ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w97 11/1 ojú ìwé 8-13
  • Àwọn Kristẹni àti Ayé Aráyé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Kristẹni àti Ayé Aráyé
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àpẹẹrẹ Jésù
  • Ìṣarasíhùwà Pọ́ọ̀lù sí Àwọn Ènìyàn “Tí Ń Bẹ ní Òde”
  • Ríran Àwọn Ònígbàgbọ́ Tí Kì Í Ṣe Júù Lọ́wọ́
  • Wíwàásù Láàárín “Àwọn Aláìgbàgbọ́”
  • Gbígbìyánjú Láti Gba “Gbogbo Onírúurú Ènìyàn” Là Lónìí
  • Bí Àṣà Ilẹ̀ Gíríìsì Ṣe Nípa Lórí Àwọn Tó Bẹ̀rẹ̀ Ẹ̀sìn Kristẹni
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Ìtumọ̀ Bíbélì Tí Ó Yí Ayé Padà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù Kó O Lè Tẹ̀ Síwájú Nínú Òtítọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Ojú Wo Lo Fi Ń Wo Àwọn Tó Wà ní Ìpínlẹ̀ Ìwàásù Rẹ?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2020
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
w97 11/1 ojú ìwé 8-13

Àwọn Kristẹni àti Ayé Aráyé

“Ẹ máa bá a lọ ní rírìn nínú ọgbọ́n sí àwọn wọnnì tí ń bẹ ní òde.”—KÓLÓSÈ 4:5.

1. Kí ni Jésù sọ nípa àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ àti ayé?

NÍNÚ àdúrà tí ó gbà sí Bàbá rẹ̀ ọ̀run, Jésù sọ nípa àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ayé ti kórìíra wọn, nítorí pé wọn kì í ṣe apá kan ayé, gan-an gẹ́gẹ́ bí èmi kì í ti í ṣe apá kan ayé.” Lẹ́yìn náà, ó fi kún un pé: “Mo fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ béèrè lọ́wọ́ rẹ, kì í ṣe láti mú wọn kúrò ní ayé, bí kò ṣe láti máa ṣọ́ wọn nítorí ẹni burúkú náà.” (Jòhánù 17:14, 15) Yíya àwọn Kristẹni sọ́tọ̀ kúrò nínú ayé kì í ṣe nípa ti ara—fún àpẹẹrẹ, nípa gbígbé ní àdádó nínú ilé àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ ànìkàngbé. Kàkà bẹ́ẹ̀, Kristi “rán wọn jáde sínú ayé” láti jẹ́ ẹlẹ́rìí rẹ̀ “títí dé apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé.” (Jòhánù 17:18; Ìṣe 1:8) Síbẹ̀, ó ní kí Ọlọ́run máa ṣọ́ wọn nítorí pé Sátánì, “olùṣàkóso ayé yìí,” yóò gbé ìkórìíra dìde sí wọn nítorí orúkọ Kristi.—Jòhánù 12:31; Mátíù 24:9.

2. (a) Báwo ni Bíbélì ṣe lo ọ̀rọ̀ náà, “ayé”? (b) Ìṣarasíhùwà wíwà déédéé wo ni Jèhófà ń fi hàn sí ayé?

2 Nínú Bíbélì, ọ̀rọ̀ náà, “ayé” (koʹsmos, Gíríìkì), sábà máa ń tọ́ka sí àwùjọ ènìyàn aláìṣòdodo, tí ó “wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.” (Jòhánù Kíní 5:19) Nítorí pé àwọn Kristẹni ń tẹ̀ lé ọ̀pá ìdiwọ̀n Jèhófà, tí wọ̀n sì ń kọbi ara sí àṣẹ náà láti wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fún ayé gbọ́, nígbà míràn, ipò ìbátan tí kò fara rọ máa ń wà láàárín àwọn àti ayé. (Tímótì Kejì 3:12; Jòhánù Kíní 3:1, 13) Ṣùgbọ́n, a tún lo koʹsmos nínú Ìwé Mímọ́ láti tọ́ka sí ìdílé ẹ̀dá ènìyàn lápapọ̀. Ní sísọ̀rọ̀ nípa ayé pẹ̀lú ìtumọ̀ yí lọ́kàn, Jésù wí pé: “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọkùnrin bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má baà parun ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun. Nítorí Ọlọ́run rán Ọmọkùnrin rẹ̀ jáde sí ayé, kì í ṣe kí ó lè ṣèdájọ́ ayé, bí kò ṣe kí a lè gba ayé là nípasẹ̀ rẹ̀.” (Jòhánù 3:16, 17; Kọ́ríńtì Kejì 5:19; Jòhánù Kíní 4:14) Nítorí náà, bí Jèhófà tilẹ̀ kórìíra àwọn ohun tí ń fi ètò ìgbékalẹ̀ Sátánì hàn yàtọ̀, ó fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn sí aráyé nípa rírán Ọmọkùnrin rẹ̀ wá sí ilẹ̀ ayé láti lè gba gbogbo ènìyàn tí ó bá “wá sí ìrònúpìwàdà” là. (Pétérù Kejì 3:9; Òwe 6:16-19) Ìṣarasíhùwà wíwà déédéé tí Jèhófà ní sí ayé ni ó yẹ kí ó máa darí àwọn olùjọsìn rẹ̀.

