Iwọ Ha Ranti Bi?
Iwọ ha ti ronu gidigidi lori awọn itẹjade Ilé-Ìṣọ́nà ẹnu aipẹ yii bi? Bi o bá rí bẹẹ, boya iwọ yoo rí i gẹgẹ bi ohun ti ń fanilọkan mọra lati pe awọn ohun ti ó tẹle e wọnyi pada sọkan:
▫ Ki ni “àmì ti o tumọsi iwarere-iṣeun” ti Jehofa ṣaṣepari rẹ̀ fun awọn atẹ̀lé ipasẹ Jesu? (Orin Dafidi 86:17, NW) “Ayọ ẹmi mimọ” ti ń fun awọn Kristian igbaani lokun lati farada inunibini ti o dé sí wọn ni. (1 Tessalonika 1:6) Ó rí bakan naa lonii, ó sì tẹ́ Jehofa, Olufunni ni “gbogbo ẹbun rere ati gbogbo ẹbun pípé,” lọ́rùn lati “fi ẹmi mimọ rẹ̀ fun awọn ti o ń beere lọdọ rẹ̀.” (Jakọbu 1:17; Luku 11:13) Nitori naa ayọ ẹmi mimọ ni ó ń ṣaṣepari “àmì kan ti o tumọsi iwarere-iṣeun” fun awọn ọmọlẹhin Jesu.—12/15, oju-iwe 18 si 19.
▫ Eeṣe ti o fi ṣe pataki fun wa lati tẹwọgba oju-iwoye Ọlọrun nipa irọ́ pípa? Orin Dafidi 5:6 sọ pe Ọlọrun “ó pa awọn ti ń ṣe èké run.” Ìfihàn 21:8 sọ siwaju sii pe ayanmọ gbogbo awọn opurọ jẹ́ “iku keji.” Nitori naa, titẹwọgba oju-iwoye Ọlọrun nipa irọ́ pípa fun wa ni idi lilagbara lati sọ otitọ ki a sì gba ẹbun ìyè rẹ̀.—12/15, oju-iwe 23.
▫ Ki ni ó parapọ jẹ iru-oriṣi ijọsin awọn ara Samaria? (Johannu 4:20) Awọn ara Samaria, ninu ijọsin wọn aládàlù, tẹwọgba kìkì iwe marun-un akọkọ ti Mose, Pentateuch, gẹgẹ bi Iwe Mimọ. Ni nǹkan bi ọrundun kẹrin B.C.E., wọn gbé tẹmpili kan kalẹ lori Oke Gerisimu, ni idije pẹlu tẹmpili Ọlọrun ni Jerusalemu. Bi o tilẹ jẹ pe tẹmpili awọn ara Samaria ni a parun, titi di oni olonii wọn ń ṣe ayẹyẹ Ajọ-irekọja lori oke Gerisimu.—1/1, oju-iwe 25.
▫ A ha reti pe ki awọn Kristian gbé eto igbogun ti ìsọdèérí tabi igbesẹ ìpalẹ̀-ìdọ̀tí-mọ́ larugẹ bi? Nigba ti ó wà lori ilẹ̀-ayé, Jesu kò gbiyanju lati yanju gbogbo iṣoro ẹgbẹ-oun-ọgba ti ọjọ rẹ. Nigba ti Jehofa nipasẹ Ijọba Messia rẹ̀ bá fi awọn ilana òdodo rẹ̀ lélẹ̀ jakejado gbogbo ayé, awọn iṣoro ayika ni a o yanju fáàbàdà. Nitori naa, awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa di oju-iwoye ti o wà deedee mu. Ifẹ aladuugbo ń sún wọn lati fi ọ̀wọ̀ hàn fun ohun-ìní awọn ẹlomiran, ṣugbọn wọn fi ẹ̀tọ́ fi iṣẹ iwaasu ihin-iṣẹ Ijọba Ọlọrun si ipo kin-in-ni. (Matteu 6:33)—1/1, oju-iwe 31.
