ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w93 7/1 ojú ìwé 18-23
  • Rírìn Pẹlu Ọgbọ́n Sipa Ti Ayé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Rírìn Pẹlu Ọgbọ́n Sipa Ti Ayé
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bibori Ẹtanu
  • Wọ́n Jẹ́ Onitara, Wọn Kìí Ṣe Oníjàgídíjàgan
  • Wọn Ń Bọ̀wọ̀ Funni Wọn sì ‘Muratan fun Iṣẹ Rere Gbogbo’
  • ‘Bi Ó Ba Ṣeeṣe, Ẹ Maa Wà Ní Alaafia Pẹlu Gbogbo Eniyan’
  • ‘Ṣiṣoore fun Gbogbo Eniyan’
  • Pípa Awọn Alatako Lẹnu Mọ́
  • “Ẹ Jẹ́ Ẹlẹ́mìí Àlàáfíà Pẹ̀lú Gbogbo Ènìyàn”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • “Ẹ Tọ́jú Ìwà Yín Kí ó Dára Lọ́pọ̀lọpọ̀ Láàárín Àwọn Orílẹ̀-èdè”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
  • Àwọn Kristẹni àti Ayé Aráyé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Ìgbà Tí Ẹ̀tanú Kì Yóò Sí Mọ́!
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
w93 7/1 ojú ìwé 18-23

Rírìn Pẹlu Ọgbọ́n Sipa Ti Ayé

“Ẹ maa rìn nipa ọgbọ́n si awọn ti ń bẹ lóde.”—KOLOSSE 4:5.

1. Ki ni a gbé ko awọn Kristian ijimiji loju, imọran wo sì ni Paulu fun ijọ ti o wà ni Kolosse?

AWỌN Kristian ijimiji ti wọn ń gbé ni awọn ilu-nla ayé Romu ni a ń kò loju lati ìgbà de ìgbà pẹlu ibọriṣa, wíwá faaji oniwa palapala, ati awọn ààtò ati aṣa ibọriṣa. Awọn ti wọn gbé ni Kolosse, ilu-nla kan ni iha ila-oorun aarin gbungbun Asia Kekere, laiṣe aniani ni a gbé ijọsin yèyé abo ọlọrun ati ibẹmiilo ti awọn ọmọ ibilẹ Frigia, ọgbọ́n imọ-ọran oriṣa ti awọn atipo Griki, ati isin Ju ti àgọ́ awujọ Ju ti a tẹdo kò lójú. Aposteli Paulu gba ijọ Kristian nimọran lati “maa rìn nipa ọgbọ́n” si iru awọn ohun bẹẹ “ti ń bẹ lóde.”—Kolosse 4:5.

2. Eeṣe ti awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa lonii fi nilati rìn pẹlu ọgbọ́n sipa awọn wọnni ti wọn wà lóde?

2 Lonii, awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń koju iru awọn àṣà kan-naa ti kò tọna, ati eyi ti o tilẹ ju bẹẹ lọ. Awọn pẹlu, nitori naa, nilati lo ọgbọ́n ninu ipo-ibatan wọn pẹlu awọn wọnni ti wọn wà lẹ́hìn-òde ijọ Kristian tootọ. Ọpọ awọn eniyan ninu awọn ile isin ati oṣelu ati awọn agberohinjade tako wọn. Awọn kan ninu awọn wọnyi, yala nipa ikọluni gbangba tabi, bi o ti maa ń figba gbogbo jẹ́, nipa awọn ọ̀rọ̀ aláìbáradé, ń gbiyanju lati ba orukọ rere awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa jẹ́ ki wọn si gbé ẹtanu dide lodisi wọn. Gan-an gẹgẹ bi a ti fojuwo awọn Kristian ijimiji lọna aitọ gẹgẹ bi “ẹ̀ya” onitara òdì kan ti o tilẹ lewu, awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa lonii ni wọn sábà maa ń jẹ́ ẹni ti a ń fi ẹtanu hàn si ati ẹni ti a ń ṣìlóye.—Iṣe 24:14; 1 Peteru 4:4.

