Pípa Ìwà Funfun Mọ́ Nínú Ayé Tí Ó Kún Fún Ìwà Abèṣe
“Ẹ máa ṣe ohun gbogbo láìsí ìkùnsínú àti ìjiyàn, kí ẹ lè wá jẹ́ aláìlẹ́bi àti ọlọ́wọ́ mímọ́, àwọn ọmọ Ọlọ́run láìní àbààwọ́n kan ní àárín ìran oníwà wíwọ́ àti onímàgòmágó.”—FÍLÍPÌ 2:14, 15.
1, 2. Èé ṣe ti Ọlọ́run fi ní kí a pa àwọn ará Kénáánì run ráúráú?
ÀṢẸ Jèhófà kò fi àyè sílẹ̀ fún fífi ìlànà báni dọ́rẹ̀ẹ́. Ó kù díẹ̀ kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ Ilẹ̀ Ìlérí ni wòlíì Mósè sọ fún wọn pé: “Kí ìwọ kí ó pa wọ́n run pátápátá; àwọn ọmọ Hétì, àti àwọn Ámórì, àwọn ará Kénáánì, àti àwọn Pérísì, àwọn Hífì, àti àwọn Jébúsì; bí OLÚWA Ọlọ́run rẹ ti pàṣẹ fún ọ.”—Diutarónómì 7:2; 20:17.
2 Níwọ̀n bí Jèhófà ti jẹ́ Ọlọ́run aláàánú, èé ṣe tí ó fi pàṣẹ pé kí a pa àwọn olùgbé Kénáánì run ráúráú? (Ẹ́kísódù 34:6) Ìdí kan ni pé ‘kí àwọn ará Kénáánì má baà kọ́ Ísírẹ́lì láti máa ṣe bíi gbogbo iṣẹ́ ìríra tí wọ́n ṣe sí àwọn òrìṣà wọn, tí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ ṣẹ̀ sí Olúwa Ọlọ́run.’ (Diutarónómì 20:18) Mósè tún sọ pé: “Nítorí ìwà búburú àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí ni OLÚWA ṣe lé wọn jáde kúrò níwájú rẹ.” (Diutarónómì 9:4) Àwọn ará Kénáánì jẹ́ oníwà abèṣe gbáà. Ìwà ìbàjẹ́ takọtabo àti ìbọ̀rìṣà jẹ́ ohun tí a fi ń dá ìjọsìn wọn mọ̀. (Ẹ́kísódù 23:24; 34:12, 13; Númérì 33:52; Diutarónómì 7:5) Bíbá ìbátan ẹni lò pọ̀, ìbálòpọ̀ takọtabo tí a gbé gbòdì, àti bíbá ẹranko lò pọ̀ jẹ́ “ìwà ilẹ́ Kénáánì.” (Léfítíkù 18:3-25) Wọ́n ń fi àwọn ọmọ tí kò mọwọ́ mẹsẹ̀ rúbọ lọ́nà ìkà sí àwọn ọlọ́run èké. (Diutarónómì 18:9-12) Abájọ tí Jèhófà fi ka wíwà àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí lásán sí èyí tí ń wu ire ti ara, ti ìwà híhù, àti ti ẹ̀mí àwọn ènìyàn rẹ̀ léwu!—Ẹ́kísódù 34:14-16.
3. Kí ni ìyọrísí ìkùnà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti mú àṣẹ Ọlọ́run nípa àwọn olùgbé Kénáánì ṣẹ ní kíkún?
