Ounjẹ Yii Ha Lè Ní Itumọ fun Ọ Bi?
OṢUPA àrànmọ́jú kan wẹ ilẹ mọ́ rokoṣo ni alẹ́ píparọ́rọ́ kan. Ninu iyàrá oke ilé kan ní Jerusalemu àtọjọ́mọ́jọ́, awọn ọkunrin 12 pagbo yí tabili kan ká. Awọn 11 fi iyè silẹ gidigidi bi Olukọ wọn ti ń ṣefilọlẹ ayẹyẹ onijẹẹpataki ńláǹlà kan ti o sì ń sọ awọn ọ̀rọ̀ onitumọ pataki. Akọsilẹ kan sọ pe:
“Jesu [Kristi] mú akara, ó sì súre, ó sì bù ú, ó sì fifun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, ó wi pe, Gbà, jẹ; eyiyii [tumọsi, NW] ara mi. Ó sì mú ago, ó dupẹ, ó sì fifun wọn, ó wi pe, Gbogbo yin ẹ mu ninu rẹ̀; nitori eyi [tumọsi, NW] ẹ̀jẹ̀ mi ti majẹmu titun, ti a ta silẹ fun ọpọ eniyan fun imukuro ẹṣẹ. Ṣugbọn mo wi fun yin, lati isinsinyi lọ emi kì yoo mu ninu eso àjàrà yii mọ́, titi yoo fi di ọjọ naa, nigba ti emi ó sì bá yin mu ún ni titun ni ijọba Baba mi. Nigba ti wọn sì kọ orin kan tán, wọn jade lọ sori Oke Olifi.”—Matteu 26:26-30.
Eyi wáyé lẹhin ìgbà ti oòrùn wọ̀ ni ọjọ kẹrinla oṣu Nisan ti awọn Ju ni ọdun 33 Sanmani Tiwa. Jesu ati awọn aposteli rẹ̀ ṣẹṣẹ ṣayẹyẹ Ajọ-irekọja ní ìṣèrántí idande Israeli kuro ninu oko-òǹdè awọn ará Egipti ni ọrundun kẹrindinlogun B.C.E. tán ni. Kristi ti jẹ́ ki Judasi Iskariotu, ẹni ti ó kù dẹ̀dẹ̀ fun ki ó fi i hàn jade lọ. Fun idi yii, kìkì Jesu ati awọn aposteli rẹ̀ aduroṣinṣin 11 ni wọn wà nibẹ.
Ounjẹ-alẹ yii kìí ṣe ìmútẹ̀síwájú Ajọ-irekọja ti awọn Ju. Ó jẹ́ ohun titun kan ti a wá pè ni Ounjẹ Alẹ́ Oluwa. Nipa ayẹyẹ yii, Jesu paṣẹ fun awọn ọmọlẹhin rẹ̀ pe: “Ẹ maa ṣe eyi ni iranti mi.” (Luku 22:19, 20; 1 Korinti 11:24-26) Eeṣe ti oun fi sọ eyi? Bawo sì ni iṣẹlẹ ọlọ́pọ̀ ọrundun sẹhin yii ti lè ṣeeṣe ki ó ni itumọ fun ọ?