▫ Ni awọn ọ̀nà wo ni Jesu gbà ṣiṣẹsin gẹgẹ bi olùtan ìmọ́lẹ̀ kan? (Johannu 8:12) Jesu ya araarẹ sọtọ fun wiwaasu ihinrere Ijọba Ọlọrun. (Luku 4:43; Johannu 18:37) Ó tun tudii aṣiiri awọn èké inu isin ó sì tipa bayii pese ominira tẹmi fun awọn wọnni ti a fi sabẹ isinru isin. (Matteu 15:3-9) Lọna ti o hàn gbangba, ó fẹ̀rí hàn pe oun jẹ́ ìmọ́lẹ̀ ayé nipa fifi iwalaaye ẹ̀dá eniyan pípé rẹ̀ lélẹ̀ gẹgẹ bi irapada. (Matteu 20:28; Johannu 3:16)—1/15, oju-iwe 10 si 11.
▫ Ki ni awọn idi melookan ti a fi jẹ Jehofa Ọlọrun ni gbese itẹriba? Jehofa ni Ọba-alaṣẹ Agbaye, ati fun idi yii a jẹ ẹ́ ni gbese itẹriba wa. Bakan naa pẹlu, niwọn bi Jehofa ti jẹ́ olodumare, kò sí ẹni ti o lè takò ó pẹlu aṣeyọrisirere, nitori naa a kò lè ṣaika itẹriba wa fun un sí. Gbogbo awọn ẹ̀dá ọlọgbọnloye ni a dá lati ṣiṣẹsin ète Oluṣẹda wọn, eyi sì fi gbogbo wọn sabẹ aigbọdọmaṣe lati tẹri araawọn bá fun Ọlọrun ni gbogbo ọ̀nà.—2/1, oju-iwe 10 si 11.
▫ Ki ni ó ran Josẹfu lọwọ lati yẹra fun didẹṣẹ agbere pẹlu aya Potifari? Josẹfu ni ipá alagbara ti ń sún ọkàn rẹ̀ ṣiṣẹ. Oun wà lojufo nipa ipo-ibatan rẹ̀ pẹlu Jehofa ó sì mọriri pe iṣe agbere kan yoo jẹ́ didẹṣẹ kìí ṣe si ọkọ [obinrin naa] nikan ṣugbọn, lọna ti o ṣe pataki ju, si Ọlọrun.—2/15, oju-iwe 21.
▫ Ki ni ohun ti Jesu ní lọ́kàn nigba ti o sọ pe: “Emi ni . . . otitọ”? (Johannu 14:6) Kìí ṣe kìkì pe Jesu sọ otitọ ti o sì kọni nikan ni; ó gbé igbesi-aye otitọ ó sì ṣapẹẹrẹ rẹ. Nipa bayii, isin Kristian kìí ṣe èrò lasan kan; ó jẹ́ ọ̀nà igbesi-aye.—3/1, oju-iwe 15.
▫ Ẹkọ atunininu wo ni o wà ninu Orin Dafidi 51? Orin yii ràn wá lọwọ lati mọ pe bi a bá ṣubu sinu ẹṣẹ ṣugbọn ti a ronupiwada nitootọ, Baba wa ọrun onifẹẹ yoo gbọ́ igbe wa fun aanu yoo si gbà wá kuro lọwọ ainireti. Bi o ti wu ki o ri, a gbọdọ daniyan niti gidi nipa ẹ̀gàn eyikeyii ti a mu wa sori orukọ Jehofa.—3/15, oju-iwe 18.
▫ Ki ni ohun ti iribọmi ninu omi ṣapẹẹrẹ? Iribọmi jẹ́ àmì iyasimimọ itagbangba ti ẹnikan ṣe fun Jehofa Ọlọrun. Jijẹ ẹni ti a rì sabẹ omi fihàn pe awọn ti a baptisi ń kú si ipa-ọna igbesi-aye kan ti o dalori araawọn. Jijẹ ẹni ti a fà soke kuro ninu omi ṣapẹẹrẹ pe wọn walaaye nisinsinyi lati ṣe ifẹ-inu Ọlọrun, ni fífi í si ipo akọkọ ninu igbesi-aye wọn. (Matteu 16:24)—4/1, oju-iwe 5 si 6.