3 Nítorí wọn kò mú àṣẹ Ọlọ́run ṣẹ ní kíkún, púpọ̀ nínú àwọn ará Kénáánì la ìṣẹ́gun Ísírẹ́lì lórí Ilẹ̀ Ìlérí náà já. (Àwọn Onídàájọ́ 1:19-21) Bí àkókò ti ń lọ, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í nímọ̀lára agbára ìdarí ayọ́kẹ́lẹ́ṣọṣẹ́ ti àwọn ará Kénáánì, a sì lè sọ pé: “Wọ́n [àwọn ọmọ Ísírẹ́lì] sì kọ ìlànà [Jèhófà], àti májẹ̀mú rẹ̀ sílẹ̀, tí ó bá àwọn bàbá wọn dá, àti ẹ̀rí rẹ̀ tí ó jẹ́ sí wọn: wọ́n sì ń tọ ohun asán lẹ́yìn, wọ́n sì hùwà asán, wọn sì ń tọ àwọn kèfèrí lẹ́yìn tí ó yí wọn ká, ní ti ẹni tí Olúwa ti kìlọ̀ fún wọn pé, kí wọn kí ó má ṣe ṣe bí àwọn.” (Àwọn Ọba Kejì 17:15) Bẹ́ẹ̀ ni, bí ọdún ti ń lọ, ọ̀pọ̀ ọmọ Ísírẹ́lì hu àwọn ìwà abèṣe bíburú bàlùmọ̀ tí ó mú kí Ọlọ́run pàṣẹ níjelòó pé kí a pa àwọn ará Kénáánì run ráúráú—ìbọ̀rìṣà, ìbálòpọ̀ búburú jáì, àti ìfọmọrúbọ pàápàá!—Onídàájọ́ 10:6; Àwọn Ọba Kejì 17:17; Jeremáyà 13:27.
4, 5. (a) Kí ní ṣẹlẹ̀ sí Ísírẹ́lì àti Júdà aláìṣòtítọ́? (b) Ọ̀rọ̀ ìyànjú wo ni a fúnni nínú Fílípì 2:14, 15, àwọn ìbéèrè wo ni a sì gbé dìde?
4 Nítorí náà, wòlíì Hóséà kéde pé: “Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa, ẹ̀yin ọmọ Ísírẹ́lì; nítorí Olúwa ní ẹjọ́ kan bá àwọn ará ilẹ̀ náà wí, nítorí tí kò sí òtítọ́, tàbí àánú, tàbí ìmọ̀ Ọlọ́run ní ilẹ̀ náà. Nípa ìbúra, àti èké, àti ìpani, àti olè, àti ìṣe panṣágà, wọ́n gbìjà, ẹ̀jẹ̀ sì ń kan ẹ̀jẹ̀. Nítorí náà ni ilẹ̀ náà yóò ṣe ṣọ̀fọ̀, àti olúkúlùkù ẹni tí ń gbé inú rẹ̀ yóò rọ, pẹ̀lú àwọn ẹranko ìgbẹ́, àti pẹ̀lú àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run; a óò sì mú àwọn ẹja inú òkun kúrò pẹ̀lú.” (Hóséà 4:1-3) Ní ọdún 740 ṣááju Sànmánì Tiwa, Ásíríà ṣẹ́gun ìjọba àríwá Ísírẹ́lì oníwà ìbàjẹ́. Ní nǹkan bí ọ̀rúndún kan lẹ́yìn náà, Bábílónì ṣẹ́gun ìjọba gúúsù Júdà aláìṣòtítọ́.
5 Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí ṣàpèjúwe bí ó ti léwu tó láti jẹ́ kí ìwà abèṣe gbé wa dè. Ọlọ́run kórìíra àìṣòdodo, òun kò sì ní fàyè gbà á láàárín àwọn ènìyàn rẹ̀. (Pétérù Kíní 1:14-16) Òtítọ́ ni pé a ń gbé nínú “ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan burúkú ìsinsìnyí,” nínú ayé kan tí ó túbọ̀ ń bàjẹ́ sí i. (Gálátíà 1:4; Tímótì Kejì 3:13) Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gba gbogbo Kristẹni níyànjú láti máa bá a lọ láti hùwà ní ọ̀nà kan tí ó fi hàn pé wọ́n jẹ́ “aláìlẹ́bi àti ọlọ́wọ́ mímọ́, àwọn ọmọ Ọlọ́run láìní àbààwọ́n kan ní àárín ìran oníwà wíwọ́ àti onímàgòmágó, láàárín àwọn tí ẹ̀yin ń tàn bí atànmọ́lẹ̀ nínú ayé.” (Fílípì 2:14, 15) Ṣùgbọ́n báwo ni a ṣe lè pa ìwà funfun mọ́ nínú ayé tí ó kún fún ìwà abèṣe? Ó ha ṣeé ṣe ní tòótọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀?
Ayé Róòmù Tí Ó Kún fún Ìwà Abèṣe
6. Èé ṣe tí àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní fi dojú kọ ìpèníjà nínú pípa ìwà funfun mọ́?
6 Àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní dojú kọ ìpèníjà pípa ìwà funfun mọ́ nítorí ìwà abèṣe kún inú gbogbo àwùjọ Róòmù. Ọlọ́gbọ́n èrò orí náà, Seneca, tí ó jẹ́ ọmọ ìlú Róòmù, sọ nípa àwọn alájọgbáyé rẹ̀ pé: “Àwọn ènìyàn ń figagbága nínú ìdíje alágbára ti ìwà ibi. Lójoojúmọ́, ìfẹ́ fún híhu ìwà ibi túbọ̀ ń ga sí i, ìbẹ̀rù híhu ìwà ibi túbọ̀ ń lọ sílẹ̀ sí i.” Ó fi àwùjọ Róòmù wé “àwùjọ àwọn ẹranko ẹhànnà.” Kò yani lẹ́nu nígbà náà pé, fún eré ìnàjú, àwọn ará Róòmù ń wá ìdíje oníjà àjàkú akátá àti àwọn eré orí ìtàgé tí ń gbé ìwà pálapàla lárugẹ.
7. Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe ṣàpèjúwe àwọn ìwà abèṣe tí ó wọ́pọ̀ láàárín ọ̀pọ̀ ènìyàn ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa?
7 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ti lè ní ìwà ìbàjẹ́ àwọn ènìyàn ní ọ̀rúndún kìíní lọ́kàn nígbà tí ó kọ̀wé pé: “Ọlọ́run . . . jọ̀wọ́ wọn lọ́wọ́ fún ìdálọ́rùn tí ń dójú tini fún ìbálòpọ̀ takọtabo, nítorí àwọn abo wọn yí ìlò ara wọn lọ́nà ti ẹ̀dá pa dà sí èyí tí ó lòdì sí ìwà ẹ̀dá; àti bákan náà àní àwọn akọ fi ìlò abo lọ́nà ti ẹ̀dá sílẹ̀ wọ́n sì di ẹni tí a mú ara wọn gbiná lọ́nà líle nípá nínú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ wọn sí ara wọn lẹ́nì kíní kejì, àwọn akọ pẹ̀lú àwọn akọ, ń ṣe ohun ìbàjẹ́ akóninírìíra wọ́n sì ń gba èrè iṣẹ́ kíkún rẹ́rẹ́ nínú ara wọn, èyí tí ó yẹ fún ìṣìnà wọn.” (Róòmù 1:26, 27) Ní pípinnu láti lépa àwọn ìwà àìmọ́ ti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara, àwùjọ Róòmù kún fún ìwà abèṣe.
8. Báwo ni a ṣe ń kó àwọn ọmọdé nífà lọ́pọ̀ ìgbà nínú àwùjọ Gíríìkì àti Róòmù?
8 Ìtàn kò sọ ní kedere bí ìwà ìbẹ́yà kan náà lòpọ̀ ti gbilẹ̀ tó láàárín àwọn ará Róòmù. Ṣùgbọ́n, láìsí àní-àní, àwọn Gíríìkì tí ó jẹ́ alákòóso ayé ṣáájú wọn, tí wọ́n ń fi ìwà ìbẹ́yà kan náà lòpọ̀ ṣe omi mu, nípa lórí wọn. Ó jẹ́ àṣà fún àwọn àgbà ọkùnrin láti ba àwọn ọmọdékùnrin jẹ́, ní mímú wọn wá sábẹ́ àbójútó wọn nínú ìbátan akẹ́kọ̀ọ́ àti olùkọ́, tí ó sábà máa ń ti àwọn èwe náà sínú ìwà ìbálòpọ̀ tí ó lòdì. Láìsí àní-àní, Sátánì àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ ni ó wà nídìí irú ìwà abèṣe àti bíbá àwọn ọmọdé lò lọ́nà ìkà bẹ́ẹ̀.—Jóẹ́lì 3:3; Júúdà 6, 7.
9, 10. (a) Ní ọ̀nà wo ni Kọ́ríńtì Kíní 6:9, 10 gbà dẹ́bi fún onírúurú ìwà abèṣe? (b) Kí ni ìgbésí ayé àtilẹ̀wá àwọn kan nínú ìjọ Kọ́ríńtì, ìyípadà wo sì ni ó ṣẹlẹ̀ nínú ọ̀ràn tiwọn?
