ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w93 11/15 ojú ìwé 12-17
  • Fi Tìgboyà-Tìgboyà Rìn ní Àwọn Ọ̀nà Jehofa

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Fi Tìgboyà-Tìgboyà Rìn ní Àwọn Ọ̀nà Jehofa
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun tí Ìgboyà Jẹ́
  • Ìgboyà Láti Polongo Ìhìn-Iṣẹ́ Ọlọrun
  • Ìgboyà Lábẹ́ Àdánwò
  • Ìgboyà Láti Ṣègbọràn sí Ọlọrun
  • Ìgboyà Láti Dúró Pẹ̀lú Àwọn Ènìyàn Ọlọrun
  • Ìgboyà Láti ‘Tẹ̀lé Jehofa Pátápátá’
  • Ìgboyà Láti Gbẹ́kẹ̀lé Ọlọrun
  • Ìgboyà Láti Bọlá fún Jehofa kí A sì Gbé Ìjọsìn Mímọ́gaara Ga
  • “Jẹ́ Onígboyà Àti Alágbára Gidigidi”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Ẹ ní Ìgboyà Dáradára!
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Jẹ́ Onígboyà, Jèhófà Wà Pẹ̀lú Rẹ!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
  • “Jẹ́ Onígboyà . . . Kí O sì Gbé Ìgbésẹ̀”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2017
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
w93 11/15 ojú ìwé 12-17

Fi Tìgboyà-Tìgboyà Rìn ní Àwọn Ọ̀nà Jehofa

“Aláyọ̀ ni olúkúlùkù ènìyàn tí ń bẹ̀rù Jehofa, tí ń rìn ní àwọn ọ̀nà rẹ̀.” —ORIN DAFIDI 128:1, NW.

1, 2. Ìrànlọ́wọ́ wo ni àkọsílẹ̀ Bibeli nípa ọ̀rọ̀ àti ìṣe àwọn ẹlẹ́rìí Jehofa ní ìjímìjí lè ṣe fún wa?

Ọ̀RỌ̀ Mímọ́-Ọlọ́wọ̀ ti Jehofa kún fún àwọn àkọsílẹ̀ nípa àdánwò àti ayọ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ adúróṣinṣin. Àwọn ìrírí Noa, Abrahamu, Sara, Joṣua, Debora, Baraki, Dafidi, àti àwọn mìíràn ni a lè rí níti gidi nínú àwọn ojú-ewé rẹ̀. Gbogbo wọn jẹ́ ènìyàn gidi tí ó ti wà rí pẹ̀lú ohun pàtàkì kan tí ó wọ́pọ̀ nípa gbogbo wọn. Wọ́n ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọrun wọ́n sì fi tìgboyà-tìgboyà rìn ní àwọn ọ̀nà rẹ̀.

2 Ọ̀rọ̀ àti ìṣe àwọn ẹlẹ́rìí fún Jehofa ní ìgbà ìjímìjí lè fún wa níṣìírí bí a ti ń sakun láti rìn ní àwọn ọ̀nà Ọlọrun. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ayọ̀ yóò jẹ́ tiwa bí a ti ń fi ọ̀wọ̀ ńlá hàn fún Ọlọrun tí a sì ń fi ìbẹ̀rù pípéye láti máṣe mú un bínú hàn. Eyí jẹ́ òtítọ́ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ń dojúkọ àdánwò nínú ìgbésí-ayé, nítorí olórin náà tí a mísí kọrin pé: “Aláyọ̀ ni olúkúlùkù ènìyàn tí ń bẹ̀rù Jehofa, tí ń rìn ní àwọn ọ̀nà rẹ̀.”—Orin Dafidi 128:1, NW.

Ohun tí Ìgboyà Jẹ́

3. Kí ni ìgboyà jẹ́?

3 Láti rìn ní àwọn ọ̀nà Jehofa, a gbọ́dọ̀ ní ìgboyà. Níti tòótọ́, Ìwé Mímọ́ pàṣẹ fún àwọn ènìyàn Ọlọrun láti fi ànímọ́ yìí hàn. Fún àpẹẹrẹ, olórin náà Dafidi kọrin pé: “[Ẹ jẹ́ onígboyà, NW], yóò sì mú yín ní àyà le, gbogbo ẹ̀yin tí ó ní ìrètí níti Oluwa.” (Orin Dafidi 31:24) Ìgboyà jẹ́ “okun ti èrò-orí àti ti ìwàrere láti dágbálé, forítì, àti láti ko ewu, ìbẹ̀rù, tàbí ìṣòro lójú.” (Webster’s Ninth New Collegiate Dictionary) Ẹnìkan tí ó gbóyà jẹ́ alágbára, aláìṣojo, alákíkanjú. Pé Jehofa fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ní ìgboyà ṣe kedere láti inú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tí aposteli Paulu sọ fún alábàáṣiṣẹ́pọ̀ rẹ̀ Timoteu: “Ọlọrun kò fún wa ní ẹ̀mí ìbẹ̀rù; bíkòṣe ti agbára, àti ti ìfẹ́, àti ti inú tí ó yè kooro.”—2 Timoteu 1:7.

