Ṣíṣiṣẹ́sìn Pẹ̀lú Òye Ìmọ̀lára Ìjẹ́kánjúkánjú
GẸ́GẸ́ BÍ HANS VAN VUURE ṢE SỌ Ọ́
Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kan ní 1962, Paul Kushnir, alábòójútó ẹ̀ka Watch Tower Society ní Netherlands, bá mi pàdé ní àgbègbè èbúté ọkọ̀ òkun ti Rotterdam. Bí ó ti ń wò mi lódìkejì tábìlì nínú ilé-àrójẹ kan tí a tanná tí ń jó lọ́úlọ́ú sí, ó sọ pe: “Ǹjẹ́ o mọ̀, Hans, pè bí ìwọ bá tẹ́wọ́gba iṣẹ́-àyànfúnni yìí, kìkì tíkẹ́ẹ̀tì àlọ ni ìwọ àti aya rẹ yóò rígbà?”
“BẸ́Ẹ̀NI, ò sì dá mi lójú ṣáká pé Susie pẹ̀lú yóò fohùnṣọ̀kan pẹ̀lú ìyẹn.”
“Ó dára, jíròrò rẹ̀ pẹ̀lú Susie. Ẹ sì jẹ́ kí n mọ èrò yín bí ó bá ti lè ṣeéṣe kí ó yá tó.”
Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì ó rí ìdáhùn wa gbà: “Àwa yóò lọ.” Nítorí náà ní December 26, 1962, a gbá àwọn ìbátan àti ọ̀rẹ́ mọ́ra ní Ibùdókọ̀-Òfuurufú Schiphol ti Amsterdam tí ó kún fún òjò dídì, a sì bá ọkọ̀ òfuurufú lọ sí ìpínlẹ̀ ìjíhìn-iṣẹ́-Ọlọ́run titun kan—Netherlands New Guinea (tí ń jẹ́ West Irian, Indonesia nísinsìnyí)—ilẹ̀ àwọn ará Papua.
Ǹjẹ́ a ní iyèméjì nípa títẹ́wọ́gba iṣẹ́-àyànfúnni tí ń peniníjà yìí bí? Bẹ́ẹ̀kọ́ rárá. A ti fi tọkàntọkàn ya ìgbésí-ayé wa sí mímọ́ fún ṣíṣe ìfẹ́-inú Ọlọrun, a sì nígbẹ̀ẹ́kẹ̀lé pé òun yòó tì wá lẹ́yìn. Bí a ti ń ronú sẹ́yìn nípa ìgbésí-ayé wa, a lè ríi pé ìgbọ́kànlé wa nínú Jehofa ni a kò tíì ṣì gbé. Ṣùgbọ́n ṣáájú sísọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ní Indonesia, jẹ́ kí n sọ fún ọ nípa àwọn ọdún ìbẹ̀rẹ̀ wa.
Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Ìgbà Ogun
Nígbà tí Arthur Winkler Ẹlẹ́rìí onígboyà yẹn kọ́kọ́ bẹ ìdílé mi wò ní 1940, mo jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́wàá péré. Àwọn òbí mi takìjí nígbà tí wọ́n ṣàwárí ohun tí Bibeli ní láti sọ nípa àwọn ẹ̀kọ́ èké Kristẹndọm. Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé Nazi ti Germany gba Netherlands kan nígbà náà tí a sì ń ṣenúnibíni sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, àwọn òbí mi nílati pinnu yálà láti darapọ̀ mọ́ ètò-àjọ kan tí a ti fòfindè. Wọ́n pinnu láti ṣe bẹ́ẹ̀.