Bibori Ẹtanu

3, 4. (a) Eeṣe ti ayé kì yoo fi nifẹẹ si awọn Kristian tootọ lae, ṣugbọn ki ni a gbọdọ gbiyanju lati ṣe? (b) Ki ni onṣewe kan kọ nipa awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti a fi si itimọle ninu ọgbà iṣẹniniṣẹẹ Nazi kan?

3 Awọn Kristian tootọ kò reti pe ki ayé nifẹẹ wọn, eyi ti, gẹgẹ bi aposteli Johannu ti sọ, ó “wà ni [abẹ́] agbara ẹni buburu ni.” (1 Johannu 5:19) Bi o tilẹ ri bẹẹ, Bibeli fun awọn Kristian ni iṣiri lati sakun lati jere awọn eniyan sọdọ Jehofa ati isin rẹ̀ mimọ gaara. Eyi ni awa ń ṣe nipa iwaasu taarata ati pẹlu nipa iwa hihu wa ti o dara. Aposteli Peteru kọwe pe: “Ki ìwà yin laaarin awọn Keferi ki o dara; pe, bi wọn ti ń sọrọ yin bi oluṣe buburu, nipa iṣẹ rere yin, ti wọn ó maa kiyesi, ki wọn ki o lè maa yin Ọlọrun lógo ni ọjọ ibẹwo.”—1 Peteru 2:12.

4 Ninu iwe rẹ̀ Forgive—But Do Not Forget, onṣewe Sylvia Salvesen sọ nipa awọn obinrin Ẹlẹ́rìí ti wọn jumọ jẹ́ ẹlẹ́wọ̀n ni ọgbà ìṣẹniníṣẹ̀ẹ́ Nazi kan pe: “Awọn meji yẹn, Käthe ati Margarethe, ati ọpọlọpọ awọn miiran, ràn mí lọwọ gan-an ni, kìí ṣe kiki nipa igbagbọ wọn nikan ni ṣugbọn ninu awọn ọ̀ràn gbigbeṣẹ. Wọn pese awọn akisa mímọ́ tonitoni akọkọ ti a ní fun awọn egbò wa . . . Ni kukuru a rí araawa laaarin awọn eniyan ti wọn ro rere si wa, ti wọn sì fi imọlara bi ọ̀rẹ́ wọn hàn nipa awọn igbesẹ wọn.” Ẹ wo iru ẹ̀rí rere ti eyi jẹ́ lati ọ̀dọ̀ “awọn ti ń bẹ lóde”!

5, 6. (a) Iṣẹ wo ni Kristi ń ṣaṣepari rẹ̀ ni akoko isinsinyi, ki sì ni awa kò gbọdọ gbagbe? (b) Ki ni o gbọdọ jẹ iṣarasihuwa wa sipa ti awọn eniyan ayé, eesitiṣe?

5 A lè ṣe pupọ lati paná ẹtanu nipa ọ̀nà ọgbọ́n ti a ń gbà dari araawa sipa awọn ara òde. Lotiitọ, awa ń gbé ni akoko naa nigba ti Ọba wa ti ń ṣakoso, Kristi Jesu, ń ṣe iyasọtọ awọn eniyan orilẹ-ede gbogbo, “gẹgẹ bi oluṣọ-agutan tií ya agutan rẹ̀ kuro ninu ewurẹ.” (Matteu 25:32) Ṣugbọn maṣe gbagbe lae pe Kristi ni Onidaajọ; oun ni ẹni ti ń pinnu awọn ti wọn jẹ́ “agutan” ati awọn ti wọn jẹ́ “ewurẹ.”—Johannu 5:22.

