ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w97 7/15 ojú ìwé 14-19
  • Ìwọ Ha Ń lépa Ìwà Funfun Bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìwọ Ha Ń lépa Ìwà Funfun Bí?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ó Lépa Ìwà Funfun
  • Wọ́n Ń Bá A Lọ Ní Jíjẹ́ Oníwà Funfun
  • Lílépa Ìwà Funfun Lónìí
  • Ẹ Máa Ṣọ́ra!
  • Ipa Tí Ìkẹ́kọ̀ọ́ àti Àṣàrò Ń Kó
  • Ìwà Funfun àti Ẹgbẹ́ Kíkó
  • Máa Bá A Lọ Láti Lépa Ìwà Funfun
  • Bawo Ni a Se Lè Fi Iwafunfun Kún Igbagbọ Wa?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Bí a Ṣe Lè ní Ìwà Funfun
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Èé Ṣe Tó Fi Yẹ Ká Níwà Funfun?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Pípa Ìwà Funfun Mọ́ Nínú Ayé Tí Ó Kún Fún Ìwà Abèṣe
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
w97 7/15 ojú ìwé 14-19

Ìwọ Ha Ń lépa Ìwà Funfun Bí?

“Ìwà funfun yòó wù tí ó bá wà, ohun yòó wù tí ó bá sì wà tí ó yẹ fún ìyìn, ẹ máa bá a lọ ní gbígba nǹkan wọ̀nyí rò.”—FÍLÍPÌ 4:8.

1. Kí ni ìwà abèṣe, èé sì ti ṣe tí kò tí ì ba ìjọsìn Jèhófà jẹ́?

ÌWÀ abèṣe jẹ́ ìwà pálapàla tàbí ìwà ìbàjẹ́. Ó kún inú ayé tí a ń gbé. (Éfésù 2:1-3) Àmọ́ ṣáá o, Jèhófà Ọlọ́run kò ní yọ̀ǹda pé kí a ba ìjọsìn rẹ̀ mímọ́ gaara jẹ́. Àwọn ìtẹ̀jáde Kristẹni, ìpàdé, àpéjọ, àti àpéjọpọ̀ ń fún wa ní ìkìlọ̀ tí ó bọ́ sí àkókò nípa ìwà àìṣòdodo. A ń gba ìrànlọ́wọ́ tí ó yè kooro tí a gbé ka Ìwé Mímọ́ láti “dìrọ̀ mọ́ ohun rere” ní ojú Ọlọ́run. (Róòmù 12:9) Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí ètò àjọ kan, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń tiraka láti wà ní mímọ́, kí wọ́n sì jẹ́ oníwà funfun. Ṣùgbọ́n àwa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan ńkọ́? Ní tòótọ́, ìwọ ha ń lépa ìwà funfun bí?

2. Kí ni ìwà funfun, èé sì ti ṣe tí ó fi gba ìsapá láti máa bá a lọ ní jíjẹ́ oníwà funfun?

2 Ìwà funfun jẹ́ ìwà gíga lọ́lá, ìwà rere, ìgbésẹ̀ àti ìrònú títọ́. Kì í ṣe ànímọ́ tí kì í ṣiṣẹ́, ṣùgbọ́n ó jẹ́ èyí tí ń ṣiṣẹ́, tí ń ṣiṣẹ́ rere. Ìwà funfun ní nínú ju yíyẹra fún ẹ̀ṣẹ̀ lọ; ó túmọ̀ sí lílépa ohun rere. (Tímótì Kíní 6:11) Àpọ́sítélì Pétérù gba àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ níyànjú pé: “Ẹ pèsè ìwà funfun kún ìgbàgbọ́ yín.” Lọ́nà wo? Nípa “fífi gbogbo ìsapá àfi-taratara-ṣe ṣèrànlọ́wọ́ fún ìtìlẹ́yìn ní ìdáhùnpadà [sí àwọn ìlérí oníyebíye tí Ọlọ́run ti ṣe].” (Pétérù Kejì 1:5) Nítorí jíjẹ́ tí a jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, ó gba ìsapá gidigidi láti máa bá a lọ ní jíjẹ́ oníwà funfun. Síbẹ̀, àwọn ènìyàn ìgbàanì tí wọ́n bẹ̀rù Ọlọ́run ṣe bẹ́ẹ̀, àní lójú ìdènà kíkàmàmà pàápàá.

Ó Lépa Ìwà Funfun

3. Ìwà burúkú wo ni Ọba Áhásì jẹ̀bi rẹ̀?

3 Ìwé Mímọ́ kún fún ìròyìn àwọn tí wọ́n lépa ìwà funfun. Fún àpẹẹrẹ, gbé oníwà funfun náà, Hesekáyà, yẹ̀ wò. Dájúdájú, bàbá rẹ̀, Ọba Áhásì ti Júdà jọ́sìn Mólékì. “Ẹni ogún ọdún ni Áhásì nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí í jọba, ó sì jọba ọdún mẹ́rìndínlógún ní Jerúsálẹ́mù, kò sì ṣe èyí tí ó tọ́ ní ojú Olúwa Ọlọ́run rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Dáfídì bàbá rẹ̀. Ṣùgbọ́n ó rìn ní ọ̀nà àwọn ọba Ísírẹ́lì, ní tòótọ́, ó sì mú kí ọmọ rẹ̀ kí ó kọjá láàárín iná pẹ̀lú, gẹ́gẹ́ bí ìṣe ìríra àwọn kèfèrí, tí Olúwa lé jáde níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Ó sì rúbọ, ó sì sun tùràrí ní ibi gíga wọnnì, àti lórí àwọn òkè kéékèèké, àti lábẹ́ gbogbo igi tútù.” (Àwọn Ọba Kejì 16:2-4) Àwọn kan sọ pé, ‘kíkọjá láàárín iná’ dúró fún irú ètùtù ìsọdimímọ́ kan, kì í ṣe fífi ènìyàn rúbọ. Bí ó ti wù kí ó rí, ìwé Molech—A God of Human Sacrifice in the Old Testament, láti ọwọ́ John Day, sọ pé: “Ẹ̀rí ń bẹ ní ayé Gíríìkì àti Róòmù ìgbàanì àti nínú Púníìkì [àwọn ará Kátágì], àti nínú ẹ̀rí ìwalẹ̀pìtàn, pé wọ́n fi ènìyàn rúbọ . . . nínú ayé àwọn ará Kénáánì, nítorí náà, kò sí ìdí láti ṣiyèméjì nípa ohun tí Májẹ̀mú Láéláé sọ nípa [fífi ènìyàn rúbọ].” Síwájú sí i, Kíróníkà Kejì 28:3 sọ ní pàtó pé Áhásì “sun àwọn ọmọ rẹ̀ nínú iná.” (Fi wé Diutarónómì 12:31; Orin Dáfídì 106:37, 38.) Ẹ wo irú ìwà burúkú gbáà ti èyí jẹ́!

4. Báwo ni Hesekáyà ṣe hùwà nínú àyíká tí ó kún fún ìwà abèṣe?

4 Báwo ni nǹkan ti rí fún Hesekáyà nínú àyíká tí ó kún fún ìwà abèṣe yìí? Orin Dáfídì ìkọkàndínlọ́gọ́fà gba àfiyèsí, nítorí àwọn kan gbà gbọ́ pé Hesekáyà ni ó kọ ọ́, nígbà tí ó ṣì jẹ́ ọmọ ọba. (Orin Dáfídì 119:46, 99, 100) Nítorí náà, àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí lè fi bí nǹkan ti rí fún un hàn: “Àní àwọn ọmọ aládé jókòó; wọ́n bá ara wọn sọ̀rọ̀ lẹ́nì kíní kejì lòdì sí mi. Ní ti ìránṣẹ́ rẹ, àwọn ìlànà rẹ ni ìdàníyàn rẹ̀. Ọkàn mi kò lè sùn nítorí ẹ̀dùn ọkàn.” (Orin Dáfídì 119:23, 28, NW) Bí àwọn olùjọsìn èké ti yí i ká, Hesekáyà lè ti di ẹni tí àwọn tí ń gbé ní ààfin ọba ń fi ṣẹlẹ́yà, tí ó fi jẹ́ pé kò lè sùn. Síbẹ̀, ó lépa ìwà funfun, kò pẹ́ kò jìnnà ó di ọba, ó sì “ṣe èyí tí ó tọ́ ní ojú Olúwa . . . Ó gbẹ́kẹ̀ lé Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì.”—Àwọn Ọba Kejì 18:1-5.

Wọ́n Ń Bá A Lọ Ní Jíjẹ́ Oníwà Funfun

5. Àdánwò wo ni Dáníẹ́lì àti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta dojú kọ?

5 Dáníẹ́lì àti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ mẹ́ta tí wọ́n jẹ́ Hébérù, tí orúkọ wọn ń jẹ́ Hananáyà, Míṣáẹ́lì, àti Asaráyà, pẹ̀lú jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ ní ti ìwà funfun. A fipá mú wọn láti ilẹ̀ ìbílẹ̀ wọn, a sì kó wọn nígbèkùn lọ sí Bábílónì. A fún àwọn èwe mẹ́rin náà ní orúkọ àwọn ará Bábílónì—Bẹlitéṣásárì, Ṣádírákì, Méṣákì, àti Àbẹ́dínígò. A fi “àdídùn ọba,” tí ó ní àwọn oúnjẹ tí Òfin Ọlọ́run kà léèwọ̀ nínú, lọ̀ wọ́n. Síwájú sí i, a fi dandan mú wọn láti gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ ọlọ́dún mẹ́ta, tí ó ní í ṣe pẹ̀lú “ìwé àti èdè àwọn ará Kálídíà.” Èyí ju kíkọ́ èdè míràn lọ, nítorí ó ṣeé ṣe kí ẹ̀dà ọ̀rọ̀ náà, “àwọn ará Kálídíà,” tí a lò níhìn-ín dúró fún àwọn ọ̀mọ̀wé. Nípa báyìí, a jọ̀wọ́ àwọn èwe Hébérù wọ̀nyí fún agbára ìdarí àwọn ẹ̀kọ́ òdì Bábílónì.—Dáníẹ́lì 1:1-7.

6. Èé ṣe tí a fi lè sọ pé Dáníẹ́lì lépa ìwà funfun?

6 Láìka fífòòró tí wọ́n fòòró ẹ̀mí wọn sí láti ṣe ohun tí ayé ń ṣe, Dáníẹ́lì àti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yan ìwà funfun dípò ìwà abèṣe. Dáníẹ́lì 1:21 (NW) sọ pé: “Dáníẹ́lì sì ń bá a lọ títí di ọdún àkọ́kọ́ Kírúsì ọba.” Bẹ́ẹ̀ ni, Dáníẹ́lì “ń bá a lọ” gẹ́gẹ́ bí oníwà funfun ìránṣẹ́ Jèhófà fún èyí tí ó lé ní 80 ọdún—jálẹ̀ ìdìde àti ìṣubú ọ̀pọ̀ ọba alágbára. Ó dúró gẹ́gẹ́ bí olùṣòtítọ́ sí Ọlọ́run láìka rìkíṣí àti ọ̀tẹ̀ àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba tí wọ́n jẹ́ oníbàjẹ́ àti láìka ìwà abèṣe ní ti ìbálòpọ̀ tí ó kún inú ìsìn àwọn ará Bábílónì sí. Dáníẹ́lì ń bá a lọ láti pa ìwà funfun mọ́.

7. Kí ni a lè rí kọ́ nínú ipa ọ̀nà tí Dáníẹ́lì àti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tọ̀?

7 A lè rí ẹ̀kọ́ púpọ̀ kọ́ lára Dáníẹ́lì olùbẹ̀rù Ọlọ́run àti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀. Wọ́n lépa ìwà funfun, wọ́n sì kọ̀ láti jẹ́ kí a mú wọn wọnú àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ Bábílónì. Bí a tilẹ̀ fùn wọn ní orúkọ àwọn ará Bábílónì, wọn kò gbàgbé láé pé ìránṣẹ́ Jèhófà ni àwọn. Họ́wù, ní nǹkan bí 70 ọdún lẹ́yìn náà, ọba Bábílónì fi orúkọ Hébérù tí Dáníẹ́lì ń jẹ́ pè é! (Dáníẹ́lì 5:13) Jálẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀ gígùn, Dáníẹ́lì kọ̀ láti juwọ́ sílẹ̀, kódà nínú àwọn ohun kéékèèké pàápàá. Gẹ́gẹ́ bí èwe, ó ti “pinnu rẹ̀ ní ọkàn rẹ̀ pé, òun kì yóò fi oúnjẹ àdídùn ọba . . . ba ara òun jẹ́.” (Dáníẹ́lì 1:8) Dájúdájú, ìdúró aláìyẹsẹ̀ yí tí Dáníẹ́lì àti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta dì mú fún wọn lókun láti la àdánwò ìyè-òun-ikú tí wọ́n dojú kọ lẹ́yìn náà já.—Dáníẹ́lì, orí 3 àti 6.

Lílépa Ìwà Funfun Lónìí

8. Báwo ni àwọn èwe Kristẹni ṣe lè dènà wíwọnú ayé Sátánì?

8 Gẹ́gẹ́ bíi Dáníẹ́lì àti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, àwọn ènìyàn Ọlọ́run lónìí ń dènà dídi apá kan ayé burúkú ti Sátánì. (Jòhánù Kíní 5:19) Bí o bá jẹ́ èwe Kristẹni, àwọn ojúgbà rẹ lè máa fòòró ẹ̀mí rẹ láti fára wé ìwà àṣejù wọn nínú ìwọṣọ, ìmúra, àti orin. Ṣùgbọ́n, dípò títẹ̀lé gbogbo àṣà ìgbàlódé tàbí ìmúra tí ó gbòde, dúró gbọn-in, má sì ṣe “dáṣà ní àfarawé ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan yìí.” (Róòmù 12:2) ‘Kọ àìṣèfẹ́ Ọlọ́run jù sílẹ̀ àti àwọn ìfẹ́ ọkàn ti ayé kí o sì gbé pẹ̀lú ìyèkooro èrò inú àti òdodo àti ìfọkànsin Ọlọ́run.’ (Títù 2:11, 12) Rírí ìtẹ́wọ́gbà Jèhófà ni ó ṣe pàtàkì jù, kì í ṣe rírí ìtẹ́wọ́gbà àwọn ojúgbà rẹ.—Òwe 12:2.

9. Àwọn ohun tí ń fòòró ẹ̀mí ẹni wo ni àwọn Kristẹni tí ń ṣòwò ń dojú kọ, báwo sì ni ó ṣe yẹ kí wọ́n hùwà?

9 Àwọn àgbà Kristẹni pẹ̀lú dojú kọ ohun tí ń fòòró ẹ̀mí wọn, wọ́n sì gbọ́dọ̀ jẹ́ oníwà funfun. A lè dẹ àwọn Kristẹni tí ń ṣòwò wò láti ṣe màgòmágó tàbí láti kọ ìlànà ìjọba àti òfin owó orí sílẹ̀. Ṣùgbọ́n, láìka bí àwọn oníṣòwò ẹlẹgbẹ́ wa tàbí àwọn òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ wa ṣe lè máa hùwà sí, a “dàníyàn láti máa mú ara wa hùwà láìṣàbòsí nínú ohun gbogbo.” (Hébérù 13:18) Ìwé Mímọ́ béèrè pé kí a jẹ́ aláìlábòsí àti olóòótọ́ pẹ̀lú àwọn agbanisíṣẹ́ wa, àwọn tí a gbà síṣẹ́, àwọn oníbàárà wa, àti ìjọba ayé. (Diutarónómì 25:13-16; Mátíù 5:37; Róòmù 13:1; Tímótì Kíní 5:18; Títù 2:9, 10) Ẹ jẹ́ kí a tún tiraka láti wà létòletò nínú ọ̀ràn òwò wa. Nípa pípa àkọsílẹ̀ pípéye mọ́, àti kíkọ àdéhùn sílẹ̀, a lè yẹra fún èdèkòyedè lọ́pọ̀ ìgbà.

Ẹ Máa Ṣọ́ra!

10. Èé ṣe tí ó fi ṣe pàtàkì láti lo ‘ìṣọ́ra’ nígbà tí ó bá kan irú orin tí a yàn láàyò?

10 Orin Dáfídì 119:9 (NW) tẹnu mọ́ apá mìíràn nínú bíbá a lọ láti jẹ́ oníwà funfun lójú Ọlọ́run. Onísáàmù náà kọrin pé: “Báwo ni ọ̀dọ́kùnrin ṣe lè mú ipa ọ̀nà rẹ̀ mọ́? Nípa ṣíṣọ́ra ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ rẹ.” Ọ̀kan lára ohun ìjà gbígbéṣẹ́ jù lọ tí Sátánì ń lò ni orin, tí ó ní agbára láti ru ìmọ̀lára sókè. Ó bani nínú jẹ́ pé, àwọn Kristẹni kan ti kùnà láti “ṣọ́ra” nígbà tí ó bá di ọ̀ràn orin, tí ọkàn wọ́n sì ń fà sí èyí tí ó burú jù nínú wọn, irú bí orin ọlọ́rọ̀ wótòwótò àti orin onílù dídún kíkankíkan. Àwọn kan lè jiyàn pé irú orin bẹ́ẹ̀ kì í pa wọ́n lára tàbí pé àwọn kì í fetí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀. Àwọn mìíràn sọ pé kìkì ìlù rẹ̀ tàbí gìtá rẹ̀ tí ń dún kíkankíkan ni àwọn ń gbádùn. Ṣùgbọ́n, fún àwọn Kristẹni, ọ̀ràn náà kì í ṣe bóyá ohun kan gbádùn mọ́ni. Ohun tí ó jẹ wọ́n lógún ni bóyá ó ṣe “ìtẹ́wọ́gbà fún Olúwa.” (Éfésù 5:10) Ní gbogbogbòò, orin onílù dídún kíkankíkan àti orin ọlọ́rọ̀ wótòwótò ń gbé irú ìwà abèṣe bíi lílo èdè àìmọ́, àgbèrè, àti ìjọsìn Sátánì pàápàá lárugẹ—àwọn ohun tí kò ní àyè kankan rárá láàárín àwọn ènìyàn Ọlọ́run.a (Éfésù 5:3) Yálà a jẹ́ àgbà tàbí ọmọdé, yóò dára bí ẹnìkọ̀ọ̀kan wa bá gbé ìbéèrè yí yẹ̀ wò, Nípa orin tí mo yàn, èmi ha ń lépa ìwà funfun tàbí ìwà abèṣe?

11. Báwo ni Kristẹni kan ṣe lè lo ìṣọ́ra ní ti ìtòlẹ́sẹẹsẹ orí tẹlifíṣọ̀n, fídíò, àti sinimá?

11 Ọ̀pọ̀ ìtòlẹ́sẹẹsẹ orí tẹlifíṣọ̀n, fídíò, àti sinimá ń gbé ìwà abèṣe lárugẹ. Gẹ́gẹ́ bí gbajúmọ̀ kan nínú iṣẹ́ ìṣègùn ọpọlọ ti sọ, ‘ìgbésí ayé aláfẹ́, ìwà pálapàla, ìwà ipá, ìwọra, àti ìmọtara-ẹni-nìkan’ ni ó pọ̀ jù lọ nínú ọ̀pọ̀ sinimá tí a ń ṣe jáde lónìí. Nítorí náà, ṣíṣọ́ra kan ṣíṣe àṣàyàn àwọn ohun tí a óò máa wò. Onísáàmù náà gbàdúrà pé: “Yí ojú mi pa dà kúrò láti máa wo ohun asán.” (Orin Dáfídì 119:37) Èwe Kristẹni kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jósẹ́fù fi ìlànà yí sílò. Nígbà tí sinimá kan bẹ̀rẹ̀ sí í gbé àwòrán ìbálòpọ̀ àti ìwà ipá yọ, ó fi gbọ̀ngàn ìwòran náà sílẹ̀. Ojú ha tì í láti ṣe èyí bí? Jósẹ́fù sọ pé: “Ó tì o. Mo kọ́kọ́ ronú nípa Jèhófà àti ṣíṣe ohun tí ó wù ú.”

Ipa Tí Ìkẹ́kọ̀ọ́ àti Àṣàrò Ń Kó

12. Èé ṣe tí ìdákẹ́kọ̀ọ́ àti àṣàrò fi ṣe pàtàkì láti lè lépa ìwà funfun?

12 Yíyẹra fún àwọn ohun búburú nìkan kò tó. Lílépa ìwà funfun tún ní í ṣe pẹ̀lú kíkẹ́kọ̀ọ́ àti ṣíṣàṣàrò lórí àwọn ohun rere tí a kọ sílẹ̀ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kí a baà lè fi àwọn ìlànà òdodo rẹ̀ sílò nínú ìgbésí ayé. Onísáàmù náà sọ pé: “Èmi ti fẹ́ òfin rẹ tó! ìṣàrò mi ni ní ọjọ́ gbogbo.” (Orin Dáfídì 119:97) Ìdákẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti àwọn ìtẹ̀jáde Kristẹni ha jẹ́ apá kan ìtòlẹ́sẹẹsẹ rẹ ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ bí? Ní tòótọ́, wíwá àkókò fún ìkẹ́kọ̀ọ́ aláápọn nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti ṣíṣàṣàrò lórí rẹ̀ tàdúràtàdúrà lè jẹ́ ìpèníjà. Ṣùgbọ́n, lọ́pọ̀ ìgbà, ó ṣeé ṣe láti ra àkókò pa dà láti inú àwọn ìgbòkègbodò míràn. (Éfésù 5:15, 16) Bóyá ọwọ́ àárọ̀ yóò jẹ́ àkókò tí ó dára fún ọ láti gbàdúrà, láti kẹ́kọ̀ọ́, àti láti ṣàṣàrò.—Fi wé Orin Dáfídì 119:147.

13, 14. (a) Èé ṣe tí a kò fi lè fọwọ́ rọ́ ṣíṣàṣàrò sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan? (b) Ṣíṣàṣàrò lórí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wo ni ó lè ràn wá lọ́wọ́ láti kórìíra ìwà pálapàla tẹ̀gàntẹ̀gàn?

13 Àṣàrò kò ṣeé fọwọ́ rọ̀ sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, nítorí ó ń ràn wá lọ́wọ́ láti rántí ohun tí a kọ́. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ó lè ràn wá lọ́wọ́ láti gbé ojú ìwòye Ọlọ́run lárugẹ. Láti ṣàkàwé: Ohun kan ni láti mọ̀ pé Ọlọ́run ka àgbèrè léèwọ̀, ṣùgbọ́n ohun mìíràn ni láti ‘kórìíra ohun burúkú tẹ̀gàntẹ̀gàn, kí a sì dìrọ̀ mọ́ ohun rere.’ (Róòmù 12:9) Ní ti gidi, a lè fi irú ojú tí Jèhófà fi wo ìwà pálapàla wò ó nípa ṣíṣàṣàrò lórí àwọn ẹsẹ Bíbélì ṣíṣe kókó, bíi Kólósè 3:5, tí ó rọ̀ wá pé: “Nítorí náà, ẹ sọ àwọn ẹ̀yà ara yín tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé di òkú ní ti àgbèrè, ìwà àìmọ́, ìdálọ́rùn fún ìbálòpọ̀ takọtabo, ìfẹ́ ọkàn tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́, àti ojúkòkòrò, tí í ṣe ìbọ̀rìṣà.” Bí ara rẹ léèrè pé: ‘Irú ìdálọ́rùn fún ìbálòpọ̀ takọtabo wo ni mo gbọ́dọ̀ sọ di òkú? Kí ni ó lè ru ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sókè tí ó yẹ kí n yẹra fún? Mo ha ní láti ṣe ìyípadà nínú ọ̀nà tí mo gbà ń bá ẹ̀yà kejì lò bí?’—Fi wé Tímótì Kíní 5:1, 2.

14 Pọ́ọ̀lù rọ àwọn Kristẹni láti takété sí àgbèrè, kí wọ́n sì lo ìkóra-ẹni-níjàánu “kí ẹni kankan má ṣe lọ títí dé àyè ṣíṣe ìpalára fún àti rírakaka lé àwọn ẹ̀tọ́ arákùnrin rẹ̀.” (Tẹsalóníkà Kíní 4:3-7) Bi ara rẹ léèrè pé: ‘Èé ṣe ti ṣíṣàgbèrè fi ń pani lára? Ìpalára wo ni n óò ṣe fún ara mi tàbí fún ẹlòmíràn bí mo bá ṣubú sínú ìwà yí? Báwo ni èyí yóò ṣe nípa lórí mi nípa tẹ̀mí, ní ti ìmọ̀lára, àti nípa tara? Àwọn ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú ìjọ tí wọ́n ti tẹ òfin Ọlọ́run lójú, tí wọ́n sì kọ̀ láti ronú pìwà dà ńkọ́? Báwo ni ìgbésí ayé wọn ti rí?’ Fífi ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ nípa irú ìwà bẹ́ẹ̀ sọ́kàn lè mú kí a túbọ̀ kórìíra ohun tí ó burú lójú Ọlọ́run. (Ẹ́kísódù 20:14; Kọ́ríńtì Kíní 5:11-13; 6:9, 10; Gálátíà 5:19-21; Ìṣípayá 21:8) Pọ́ọ̀lù sọ pé alágbèrè kan “kì í ṣe ènìyàn ni ó ń ṣàìkà sí, bí kò ṣe Ọlọ́run.” (Tẹsalóníkà Kíní 4:8) Kristẹni tòótọ́ wo ni yóò ṣàìka Bàbá rẹ̀ ọ̀run sí?

Ìwà Funfun àti Ẹgbẹ́ Kíkó

15. Ipa wo ni ẹgbẹ́ tí a ń kó ní nínú lílé tí a ń lépa ìwà funfun?

15 Ẹgbẹ́ rere jẹ́ àrànṣe mìíràn láti máa bá a lọ ní jíjẹ́ oníwà funfun. Onísáàmù náà kọrin pé: “Ẹgbẹ́ gbogbo àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ [Jèhófà] ni èmi, àti ti àwọn tí ń pa ẹ̀kọ́ rẹ mọ́.” (Orin Dáfídì 119:63) A nílò ẹgbẹ́ gbígbámúṣé tí a ń rí nínú ìpàdé Kristẹni. (Hébérù 10:24, 25) Bí a bá ya ara wa láṣo, a lè di ẹni tí èrò tirẹ̀ nìkan ń jọ lójú, ó sì lè rọrùn láti ṣubú sínú ìwà abèṣe. (Òwe 18:1) Ṣùgbọ́n ìkẹ́gbẹ́pọ̀ ọlọ́yàyà ti Kristẹni lè túbọ̀ fún ìpinnu wa lókun láti máa bá a lọ ní jíjẹ́ oníwà funfun. Dájúdájú, a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra fún ẹgbẹ́ búburú. A lè bá àwọn aládùúgbò wa, òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ wa, àti àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ wa rẹ́. Ṣùgbọ́n bí a bá ń rìn nínú ọgbọ́n ní tòótọ́, a óò yẹra fún ṣíṣe wọléwọ̀de pẹ́lù àwọn tí kì í lépa ìwà funfun Kristẹni.—Fi wé Kólósè 4:5.

16. Báwo ni fífi Kọ́ríńtì Kíní 15:33 sílò ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti lépa ìwà funfun?

16 Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Àwọn ẹgbẹ́ búburú a máa ba àwọn àṣà ìhùwà wíwúlò jẹ́.” Nípa sísọ gbólóhùn yí jáde, ó ń kìlọ̀ fún àwọn onígbàgbọ́ pé wọ́n lè sọ ìgbàgbọ́ wọn nù nípa kíkẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn aláfẹnujẹ́ Kristẹni, tí wọ́n kọ ẹ̀kọ́ tí Ìwé Mímọ́ fi kọ́ni nípa àjíǹde sílẹ̀. Ìlànà tí ó wà nídìí ìkìlọ̀ Pọ́ọ̀lù kan ẹgbẹ́ tí a ń kó lóde àti nínú ìjọ. (Kọ́ríńtì Kíní 15:12, 33) Gẹ́gẹ́ bí ohun tí a ń retí, a kì í fẹ́ láti ṣá àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa nípa tẹ̀mí tì, nítorí pé wọn kò fohùn ṣọ̀kan pẹ̀lú wa nínú ojú ìwòye ara ẹni tí a ní. (Mátíù 7:4, 5; Róòmù 14:1-12) Bí ó ti wù kí ó rí, a nílò ìṣọ́ra bí àwọn kan nínú ìjọ bá ń lọ́wọ́ nínú ìwà tí ó lè gbé ìbéèrè dìde tàbí tí wọ́n bá ń fi ẹ̀mí ìbániṣọ̀tá tàbí ti ìráhùn hàn. (Tímótì Kejì 2:20-22) Ó jẹ́ ìwà ọlọgbọ́n láti rìn mọ́ àwọn tí a lè gbádùn “pàṣípààrọ̀ ìṣírí” pẹ̀lú wọn. (Róòmù 1:11, 12) Èyí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti lépa ipa ọ̀nà oníwà funfun, kí a sì máa bá a lọ láti wà lójú “ipa ọ̀nà ìyè.”—Orin Dáfídì 16:11.

Máa Bá A Lọ Láti Lépa Ìwà Funfun

17. Gẹ́gẹ́ bí Númérì orí 25 ti sọ, àgbákò wo ni ó dé bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ẹ̀kọ́ wo sì ni èyí fi kọ́ wa?

17 Kété ṣáájú kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó gba Ilẹ̀ Ìlérí, ẹgbẹẹgbẹ̀rún wọn yàn láti lépa ìwà abèṣe—wọ́n sì kàgbákò. (Númérì, orí 25) Lónìí, àwọn ènìyàn Jèhófà wà ní bèbè ayé tuntun òdodo. Wíwọnú rẹ̀ yóò jẹ́ ìbùkún aláǹfààní fún àwọn tí ń bá a lọ láti kọ ìwà abèṣe inú ayé yìí sílẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá aláìpé, a lè ní ìtẹ̀sí tí ó lòdì, ṣùgbọ́n Ọlọ́run lè ràn wá lọ́wọ́ láti tẹ̀lé ìdarí òdodo ti ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀. (Gálátíà 5:16; Tẹsalóníkà Kíní 4:3, 4) Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a kọbi ara sí ọ̀rọ̀ ìyànjú tí Jóṣúà fún Ísírẹ́lì pé: “Ẹ bẹ̀rù Olúwa, kí ẹ sì máa sìn ín ní òdodo àti ní òtítọ́.” (Jóṣúà 24:14) Ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ láti má ṣe lọ́wọ́ nínú ohun tí yóò bí Jèhófà nínú yóò ràn wá lọ́wọ́ láti lépa ipa ọ̀nà ìwà funfun.

18. Ní ti ìwà abèṣe àti ìwà funfun, kí ní yẹ kí ó jẹ́ ìpinnu gbogbo Kristẹni?

18 Bí ó bá jẹ́ ìfẹ́ ọkàn rẹ láti mú inú Ọlọ́run dùn, pinnu láti kọbi ará sí ọ̀rọ̀ ìyànjú Pọ́ọ̀lù pé: “Ohun yòó wù tí ó jẹ́ òótọ́, ohun yòó wù tí ó jẹ́ ti ìdàníyàn ṣíṣe pàtàkì, ohun yòó wù tí ó jẹ́ òdodo, ohun yòó wù tí ó jẹ́ mímọ́ níwà, ohun yòó wù tí ó dára ní fífẹ́, ohun yòó wù tí a ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ dáadáa, ìwà funfun yòó wù tí ó bá wà, ohun yòó wù tí ó bá sì wà tí ó yẹ fún ìyìn, ẹ máa bá a lọ ní gbígba nǹkan wọ̀nyí rò.” Bí o bá ṣe èyí, kí ni yóò jẹ́ àbájáde rẹ̀? Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹ máa fi ìwọ̀nyí ṣèwàhù; Ọlọ́run àlàáfíà yóò sì wà pẹ̀lú yín.” (Fílípì 4:8, 9) Bẹ́ẹ̀ ni, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, o lè kọ ìwà abèṣe sílẹ̀, kí o sì lépa ìwà funfun.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo Ilé-Ìṣọ́nà, April 15, 1993, ojú ìwé 19 sí 24, àti àwọn ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . ” nínú Jí! February 8, February 22, àti March 22, 1993, àti November 22, 1996.

Àwọn Kókó fún Àtúnyẹ̀wò

◻ Kí ni a ń béèrè bí a óò bá lépa ìwà funfun?

◻ Lábẹ́ ìpo wo ni Hesekáyà, Dáníẹ́lì, àti àwọn Hébérù mẹ́ta náà ti ń bá a lọ láti jẹ́ oníwà funfun?

◻ Bawo ni a ṣe lè dà bíi Dáníẹ́lì nínú kíkọ àwọn ìhùmọ̀ Sátánì sílẹ̀?

◻ Èé ṣe tí àwọn Kristẹni fi gbọ́dọ̀ lo ìṣọ́ra ní ti eré ìnàjú?

◻ Ipa wo ni ìkẹ́kọ̀ọ́, àṣàrò, àti ìkẹ́gbẹ́pọ̀ ń kó nínú lílépa ìwà funfun?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Hesekáyà ọ̀dọ́ lépa ìwà funfun, bí àwọn olùjọsìn Mólékì tilẹ̀ yí i ká

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Àwọn Kristẹni gbọ́dọ̀ lo ìṣọ́ra nígbà tí ó bá di ọ̀ràn eré ìnàjú

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́