Lẹ́yìnwá ìgbà náà, ìgboyà màmá mi àti ìmúratàn rẹ̀ láti farawewu pípàdánù òmìnira àti ìwàláàyè wú mi lórí. Nígbà kan rí ó gun kẹ̀kẹ́ kìlómítà mọ́kànlá ó sì dúró nínú òkùnkùn pẹ̀lú báàgì kan tí ó kún fún àwọn ìwé-àṣàrò-kúkúrú Bibeli. Ní àkókò tí a ti yàn fún àkànṣe ìgbétáásì láti bẹ̀rẹ̀, ó yára wa kẹ̀kẹ́ náà bí ó ti lè ṣe tó, ó ń tọwọ́ bọ inú báàgì rẹ̀ déédéé, ó sì ń fọ́n àwọn ìwé-àṣàrò-kúkúrú káàkiri òpópónà. Ọkùnrin kan tí ń fi kẹ̀kẹ́ lé e bá a nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, bí ó sì ti ń mí hẹlẹhẹlẹ, ó kígbe pé: “Obìnrin yìí, obìnrin yìí, o ń pàdánù ohun kan!” A rẹ́rìn-ín àríntàkìtì nígbà tí Màmá sọ ìtàn yìí fún wa.
Mo kéré púpọ̀, ṣùgbọ́n mo mọ ohun tí mo fẹ́ láti fi ìgbésí-ayé mi ṣe. Nígbà ti a ń ṣe ọ̀kan nínú àwọn ìpàdé wa lọ́wọ́ ní àárín ọdún 1942, nígbà tí olùdarí béèrè pe, “Ta ni ó fẹ́ láti ṣèrìbọmi ní àkókò-ìṣẹ̀lẹ̀ tí ń bọ̀?” Mo náwọ mi sókè. Àwọn òbi mi wo araawọn lójú pẹ̀lú ìdààmú, ní ṣíṣiyèméjì pé bóyá ni mo lóye ìjẹ́pàtàkì irú ìpinnu bẹ́ẹ̀. Àní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọ ọdún méjìlá péré ni mi, mo lóye ohun tí ìyàsímímọ́ sí Ọlọrun túmọ̀sí.
Wíwàásù láti ilé dé ilé bí àwọn Nazi tí ń lépa wa béèrè fún ìṣọ́ra. Láti yẹra fún ṣíṣèbẹ̀wò sí ilé àwọn wọnnì tí wọ́n lè fi wá sùn ohun tí mo máà ń ṣe ni pé, ní àwọn ọjọ́ tí àwọn alátìlẹ́yìn Nazi bá lẹ ìwé ìsọfunni mọ ara wíńdò wọn, èmi yóò gun kẹ̀kẹ́ káàkiri èmi yóò sì kọ àdírẹ́sì wọ́n sílẹ̀. Lẹ́ẹ̀kan rí ọkùnrin kan ṣàkíyèsí mi ó sì kérara pé: “Ó káre láé, ọmọ mi. Kọ orúkọ wọn sílẹ̀—gbogbo wọn pátá!” Mo ní ìháragàgà ṣùgbọ́n ó ṣe kedere pé òye mi kò pọ̀ tó! Ní ìparí ogun náà ní 1945, inú wa dùn sí ìfojúsọ́nà fún òmìnira púpọ̀ síi láti wàásù.
Ìbẹ̀rẹ̀ Iṣẹ́ Ìgbésí-Ayé Kan
Ní November 1, 1948, lẹ́yìn tí mo ti parí lílọ sí ilé-ẹ̀kọ́, mo tẹ́wọ́gba iṣẹ́-àyànfúnni ìwàásù alákòókò kíkún mi àkọ́kọ́ gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà. Ní oṣù kan lẹ́yìn náà Arákùnrin Winkler bẹ ìdílé tí mo ń bá gbé wò. Ó ti gbọ́dọ̀ jẹ́ pé ó wá láti mọ irú ẹni tí mo jẹ́ ni nítorí láìpẹ́ lẹ́yìn náà a késí mi láti ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka ọ́fíìsì Society ní Amsterdam.
Nígbà tí ó yá, a sọ fún mi láti bẹ ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa wò gẹ́gẹ́ bí alábòójútó àyíká. Lẹ́yìn náà, ní ìgbà ìwọ́wé 1952, mo rí ìkésíni kan gbà láti lọ sí kíláàsì kọkànlélógún ti Watchtower Bible School of Gilead ní New York láti gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ míṣọ́nárì. Nítorí náà, ní apá ìparí ọdún 1952, àwa mẹ́jẹ̀ẹ̀jọ tí a ti Netherlands wá wọ ọkọ̀ òkun náà Nieuw Amsterdam a sì rìnrìn-àjò ojú-omi lọ sí America.