Àpẹẹrẹ Jésù

3, 4. (a) Ipò wo ni Jésù dì mú ní ti ọ̀ràn ìṣàkóso? (b) Ojú wo ni Jésù fi wo ayé aráyé?

3 Kété ṣáájú ikú rẹ̀, Jésù sọ fún Pọ́ńtíù Pílátù pé: “Ìjọba mi kì í ṣe apá kan ayé yìí.” (Jòhánù 18:36) Ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ṣáájú àkókò náà, Jésù ti kọ̀ láti gba ọlá àṣẹ tí Sátánì fi lọ̀ ọ́ pé kí ó ṣàkóso lórí àwọn ìjọba ayé, ó sì ti kọ̀ kí àwọn Júù fi òun jẹ ọba. (Lúùkù 4:5-8; Jòhánù 6:14, 15) Síbẹ̀, Jésù fi ìfẹ́ ńláǹlà hàn sí ayé aráyé. Àpọ́sítélì Mátíù ròyìn irú àpẹẹrẹ èyí pé: “Nígbà tí ó rí àwọn ogunlọ́gọ̀ àánú wọ́n ṣe é, nítorí a bó wọn láwọ a sì fọ́n wọn ká bí àwọn àgùntàn tí kò ní olùṣọ́ àgùntàn.” Nítorí ìfẹ́ tí ó ní sí wọn, ó wàásù fún àwọn ènìyàn nínú ìlú àti ìletò wọn. Ó kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́, ó sì wo àìsan wọn sàn. (Mátíù 9:36) Ó tún tètè kíyè sí àìní ti ara tí àwọn tí wọ́n wá kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ rẹ̀ ní. A kà pé: “Jésù pe àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀ ó sì wí pé: ‘Àánú ogunlọ́gọ̀ náà ń ṣe mí, nítorí pé ó ti di ọjọ́ mẹ́ta nísinsìnyí tí wọ́n ti wà pẹ̀lú mi wọn kò sì ní nǹkan kan láti jẹ; èmi kò sì fẹ́ rán wọn lọ ní gbígbààwẹ̀. Ó ṣeé ṣe kí okun wọ́n tán ní ojú ọ̀nà.’” (Mátíù 15:32) Ẹ wo irú àníyàn onífẹ̀ẹ́ tí ìyẹn jẹ́!

4 Àwọn Júù ní ẹ̀tanú lílágbára sí àwọn ará Samáríà, ṣùgbọ́n Jésù bá obìnrin ará Samáríà kan sọ ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀, ó sì fi ọjọ́ méjì jẹ́rìí kúnnákúnná ní ìlú kan ní Samáríà. (Jòhánù 4:5-42) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé “àwọn àgùntàn ilé Ísírẹ́lì tí wọ́n sọ nù” ni Ọlọ́run rán an sí, ní àwọn àkókò kan, Jésù dáhùn pa dà sí ìgbàgbọ́ tí àwọn tí kì í ṣe Júù fi hàn. (Mátíù 8:5-13; 15:21-28) Bẹ́ẹ̀ ni, Jésù fi hàn pé ó ṣeé ṣe kí a máà jẹ́ “apá kan ayé,” síbẹ̀, kí a fi ìfẹ́ hàn sí ayé aráyé, sí àwọn ènìyàn. Àwa ha ń fi ìyọ́nú hàn sí àwọn ènìyàn níbi tí a ń gbé, níbi iṣẹ́ wa, tàbí níbi tí a ti ń ra nǹkan bí? A ha ń dàníyàn nípa ire wọn—kì í ṣe fún àìní wọn nípa tẹ̀mí nìkan, ṣùgbọ́n fún àwọn àìní wọn mìíràn pẹ̀lú, bí a bá ní agbára láti ṣèrànwọ́? Jésù ṣe bẹ́ẹ̀, nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀ rẹ̀, ó ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún kíkọ́ àwọn ènìyàn nípa Ìjọba náà. Lóòótọ́, a kò lè ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu nípa ti ara bí Jésù ti ṣe. Ṣùgbọ́n, ní ti gidi, ìwà onínúure sábà máa ń ṣiṣẹ́ ìyanu ní wíwó ẹ̀tanú palẹ̀.

