Ìgbà Tí Ẹ̀tanú Kì Yóò Sí Mọ́!
GẸ́GẸ́ bí a ti ròyìn rẹ̀, onímọ̀ sáyẹ́ǹsì Albert Einstein sọ nígbà kan pé, nínú ayé oníbànújẹ́ yìí, ó ṣòro láti borí ẹ̀tanú jù láti fọ́ átọ́ọ̀mù kan lọ. Lọ́nà jíjọra, Edward R. Murrow, akọ̀ròyìn kan tí ó di olókìkí nígbà Ogun Àgbáyé Kejì, tí ó sì di olùdarí Ilé Iṣẹ́ Ìsọfúnni ti United States lẹ́yìn náà, sọ pé, “kò sí ẹni tí ó lè mú ẹ̀tanú kúrò—ṣáà gbà pé ó wà.”
Òtítọ́ ha ni àwọn gbólóhùn wọ̀nyí bí? Kò ha ṣeé ṣe láti mú àìbáni lò lọ́gbọọgba àti ẹ̀yà ìran tèmi lọ̀gá kúrò bí? Kí ni èrò Ọlọrun nípa ẹ̀tanú?
Ọlọrun Kì í Ṣe Ojúsàájú
Bibeli sọ̀rọ̀ lòdì sí ṣíṣe ojúsàájú. (Owe 24:23; 28:21) Ó sọ pé “ọgbọ́n tí ó wá lati òkè á kọ́kọ́ mọ́níwà, lẹ́yìn naa ó lẹ́mìí-àlàáfíà, ó ń fòyebánilò, ó múra tán lati ṣègbọràn, ó kún fún àánú ati awọn èso rere, kì í pa awọn ààlà-ìyàtọ̀ olójúsàájú, kì í ṣe àgàbàgebè.” (Jakọbu 3:17) A tẹnu mọ́ irú ọgbọ́n bẹ́ẹ̀ fún àwọn onídàájọ́ ní Israeli ìgbàanì. A fún wọn ní ìtọ́ni pé: “Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ ṣe àìṣòdodo ní ìdájọ́ . . . ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ojúsàájú alágbára: ní òdodo ni kí ìwọ kí ó máa ṣe ìdájọ́ ẹnì kejì rẹ.”—Lefitiku 19:15.
Jesu Kristi pẹ̀lú aposteli Peteru àti Paulu tẹnu mọ́ àtakò lílágbára tí Bibeli ṣe sí ojúsàájú àti ẹ̀tanú. Jesu kò ṣe ojúsàájú sí ‘àwọn tí a bó láwọ tí a sì fọ́n ká bí àwọn àgùntàn tí kò ní olùṣọ́ àgùntàn.’ (Matteu 9:36) Ó kọ́ni pé: “Ẹ dẹ́kun ṣíṣèdájọ́ lati inú ìrísí òde, ṣugbọn ẹ máa ṣèdájọ́ pẹlu ìdájọ́ òdodo.”—Johannu 7:24.
Peteru àti Paulu fi dá wa lójú pé, Jehofa Ọlọrun fúnra rẹ̀ kì í ṣe ojúsàájú. Peteru sọ pé: “Dájúdájú láìsí tabi ṣugbọn mo róye pé Ọlọrun kì í ṣe ojúsàájú, ṣugbọn ní gbogbo orílẹ̀-èdè ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀ tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un.” (Ìṣe 10:34, 35) Aposteli Paulu sọ fún wa pé: “Kò sí ojúsàájú lọ́dọ̀ Ọlọrun.”—Romu 2:11.
Agbára Ìdarí Tí Bibeli Ń Ní
Bibeli ní agbára láti yí àkópọ̀ ìwà àwọn tí ó ń darí padà. Heberu 4:12 sọ pé: “Ọ̀rọ̀ Ọlọrun wà láàyè ó sì ń sa agbára.” Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jehofa, ẹlẹ́tanú kan lè yí ọ̀nà ìrònú rẹ̀ padà, kí ó sì di aláìṣojúsàájú nínú ìbálò rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn.