6 Eyi gbọdọ nipa lori ihuwa wa sipa awọn wọnni ti wọn kìí ṣe apakan eto-ajọ Jehofa. Awa lè ronu nipa wọn gẹgẹ bi eniyan ayé, ṣugbọn wọn jẹ́ apakan ayé araye ti “Ọlọrun fẹ́ . . . tobẹẹ gẹ́ẹ́, ti o fi fi Ọmọ-bíbí rẹ̀ kanṣoṣo funni, ki ẹnikẹni ti o bá gbà á gbọ́ ma baa ṣegbe, ṣugbọn ki o lè ni iye ainipẹkun.” (Johannu 3:16) O sàn ju lọpọlọpọ lati ka awọn eniyan si agutan lọjọ iwaju ju ki a fi abẹbẹlubẹ pinnu pe ewurẹ ni wọn jẹ́ lọ. Awọn kan ti wọn ti figbakanri jẹ́ alatako si otitọ lọna ti o mú iwa-ipa dani ti di Ẹlẹ́rìí oluṣeyasimimọ bayii. Pupọ ninu awọn wọnyi ni a si kọkọ jere nipasẹ awọn iṣe oninurere, ṣaaju ki wọn to dahunpada si iwaasu taarata eyikeyii. Wo aworan ti o wà ni oju-iwe 18, fun apẹẹrẹ.

Wọ́n Jẹ́ Onitara, Wọn Kìí Ṣe Oníjàgídíjàgan

7. Èrò lámèyítọ́ wo ni poopu sọ jade, ṣugbọn ibeere wo ni a lè beere?

7 Poopu John Paul II ṣe lámèyítọ́ awọn ẹ̀ya isin lapapọ, ati awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni pataki, nigba ti o sọ pe: “Itara naa ti o fẹrẹẹ jẹ ti oníjàgídíjàgan eyi ti awọn diẹ fi ń wá awọn ọmọ-ẹhin titun, lilọ lati ile de ile, tabi dídá awọn ti ń kọja lọ loju ọ̀nà duro ni awọn igun opopona, jẹ́ ayédèrú ẹmi ìgbónára bii ti awọn aposteli ati ojihin-iṣẹ-Ọlọrun lọna ìyapa.” A lè beere pe, Bi tiwa bá jẹ́ “ayédèrú ẹmi ìgbónára bii ti awọn aposteli ati ojihin-iṣẹ-Ọlọrun,” nibo ni a ti lè ri itara ijihinrere gidi? Niti tootọ kìí ṣe laaarin awọn Katoliki bẹẹ ni, niti iyẹn, kìí ṣe laaarin awọn Protẹstanti tabi awọn mẹmba ṣọọṣi Orthodox paapaa.

8. Bawo ni a ṣe gbọdọ ṣe iṣẹ iwaasu ile-de-ile wa, pẹlu ireti fun abajade wo?

8 Bi o tilẹ ri bẹẹ, lati já irọ́ ẹ̀sùn ìwà jàgídíjàgan eyikeyii ninu ijẹrii wa, awa nigba gbogbo gbọdọ ni iwapẹlẹ, kun fun ọ̀wọ̀, ki a sì jẹ ẹni-bi-ọrẹ nigba ti a bá tọ awọn eniyan lọ. Ọmọ-ẹhin naa Jakọbu kọwe pe: “Ta ni o gbọ́n ti o sì ni ìmọ̀ ninu yin? Ẹ jẹ ki o fi iṣẹ rẹ̀ hàn nipa iwa rere, nipa iwa tutu ti ọgbọ́n.” (Jakọbu 3:13) Aposteli Paulu rọ̀ wa ‘ki a má jẹ́ oníjà.’ (Titu 3:2) Fun apẹẹrẹ, dipo didẹbi fun igbagbọ ẹni kan ti a ń waasu fun lẹsẹkẹsẹ, eeṣe ti a kò fi ọkàn-ìfẹ́ atọkanwa hàn si awọn ero-ọkan rẹ̀? Lẹhin naa sọ ihinrere fun ẹni naa bi o ti wà ninu Bibeli. Nipa mimu iyọsini onifojusọna fun rere ati fifi ọ̀wọ̀ ti o yẹ hàn fun awọn eniyan ti wọn ní awọn igbagbọ miiran, awa yoo ràn wọ́n lọwọ lati ni ero-inu ti o dara ju lati fetisilẹ, ati boya wọn yoo fòye mọ iniyelori ihin-iṣẹ Bibeli. Abajade rẹ̀ lè jẹ́ pe awọn diẹ yoo wá lati “yin Ọlọrun lógo.”—1 Peteru 2:12.