Ìṣarasíhùwà Pọ́ọ̀lù sí Àwọn Ènìyàn “Tí Ń Bẹ ní Òde”

5, 6. Báwo ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe bá àwọn Júù tí wọ́n wà “ní òde” lò?

5 Nínú lẹ́tà rẹ̀ mélòó kan, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tọ́ka sí àwọn ènìyàn tí ń bẹ “ní òde,” ìyẹn ni àwọn tí kì í ṣe Kristẹni, yálà wọ́n jẹ́ Júù tàbí Kèfèrí. (Kọ́ríńtì Kíní 5:12; Tẹsalóníkà Kíní 4:12; Tímótì Kíní 3:7) Báwo ni ó ṣe bá irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lò? Ó ‘di ohun gbogbo fún ènìyàn gbogbo, kí ó lè gba àwọn kan là lọ́nàkọnà.’ (Kọ́ríńtì Kíní 9:20-22) Nígbà tí ó dé ìlú kan, ọ̀nà tí ó gbà wàásù ni láti kọ́kọ́ tọ àwọn Júù tí wọ́n ń gbé ibẹ̀ lọ. Ọ̀nà wo ni ó gbà bá wọn sọ̀rọ̀? Ní lílo ọgbọ́n àti ọ̀wọ̀, ó pèsè àwọn ẹ̀rí tí kò ṣeé já ní koro láti inú Bíbélì pé, Mèsáyà náà ti wá, ó ti kú ikú ìrúbọ, a sì ti jí i dìde.—Ìṣe 13:5, 14-16, 43; 17:1-3, 10.

6 Lọ́nà yí, Pọ́ọ̀lù lo ìmọ̀ tí àwọn Júù ní nípa Òfin àti àwọn wòlíì láti kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ nípa Mèsáyà náà àti Ìjọba Ọlọ́run. Ó sì kẹ́sẹ járí nínú yíyí àwọn kan lérò pa dà. (Ìṣe 14:1; 17:4) Láìka àtakò tí àwọn aṣáájú Júù ṣe sí, Pọ́ọ̀lù fi ìfẹ́ hàn sí àwọn Júù ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ nígbà tí ó kọ̀wé pé: “Ẹ̀yin ará, ìfẹ́ rere ọkàn àyà mi àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ mi sí Ọlọ́run fún wọn [àwọn Júù], ní tòótọ́, jẹ́ fún ìgbàlà wọn. Nítorí mo jẹ́rìí wọn pé wọ́n ní ìtara fún Ọlọ́run; ṣùgbọ́n kì í ṣe ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀ pípéye.”—Róòmù 10:1, 2.