Nígbà tí ó kù díẹ̀ kí ìtòlẹ́sẹẹsẹ ẹ̀kọ́ náà parí, Maxwell Friend, ọ̀kan lára àwọn olùkọ́, sọ pé: “Ẹ̀yin yóò gbàgbé púpọ̀ nínú àwọn ohun tí ẹ ti kọ́ níbí, ṣùgbọ́n a nírètí pé àwọn ohun mẹ́ta kò ní fi yín sílẹ̀: ìgbàgbọ́, ìrètí, àti ìfẹ́.” Àwọn ohun ìrántí ṣíṣeyebíye nípa ètò-àjọ Jehofa tí ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú òye-ìmọ̀lára ìjẹ́kánjúkánjú ni mo tún pamọ́ sínú èrò-inú àti ọkàn-àyà mi.
Lẹ́yìnwá ìgbà náà ìjákulẹ̀ ńlá kan dé bá mi. Ìdajì nínú àwùjọ àwa tí a ti Netherlands wá—títíkan èmi náà—ni a yanṣẹ́ fún láti padà lọ sí Netherlands. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ní ìjákulẹ̀, ọkàn mi kò gbọgbẹ́. Mo kàn ṣáà nírètí pé èmi kì yóò dúrò, bíi ti Mose ìgbàanì, fún ogójì ọdún kí ń tó rí iṣẹ́-àyànfúnni gbà sí ilẹ̀ òkèèrè.—Iṣe 7:23-30.
Alábàáṣègbéyàwó tí Ó Jẹ́ Ẹni Ọ̀wọ́n fún Mi
Nígbà tí Fritz Hartstang, ọ̀rẹ́ kan tí ó dàbí bàbá fún mi, gbọ́ nípa ìwéwèé ìgbéyàwó mi, ó finú hàn mí pé: “Agbára káká ni èmi fi lè ronú nípa yíyàn kan tí ó sànjù.” Bàbá Susie, Casey Stoové, ti jẹ́ amúpò iwájú nínú Àjọ tí ń bá àwọn aláṣẹ Nazi jà nígba Ogun Àgbáyé Kejì. Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn Ẹlẹ́rìí ṣe ìkésíni sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ ní 1946, pẹ̀lú ìmúratán ni ó fi tẹ́wọ́gba àwọn òtítọ́ Bibeli. Láìpẹ́ òun àti mẹ́ta nínú àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́fà—Susie, Marian, àti Kenneth—ni a baptisi. Ní May 1, 1947, gbogbo àwọn ọmọ wọ̀nyí bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́-òjíṣẹ́ alákòókò kíkún gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà. Ní 1948, Casey ta iṣẹ́-àmójútó rẹ̀ fún ẹlòmíràn, òun pẹ̀lú sì bẹ̀rẹ̀ síi ṣe aṣáájú-ọ̀nà. Lẹ́yìn náà ó sọ ọ̀rọ̀ àkíyèsí yìí: “Àwọn ọdún wọ̀nyẹn ni wọ́n mú mi láyọ̀ jùlọ nínú ìgbésí-ayé mi!”
Mo mọ Susie gẹ́gẹ́ bí ẹnìkan ní 1949, nígbà tí a késí i láti wá ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka ọ́fíìsì Amsterdam. Bí ó ti wù kí ó rí, ní ọdún tí ó tẹ̀lé e, òun àti àbúrò rẹ̀ obìnrin Marian ti ibẹ̀ lọ sí kíláàsì kẹrìndínlógún ti Gileadi wọ́n sì wọkọ̀ ojú-omi lọ síbi iṣẹ́ àyànfúnni wọn gẹ́gẹ́ bí mísọ́nárì—Indonesia. Ní February 1957, lẹ́yìn ọdún márùn-ún ti iṣẹ́-ìsìn míṣọ́nárì níbẹ̀, Susie padà wá sí Netherlands láti fẹ́ mi. Ni àkókò yẹn, mo ń ṣiṣẹ́sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó àyíká, léraléra ni òun sì ti ṣàṣefihàn ìmúratán láti dá ṣe àwọn ìrúbọ nítorí iṣẹ́-ìsìn Ìjọba náà, jálẹ̀ àwọn ọdún ìgbéyàwó wa.
