ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w93 3/1 ojú ìwé 26-29
  • Jehofa Pa Iwalaaye Ai Mọ́ Ninu Ọgbà-ẹ̀wọ̀n Aṣálẹ̀ Kan

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jehofa Pa Iwalaaye Ai Mọ́ Ninu Ọgbà-ẹ̀wọ̀n Aṣálẹ̀ Kan
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • A Fàṣẹ-ọba Mú Mi
  • Nigba Ti A Wà Ninu Ìtìmọ́lé
  • Ọgbà-ẹ̀wọ̀n Inú Aṣálẹ̀ Kan
  • Igbesi-aye Ninu Ọgbà-ẹ̀wọ̀n
  • Bibaa Lọ Ni Jijẹ Alagbara Nipa Tẹmi
  • Bíbá Awọn Ọ̀rẹ́ Wa Sọrọpọ
  • A Tú Wa Silẹ Nikẹhin!
  • Èmi Ògbóǹkangí Olóṣèlú Tẹ́lẹ̀ Di Kristẹni Tí Kò Dá Sí Ìṣèlú Mọ́
    Jí!—2002
  • Ohun Tí Ó Lé Ní 50 Ọdún ‘Ríré Kọjá Wá’
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Mo Gba Ọ̀pọ̀ Ìbùkún Ní “Àsìkò Tí Ó Rọgbọ àti Ní Àsìkò Tí Ó Kún Fún Ìdààmú”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Ìgárá Arúfin Ni Mí Tẹ́lẹ̀
    Jí!—1996
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
w93 3/1 ojú ìwé 26-29

Jehofa Pa Iwalaaye Ai Mọ́ Ninu Ọgbà-ẹ̀wọ̀n Aṣálẹ̀ Kan

GẸGẸ BI ISAIAH MNWE TI SỌ Ọ

Wọn kò bá mi ṣẹjọ́ tì, kìí sìí ṣe pe mo ti hu iwa-ọdan kankan. Sibẹ, a dájọ́ iṣẹ́ àṣekára fun mi ninu ibi ti a ti ń fiya jẹ awujọ awọn ọdaran ni àárín gbùngbùn Aṣálẹ̀ Sahara ti Africa ti o móoru rekọja ààlà. Ohun ti ó mú un buru jai ni pe, kò sí ọ̀kankan ninu awọn ọ̀rẹ́ mi ti ó mọ ibi ti mo wà. Eyi ṣẹlẹ ni nǹkan ti ó ju ọdun mẹjọ lọ sẹhin, ni ìgbà ẹ̀rùn 1984. Ẹ jẹ ki n ṣalaye bi mo ṣe wá wà ninu ipo lilekoko yẹn.

NI 1958, nigba ti mo wulẹ jẹ ọmọ ọdun 12, ẹ̀gbọ́n mi ọkunrin di ọ̀kan lara awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Bi o ti wu ki o ri, baba ati ìyá mi ń baa lọ lati maa sin awọn ọlọrun ẹ̀yà-ìran ti Ipinlẹ Abia, ni Nigeria, nibi ti a ń gbé.

Ni 1968, mo darapọ mọ ẹgbẹ-ọmọ-ogun Biafra. Nigba ti a wà loju ogun, mo ronu nipa ipo aidasi tọtun-tosi awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, mo sì gbadura si Ọlọrun lati ràn mi lọwọ. Mo ṣeleri pe bi ó bá lè yọnda fun mi lati la ogun naa já, emi yoo di ọ̀kan lara awọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀.