Ríran Àwọn Ònígbàgbọ́ Tí Kì Í Ṣe Júù Lọ́wọ́

7. Báwo ni ọ̀pọ̀ àwọn aláwọ̀ṣe ṣe dáhùn pa dà sí ìhìn rere tí Pọ́ọ̀lù wàásù?

7 Àwọn tí kì í ṣe Júù, tí a kọ nílà, tí wọ́n sì ti di ẹlẹ́sìn Júù, ni a ń pè ní aláwọ̀ṣe. Ó hàn gbangba pé àwọn aláwọ̀ṣe Júù ń bẹ ní Róòmù, Áńtíókù ti Síríà, Etiópíà, àti Áńtíókù ti Písídíà—àní jákèjádò Ibùdó Àwọn Júù ti Ẹ̀yin Ilẹ̀ Palẹ́sìnì pàápàá. (Ìṣe 2:8-10; 6:5; 8:27; 13:14, 43; fi wé Mátíù 23:15.) Láìdà bí ọ̀pọ̀ olùṣàkóso Júù, ó lè jẹ́ pé àwọn aláwọ̀ṣe kì í ṣe onírera, wọn kò sì lè ṣe fọ́ńté pé àwọn jẹ́ àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù. (Mátíù 3:9; Jòhánù 8:33) Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n ti pa àwọn òrìṣà tì, wọ́n sì ti fi ìrẹ̀lẹ̀ yíjú sí Jèhófà, ní jíjèrè ìmọ̀ díẹ̀ nípa òun àti àwọn òfin rẹ̀. Wọ́n sì ní ìrètí tí àwọn Júù ní nípa bíbọ̀ Mèsáyà. Níwọ̀n bí wọ́n ti fi hàn tẹ́lẹ̀ pé bí àwọn ti ń wá òtítọ́ kiri, àwọn lè yí pa dà, ọ̀pọ̀ lára wọn ti ṣe tán láti túbọ̀ yí pa dà, kí wọ́n sì dáhùn pa dà sí ìwàásù àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. (Ìṣe 13:42, 43) Nígbà tí aláwọ̀ṣe kan tí ó ń jọ́sìn àwọn òrìṣà tẹ́lẹ̀ bá di Kristẹni, ó ti gbára dì lọ́nà àrà ọ̀tọ̀ kan láti jẹ́rìí fún àwọn Kèfèrí yòó kù tí wọ́n ṣì ń jọ́sìn àwọn òrìṣà wọnnì.

8, 9. (a) Yàtọ̀ sí àwọn aláwọ̀ṣe, ẹgbẹ́ mìíràn wo nínú àwọn Kèfèrí ni ẹ̀sìn Júù fà mọ́ra? (b) Báwo ni ọ̀pọ̀ àwọn aláìkọlà olùbẹ̀rù Ọlọ́run ṣe dáhùn pa dà sí ìhìn rere?

8 Yàtọ̀ sí àwọn aláwọ̀ṣe tí a kọ nílà, ẹ̀sìn Júù fa àwọn mìíràn tí kì í ṣe Júù mọ́ra. Ọ̀kan lára àwọn wọ̀nyí tí ó kọ́kọ́ di Kristẹni ni Kọ̀nílíù, bí òun kì í tilẹ̀ ṣe aláwọ̀ṣe, ó jẹ́ “olùfọkànsìn ènìyàn àti ẹnì kan tí ń bẹ̀rù Ọlọ́run.” (Ìṣe 10:2) Nínú àlàyé rẹ̀ lórí ìwe Ìṣe, Ọ̀jọ̀gbọ́n F. F. Bruce kọ̀wé pé: “A sábà máa ń pé irú àwọn Kèfèrí bẹ́ẹ̀ ní ‘olùbẹ̀rù Ọlọ́run’; bí èyí kì í tilẹ̀ ṣe orúkọ tí a pilẹ̀ fún wọn, ó jẹ́ ọ̀kan tí ó bójú mu láti lò. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kò ṣe tán láti di ẹlẹ́sìn Júù pátápátá (dídi ẹni tí a kọ nílà jẹ́ òkúta ìkọ̀sẹ̀ ní ti gidi fún àwọn ọkùnrin), ọ̀nà ìjọsìn rírọrùn, ti jíjọ́sìn tí àwọn Júù ń jọ́sìn Ọlọ́run kan ṣoṣo nínú sínágọ́gù àti ti ìgbésí ayé tí ó ní ọ̀pá ìdiwọ̀n gíga tí àwọn Júù ń gbé, fa ọ̀pọ̀ àwọn Kèfèrí ìgbà náà mọ́ra. Díẹ̀ lára wọn máa ń lọ sí sínágọ́gù, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ mọ àdúrà àti ẹ̀kọ́ Ìwé Mímọ́, tí wọ́n ń gbọ́ kíkà rẹ̀ ní èdè Gíríìkì.”

