Iná Ọrun-apaadi—Ó Ń Jó Bùlàbùlà Tabi Ó Ń Kúlọ Diẹdiẹ?
ONIWAASU Protẹstanti Jonathan Edwards nigba kan rí maa ń kó ipaya bá ọkàn awọn ará America ti a Ń Gbókèèrè Ṣakoso ni ọrundun kejidinlogun pẹlu bi o ṣe ń gbe ọrun-apaadi alaworan jade. Lẹẹkanri ó ṣapejuwe ìran kan ninu eyi ti Ọlọrun ti ń fi awọn ẹlẹṣẹ dirodiro bi aláǹtakùn ti a koriira lori ẹ̀là iná. Edwards bá ijọ rẹ̀ wí pe: “Iwọ ẹlẹṣẹ, òwú tín-ín-rín ni ó so ọ́ rọ̀, pẹlu ẹ̀là iná ibinu atọrunwa tí ń bù yẹ̀rì yika rẹ̀, ti ó sì ṣetan ni gbogbo akoko lati wì í, ki ó sì jó o palẹ̀.”
Bi o ti wu ki o ri, gẹ́rẹ́ lẹhin ti Edwards ṣe iwaasu olokiki buburu yii tán, igbagbọ ninu ẹkọ ọrun-apaadi, bi ọ̀ràn naa ti rí, bẹrẹ síí jó lọ́úlọ́ú ti o si ń kúlọ diẹdiẹ.a Iwe naa The Decline of Hell, lati ọwọ D. P. Walker, ṣakiyesi pe “nigba ti o fi maa di ẹwadun kẹrin ti ọrundun kejidinlogun ẹkọ idaloro ayeraye fun awọn ti a dẹbi fun ni a ń penija nígbangba-gbàǹgbà.” Ni ọrundun kọkandinlogun, igbagbọ ninu ẹkọ ina ọrun-apaadi ń baa lọ lati maa kú lọ diẹdiẹ, nigba ti o sì fi maa di aarin ọrundun ogun, oju-iwoye Edwards nipa ọrun-apaadi gẹgẹ bi ‘ìléru oníná nibi ti a ti ń dá awọn ojiya rẹ̀ lóró lọna ti ó lékenkà kan ninu ọkàn wọn ati ni òde ara wọn titi ayeraye’ ti dawọ duro lati maa jẹ́ akori ibanisọrọpọ kan. “Bi ọgbọ́n ìrònújinlẹ̀ igbalode ti gbéjà kò ó tí ẹ̀là iná Hiroshima ati Iparundeeru naa si ti sọ ọ́ di eyi ti o ṣá,” ni akọrohin Jeffery Sheler sọ, “aworan adẹrubani ti ọrun-apaadi padanu pupọ ninu awọn ìpániláyà rẹ̀.”
Ọpọ awọn oniwaasu ti padanu ìfẹ́ràn wọn fun iná ati imí-ọjọ́ pẹlu. Awọn iwaasu kikamama lori ìpayà ọrun-apaadi pòórá lati inu awọn ọ̀rọ̀ ayinileropada ori pepele iwaasu awọn ṣọọṣi ibilẹ ti Kristẹndọm. Fun eyi ti o pọ julọ ninu awọn ẹlẹkọọ-isin, ọrun-apaadi di koko ẹkọ ti o ti di alaibagbamu ju fun ẹkọ-giga ti o jinlẹ. Ni awọn ọdun bii melookan sẹhin opitan ṣọọṣi kan ń ṣe iwadii nipa ọrun-apaadi fun awiye ile-ẹkọ yunifasiti kan, ó sì ṣayẹwo awọn atọka ninu oniruuru awọn iwe-agberohinjade ti ó jẹ́ ti awọn ọmọwe. Oun kò lè rí akọsilẹ kanṣoṣo nipa rẹ̀. Ni ibamu pẹlu iwe-irohin Newsweek, opitan naa pari ero pe: “Ọrun-apaadi pòórá. Kò sì sí ẹni ti o fura.”
