ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w93 5/15 ojú ìwé 31
  • Ibeere Lati Ọwọ́ Awọn Òǹkàwé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ibeere Lati Ọwọ́ Awọn Òǹkàwé
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Sọ Fún Wa, Ìgbà Wo Ni Nǹkan Wọ̀nyí Yóò Ṣẹlẹ̀?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
  • Ọjọ́ Ọ̀la Wo Ni Ó Wà Fún Àwọn Àgùntàn àti Ewúrẹ́?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Máa Fi Ìdúróṣinṣin Ti Àwọn Arákùnrin Kristi Lẹ́yìn
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Kristi Ṣèdájọ́ Àgùntàn àti Ewúrẹ́
    Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
w93 5/15 ojú ìwé 31

Ibeere Lati Ọwọ́ Awọn Òǹkàwé

Awọn eniyan ni a o ha jí dide bi wọn kò bá tẹwọgba isin Kristian tootọ nisinsinyi ti wọn sì kú ṣaaju ki ipọnju nla tó bẹrẹ bi?

Ó dara ki gbogbo wa dènà itẹsi eyikeyii lati huwa gẹgẹ bi awọn onidaajọ, ní mímọ̀ pe ni àbárèbábọ̀, idajọ Jehofa nipasẹ Jesu Kristi ni ó ṣe pataki. (Johannu 5:22; Iṣe 10:42; 2 Timoteu 4:1) Ṣugbọn Iwe Mimọ pese awọn isọfunni rirannilọwọ diẹ ni idahun si ibeere ti a ṣẹṣẹ beere tán yii.

Iwaasu ihinrere Ijọba Ọlọrun kari-aye jẹ́ ìhà ṣiṣekoko kan ninu ‘àmì wíwà-níhìn-ín Jesu.’ Àmì yii ni a ti ń ri ẹ̀rí rẹ̀ lati kutukutu ọrundun yii. Iṣẹ iwaasu naa ti ń yọrisi pípín awọn eniyan orilẹ-ede gbogbo ni imuṣẹ òwe-àkàwé Jesu nipa “agutan” ati “ewurẹ.” Pẹlu ipari igbokegbodo wiwaasu ati pípín yii, “ipọnju nla” naa yoo mú opin débá eto-igbekalẹ awọn nǹkan buburu yii.—Matteu 24:3, 21, 22; 25:31-46.

Jehofa, papọ pẹlu Ọmọkunrin rẹ̀, ni wọn yoo ṣedajọ yala ẹnikẹni ti o kọ ihin-iṣẹ Ijọba naa silẹ ti ó sì kú ṣaaju ibẹsilẹ ipọnju nla ni a o kàsí ẹgbẹ́ ewurẹ. Jesu sọ pe awọn ewurẹ “yoo kọja lọ sinu ìkékúrò ainipẹkun.” Nitori naa, a lè pari-ero si pe awọn wọnni ti Ọlọrun pinnu pe wọn jẹ́ ewurẹ kò ni ri ajinde gbà. Wọn ni idajọ ti ó dọgba pẹlu ti awọn wọnni ti wọn “yoo jiya iparun ainipẹkun” ni akoko ipọnju nla.—2 Tessalonika 1:9.

Ṣugbọn ki ni nipa ti awọn wọnni ti ó lè jọbi pe a kò tíì la oju wọn si ihin-iṣẹ Ijọba naa lọna ti ó tó tẹ́rùn ki o baa ti lè ṣeeṣe fun wọn lati ṣe yíyàn ti o lọgbọn-ninu fun tabi lodisi otitọ ṣaaju ki wọn tó kú ni “ikẹhin ọjọ” wọnyi?—2 Timoteu 3:1.

Ọpọlọpọ ti ó kú nigba ti iṣẹ iwaasu naa ṣì ń lọ lọwọ ṣaaju ipọnju nla ni o ṣe kedere pe wọn yoo gba ajinde. Eyi ni a fihàn nipa ohun ti a kà ni Ìfihàn 6:7, 8 nipa ìgẹṣin awọn ọkunrin ẹlẹṣin afiṣapẹẹrẹ naa. Ọpọlọpọ eniyan ti kú gẹgẹ bi awọn ojiya ipalara awọn ogun, aito ounjẹ, ati awọn àrùn panipani. Niwọn bi o ti jẹ pe “Ipo-oku” ni o gba awọn ojiya ipalara “Iku” wọnyi, a o jí wọn dide nigba Iṣakoso Ẹlẹgbẹrun Ọdun ti Kristi, nigba ti Ipo-oku bá jọ̀wọ́ gbogbo òkú ti ó wà ninu rẹ̀ lọwọ. (Ìfihàn 20:13) Ọpọ ninu awọn wọnni ti a o jí dide ti lè ni ifarakanra diẹ pẹlu ihin-iṣẹ Ijọba naa ṣaaju ki wọn tó kú.

A ti nilati kún fun imoore tó pe Jesu kò fi silẹ fun awọn eniyan lati pinnu awọn wo ni wọn dabi agutan ati awọn wo ni wọn dabi ewurẹ! Awọn eniyan alaipe kò lè ṣediyele bi anfaani ti ẹni pato kan ní lati gbọ́ ki ó sì tẹwọgba ihinrere naa ti pọ̀ tó lọna bibojumu. Awa ha lè mọ ohun ti ipo ọkan-aya rẹ̀ jẹ́ tabi boya ó nifẹẹ òdodo nitootọ bi? Awa ha lè diwọn bi idile rẹ̀ ti lè nipa lori idahunpada rẹ̀ tó, ipo atilẹwa rẹ̀ niti isin, tabi awọn agbara-idari miiran bi? Bẹẹkọ ni kedere. Sibẹ, a lè ni idaniloju pe Jehofa Ọlọrun ati Jesu Kristi lè ṣediyele iru awọn ọ̀ràn bẹẹ ki wọn sì dori idajọ ti ó péye, ti o bá ẹ̀tọ́ mu, ti ó sì jẹ́ òdodo.—Deuteronomi 32:4; Isaiah 11:1-5.

Nitori eyi, kò sí idi kankan fun wa lati maa méfò nipa awọn wo lara awọn wọnni ti wọn ti kú lẹnu aipẹ yii ni a lè tabi ni a kò lè jí dide. Eyi jẹ́ ohun kan ti a kò tíì fun wa laṣẹ lati ṣe. (Fiwe Luku 12:13, 14.) Ó fi pupọpupọ bọ́gbọ́nmu julọ fun wa lati duro lori ipinnu awọn Onidaajọ òdodo naa, Jehofa Ọlọrun ati Jesu Kristi. Eyi yoo tubọ fun wa ni alaafia ọkan gẹgẹ bi iranṣẹ Jehofa. Yoo tun ràn wá lọwọ lati fi iyè ti o tubọ dara si ohun ti a ti yàn fun wa lati ṣe—‘ẹ lọ sọ awọn eniyan orilẹ-ede gbogbo di ọmọ-ẹhin, ni kíkọ́ wọn lati kiyesi ohun gbogbo ti Jesu ti palaṣẹ.’—Matteu 28:19, 20.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 30]

Agutan Leicester, Meyers

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́