4. Kí ni ọ̀nà kan tí a lè gbà jèrè ìgboyà?

4 Ọ̀nà kan tí a lè gbà jèrè ìgboyà tí Ọlọrun fifúnni ni láti fi tàdúrà-tàdúrà gbé Ọ̀rọ̀ Jehofa, Bibeli yẹ̀wò. Púpọ̀ àwọn àkọsílẹ̀ tí ó farahàn nínú Ìwé Mímọ́ lè ràn wá lọ́wọ́ láti túbọ̀ nígboyà. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a kọ́kọ́ wo ohun tí a lè rí kọ́ láti inú àkọsílẹ̀ Ìwé Mímọ́ Lédè Heberu nípa àwọn kan tí wọ́n fi tìgboyà-tìgboyà rìn ní àwọn ọ̀nà Jehofa.

Ìgboyà Láti Polongo Ìhìn-Iṣẹ́ Ọlọrun

5. Báwo ni ìgboyà Enoku ṣe lè ṣàǹfààní fún àwọn ìránṣẹ́ Jehofa ní ọjọ́ tiwa?

5 Ìgboyà Enoku lè ran àwọn ìránṣẹ́ Jehofa òde-òní lọ́wọ́ láti fi tìgboyà-tìgboyà sọ̀rọ̀ ìhìn-iṣẹ́ Ọlọrun. Ṣáájú kí a tó bí Enoku, “àwọn ènìyàn bẹ̀rẹ̀ síí képe orúkọ [Jehofa, NW].” Àwọn ọ̀mọ̀wèé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan sọ pé àwọn ènìyàn “bẹ̀rẹ̀ lọ́nà ìsọdaláìmọ́” láti máa képe orúkọ Jehofa. (Genesisi 4:25, 26; 5:3, 6) Orúkọ àtọ̀runwá náà ni wọ́n ti lè fi pe àwọn ènìyàn tàbí òrìṣà. Fún ìdí yìí, ìsìn èké ń gbilẹ̀ nígbà tí a bí Enoku ní 3404 B.C.E. Níti tòótọ́, ó jọ pé òun nìkanṣoṣo ni ó ‘ń bá Ọlọrun rìn,’ ní bíbáa nìṣó ní ipa-ọ̀nà òdodo tí ó báramu pẹ̀lú àwọn òtítọ́ Jehofa tí a ṣípayá.—Genesisi 5:18, 24.

6. (a) Ìhìn-iṣẹ́ alágbára wo ni Enoku polongo? (b) Ìgbọ́kànlé wo ni a lè ní?

6 Enoku fi tìgboyà-tìgboyà jíhìn-iṣẹ́ Ọlọrun, ó ṣeéṣe kí ó jẹ́ nípa wíwàásù. (Heberu 11:5; fiwé 2 Peteru 2:5.) “Kíyèsí i,” ni ẹlẹ́rìí kanṣoṣo gíro yìí polongo, “Oluwa ń bọ̀ pẹ̀lú ẹgbẹgbàárùn-ún àwọn ènìyàn rẹ̀ mímọ́, láti ṣe ìdájọ́ gbogbo ènìyàn, láti dá gbogbo àwọn aláìwà-bí-Ọlọ́run lẹ́bi níti gbogbo ìṣe àìwà-bí-Ọlọ́run wọn, tí wọ́n ti fi àìwà-bí-Ọlọ́run ṣe, àti níti gbogbo ọ̀rọ̀ líle tí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ aláìwà-bí-Ọlọrun ti sọ sí i.” (Juda 14, 15) Enoku ní ìgboyà láti lo orúkọ náà Jehofa nígbà tí ó bá ń jíhìn-iṣẹ́ yẹn tí ó sì ń dá àwọn aláìwà-bí-Ọlọ́run lẹ́bi. Bí Ọlọrun sì ti fún Enoku ní ìgboyà láti polongo ìhìn-iṣẹ́ lílágbára yẹn, bẹ́ẹ̀ ni Jehofa ti ṣe fi agbára fún àwọn Ẹlẹ́rìí Rẹ̀ ní ọjọ́ tiwa láti fi ìgboyà sọ ọ̀rọ̀ Rẹ̀ nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́, ní ilé-ẹ̀kọ́, àti níbòmíràn.—Fiwé Iṣe 4:29-31.