9. Ọ̀nà wo ni a lè gbà ṣe ifisilo imọran ti Paulu fifunni (a) ninu Kolosse 4:5? (b) ninu Kolosse 4:6?

9 Aposteli Paulu gbaninimọran pe: “Ẹ maa rìn nipa ọgbọ́n si awọn ti ń bẹ lóde, ki ẹ si maa ṣe irapada ìgbà.” (Kolosse 4:5) Nigba ti o ń ṣalaye ọ̀rọ̀ ti o kẹhin yii, J. B. Lightfoot kọwe pe: “Maṣe padanu anfaani eyikeyii, ti sísọ ati ṣíṣe ohun ti o lè mú ọ̀nà Ọlọrun tẹsiwaju.” (Ikọwe winniwinni jẹ́ tiwa.) Bẹẹni, a gbọdọ wà ni muratan pẹlu awọn ọ̀rọ̀ ati iṣe ni akoko ti o wọ̀. Iru ọgbọ́n bẹẹ tun ni ninu yiyan akoko ti o wọ̀ lati ṣe awọn ikesini. Bi a bá kọ ihin-iṣẹ wa, o ha jẹ́ nitori pe awọn eniyan kò mọriri rẹ̀ ni, tabi o ha jẹ́ nitori pe a ṣe ikesini ní akoko kan ti o ṣeeṣe ki o má wọ̀ bi? Paulu tun kọwe pe: “Ẹ jẹ́ ki ọ̀rọ̀ yin ki o dapọ mọ́ oore-ọfẹ nigba gbogbo, eyi ti a fi iyọ̀ dùn, ki ẹyin ki o lè mọ bi ẹyin ó ti maa dá olukuluku eniyan lóhùn.” (Kolosse 4:6) Eyi gba ironu ṣaaju ati ifẹ tootọ fun aladuugbo. Ẹ jẹ́ ki a maa gbé ihin-iṣẹ Ijọba naa kalẹ̀ pẹlu oore-ọfẹ nigba gbogbo.

Wọn Ń Bọ̀wọ̀ Funni Wọn sì ‘Muratan fun Iṣẹ Rere Gbogbo’

10. (a) Imọran wo ni aposteli Paulu fifun awọn Kristian ti wọn ń gbé ni Krete? (b) Bawo ni awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti ṣe jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ ní titẹle imọran Paulu?

10 Awa kò lè fi awọn ilana Bibeli bánidọ́rẹ̀ẹ́. Ni ọwọ́ keji ẹ̀wẹ̀, a kò gbọdọ jiyàn nipa awọn ibeere ti kò kan iwatitọ Kristian. Aposteli Paulu kọwe pe: “Maa rán wọn [awọn Kristian ni Krete] leti lati maa tẹriba fun awọn ijoye, ati fun awọn alaṣẹ, lati maa gbọ tiwọn, ati lati maa mura si iṣẹ rere gbogbo, ki wọn má sọrọ ẹnikẹni ni ibi, ki wọn má jẹ́ oníjà, bikoṣe ẹni pẹlẹ, ki wọn maa fi iwa tutu gbogbo hàn si gbogbo eniyan.” (Titu 3:1, 2) Akẹkọọ Bibeli jinlẹ E. F. Scott kọwe nipa apá àyọkà ọ̀rọ̀ inu iwe yii: “Kìí ṣe pe awọn Kristian nilati ṣegbọran si awọn alaṣẹ nikan ni, ṣugbọn wọn gbọdọ muratan fun iṣẹ rere gbogbo. Eyi . . . tumọsi pe, nigba ti akoko bá beere fun un, awọn Kristian nilati wà laaarin awọn ti wọn mú ipo iwaju julọ ninu fífi ifọkansin fun anfaani gbogbo eniyan hàn. Lati ìgbà de ìgbà ni iṣẹlẹ iná, ajakalẹ arun, jamba oriṣiriṣi yoo maa ṣẹlẹ, nigba ti gbogbo awọn ọmọ orilẹ-ede rere yoo daniyan lati ṣeranwọ fun awọn aladuugbo wọn.” Jakejado ayé ọpọlọpọ apẹẹrẹ àjálù ti wà ti o ti ṣẹlẹ ti o sì jẹ́ pe awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa wà lara awọn ẹni akọkọ lati ṣe iṣẹ ipese iranlọwọ. Wọn ti ṣeranlọwọ fun kìí ṣe kiki awọn ará wọn nikan ṣugbọn awọn ti wọn wà lóde pẹlu.