9 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù bá ọ̀pọ̀ àwọn olùbẹ̀rù Ọlọ́run pàdé nígbà tí ó ń wàásù nínú sínágọ́gù ní Éṣíà Kékeré àti Gíríìsì. Ní Áńtíókù ti Písídíà, ó pe àwọn tí ó wà nínú sínágọ́gù ní “ẹ̀yin ènìyàn, ẹ̀yin ọmọ Ísírẹ́lì àti ẹ̀yin yòó kù tí ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run.” (Ìṣe 13:16, 26) Lúùkù kọ̀wé pé lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù wàásù nínú sínágọ́gù ní Tẹsalóníkà fún Sábáàtì mẹ́ta, “àwọn kan lára wọ́n [àwọn Júù] di onígbàgbọ́ [Kristẹni] wọ́n sì da ara wọn pọ̀ mọ́ Pọ́ọ̀lù àti Sílà, àti ògìdìgbó ńlá àwọn Gíríìkì tí ń jọ́sìn Ọlọ́run, kì í sì í ṣe ìwọ̀nba díẹ̀ lára àwọn sàràkí sàràkí obìnrin ni wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀.” (Ìṣe 17:4) Ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé, àwọn kan lára àwọn Gíríìkì náà jẹ́ àwọn aláìkọlà olùbẹ̀rù Ọlọ́run. Ẹ̀rí wà pé, ọ̀pọ̀ lára irú àwọn Kèfèrí bẹ́ẹ̀ dara pọ̀ mọ́ àwùjọ Júù.

Wíwàásù Láàárín “Àwọn Aláìgbàgbọ́”

10. Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe wàásù fún àwọn Kèfèrí tí wọn kò ní ìmọ̀ Ìwé Mímọ́ kankan tẹ́lẹ̀, kí sì ni ó yọrí sí?

10 Nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì, ọ̀rọ̀ náà, “aláìgbàgbọ́,” lè tọ́ka sí àpapọ̀ àwọn ènìyàn tí wọ́n wà lóde ìjọ Kristẹni. Ó sábà máa ń tọ́ka sí àwọn abọ̀rìṣà. (Róòmù 15:31; Kọ́ríńtì Kíní 14:22, 23; Kọ́ríńtì Kejì 4:4; 6:14) Ní Áténì, ọ̀pọ̀ àwọn aláìgbàgbọ́ kẹ́kọ̀ọ́ nípa ọgbọ́n èrò orí Gíríìkì, tí wọn kò sì mọ ohunkóhun nípa Ìwé Mímọ́ rárá. Èyí ha kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá Pọ́ọ̀lù láti jẹ́rìí fún wọn bí? Rárá o. Ṣùgbọ́n, ó mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ bá ipò wọn mu. Ó fi òye gbé àwọn èrò inú Bíbélì kalẹ̀ láìfa ọ̀rọ̀ yọ ní tààràtà láti inú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù, tí àwọn ará Áténì kò mọ̀. Ó fi làákàyè fi ìjọra tí ó wà láàárín òtítọ́ Bíbélì àti àwọn èrò kan tí àwọn akéwì Sítọ́íkì ìgbàanì ní hàn. Ó sì gbé èròǹgbà Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo ní ń bẹ fún gbogbo aráyé kalẹ̀, Ọlọ́run kan tí yóò ṣèdájọ́ ní òdodo nípasẹ̀ ọkùnrin kan tí ó kú, tí a sì jí dìde. Nípa báyìí, Pọ́ọ̀lù fi ọgbọ́n wàásù nípa Kristi fún àwọn ará Áténì. Kí ni ó yọrí sí? Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ jù lọ fi í ṣe ẹlẹ́yà tàbí ṣiyè méjì nípa ọ̀rọ̀ rẹ̀, “àwọn ènìyàn kan da ara wọn pọ̀ mọ́ ọn wọ́n sì di onígbàgbọ́, lára wọn pẹ̀lú ni Díónísíù, adájọ́ kan ní kóòtù Áréópágù, àti obìnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Dámárì, àti àwọn mìíràn ní àfikún sí wọn.”—Ìṣe 17:18, 21-34.

