ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w93 7/15 ojú ìwé 18-23
  • Bawo Ni a Se Lè Fi Iwafunfun Kún Igbagbọ Wa?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bawo Ni a Se Lè Fi Iwafunfun Kún Igbagbọ Wa?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun ti Iwafunfun Jẹ́
  • Jíjẹ́ Alaipe Ṣugbọn Sibẹ Oniwafunfun
  • Iwafunfun ati Awọn Èrò Wa
  • Iwafunfun ati Ọrọ-Sisọ Wa
  • Iwafunfun ati Awọn Iṣesi Wa
  • Iwafunfun Jẹ́ Iwarere-Iṣeun ti O Walaaye
  • Ìwọ Ha Ń lépa Ìwà Funfun Bí?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Bí a Ṣe Lè ní Ìwà Funfun
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Èé Ṣe Tó Fi Yẹ Ká Níwà Funfun?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Dahunpada Si Awọn Ileri Ọlọrun Nipa Lilo Igbagbọ
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
w93 7/15 ojú ìwé 18-23

Bawo Ni a Se Lè Fi Iwafunfun Kún Igbagbọ Wa?

“Nipa fifi gbogbo ìsapá onifọkansi yin ṣeranlọwọ-afikun ni idahunpada, ẹ fi iwafunfun kún igbagbọ.”—2 PETERU 1:5, NW.

1, 2. Eeṣe ti a fi nilati reti pe ki awọn eniyan Jehofa ṣe ohun ti o niwafunfun?

JEHOFA sábà maa ń huwa ni ọ̀nà iwafunfun. Ó ń ṣe ohun ti o jẹ́ òdodo ati rere. Nitori naa, aposteli Peteru lè sọ nipa Ọlọrun gẹgẹ bi ẹni ti o pe awọn Kristian ẹni-ami-ororo ‘nipasẹ ògo ati iwafunfun Rẹ̀.’ Ìmọ̀ pipeye nipa Baba wọn ọ̀run oniwafunfun ti fi ohun ti wọn nilo lati lépa igbesi-aye ifọkansin oniwa-bi-Ọlọrun tootọ hàn wọn.—2 Peteru 1:2, 3.

2 Aposteli Paulu rọ awọn Kristian lati “maa ṣe afarawe Ọlọrun bi awọn ọmọ ọ̀wọ́n.” (Efesu 5:1) Bii Baba wọn ọ̀run, awọn olujọsin Jehofa nilati ṣe ohun ti o niwafunfun ni ipo eyikeyii. Ṣugbọn ki ni iwafunfun?

Ohun ti Iwafunfun Jẹ́

3. Bawo ni a ṣe tumọ “iwafunfun”?

3 Awọn iwe atumọ-ede ode-oni tumọ “iwafunfun” gẹgẹ bi “ìtayọlọ́lá iwarere; iwarere-iṣeun.” Ó jẹ́ “igbesẹ ati èrò titọna; didara ninu iwa.” Oniwafunfun kan jẹ́ olódodo. Iwafunfun ni a tún ti tumọ gẹgẹ bi “ìbáṣedéédéé pẹlu ọpa-idiwọn ẹ̀tọ́.” Fun awọn Kristian, nitootọ, “ọpa-idiwọn ẹ̀tọ́” ni a pinnu lati ọ̀dọ̀ Ọlọrun ti a sì mú ṣe kedere ninu Ọ̀rọ̀ Mimọ rẹ̀, Bibeli.

