀kọ́ Bàbá rẹ̀. (Owe 8:22, 30, NW) Níti tòótọ́, ó di Aṣojú, nípasẹ̀ ẹni tí Bàbá náà dá ohun gbogbo mìíràn, títí kan “àwọn ọmọ Ọlọrun” tí wọ́n jẹ́ ẹ̀mí. Ẹ wo bí wọn yóò ti yọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ tó pé Ọlọrun kọ́ wọn! (Jobu 1:6; 2:1; 38:7; Kolosse 1:15-17) Lẹ́yìn náà, a dá ẹ̀dá ènìyàn àkọ́kọ́, Adamu. Òun pẹ̀lú jẹ́ “ọmọkùnrin Ọlọrun,” Bibeli sì ṣípayá pé Jehofa fún un ní ìtọ́ni.—Luku 3:38; Genesisi 2:7, 16, 17.
5. Àǹfààní tí ó ṣeyebíye wo ni Adamu pàdánù, síbẹ̀ ta ni Jehofa kọ́, èésìtiṣe?
5 Ó bani lọ́kàn jẹ́ pé, Adamu, nípasẹ̀ àìgbọràn rẹ̀ tí ó fínnúfíndọ̀ ṣe, pàdánù àǹfààní bíbá a nìṣó láti jẹ́ ọmọkùnrin Ọlọrun. Nítorí náà, àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀ kò lè fi pẹ̀lú ẹ̀tọ́ jẹ́wọ́ ipò-ìbátan jíjẹ́ àwọn ọmọkùnrin Ọlọrun kìkì lórí ìpìlẹ̀ ìbí. Síbẹ̀, Jehofa kọ́ àwọn ẹ̀dá ènìyàn aláìpé tí wọ́n bá wò ó fún ìtọ́sọ́nà. Fún àpẹẹrẹ, Noa fi ẹ̀rí hàn pé òun jẹ́ “olóòótọ́” tí ó “bá Ọlọrun rìn,” Jehofa sì tìtorí èyí fún Noa ní ìtọ́ni. (Genesisi 6:9, 13–7:5) Nípasẹ̀ ìgbọràn rẹ̀, Abrahamu fi ẹ̀rí hàn pé òun jẹ́ “ọ̀rẹ́ Ọlọrun,” nítorí náà òun pẹ̀lú di ẹni tí Jehofa kọ́.—Jakọbu 2:23; Genesisi 12:1-4; 15:1-8; 22:1, 2.
6. Ta ni Jehofa wá kà sí “ọmọ” rẹ̀, irú olùkọ́ wo ni òun sì jẹ́ fún wọn?
6 Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún, ní ọjọ́ Mose, Jehofa wọnú ipò-ìbátan onímájẹ̀mú pẹ̀lú orílẹ̀-èdè Israeli. Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí rẹ̀, orílẹ̀-èdè náà di àwọn ènìyàn tí òun yàn a sì kà wọ́n sí “ọmọ” rẹ̀. Ọlọrun wí pé: “Ọmọ mi ni Israeli.” (Eksodu 4:22, 23; 19:3-6; Deuteronomi 14:1, 2) Lórí ìpìlẹ̀ ipò-ìbátan onímájẹ̀mú náà, àwọn ọmọ Israeli lè sọ, gẹ́gẹ́ bí wòlíì Isaiah ṣe sọ pé: “Ìwọ Oluwa, ni bàbá wa.” (Isaiah 63:16) Jehofa tẹ́wọ́gba ẹrù-iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí bàbá ó sì fi tìfẹ́tìfẹ́ kọ́ àwọn ọmọ rẹ̀, Israeli. (Orin Dafidi 71:17; Isaiah 48:17, 18) Níti tòótọ́, nígbà tí wọ́n di aláìṣòtítọ́, ó rọ̀ wọ́n tàánú tàánú pé: “Padà, ẹ̀yin apẹ̀yìndà ọmọ.”—Jeremiah 3:14.
7. Ipò-ìbátan wo ni Israeli ní pẹ̀lú Jehofa?
7 Gẹ́gẹ́ bí àbájáde ipò-ìbátan onímájẹ̀mú pẹ̀lú Israeli, lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ Jehofa di Ọkọ orílẹ̀-èdè náà, orílẹ̀-èdè náà sì di aya rẹ̀ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ. Wòlíì Isaiah kọ̀wé nípa rẹ̀ pé: “Atóbilọ́lá Ẹlẹ́dàá rẹ ni ọkọ tí ó ni ọ́, Jehofa àwọn ọmọ ogun ní orúkọ rẹ̀.” (Isaiah 54:5, NW; Jeremiah 31:32) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Jehofa ṣe ojúṣe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọkọ lọ́nà tí ó lọ́lá, orílẹ̀-èdè Israeli di aláìṣòtítọ́ aya. Jehofa wí pé: “Gẹ́gẹ́ bí aya ti í fi àrékérekè lọ kúrò lọ́dọ̀ ọkọ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin ti hùwà àrékérekè sí mi, ìwọ ilé Israeli.” (Jeremiah 3:20) Jehofa kò dáwọ́ dúró láti máa rọ àwọn ọmọ aya rẹ̀ aláìṣòtítọ́; ó ń bá a nìṣó láti jẹ́ “Atóbilọ́lá Olùfúnni ní ìtọ́ni wọn.”—Isaiah 30:20, NW; 2 Kronika 36:15.
8. Àní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Israeli jẹ́ orílẹ̀-èdè kan tí Jehofa ta nù, aya ìṣàpẹẹrẹ amápẹẹrẹṣẹ wo ni òun ní síbẹ̀síbẹ̀?
8 Nígbà tí Israeli kọ Ọmọkùnrin Rẹ̀, Jesu Kristi sílẹ̀, tí wọ́n sì pa á, Ọlọrun kọ òun náà sílẹ̀ nígbẹ̀yìn gbẹ́yín. Nítorí náà orílẹ̀-èdè Júù yẹn kì í ṣe aya ìṣàpẹẹrẹ fún un mọ́, bẹ́ẹ̀ sì ni òun kì í ṣe Bàbá àti Olùkọ́ fún àwọn ọmọ rẹ̀ oníwà wíwọ́ mọ́. (Matteu 23:37, 38) Bí ó ti wù kí ó rí, Israeli wulẹ̀ jẹ́ aya àpẹẹrẹ-irú, tàbí aya ìṣàpẹẹrẹ. Aposteli Paulu ṣàyọlò Isaiah 54:1, tí ó sọ̀rọ̀ nípa “àgàn” tí ó yàtọ̀ tí ó sì dáyàtọ̀ kedere sí “obìnrin náà tí ó ní ọkọ,” orílẹ̀-èdè Israeli àbínibí. Paulu ṣípayá pé àwọn Kristian ẹni-àmì-òróró ni ọmọ “àgàn” náà, tí òun pè ní “Jerusalemu ti òkè.” Obìnrin ìṣàpẹẹrẹ amápẹẹrẹṣẹ yìí ní nínú ètò-àjọ Ọlọrun ti àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí ní òkè-ọ̀run.—Galatia 4:26, 27.
9. (a) Àwọn wo ni Jesu ń tọ́ka sí nígbà tí ó sọ pé ‘Jehofa yóò sì kọ́ àwọn ọmọ rẹ’? (b) Lórí ìpìlẹ̀ wo ni àwọn ènìyàn fi ń di ọmọ tẹ̀mí fún Ọlọrun?
9 Nípa báyìí, nínú sinagogu Kapernaumu, nígbà tí Jesu ṣàyọlò àsọtẹ́lẹ̀ Isaiah pé: “A óò sì kọ́ gbogbo àwọn ọmọ rẹ láti ọ̀dọ̀ Oluwa,” ó ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn wọnnì tí wọn yóò di “ọmọ” ti “Jerusalemu ti òkè,” ètò-àjọ Ọlọrun ní ọ̀run tí ó dàbí aya rẹ̀. Nípa títẹ́wọ́gba ẹ̀kọ́ aṣojú Ọlọrun láti ọ̀run, Jesu Kristi, àwọn Júù tí wọ́n tẹ́tísílẹ̀ wọnnì lè di ọmọ obìnrin Ọlọrun ní ọ̀run tí ó yàgàn tẹ́lẹ̀ kí wọ́n sì parapọ̀ di “orílẹ̀-èdè mímọ́,” “Israeli Ọlọrun” nípa tẹ̀mí. (1 Peteru 2:9, 10; Galatia 6:16) Ní ṣíṣàpèjúwe àǹfààní pípabambarì tí Jesu mú wà lárọ̀ọ́wọ́tó fún dídi ọmọ tẹ̀mí ti Ọlọrun, aposteli Johannu kọ̀wé pé: “Ó wá sí ilé oun fúnra rẹ̀, ṣugbọn awọn ènìyàn oun fúnra rẹ̀ kò gbà á wọlé. Bí ó ti wù kí ó rí, gbogbo awọn tí wọ́n gbà á, awọn ni oun fún ní ọlá-àṣẹ lati di ọmọ Ọlọrun, nitori pé wọ́n ń lo ìgbàgbọ́ ninu orúkọ rẹ̀.”—Johannu 1:11, 12.
Àwọn Ẹ̀kọ́ Jehofa Tí Ó Ṣe Pàtàkì
10. Kété lẹ́yìn ìṣọ̀tẹ̀ ní Edeni, kí ni ohun tí Jehofa kọ́ni nípa “irú-ọmọ” náà, ta sì ni ẹ̀rí fi hàn pé ó jẹ́ Irú-Ọmọ náà?
10 Jehofa, gẹ́gẹ́ bí Bàbá onífẹ̀ẹ́, ń fi àwọn ète rẹ̀ tó àwọn ọmọ rẹ̀ létí. Nípa báyìí, nígbà tí áńgẹ́lì ọlọ̀tẹ̀ kan sún tọkọtaya ẹ̀dá ènìyàn àkọ́kọ́ láti ṣàìgbọràn, ojú-ẹsẹ̀ ní Jehofa sọ ohun tí òun yóò ṣe láti mú ète rẹ̀ ṣẹ láti sọ ilẹ̀-ayé di paradise. Ó wí pé òun yóò fi ọ̀tá sáàárín “ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀ naa,” ẹni tíí ṣe Satani Èṣù, “àti obìnrin náà.” Lẹ́yìn náà ó ṣàlàyé pé “irú-ọmọ” obìnrin náà yóò fọ Satani “ní orí,” lọ́nà tí yóò yọrí sí ikú. (Genesisi 3:1-6, 15; Ìṣípayá 12:9; 20:9, 10) Gẹ́gẹ́ bí a ti ṣàkíyèsí, obìnrin náà—tí a mọ̀ sí “Jerusalemu ti òkè” lẹ́yìn náà—ni ètò-àjọ Ọlọrun ti àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí ní ọ̀run. Ṣùgbọ́n ta ni “irú-ọmọ” rẹ̀? Ọmọkùnrin Ọlọrun, Jesu Kristi ni, ẹni náà tí a rán wá láti ọ̀run ẹni náà tí yóò sì pa Satani run nígbẹ̀yìn gbẹ́yín.—Galatia 4:4; Heberu 2:14; 1 Johannu 3:8.
11, 12. Báwo ni Jehofa ṣe mú ẹ̀kọ́ rẹ̀ tí ó ṣe pàtàkì nípa “irú-ọmọ” náà gbòòrò síi?
11 Jehofa mú ẹ̀kọ́ tí ó ṣe pàtàkì yìí gbòòrò síi nípa “irú-ọmọ” náà nígbà tí ó ṣèlérí fún Abrahamu pé: “Ní bíbísíi èmi óò mú irú-ọmọ rẹ bí síi bí ìràwọ̀ ojú-ọ̀run . . . Àti nínú irú-ọmọ rẹ ni a óò bùkún fún gbogbo orílẹ̀-èdè ayé.” (Genesisi 22:17, 18) Jehofa lo aposteli Paulu láti ṣàlàyé pé Jesu Kristi ni Irú-Ọmọ Abrahamu tí a ṣèlérí náà ṣùgbọ́n pé àwọn mìíràn pẹ̀lú yóò di apákan “irú-ọmọ” náà. Paulu kọ̀wé pé: “Bí ẹ̀yin bá jẹ́ ti Kristi, ẹ̀yin jẹ́ irú-ọmọ Abrahamu níti tòótọ́, ajogún ní ìsopọ̀ pẹlu ìlérí.”—Galatia 3:16, 29.
12 Jehofa tún ṣípayá pé Kristi, Irú-Ọmọ náà, yóò wá láti ìlà-ìdílé aládé ti Juda àti pé tirẹ̀ ní “àwọn ènìyàn yóò máa gbọ́.” (Genesisi 49:10) Níti Ọba Dafidi ti ẹ̀yà Juda, Jehofa ṣèlérí pé: “Irú-ọmọ rẹ . . . ni èmi óò mú pẹ́ títí, àti ìtẹ́ rẹ bí ọjọ́ ọ̀run. Irú-ọmọ rẹ yóò dúró títí láéláé, àti ìtẹ́ rẹ bí oòrùn níwájú mi.” (Orin Dafidi 89:3, 4, 29, 36) Nígbà tí áńgẹ́lì Gabrieli kéde ìbí Jesu, ó ṣàlàyé pé ọmọ náà jẹ́ Olùṣàkóso tí Ọlọrun ti yànsípò, Irú-Ọmọ Dafidi. Gabrieli wí pé: “Ẹni yii yoo jẹ́ ẹni ńlá a óò sì pè é ní Ọmọkùnrin Ẹni Gíga Jùlọ; Jehofa Ọlọrun yoo sì fi ìtẹ́ Dafidi baba rẹ̀ fún un, . . . kì yoo sì sí òpin fún ìjọba rẹ̀.”—Luku 1:32, 33; Isaiah 9:6, 7; Danieli 7:13, 14.
13. Láti lè rí ìbùkún Jehofa gbà, báwo ni a gbọ́dọ̀ ṣe dáhùnpadà sí ẹ̀kọ́ rẹ̀?
13 Láti lè rí ìbùkún Jehofa gbà, a gbọ́dọ̀ mọ ẹ̀kọ́ tí ó ṣe pàtàkì nípa Ìjọba Ọlọrun yìí kí a sì ṣiṣẹ́ lé e lórí. A gbọ́dọ̀ gbàgbọ́ pé Jesu wá láti ọ̀run, pé òun ni Ọba tí Ọlọrun ti yànsípò—Irú-Ọmọ aládé náà tí yóò ṣàbójútó ìmúpadàbọ̀sípò Paradise lórí ilẹ̀-ayé—àti pé òun yóò jí àwọn òkú dìde. (Luku 23:42, 43; Johannu 18:33-37) Ní Kapernaumu nígbà tí Jesu sọ̀rọ̀ nípa jíjí àwọn òkú dìde, ó ti níláti dá àwọn Júù lójú pé òtítọ́ ni ó sọ. Họ́wù, kìkì ọ̀sẹ̀ díẹ̀ ṣáájú, bóyá níbẹ̀ gan-an ní Kapernaumu, ó ti jí ọmọbìnrin onípò-àṣẹ alága sinagogu tí ó jẹ́ ẹni ọdún 12 dìde! (Luku 8:49-56) Dájúdájú àwa pẹ̀lú ní ìdí púpọ̀ láti gbàgbọ́ nínú ẹ̀kọ́ Jehofa tí ń ru ìrètí nípa Ìjọba rẹ̀ sókè kí a sì hùwà ní ìbámu pẹ̀lú rẹ̀!
14, 15. (a) Báwo ni Ìjọba Jehofa ti ṣe pàtàkì tó fún Jesu? (b) Kí ni ó yẹ kí a lóye kí a sì le ṣàlàyé nípa Ìjọba Jehofa?
14 Jesu fi ìgbésí-ayé rẹ̀ lórí ilẹ̀-ayé jìn fún ẹ̀kọ́ nípa Ìjọba Jehofa. Ó fi ṣe ẹṣin-ọ̀rọ̀ iṣẹ́-òjíṣẹ́ rẹ̀, ó tilẹ̀ sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti gbàdúrà fún un. (Matteu 6:9, 10; Luku 4:43) Àwọn Júù àbínibí ní ẹ̀tọ́ láti di “awọn ọmọ ìjọba,” ṣùgbọ́n nítorí àìnígbàgbọ́, ọ̀pọ̀ jùlọ lára wọn sọ àǹfààní náà nù. (Matteu 8:12; 21:43) Jesu ṣípayá pé kìkì “agbo kékeré” ni ó gba àǹfààní náà láti di “awọn ọmọ ìjọba.” “Awọn ọmọ” wọ̀nyí di “ajogún pẹlu Kristi” nínú Ìjọba rẹ̀ ní ọ̀run.—Luku 12:32; Matteu 13:38; Romu 8:14-17; Jakọbu 2:5.
15 Mélòó ni àwọn ajogún Ìjọba tí Kristi yóò mú lọ sí ọ̀run láti ṣàkóso orí ilẹ̀-ayé pẹ̀lú rẹ̀? Gẹ́gẹ́ bí Bibeli ti sọ, kìkì 144,000 ni. (Johannu 14:2, 3; 2 Timoteu 2:12; Ìṣípayá 5:10; 14:1-3; 20:4) Ṣùgbọ́n Jesu wí pé òun ní “awọn àgùtàn mìíràn,” tí yóò jẹ̀ ọmọ-abẹ́ ìṣàkóso Ìjọba náà lórí ilẹ̀-ayé. Àwọn wọ̀nyí yóò gbádùn ìlera pípé àti àlàáfíà títí láé lórí paradise ilẹ̀-ayé. (Johannu 10:16; Orin Dafidi 37:29; Ìṣípayá 21:3, 4) Ó yẹ kí a lóye ẹ̀kọ́ Jehofa nípa Ìjọba náà kí a sì lè ṣàlàyé rẹ̀.
16. Ẹ̀kọ́ Jehofa tí ó ṣe pàtàkì wo ni a níláti kọ́ kí a sì sọ dàṣà?
16 Aposteli Paulu fi ẹ̀kọ́ Jehofa mìíràn tí ó ṣe pàtàkì hàn. Ó wí pé: “Ọlọrun ti kọ́ ẹ̀yin fúnra yín lati nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nìkínní kejì.” (1 Tessalonika 4:9) Láti lè mú inú Jehofa dùn, a níláti fi irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ hàn. Bibeli sọ pé: “Ọlọrun jẹ́ ìfẹ́,” a sì gbọ́dọ̀ ṣàfarawé àpẹẹrẹ rẹ̀ ti fífi ìfẹ́ hàn. (1 Johannu 4:8; Efesu 5:1, 2) Ó bani lọ́kàn jẹ́ pé, àwọn ènìyàn tí ó pọ̀ jùlọ ti kùnà gidigidi láti kọ́ láti nífẹ̀ẹ́ ẹ̀dá ènìyàn ẹlẹgbẹ́ wọn gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti kọ́ wa pé kí a ṣe. Àwa ńkọ́? A ha ti dáhùnpadà sí ẹ̀kọ́ Jehofa yìí bí?
17. Ìṣarasíhùwà ta ni a níláti ṣàfarawé?
17 Ó ṣe pàtàkì pé kí a ṣetán láti gba gbogbo ẹ̀kọ́ Jehofa. Ǹjẹ́ kí ìṣarasíhùwà wa jẹ́ ti onipsalmu Bibeli náà tí ó kọ̀wé pé: “Fi ọ̀nà rẹ hàn mí, Oluwa; kọ́ mi ní ipa tìrẹ. Sìn mí ní ọ̀nà òtítọ́ rẹ, kí o sì kọ́ mi.” “Kọ́ mi ní ìlànà rẹ. . . . Kọ́ mi ní ìwà àti ìmọ rere . . . Kọ́ mi ní ìdájọ́ òdodo rẹ.” (Orin Dafidi 25:4, 5; 119:12, 66, 108) Bí èrò-ìmọ̀lára rẹ bá rí bákan náà pẹ̀lú ti onipsalmu náà, o lè wà lára ogunlọ́gọ̀ rẹpẹtẹ tí Jehofa ń kọ́.
Ogunlọ́gọ̀ Ńlá ti Àwọn Tí A Kọ́
18. Kí ni wòlíì Isaiah sọtẹ́lẹ̀ pé yóò ṣẹlẹ̀ ní àkókò wa?
18 Wòlíì Isaiah sọtẹ́lẹ̀ nípa ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ ní àkókò tiwa: “Yóò si ṣe ní ọjọ́ ìkẹyìn, a óò fi òkè ilé Oluwa kalẹ̀ lórí àwọn òkè ńlá, a óò sì gbé e ga ju àwọn òkè kéékèèké lọ . . . Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn yóò sì lọ wọn óò sì wí pé, Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a lọ sí òkè Oluwa, sí ilé Ọlọrun [Jekọbu]; Òun óò sì kọ́ wa ní ọ̀nà rẹ̀.” (Isaiah 2:2, 3, ìkọ̀wé wínníwínní jẹ́ tiwa; Mika 4:2) Àwọn wo ni àwọn wọ̀nyí tí Jehofa ń kọ́?
19. Àwọn wo lónìí ni wọ́n wà lára àwọn tí Jehofa ń kọ́?
19 Wọ́n ní àwọn mìíràn nínú yàtọ̀ sí àwọn wọnnì tí yóò ṣàkóso ní ọ̀run pẹ̀lú Kristi. Gẹ́gẹ́ bí a ti ṣàkíyèsí ní ìṣáájú, Jesu wí pé òun ní “awọn àgùtàn mìíràn”—àwọn ọmọ-abẹ Ìjọba rẹ̀ lórí ilẹ̀-ayé—ní àfikún sí “agbo kékeré” náà ti ajogún Ìjọba. (Johannu 10:16; Luku 12:32) “Ogunlọ́gọ̀ ńlá,” tí wọ́n bá la “ìpọ́njú ńlá” já, ní ẹgbẹ́ àgùtàn mìíràn náà, wọn yóò sì gbádùn ìdúró onítẹ̀ẹ́wọ́gbà níwájú Jehofa lórí ìpìlẹ̀ ìgbàgbọ́ wọn nínú ẹ̀jẹ̀ Jesu tí a ta sílẹ̀. (Ìṣípayá 7:9, 14) Àní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn àgùtàn mìíràn náà kò sí ní tààràtà lára “àwọn ọmọ” tí a sọ̀rọ̀ wọn nínú Isaiah 54:13, a bùkún wọn pẹ̀lú dídi ẹni tí Jehofa kọ́. Nítorí náà, lọ́nà tí ó tọ́ wọ́n pe Ọlọrun ní “Baba” nítorí pé, níti gidi, òun yóò di Bàbá Àgbà fún wọn nípasẹ̀ “Bàbá Ayérayé,” Jesu Kristi.—Matteu 6:9; Isaiah 9:6.
Bí Jehofa Ṣe Ń Kọ́ni
20. Ní àwọn ọ̀nà wo ni Jehofa gbà ń kọ́ni?
20 Ọ̀nà púpọ̀ ni Jehofa ń gbà kọ́ni. Fún àpẹẹrẹ, ó ń ṣe bẹ́ẹ̀ nípasẹ̀ àwọn iṣẹ́ rẹ̀, tí ń jẹ́rìí sí wíwà rẹ̀ àti ọgbọ́n rẹ̀ tí ó ga. (Jobu 12:7-9; Orin Dafidi 19:1, 2; Romu 1:20) Ní àfikún síi, ó ń kọ́ni nípa ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ ní tààràtà, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ní fífún Jesu ṣáájú kí ó tó di ènìyàn ní ìtọ́ni. Bákan náà, ní àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ mẹ́ta tí a kọsílẹ̀, ó sọ̀rọ̀ ní tààràtà láti ọ̀run sí àwọn ènìyàn lórí ilẹ̀-ayé.—Matteu 3:17; 17:5; Johannu 12:28.
21. Áńgẹ́lì wo ní pàtàkì ni Jehofa lò gẹ́gẹ́ bí aṣojú rẹ̀, ṣùgbọ́n báwo ni a ṣe mọ̀ pé a lò àwọn mìíràn pẹ̀lú?
21 Jehofa tún lo àwọn áńgẹ́lì aṣojú rẹ̀ láti kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́, títí kan Àkọ́bí rẹ̀, “Ọ̀rọ̀.” (Johannu 1:1-3) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Jehofa ìbá ti bá ọmọkùnrin rẹ̀ ẹ̀dá ènìyàn pípé, Adamu, sọ̀rọ̀ ní tààràtà nínú ọgbà-ọ̀gbìn Edeni, ó ṣeé ṣe kí ó ti lo Jesu ṣáájú kí ó tó di ènìyàn láti gbẹnusọ fún Un. (Genesisi 2:16, 17) Ẹni yìí ni ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ “áńgẹ́lì Ọlọrun náà tí ó ṣáájú ogun Israeli” àti ẹni tí Jehofa pàṣẹ nípa rẹ̀ pé: “Gba ohùn rẹ̀ gbọ́.” (Eksodu 14:19; 23:20, 21) Kò sí iyèméjì pé Jesu ṣáájú kí ó tó di ènìyàn ni “olórí ogun Oluwa” tí ó fi ara han Joṣua láti fún un lókun. (Joṣua 5:14, 15) Jehofa tún lo àwọn áńgẹ́lì mìíràn láti gbin ẹ̀kọ́ rẹ̀ síni lọ́kàn, irú àwọn wọnnì tí ó lò láti fún Mose ní Òfin rẹ̀.—Eksodu 20:1; Galatia 3:19; Heberu 2:2, 3.
22. (a) Àwọn wo lórí ilẹ̀-ayé ni Jehofa ti lo láti máa kọ́ni? (b) Ọ̀nà pàtàkì wo ni Jehofa fi ń fún àwọn ẹ̀dá ènìyàn rẹ̀ ní ìtọ́ni lónìí?
22 Ní àfikún síi, Jehofa Ọlọrun ń lo àwọn ẹ̀dá ènìyàn aṣojú rẹ̀ láti kọ́ni. Àwọn òbí ní Israeli níláti kọ́ àwọn ọmọ wọn; àwọn wòlíì, àlùfáà, ọmọ-aládé, àti ọmọ Lefi kọ́ orílẹ̀-èdè náà ní Òfin Jehofa. (Deuteronomi 11:18-21; 1 Samueli 12:20-25; 2 Kronika 17:7-9) Jesu ni olórí Agbọ̀rọ̀sọ Ọlọrun lórí ilẹ̀-ayé. (Heberu 1:1, 2) Jesu máa ń sọ nígbà gbogbo pé ohun tí òun ń fi kọ́ni ṣe rẹ́gí pẹ̀lú ohun tí òun ti kọ́ lọ́dọ̀ Bàbá, nítorí náà àwọn olùgbọ́ rẹ̀, níti gidi, ni a ń kọ́ láti ọ̀dọ̀ Jehofa. (Johannu 7:16; 8:28; 12:49; 14:9, 10) Jehofa ti mú kí a kọ àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ sílẹ̀, ní ọjọ́ wa ó sì ń kọ́ àwọn ẹ̀dá ènìyàn ní pàtàkì nípasẹ̀ àwọn Ìwé Mímọ́ wọ̀nyí tí a mí sí.—Romu 15:4; 2 Timoteu 3:16.
23. Àwọn ìbéèrè wo ni a óò gbé yẹ̀wò nínú ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ tí yóò tẹ̀lé e?
23 A ń gbé ní àwọn àkókò tí ó ṣe pàtàkì, níwọ̀n bí Ìwé Mímọ́ ti ṣèlérí pé ‘ní ọjọ́ ìkẹyìn [èyí tí a ń gbé nínú rẹ̀] ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni a óò fún ní ìtọ́ni nípa àwọn ọ̀nà Jehofa.’ (Isaiah 2:2, 3) Báwo ni a ṣe ń pèsè ìtọ́ni yìí? Kí ni a gbọ́dọ̀ ṣe láti lè jàǹfààní láti inú ètò ẹ̀kọ́ pípabambarì ti Jehofa tí ń lọ lọ́wọ́ nísinsìnyí, kí a sì nípìn-ín nínú rẹ̀? A óò gbé irú àwọn ìbéèrè bẹ́ẹ̀ yẹ̀wò nínú ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ tí ó tẹ̀lé e.
Báwo Ni Ìwọ Yóò Ṣe Dáhùn?
◻ Báwo ni Jehofa ṣe di Bàbá, Olùkọ́, àti Ọkọ?
◻ Kí ni ohun tí Jehofa fi kọ́ni nípa “irú-ọmọ” náà?
◻ Ẹ̀kọ́ wo tí ó ṣe pàtàkì láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun ni a gbọ́dọ̀ kíyèsí?
◻ Báwo ni Jehofa ṣe ń kọ́ni?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Jíjí ọmọbìnrin Jairu dìde pèsè ìpìlẹ̀ láti gbà ìlérí àjíǹde tí Jesu ṣe gbọ́