11. Irú ìlú wo ni Kọ́ríńtì jẹ́, kí sì ni ìgbòkègbodò ìwàásù Pọ́ọ̀lù níbẹ̀ yọrí sí?

11 Àwùjọ Júù tí ó pọ̀ díẹ̀ ń gbé ní Kọ́ríńtì, nítorí náà, Pọ́ọ̀lù bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ níbẹ̀ nípa wíwàásù nínú sínágọ́gù. Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn Júù wá di alátakò, Pọ́ọ̀lù lọ sí àwùjọ àwọn Kèfèrí. (Ìṣe 18:1-6) Ẹ sì wo irú àwùjọ ńlá ti wọ́n jẹ́! Kọ́ríńtì jẹ́ ìlú kan tí ó kún fún rọ̀tìrọ̀tì, ìlú gbogbo ayé, ìlú ìṣòwò, tí ó lókìkí jákèjádò ayé Gíríìkì òun Róòmù nítorí ìwà pálapàla rẹ̀. Ní tòótọ́, “láti hùwà bí àwọn ará Kọ́ríńtì” túmọ̀ sí láti hùwà pálapàla. Síbẹ̀, lẹ́yìn tí àwọn Júù kọ ìwàásù Pọ́ọ̀lù ni Kristi fara hàn án, tí ó sì wí fún un pé: “Má bẹ̀rù, ṣùgbọ́n máa bá a nìṣó ní sísọ̀rọ̀ . . . , nítorí tí mo ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ní ìlú ńlá yìí.” (Ìṣe 18:9, 10) Gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti wí, Pọ́ọ̀lù dá ìjọ kan sílẹ̀ ní Kọ́ríńtì, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan lára àwọn mẹ́ńbà rẹ̀ ti gbé ìgbésí ayé “àwọn ará Kọ́ríńtì” rí.—Kọ́ríńtì Kíní 6:9-11.

Gbígbìyánjú Láti Gba “Gbogbo Onírúurú Ènìyàn” Là Lónìí

12, 13. (a) Báwo ni ìpínlẹ̀ wa lónìí ṣe bá ti ọjọ́ Pọ́ọ̀lù mu? (b) Ẹ̀mí wo ni a ń fi hàn ní àwọn ìpínlẹ̀ tí àwọn ẹ̀sìn Kirisẹ́ńdọ̀mù ti fìdí múlẹ̀ tipẹ́tipẹ́ tàbí tí ètò ìsìn ti sú ọ̀pọ̀lọpọ̀?

12 Lónìí, gẹ́gẹ́ bí ó ti rí ní ọ̀rúndún kìíní, “inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run . . . ń mú ìgbàlà wá fún gbogbo onírúurú ènìyàn.” (Títù 2:11) Ìpínlẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere náà ti gbòòrò dé gbogbo àgbáálá ilẹ̀ àti ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn erékùṣù òkun. Gẹ́gẹ́ bí ó sì ti rí ní ọjọ́ Pọ́ọ̀lù, “gbogbo onírúurú ènìyàn” ni a ń bá pàdé ní tòótọ́. Fún àpẹẹrẹ, àwọn kan lára wa ń wàásù ní àwọn ilẹ̀ tí ṣọ́ọ̀ṣì Kirisẹ́ńdọ̀mù ti fìdí múlẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún. Bíi ti àwọn Júù ọ̀rúndún kìíní, ó lè jẹ́ pé àwọn òfin àtọwọ́dọ́wọ́ ìsìn ti de àwọn mẹ́ńbà wọn mọ́lẹ̀ pinpin. Síbẹ̀, a ń láyọ̀ láti wá àwọn tí wọ́n ní ọkàn àyà rere jáde, kí a sì lo ìmọ̀ èyíkéyìí tí wọ́n ti ní láti inú Bíbélì. A kì í ṣáátá wọn, bẹ́ẹ̀ sì ni a kì í fojú tẹ́ńbẹ́lù wọn, àní bí àwọn aṣáájú ìsìn wọn pàápàá tilẹ̀ ta kò wá, tí wọ́n sì ṣenúnibíni sí wa nígbà míràn. Kàkà bẹ́ẹ̀, a mọ̀ pé àwọn kan lára wọn ní “ìtara fún Ọlọ́run,” bí wọn kò tilẹ̀ ní ìmọ̀ pípéye. Gẹ́gẹ́ bíi Jésù àti Pọ́ọ̀lù, a ń fi ojúlówó ìfẹ́ hàn sí àwọn ènìyàn, ó jẹ́ ìfẹ́ ọkàn wa gidigidi pé kí wọ́n rí ìgbàlà.—Róòmù 10:2.