9 Ní kíkọ̀wé lábẹ́ ìmísí Ọlọ́run, Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn Kristẹni ní Kọ́ríńtì pé: “Kínla! Ẹ̀yin kò ha mọ̀ pé àwọn aláìṣòdodo ènìyàn kì yóò jogún ìjọba Ọlọ́run? Kí a má ṣe ṣì yín lọ́nà. Kì í ṣe àwọn àgbèrè, tàbí àwọn abọ̀rìṣà, tàbí àwọn panṣágà, tàbí àwọn ọkùnrin tí a pa mọ́ fún àwọn ète tí ó lòdì sí ti ẹ̀dá, tàbí àwọn ọkùnrin tí ń bá ọkùnrin dà pọ̀, tàbí àwọn olè, tàbí àwọn oníwọra ènìyàn, tàbí àwọn ọ̀mùtípara, tàbí àwọn olùkẹ́gàn, tàbí àwọn alọ́nilọ́wọ́gbà ni yóò jogún ìjọba Ọlọ́run. Síbẹ̀ ohun tí àwọn kan lára yín sì ti jẹ́ rí nìyẹn. Ṣùgbọ́n a ti wẹ̀ yín mọ́, ṣùgbọ́n a ti sọ yín di mímọ́, ṣùgbọ́n a ti polongo yín ní olódodo ní orúkọ Olúwa wa Jésù Kristi àti pẹ̀lú ẹ̀mí Ọlọ́run wa.”—Kọ́ríńtì Kíní 6:9-11.
10 Nípa báyìí, lẹ́tà Pọ́ọ̀lù tí a mí sí dẹ́bi fún ìwà pálapàla takọtabo, ní sísọ pé “àwọn àgbèrè” kì “yóò jogún ìjọba Ọlọ́run.” Ṣùgbọ́n, lẹ́yìn dídárúkọ ọ̀pọ̀ ìwà abèṣe, Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ohun tí àwọn kan lára yín sì ti jẹ́ rí nìyẹn. Ṣùgbọ́n a ti sọ yín di mímọ́.” Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run, ó ṣeé ṣe fún àwọn oníwà àìtọ́ láti di mímọ́ ní ojú rẹ̀.
11. Báwo ni àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní ṣe ṣe sí nínú àyíká burúkú ọjọ́ wọn?
11 Bẹ́ẹ̀ ni, ìwà funfun Kristẹni gbèèrú àní nínú ayé ọ̀rúndún kìíní tí ó kún fún ìwà abèṣe. Àwọn onígbàgbọ́ ‘para dà nípa yíyí èrò inú wọn pa dà.’ (Róòmù 12:2) Wọ́n kọ ‘ìlà ipa ọ̀nà ìwà wọn àtijọ́’ sílẹ̀, wọ́n sì ‘di tuntun nínú ipá tí ń mú èrò inú wọn ṣiṣẹ́.’ Nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n sá fún àwọn ìwà abèṣe inú ayé, wọ́n sì “gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀ èyí tí a dá ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ inú Ọlọ́run nínú òdodo tòótọ́ àti ìdúróṣinṣin.”—Éfésù 4:22-24.
Ayé Òde Òní Tí Ó Kún fún Ìwà Abèṣe
12. Ìyípadà wo ni ó ti ṣẹlẹ̀ nínú ayé láti ọdún 1914?
12 Ọjọ́ wa ńkọ́? Ayé tí a ń gbé inú rẹ̀ kún fún ìwà abèṣe ju ti ìgbàkígbà rí lọ. Pàápàá jù lọ láti ọdún 1914, ìwà rere ti jó àjórẹ̀yìn kárí ayé. (Tímótì Kejì 3:1-5) Ní kíkọ èrò tí ó fìdí múlẹ̀ nípa ìwà funfun, ìwà rere, orúkọ rere, àti ìlànà ìwà híhù sílẹ̀, ọ̀pọ̀ ti di ajọra-ẹni-lójú nínú ìrònú wọn, wọ́n sì ti “ré kọjá gbogbo agbára òye ìwà rere.” (Éfésù 4:19) Ìwé ìròyìn Newsweek sọ pé: “A ń gbé ní àkókò oní-hùwà-bí-ó-ti-wù-ọ́,” ó fi kún un pé, ìwà tí ó kún inú ayé “ti sọ gbogbo èrò tí a ní nípa rere àti búburú di ọ̀ràn bí o ṣe fẹ́, bí ìmọ̀lára rẹ ṣe rí tàbí yíyàn tí ó wù ọ́.”