Ìgboyà Lábẹ́ Àdánwò

7. Àpẹẹrẹ ìgboyà wo ni Noa pèsè?

7 Àpẹẹrẹ Noa lè ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ onígboyà nínú síṣe àwọn iṣẹ́ òdodo nígbà tí a bá wà lábẹ́ àdánwò. Pẹ̀lú ìgboyà àti ìgbàgbọ́, ó ṣiṣẹ́ lórí ìkìlọ̀ àtọ̀runwá nípa ìkún-omi kárí gbogbo ayé ó sì “kan ọkọ̀ fún ìgbàlà ilé rẹ̀.” Nípa àwọn ìṣe onígboyà àti ti òdodo, Noa dẹ́bi fún ayé aláìgbàgbọ́ náà fún iṣẹ́ ibi rẹ̀ ó sì fẹ̀rí hàn pé ó yẹ fún ìparun. (Heberu 11:7; Genesisi 6:13-22; 7:16) Ṣíṣàṣàrò lórí ọ̀nà tí Noa gbà hùwà ń ran àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun ti òde-òní lọ́wọ́ láti fi tìgboyà-tìgboyà kópa nínú irúfẹ́ àwọn iṣẹ́ òdodo bíi iṣẹ́-òjíṣẹ́ Kristian.

8. (a) Kí ni Noa dojúkọ gẹ́gẹ́ bí “oníwàásù òdodo” tí ó gbóyà? (b) Kí ni Jehofa yóò ṣe fún wa bí a bá jẹ́ oníwàásù òdodo tí ó gbóyà?

8 Bí a bá ń báa nìṣó ní ipa-ọ̀nà òdodo ṣùgbọ́n tí a kò mọ bí a ṣe lè kojú àdánwò kan pàtó, ẹ jẹ́ kí a gbàdúrà fún ọgbọ́n láti lè kojú rẹ̀. (Jakọbu 1:5-8) Ìdúróṣinṣin Noa ti Ọlọrun lábẹ́ ìdánwò fihàn pé ó ṣeéṣe láti fi ìgboyà àti ìṣòtítọ́ kojú àwọn àdánwò. Ó farada ìkìmọ́lẹ̀ láti inú ayé búburú àti láti ọ̀dọ̀ àwọn angeli tí wọ́n gbé ara ènìyàn wọ̀ àti àwọn àdàmọ̀dì ọmọ tí wọ́n bí. Bẹ́ẹ̀ni, Noa jẹ́ “oníwàásù òdodo” tí ó gbóyà fún “ayé ìgbàanì” tí ó forílé ìparun. (2 Peteru 2:4, 5; Genesisi 6:1-9) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó sọ̀rọ̀ láìṣojo gẹ́gẹ́ bí olùkéde kan tí ń polongo ìkìlọ̀ Ọlọrun fún àwọn tí ń gbé ayé ṣáájú ìkún omi náà, “wọn kò sì mọ̀ títí omi fi dé, tí ó gbá gbogbo wọn lọ.” (Matteu 24:36-39) Ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí a rántí pé láìka inúnibíni àti kíkọ̀ tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ kọ àwọn ìhìn-iṣẹ́ wa tí a gbékarí Bibeli sí lónìí, Jehofa yóò tì wá lẹ́yìn bí ó ṣe ti Noa lẹ́yìn bí a bá fi irú ìgbàgbọ́ àti ìgboyà kan-náà hàn gẹ́gẹ́ bí oníwàásù òdodo.

Ìgboyà Láti Ṣègbọràn sí Ọlọrun

9, 10. Ní àwọn ọ̀nà wo ni Abrahamu, Sara, àti Isaaki gbà fi ìgbọràn onígboyà hàn?