13 Bí a ti ń wàásù, ọ̀pọ̀ nínú wa máa ń bá àwọn ènìyàn tí ètò ìsìn ti sú pàdé. Ṣùgbọ́n, wọ́n ṣì lè jẹ́ olùbẹ̀rù Ọlọ́run, tí ó nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run dé àyè kan, tí ó sì ń gbìyànjú láti gbé ìgbésí ayé oníwà rere. Nínú ìran oníwà wíwọ́ yìí, tí àìgbọlọ́rungbọ́ ń pọ̀ sí i, kò ha yẹ kí inú wa dùn láti bá àwọn ènìyàn tí wọ́n ní ìgbàgbọ́ díẹ̀ nínú Ọlọ́run pàdé bí? A kò ha sì ń hára gàgà láti darí wọn sí irú ìjọsìn kan tí kò ní àgàbàgebè àti èké nínú bí?—Fílípì 2:15.

14, 15. Báwo ni pápá gbígbòòrò ṣe wá wà fún wíwàásù ìhìn rere náà?

14 Nínú àkàwé rẹ̀ nípa àwọ̀n, Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé ìpínlẹ̀ ńlá yóò wà fún iṣẹ́ ìwàásù náà. (Mátíù 13:47-49) Ní ṣíṣàlàyé àkàwé yìí, Ilé-Ìṣọ́nà June 15, 1992, sọ ní ojú ìwé 20 pé: “La ọpọ ọrundun ja awọn mẹmba Kristendom kó ipa pataki ninu titumọ, ṣíṣẹ̀dà, ati pípín Ọrọ Ọlọrun kiri. Awọn ṣọọṣi lẹhin naa dá ẹgbẹ [atúmọ̀] Bibeli, eyi ti ó tumọ Bibeli si èdè awọn ilẹ jijinna réré silẹ tabi ṣetilẹhin fun un. Wọn tun rán awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun oniṣegun ati olukọ jade, awọn ti wọn sọ awọn eniyan di Kristian onírẹsì. Eyi kó ọpọ jaburata awọn ẹja ti kò yẹ jọ, awọn ti kò ni itẹwọgba Ọlọrun. Ṣugbọn ó keretan ó sọ araadọta-ọkẹ awọn ti wọn ki i ṣe Kristian di ojulumọ Bibeli ati si oriṣi isin Kristian kan, bi o tilẹ jẹ pe o dibajẹ.”

15 Ìsọnidaláwọ̀ṣe nípasẹ̀ Kirisẹ́ńdọ̀mù ti gbéṣẹ́ ní pàtàkì ní Gúúsù Amẹ́ríkà, Áfíríkà, àti àwọn erékùṣù òkun kan. Ní ọjọ́ wa, a ti wá ọ̀pọ̀ ọlọ́kàn tútù rí ní àwọn àgbègbè wọ̀nyí, a sì lè túbọ̀ ṣe wọ́n láǹfààní bí a bá ní ẹ̀mí nǹkan-yóò-dára, tí a ń fi ìfẹ́ hàn sí irú àwọn onírẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀, àní bí Pọ́ọ̀lù ti ṣe sí àwọn aláwọ̀ṣe Júù. Lára àwọn tí wọ́n tún nílò ìrànwọ́ wa ni àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ènìyàn tí a lè pè ní “àwọn atẹ́wọ́gba ojú ìwòye” Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Inú wọn máa ń dùn ní gbogbo ìgbà tí a bá bẹ̀ wọ́n wò. Àwọn kan lára wọn ti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú wa, wọ́n ti wá sí àwọn ìpàdé wa, ní pàtàkì Ìṣe Ìrántí ikú Kristi tí a ń ṣe ní ọdọọdún. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ kò ha dúró fún pápá ńlá fún wíwàásù ìhìn rere Ìjọba náà bí?

16, 17. (a) Irú àwọn ènìyàn wo ni a ń mú ìhìn rere náà tọ̀ lọ? (b) Báwo ni a ṣe ń fara wé Pọ́ọ̀lù nínú wíwàásù fún onírúurú ènìyàn?

