Sáàmù
Fún olùdarí. Orin Dáfídì.
140 Jèhófà, gbà mí lọ́wọ́ àwọn aṣebi;
Dáàbò bò mí lọ́wọ́ àwọn oníwà ipá,+
2 Àwọn tó ń gbèrò ibi nínú ọkàn wọn,+
Tí wọ́n sì ń dá ìjà sílẹ̀ látàárọ̀ ṣúlẹ̀.
4 Jèhófà, dáàbò bò mí lọ́wọ́ ẹni burúkú;+
Máa ṣọ́ mi lọ́wọ́ àwọn oníwà ipá,
Àwọn tó ń gbèrò láti mú kí n yọ̀ ṣubú.
5 Àwọn agbéraga dẹ pańpẹ́ pa mọ́ dè mí;
Wọ́n fi okùn ta àwọ̀n sẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà.+
Wọ́n dẹkùn fún mi.+ (Sélà)
6 Mo sọ fún Jèhófà pé: “Ìwọ ni Ọlọ́run mi.
Jèhófà, jọ̀wọ́ gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi fún ìrànlọ́wọ́.”+
7 Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, Olùgbàlà mi tó lágbára,
O dáàbò bo orí mi ní ọjọ́ ogun.+
8 Jèhófà, má ṣe fún àwọn ẹni burúkú ní ohun tí ọkàn wọn fẹ́.
Má ṣe jẹ́ kí ohun tí wọ́n gbèrò bọ́ sí i, kí wọ́n má bàa gbé ara wọn ga.+ (Sélà)
9 Kí ọ̀rọ̀ ibi tí àwọn tó yí mi ká ń fẹnu wọn sọ+
Dà lé wọn lórí.
10 Kí òjò ẹyin iná rọ̀ lé wọn lórí.+
11 Kí àwọn abanijẹ́ má ṣe ríbi gbé nínú ayé.*+
Kí ibi máa lépa àwọn oníwà ipá, kó sì mú wọn balẹ̀.
12 Mo mọ̀ pé Jèhófà máa gbèjà àwọn aláìní
Á sì ṣèdájọ́ òdodo fún àwọn tálákà.+