11, 12. (a) Bawo ni o ṣe yẹ ki awọn Kristian huwa si awọn alaṣẹ? (b) Ki ni itẹriba fun awọn alaṣẹ ni ninu nigba ti o bá kan kíkọ́ awọn Gbọngan Ijọba?

11 Apá àyọkà ọ̀rọ̀ yii kan-naa lati inu lẹta Paulu si Titu tun pe afiyesi sí ijẹpataki mímú iwa ọ̀wọ̀ lò sipa awọn alaṣẹ. Awọn Kristian ọ̀dọ́ ti farahan niwaju awọn adajọ nitori iduro wọn lori ọ̀ràn aidasitọtuntosi wọn ni pataki nilati fi sọkan lati rìn pẹlu ọgbọ́n sipa awọn wọnni ti wọn wà lóde. Wọn lè ṣe pupọ lati buyì kún tabi lati ba orukọ rere awọn eniyan Jehofa jẹ́ nipa irisi wọn, ihuwa wọn, ati ọ̀nà ti wọn gbà sọrọ si iru awọn alaṣẹ bẹẹ. Wọn gbọdọ “san . . . ọlá fun ẹni ti ọlá í ṣe tirẹ̀,” ki wọn sì ṣe igbeja wọn pẹlu ọ̀wọ̀ ti o jinlẹ.—Romu 13:1-7; 1 Peteru 2:17; 3:15.

12 “Awọn alaṣẹ” ni ninu awọn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ. Nisinsinyi ti o jẹ́ pe pupọ pupọ awọn Gbọngan Ijọba ni a ń kọ́ sii, ibaṣepọ pẹlu awọn alaṣẹ ibilẹ ni a kò lè yẹ̀ silẹ. Awọn alagba sábà maa ń koju ẹ̀tanú. Ṣugbọn a ti ri i pe nibi ti awọn aṣoju fun ijọ bá ti gbé ibaṣepọ rere kalẹ pẹlu awọn alaṣẹ ti wọn sì fọwọsowọpọ pẹlu ajọ ti ń ṣeto ilu, ẹ̀tanú yii ni a lè wó palẹ̀. Ni ọpọ ìgbà ijẹrii daradara kan ni a ṣe fun awọn eniyan ti wọn kò mọ pupọ tabi ohunkohun nipa awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ati ihin-iṣẹ wọn.

‘Bi Ó Ba Ṣeeṣe, Ẹ Maa Wà Ní Alaafia Pẹlu Gbogbo Eniyan’

13, 14. Imọran wo ni Paulu fun awọn Kristian ni Romu, bawo ni awa sì ṣe lè fi i silo ninu ibatan wa pẹlu awọn ti wọn wà lóde?