Fún àpẹẹrẹ, gbé ọ̀ràn Saulu ará Tarsu yẹ̀ wò. Gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ Bibeli ti wí, nígbà kan, ó fi ìwà ipá ta ko ìjọ Kristian nítorí pé ó tẹ̀ lé òfin àtọwọ́dọ́wọ́ líle koko tí ó jẹ́ ti ìsìn. (Ìṣe 8:1-3) Òfin àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn Júù mú un gbà gbọ́ dájú pátápátá pé, gbogbo Kristian ni apẹ̀yìndà àti ọ̀tá ìjọsìn tòótọ́. Ẹ̀tanú rẹ̀ sún un sí ṣíṣe ìtìlẹyìn fún pípa àwọn Kristian. Bibeli sọ pé, ó “ń mí èémí ìhalẹ̀mọ́ni ati ìṣìkàpànìyàn sí awọn ọmọ-ẹ̀yìn Oluwa.” (Ìṣe 9:1) Bí ó ti ń ṣe bẹ́ẹ̀, ó rò pé òún ń ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ ọlọ́wọ̀ sí Ọlọrun.—Fi wé Johannu 16:2.
Síbẹ̀, Saulu ará Tarsu lè já ẹ̀tanú rẹ̀ lílé kenkà sílẹ̀. Òun alára tilẹ̀ di Kristian! Lẹ́yìn náà, nígbà tí ó di Paulu, aposteli Jesu Kristi, ó kọ̀wé pé: “Tẹ́lẹ̀rí mo jẹ́ asọ̀rọ̀ òdì ati onínúnibíni ati aláfojúdi. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, a fi àánú hàn sí mi, nitori tí mo jẹ́ aláìmọ̀kan tí mo sì gbé ìgbésẹ̀ pẹlu àìnígbàgbọ́.”—1 Timoteu 1:13.
Kì í ṣe Paulu nìkan ni ó ṣe irú àwọn ìyípadà pátápátá bẹ́ẹ̀ nínú ọ̀nà ìrònú rẹ̀. Nínú lẹ́tà rẹ̀ sí Titu, ajíhìnrere ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, Paulu ṣí àwọn Kristian létí “lati máṣe sọ̀rọ̀ ẹni kankan lọ́nà ìbàjẹ́, lati máṣe jẹ́ aríjàgbá, lati jẹ́ afòyebánilò, kí wọ́n máa fi gbogbo ìwàtútù hàn sójútáyé sí ènìyàn gbogbo. Nitori àní awa nígbà kan rí jẹ́ òpònú, aláìgbọràn, ẹni tí a ṣìlọ́nà, ẹrú fún onírúurú ìfẹ́-ọkàn ati adùn, tí a ń bá a lọ ninu ìwà búburú ati ìlara, a jẹ́ ẹni ìkórìíra tẹ̀gàntẹ̀gàn, a kórìíra ara wa lẹ́nìkínní kejì.”—Titu 3:2, 3.
Bíbi Àwọn Ìdènà Ẹ̀tanú Wó
Lónìí, àwọn ojúlówó Kristian ń làkàkà láti tẹ̀ lé ìmọ̀ràn yẹn. Wọ́n fẹ́ yẹra fún ṣíṣèdájọ́ àwọn ènìyàn lórí ìpìlẹ̀ èrò oréfèé. Èyí kì í mú kí wọ́n ‘sọ̀rọ̀ ìbàjẹ́’ nípa àwọn ẹlòmíràn. Wọ́n ń gbádùn ẹgbẹ́ ará kárí ayé tí ó ré kọjá ààlà orílẹ̀-èdè, ẹ̀yà ìbílẹ̀, àti ẹ̀yà ìran ayé yìí.
Gbé ìrírí Henrique yẹ̀ wò, aláwọ̀ dúdú ará Brazil. A ti hùwà kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà sí òun alára rí, ó mú ìkórìíra jíjinlẹ̀ dàgbà fún àwọn aláwọ̀ funfun. Ó ṣàlàyé pé: “Àwọn Ẹlẹ́rìí méjì tí wọ́n jẹ́ aláwọ̀ funfun wá sí ilé mi láti bá mi sọ̀rọ̀ nípa orúkọ Ọlọrun. Lákọ̀ọ́kọ́, n kò fẹ́ fetí sílẹ̀ nítorí pé n kò fọkàn tán àwọn aláwọ̀ funfun. Ṣùgbọ́n kò pẹ́ tí ìhìn iṣẹ́ wọn bẹ̀rẹ̀ sí í yé mi, ó sì dà bí òtítọ́. Tóò, mo tẹ́wọ́ gba ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli. Ìbéèrè àkọ́kọ́ ti mo béèrè ni pé, ‘Àwọn aláwọ̀ dúdú ha wà ní ṣọ́ọ̀ṣì yín bí?’ Wọ́n dáhùn pé, ‘Bẹ́ẹ̀ ni.’ Nígbà náà ni wọ́n fi àwòrán tí ó kẹ́yìn nínú Iwe Itan Bibeli Mia hàn mí, tí ń fi àwọn ọ̀dọ́ láti inú ẹ̀yà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ hàn. Ọmọdékùnrin dúdú kan wà níbẹ̀, èyí sì fún mi níṣìírí. Lẹ́yìn náà, mo bẹ Gbọ̀ngàn Ìjọba Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa wò, níbi tí mo ti rí àwọn ènìyàn láti inú ẹ̀yà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí wọ́n ń fi ọ̀wọ̀ bá ẹnì kíní kejì lò. Èyí jọ mí lójú gidigidi.”
Wàyí o, gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan nínú àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, inú Henrique dùn láti wà nínú ojúlówó ẹgbẹ́ àwọn ará Kristian. Ó lóye pé ìyìn náà kò lọ sọ́dọ̀ ẹ̀dá ènìyàn kankan. Ó sọ pé: “Lónìí mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jehofa àti Jesu fún ohun gbogbo tí wọ́n ti ṣe fún mi. Mo ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ìránṣẹ́ adúróṣinṣin sí Jehofa láti inú gbogbo ẹ̀yà ìran, àwọ̀, àti ipò àtilẹ̀wá, tí wọ́n ní ète kan náà.”
Bí ó ṣe ń dàgbà, Dario tún jẹ́ ẹlòmíràn tí a ṣe ẹ̀tanú sí. Nígbà tí ó jẹ́ ọmọ ọdún 16, ó bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Ó sọ pé: “Láàárín àwọn Ẹlẹ́rìí, mo ti rí i pé kò sí ìmọ̀lára ẹ̀yà ìran tèmi lọ̀gá.” Ipò olójúlówó ìfẹ́ náà wú u lórí. Ní pàtàkì, ó ṣàkíyèsí pé, olúkúlùkù tí ó wá láti ẹ̀yà ìran ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ń ṣiṣẹ́ sìn ní ipò ẹrù iṣẹ́ nínú ìjọ. Nígbàkigbà tí àwọn tí kò sí nínú ìjọ bá ṣe ẹ̀tanú sí i tàbí tí wọn kò bá bá a lò lọ́gbọọgba, Dario ń rántí pé, Jehofa nífẹ̀ẹ́ gbogbo ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹ̀yà èdè, àti ahọ́n.
Bí A Ṣe Lè Kojú Rẹ̀
Gbogbo wa ni a fẹ́ kí a bu iyì àti ọ̀wọ̀ fún wa. Ìdí nìyẹn tí jíjẹ́ ẹni tí a ṣe ẹ̀tanú sí fi jẹ́ ìdánwò tí ó ṣòro láti fara dà. Ìjọ Kristian kì í dáàbò bò wá kúrò lọ́wọ́ dídi ẹni tí a ṣe ẹ̀tanú ti ayé búburú yìí sí. Níwọ̀n ìgbà tí Satani Eṣu bá ṣì ń darí àlámọ̀rí ayé, kò lè sí ìdájọ́ òdodo. (1 Johannu 5:19) Ìṣípayá 12:12 kìlọ̀ fún wa pé: “Ègbé ni fún ilẹ̀-ayé ati fún òkun, nitori Èṣù ti sọ̀kalẹ̀ wá bá yín, ó ní ìbínú ńlá, ní mímọ̀ pé sáà àkókò kúkúrú ni oun ní.” Èrò rẹ̀ kì í wulẹ̀ ṣe láti dá wàhálà sílẹ̀. A fi wé ẹran tí ń wá ẹran ìjẹ. Aposteli Peteru sọ fún wa pé: “Elénìní yín, Èṣù, ń rìn káàkiri bí kìnnìún tí ń ké ramúramù, ó ń wá ọ̀nà lati pa ẹni kan jẹ.”—1 Peteru 5:8.
Bibeli tún sọ fún wa pé: “Nitori naa, ẹ fi ara yín sábẹ́ Ọlọrun; ṣugbọn ẹ kọ ojú ìjà sí Èṣù, oun yoo sì sá kúrò lọ́dọ̀ yín.” (Jakọbu 4:7) Ìrànlọ́wọ́ àtàtà láti lè kojú ẹ̀tanú ni láti yíjú sí Ọlọrun fún ààbò, gẹ́gẹ́ bí Ọba Dafidi ti ṣe: “Gbà mí, Ọlọrun mi, ní ọwọ́ àwọn ènìyàn búburú, ni ọwọ́ aláìṣòdodo àti ìkà ọkùnrin.” (Orin Dafidi 71:4) A tún lè gbàdúrà bí onipsalmu náà pé: “Ọlọrun, ṣàánú fún mi: nítorí tí ènìyàn ń fẹ́ gbé mi mì; ó ń bá mi jà lójoojúmọ́, ó ń ni mí lára.”—Orin Dafidi 56:1.
Báwo ni Ọlọrun yóò ṣe dáhùn padà sí irú àwọn àdúrà bẹ́ẹ̀? Bibeli dáhùn pé: “Yóò gba aláìní nígbà tí ó bá ń ké: tálákà pẹ̀lú, àti ẹni tí kò ní olùrànlọ́wọ́. Òun óò dá tálákà àti aláìní sí, yóò sì gba ọkàn àwọn aláìní là.” (Orin Dafidi 72:12, 13) Ẹ wo bí ó ṣe dára tó láti mọ̀ pé ní àkókò yíyẹ, Jehofa yóò mú ìtura wá fún gbogbo àwọn tí a ti hùwà àìṣèdájọ́ òdodo sí!
“Wọn Kì Yóò Pani Lára”
Ìjọba ayé yìí lè máa bá a nìṣó ní fífi àwọn òfin àti ètò wọn gbéjà ko ẹ̀tanú. Wọ́n lè máa bá a nìṣó láti ṣèlérí ìbánilò lọ́gbọọgba àti ẹ̀tọ́. Ṣùgbọ́n wọn kò lè ṣàṣeyọrí. (Orin Dafidi 146:3) Ọlọrun nìkan ṣoṣo ni ó lè mú ìwà ẹ̀tanú kúrò, òun ni yóò sì mú un kúrò. Yóò sọ aráyé di ìdílé kan ṣoṣo tí ó wà ní ìṣọ̀kan. “Ogunlọ́gọ̀ ńlá kan, èyí tí ẹni kankan kò lè kà, lati inú gbogbo awọn orílẹ̀-èdè ati ẹ̀yà ati ènìyàn ati ahọ́n,” yóò la òpin ètò ìgbékalẹ̀ ìsinsìnyí yìí já, wọ́n yóò sì gbádùn gbígbé ní àlàáfíà.—Ìṣípayá 7:9, 10.
Jehofa yóò mú gbogbo ìpalára tí ẹ̀tanú ẹ̀yà ìran àti ti ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà ń ṣokùnfà kúrò. Fojú inú wò ó ná, kò sí ẹnì kan tí a óò bá lò lọ́nà àìtọ́ mọ́! “Wọn óò jókòó olúkúlùkù lábẹ́ àjàrà rẹ̀ àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀; ẹnì kan kì yóò sì dáyà fò wọ́n.” (Mika 4:4) Isaiah 11:9 sì sọ pé: “Wọn kì yóò pani lára.”
Bí a bá ń ṣe ẹ̀tanú sí ọ nísinsìnyí, ìrètí àgbàyanu ọjọ́ ọ̀la yìí yóò fún ipò ìbátan rẹ pẹ̀lú Jehofa lókun. Yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti fara da àìṣèdájọ́ òdodo nínú ètò ìgbékalẹ̀ búburú yìí. Bí o ṣe ń kojú ẹ̀tanú, tí o sì ń fojú sọ́nà fún ọjọ́ ọ̀la, tẹ̀ lé ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n tí Bibeli fúnni pé: “Ẹ ní ìgboyà, kí ẹ sì mú ọkàn-àyà yín le, gbogbo ẹ̀yin tí ń dúró de Jehofa.”—Orin Dafidi 31:24, NW.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A tẹ̀ ẹ́ jáde láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 4]
Fọ́tò U.S. National Archives