9 Abrahamu “ọ̀rẹ́ Ọlọrun” jẹ́ àpẹẹrẹ rere níti ìgbọ́ràn onígboyà sí Ọlọrun. (Jakọbu 2:23) Abrahamu nílò ìgbàgbọ́ àti ìgboyà láti ṣègbọràn sí Jehofa kí ó sì fi Uri ti Kaldea sílẹ̀, ìlú kan tí ó kún fún àwọn àǹfààní ohun ti ara. Ò gba ìlérí Ọlọrun gbọ pé “gbogbo ìdílé ayé” ni a ó bùkún fún nípasẹ̀ òun àti pé irú-ọmọ òun ni a óò fún ní ilẹ̀ kan. (Genesisi 12:1-9; 15:18-21) Nípa ìgbàgbọ́ ni Abrahamu “ṣe àtìpó ní ilẹ̀ ìlérí” tí ó sì ń fojúsọ́nà fún “ìlú tí ó ní ìpìlẹ̀”—Ìjọba Ọlọrun ní ọ̀run, lábẹ́ èyí tí a ó ti jí i dìde sí ìyè lórí ilẹ̀-ayé.—Heberu 11:8-16.

10 Aya Abrahamu, Sara, ní ìgbàgbọ́ àti ìgboyà náà tí ó béèrè fún láti fi Uri sílẹ̀, kí ó tẹ̀lé ọkọ rẹ̀ lọ sí ilẹ̀ àjèjì kan, kí ó sì farada ìnira tí wọn yóò bá pàdé níbẹ̀. A sì ti san èrè fún un tó fún ìgbọràn onígboyà rẹ̀ sí Ọlọrun! Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó yàgàn títí ó fi di nǹkan bí ẹni àádọ́rùn-ún ọdún tí ó sì ti “kọjá ìgbà rẹ̀,” Sara ní a fi agbára fún ‘láti lóyún nítorí tí ó ka ẹni tí ó ṣe ìlérí sí olóòótọ́.’ Nígbà tí àkókò tó, ó bí Isaaki. (Heberu 11:11, 12; Genesisi 17:15-17; 18:11; 21:1-7) Ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, Abrahamu fi tìgboyà-tìgboyà ṣègbọràn sí Ọlọrun ‘tí ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ fi Isaaki rúbọ.’ Bí angeli kan ti dá a dúró, baba olórí ìdílé náà gba ọmọ rẹ̀ onígboyà àti onígbọràn kúrò lọ́wọ́ ikú ‘ní ọ̀nà àpẹẹrẹ.’ Nípa báyìí òun àti Isaaki lọ́nà àsọtẹ́lẹ̀ ṣàpẹẹrẹ ní kedere pé Jehofa Ọlọrun yóò pèsè Ọmọkùnrin rẹ̀, Jesu Kristi, gẹ́gẹ́ bí ìràpadà kí àwọn wọnnì tí wọ́n ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ baà lè ní ìyè ayérayé. (Heberu 11:17-19; Genesisi 22:1-19; Johannu 3:16) Dájúdájú, ìgbọràn onígboyà Abrahamu, Sara, àti Isaaki níláti sún wa láti ṣègbọràn sí Jehofa kí a sì máa ṣe ìfẹ́-inú rẹ̀ nígbà gbogbo.

Ìgboyà Láti Dúró Pẹ̀lú Àwọn Ènìyàn Ọlọrun

11, 12. (a) Báwo ni Mose ṣe fi ìgboyà hàn níti àwọn ènìyàn Jehofa? (b) Lójú-ìwòye ìgboyà tí Mose ní, ìbéèrè wo ni a lè béèrè?

11 Mose fi tìgboyà-tìgboyà mú ìdúró rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn Ọlọrun tí a nilára. Ní ọ̀rúndún kẹrìndínlógún B.C.E., àwọn òbí Mose fúnraawọn fi ìgboyà hàn. Láìbẹ̀rù àṣẹ ọba láti pa àwọn ọmọdékùnrin Heberu tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ bí, wọ́n fi Mose pamọ́ wọ́n sì wá gbé e sínú áàkì láàárín esùsú ní etí odò Naili lẹ́yìn náà. Ọmọbìnrin Farao rí i, a sì tọ́ ọ dàgbà gẹ́gẹ́ bí ọmọkùnrin tirẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó kọ́kọ́ gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ tẹ̀mí ní ilé àwọn òbí rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí apákan agbo-ilé Farao, Mose ni ‘a kọ́ ní gbogbo ọgbọ́n àwọn ará Egipti ó sì pọ̀ ní ọ̀rọ̀ àti ní ìṣe,’ ó jẹ́ alágbára níti ìdáńgájíyá èrò-orí àti ara-ìyára.—Iṣe 7:20-22; Eksodu 2:1-10; 6:20.

12 Láìka àwọn àǹfààní ohun ti ara tí ó wà ní ilé kábíyèsí sí, Mose fi tìgboyà-tìgboyà yàn láti mú ìdúró rẹ̀ pẹ̀lú àwọn olùjọ́sìn Jehofa, tí àwọn ará Egipti sọ dẹrú nígbà náà. Ní ìgbèjà ọmọ Israeli kan, ó pa ọmọ Egipti kan ó sì sálọ sí Midiani lẹ́yìn náà. (Eksodu 2:11-15) Ní nǹkan bíi ogójì ọdún lẹ́yìn náà, Ọlọrun lò ó láti ṣamọ̀nà àwọn ọmọ Israeli jáde kúrò ní ìgbèkùn. Nígbà náà ni Mose “kọ Egipti sílẹ̀ ní àìbẹ̀rù ìbínú ọba,” ẹni tí ó fi ikú halẹ̀mọ́ ọn fún ṣíṣojú fún Jehofa nítìtorí àwọn ọmọ Israeli. Mose rìn bí ẹni pé ó rí “ẹni àìrí,” Jehofa Ọlọrun. (Heberu 11:23-29; Eksodu 10:28) Ìwọ ha ní irú ìgbàgbọ́ àti ìgboyà bẹ́ẹ̀ débi tí ìwọ yóò fi faramọ́ Jehofa àti àwọn ènìyàn rẹ̀ tímọ́tímọ́ láìka ìnira àti inúnibíni sí bí?

Ìgboyà Láti ‘Tẹ̀lé Jehofa Pátápátá’

13. Báwo ni Joṣua àti Kalebu ṣe pèsè àpẹẹrẹ ìgboyà?

13 Joṣua àti Kalebu onígboyà pèsè ẹ̀rí pé a lè rìn ní àwọn ọ̀nà Ọlọrun. Wọ́n “tẹ̀lé Oluwa lẹ́yìn pátápátá.” (Numeri 32:12) Joṣua àti Kalebu wà lára àwọn ọkùnrin méjìlá tí a rán láti ṣamí Ilẹ̀ Ìlérí. Ní bíbẹ̀rù àwọn olùgbé inú rẹ̀, àwọn amí mẹ́wàá gbìyànjú láti yí Israeli lérò padà láti wọ Kenaani. Bí ó ti wù kí ó rí, Joṣua àti Kalebu fi tìgboyà-tìgboyà sọ pé: “Bí OLUWA bá fẹ́ wa, ǹjẹ́ yóò mú wa wọ inú ilẹ̀ náà yìí, yóò sì fi í fún wa; ilẹ̀ tí ń ṣàn fún wàrà àti fún oyin. Ṣùgbọ́n ẹ máṣe ṣọ̀tẹ̀ sí OLUWA, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ máṣe bẹ̀rù àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà; nítorí pé oùnjẹ wa ni wọ́n; ààbò wọn ti fi wọ́n sílẹ̀, OLUWA sì wà pẹ̀lú wa: ẹ máṣe bẹ̀rù wọn.” (Numeri 14:8, 9) Bí wọ́n ti ṣaláìní ìgbàgbọ́ àti ìgboyà, ìran àwọn ọmọ Israeli yẹn kò dé ilẹ̀ ìlérí rárá. Ṣùgbọ́n Joṣua àti Kalebu, papọ̀ pẹ̀lú ìran titun kan, wọ ilẹ̀ náà.

14, 15. (a) Bí Joṣua ti fi àwọn ọ̀rọ̀ Joṣua 1:7, 8 sílò, kí ni òun àti àwọn ọmọ Israeli nírìírí rẹ̀? (b) Ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n wo tí ó wémọ́ ìgboyà ni a kọ́ lára Joṣua àti Kalebu?

14 Ọlọrun sọ fún Joṣua pé: “Sáà ṣe gírí kí o sì mú àyà le gidigidi, kí ìwọ kí ó lè kíyèsí àti ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo òfin tí Mose ìránṣẹ́ mi ti paláṣẹ fún ọ: máṣe yà kúrò nínú rẹ̀ sí ọ̀tún tàbí sí òsì, kí ó lè dára fún ọ níbikíbi tí ìwọ bá lọ. Ìwé òfin yìí kò gbọ́dọ̀ kúrò ní ẹnu rẹ, ṣùgbọ́n ìwọ ó máa ṣe àṣàrò nínú rẹ̀ ní ọ̀sán àti ní òru, kí ìwọ kí ó lè kíyèsí àti ṣe gẹ́gẹ́ bíi gbogbo èyí tí a kọ sínú rẹ̀: nítorí nígbà náà ni ìwọ ó ṣe ọ̀nà rẹ̀ ní rere, nígbà náà ni yóò sì dára fún ọ.”—Joṣua 1:7, 8.

15 Bí Joṣua ti fi àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn sílò, Jeriko àti àwọn ìlú-ńlá mìíràn ṣubú sọ́wọ́ àwọn ọmọ Israeli. Ọlọrun tilẹ̀ mú kí oòrùn dúró gbagidi tí ó fi jẹ́ pé ó ń ràn ṣáá títí tí Israeli fi jagunmólú ní Gibeoni. (Joṣua 10:6-14) Nígbà tí a wu wọ́n léwu nípasẹ̀ àgbájọpọ̀ agbo ọmọ ogun ọ̀tá ‘tí wọ́n pọ̀ bí iyanrìn tí ń bẹ ní etí-òkun,’ Joṣua fi tìgboyà-tìgboyà gbégbèésẹ̀, Ọlọrun sì tún mú kí Israeli jagunmólú. (Joṣua 11:1-9) Bí a tilẹ̀ jẹ́ ènìyàn aláìpé, bíi ti Joṣua àti Kalebu, a lè tẹ̀lé Jehofa pátápátá, Ọlọrun sì lè fi agbára fún wa láti fi tìgboyà-tìgboyà rìn ní àwọn ọ̀nà rẹ̀.

Ìgboyà Láti Gbẹ́kẹ̀lé Ọlọrun

16. Ní àwọn ọ̀nà wo ni Debora, Baraki, ati Jaeli gbà fi ìgboyà hàn?

16 Ìgbẹ́kẹ̀lé onígboyà nínú Ọlọrun ni a san èrè fún, gẹ́gẹ́ bí a ti fihàn nípasẹ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ní ìgbà tí àwọn onídàájọ́ fi fi ìdájọ́-òdodo sílò ní Israeli. (Rutu 1:1) Fún àpẹẹrẹ, Onídàájọ́ Baraki àti wòlíì obìnrin Debora fi tìgboyà-tìgboyà gbẹ́kẹ̀lé Ọlọrun. Jabini ọba Kenaani ti ni Israeli lára fún ogún ọdún nígbà tí Jehofa tipasẹ̀ Debora sún Baraki láti kó ẹgbàá márùn-ún ènìyàn jọ lórí Òkè Tabori. Olórí ogún Jabini, Sisera, yára lọ sí àfonífojí àgbàrá ti Kiṣoni, ó dá a lójú pé lórí ilẹ̀ títẹ́jú yìí àwọn ọkùnrin Israeli kò ní lágbára tó àwọn ọmọ-ogun òun àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ pẹ̀lú àwọn dòjé irin lára àgbá-kẹ̀kẹ́ wọn. Nígbà tí àwọn ọmọ Israeli yan lọ sínú pẹ̀tẹ́lẹ̀ àfonífojì náà, Ọlọrun gbégbèésẹ̀ nítorí tiwọn, ìkún-omi ayalunilójijì kan sì sọ pápá ogun náà di ibi àbàtà tí ó mú kí àwọn kẹ̀kẹ́-ogun Sisera má lè lọ. Àwọn ọkùnrin Baraki borí, tí ó fi jẹ́ pé ‘gbogbo ibùdó Sisera ti ojú idà ṣubú.’ Sisera sá lọ sínú àgọ́ Jaeli, ṣùgbọ́n bí ó ti sùn lọ, obìnrin náà ní ìgboyà láti pa á nípa gbígbá èèkàn àgọ́ wọ inú ẹ̀bátí rẹ̀ lọ. Ní ìmúṣẹ gbólóhùn alásọtẹ́lẹ̀ Debora fún Baraki, “ọlá” ìṣẹ́gun yìí tipa bẹ́ẹ̀ lọ sọ́dọ̀ obìnrin. Nítorí pé Debora, Baraki, àti Jaeli fi tìgboyà-tìgboyà gbẹ́kẹ̀lé Ọlọrun, Israeli “sinmi ní ogójì ọdún.”—Onidajọ 4:1-22; 5:31.

17. Àpẹẹrẹ wo ni Onídàájọ́ Gideoni pèsè nípa ìgbẹ́kẹ̀lé onígboyà nínú Jehofa?