Lẹ́yìn ètò ìgbéyàwó wa, a ń báa lọ láti máa bẹ àwọn ìjọ wò ní àwọn apá ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ní Netherlands. Àwọn ọdún ti Susie ti lò fún iṣẹ́ míṣọ́nárì ní àwọn ibi iṣẹ́-àyànfúnni nínira ti múra rẹ̀ sílẹ̀ dáradára fún àwọn ìrìn-àjò kéékèèké wa lórí kẹ̀kẹ́ láti ìjọ kan sí òmíràn. Ní àkókò náà tí a fi wà lẹ́nu iṣẹ́ àyíká ní 1962 ni Arákùnrin Kushnir bẹ̀ mí wò ní Rotterdam tí ó sì késí wa láti ṣí lọ sí West Irian, Indonesia.
Iṣẹ́-Ìsìn Míṣọ́nárì ní Indonesia
A gúnlẹ̀ sí ìlú Manokwari—apá ilẹ̀-ayé kan tí ó yàtọ̀ pátápátá! Àwọn ìró ọwọ́ alẹ́ ti ilẹ̀ olóoru tí ń banilẹ́rù àti ooru àti erukuru wà. Àwọn ará Papua tí wọ́n ti ààrin ìlú wá sì tún wà níbẹ̀ tí wọ́n ń wọ kìkì aṣọ-ìpèlé, tí wọ́n ń mú àdá dání, tí wọ́n fẹ́ràn láti máa rìn tọ̀ wá lẹ́yìn kí wọ́n sì máa fọwọ́ kan awọ ara wa tí ó funfun—gbogbo èyí kò rọrùn láti mọ́ wa lára.
Láàárín àwọn ọ̀sẹ̀ díẹ̀ tí a débẹ̀, àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì ka lẹ́tà kan láti orí àga ìwàásù ní ṣíṣèkìlọ̀ lòdìsí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, wọ́n sì fi ẹ̀dà rẹ̀ fún gbogbo àwọn tí ó pésẹ̀. Ibùdó ilé-iṣẹ́ radio tí ó wà ládùúgbò tilẹ̀ gbé lẹ́tà náà jáde lórí afẹ́fẹ́. Lẹ́yìn náà ni àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì bẹ̀ wá wò tí wọ́n sì fi dandangbọ̀n sọ pé kí a kọjá lọ sí ààrin ìlú láti ṣiṣẹ́ láàárín àwọn tí wọ́n kà sí “abọ̀rìṣà.” Ọ̀gá ọlọ́pàá onípò-gíga kan ni Papua ni òun pẹ̀lú tún sọ fún wa láti fi ibẹ̀ sílẹ̀, mẹ́ḿbà kan nínú àwọn ọlọ́pàá inú náà sọ fún wa pé wọ́n ti ń wéwèé láti pa wá.
Síbẹ̀, kìí ṣe gbogbo ènìyàn ni ó takò wá. Òṣèlú olùgbaninímọ̀ràn kan fún àwọn ará Papua, tí ó jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ Netherlands tí ó ti fẹ́ ṣí lọ sí Netherlands, mú wa mọ àwọn ìjòyè Papua mélòókan. “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa yóò mú irú ìsìn Kristian kan wá tí ó sàn ju èyí tí ẹ ti mọ̀ lọ,” ni òun sọ fún wọn. “Nítorí náà, ẹ nílatí gbà wọ́n tọwọ́-tẹsẹ̀.”