13 Paulu fun awọn Kristian ti wọn ń gbé ni Romu ilẹ oloriṣa ni imọran ti o tẹlee yii: “Ẹ maṣe fi buburu san buburu fun ẹnikẹni. Ẹ maa pese ohun ti o tọ́ niwaju gbogbo eniyan. Bi o le ṣe, bi o ti wà ni ipa ti yin, ẹ maa wà ni alaafia pẹlu gbogbo eniyan. Olufẹ, ẹ maṣe gbẹ̀san araayin, ṣugbọn ẹ fi àyè silẹ fun ibinu; nitori a ti kọ ọ́ pe, Oluwa wi pe, temi ni ẹ̀san, emi ó gbẹ̀san. Ṣugbọn bi ebi bá ń pa ọ̀tá rẹ, fun un ni ounjẹ; bi oungbẹ bá ń gbẹ ẹ́, fun un ni omi mu: ni ṣiṣe bẹẹ iwọ ó kó ẹyìn iná lé e ni ori. Maṣe jẹ́ ki buburu ṣẹgun rẹ, ṣugbọn fi rere ṣẹgun buburu.”—Romu 12:17-21.

14 Ninu ibaṣepọ wa pẹlu awọn ti wọn wà lóde, awa gẹgẹ bi Kristian tootọ laiṣeeyẹ silẹ ń bá awọn alatako pade. Ninu apá àyọkà ọ̀rọ̀ ti o wà loke, Paulu fihàn pe ipa ọ̀nà ọgbọ́n ni lati sakun lati bori atako naa nipa awọn iṣe oninurere. Bi ẹyin iná gbigbona, awọn iṣe inurere wọnyi lè yọ́ ìṣọ̀tá naa ki o sì jere alatako naa sinu ihuwa ti o tubọ jẹ́ oninurere sipa awọn eniyan Jehofa, ó tilẹ lè ṣeeṣe ki o ru ọkàn-ìfẹ́ rẹ̀ ninu ihinrere naa soke. Nigba ti eyi bá ṣẹlẹ, ire ti bori ibi niyẹn.

15. Nigba wo ni awọn Kristian nilati ṣọra ni pataki lati rìn pẹlu ọgbọ́n sipa awọn wọnni ti wọn wà lóde?

15 Rírìn ninu ọgbọ́n sipa awọn ti wọn wà lòde ṣe pataki niti gidi ni awọn ile nibi ti ọ̀kan ninu awọn alájọṣègbéyàwó kò bá tẹwọgba otitọ. Fifi awọn ilana Bibeli silo ń pese ọkọ ti o dara ju, aya ti o dara ju, baba ti o dara ju, iya ti o dara ju, ati awọn ọmọ ti wọn jẹ́ onigbọran ju ti wọn sì ń kẹkọọ kárakára ni ile-ẹkọ. Alaigbagbọ kan gbọdọ lè rí ipa daradara ti awọn ilana Bibeli ní lori onigbagbọ kan. Nipa bayii, awọn diẹ ni a “le jere wọn ni aisọrọ nipa iwa” awọn mẹmba idile ti wọn ti ṣeyasimimọ.—1 Peteru 3:1, 2.

‘Ṣiṣoore fun Gbogbo Eniyan’

16, 17. (a) Iru awọn ẹbọ wo ni inu Ọlọrun dùn sí jọjọ? (b) Bawo ni a ṣe gbọdọ “ṣoore” fun awọn ará wa ati pẹlu fun awọn wọnni ti wọn wà lóde?

16 Rere giga julọ ti a lè ṣe fun aladuugbo wa ni lati mú ihin-iṣẹ iwalaaye wá sọdọ rẹ̀, ki a si kọ́ ọ nipa ìlàjà pẹlu Jehofa nipasẹ Jesu Kristi. (Romu 5:8-11) Nitori naa aposteli Paulu sọ fun wa pe: “Ǹjẹ́ nipasẹ rẹ̀ [Kristi], ẹ jẹ́ ki a maa rú ẹbọ iyin si Ọlọrun nigba gbogbo, eyiini ni eso ètè wa, ti ń jẹwọ orukọ rẹ̀.” (Heberu 13:15) Paulu fikun un pe: “Ṣugbọn ati maa ṣoore oun ati maa pinfunni ẹ maṣe gbàgbé: nitori iru ẹbọ wọnni ni inu Ọlọrun dùn si jọjọ.” (Heberu 13:16) Ní afikun si ijẹrii wa ni gbangba, a kò gbọdọ gbagbe ‘ṣiṣoore.’ Ó jẹ́ apa pataki awọn ẹbọ ti inu Ọlọrun dun si jọjọ.