Ipadawa Ọrun-Apaadi
Ó ha pòórá bi? Bẹẹkọ niti gidi. Lọna ti o yanilẹnu, ni awọn ọdun lọ́ọ́lọ́ọ́ yii ẹkọ nipa ọrun-apaadi ti jó soke lẹẹkan sii ni awọn ibi melookan. Awọn iwadii ti a ṣe ni America fihàn pe iye awọn eniyan ti wọn sọ pe awọn gbagbọ ninu ọrun-apaadi lọ soke lati ori ipin 53 ninu ọgọrun-un ni 1981 si ipin 60 ninu ọgọrun-un ni 1990. Fi ilọsoke kaakiri agbaye niti awọn ajọ igbokegbodo ajihinrere ti wọn ń waasu ọrun-apaadi kun eyi, ó sì jẹ́ eyi ti o ṣe kedere pe ipadabọ ọrun-apaadi ti o kamama ninu ironu Kristẹndọm jẹ́ ifarahan ti o yanilẹnu kaakiri agbaye niti gidi gan-an.
Ṣugbọn ìtúnmúsọjí yii ha kan kìkì awọn eniyan ijọ bi, tabi ó ha ti dé ọ̀dọ̀ awọn alufaa pẹlu bi? Otitọ naa ni pe ina ọrun-apaadi gẹgẹ bi Jonathan Edwards ṣe waasu rẹ̀ ni 250 ọdun sẹhin kò tíì pòórá lori pepele iwaasu awọn Kristẹndọm melookan ti kò fẹ́ iyipada. Ni 1991, U.S.News & World Report ṣakiyesi pe: “Àní laaarin awọn ògúnná gbongbo ẹya-isin ti o nifẹẹ si iyipada melookan paapaa, awọn ami wà pe awọn ẹlẹkọọ-isin ti bẹrẹ síí ronu kikankikan sii nipa ero ọrun-apaadi ju bi wọn ti ṣe ni awọn ẹwadun lọ.” Lọna ti o ṣe kedere, lẹhin awọn ọdun ìpatì, ina ọrun-apaadi ti di ohun ti o lokiki ti a sì kà sí pataki lẹẹkan sii kaakiri agbaye. Bi o ti wu ki o ri, ó ha ti di awọn ìrísí oníná rẹ̀ mú bi?
Awọn Ibeere Ti A Gbé Dìde
Ẹlẹkọọ-isin W. F. Wolbrecht kò ni iyèméjì pe: “Ọrun-apaadi ni ọrun-apaadi ń jẹ́, kò sì sí idaniyan tabi ironu eniyan kan ti o lè mú ki ó dinku si ìyà ainipẹkun.” Ọpọ ninu awọn ti ń lọ si ṣọọṣi ni kò fi bẹẹ daloju. Bi o tilẹ jẹ pe wọn kò ṣiyemeji nipa wíwà ọrun-apaadi, wọn ni awọn ibeere nipa bi ọrun-apaadi ti rí. Ẹlẹkọọ-isin miiran jẹwọ pe: “Fun emi pẹlu, ọrun-apaadi jẹ́ otitọ gidi kan ti a kò gbé ibeere dìde si, ti a kede ni kedere ninu ẹ̀rí Bibeli, ṣugbọn ìrísi rẹ̀ niti pato jẹ́ eyi ti o ni iṣoro.” Bẹẹni, fun iye awọn ẹlẹkọọ-isin ati awọn ọmọ ijọ ti ń pọ̀ sii, ibeere naa lonii kìí ṣe, “Ǹjẹ́ ọrun-apaadi kan ha wà bi?” ṣugbọn, “Ki ni ọrun-apaadi jẹ́?”
Bawo ni iwọ yoo ṣe dahun? Ki ni a ti sọ fun ọ nipa irisi ọrun-apaadi? Eesitiṣe ti awọn Kristian olotiitọ-inu fi ń daamu nipa ẹkọ yii?
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ni July 8, 1741, Edwards ṣe iwaasu naa “Awọn Ẹlẹṣẹ Lọwọ Ọlọrun Onibiinu Kan.”
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 2]
Cover: Doré’s illustration of Tumult and Escape for Dante’s Divine Comedy
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]
Aworan Eṣu ati Virgil ti Doré yà fun Divine Comedy ti Dante