Nígbà tí ó yá, ìjòyè-òṣìṣẹ́ ìjọba kan tọ Susie wá lójú pópó ó sì sọ̀rọ̀ wúyẹ́wúyẹ́ pé: “Wọn ti ròyìn rẹ̀ fún wa pé ẹ ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ titun kan níbí, àti, nítorí náà, àwa kò lè jẹ́ kí ẹ dúró. Ṣùgbọ́n, hẹn-ẹn, . . . kìkì bí ẹ bá lè ní ṣọ́ọ̀ṣì kan.” Ìtanilólobó! Kíá a ti wó àwọn ògiri ní ilé wa, a to àwọn aga gbọọrọ kalẹ̀, à gbé tábìlì ìbánisọ̀rọ̀ dúró, a sì gbé àmì kan síwájú ìta tí ó kà pé “Gbọ̀ngàn Ìjọba.” Lẹ́yìn náà a késí òṣìṣẹ́-olóyè náà láti ṣèbẹ̀wò. Ó mirí, ó rẹ́rìn-ín músẹ́, ó sì fi ìka-ìlábẹ̀ rẹ̀ gbá ẹ̀bá orí pẹ́pẹ́, ó wá dàbí ẹni ń sọ pé, ‘Ọgbọ́n pọ̀, ọgbọ́n pọ̀.’
Ní June 26, 1964, ọdún kan àti ààbọ̀ lẹ́yìn tí a gúnlẹ̀ síbẹ̀, àwọn méjìlá àkọ́kọ́ nínú àwọn ará Papua tí wọ́n jẹ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli wa ni a baptisi. Láìpẹ́, àwọn mẹ́wàá síi tún tẹ̀lé e, ìpíndọ́gba àwọn tí ń wá sí ìpàdé wa sì wọ ogójì. Àwọn aṣáájú-ọ̀nà ará Indonesia méjì ni a rán wá lati ràn wá lọ́wọ́. Nígbà tí ìjọ ti fìdímúlẹ̀ dáradára ní Manokwari, ẹ̀ka ti Society ní Indonesia fún wa ní ibi iṣẹ́-àyànfúnni ìwàásù mìíràn, ní December 1964.
Ṣáájú kí a tó kúrò, olórí fún Ẹ̀ka-Iṣẹ́ Ìpèsè-Ìsọfúnni fún Aráàlú ti ìjọba bá wa sọ̀rọ̀ níkọ̀kọ̀ ó sì wí pé: “O dún mi pé ẹ ń fi wá sílẹ̀. Lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ ni àlùfáà ń jírẹ̀ẹ́bẹ̀ fún mi láti lé yín kúrò nítorí wọ́n sọ pé ẹ ń jí èso wọn ká mọ́ wọn lọ́wọ́. Ṣùgbọ́n mo sọ fún wọn pé: ‘Bẹ́ẹ̀kọ́, kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n ń bùlẹ̀dú sídìí igi yin ni.’” Ó fikún un pé: “Níbikíbi tí ẹ bá lọ, ẹ máa jà nìṣó. Ẹ̀yin yóò ṣẹ́gun!”
Láàárín Ìfipá-Gba-Ìjọba
Ní alẹ́ ọjọ́ kan ní September 1965, nígbà tí a ń ṣiṣẹ́sìn ní olú-ìlú, Djakarta, àwọn ọlọ̀tẹ̀ Kọmunist pa ọ̀pọ̀ àwọn aṣáájú ológun, wọ́n dánásun Djakarta, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ ìjàkadì kan jákèjádò ìlú èyí tí ó wá yọrí nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín sí gbígbàjọba mọ́ Sukarno, ààrẹ orílẹ̀-èdè náà lọ́wọ́. Nǹkan bíi ogún ọ̀kẹ́ pàdánù ìwàláàyè wọn!
Nígbà kan a ń wàásù lọ́wọ́ nígbà tí ó jẹ́ pé ìbọn yíyìn àti ilé jíjó ń lọ lọ́wọ́ ní òpópónà kejì. Ní ọjọ́ tí ó tẹ̀lé e a gbọ́ pé àwọn ológun ti fẹ́ láti ba ilé-lílò ti àwọn Kọmunist tí ó wà nítòsí jẹ́. Ẹ̀rù jìnnìjìnnì hàn lójú àwọn onílé bí a tí ń tọ̀ wọ́n lọ, ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n gbọ́ àwọn ìhìn-iṣẹ́ Bibeli wa, ara wọn rọ̀ wọ̀ọ̀ wọ́n sì késí wa wọnú ilé. Wíwà wa pẹ̀lú wọn mú wọn nímọ̀lára wíwà láìséwu. Àkókò yẹn kọ́ gbogbo wa láti gbáralé Jehofa kí a sì pa ìwàdéédéé mọ́ lábẹ́ àwọn ipò tí kò báradé.