13. (a) Báwo ni ọ̀pọ̀ eré ìnàjú òde òní ṣe ń gbé ìwà abèṣe lárugẹ? (b) Ipa búburú wo ni eré ìnàjú tí kò bójú mu lè ní lórí ẹnì kọ̀ọ̀kan?
13 Gẹ́gẹ́ bí ó ti rí ní ọ̀rúndún kìíní, eré ìnàjú tí ń bani jẹ́ wọ́pọ̀ lónìí. Tẹlifíṣọ̀n, rédíò, sinimá, àti fídíò ń mú àwọn eré tí ń gbé ìbálòpọ̀ lárugẹ jáde léraléra. Ìwà abèṣe ti wọnú ìgbékalẹ̀ ìsokọ́ra kọ̀ǹpútà pàápàá. Àwọn àwòrán arùfẹ́ ìṣekúṣe sókè túbọ̀ ń pọ̀ sí i nínú ìgbékalẹ̀ ìsokọ́ra kọ̀ǹpútà òde òní, àwọn ènìyàn onírúurú ọjọ́ orí sì ń wò ó. Kí ni àbájáde gbogbo èyí? Òǹkọ̀wé ìwé agbéròyìnjáde kan sọ pé: “Nígbà tí ìtàjẹ̀sílẹ̀ àti ìwà ipá àti ìṣekúṣe rin ẹgbẹ́ àwùjọ wa gbígbajúmọ̀ gbingbin, ìtàjẹ̀sílẹ̀ àti ìwà ipá àti ìṣekúṣe kò jọ wá lójú mọ́. A di aláìbìkítà mọ́. Ìwà ìbàjẹ́ túbọ̀ ń di èyí tí a tẹ́wọ́ gbà nítorí pé kì í fi bẹ́ẹ̀ mú wa gbọ̀n rìrì mọ́.”—Fi wé Tímótì Kíní 4:1, 2.
14, 15. Ẹ̀rí wo ni ó wà pé ìwà rere takọtabo ti jó rẹ̀yìn jákèjádò ayé?
14 Gbé ìròyìn tí ìwé agbéròyìnjáde The New York Times sọ yẹ̀ wò: “Ohun tí àwọn ènìyàn ní ọdún 25 ṣéyìn kà sí ohun tí ń múni gbọ̀n rìrì ti di ìṣètò àjọgbépọ̀ tí a tẹ́wọ́ gbà nísinsìnyí. Iye àwọn tọkọtaya tí ó yàn láti máa gbé pọ̀ dípò ṣíṣègbéyàwó ti lọ sókè sí ìpín 80 nínú ọgọ́rùn-ún [ní United States] láàárín ọdún 1980 sí 1991.” Èyí kì í ṣe ohun tí ń ṣẹlẹ̀ ní Àríwá America nìkan. Ìwé ìròyìn Asiaweek ròyìn pé: “Ìjiyàn kan nípa àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ ń lọ lọ́wọ́ ní àwọn orílẹ̀-èdè jákèjádò [Éṣíà]. Àríyànjiyàn náà ni òmìnira ìbálòpọ̀ àti àwọn ìlànà àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀, agbára ìdarí láti ṣe ìyípadà sì ń ga sí i léraléra.” Ìṣirò fi hàn pé iye àwọn tí ó tẹ́wọ́ gba panṣágà àti ìbálòpọ̀ ṣáájú ìgbéyàwó túbọ̀ ń ga sí i ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀.