16 Ní àfikún sí i, àwọn tí wọ́n wá láti inú ẹ̀sìn tí kì í ṣe ti Kirisẹ́ńdọ̀mù ńkọ́—yálà a bá wọn pàdé ní ìlú wọn tàbí tí wọ́n ṣí wá sí àwọn ilẹ̀ Ìwọ̀ Oòrùn? Àwọn àràádọ́ta ọ̀kẹ́ wọnnì tí wọ́n ti kẹ̀yìn sí ìsìn pátápátá, tí wọ́n ti di aláìgbọlọ́rungbọ́ tàbí onígbàgbọ́ Ọlọ́run-kò-ṣeé-mọ̀ ńkọ́? Síwájú sí i, àwọn tí ń fi ìháragàgà tẹ́wọ́ gba ọgbọ́n èrò orí òde òní tàbí ìrònú òun ìhùwà lílókìkí tí a ń tẹ̀ jáde nínú ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ìwé tí ń pèsè ìmọ̀ràn bí-a-tií-ṣe-é, tí a ń rí ní àwọn ilé ìtàwé ńkọ́? Ó ha yẹ kí a pa èyíkéyìí nínú irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ tì, kí a kà wọ́n sí ẹni tí kò ṣeé rà pa dà mọ́? A kò ní ṣe bẹ́ẹ̀ bí a bá fara wé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù.

17 Nígbà tí ó wàásù ní Áténì, Pọ́ọ̀lù kò kó sínú ọ̀fìn bíbá àwọn olùgbọ́ rẹ̀ jiyàn lórí ọgbọ́n èrò orí. Ṣùgbọ́n, ó mú ìrònú rẹ̀ bá ti àwọn tí ó ń bá sọ̀rọ̀ mú, ní gbígbé òtítọ́ Bíbélì kalẹ̀ lọ́nà tí ó ṣe kedere, tí ó sì bọ́gbọ́n mu. Lọ́nà kan náà, kò dìgbà tí a bá di ògbógi nínú ìsìn tàbí ọgbọ́n èrò orí àwọn tí a ń wàásù fún kí a tó lè bá wọn jíròrò. Ṣùgbọ́n, a máa ń mú ọ̀rọ̀ wa bá ipò wọn mu láti lè mú kí ìjẹ́rìí wa gbéṣẹ́, a sì ń tipa báyìí di “ohun gbogbo fún ènìyàn gbogbo.” (Kọ́ríńtì Kíní 9:22) Nígbà tí ó ń kọ̀wé sí àwọn Kristẹni tí ó wà ní Kólósè, Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹ máa bá a lọ ní rírìn nínú ọgbọ́n sí àwọn wọnnì tí ń bẹ ní òde, kí ẹ máa ra àkókò tí ó rọgbọ pa dà fún ara yín. Nígbà gbogbo ẹ jẹ́ kí gbólóhùn àsọjáde yín máa jẹ́ pẹ̀lú oore ọ̀fẹ́, tí a fi iyọ̀ dùn, kí ẹ lè mọ bí ó ti yẹ kí ẹ fi ìdáhùn fún ẹni kọ̀ọ̀kan.”—Kólósè 4:5, 6.

18. Ẹrù iṣẹ́ wo ni a ní, kí sì ni kò yẹ kí a gbàgbé láé?

18 Bíi Jésù àti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, ẹ jẹ́ kí a fi ìfẹ́ hàn sí onírúurú ènìyàn gbogbo. Ní pàtàkì, ẹ jẹ́ kí a tiraka láti ṣàjọpín ìhìn rere Ìjọba náà pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, kí a má ṣe gbàgbé láé pé Jésù sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Wọn kì í ṣe apá kan ayé.” (Jòhánù 17:16) A óò túbọ̀ gbé ohun tí èyí túmọ̀ sí fún wa yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tí ó tẹ̀ lé e.

Lọ́nà Àtúnyẹ̀wò

◻ Ṣàpèjúwe ìṣarasíhùwà wíwà déédéé tí Jésù ní sí ayé.

◻ Báwo ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe wàásù fún àwọn Júù àti aláwọ̀ṣe?

◻ Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe bá àwọn olùbẹ̀rù Ọlọ́run àti àwọn aláìgbàgbọ́ sọ̀rọ̀?

◻ Báwo ni a ṣe lè di “ohun gbogbo fún ènìyàn gbogbo” nínú ìgbòkègbodò ìwàásù wa?

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Nípa híhùwà onínúure sí àwọn aládùúgbò wọn, àwọn Kristẹni lè wó ẹ̀tanú palẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́