Lẹhin ogun mo tètè gbégbèésẹ̀ lati mú ileri mi ṣẹ. A baptisi mi ni July 1970 mo sì bẹrẹ iṣẹ-ojiṣẹ alakooko kikun gẹgẹ bi aṣaaju-ọna lọ́gán. Bi akoko ti ń lọ a yàn mi gẹgẹ bi alagba kan ninu ijọ Kristian. Laipẹ mo rí ikesini gbà lati ẹka ọfiisi Nigeria lati bẹrẹ iṣẹ-àyànfúnni ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni orilẹ-ede ti ó wà nitosi nibi ti a kò tíì dá awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa mọ̀ labẹ ofin. Mo tẹwọgba a, nigba ti ó sì maa fi di January 1975, pẹlu ìwé-ìrìnnà lọwọ, mo ti mú ọ̀nà mi pọ̀n.

A Fàṣẹ-ọba Mú Mi

Ni 1978, a yàn mi lati bẹ awọn Ẹlẹ́rìí jakejado orilẹ-ede naa wò. Niwọn bi o ti jẹ́ pe wọn kere niye, mo rinrin-ajo la agbegbe gbigbooro já, ní bibẹ gbogbo awọn ilu-nla nibi ti awọn ijọ wà, ati awọn agbegbe nibi ti awọn olufifẹhan wà wò. Niye ìgbà a ń fọrọ wa mi lẹnu wo ni awọn ibi ti awọn ọlọpaa ti ń ṣọ́ oju-ọna. Lẹẹmeji, fun ọjọ mẹrin nigba kọọkan, a dá mi duro ti a sì fi ibeere wadii ọ̀rọ̀ lẹnu mi nipa iṣẹ wa.

Lẹhin naa, ni June 1984, bi a ti ń murasilẹ fun iṣẹ-ojiṣẹ pápá ni ọjọ Sunday kan, oṣiṣẹ-oloye ẹni bí ọ̀rẹ́ kan fi tó wa létí pe awọn ọlọpaa ń wá ọ̀nà lati fàṣẹ-ọba mú awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Ni ọsẹ kan lẹhin naa Djagli Koffivi, ti ó wá lati Togo, ati emi ni a fàṣẹ-ọba mú. A mú wa lọ sí orile-iṣẹ awọn ọlọpaa a sì paṣẹ fun wa lati fi orukọ gbogbo awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti wọn wà ninu ilu-nla yẹn lélẹ̀. “Àyàfi bi ẹ bá fun wa ni awọn orukọ naa,” ni wọn sọ, “awa kò ni tú yin silẹ.”

“Ẹyin ni ọlọpaa,” ni mo dahun. “Iṣẹ́ yin ni lati wá awọn eniyan ti ẹ ń fẹ́. Emi kìí ṣe aṣoju yin.” A wíjọ́ fun nǹkan bii 30 iṣẹju, awọn ọlọpaa naa sì fi lílù halẹ̀ mọ́ wa. Sibẹ, awa kò fun wọn ni orukọ awọn Kristian arakunrin wa. Wọn pinnu lẹhin naa lati faṣẹ kó awọn iwe atọka Bibeli inu pẹpẹ ìkówèésí mi titobi.

Nigba Ti A Wà Ninu Ìtìmọ́lé

Lẹhin pipada si àgọ́ ọlọpaa pẹlu awọn iwe naa, Djagli ati emi já wọn silẹ. Bi a ti ń ṣe bẹẹ, bébà kan yọbọ́ lati inu Bibeli mi onilẹta gadagbagadagba. Itolẹsẹẹsẹ apejọ agbegbe ti a tẹ orukọ gbogbo awọn Kristian alagba ni orilẹ-ede naa sí ni. Lọ́gán ni mo hé nílẹ̀ ti mo sì tẹ̀ ẹ́ bọ inu àpò mi. Bi o ti wu ki o ri, ọ̀kan lara awọn ọlọpaa naa rí mi ó sì paṣẹ fun mi lati fi lé oun lọwọ. Dajudaju, idaamu bá mi.

