Àwọn Olùpòkìkí Ìjọba Ròyìn
Dídé Àwọn Àdádó Tí Ó Jìnnàréré ní Greenland
FÚN ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti lo ìwé ìròyìn Ilé-Ìṣọ́nà àti Jí! nínú wíwàásù ìhìnrere náà. Àwọn ìwé àtìgbàdégbà wọ̀nyí ń gbé ọgbọ́n Jehofa ga gẹ́gẹ́ bí a ti sọ ọ́ nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀, Bibeli. Wọ́n ń wo àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ayé tí ó níí ṣe pẹ̀lú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bibeli, wọ́n sì ń mú àwọn ìmọ̀ràn Bibeli tí ó bọ́gbọ́nmu bá àwọn ìṣòro òde-òní mu.—Jakọbu 3:17.
Ní 1994, àwọn Ẹlẹ́rìí ní Greenland ṣe àkànṣe ìsapá láti fi Ilé-Ìṣọ́nà àti Jí! lọ àwọn ènìyàn púpọ̀ bí ó ti ṣeé ṣe tó. Ní ìgbà ẹ̀rùn, wọ́n ṣètò láti ṣe ìbẹ̀wò sí àwọn àdádó tí ó jìnnàréré jùlọ ní Greenland. Àwùjọ àwọn olùpòkìkí Ìjọba kan lo ọkọ̀ ọ̀pẹẹrẹ láti rìrìn-àjò lọ sí èyí tí ó ju 4,000 kìlómítà sókè ìwọ̀-oòrùn èbúté Qaanaaq (Thule), wọ́n sì dé àwọn àdúgbò tí ó jìnnà jùlọ ní àríwá òbírí ilé-ayé. Ìrìn-àjò wọn gba ọ̀sẹ̀ méje. Ní ìlà-oòrùn èbúté náà, tọkọtaya Ẹlẹ́rìí kan dé àdádó kan ní Ittoqqortoormiit wọ́n sì kárí rẹ̀ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé fún ìgbà àkọ́kọ́ pẹ̀lú ìhìnrere.
Ṣáájú ní ọdún náà, ní oṣù April, 7,513 ẹ̀dà Ilé-Ìṣọ́nà àti Jí! ni a fi sóde sọ́dọ̀ àwọn ará Greenland. Ìyẹn túmọ̀ sí pé, ní ìpíndọ́gba, ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn 127 akéde Ìjọba fi ìwé ìròyìn 59 sóde—ìwé ìròyìn 1 fún ìpíndọ́gba olùgbé 7. Ní oṣù yẹn, Jí! gbé ọ̀wọ́ àwọn ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ jáde lábẹ́ àkórí ẹ̀yìn-ìwé náà “Àrùn Jẹjẹrẹ Ọmú—Ẹ̀rù Gbogbo Obìnrin.” Ẹlẹ́rìí kan, ẹni tí ó fi ìwé ìròyìn 140 sóde, fi àwọn ẹ̀dà Jí! náà sílẹ̀ fún akọ̀ròyìn orí tẹlifíṣọ̀n kan. Ọjọ́ díẹ̀ lẹ́yìn náà, ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìròyìn kan lórí tẹlifíṣọ̀n gbé àwọn ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ lórí àrùn jẹjẹrẹ jáde. Akọ̀ròyìn náà fi ìwé ìròyìn náà hàn lórí ẹ̀rọ ayàwòrán, ó fi àwọn ojú-ìwé mélòókan hàn bí ó ti ń gbóríyìn fún ìjójúlówó ìtumọ̀ èdè Greenland. Ó tún tẹnumọ́ àwọn àbá gbígbéṣẹ́ tí Jí! fúnni gẹ́gẹ́ bí ìdènà àbójútó ìlera.
Ẹlẹ́rìí náà tí ó fi àwọn ìwé ìròyìn náà sóde lákọ̀ọ́kọ́ sọ́dọ̀ akọ̀ròyìn náà ni a fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò lórí ìtòlẹ́sẹẹsẹ orí tẹlifíṣọ̀n kan náà. Ó dáhùn ọ̀pọ̀ àwọn ìbéèrè nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ó sì sọ̀rọ̀ nípa pípín tí a pín ìwé ìròyìn náà lọ́nà gbígbòòrò ní oṣù náà. Ó tún sọ̀rọ̀ nípa ọgbọ́n tí ó ṣeé múlò tí a rí nínú Bibeli ó sì fà á yọ pé irú ìmọ̀ràn tí ó bọ́gbọ́n mu bẹ́ẹ̀ lè ràn wá lọ́wọ́ láti kojú àwọn ìṣòro òde-òní.
Ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà parí pẹ̀lú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò ààrẹ Ẹgbẹ́ Tí Ń Rí Sí Àrùn Jẹjẹrẹ ní Greenland. Ó ṣàkíyèsí pé òun kò tí ì rí irú àkójọpọ̀-ọ̀rọ̀ àtàtà tí ó sì kún fún ìsọfúnni lórí ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ yìí rí ní èdè ti òun. Lẹ́yìn náà ó késí gbogbo àwọn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ọkàn sí kókó ọ̀rọ̀ jẹjẹrẹ ọmú láti ka àwọn ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ Jí! náà. Ó sọ pé ìdí tí ó dára wà láti dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa fún àtinúdá wọn.
Gẹ́gẹ́ bí ó ti rí ní Greenland, àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa káàkiri ayé ń tẹ̀síwájú láti wàásù ìhìnrere “ninu gbogbo ìṣẹ̀dá tí ń bẹ lábẹ́ ọ̀run.” (Kolosse 1:23; Ìṣe 1:8) Pẹ̀lú ìlò ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli, èyí tí ó ní nínú Ilé-Ìṣọ́nà àti Jí!, wọ́n ń ran gbogbo onírúurú ènìyàn lọ́wọ́ láti kojú àwọn ìṣòro òde-òní wọ́n sì ń fún wọn ní ìrètí fún ọjọ́-iwájú tí ó sàn jù.
[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 8]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
Qaanaaq (Thule)
Ittoqqortoormiit
Nuuk (Godthåb)