15 Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé ìgbòkègbodò oníwà ìkà gbáà yóò máa pọ̀ sí i ní ọjọ́ wa. (Ìṣípayá 12:12) Nígbà náà, kò yẹ kí ó yà wá lẹ́nu pé ìwà abèṣe túbọ̀ ń gbalẹ̀ sí i lọ́nà tí ń dẹ́rù bani. Fún àpẹẹrẹ, fífi ìbálòpọ̀ kó àwọn ọmọdé nífà ti tàn kálẹ̀.a Ètò Àjọ Àkànlò Owó Ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè fún Àwọn Ọmọdé ròyìn pé “ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ ní gbogbo orílẹ̀-èdè lágbàáyé ni òwò fífi ìbálòpọ̀ kóni nífà ti ń ṣàkóbá fún àwọn ọmọdé.” Lọ́dọọdún, “iye tí ó lé ní mílíọ̀nù 1 àwọn ọmọdé jákèjádò ayé ni a ròyìn pé a ń fipá mú wọnú ṣíṣe iṣẹ́ aṣẹ́wó, tí a ń gbé lọ sí ilẹ̀ míràn tí a sì ń tà fún ète ìbálòpọ̀, tí a sì ń lò fún mímú àwọn àwòrán arùfẹ́ ìṣekúṣe sókè jáde.” Ìbẹ́yà kan náà lò pọ̀ tún wọ́pọ̀, tí àwọn òṣèlú àti àwọn aṣáájú ìsìn kan sì máa ń mú ipò iwájú ní gbígbé e lárugẹ gẹ́gẹ́ bí “ọ̀nà míràn láti gbà gbé ìgbésí ayé.”
Kíkọ Ìwà Abèṣe Inú Ayé Sílẹ̀
16. Ìdúró wo ni Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń mú ní ti ìwà rere takọtabo?
16 Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò gbà pẹ̀lú àwọn tí wọ́n fọwọ́ sí ọ̀pá ìdiwọ̀n ìgbọ̀jẹ̀gẹ́ ní ti ọ̀ràn ìbálòpọ̀. Títù 2:11, 12 sọ pé: “Inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run tí ń mú ìgbàlà wá fún gbogbo onírúurú ènìyàn ni a ti fi hàn kedere, ó ń fún wa ní ìtọ́ni láti kọ àìṣèfẹ́ Ọlọ́run jù sílẹ̀ àti àwọn ìfẹ́ ọkàn ti ayé àti láti gbé pẹ̀lú ìyè kooro èrò inú àti òdodo àti ìfọkànsin Ọlọ́run nínú ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan ìsinsìnyí.” Bẹ́ẹ̀ ni, a ń mú ìkórìíra gidi, ìkórìíra tẹ̀gàntẹ̀gàn, dàgbà fún irú ìwà abèṣe bí ìbálòpọ̀ ṣáájú ìgbéyàwó, panṣágà, àti ìbẹ́yà kan náà lò pọ̀.b (Róòmù 12:9; Éfésù 5:3-5) Pọ́ọ̀lù gbani ní ìyànjú yìí: “Kí gbogbo ẹni tí ń pe orúkọ Jèhófà kọ àìṣòdodo sílẹ̀ ní àkọ̀tán.”—Tímótì Kejì 2:19.
17. Ojú wo ni àwọn Kristẹni tòótọ́ fi ń wo ọtí mímu?
17 Àwọn Kristẹni tòótọ́ ń kọ ojú ìwòye tí ayé ní sílẹ̀ nípa àwọn ìwà abèṣe tí ó jọ bíi pé kò tó nǹkan. Fún àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ ènìyàn lónìí ń wo ìmutípara gẹ́gẹ́ bíi fàájì lásán. Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn Jèhófà ń ṣègbọràn sí ìmọ̀ràn inú Éfésù 5:18 pé: “Ẹ má ṣe máa mu ọtí wáìnì ní àmupara, nínú èyí tí ìwà wọ̀bìà wà, ṣùgbọ́n ẹ máa kún fún ẹ̀mí.” Bí Kristẹni kan bá yàn láti mutí, yóò ṣe bẹ́ẹ̀ ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì.—Òwe 23:29-32.
18. Báwo ni àwọn ìlànà Bíbélì ṣe ń darí àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà nínú ìbálò wọn pẹ̀lú àwọn mẹ́ńbà ìdílé wọn?