Bébà naa ni a fi sori tabili ninu iyàrá ibi ti Djagli ati emi ń kó awọn iwe naa wá sí. Nigba ti mo wọle pẹlu ẹrù iwe mi ti o tẹle e, mo lọ sori tabili naa, mú bébà naa, mo sì rún un mọ́ inu àpò mi. Lẹhin naa mo sọ pe mo fẹ́ lọ ṣe gá. Ọlọpaa kan sin mi lọ si agbegbe ilé ìgbọ̀nsẹ̀. Lẹhin ti mo ti wọle ti mo sì ti ilẹkun, mo fa bébà naa ya sí wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́ mo sì fi omi ṣàn án lọ sinu kòtò ile ìyàgbẹ́ naa.

Nigba ti awọn ọlọpaa naa mọ ohun ti ó ṣẹlẹ, ori wọn gbóná. Ṣugbọn ẹ̀rù bà wọn lati ṣe ohunkohun nipa rẹ̀, niwọn bi awọn ọ̀gá wọn patapata yoo ti fẹ̀sùn aimọṣẹniṣẹ kàn wọn fun fífààyè gbà mi lati ní anfaani lati fa bébà naa ya. Lẹhin ti wọn fi wá sinu ìtìmọ́lé fun ọjọ 17, ọ̀gá ọlọpaa patapata kan sọ fun wa lati di ẹrù wa nitori pe wọn yoo kó wa lọ si ibomiran. A kó awọn aṣọ diẹ sinu àpò ọlọ́ràá kan, ni isalẹ rẹ̀ ni mo sì fi Bibeli kekere kan ti olubẹwo kan ti dọgbọn mú wa fun wa si.

Ó ṣeeṣe fun wa lati fi tó awọn Ẹlẹ́rìí létí pe wọn ń kó wa lọ ṣugbọn pe a kò mọ ibẹ̀. Ní kutukutu ọjọ keji, July 4, 1984, ọ̀gá ọlọpaa patapata naa jí wa. Ó yẹ ara wa wò fínnífínní, ni sisọ fun wa pe ki a kó awọn aṣọ wa jade lati inu àpò naa ki a sì fi wọn kọ́ apa wa. Ṣugbọn nigba ti o ku ki ń mu ẹ̀wù ṣẹ́ẹ̀tì ti ó wà nisalẹ patapata, ó sọ pe mo lè kó awọn ẹ̀wù naa pada sinu àpò, nipa bẹẹ Bibeli naa ni a kò rí.

Ọgbà-ẹ̀wọ̀n Inú Aṣálẹ̀ Kan

Ọlọpaa naa wà wá lọ si pápá ọkọ̀ ofuurufu, nibi ti a ti wọ ọkọ̀ ofuurufu ologun kan. Ni ọpọlọpọ wakati lẹhin naa a dé ilu kan ti ó ni nǹkan bii 2,000 eniyan, nibi ti ọgbà-ẹ̀wọ̀n kan ti wà nitosi. Nǹkan bii 650 kilomita ni si ilu ti ó sunmọ julọ ti a bá tọ oju-ọna ilẹ. A kó wa jade kuro ninu ọkọ̀ ofuurufu lọ sinu ọgbà-ẹ̀wọ̀n naa a sì fi wá lé oluṣabojuto ọgbà-ẹ̀wọ̀n naa lọwọ. Kò sí ọ̀kankan ninu awọn idile tabi ọ̀rẹ́ wa ti ó mọ ibi ti wọn kó wa lọ.

Ilu ti a kó wa lọ jẹ́ ibi adágún-omi ninu Sahara. Awọn igi keekeeke, iwọnba igi diẹ, ati awọn ile ti a fi amọ̀ kọ́ wà nibẹ. A lè rí omi nipa wiwulẹ gbẹ́ nǹkan bi mita kan si mita kan ati ààbọ̀ jìn sísàlẹ̀. Sibẹ, ọmọ ibilẹ adugbo naa ẹni ọdun 31 sọ fun wa pe ẹ̀ẹ̀kanṣoṣo péré ni ojo tíì rọ̀ loju oun rí jalẹ akoko igbesi-aye oun! Agbegbe naa sì gbóná bi ajere. Ẹlẹwọn kan sọ pe ọ̀pá ìwọ̀n ìgbóná-ìtutù ti ó wà ninu ile awọn ẹlẹwọn naa fi akọsilẹ 140 hàn lori ìwọ̀n Fahrenheit! Atẹgun lilagbara kan maa ń fẹ́ laidawọduro, ni gbígbá yanrìn tí ń tanilára ti o sì ń kowọnu oju.