A Bóri Àtakò Síwájú Síi
Ní apá ìparí 1966 a ṣí lọ sí ilú Ambon ní gúúsù ẹlẹ́wà ti erékùṣù Molucca. Níbẹ̀, láàárín àwọn olùgbé ìlú oníwà-bí-ọ̀rẹ́, àti aláraáyọ̀mọ́ni náà, a rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ tí ó nífẹ̀ẹ́ sí ohun tẹ̀mí. Ìjọ wa kékeré yára gbèrú, iye àwọn tí ń wá sí ìpàdé sì súnmọ́ ọgọ́rùn-ún kan. Nítorí náà àwọn olóyè inú ṣọ́ọ̀ṣì Kristẹndọm lọ sí Ilé-Iṣẹ́ fún Àwọn Àlámọ̀rí Ìsìn láti fipá mú olórí wọn níbẹ̀ pé kí ó lé wa kúrò ní Ambon. Ṣùgbọ́n níbẹ̀ lórí tábìlì ìkọ̀wé olórí náà, wọ́n rí àwọn ìwé Watch Tower Society tí a fi sí ibi tí ojú ti lè tó o! Bí wọ́n ti kùnà láti yí ọkàn olórí náà padà, wọ́n tọ àwọn ìjòyè-òṣìṣẹ́ Ẹ̀ka-Iṣẹ́ Ìjọba tí Ń Bójútó Ọ̀ràn Ìsìn lọ ni Djakarta, ní wíwá ọ̀nà láti lé wa jáde kìí ṣe kúrò ni Ambon nìkan ṣùgbọ́n ní gbogbo Indonesia pẹ̀lú.
Lákòókò yìí ó dàbí ẹni pé wọ́n ṣàṣeyọrí, nítorí pé February 1, 1968, ni wọ́n dá gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ ìlékúrò wa. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn Kristian arákùnrin wa ní Djakarta tọ olóyè Musulumi gíga kan lọ ní Ẹ̀ka-Iṣẹ́ Ìjọba tí ń bójútó ọ̀ràn Ìsìn, ó sì ṣèrànwọ́ láti yí ìpinnu náà padà. Ní àfikún síi, ìlànà-ètò kan tí ó ti wà tẹ́lẹ̀rí ni a yípadà, a sí fún àwọn míṣọ́nárì mìíràn síi ní ìyọ̀ǹda láti wọlé wá.
Nípa báyìí, láàárín ọdún mẹ́wàá tí ó tẹ̀lé e, nínú àyíká kan tí ó ní àwọn òkè-ńlá, ẹgàn, àti àwọn adágún pípinmirin ní ìhà-àríwá Sumatra, a ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn míṣọ́nárì tí wọ́n wá láti Australia, Austria, Germany, Philippines, Sweden, àti United States. Iṣẹ́ ìwàásù náà láásìkí, pàápàá jùlọ láàárín àwùjọ ẹ̀yà-ìran tí ó pọ̀ jùlọ ní ẹkùn náà, àwọn Batak.
Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn olùhùmọ̀ nípa ìsìn kẹ́sẹjárí nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín ní mímú kí a fòfinde iṣẹ́ ìwàásù wa ní December 1976, ọ̀pọ̀ jùlọ nínú àwọn míṣọ́nárì sì fi ibẹ̀ sílẹ̀ lọ síbi àwọn iṣẹ́-àyànfúnni ní àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn ní ọdún tí ó tẹ̀lé e. Lákòótán, ní 1979, àwa pẹ̀lú níláti lọ.
Sí South America
Ní báyìí a ti tó nǹkan bíi ẹni àádọ́ta ọdún, a sì ń ṣe kàyééfì bí a bá ṣì lè ṣèyípadà mú araawa bá orílẹ̀-èdè mìíràn mu. “Àwa yóò ha tẹ́wọ́gba iṣẹ́-àyànfúnni titun tàbí kàkà bẹ́ẹ̀ kí a kúkú fìdíkalẹ̀ síbìkan?” ni Susie béèrè.