18 Gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Jèhófà, a tún kọ ojú ìwòye tí àwọn kan nínú ayé ní pé jíjágbe àti pípariwo mọ́ alábàáṣègbéyàwó ẹni àti àwọn ọmọ ẹni tàbí yíyọ èébú lára wọn jẹ́ ìwà tí ó ní ìtẹ́wọ́gbà. Pẹ̀lú ìpinnu láti tọ ipa ọ̀nà ìwà funfun, àwọn tọkọtaya Kristẹni ń ṣiṣẹ́ pọ̀ láti fi ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù sílò pé: “Kí ẹ mú gbogbo ìkorò onínú burúkú àti ìbínú àti ìrunú àti ìlọgun àti ọ̀rọ̀ èébú kúrò lọ́dọ̀ yín pa pọ̀ pẹ̀lú gbogbo ìwà búburú. Ṣùgbọ́n kí ẹ di onínúrere sí ara yín lẹ́nì kíní kejì, ní fífi ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ hàn, kí ẹ máa dárí ji ara yín lẹ́nì kíní kejì fàlàlà gan-an gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run pẹ̀lú ti tipasẹ̀ Kristi dárí jì yín fàlàlà.”—Éfésù 4:31, 32.
19. Báwo ni ìwà abèṣe ṣe kún inú ayé òwò tó?
19 Ìwà àbòsí, jìbìtì, irọ́ pípa, òwò gbájúẹ̀, àti olè jíjà pẹ̀lú wọ́pọ̀ lónìí. Àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé ìròyìn òwò CFO ròyìn pé: “Ìwádìí àwọn 4,000 òṣìṣẹ́ . . . fi hàn pé ìpín 31 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn tí a ṣèwádìí nípa wọn ti rí ‘ìwàkiwà burúkú bùrùjà’ ní ọdún tí ó ṣáájú.” Irú ìwàkiwà bẹ́ẹ̀ ní irọ́ pípa, ìwé yíyí, ìfìbálòpọ̀ fòòró ẹni, àti olè jíjà nínú. Bí a óò bá máa bá a lọ ní wíwà ní mímọ́ ní ti ìwà híhù lójú Jèhófà, a gbọ́dọ̀ yẹra fún irú ìwà bẹ́ẹ̀, kí a sì jẹ́ aláìlábòsí nínú ìbálò wa ní ti ìṣúnná owó.—Míkà 6:10, 11.
20. Èé ṣe tí àwọn Kristẹni ṣe ní láti yẹra fún “ìfẹ́ owó”?
20 Ṣàgbéyẹ̀wò ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí ọkùnrin kan tí ó ronú pé òun yóò ní àkókò púpọ̀ sí i fún iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run bí òun bá jèrè gọbọi nínú okòwò òun. Ó fa àwọn ẹlòmíràn sínú okòwò kan nípa lílénu fún wọn pé èrè gọbọi ni yóò wọlé fún wọn. Nígbà tí nǹkan kò rí bí ó ṣe retí, ó di ẹni tí ó gbékú tà láti jèrè owó gọbọi tí ó pàdánù pa dà, débi pé ó jí owó tí a fi pa mọ́ sí i lọ́wọ́. Nítorí ìgbésẹ̀ rẹ̀ àti àìronúpìwàdà rẹ̀, a yọ ọ́ lẹ́gbẹ́ kúrò nínú ìjọ Kristẹni. Òtítọ́ gidi ni ìkìlọ̀ Bíbélì náà jẹ́ pé: “Àwọn wọnnì tí wọ́n pilẹ̀ pinnu láti di ọlọ́rọ̀ máa ń ṣubú sínú ìdẹwò àti ìdẹkùn àti ọ̀pọ̀ àwọn ìfẹ́ ọkàn òpònú àti aṣenilọ́ṣẹ́, èyí tí ń ri ènìyàn sínú ìparun àti ìrunbàjẹ́. Nítorí ìfẹ́ owó ni gbòǹgbò onírúurú ohun aṣeniléṣe gbogbo, àti nípa nínàgà fún ìfẹ́ yìí a ti mú àwọn kan ṣáko lọ kúrò nínú ìgbàgbọ́ wọ́n sì ti fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrora gún ara wọn káàkiri.”—Tímótì Kíní 6:9, 10.
21. Ìwà wo ni ó wọ́pọ̀ láàárín àwọn ènìyàn ńlá nínú ayé, ṣùgbọ́n báwo ni àwọn tí wọ́n wà ní ipò pàtàkì nínú ìjọ Kristẹni ṣe ní láti hùwà?