Ẹnikẹni ti ó bá dé ibẹ̀ yẹn yoo mọ̀ pe oun wà ni ibùdó ifiyajẹni ti ó ga julọ ti orilẹ-ede naa. Ọgbà-ẹ̀wọ̀n naa ni a fi ògiri giga ti o pese iwọn ààbò diẹ kuro lọwọ atẹ́gùn ati oorun yika. Bi o ti wu ki o ri, awọn ògiri ni a kò nilo lati ṣediwọ fun sisalọ, niwọn bi kò ti sí ibikankan lati lọ. Lẹhin ode ibi omi inu aṣálẹ̀ naa, kò sí igi kanṣoṣo, kò sí ohunkohun rárá, lati fun ẹnikẹni ti o bá fẹ́ lati salọ ni ibòji.

Ṣaaju ki a tó wọle, oluṣabojuto ọgbà-ẹ̀wọ̀n naa yẹ ara wa wò fínnífínní. Ó sọ fun wa lati kó gbogbo nǹkan ti ó wà ninu àpò wa jade. Mo bẹrẹ sii yọ awọn ẹ̀wù ṣéẹ̀tì wa jade lọkọọkan. Nigba ti ó ku kìkì ṣẹ́ẹ̀tì ti ó bo Bibeli naa, mo na àpò naa sí i lati fi ṣẹ́ẹ̀tì ti o wà ninu rẹ̀ hàn án mo sì sọ pe: “Gbogbo ohun ti wọn yọnda wa lati mú niyii.” Bi o ti tẹ́ ẹ lọ́rùn, ó sọ pe ki a wọnu ọgbà-ẹ̀wọ̀n lọ. Bibeli naa ni itẹjade kanṣoṣo ti a ní.

Igbesi-aye Ninu Ọgbà-ẹ̀wọ̀n

Lapapọ, nǹkan bi awọn ẹlẹwọn 34 ni o wà. Wọn jẹ́ awọn ọdaran ti wọn lokiki buruku ti wọn sì jẹ́ eléwu julọ ni orilẹ-ede naa. Ọpọ ninu wọn jẹ́ apaniyan ti a ti kà sí awọn ti o ti rekọja atunṣe. Gbogbo wa sùn ninu awọn yàrá-àhámọ́ ńlá meji ti ilé-ìwẹ̀ gbayawu kan là laaarin. Ilé-ìwẹ̀ naa ní àgbá kan ti kò ní ìdérí ti a ń lò gẹgẹ bi ilé-ìgbọ̀nsẹ̀. Bi o tilẹ jẹ́ pe eyi ni awọn ẹlẹwọn ń dànù laraarọ, ń ṣe ni ó dabi ẹni pe gbogbo eṣinṣin inu aṣálẹ̀ naa ń wá lati gbadun òjìji ati òórùn àgbá yẹn.

Kìkì ounjẹ ti wọn ń fun wa ni ọkà-bàbà. Ẹlẹwọn kan ni yoo gún un, sè é, ti yoo sì wọ̀n ọ́n sinu abọ́, eyi ti yoo gbé jade lẹhin naa, ọ̀kan lori ẹní ti ẹlẹwọn kọọkan fi ń sùn. Ounjẹ naa ni a kìí bò. Nigba ti a bá fi maa ti ibi iṣẹ́ dé, ọgọrọọrun eṣinṣin á ti bo ori àwo ounjẹ ọkà-bàbà kọọkan ṣíbá. Nigba ti a bá gbé abọ́ ounjẹ wa nilẹ, awọn eṣinṣin naa yoo ṣe wọnyin. Fun ọjọ meji akọkọ, a kò jẹ ohunkohun. Asẹhinwa-asẹhinbọ, ni ọjọ kẹta, lẹhin lílé awọn eṣinṣin kuro ti a sì bó èépá ti ó wà loke dànù tán, a bẹrẹ sii jẹ ounjẹ ọkà-bàbà naa. A gbadura pe ki Jehofa daabobo ilera wa.

A ṣiṣẹ labẹ oòrùn, ní fífọ́ ogiri agbala ọgbà-ẹ̀wọ̀n naa ti a sì ń kọ́ titun. Ó jẹ́ iṣẹ aṣekara gidigidi. A ń ṣiṣẹ laisi isinmi lati agogo 6:00 owurọ titi di ọjọ́ kanrí, a o fi nǹkan panu, lẹhin naa a o ṣiṣẹ titi di agogo 6:00 irọlẹ. Kò sí ọjọ kan ti a kìí ṣiṣẹ. Kìí ṣe kìkì pe a ń jiya lọwọ oorun naa nikan ni ṣugbọn nigba ìwọ́wé òtútù ń pa wá. A sì tún ń jiya lọwọ awọn ẹ̀ṣọ́ ti wọn jẹ́ òǹrorò.

Bibaa Lọ Ni Jijẹ Alagbara Nipa Tẹmi

Djagli ati emi ń ka Bibeli ni idakọnkọ, a sì ń bá ara wa sọrọ nipa ohun ti a kọ́. A kò lè kawe ni gbangba nitori pe wọn ìbá ti gba Bibeli naa kuro wọn ìbá sì ti fiya jẹ wá. Ẹlẹwọn kan ti mo bẹrẹ ikẹkọọ Bibeli pẹlu rẹ̀ ní àtùpà oníkẹrosín-ìn-nì kan ti ó ń jẹ́ ki a jìjọ lò. Niye ìgbà mo ń jí ni agogo kan tabi meji òru ti mo sì ń kàwé titi di nǹkan bi agogo marun-un. Ni ọ̀nà yẹn ó ṣeeṣe fun mi lati ka odindi Bibeli lati ibẹrẹ dopin.

A waasu fun awọn ẹlẹwọn miiran, ọ̀kan ninu wọn sì sọ nipa wa fun olori ẹ̀ṣọ́ awọn ẹlẹwọn. Lairotẹlẹ, ẹ̀ṣọ́ naa fun ẹlẹwọn naa ni iwe-irohin Ji! kan ti ó ní, ẹlẹwọn naa sì fi ṣọwọ́ si wa. Mo kà á laimọye ìgbà leralera. Iwe kíkà ati iwaasu wa ràn wá lọwọ lati maa baa lọ ni jijẹ alagbara nipa tẹmi.

Bíbá Awọn Ọ̀rẹ́ Wa Sọrọpọ

A kò yọnda fun wa lati kọ tabi fi lẹta ranṣẹ. Bi o ti wu ki o ri, ẹnikan ti ó ti jẹ́ ọ́rẹ́ sọ pe oun yoo ràn mi lọwọ. Ni August 20, nǹkan bi ọsẹ mẹfa lẹhin ìgbà ti a dé, mo yọ́ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ kọ lẹta meji, ọ̀kan si ọfiisi aṣoju ijọba Nigeria ati omiran si awọn ọ̀rẹ́ ti wọn jẹ́ Ẹlẹ́rìí. Mo bò wọn mọnu yanrìn mo sì fi okuta ńlá kan sami si ibẹ̀. Lẹhin naa ọ̀rẹ́ mi wá ó sì hú wọn jade.

Ọpọlọpọ ọsẹ kọja, emi kò sì gbọ́ ohunkohun. Ni kẹrẹkẹrẹ mo sọ ireti pe lẹta naa ni a ti fi jiṣẹ nù. Ṣugbọn ó kọja sọwọ wọn, awọn Ẹlẹ́rìí ẹlẹgbẹ wa sì tẹwọgba ìjà lati wá ìtúsílẹ̀ fun wa. Ile-iṣẹ Ijọba Nigeria Ti Ń Bojuto Awọn Ọ̀ràn Ilẹ Okeere tun ni ọkàn-ìfẹ́ ninu ọ̀ràn naa o sì beere lọwọ ijọba orilẹ-ede ti a ti fi mi sẹwọn idi ti o fi fi mi sẹwọn ninu iru ọgbà-ẹ̀wọ̀n kan bẹẹ.

Laaarin afo akoko yii ná, ni owurọ November 15, 1984, a kó wa lọ ṣe iṣẹ ìkópàǹtírí diẹ. Awọn ẹ̀ṣọ́ sìn mi lọ si ilé-ìgbọ̀nsẹ̀ ile-ẹkọ sẹkọndri kan ti awọn eniyan ti ń lò fun ọpọlọpọ ọsẹ laika dídí ti ó ti dí sí. Ó kún fun ìgbẹ́. Iṣẹ mi ni lati fọ̀ ọ́ mọ́, ni ẹ̀ṣọ́ naa wí. Irin-iṣẹ kanṣoṣo ti mo ní ni awọn ọwọ́ mi. Bi mo ti ń ronu nipa bi a tií yanju iṣẹ́ akóninírìíra patapata yii, olori ẹ̀ṣọ́ awọn ẹlẹwọn wá ó si sọ pe ijoye-oṣiṣẹ agbegbe ayika naa yoo fẹ́ lati rí mi.

Nigba ti mo dé ọ̀dọ̀ rẹ̀ ijoye-oṣiṣẹ agbegbe naa sọ pe oun ṣẹṣẹ bá ààrẹ orilẹ-ede naa, ẹni ti o ti gbọ́ nipa ọ̀ràn-ìṣòro mi sọrọ tán laipẹ yii ni. Ààrẹ ṣalaye pe bi emi yoo bá sọ orukọ awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni orilẹ-ede naa, a o tú mi silẹ loju-ẹsẹ emi sì lè bá ọkọ̀ ofuurufu ti yoo tẹle e rìn. Lẹẹkan sii mo sọ pe bi wọn bá ń wá awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, iṣẹ́ awọn ọlọpaa ni lati rí wọn. Ijoye-oṣiṣẹ agbegbe naa sọ fun mi pe ki ń tun ifilọni naa gbeyẹwo pẹlu ironu jinlẹ. Oun yoo fun mi ni ọjọ mẹrin tabi marun-un lati ronu siwa-sẹhin nipa rẹ̀. Nigba naa ni wọn jẹ́ ki n lọ kuro, mo kun fun ọpẹ pe, ẹ̀ṣọ́ naa sìn mi pada sinu ọgbà-ẹ̀wọ̀n, kìí sìí ṣe ilé-ìgbọ̀nsẹ̀ naa!

Lẹhin ọjọ marun-un ijoye-oṣiṣẹ agbegbe naa késí mi ó sì beere ohun ti mo ti pinnu lati ṣe. Mo sọ pe idi kanṣoṣo ti mo fi wà ninu ọgbà-ẹ̀wọ̀n wọn jẹ́ nitori pe mo jẹrii si Ọlọrun tootọ naa ati pe emi kò ṣe ohun aitọ kankan. Mo ṣalaye pe mo ni ìwé-ìrìnnà ti ó bá ofin mu ati ìwé-àṣẹ lati gbé nílùú. Gbogbo ìwé mi ni ó pé, igbakugba ti mo bá sì rinrin-ajo lọ si ilu-nla eyikeyii, mo maa ń lọ sọdọ awọn ọlọpaa ki wọn lè rí i daju pe gbogbo nǹkan wà letoleto. Niwọn bi emi kò ti hu iwa-ọdaran kankan, mo beere pe: “Eeṣe ti a fi ń fiya jẹ mi? Bi a kò bá fẹ́ mi ninu orilẹ-ede naa, eeṣe ti a kò fi lé mi pada? Eeṣe ti a fi pa mi tì sí ibi yii?”