17 Lọna ti ó bá iwa ẹ̀dá mu, a ń ṣoore fun awọn ará wa nipa tẹmi, awọn ti wọn lè wà ninu aini nipa ti ero-imọlara, nipa tẹmi, nipa ti ara, tabi nipa ti èrò ọpọlọ. Paulu tọka si eyi nigba ti o kọwe pe: “Ǹjẹ́ bi a ti ń ri akoko, ẹ jẹ́ ki a maa ṣoore fun gbogbo eniyan, ati paapaa fun awọn tíí ṣe ará ile igbagbọ.” (Galatia 6:10; Jakọbu 2:15, 16) Bi o ti wu ki o ri, a kò gbọdọ gbagbe awọn ọ̀rọ̀ naa pe, “Ẹ jẹ́ ki a maa ṣoore fun gbogbo eniyan.” Iṣe inurere si ẹbí, aladuugbo, tabi alajọṣiṣẹ kan lè ṣe pupọ lati mú ẹ̀tanú lodisi wa kuro kí ó sì ṣí ọkan-aya ẹni naa payá si otitọ.

18. (a) Awọn ewu wo ni a gbọdọ yẹra fun? (b) Bawo ni a ṣe lè lo iṣoore Kristian wa gẹgẹ bi itilẹhin kan fun iṣẹ ijẹrii wa fun gbogbo eniyan?

18 Lati ṣe eyi, a kò nilati ní ibadọrẹẹ timọtimọ pẹlu awọn wọnni ti wọn wà lóde. Iru awọn ibakẹgbẹpọ bẹẹ lè lewu. (1 Korinti 15:33) Kò sì sí ìdí lati jẹ́ ọ̀rẹ́ pẹlu ayé. (Jakọbu 4:4) Ṣugbọn iwarere Kristian wa lè fun iwaasu wa ni itilẹhin. Ní awọn ilẹ kan o tubọ ń ṣoro sii lati bá awọn eniyan sọrọ ni awọn ile wọn. Awọn ile gbigbe kan ni a ti daabobo pẹlu awọn ohun eelo ati ọ̀nà ìgbàṣe-nǹkan ti ń ṣediwọ fun wa lati bá awọn olugbe ibẹ sọrọ. Ni awọn orilẹ-ede ti wọn ti goke agba, ẹrọ tẹlifoonu pese ọ̀nà kan fun wiwaasu. Ní ọpọ awọn orilẹ-ede iwaasu opopona ni a lè ṣe. Sibẹ, ni gbogbo orilẹ-ede, jíjẹ́ ẹni bí-ọ̀rẹ́, ọlọ́wọ̀, oninurere, ati oluranlọwọ fun awọn ẹlomiran ń ṣí anfaani pupọ silẹ lati wó ẹ̀tanú palẹ̀ ki a sì funni ni ijẹrii daradara.

Pípa Awọn Alatako Lẹnu Mọ́

19. (a) Niwọn bi a kò ti nireti lati tẹ́ awọn eniyan lọ́rùn, ki ni a lè retí? (b) Bawo ni a ṣe nilati sakun lati tẹle apẹẹrẹ Danieli ki a sì fi imọran Peteru silo?

