Àwọn Wo Ló Máa Fẹ́ Ka Àpilẹ̀kọ Yìí?
1. Tá a bá ń ka Ilé Ìṣọ́ tàbí Jí!, kí ló yẹ ká máa rò, kí sì nìdí?
1 Gbogbo èèyàn kárí ayé la ṣe Ilé Ìṣọ́ àti Jí! fún. Torí náà, àwọn àpilẹ̀kọ tó wà nínú wọn dá lórí oríṣiríṣi kókó ọ̀rọ̀. Tá a bá ń ka ẹ̀dà tiwa, ó yẹ ká máa ronú nípa àwọn tó tún lè nífẹ̀ẹ́ sí àwọn àpilẹ̀kọ tó wà níbẹ̀, ká sì gbìyànjú láti lọ fún wọn.
2. Irú àwọn àkòrí wo nínú àwọn ìwé ìròyìn wa ni àwọn kan lè nífẹ̀ẹ́ sí?
2 Bó o ṣe ń ka Ilé Ìṣọ́ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde, o lè rí àpilẹ̀kọ kan tó dá lórí ohun tí ìwọ àti ẹni tẹ́ ẹ jọ ń ṣiṣẹ́ ti jọ jíròrò. O tún lè rí àpilẹ̀kọ tó dá lórí ìdílé, tó sì máa wúlò fún ẹnì kan tó sún mọ́ ẹ? O lè rí àpilẹ̀kọ kan nínú Jí! nípa orílẹ̀-èdè tí ọ̀rẹ́ rẹ kan ń múra láti lọ. Àwọn oníṣòwò àtàwọn ọ́fíìsì ìjọba tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín sì lè nífẹ̀ẹ́ sí àwọn kan nínú àwọn ìwé ìròyìn wa. Bí àpẹẹrẹ, ìwé ìròyìn wa tó bá sọ̀rọ̀ nípa ìṣòro táwọn àgbàlagbà máa ń ní, lè wúlò fún àwọn arúgbó àtàwọn tó ń tọ́jú wọn. Bákan náà, àwọn agbófinró lè nífẹ̀ẹ́ sí ìwé wa tó bá sọ̀rọ̀ nípa ìwà ọ̀daràn.
3. Sọ ìrírí kan tó dá lórí ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa ronú nípa àwọn tó lè nífẹ̀ẹ́ sí àwọn àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé ìròyìn wa, ká sì máa mú un lọ fún wọn.
3 Àṣeyọrí: Nígbà tí tọkọtaya kan lórílẹ̀-èdè South Africa rí i pé ohun tó wà nínú Jí! October–December 2011 tó dá lórí “Bí Àwọn Òbí Ṣe Lè Tọ́ Àwọn Ọmọ Yanjú,” máa wúlò fún àwọn ilé ẹ̀kọ́ kan ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wọn, wọ́n tẹ ilé ẹ̀kọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25] láago. Méjìlélógún [22] lára àwọn ilé ẹ̀kọ́ yẹn ló gba àwọn ẹ̀dà ìwé ìròyìn náà, tí wọ́n sì pín in fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wọn. Tọkọtaya míì lórílẹ̀-èdè yẹn tún ṣe ohun kan náà. Àwọn olùkọ́ ní ọ̀kan lára àwọn ilé ẹ̀kọ́ tó gba àwọn ìwé ìròyìn náà pinnu pé àwọn yóò lo ìwé náà láti kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Nígbà tí tọkọtaya yìí sọ ìrírí náà fún alábòójútó àyíká kan, ó gba àwọn ará tó wà ní àyíká náà níyànjú pé kí àwọn náà kàn sí àwọn iléèwé tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wọn. Ẹ̀ka ọ́fíìsì ní láti tún ẹ̀dà ìwé ìròyìn yẹn tẹ̀ torí pé àwọn tó ń béèrè fún un ti wá pọ̀ sí i!
4. Kí nìdí tí a fi fẹ́ kí àwọn èèyàn púpọ̀ sí i máa ka àwọn ìwé ìròyìn wa?
4 Àwọn ìwé ìròyìn wa máa ń ṣàlàyé ohun táwọn ìṣẹ̀lẹ̀ lọ́ọ́lọ́ọ́ túmọ̀ sí gan-an, ó sì ń jẹ́ káwọn èèyàn túbọ̀ mọ̀ nípa Bíbélì àti Ìjọba Ọlọ́run. Ìwé ìròyìn wa nìkan ni ìwé ìròyìn tó ń “kéde ìgbàlà.” (Aísá. 52:7) Torí náà, á fẹ́ kí àwọn èèyàn púpọ̀ sí i máa kà á. Ọ̀kan lára ọ̀nà tá a lè gbà mú kí àwọn èèyàn púpọ̀ sí i máa ka àwọn ìwé ìròyìn wa ni pé ká máa bi ara wa pé: ‘Àwọn wo ló máa fẹ́ ka àpilẹ̀kọ yìí?’