4. Awọn animọ wo ti a mẹnukan ni 2 Peteru 1:5-7 (NW) ni awọn Kristian gbọdọ ṣiṣẹ kára lati mú dagba?

4 Awọn Kristian tootọ bá ọpa-idiwọn òdodo Jehofa Ọlọrun ṣe deedee, wọn sì dahunpada si awọn ileri ṣiṣeyebiye rẹ̀ nipa lilo igbagbọ. Wọn tún kọbiara si imọran Peteru pe: “Nipa fifi gbogbo ìsapá onifọkansi yin ṣeranlọwọ-afikun, ni idahunpada, ẹ fi iwafunfun kún igbagbọ yin, ìmọ̀ kún iwafunfun yin, ikora-ẹni-nijaanu kún ìmọ̀ yin, ifarada kún ikora-ẹni-nijaanu yin, ifọkansin oniwa-bi-Ọlọrun kún ifarada yin, ifẹni ará kún ifọkansin oniwa-bi-Ọlọrun yin, ifẹ kún ifẹni ará yin.” (2 Peteru 1:5-7, NW) Kristian kan gbọdọ ṣiṣẹ kára lati mú awọn animọ wọnyi gbèrú sii. Eyi ni a kò lè ṣe niwọnba awọn ọjọ tabi ọdun diẹ ṣugbọn ó beere fun isapa tí ń baa lọ jalẹ akoko igbesi-aye. Họwu, fifi iwafunfun kún igbagbọ wa jẹ́ ipenija kan funraarẹ!

5. Ki ni iwafunfun loju-iwoye Iwe Mimọ?

5 Olutumọ-ede M. R. Vincent sọ pe èrò-ìtumọ̀ ipilẹsẹ ti ọ̀rọ̀ Griki igbaani ti a tumọ si “iwafunfun” duro fun “iru ìtayọlọ́lá eyikeyii.” Peteru lo ẹ̀dà ẹlẹ́yọ pupọ rẹ̀ nigba ti o sọ pe awọn Kristian ni wọn nilati kéde kaakiri “awọn ìtayọlọ́lá,” tabi iwafunfun, Ọlọrun. (1 Peteru 2:9, NW) Loju iwoye Iwe Mimọ, iwafunfun ni a ṣapejuwe kìí ṣe gẹgẹ bi alailagbara ṣugbọn gẹgẹ bi “agbara iwarere, okun-inu iwarere, okunra ọkàn.” Ni mimẹnukan iwafunfun, Peteru ní ìtayọlọ́lá iwarere onigboya ti a reti pe ki awọn iranṣẹ Ọlọrun fihàn ki wọn sì pamọ́ lọ́kàn. Bi o ti wu ki o ri, niwọn bi a ti jẹ́ alaipe, awa ha lè ṣe ohun ti o jẹ́ iwafunfun niti gidi ni oju Ọlọrun bi?

Jíjẹ́ Alaipe Ṣugbọn Sibẹ Oniwafunfun

6. Bi o tilẹ jẹ pe a jẹ́ alaipe, eeṣe ti a fi lè sọ pe a lè ṣe ohun ti o ni iwafunfun loju Ọlọrun?

6 A ní aipe ati ẹṣẹ ti a ti jogunba, nitori naa a lè ṣe kayeefi bi a ṣe lè ṣe ohun ti o jẹ́ iwafunfun niti gidi ni oju Ọlọrun. (Romu 5:12) A nilo iranlọwọ Jehofa dajudaju bi a bá nilati ní ọkan-aya mimọgaara, lati inu eyi ti awọn ironu, ọ̀rọ̀, ati iṣe oniwafunfun ti lè jade wá. (Fiwe Luku 6:45.) Lẹhin didẹṣẹ ni isopọ pẹlu Batṣeba, Dafidi olorin ti o ronupiwada naa bẹbẹ pe: “Dá ọkan-aya mimọgaara si inu mi, Óò Ọlọrun, ki o sì fi ẹmi titun si inu mi, ọ̀kan ti o duroṣanṣan.” (Orin Dafidi 51:10, NW) Dafidi gba idariji Ọlọrun ati iranlọwọ ti o nilo lati lépa ipa-ọna iwafunfun kan. Fun idi eyi, bi a bá ti ṣaṣiṣe lọna ti o wúwo ṣugbọn ti a ti fi ironupiwada tẹwọgba iranlọwọ Ọlọrun ati ti awọn alagba ijọ, a lè pada si ipa-ọna iwafunfun ki a sì maa baa lọ ninu rẹ̀.—Orin Dafidi 103:1-3, 10-14; Jakọbu 5:13-15.

7, 8. (a) Bi a bá nilati maa baa lọ ni oniwafunfun, ki ni o pọndandan? (b) Iranlọwọ wo ni awọn Kristian ní ninu jíjẹ́ oniwafunfun?

7 Nitori ipo ti o kun fun ẹṣẹ ti a ti jogun, a gbọdọ maa bá ijakadi inu lọhun-un lọ lati ṣe ohun ti ipa-ọna iwafunfun yoo beere lọwọ wa. Bi awa bá nilati maa baa lọ ni oniwafunfun, a kò lè faaye gba araawa lae lati di ẹrú ẹṣẹ. Kaka bẹẹ, a gbọdọ jẹ́ “ẹrú òdodo,” ni rironu, sisọrọ, ati hihuwa ni ọ̀nà iwafunfun nigba gbogbo. (Romu 6:16-23) Nitootọ, ìfẹ́-ọkàn ti ẹran-ara ati awọn itẹsi wa ti o kún fun ẹṣẹ lagbara, a sì dojukọ iforigbari laaarin iwọnyi ati awọn ohun oniwafunfun ti Ọlọrun ń beere lọwọ wa. Nitori naa, ki ni a nilati ṣe?

8 Fun ohun kan, a nilati tẹle idari ẹmi mimọ, tabi ipá agbekankanṣiṣẹ Jehofa. Nitori naa a nilati kọbiara si imọran Paulu pe: “Ẹ maa rìn nipa ti ẹmi, ẹyin kì yoo sì mú ifẹkufẹẹ ti ara ṣẹ. Nitori ti ara ń ṣe ifẹkufẹẹ lodi si ẹmi, ati ẹmi lodi si ara: awọn wọnyi sì lodi si ara wọn; ki ẹ ma baa lè ṣe ohun ti ẹyin ń fẹ́.” (Galatia 5:16, 17) Bẹẹni, gẹgẹ bi ipá fun òdodo, a ní ẹmi Ọlọrun, ati gẹgẹ bi itọsọna si iwa tí ó tọ́, a ní Ọ̀rọ̀ rẹ̀. A tun ní iranlọwọ onifẹẹ ti eto-ajọ Jehofa ati imọran “ẹrú oluṣotitọ ati ọlọgbọn-inu.” (Matteu 24:45-47, NW) Nipa bayii, a lè gbéjà àjàyọrí ko awọn itẹsi ti o kun fun ẹṣẹ. (Romu 7:15-25) Nitootọ, bi èrò ti kò mọ́ bá wá si ọkàn, a gbọdọ tú u ká ni wàràǹṣesà ki a sì gbadura fun iranlọwọ Ọlọrun lati dena idẹwo eyikeyii lati huwa ni ọ̀nà eyikeyii ti o ṣalaini iwafunfun.—Matteu 6:13.

Iwafunfun ati Awọn Èrò Wa

9. Iṣe oniwafunfun beere fun iru ironu wo?

9 Iwafunfun bẹrẹ pẹlu ọ̀nà ti ẹnikan ń gbà ronu. Lati gbadun ojurere atọrunwa, a gbọdọ ronu nipa awọn ohun ti o jẹ́ òdodo, rere, oniwafunfun. Paulu sọ pe: “Ẹyin ará, awọn ohun yoowu ti wọn jẹ́ tootọ, awọn ohun yoowu ti wọn jẹ aniyan-ọkan onironu, awọn ohun yoowu ti wọn jẹ òdodo, awọn ohun yoowu ti wọn jẹ́ oniwa-mimọ, awọn ohun yoowu ti wọn yẹ ni fífẹ́, awọn ohun yoowu ti a ń sọrọ wọn daradara, iwafunfun yoowu ti o bá wà ati ohun yoowu tí ó yẹ fun igboriyin ti o bá wà, ẹ maa baa lọ ni gbígba nǹkan wọnyi rò.” (Filippi 4:8, NW) A nilati gbé ọkàn wa kari awọn ohun òdodo, oniwa-mimọ, ohunkohun ti kò bá sì niwafunfun kò nilati fà wá mọra. Paulu lè sọ pe: “Awọn ohun ti ẹyin kọ́ ti ẹ sì tẹwọgba ti ẹ sì gbọ́ ti ẹ sì rí ni isopọ pẹlu mi, ẹ sọ awọn wọnyi di àṣà.” Bi a bá dabi Paulu—ti a ni iwafunfun ni èrò, ọrọ-sisọ, ati iṣe—awa yoo jẹ́ olubakẹgbẹ rere ati apẹẹrẹ rere ninu gbigbe igbesi-aye Kristian, ‘Ọlọrun alaafia yoo sì wà pẹlu wa.’—Filippi 4:9, NW.

10. Bawo ni ifisilo 1 Korinti 14:20 fun ara-ẹni ṣe lè ràn wá lọwọ lati maa baa lọ ni oniwafunfun?

10 Bi o bá jẹ́ ìfẹ́-ọkàn wa lati maa baa lọ ni oniwafunfun ni èrò ki a sì tipa bayii tẹ́ Baba wa ọ̀run lọ́rùn, ó pọndandan pe ki a fi imọran Paulu silo pe: “Ẹ maṣe jẹ́ ọmọde ni òye: ṣugbọn ẹ jẹ́ ọmọde ni arankan, ṣugbọn ni òye ki ẹ jẹ́ àgbà.” (1 Korinti 14:20) Eyi tumọ si pe gẹgẹ bíi Kristian a kìí wá ìmọ̀ tabi iriri ninu iwa buburu. Dipo fifaaye gba ero-inu wa lati di eyi ti a mú dibajẹ ni ọ̀nà yii, a fi ọgbọ́n yàn lati wà ni alaini iriri ati alaimọwọmẹsẹ gẹgẹ bi awọn ọmọde ni ọ̀nà yii. Lakooko kan-naa, a lóye ni kikun pe iwapalapala ati ìwà-àìtọ́ jẹ́ ẹṣẹ ni oju Jehofa. Ìfẹ́-ọkàn mímúhánhán ti o ti ọkàn wá lati tẹ́ ẹ lọ́rùn nipa jíjẹ́ oniwafunfun yoo ṣanfaani fun wa, nitori pe yoo sún wa lati yẹra fun iru oriṣiriṣi ere-idaraya ti kò mọ́ ati awọn agbara idari miiran ti ń sọni dibajẹ niti ero-ori eyi ti o jẹ́ ti ayé yii ti ó wà labẹ agbara Satani.—1 Johannu 5:19.

Iwafunfun ati Ọrọ-Sisọ Wa

11. Jíjẹ́ oniwafunfun beere fun iru ọrọ-sisọ wo, ati ni ọ̀nà yii, awọn apẹẹrẹ wo ni a ní ninu Jehofa Ọlọrun ati Jesu Kristi?

11 Bi awọn èrò wa bá jẹ́ ti iwafunfun, eyi yoo ni ipa ti o jinlẹ lori ohun ti a ń sọ. Jíjẹ́ oniwafunfun beere fun ọrọ-sisọ ti ń gbeniro, ti o mọ́, ti o péye, ti o sì jẹ́ otitọ. (2 Korinti 6:3, 4, 7) Jehofa ni “Ọlọrun otitọ.” (Orin Dafidi 31:5) Ó jẹ́ oluṣotitọ ninu gbogbo ìbálò rẹ̀, awọn ileri rẹ̀ sì daju nitori pe oun kò lè purọ́. (Numeri 23:19; 1 Samueli 15:29; Titu 1:2) Ọmọkunrin Ọlọrun, Jesu Kristi, “kún fun oore-ọfẹ ati otitọ.” Nigba ti o wà lori ilẹ̀-ayé, ó maa ń sọ otitọ nigba gbogbo gẹgẹ bi ó ti gbà á lati ọ̀dọ Baba rẹ̀. (Johannu 1:14; 8:40) Ju bẹẹ lọ, Jesu “ko dẹṣẹ, bẹẹ ni a kò sì rí arekereke ni ẹnu rẹ̀.” (1 Peteru 2:22) Bi a bá jẹ́ iranṣẹ Ọlọrun ati Kristi nitootọ, awa yoo jẹ́ oloootọ ninu ọ̀rọ̀ ati aduroṣanṣan ninu iwa, gẹgẹ bi pe a “fi amure otitọ di ẹ̀gbẹ́.”—Efesu 5:9; 6:14.

12. Bi awa yoo bá jẹ́ oniwafunfun, iru ọrọ-sisọ wo ni a gbọdọ yẹra fun?

12 Bi a bá niwafunfun, iru awọn ọrọ-sisọ kan wà ti a o yẹra fun. A o dari wa nipasẹ imọran Paulu pe: “Gbogbo iwa kikoro, ati ibinu, ati irunu, ati ariwo, ati ọ̀rọ̀ buburu ni ki a mú kuro lọdọ yin, pẹlu gbogbo arankan.” “Ṣugbọn àgbèrè, ati gbogbo iwa èérí, tabi ojukokoro, ki a má tilẹ darukọ rẹ̀ laaarin yin mọ̀, bi o ti yẹ awọn eniyan mímọ́; ìbáà ṣe iwa ọ̀bùn, ati isọrọ wèrè, tabi iṣẹfẹ, awọn ohun ti kò tọ́: ṣugbọn ẹ kuku maa dupẹ.” (Efesu 4:31; 5:3, 4) Yoo tu awọn ẹlomiran lara lati wà ninu awujọ wa nitori pe ọkan-aya òdodo wa sún wa lati yẹra fun ọrọ-sisọ ti kò bá ti Kristian mu.

13. Eeṣe ti awọn Kristian fi nilati kó ahọ́n nijaanu?

13 Ìfẹ́-ọkàn lati wu Ọlọrun ki a sì sọ awọn ohun oniwafunfun yoo ràn wá lọwọ lati kó ahọ́n nijaanu. Nitori awọn itẹsi ti o kun fun ẹṣẹ, gbogbo wa ń kọsẹ ninu ọ̀rọ̀ nigba miiran. Sibẹ, ọmọ-ẹhin naa Jakọbu sọ pe “bi a bá sì fi ijanu bọ ẹṣin ni ẹnu,” wọn a fi igbọran lọ si ibi ti a bá dari wọn si. Fun idi yii, a nilati ṣiṣẹ kára lati kó ahọ́n nijaanu ki a sì gbiyanju lati lò ó kìkì lọna iwafunfun. Ahọ́n ti a kò kó nijaanu jẹ́ “ayé ẹṣẹ.” (Jakọbu 3:1-7) Gbogbo iru animọ-iwa buburu ti ayé alaiwa-bi-Ọlọrun yii ni a sopọ pẹlu ahọ́n ti a kò tù loju. Oun ni o maa ń dahun fun awọn ohun ti ń banijẹ bi ẹ̀rí èké, kíkẹ́gàn, ati ìṣáátá. (Isaiah 5:20; Matteu 15:18-20) Nigba ti ahọ́n alaigbọran bá si ń sọ awọn ọ̀rọ̀ èébú, adunni-wọra, tabi abanijẹ, ó kún fun majele iku tíí pani.—Orin Dafidi 140:3; Romu 3:13; Jakọbu 3:8.

14. Ọpa-idiwọn onílọ̀ọ́po meji wo ninu ọrọ-sisọ ni awọn Kristian gbọdọ yẹra fun?

14 Gẹgẹ bi Jakọbu ti fihàn, kò ni ṣe deedee délẹ̀ lati “yin Oluwa” nipa sisọrọ Ọlọrun daradara ṣugbọn ki a ṣi ahọ́n lò lati “bú eniyan” nipa gígégùn-ún lé wọn lori. Ó ti kún fun ẹṣẹ tó lati kọrin iyin Ọlọrun ni awọn ipade ati lẹhin naa ki a jade ki a sì sọrọ awọn onigbagbọ ẹlẹgbẹ wa láìdára! Omi didun ati omiró kò lè rú jade lati orisun kan-naa. Bi a bá ń ṣiṣẹsin Jehofa, awọn miiran ní ẹ̀tọ́ lati reti pe ki a sọ awọn ohun oniwafunfun dipo sisọ awọn ọ̀rọ̀ ti kò dùn lati gbọ́. Ẹ jẹ ki a ṣá ọ̀rọ̀ buburu tì nigba naa ki a sì wá ọ̀nà lati sọ awọn ohun ti yoo ṣanfaani fun awọn alabaakẹgbẹ wa ti yoo sì gbé wọn ró nipa tẹmi.—Jakọbu 3:9-12.

Iwafunfun ati Awọn Iṣesi Wa

15. Eeṣe ti o fi ṣe pataki tobẹẹ lati yẹra fun yiyiju si awọn ọ̀nà oníbékebèke?

15 Niwọn ìgbà ti èrò ati ọ̀rọ̀ ti Kristian kan ń sọ ti gbọdọ niwafunfun, ki ni nipa awọn iṣesi wa? Jíjẹ́ oniwafunfun ni ìwà ni kìkì ọ̀nà ti a lè gbà ní itẹwọgba Ọlọrun. Kò sí iranṣẹ Jehofa kan ti o lè pa iwafunfun tì, ki o sì yiju si jíjẹ́ oníbékebèke ati atannijẹ, ki o sì fi ẹ̀tọ́ ronu pe iru awọn ohun bẹẹ yoo rí itẹwọgba lọdọ Ọlọrun. Owe 3:32 (NW) sọ pe: “Oníbékebèke jẹ́ ohun irira si Jehofa, ṣugbọn ìbárẹ́ timọtimọ Rẹ̀ wà pẹlu awọn aduroṣanṣan.” Bi a bá ṣikẹ ipo-ibatan wa pẹlu Jehofa Ọlọrun, awọn ọ̀rọ̀ ti ń ru ironu soke wọnyẹn nilati dí wa lọwọ kuro ninu gbígbìrò lati ṣokunfa ipalara tabi ṣiṣe ohunkohun ti o jẹ́ békebèke. Họwu, lara awọn ohun meje ti o kó ọkàn Jehofa niriira ni “àyà ti ń humọ buburu”! (Owe 6:16-19) Nitori idi eyi ẹ jẹ ki a yẹra fun iru awọn iṣesi bẹẹ ki a sì ṣe ohun ti o niwafunfun, si ire awọn eniyan ẹlẹgbẹ wa ati ògo Baba wa ọ̀run.

16. Eeṣe ti awọn Kristian kò fi gbọdọ lọwọ ninu awọn iṣesi alagabagebe eyikeyii?

16 Fifi iwafunfun hàn beere pe ki a jẹ́ alailabosi. (Heberu 13:18) Alagabagebe kan, ẹni ti awọn iṣesi rẹ̀ kò wà ni ibamu pẹlu awọn ọ̀rọ̀ rẹ̀, kìí ṣe oniwafunfun. Ọ̀rọ̀ Griki naa ti a tumọ si “agabagebe” (hy·po·kri·tesʹ) tumọsi “ẹnikan ti ń dahun” ó sì tun duro fun oṣere orí-ìtàgé. Niwọn bi awọn oṣere Griki ati Romu ti ń wọ agọ̀, ọ̀rọ̀ yii ni a wá lò lọna apejuwe fun ẹnikan ti ń díbọ́n. Awọn agabagebe jẹ́ “awọn alaiṣootọ.” (Fi Luku 12:46, [NW] wera pẹlu Matteu 24:50, 51.) Agabagebe (hy·poʹkri·sis) tún lè duro fun iwa-buburu ati alumọkọrọyi. (Matteu 22:18; Marku 12:15; Luku 20:23) Ó ti banininujẹ tó nigba ti ẹnikan ti o finútánni bá di ẹni ti a tanjẹ nipasẹ ẹ̀rín-músẹ́, ìpọ́nni, ati awọn iṣesi ti wọn jẹ́ kìkì ìdíbọ́n lásán! Ṣugbọn ó múnilọ́kàn yọ̀ nigba ti a bá mọ̀ pe a ń bá awọn Kristian ti wọn ṣee fọkantan lò. Ọlọrun sì ń bukun wa fun jíjẹ́ oniwafunfun ati alaini agabagebe. Itẹwọgba rẹ̀ wà fun awọn wọnni ti wọn ń fi “ifẹni ará laisi agabagebe” hàn ti wọn sì tun ni “igbagbọ àìṣẹ̀tàn.”—1 Peteru 1:22, NW; 1 Timoteu 1:5.

Iwafunfun Jẹ́ Iwarere-Iṣeun ti O Walaaye

17, 18. Bi a ti ń fi eso iwarere-iṣeun ti ẹmi hàn, bawo ni a o ṣe bá awọn ẹlomiran lò?

17 Bi a bá fi iwafunfun kún igbagbọ wa, awa yoo sakun lati fasẹhin kuro ninu rironu, sisọ, ati ṣiṣe awọn ohun ti kò ṣetẹwọgba fun Ọlọrun. Bi o ti wu ki o ri, fifi iwafunfun Kristian hàn tun beere pe ki a sọ iwarere-iṣeun ti o walaaye di àṣà. Nitootọ, iwafunfun ni a ti tumọ gẹgẹ bi iwarere-iṣeun. Iwarere-iṣeun sì jẹ́ eso ẹmi mimọ Jehofa, kìí ṣe imujade isapa eniyan lasan. (Galatia 5:22, 23, NW) Bi a ti ń fi eso iwarere-iṣeun ti ẹmi hàn, awa ni a o sún lati ronu daradara nipa awọn ẹlomiran ati lati gboriyin fun wọn fun awọn animọ rere wọn laika aipe wọn sí. Wọn ha ti fi iṣotitọ ṣiṣẹsin Jehofa fun ọpọ ọdun bi? Nigba naa a nilati fi ọ̀wọ̀ hàn fun wọn ki a sì sọrọ nipa wọn ati iṣẹ-isin wọn si Ọlọrun lọna ti o dara. Baba wa ọ̀run ń ṣakiyesi ifẹ ti wọn fihàn si orukọ rẹ̀ ati awọn iṣẹ oniwafunfun ti igbagbọ wọn, bẹẹ sì ni awa pẹlu nilati ṣe.—Nehemiah 13:31b; Heberu 6:10.

18 Iwafunfun ń mu wa jẹ́ onisuuru, olóye, oníyọ̀ọ́nú. Bi olujọsin Jehofa ẹlẹgbẹ wa kan bá ń jiya ipọnju tabi isorikọ, awa yoo sọrọ lọna ti ń tunininu a o sì wá ọ̀nà lati fun un ni itunu, àní gẹgẹ bi Baba wa ọ̀run ti ń tù wá ninu. (2 Korinti 1:3, 4; 1 Tessalonika 5:14) A ń bá awọn wọnni ti wọn ń banujẹ, boya nitori àdánù ololufẹ kan ninu iku kẹdun. Bi a bá lè ṣe ohunkohun lati mú ijiya naa dẹrùn, awa yoo ṣe e, nitori ẹmi iwafunfun ń súnni lati gbé igbesẹ onifẹẹ ati ẹlẹmii iṣoore.

19. Bawo ni awọn ẹlomiran ti ṣe lè bá wa lò bi a bá jẹ́ oniwafunfun ninu èrò, ọ̀rọ̀, ati iṣe?

19 Gan-an gẹgẹ bi a ti ń fi ibukun fun Jehofa nipa sisọrọ rẹ̀ daradara, awọn miiran ni o ṣeeṣe ki wọn maa bukun wa bi a bá jẹ́ oniwafunfun ni èrò, ọ̀rọ̀, ati iṣe. (Orin Dafidi 145:10) Owe ọlọgbọn kan sọ pe: “Ibukun wà ni ori olódodo: ṣugbọn iwa-agbara ni yoo bo ẹnu eniyan buburu.” (Owe 10:6) Ẹni buburu ati oniwa-ipa kan ṣaini iwafunfun ti o lè mú un di ẹni ọ̀wọ́n fun awọn ẹlomiran. Ó ń kórè oun ti o gbìn, nitori pe awọn eniyan kò lè fi ailabosi fun un ni ibukun wọn nipa sisọrọ rẹ̀ lọna rere. (Galatia 6:7) O ti dara pupọ tó fun awọn wọnni ti ń ronu, sọrọ, ati huwa ni awọn ọ̀nà iwafunfun gẹgẹ bi iranṣẹ Jehofa! Wọn jere ifẹ, igbẹkẹle, ati ọ̀wọ̀ awọn miiran, ti a sún lati bukun wọn ki wọn sì sọrọ wọn lọna rere. Ju bẹẹ lọ, iwafunfun oniwa-bi-Ọlọrun wọn ń yọrisi ibukun Jehofa ti kò ṣeediyele.—Owe 10:22.

20. Awọn èrò, ọrọ-sisọ, ati iṣesi lè ní ipa wo lori ijọ awọn eniyan Jehofa?

20 Awọn èrò, ọrọ-sisọ, ati iṣe oniwafunfun ni o daju pe yoo ṣanfaani fun ijọ awọn eniyan Jehofa. Nigba ti awọn onigbagbọ ẹlẹgbẹ wa bá ni ironu ọlọ́wọ̀ siha ẹnikinni keji, ifẹ ará a maa gbèrú laaarin wọn. (Johannu 13:34, 35) Ọrọ-sisọ oniwafunfun, papọ pẹlu igboriyin funni ati iṣiri olotiitọ-inu, ń mú imọlara ọlọyaya ti ifọwọsowọpọ ati iṣọkan dagba. (Orin Dafidi 133:1-3) Awọn iṣesi amọ́kànyọ̀, oniwafunfun sì ń ru awọn miiran soke lati dahunpada ni ọ̀nà kan-naa. Lékè gbogbo rẹ̀, fifi iwafunfun Kristian ṣewahu ń yọrisi itẹwọgba ati ibukun Baba wa ọ̀run oniwafunfun, Jehofa. Ǹjẹ́ ki awa nitori naa sọ ọ́ di gongo wa lati dahunpada si awọn ileri ṣiṣeyebiye ti Ọlọrun nipa lilo igbagbọ. Ati ni gbogbo ọ̀nà ẹ jẹ ki a lo isapa onifọkansi lati fi iwafunfun kún igbagbọ wa.

Ki Ni Awọn Idahun Rẹ?

◻ Bawo ni iwọ yoo ṣe tumọ “iwafunfun,” eesitiṣe ti awọn eniyan alaipe fi lè jẹ́ oniwafunfun?

◻ Iwafunfun beere fun iru awọn ironu wo?

◻ Bawo ni iwafunfun ṣe nilati nipa lori ọrọ-sisọ wa?

◻ Ipa wo ni iwafunfun nilati ní lori iṣesi wa?

◻ Ki ni awọn anfaani diẹ ti jíjẹ́ oniwafunfun?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]

Niwọn bi omi dídùn ati omiró kò ti lè rú jade lati orisun kan-naa, awọn miiran fi ẹ̀tọ́ reti pe ki awọn iranṣẹ Jehofa maa sọ kìkì ohun ti o niwafunfun

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́