19 Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa kìí ṣe aláṣewù eniyan tabi olùbẹ̀rù eniyan. (Owe 29:25; Efesu 6:6) Wọn mọ̀ ni ẹkunrẹrẹ pe loju gbogbo isapa wọn lati jẹ́ olusan owó-ori ati ọmọ orilẹ-ede rere ti a ń wò gẹgẹ bi apẹẹrẹ, awọn alatako yoo tan irọ́ akoniniriira kálẹ̀ wọn yoo sì sọrọ alainilaari nipa wọn. (1 Peteru 3:16) Ní mímọ eyi, wọn gbiyanju lati ṣafarawe Danieli, ẹni ti awọn ọ̀tá rẹ̀ sọ nipa rẹ̀ pe: “Awa ki yoo lè rí ẹ̀fẹ́kẹ́fẹ̀ẹ́ kan si Danieli bikoṣe pe a ba rí i sí i nipasẹ ofin Ọlọrun rẹ̀.” (Danieli 6:6) Awa kì yoo fi awọn ilana Bibeli bánidọ́rẹ̀ẹ́ lae lati tẹ́ eniyan lọ́rùn. Ní ọwọ́ keji ẹ̀wẹ̀, awa kò wá iku ajẹ́rìíkú. A ń gbiyanju lati gbé ni alaafia ki a sì ṣegbọran si imọran aposteli naa: “Bẹẹ ṣáà ni ifẹ Ọlọrun, pe ni rere í ṣe, ki ẹ lè dá òpè awọn wèrè eniyan lẹ́kun.”—1 Peteru 2:15.

20. (a) Ki ni a ni idaniloju nipa rẹ̀, iṣiri wo sì ni Jesu fun wa? (b) Bawo ni a ṣe lè maa baa lọ ni rírìn pẹlu ọgbọ́n sipa awọn wọnni ti wọn wà lóde?

20 Ó dá wa loju pe ipo ìyara-ẹni sọtọ kuro ninu ayé wa wà ni iṣọkan lẹkun-un-rẹrẹ pẹlu Bibeli. Ohun ni a ṣetilẹhin fun nipasẹ ìtàn awọn Kristian ọgọrun-un ọdun kìn-ín-ní. Awọn ọ̀rọ̀ Jesu mú wa lọ́kàn le pe: “Ninu ayé, ẹyin o ní ipọnju; ṣugbọn ẹ tujuka; mo ti ṣẹgun ayé.” (Johannu 16:33) Awa kò bẹru. “Ta ni yoo sì ṣe yin ni ibi, bi ẹyin bá jẹ́ onitara si ohun rere? Ṣugbọn bi ẹyin bá jìyà nitori òdodo, alaafia ni: ẹ maṣe bẹru wọn, ki ẹ má sì ṣe kọminu; Ṣugbọn ẹ bọwọ fun Kristi Oluwa lọ́kàn yin: ki ẹ si mura tan nigba gbogbo lati dá olukuluku lóhùn ti ń beere ireti ti o ń bẹ ninu yin, ṣugbọn pẹlu ọkàn tútù ati ibẹru.” (1 Peteru 3:13-15) Bi a ti ń huwa ni ọ̀nà yii, awa yoo maa baa lọ ni rírìn pẹlu ọgbọ́n sipa ti awọn wọnni ti wọn wà lóde.

Ni Ọ̀nà Atunyẹwo

◻ Eeṣe ti awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa fi nilati rìn pẹlu ọgbọ́n sipa ti awọn wọnni ti wọn wà lóde?

◻ Eeṣe ti awọn Kristian tootọ kò fi gbọdọ reti lae pe ki ayé nifẹẹ wọn, ṣugbọn ki ni wọn gbọdọ gbiyanju lati ṣe?

◻ Ki ni o nilati jẹ iṣarasihuwa wa sipa awọn eniyan ayé, eesitiṣe?

◻ Eeṣe ti a fi gbọdọ “ṣoore” kìí ṣe fun awọn ará wa nikan ṣugbọn fun awọn wọnni ti wọn wà lóde pẹlu?

◻ Bawo ni rírìn wa pẹlu ọgbọ́n sipa awọn wọnni ti wọn wà lóde ṣe lè ràn wá lọwọ ninu iṣẹ wiwaasu wa fun gbogbo eniyan?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]

Ní apa òsì: Awọn Kristian tootọ ni France ti wọn ń ṣeranlọwọ fun awọn aladuugbo wọn lẹhin omíyalé kan

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]

Awọn iṣe inurere Kristian lè ṣe pupọ lati wó ẹ̀tanú palẹ̀

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Awọn Kristian gbọdọ “muratan fun iṣẹ rere gbogbo”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́