17 Onídàájọ́ Gideoni fi tìgboyà-tìgboyà gbẹ́kẹ̀lé Jehofa Ọlọrun nígbà tí àwọn ará Midiani àti àwọn mìíràn wọlé wá gbógun ti Israeli. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé nǹkan bíi ọ̀kẹ́ mẹ́fà ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbàájọ àwọn awọlégbóguntini náà pọ̀ níye jù wọ́n lọ, síbẹ̀ ẹgbàá mẹ́rìndínlógún àwọn ọkùnrin ogun Israeli náà lè nítẹ̀sí láti ka ìṣẹ́gun náà tí Ọlọrun fifún wọn sí tiwọn gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó gbójú. Nítorí náà lábẹ́ ìdarì Jehofa, Gideoni dín agbo ọmọ ogun rẹ̀ kù sí àwùjọ mẹ́ta tí ọ̀kọ̀ọ̀kan ní ọgọ́rùn-ún ọkùnrin nínú. (Onidajọ 7:1-7, 16; 8:10) Bí àwọn ọ̀ọ́dúnrún náà ti yí àgọ́ Midiani ká ní òru, ọ̀kọ̀ọ̀kan ní ipè kan, àti ìṣà omi nínú èyí tí ètùfù wà. Bí wọ́n ti rí àmì, wọ́n fun àwọn ipè náà, fọ́ àwọn ìṣà, na àwọn ètùfù tí ń jólala sókè, wọ́n sì kígbe pé: “Idà Jehofa àti ti Gideoni!” (Onidajọ 7:20, NW) Àwọn ará Midiani tí ìpayà ti bá náà bẹ̀rẹ̀ síí sálọ a sì borí wọn. Irúfẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ níláti mú kí ó dá wa lójú pé ìgbẹ́kẹ̀lé onígboyà nínú Ọlọrun ni a ń san èrè fún lónìí.

Ìgboyà Láti Bọlá fún Jehofa kí A sì Gbé Ìjọsìn Mímọ́gaara Ga

18. Kí ni Dafidi fi tìgboyà-tìgboyà ṣe nígbà tí ó mú Goliati balẹ̀?

18 Àwọn àpẹẹrẹ Bibeli díẹ̀ fúnni ní ìgboyà láti bọlá fún Jehofa kí a sì gbé ìjọsìn mímọ́gaara ga. Dafidi ọ̀dọ́, tí ó fi àìṣojo yọ àgùtàn baba rẹ̀ kúrò nínú èwu, fẹ̀rí jíjẹ́ onígboyà hàn níwájú òmìrán Filistini náà Goliati. “Ìwọ mú idà, àti ọ̀kọ̀, àti [asà] tọ̀ mí wá” ni Dafidi sọ, “ṣùgbọ́n èmi tọ̀ ọ́ wá ní orúkọ Oluwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọrun ogun Israeli tí ìwọ ti gàn. Lónìí yìí ni Oluwa yóò fi ìwọ lé mi lọ́wọ́, èmi ó pa ọ́, èmi ó sì ké orí rẹ kúrò ní ara rẹ; . . . gbogbo ayé yóò sì mọ̀ pé, Ọlọrun wà fún Israeli. Gbogbo ìjọ ènìyàn yóò sì mọ̀ dájú pé, Oluwa kò fi idà òun ọ̀kọ̀ gbanilà: nítorí pé ogun náà ti Oluwa ni.” (1 Samueli 17:32-37, 45-47) Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àtọ̀runwá, Dafidi fi tìgboyà-tìgboyà bọlá fún Jehofa, ó mú Goliati balẹ̀, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ kó ipa ṣíṣekókó kan nínú mímú ewu tí Filistini kan ìbá fi wu ìjọsìn mímọ́gaara kúrò.

19. Fún ìwéwèédáwọ́lé wo ni Solomoni nílò ìgboyà, báwo ni a sì ṣe lè fi ọ̀nà tí ó gbà bójútó o sílò ní ọjọ́ wa?

19 Nígbà tí ó kù díẹ̀ kí Solomoni ọmọkùnrin Ọba Dafidi kọ́ tẹ́ḿpìlì Ọlọrun, baba rẹ̀ arúgbó rọ̀ ọ́ pé: “Múrale kí o sì gbóyà, kí o sì ṣiṣẹ́: má bẹ̀rù, bẹ́ẹ̀ ni kí o máṣe dààmú: nítorí Oluwa Ọlọrun, àní Ọlọrun mi wà pẹ̀lú rẹ; òun kì yóò yẹ̀ ọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò kọ̀ ọ́ sílẹ̀ títí ìwọ ó fi parí gbogbo iṣẹ́ fún ìsìn ilé Oluwa.” (1 Kronika 28:20) Nípa gbígbé ìgbésẹ̀ onígboyà, Solomoni fi pẹ̀lú àṣeyọrísírere parí tẹ́ḿpìlì náà. Nígbà ti ilé kíkọ́ ti ìṣàkóso Ọlọrun bá gbé ìpèníjà dìde lónìí, ẹ jẹ́ kí a rántí àwọn ọ̀rọ̀ Dafidi: “Múrale kí o sì gbóyà, kí o sì ṣiṣẹ́.” Èyí ti jẹ́ ọ̀nà dídára tó láti bọlá fún Jehofa kí a sì gbé ìjọsìn mímọ́gaara ga!

20. Ní ọ̀nà wo ni Ọba Asa gba lo ìgboyà?

20 Nítorí ìfẹ́-ọkàn Ọba Asa láti bọlá fún Ọlọrun kí ó sì gbé ìjọsìn mímọ́gaara ga, ó mú àwọn òrìṣà àti àwọn kárùwà ọkùnrin inú tẹ́ḿpìlì kúrò ní Juda. Ó tún mú ìyá rẹ̀ àgbà kúrò ní ipò rẹ̀ gíga ó sì finásun “ère” rẹ̀. (1 Ọba 15:11-13) Bẹ́ẹ̀ni, Asa “mú ara le, ó sì mú àwọn ohun ìríra kúrò láti inú [gbogbo] ilẹ̀ Juda àti Benjamini, àti láti inú ìlú tí ó ti gbà láti òkè Efraimu, ó sì tún pẹpẹ Oluwa ṣe, tí ó wà níwájú ìloro Oluwa.” (2 Kronika 15:8) Ìwọ pẹ̀lú ha fi tìgboyà-tìgboyà ṣá ìpẹ̀yìndà tì tí o sì ń gbé ìjọsìn mímọ́gaara ga bí? Ìwọ ha ń lo àwọn ohun àmúṣọrọ̀ rẹ láti mú àǹfààní ire Ìjọba náà tẹ̀síwájú bí? Ìwọ ha sì ń wọ́nà láti bọlá fún Jehofa nípa nínípìn-ín déédéé nínú pípolongo ìhìnrere náà gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀ bí?

21. (a) Báwo ni àkọsílẹ̀ àwọn olùpàwàtítọ́mọ́ ṣáájú àkókò Kristian ṣe lè ràn wá lọ́wọ́? (b) Kí ni a óò gbé yẹ̀wò nínú ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ tí yóò tẹ̀lé e?

21 Àwa ti kún fún ọpẹ́ tó pé Ọlọrun ti pa àwọn àkọsílẹ̀ Ìwé Mímọ́ mọ́ nípa àwọn olùpàwàtítọ́mọ́ onígboyà ṣáájú àkókò àwọn Kristian! Dájúdájú, àwọn àpẹẹrẹ rere wọn lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe iṣẹ́-ìsìn mímọ́ ọlọ́wọ̀ fún Jehofa pẹ̀lú ìgboyà, ìbẹ̀rù oníwà-bí-Ọlọrun, àti ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀. (Heberu 12:28) Ṣùgbọ́n Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Griki tún ní àwọn àpẹẹrẹ nínú nípa ìgboyà oníwà-bí-Ọlọ́run lẹ́nu iṣẹ́. Báwo ni díẹ̀ nínú àwọn àkọsílẹ̀ wọ̀nyí ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti fi tìgboyà-tìgboyà rìn ní àwọn ọ̀nà Jehofa?

Báwo Ni Ìwọ Yóò Ṣe Fèsìpadà?

◻ Kí ni ìgboyà jẹ́?

◻ Báwo ni Enoku àti Noa ṣe fi ìgboyà hàn?

◻ Ní àwọn ọ̀nà wo ni Abrahamu, Sara, àti Isaaki gbà gbégbèésẹ̀ tìgboyàtìgboyà?

◻ Àwọn àpẹẹrẹ ìgboyà wo ni Mose, Joṣua, àti Kalebu fi lélẹ̀?

◻ Báwo ni àwọn mìíràn ṣe fihàn pé àwọn ní ìgboyà láti gbẹ́kẹ̀lé Ọlọrun?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Gideoni àti àgbo ẹgbẹ́ àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ kékeré fi tìgboyà-tìgboyà gbẹ́kẹ̀lé Jehofa

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́