21 Àwọn ènìyàn ńlá nínú ayé, tí wọ́n tún jẹ́ abẹnugan kì í sábà ní ìwà funfun, wọ́n sì máa ń fi ìjótìítọ́ ọ̀rọ̀ náà hàn pé, ‘Agbára máa ń gunni.’ (Oníwàásù 8:9) Ní àwọn ilẹ̀ kan, àbẹ̀tẹ́lẹ̀ àti àwọn ìwà ìbàjẹ́ mìíràn jẹ́ ọ̀nà ìgbésí ayé àwọn adájọ́, ọlọ́pàá, àti òṣèlú. Ṣùgbọ́n, àwọn tí ń mú ipò iwájú nínú ìjọ Kristẹni gbọ́dọ̀ jẹ́ oníwà funfun, wọn kò sì gbọ́dọ̀ jẹ olúwa lé àwọn ẹlòmíràn lórí. (Lúùkù 22:25, 26) Àwọn alàgbà, àti àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́, kì í ṣiṣẹ́ sìn “nítorí ìfẹ́ fún èrè àbòsí.” Wọ́n gbọ́dọ̀ yẹra fún ìdánwò èyíkéyìí láti yí ìdájọ́ po tàbí láti jẹ́ kí a lo agbára lórí ìdájọ́ wọn nítorí ìfojúsọ́nà àtikó ọrọ̀ jọ.—Pétérù Kíní 5:2; Ẹ́kísódù 23:8; Òwe 17:23; Tímótì Kíní 5:21.
22. Kí ni àpilẹ̀kọ tí ó tẹ̀ lé e yóò jíròrò?
22 Ní gbogbogbòò, àwọn Kristẹni ń ṣàṣeyọrí nínú kíkojú ìpèníjà òde òní ti pípa ìwà funfun mọ́ nínú ayé wa tí ó kún fún ìwà abèṣe. Síbẹ̀, ìwà funfun ní nínú ju yíyẹra fún ìwà ibi lọ. Àpilẹ̀kọ tí ó tẹ̀ lé e yóò jíròrò ohun tí mímú ìwà funfun dàgbà ń béèrè fún ní ti gidi.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ náà, “Dáàbòbo Awọn Ọmọ Rẹ!,” tí ó fara hàn nínú Jí! October 8, 1993.
b Àwọn tí wọ́n ti lọ́wọ́ nínú ìwà ìbẹ́yà kan náà lò pọ̀ tẹ́lẹ̀ rí lè yí ìwà wọn pa dà, bí àwọn kan ti ṣe ní ọ̀rúndún kìíní. (Kọ́ríńtì Kíní 6:11) A pèsè ìsọfúnni tí ó wúlò nínú Jí! March 22, 1995, ojú ìwé 21 sí 23.
Àwọn Kókó fún Àtúnyẹ̀wò
◻ Èé ṣe tí Jèhófà fi pàṣẹ pé kí a pa àwọn ará Kénáánì run ráúráú?
◻ Àwọn ìwà abèṣe wo ni ó wọ́pọ̀ ní ọ̀rúndún kìíní, báwo sì ni àwọn Kristẹni ṣe ṣe sí nínú irú àyíká bẹ́ẹ̀?
◻ Ẹ̀rí wo ni ó wà pé ayé ti rí ìwà rere tí ń jó rẹ̀yìn jákèjádò ayé láti ọdún 1914?
◻ Àwọn ìwà abèṣe tí ó wọ́pọ̀ wo ni àwọn ènìyàn Jèhófà gbọ́dọ̀ kọ̀ sílẹ̀?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní jẹ́ oníwà funfun, bí wọ́n tilẹ̀ gbé nínú ayé tí ó kún fún ìwà abèṣe
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Ìwà abèṣe ti wọ inú ìgbékalẹ̀ ìsokọ́ra kọ̀ǹpútà pàápàá, ní fífún ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ àti àwọn mìíràn láǹfààní láti wo àwọn àwòrán arùfẹ́ ìṣekúṣe sókè
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Àwọn Kristẹni gbọ́dọ̀ pa ìwà funfun mọ́, láìfara wé ọgbọ́n àbòsí àwọn ẹlòmíràn