Mo sọrọ fun nǹkan bi iṣẹju 15. Nigba ti mo ṣetan, a sọ fun mi lati kọ ohun ti mo ṣẹṣẹ sọ tán naa silẹ, a sì sọ fun mi pe awọn alaye mi ni a o fi siwaju ààrẹ. A fun mi ni bébà, mo sì kọ oju-iwe mẹrin.

A Tú Wa Silẹ Nikẹhin!

Emi kò gbọ́ ohunkohun mọ́ nipa ọ̀ràn naa titi di January 1985, nǹkan bi oṣu meje lẹhin ti a fi mi sẹwọn. Ni akoko yẹn, olori ẹ̀ṣọ́ awọn ẹlẹwọn wá ó sì beere lọwọ mi bi mo bá ti kọ lẹta kan si ọfiisi aṣoju ijọba Nigeria. “Bẹẹni,” ni mo fesipada.

“Eeṣe ti o fi ṣe e? Eeṣe ti o kò fi jẹ́ ki n mọ̀?” ni ó beere.

Mo sọ fun un pe ọ̀ràn naa kò kàn án. Ṣugbọn mo fi yé e pe emi kò kọ ohunkohun lodi sí i, niwọn bi oun kò ti ní ohunkohun ṣe pẹlu rírán ti a rán mi si ọgbà-ẹ̀wọ̀n. “Ìyá mi paapaa kò mọ ibi ti mo wà,” ni mo sọ. Oun lẹhin naa ń fẹ́ lati mọ bi mo ṣe fi lẹta naa ranṣẹ, ṣugbọn mo kọ̀ lati sọ fun un.

Ni ọjọ keji awọn ẹ̀ṣọ́ naa tún ọkọ LandRover kan ṣe wọn sì sọ fun mi pe Djagli ati emi ni a ń ṣí nipo pada. A mú wa jade, wọn tú ara wa, wọn sì yẹ̀ wá wò kínníkínní. Ṣaaju mo ti fun ẹlẹwọn kan ti mo ń bá ṣe ikẹkọọ ni Bibeli mi nitori ti mo mọ̀ pe awọn ẹ̀ṣọ́ naa yoo gbẹsẹle e bi wọn bá rí i lara mi. Ọkunrin yii sọ fun wa pe nigba ti a bá tú oun silẹ, oun yoo di ọ̀kan lara awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. A reti pe ki o ṣe bẹẹ.

Ni kété lẹhin ìgbà naa, a lé mi pada si Nigeria, ati ni February 1985, mo bẹrẹ iṣẹ-ojiṣẹ mi gẹgẹ bi alaboojuto arinrin-ajo kan ni orilẹ-ede yẹn. Lati 1990, mo ti ń ṣiṣẹsin gẹgẹ bi alaboojuto agbegbe ni Nigeria. Djagli ń ṣiṣẹsin gẹgẹ bi Ẹlẹ́rìí oluṣotitọ nisinsinyi ni Côte d’Ivoire.

Lati inu iriri yii, mo funraami mọ pe Jehofa Ọlọrun lè tì wá lẹhin labẹ ikimọlẹ ti o lekoko julọ paapaa. Leralera a rí ọwọ alaabo rẹ̀ lara wa ninu ọgbà-ẹ̀wọ̀n naa. Ìtúsílẹ̀ wa tẹ̀ ẹ́ mọ mi lọ́kàn pe kìí ṣe pe Jehofa mọ ibi ti awọn iranṣẹ rẹ̀ wà ati ohun ti wọn ń jiya rẹ̀ nikan ni ṣugbọn ó tún mọ ọ̀nà lati dá wọn nide kuro ninu adanwo.—2 Peteru 2:9.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́