ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w93 3/1 ojú ìwé 8-13
  • Ẹ Jẹ́ Ẹni ti a Yipada ni Ero-inu ti a Sì Làlóye ni Ọkan-aya

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ Jẹ́ Ẹni ti a Yipada ni Ero-inu ti a Sì Làlóye ni Ọkan-aya
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ‘Bi Awọn Orilẹ-ede Ti Ń Rìn’
  • Ero-inu Aláìlérè Ti Ó Sì Ṣókùnkùn
  • Awọn Ọkan-aya Aláìmọ̀kan ati Aláìmòye
  • “Kọja Gbogbo Agbára-òye Iwarere”
  • “Ẹ Maa Baa Lọ Ní Rírìn Gẹgẹ Bi Awọn Ọmọ Ìmọ́lẹ̀”
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Sá fún Òkùnkùn—Wá Sínú Ìmọ́lẹ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2024
  • Máa Rìn Ní Ọ̀nà Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ìmọ́lẹ̀ Ọlọ́run Ń lé Òkùnkùn Dà Nù!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
w93 3/1 ojú ìwé 8-13

Ẹ Jẹ́ Ẹni ti a Yipada ni Ero-inu ti a Sì Làlóye ni Ọkan-aya

“Nitori naa, eyi ni mo wí ti mo sì jẹrii si ninu Oluwa, pe ki ẹ maṣe maa baa lọ ni rínrìn gan-an gẹgẹ bi awọn orilẹ-ede pẹlu ti ń rìn.”—EFESU 4:17, NW.

1. Ki ni awọn ero-inu ati ọkan-aya wa ń ṣe fun wa?

ERO-INU ati ọkan-aya jẹ́ meji ninu awọn agbara-ọgbọn-ero ti o jẹ́ agbayanu julọ ti awọn eniyan ní. Bi o tilẹ jẹ pe ọ̀nà ìgbàṣiṣẹ́ wọn kò lóǹkà, awọn funraawọn wà fun kìkì awọn eniyan lẹnikọọkan. Animọ, ọrọ-sisọ, ìhùwà, awọn ero-imọlara, ati awọn ọpa-idiyele wa ni a nipa lori gbogbo wọn nipa ọ̀nà ti ero-inu ati ọkan-aya wa ń gbà ṣiṣẹ.

2, 3. (a) Bawo ni Bibeli ṣe lo èdè-ìsọ̀rọ̀ naa “ọkan-aya” ati “ero-inu”? (b) Eeṣe ti a fi nilati daniyan nipa ọkan-aya ati ero-inu?

2 Ninu Bibeli, “ọkan-aya” ni gbogbogboo tọka si isunniṣe, awọn ero-imọlara, ati awọn imọlara inú lọ́hùn-ún, ti “ero-inu” sì tọka si awọn ọgbọn ironumoye ati ironu. Sibẹ, wọn kìí ṣe alaibaradọgba. Fun apẹẹrẹ, Mose rọ awọn ọmọ Israeli pe: “Ẹyin . . . gbọdọ pè é pada si ọkan-aya yin [akiyesi ẹsẹ-iwe, “gbọdọ tún un pè pada si ero-inu yin”] pe Jehofa ni Ọlọrun otitọ.” (Deuteronomi 4:39, NW) Fun awọn akọwe ti wọn ń hùmọ̀ lodisi i, Jesu sọ pe: “Nitori ki ni ẹyin ṣe ń ro buburu ninu [“ọkan-aya,” NW] yin?”—Matteu 9:4; Marku 2:6, 7.

3 Eyi fihàn pe ero-inu ati ọkan-aya tanmọra pẹkipẹki. Wọn nipa lori araawọn, nigba miiran wọn ń tun araawọn fun lokun lati ṣiṣẹ gẹgẹ bi ẹgbẹ kan ti ó ṣọkan, sibẹ niye ìgbà wọn maa ń bá araawọn jà ninu ijakadi fun ijọbabori. (Matteu 22:37; fiwe Romu 7:23.) Fun idi yii, lati jere ojurere Jehofa, kìí ṣe kìkì pe a gbọdọ mọ ipo awọn ero-inu ati ọkan-aya wa daju nikan ni ṣugbọn a tun gbọdọ kọ́ wọn lẹkọọ lati ṣiṣẹ papọ ni iṣọkan, lati dari si ọ̀nà kan-naa. A gbọdọ jẹ́ ẹni ti a yipada ni ero-inu ti a sì làlóye ni ọkan-aya.—Orin Dafidi 119:34; Owe 3:1.

‘Bi Awọn Orilẹ-ede Ti Ń Rìn’

4. Bawo ni Satani ti ṣe nipa lori ero-inu ati ọkan-aya awọn eniyan, ki sì ni abajade rẹ̀?

4 Satani ni ọ̀gá ẹlẹ́tàn ati onímàdàrú. Ó mọ̀ pe lati lè dari awọn eniyan, oun gbọdọ foju sun awọn ero-inu ati ọkan-aya wọn. Taarata lati ibẹrẹ ìtàn eniyan, ó ti ń lo awọn ọgbọ́n-ìhùmọ̀ iru kan tabi omiran lati nipa lori ero-inu ati ọkan-aya awọn eniyan. Gẹgẹ bi iyọrisi iyẹn, “gbogbo ayé ni ó wà ni agbara ẹni buburu nì.” (1 Johannu 5:19) Nitootọ, Satani ti fi aṣeyọrisirere nipa lori ọkan-aya ati ero-inu awọn eniyan ayé debi pe Bibeli ṣapejuwe wọn gẹgẹ bi “iran wíwọ́ ati onímàgòmágó.” (Filippi 2:15, NW) Aposteli Paulu ṣapejuwe ipo ọkan-aya ati ero-inu iran wíwọ́ ati onímàgòmágó yẹn kínníkínní, awọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì ṣiṣẹ gẹgẹ bi ikilọ fun gbogbo wa lonii. Fun apẹẹrẹ, jọwọ ka Efesu 4:17-19, ki o sì fiwe awọn ọ̀rọ̀ Paulu ni Romu 1:21-24.

5. Eeṣe ti Paulu fi kọ imọran alagbara bẹẹ si awọn ará Efesu?

5 A lè mọriri idi ti Paulu fi kọ iru awọn ọ̀rọ̀ alagbara bẹẹ si awọn Kristian ni Efesu nigba ti a bá ranti pe ilu-nla naa ni ó lokiki buruku fun iwolulẹ iwarere ati ijọsin ère awọn abọriṣa rẹ̀. Bi o tilẹ jẹ pe awọn Griki ní awọn ronúronú ati ọmọran olokiki wọn, ó jọ pe imọ-ẹkọ Griki fun awọn eniyan ni agbara-iṣe ti o tubọ pọ sii fun iwa buburu, iṣẹdalẹ wọn sì wulẹ mú wọn jafafa sii ninu awọn iwa-ibajẹ wọn ni. Paulu daniyan gidigidi nipa awọn Kristian ẹlẹgbẹ rẹ̀ ti wọn ń gbé ninu iru ipo ayika kan bẹẹ. Ó mọ̀ pe ọpọlọpọ ninu wọn ti jẹ́ awọn eniyan orilẹ-ede tẹlẹri wọn sì ti “rìn rí gẹgẹ bi ipa ti ayé yii.” Ṣugbọn nisinsinyi wọn ti gba otitọ. Ero-inu wọn ni a ti yipada, ọkan-aya wọn ni a sì ti làlóye. Leke gbogbo ohun miiran, Paulu fẹ́ ki wọn maa “rin bi o ti yẹ fun ipe naa.”—Efesu 2:2; 4:1.

6. Eeṣe ti a fi nilati nifẹẹ-ọkan ninu awọn ọ̀rọ̀ Paulu?

6 Ipo naa baramu lonii. Awa pẹlu ń gbé ninu ayé kan ti ó ní awọn ọpa-idiyele wíwọ́, iwa aláìdára fun ohunkohun, ati awọn aṣa isin èké. Ọpọlọpọ ninu wa ti gbé ni ibamu pẹlu eto-igbekalẹ awọn nǹkan ti ayé yii nigbakan ri. Awọn miiran ninu wa nilati ṣe wọlé-wọ̀de pẹlu awọn eniyan ayé lojoojumọ. Awọn kan ń gbé ninu agbo-ile nibi ti ẹmi ayé ti ń mókè. Nitori naa, ó ṣe pataki pe ki a lóye itumọ awọn ọ̀rọ̀ Paulu ki a sì janfaani lati inu imọran rẹ̀.

Ero-inu Aláìlérè Ti Ó Sì Ṣókùnkùn

7. Ki ni Paulu nilọkan nipa gbolohun-ọrọ naa “àìlérè ero-inu wọn”?

7 Lati fi itilẹhin alagbara fun igbaniniyanju rẹ̀ pe ki awọn Kristian “maṣe maa baa lọ ni rírìn gan-an gẹgẹ bi awọn orilẹ-ede pẹlu ti ń rìn,” Paulu kọ́kọ́ mẹnukan “àìlérè ero-inu wọn.” (Efesu 4:17, NW) Ki ni iyẹn tumọsi? Ọ̀rọ̀ naa ti a tumọsi “àìlérè,” ni ibamu pẹlu The Anchor Bible, “dọgbọn tumọsi òfo, àìríkan-ṣè-kan, asán, iwa-omugọ, aláìníláárí, ati imujakulẹ.” Nipa bayii, Paulu ń ṣalaye pe okiki ati ògo awọn ayé Griki ati ti Romu ti lè jọ bi eyi ti ó wọni lọ́kàn ṣugbọn lilepa wọn jẹ́ òfo, omugọ, ati aláìníláárí niti tootọ. Awọn wọnni ti wọn gbé ọkàn wọn lé okiki ati ògo kì yoo pari rẹ̀ sí ohun miiran bikoṣe imujakulẹ ati ijanikulẹ. Ilana kan-naa ni ó jẹ́ otitọ nipa ayé lonii.

8. Ni awọn ọ̀nà wo ni awọn ìsapá ayé gbà jẹ́ aláìlérè?

8 Ayé ní awọn aronumoye ati ọ̀tọ̀kùlú rẹ̀ ti awọn eniyan ń wò fun idahun si iru awọn ibeere ńláǹlà bi orisun ati ète igbesi-aye ati kadara araye. Ṣugbọn oye-inu ati itọsọna wo ni wọn ní lati funni? Aigbọlọrungbọ, ìgbàgbọ́-Ọlọ́run-kò-ṣeémọ̀, efoluṣọn, ati ailonka awọn èròǹgbà ati àbá-èrò-orí ti ń dani lojuru ti wọn sì ń forigbari ti wọn kò lanilóye ju bi awọn ààtò isin ati igbagbọ awọn ohun asán ìgbà atijọ ti ṣe lọ. Ọpọ awọn ilepa ayé tun jọ pe wọn ń pese iwọn itẹlọrun ati imuṣẹ kan. Awọn eniyan ń sọrọ nipa aṣeyọrisirere ati ohun ti wọn ti rígbà ninu imọ-ijinlẹ, imọ iṣẹ́-ọnà, ere-idaraya, iṣelu, ati bẹẹ bẹẹ lọ. Wọn yọ̀ ninu awọn sáà akoko ògo wọn tí ó wà fun ìgbà diẹ. Sibẹ, akọsilẹ ìtàn ati awọn iwe akọsilẹ ti ode-oni kún fun awọn akọni ti a ti gbàgbé. Gbogbo eyi kò jẹ nǹkankan bikoṣe òfo, àìríkan-ṣè-kan, asán, iwa-omugọ, aláìníláárí, ati imujakulẹ.

9. Awọn ilepa aláìlérè wo ni ọpọlọpọ yiju si?

9 Ni mímọ àìlérè iru awọn ìsapá bẹẹ dunju, ọpọlọpọ yiju si ilepa ọrọ̀-àlùmọ́nì—ni kíkó owó jọ pelemọ ati níní awọn ohun ti owó lè rà—ti wọn sì fi iwọnyi ṣe ilepa wọn ninu igbesi-aye. Ó dá wọn loju pe ayọ ń wá lati inu ọrọ̀, ohun-ìní, ati wíwá fàájì. Kìí ṣe kìkì pe wọn gbé ero-inu wọn lé e nikan ni ṣugbọn wọn muratan lati fi ohun gbogbo rubọ—ilera, idile, àní ẹ̀rí-ọkàn paapaa. Ki ni iyọrisi rẹ̀? Dipo jijẹ ẹni ti ó nitẹẹlọrun, wọn ti “fi ibinujẹ pupọ gun ara wọn ni ọ̀kọ̀.” (1 Timoteu 6:10) Kò yanilẹnu pe Paulu rọ awọn Kristian ẹlẹgbẹ rẹ̀ lati dawọ duro ni rírìn gẹgẹ bi awọn orilẹ-ede ti ń ṣe nitori àìlérè ìlà ironu yẹn.

10. Bawo ni awọn eniyan ayé ṣe wà “ninu òkùnkùn niti ero-ori”?

10 Lati fihàn pe ayé kò ni ohunkohun ti ó yẹ ni eyi ti a ń ṣe ilara si tabi ṣafarawe, Paulu sọ tẹle e pe “ero-inu wọn wà ninu òkùnkùn.” (Efesu 4:18, NW) Dajudaju, ayé ní awọn eniyan ọlọgbọn-loye ati onímọ̀ ni ohun ti o fẹrẹẹ jẹ́ gbogbo pápá ìdáwọ́lé. Sibẹ, Paulu sọ pe ero-inu wọn wà ninu òkùnkùn. Eeṣe? Awọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ kìí ṣe nipa ìgbọ́nféfé tabi òye ti ero-ori wọn. Èdè-ìsọ̀rọ̀ naa “ero-inu” tun lè tọka si àárín gbùngbùn ìfòyemọ̀ eniyan, ibùjókòó òye, ọkunrin ti inú lọ́hùn-ún. Wọn wà ninu òkùnkùn nitori pe wọn kò ni ìmọ́lẹ̀ atọnisọna tabi agbara idari ninu awọn ìdáwọ́lé wọn. Eyi ni a lè rí ninu ọgbọ́n laakaye wọn fun mímọ ẹ̀tọ́ ati àìtọ́ ti o ti di eyi ti a mú pòrúùru. Awọn eniyan lè ronu pe ẹmi-ero-ori alaidanilẹjọ, gbogbo ohun ti ó bá ti wáyé naa ni ó dara ti ode-oni jẹ́ ọ̀làjú, ṣugbọn ó jẹ́ ẹmi-ero-ori ti a mú ṣókùnkùn niti gidi, gẹgẹ bi Paulu ti wi. Nipa tẹmi, wọn ń táràrà kiri ninu òkùnkùn biribiri.—Jobu 12:25; 17:12; Isaiah 5:20; 59:6-10; 60:2; fiwe Efesu 1:17, 18.

11. Ki ni okunfa òkùnkùn ti ero-ori ninu ayé?

11 Eeṣe ti ó fi jẹ́ pe awọn eniyan lè jẹ́ ọlọgbọn-loye, ti orí wọn tilẹ pé paapaa, ninu ọpọlọpọ awọn nǹkan ati sibẹ ki wọn wà ninu òkùnkùn tẹmi? Ni 2 Kọrinti 4:4, Paulu fun wa ni idahun naa pe: “Ọlọrun ayé yii ti sọ ọkàn awọn ti kò gbagbọ di afọju, ki ìmọ́lẹ̀ ihinrere Kristi ti o lógo, ẹni tii ṣe aworan Ọlọrun, ki o maṣe mọ́lẹ̀ ninu wọn.” Ibukun ṣiṣeyebiye wo ni ó jẹ́ pe awọn wọnni ti wọn gba ihinrere naa mọra ti di awọn ti a yipada ni ero-inu ti a sì làlóye ni ọkan-aya!

Awọn Ọkan-aya Aláìmọ̀kan ati Aláìmòye

12. Ni ọ̀nà wo ni ayé gbà jẹ́ “ajeji si ìyè ti ó jẹ́ ti Ọlọrun”?

12 Lati ràn wa lọwọ siwaju sii lati rí idi ti a fi gbọdọ di ẹni ti a yipada ni ero-inu ti a sì làlóye ni ọkan-aya, Paulu dari afiyesi wa si otitọ naa pe ọ̀nà ti ayé ni a sọ “dajeji si ìyè ti o jẹ́ ti Ọlọrun.” (Efesu 4:18, NW) Kìí ṣe pe awọn eniyan kò gbagbọ ninu Ọlọrun mọ́ tabi pe wọn ti di alailọlọrun mọ́ patapata. Onkọwe iwe-irohin kan sọ ọ́ ni ọ̀nà yii pe: “Dipo alailọlọrun, ẹ jẹ ki a hùmọ̀ ọ̀rọ̀ titun kan: ti-Ọlọ́run-níwọ̀n. Bi ti Ọlọrun ti níwọ̀n awọn eniyan ń fẹ́ iyin fun gbigbagbọ ninu Ọlọrun-ajọsinfun naa nigba ti wọn gbé E pamọ sinu apoti lakooko kan-naa, ni jíjẹ́ ki O jade ni owurọ Sunday nikanṣoṣo lalaijẹ ki O ni ipa lori oju-iwoye ayé ti oṣelu tabi igbesi-aye tiwọn funraawọn ni awọn ọjọ yooku. [Wọn] gbagbọ ninu Ọlọrun lọna kan ṣaa ṣugbọn wọn kò ronu pe Ó ni ohun pupọ lati sọ nipa ẹgbẹ́ awujọ ode-oni.” Paulu sọ ọ́ lọna yii ninu lẹta rẹ̀ si awọn ará Romu pe: “Nitori ìgbà ti wọn mọ Ọlọrun, wọn kò yìn ín lógo bi Ọlọrun, bẹẹ ni wọn kò sì dupẹ.” (Romu 1:21) Lojoojumọ a ń rí awọn eniyan ti wọn ń gbé igbesi-aye laisi ironu kankan bi o ti wu ki ó mọ nipa Ọlọrun. Dajudaju, wọn kò fi ọlá tabi ọpẹ́ fun un.

13. Ki ni “ìyè ti o jẹ́ ti Ọlọrun”?

13 Gbolohun ọ̀rọ̀ naa “ìyè ti ó jẹ́ ti Ọlọrun” jẹ́ ọ̀kan ti o ṣe pataki. Ó ṣapejuwe siwaju sii nipa ọ̀nà ti òkùnkùn ti ero-ori ati tẹmi gbà ń da òye ọpa-idiyele awọn eniyan rú. Ọ̀rọ̀ Griki naa ti a tumọsi “ìyè” nihin-in kìí ṣe biʹos (lati inu eyi ti a ti fa awọn ọ̀rọ̀ bii “biology” [ẹkọ nipa awọn ohun alààyè], “biography” [ìtàn-ìgbésí-ayé] yọ), eyi ti o tumọsi ọ̀nà igbesi-aye, tabi ọ̀nà ti a gbà ń gbé igbesi-aye. Kàkà bẹẹ zo·eʹ (lati inu eyi ti a ti fa awọn ọ̀rọ̀ bii “zoo” [ọgbà awọn ẹranko], “zoology” [ẹkọ nipa awọn ẹranko] yọ) ni. Ó tumọsi “ìyè gẹgẹ bi ilana kan, ìyè láìlábùlà, ìyè gẹgẹ bi Ọlọrun ti ní i. . . . Lati inu ìyè yii ni eniyan ti di ajeji gẹgẹ bi abajade Iṣubu naa,” gẹgẹ bi Vine’s Expository Dictionary of Old and New Testament Words ti wi. Nipa bayii, Paulu ń sọ fun wa pe kìí ṣe pe òkùnkùn ti ero-ori ati tẹmi ti sin awọn eniyan ayé sinu idibajẹ ninu ẹran-ara nikan ni ṣugbọn ó tun ti yà wọn sọtọ kuro ninu ireti ìyè ainipẹkun ti Ọlọrun nawọ rẹ̀ jade. (Galatia 6:8) Eeṣe ti o fi ri bẹẹ? Paulu ń baa lọ lati sọ awọn idi naa fun wa.

14. Ki ni idi kan ti ayé fi dajeji si ìyè ti o jẹ́ ti Ọlọrun?

14 Lakọọkọ ná, ó sọ pe ó jẹ́ “nitori àìmọ̀kan ti ń bẹ ninu wọn.” (Efesu 4:18, NW) Àpólà-ọ̀rọ̀ naa “ti ń bẹ ninu wọn” tẹnumọ ọn pe àìmọ̀kan naa kìí ṣe nitori àìláǹfààní ṣugbọn ó jẹ́ iyọrisi ìmọ̀ọ́mọ̀ kọ ìmọ̀ nipa Ọlọrun silẹ. Awọn itumọ àpólà-ọ̀rọ̀ yii miiran ni: “kíkọ̀ wọn lati mọ Ọlọrun ti ó ti di bárakú” (The Anchor Bible); “laisi ìmọ̀ nitori pe wọn ti sé ọkan-aya wọn pa sí i” (Jerusalem Bible). Nitori pe wọn kọ̀, tabi mọ̀ọ́mọ̀ fi tẹgantẹgan kọ, ìmọ̀ pipeye nipa Ọlọrun, wọn kò ni idi fun jijere iru ìyè ti Jehofa nawọ rẹ̀ jade fun awọn wọnni ti wọn bá lo igbagbọ ninu Ọmọkunrin rẹ̀, ẹni ti o wi pe: “Ìyè ainipẹkun naa sì ni eyi, ki wọn ki o lè mọ̀ ọ́, iwọ nikan Ọlọrun otitọ, ati Jesu Kristi, ẹni ti iwọ rán.”—Johannu 17:3; 1 Timoteu 6:19.

15. Ki ni ó dákún ìdàjèjì ayé yii sí ìyè ti ó jẹ́ ti Ọlọrun?

15 Idi miiran ti ayé ni gbogbogboo fi jẹ́ ajeji si ìyè ti ó jẹ́ ti Ọlọrun, gẹgẹ bi Paulu ti sọ, ni “àìmòye ọkan-aya wọn.” (Efesu 4:18, NW) “Àìmòye” nihin-in ni ipilẹ tumọsi mímúle, a fi bi ẹni pe èépá bò ó. Gbogbo wa ni a mọ bi èépá ṣe maa ń gbèrú. Awọ-ara lè kọ́kọ́ rọ̀ jọ̀bọ̀jọ̀bọ̀ ki ó sì maa tètè mọ irora, ṣugbọn bi a bá fi sabẹ ikimọlẹ tabi ìfaragbora kan, yoo le yoo sì nípọn, ní didi eléèépá. Kò tún jẹ́ mọ inira naa lára mọ́. Bakan naa, awọn eniyan ni a kò bí pẹlu ọkan-aya líle tabi eyi ti o ti di eléèépá debi pe wọn jẹ́ alainimọlara si Ọlọrun lairotẹlẹ. Ṣugbọn nitori pe a ń gbé ninu ayé ti a sì ṣí wa payá si ẹmi rẹ̀, kò gba akoko gigun fun ọkan-aya lati di eléèépá tabi líle bi a kò bá daabobo o. Idi niyẹn ti Paulu fi kilọ pe: “Ẹ ṣọra, . . . ki ẹnikankan ninu yin má baa di aláyà-líle nipa agbara ẹ̀tàn ẹṣẹ.” (Heberu 3:7-13, NW; Orin Dafidi 95:8-10) Ó ti jẹ́ kanjukanju tó, nigba naa, pe ki a maṣe ṣíwọ́ jíjẹ́ ẹni ti a yipada ni ero-inu ti a sì làlóye ni ọkan-aya!

“Kọja Gbogbo Agbára-òye Iwarere”

16. Ki ni iyọrisi òkùnkùn ti ero-ori ti ayé ati ìdàjèjì si ìyè ti o jẹ́ ti Ọlọrun?

16 Abajade iru òkùnkùn ati ìdàjèjì bẹẹ ni a kópọ̀ nipa awọn ọ̀rọ̀ Paulu siwaju sii pe: “Lẹhin ti wọn ti wá kọja gbogbo agbára-òye iwarere, wọn fi ara wọn fun iwa-ainijaanu lati ṣiṣẹ oniruuru iwa-aimọ gbogbo pẹlu iwa-iwọra.” (Efesu 4:19, NW) Gbolohun-ọrọ naa “lẹhin ti wọn ti wá kọja gbogbo agbára-òye iwarere” ni olówuuru tumọsi “lẹhin ti wọn ti dawọ duro lati nimọlara irora,” irora iwarere. Bí ọkan-aya ti ó ti di eléèépá ti rí gan-an niyẹn. Gbàrà ti ó bá ti dawọ duro lati ni imọlara irora ẹ̀rí-ọkàn ati agbára-òye ijihin niwaju Ọlọrun, kò tun sí ikalọwọko eyikeyii mọ. Nipa bayii, Paulu sọ pe “wọn fi ara wọn silẹ” fun iwa-ainijaanu ati iwa-aimọ. Ó jẹ́ igbesẹ atọkanwa, ti a mọ̀ọ́mọ̀ gbé. “Iwa-ainijaanu,” gẹgẹ bi a ti lò ó ninu Bibeli, duro fun iṣarasihuwa onímòójúkuku, alainitiju, ti yíyọṣùtì si ofin ati ọla-aṣẹ. Bakan naa, “oniruuru iwa-aimọ gbogbo” ní ninu kìí ṣe ayidayida ibalopọ takọtabo nikan ṣugbọn awọn ohun idibajẹ ti a ń ṣe ni orukọ isin, iru bi ààtò-ìsìn ọlọ́mọyọyọ ati awọn ààtò ti a ń ṣe ninu tẹmpili Atemisi ni Efesu, eyi ti awọn onkawe Paulu mọ̀ dunju daradara.—Iṣe 19:27, 35.

17. Eeṣe ti Paulu fi sọ pe awọn eniyan ti wọn kọja gbogbo agbára-òye iwarere ń dẹṣẹ “pẹlu iwa-iwọra”?

17 Bi ẹni pe fifi iwa-ainijaanu ati oniruuru iwa-aimọ gbogbo kẹra-ẹni bajẹ lainijaanu kò buru tó, Paulu fikun un pe iru awọn eniyan bẹẹ ń huwa “pẹlu iwa-iwọra.” Nigba ti awọn eniyan ti wọn ṣì ni iwọn agbára-òye iwarere bá dá ẹṣẹ, ó keretan wọn lè nimọlara ikarisọ ki wọn sì gbiyanju kárakára lati maṣe tún un ṣe. Ṣugbọn awọn wọnni ti wọn ti “wá kọja gbogbo agbára-òye iwarere” dẹṣẹ “pẹlu iwa-iwọra” (“wọn sì tubọ ń wá sii,” The Anchor Bible). Wọn ń ṣubúlébú titi di ìgbà ti wọn bá tó rì wọnu ibú idibajẹ gan-an—wọn kìí sìí ronu nipa rẹ̀. Ẹ wo bi eyi ti jẹ́ aworan pipeye nipa “ifẹ-inu awọn orilẹ-ede” tó!—1 Peteru 4:3, 4.

18. Lati ṣakopọ, iru aworan wo ni Paulu gbekalẹ nipa ipo ayé niti ero-ori ati tẹmi?

18 Ninu ẹsẹ-iwe mẹta pere, Efesu 4:17-19, Paulu tipa bayii sọ bi ipo iwarere ati ipo tẹmi ti ayé ti jẹ́ nitootọ di mímọ̀. Ó ṣalaye pe awọn èrò ati àbá-èrò-orí tí awọn ronúronú ayé yii ń ṣagbatẹru rẹ̀ ati ilepa aidabọ fun ọrọ̀ ati igbadun jẹ́ aláìlérè patapata. Ó mú un ṣe kedere pe nitori òkùnkùn ti ero-ori ati tẹmi, ayé wà ninu ẹrọ̀fọ̀ ti iwarere, ti o sì jẹ́ pe wọn ń rì wọnu rẹ̀ ṣáá ni. Lakootan, nitori àìmọ̀kan ati àìmòye tí wọn ti araawọn bọ̀, ayé ti di ajeji si ìyè tí ó jẹ́ ti Ọlọrun lọna ainireti. Dajudaju, a ní awọn idi rere lati maṣe maa baa lọ ni rírìn gan-an gẹgẹ bi awọn orilẹ-ede ti ń rìn pẹlu!

19. Ibeere ti o pọndandan wo ni a gbọdọ gbeyẹwo sibẹ?

19 Niwọn bi o ti jẹ́ pe òkùnkùn ni ero-inu ati ọkan-aya ni ó ń fa ki ayé di ajeji si Jehofa Ọlọrun, bawo ni a ṣe lè mú gbogbo òkùnkùn kuro ninu ero-inu ati ọkan-aya wa? Bẹẹni, ki ni a nilati ṣe ki a baa lè maa baa lọ ní rírìn gẹgẹ bi awọn ọmọ ìmọ́lẹ̀ ki a sì maa ní ojurere Ọlọrun niṣo? Eyi ni a o gbeyẹwo ninu ọrọ-ẹkọ ti o tẹle e.

Iwọ Ha Lè Ṣalaye Bi?

◻ Ki ni ó fa imọran alagbara ti Paulu fifunni ni Efesu 4:17-19?

◻ Eeṣe ti awọn ọ̀nà ayé fi jẹ́ aláìlérè ti ó sì wà ninu òkùnkùn?

◻ Ki ni a ni lọkan nipa gbolohun-ọrọ naa “dajeji si ìyè ti o jẹ́ ti Ọlọrun”?

◻ Ki ni awọn abajade ero-inu ti o ti sòkùnkùn ati ọkan-aya ti o ti di aláìmòye?

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Efesu ni o lokiki fun ibajẹ iwarere ati ijọsin oriṣa rẹ̀

1. Eléré-ìjà-ikú Romu ni Efesu

2. Àwókù tẹmpili Atemisi

3. Ile-iṣere ni Efesu

4. Atemisi Efesu, abo-ọlọrun ọlọ́mọyọyọ

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Òye-inu wo ni awọn ọ̀tọ̀kùlú ayé ní lati fifunni?

Nero

[Credit Line]

Musei Capitolini, Roma

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́