“Ó dára, Susie,” ni mo fèsìpadà, “ìbikíbi tí Jehofa késí wa láti lọ, ó bójútó wa níbẹ̀. Ta ni mọ irú àwọn ìbùkún síwájú síi wo ní ń bẹ ní ọjọ́-iwájú?” Nípa báyìí, a gúnlẹ̀ síbi iṣẹ́-àyànfúnni wa titun, orílẹ̀-èdè Suriname ti South America. Láàárín oṣù méjì a tún ti wà lẹnu iṣẹ́ arìnrìn-àjò ara wa sì ti mọlé.
Bi a ti ń ṣàtúnyẹ̀wò iye tí ó ju ọdún márùndínláàádọ́ta tí a lò nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ alákòókò kíkún, èmi àti Susie mọ bí ìtìlẹ́yìn àwọn òbí wa ti ṣe pàtàkì tó láti ràn wá lọ́wọ́ láti máa tẹ̀síwájú nìṣó nínú iṣẹ́ míṣọ́nárì. Ní 1969, nígbà tí mo rí àwọn òbí mi lẹ́ẹ̀kan síi lẹ́yìn ọdún mẹ́fà, bàbá mi pè mi sí ẹ̀gbẹ́ kan ó sì wí pé: “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé màmá rẹ ni ó kọ́kọ́ kú, kò pọndandan fún ọ láti wá sílé. Dúró sẹ́nu iṣẹ́-àyànfúnni rẹ. Màá dọ́gbọ́n araàmi. Ṣùgbọ́n bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé èmi ni, ìwọ níláti bi màmá rẹ léèrè nípa rẹ̀.” Ohun kan-náà ni Màmá sọ.
Àwọn òbí Susie ní ẹ̀mí-ìrònú àìmọ-tara-ẹni-nìkan kan-náà. Ìgbà kan tilẹ̀ wa tí ó jẹ́ pé Susie kò sí lọ́dọ̀ wọn fún ọdún mẹ́tàdínlógún, síbẹ̀ wọn kò jẹ́ kọ̀wé tí ń múni lọ́kàn pami sí i. Àmọ́ ṣáá o, ká sọ pé ko sí ìrànlọ́wọ́ mìíràn lárọ̀ọ́wọ́tó fún àwọn òbí wa ni, à bá ti padà sílé. Kókó tí ó wà níbẹ̀ ni pé, àwọn òbí wa ni ìdíyelé kan-náà fún iṣẹ́ míṣọ́nárì, títí tí wọ́n sì fi kú, wọ́n ti ṣiṣẹ́sin Jehofa pẹ̀lú òye ìmọ̀lára ìjẹ́kánjúkánjú kan-náà tí wọ́n ti gbìn sí wa lọ́kàn.—Fiwé 1 Samueli 1:26-28.
Àwa pẹ̀lú ni a ti fún níṣìírí nípasẹ̀ àwọn tí wọn ń kọ̀wé sí wa déédéé. Àwọn díẹ̀ wà tí wọn ko pa oṣù kan jẹ rí nínú kíkọ̀wé sí wa nínú iṣẹ́-ìsìn míṣọ́nárì wa tí ó lé ní ọgbọ̀n ọdún! Ṣùgbọ́n ju gbogbo rẹ̀ lọ, àwa kò jẹ́ gbàgbé Baba wa ọ̀wọ́n tí ń bẹ lọ́run, Jehofa, ẹni tí ó mọ bí òun ti ń gbé àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ orí ilẹ̀-ayé ró. Nítorí náà, bí a ti ń súnmọ́ òtéńté àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí a ti ń wọ̀nà fún, èmi àti Susie fẹ́ láti máa ‘fi wíwàníhìn-ín ọjọ́ Jehofa sọ́kàn pẹ́kípẹ́kí’ nípa bíbáa lọ làti máa ṣiṣẹ́sin Jehofa pẹ̀lú òye-ìmọ̀lára ìjẹ́kánjúkánjú.—2 Peteru 3:12, NW.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Mo ṣègbéyàwó ní 1957
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Ó ti múnilóríyá tó—àwọn ọ̀dọ́ mẹ́fà gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà!