ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w93 12/15 ojú ìwé 3-7
  • A Ha Bí Jesu ní Ìgbà Òjò-Dídì Bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • A Ha Bí Jesu ní Ìgbà Òjò-Dídì Bí?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìjẹ́pàtàkì Wo ni Ó Ní fún Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli?
  • Àwọn Ìṣirò tí A Gbékarí Bibeli
  • Láti Orísun Wo?
  • Ó Ha Jámọ́ Nǹkankan Bí?
  • Ìgbà Wo Ni Wọ́n Bí Jésù?
    Jí!—2009
  • Ìgbà Wo Ni Wọ́n Bí Jésù?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Keresimesi—Ó Ha Bá Ìsìn Kristian Mu Nítòótọ́ Bí?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Kí Nìdí Tí Àwọn Kan Kì Í Fi í Ṣe Kérésìmesì?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
w93 12/15 ojú ìwé 3-7

A Ha Bí Jesu ní Ìgbà Òjò-Dídì Bí?

“ÀRỌ̀RỌ̀DÁ Òjò-Dídì Dá Ìrìnnà àti Iṣẹ́ Ìgbésí-Ayé Ojoojúmọ́ Dúró ní Jerusalemu” àti “Òjò-Dídì tí kò tètè Wawọ́ Da Ìhà Aríwa Láàmú.” Irú àwọn àkọlé bẹ́ẹ̀ nínú ìwé-ìròyìn The Jerusalem Post di ohun tí ó sábà maa ń wáyé fún àwọn òǹkàwé ní ilẹ̀ Israeli ní 1992, nínú ohun tí ó jásí ọ̀kan lára ìgbà òtútù Israeli tí ó lekoko jùlọ nínú ọ̀rúndún yìí.

Ní January ṣóńṣó Òkè Hamoni ni òjò-dídì tí ó ga tó ẹsẹ̀ bàtà 22 sí 40 ti bòmọ́lẹ̀, òpin ìgbà-òtútù kò sì tíì dé. Láti Ibi-Gíga Golan àti Galili Òkè la Jerusalemu àti Betlehemu tí ó wà nítòsí kọjá (tí a rí ní ẹ̀yìn-ìwé), àní ní ìhà àríwá lọ sí Negebu, láti ìgbà dé ìgbà ìgbésí-ayé ojoojúmọ́ àti ọ̀nà ìgbàṣiṣẹ́ déédéé àwọn ọmọ Israeli ni ojú-ọjọ́ olójò-dídì, lílẹ́wà, tí ó sì dára, síbẹ̀ tí ó lágbára ń ṣèdíwọ́ fún. Ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ inú ìwé-ìròyìn Jerusalem Post kan sọ pé: “Àrọ̀rọ̀dá òjò-dídì ṣe ohun tí òjò àwọn arọ̀jò rọ́kẹ́ẹ̀tì Katyusha kò lè ṣe ní ọ̀sẹ̀ tí ó kọjá lánàá, ó ń sé àwọn ibi ìtẹ̀dó mọ́ tí ó sì ń há àwọn olùgbé mọ́ inú ilé wọn.”

Ìgbà-òtútù líle náà pa àwọn olùgbé ìlú-ńlá àti àwọn mìíràn ní àdánù púpọ̀. A gbọ́ ìròyìn nípa ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn màlúù àti àwọn ọmọ màlúù, àti ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn òròmọdìẹ, tí wọ́n dì gbagidi, bí ìwọ̀n ìtutù ìgbà alẹ́ ti lọsílẹ̀ rekọ́ja ìwọ̀n dídì yìnyín. Àfi bí ẹni pé òjò-dídì náà kò tó, àrọ̀rọ̀dá òjò títutù rinrin, tún ṣe tiwọn. Ní ọjọ́ kan, àwọn ọmọdékùnrin olùṣọ́-àgùtàn méjì, tí ó hàn gbangba pé wọ́n ń gbìyànjú kíkankíkan láti dáàbòbo díẹ̀ lára àwọn àgùtàn wọn tí ìkún-omi ayalunilójijì ti gbé, ni omi pàpà gbé lọ tí wọ́n sì kú sínú àgbàrà náà.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èyí kìí ṣe irú òtútù kan tí ó wọ́pọ̀ ní Àárín-Gbùngbùn Ìlà-Oòrùn Ayé, ìwé-ìròyìn ilẹ̀ Israeli náà Eretz ròyìn pé: “Àkójọ-ìsọfúnni nípa ipò-ojú-ọjọ́ tí a gbàjọ tí a sì kọsílẹ̀ ní ilẹ̀ Israeli fún 130 ọdún sẹ́yìn fihàn pé òjò-dídì ní Jerusalemu jẹ́ àrà-mérìíyìírí tí ó túbọ̀ wọ́pọ̀ ju bí a ti lè retí lọ . . . Láàárín 1949 àti 1980, òtútù olójò-dídì rọ̀ ní ìlú-ńlá Jerusalemu ní ìgbà mẹ́rìnlélógún.” Ṣùgbọ́n èyí ha wulẹ̀ wà fún kìkì ìníyelórí ẹ̀kọ́-ìwádìí nípa ipò-ojú-ọjọ́ àti ire-àǹfààní ènìyàn, tàbí ó ha ní ìtumọ̀ pàtàkì kan fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli bí?

Ìjẹ́pàtàkì Wo ni Ó Ní fún Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli?

Nígbà tí wọ́n bá ń ronú nípa ìbí Jesu, ọ̀pọ̀ ènìyàn máa ń yàwòrán ìrísí-ìran ibùjẹ ẹran kan tí ń fa èrò-ìmọ̀lára mọ́ra tí a sábà máa ń fihàn lákòókò Keresimesi sínú ọkàn wọn. Ọmọ-ọwọ́ náà Jesu ni a tẹ́sílẹ̀, wé lọ́nà mímóoru-fẹ́ẹ́rẹ́ lábẹ́ àbójútó ìyá rẹ̀, pẹ̀lú òjò-dídì tí ń bo àwọn koríko tí ó wà láyìíká fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́. Ojú-ìwòye gbígbajúmọ̀ yìí ha bá àpèjúwe Bibeli nípa ìṣẹ̀lẹ̀ àfipìtàn yìí mu bi?

Òǹkọ̀wé Bibeli náà Luku ṣèròyìn àkọsílẹ̀ kan tí a fi ìṣọ́ra ṣe nípa ìbí Jesu: “Àwọn olùṣọ́-àgùtàn ń bẹ ní ìlú náà, wọ́n ń ṣọ́ agbo àgùtàn wọn ní òru ní pápá tí wọ́n ń gbé. Sáà sì kíyèsí i, angẹli Oluwa náà yọ sí wọn, ògo Oluwa sì ràn yí wọn ká: ẹ̀rù sì bà wọ́n gidigidi. Angẹli náà sì wí fún wọn pé, Má bẹ̀rù: sá wò ó, mo mú ìhìnrere ayọ̀ ńlá fún yín wá, tí yóò ṣe ti ènìyàn gbogbo. Nítorí a bí Olùgbàlà fún yín lónìí ní ìlú Dafidi [Betlehemu], tíí ṣe Kristi Oluwa. Èyí ni yóò sì ṣe àmì fún yín; ẹ̀yin óò rí ọmọ-ọwọ́ tí a fi ọ̀já wé, ó dùbúlẹ̀ ní ibùjẹ ẹran. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ogun ọ̀run sì yọ sí angẹli náà ní òjijì, wọ́n yin Ọlọrun, wí pé, Ògo ni fún Ọlọrun lókè ọ̀run, àti ní ayé àlàáfíà, ìfẹ́ inú rere sí ènìyàn.”—Luku 2:8-14.

Bí ìwọ bá níláti ka àkọsílẹ̀ yìí fún ọmọ Israeli kan lónìí tí o sì béèrè àkókò tí èyí lè jẹ́ nínú ọdún lọ́wọ́ rẹ̀, ó ṣeéṣe kí ó dáhùn pé, “Àkókò kan láàárín April àti October ni.” Èéṣe? Ìdáhùn náà rọrùn. November sí March jẹ́ ìgbà òtútù, tí òjò ń rọ̀ ní Israeli, ó sì dájú pé December 25 jẹ́ ìgbà-òtútù. Àwọn olùṣọ́-àgùtàn kì yóò jáde síta, ní ṣíṣọ́ agbo àwọn àgùtàn wọn nínú pápá ní òru. Ní gbígbé àwọn ìròyìn tí ó wà ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ yìí yẹ̀wò, ìwọ lè lóye ìdí rẹ̀. Betlehemu, ní ibi tí a bí Jesu sí, wà ní òkè tente ó sì jẹ́ máìlì bíi mélòókan sí Jerusalemu. Àní ní àwọn ọdún tí ipò ojú-ọjọ́ kò fi bẹ́ẹ̀ tutù dé góńgó pàápàá, o maa ń tutù gan-an níbẹ̀ ní alẹ́ ní ìgbà-òtútù.—Mika 5:2; Luku 2:15.

Yíyẹ ìtàn ìgbà ìbí Jesu wo tan ìmọ́lẹ̀ sórí òtítọ́ náà pé a kò bí i ní ìgbà òjò-dídì December. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àkókò ìbímọ Maria, ìyá Jesu ti súnmọ́lé gidigidi, ó níláti rìnrìn-àjò láti ilé rẹ̀ ní Nasareti lọ sí Betlehemu. Òun àti Josefu ṣe bẹ́ẹ̀ láti lè kájú àwọn ohun tí a béèrè fún nípa ìkànìyàn tí alákòóso ilẹ̀ Romu náà Augustu Kesari pàṣẹ rẹ̀. (Luku 2:1-7) Àwọn ènìyàn ìlú tí wọ́n jẹ́ Ju, ní ìfìbínúhàn sí ìṣàkóso Romu àti bíbu owó-orí púpọ̀ fúnni rẹ̀, ti wà ní ọ̀gẹ́gẹ́rẹ́ ìṣọ̀tẹ̀. Èéṣe tí Romu yóò fi níláti ni wọ́n lára láìnídìí nípa bíbèèrè pé kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ rìnrìn-àjò kí a lè forúkọ wọn sílẹ̀ lákòókò lílekoko jùlọ àní jálẹ̀ ojú-ọjọ́ olótùútù tí ó léwu náà? Kò ha lọ́gbọ́n-nínú jùlọ pé a ó ti pàṣẹ èyí ní àkókò kan tí yóò fi ààyè sílẹ̀ fún ìrìn-àjò, irú bíi ìgbà ìrúwé tàbí ìgbà ìkórè bí?

Àwọn Ìṣirò tí A Gbékarí Bibeli

Ẹ̀rí ìtàn àwọn ohun tí ó ṣeéfojúrí sọ December, tàbí oṣù ìgbà-òtútù èyíkéyìí mìíràn di aláìtóótun gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó bá àwọn àkọsílẹ̀ ìbí Jesu mu. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, Bibeli tipasẹ̀ àsọtẹ́lẹ̀ fi àkókò tí a bí Jesu nínú ọdún hàn. Níbo ni ó ti ṣe èyí?

Nínú ìwé Danieli, orí 9, a rí ọ̀kan lára àwọn àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ wíwúnilórí jùlọ nípa Messia náà. Ó ṣàpèjúwe dídé rẹ̀ àti kíké e kúro nínú ikú, èyí tí ó pèsè ẹbọ ìràpadà láti ṣètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ kí ó sì gbé ìpìlẹ̀ kan kalẹ̀ fún aráyé onígbọràn láti jèrè “òdodo àìnípẹ̀kun.” (Danieli 9:24-27; fiwé Matteu 20:28.) Ní ìbámu pẹ̀lú àsọtẹ́lẹ̀ yìí, gbogbo èyí ni a ó múṣẹ láàárín sáà-àkókò 70 ọ̀sẹ̀ ti ọdún, tí ó bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 455 B.C.E., nígbà tí àṣẹ náà jáde láti ṣàtúnkọ́ Jerusalemu.a (Nehemiah 2:1-11) Láti inú ọ̀nà tí a gbà pín àkókò nínú àsọtẹ́lẹ̀ yìí, a lè fòyemọ̀ pé Messia náà yóò farahàn ní ìbẹ̀rẹ̀ 70 ọ̀sẹ̀ ti ọdún náà. Èyí wáyé nígbà tí Jesu wá fún ìrìbọmi ní 29 C.E., ní bíbẹ̀rẹ̀ ipa-isẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi Messia lábẹ́ àṣẹ. ‘Ní ìdajì ọ̀sẹ̀,’ tàbí lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ mẹta àti ààbọ̀, Messia ni a ó ké kúrò nínú ikú, ní títipa bẹ́ẹ̀ mú òpin débá ìníyelórí gbogbo àwọn ẹbọ lábẹ́ májẹ̀mú Òfin Mose.—Heberu 9:11-15; 10:1-10.

Àsọtẹ́lẹ̀ yìí fihàn pé gígùn iṣẹ́-òjíṣẹ́ Jesu jẹ́ ọdún mẹ́ta àti ààbọ̀. Jesu kú ní ọjọ́ àjọ̀dún Ìrékọjá, Nisan 14 (ní ìbámu pẹ̀lú kàlẹ́ńdà àwọn Ju), ní ìgbà ìrúwé 33 C.E. Déètì tí ó bá ọdún yẹn mu yoo jẹ́ April 1. (Matteu 26:2) Kíka ọdún mẹ́ta àti ààbọ̀ padàsẹ́yìn fi ìrìbọmi rẹ̀ sí 29 C.E. ní ìbẹ̀rẹ̀ October. Luku fi tó wa létí pé Jesu jẹ́ nǹkan bí ẹni ọgbọ̀n ọdún nígbà ìrìbọmi rẹ̀. (Luku 3:21-23) Èyí yóò túmọ̀sí pé ìbí Jesu pẹ̀lú súnmọ́ ìbẹ̀rẹ̀ October. Ní ìbámu pẹ̀lú àkọsílẹ̀ Luku, ní àkókò yẹn nínú ọdún àwọn olùṣọ́-àgùtàn, yoo ṣì máa “ṣọ́ agbo àgùtàn wọn ní òru ní pápá tí wọ́n ń gbé.”—Luku 2:8.

Láti Orísun Wo?

Níwọ̀n bí ẹ̀rí ti tọ́ka sí ìbẹ̀rẹ̀ October gẹ́gẹ́ bí àkókò ìbí Jesu, èéṣe tí a fi ń ṣayẹyẹ rẹ̀ ní December 25? Ìwé agbédègbéyọ̀ The New Encyclopædia Britannica fihàn pé ayẹyẹ yìí ni a gbàmúlò ní ọ̀pọ̀ ọ̀rùndún lẹ́yìn ìbí Jesu: “Ní ọ̀rùndún kẹ́rin, ayẹyẹ ìbí Kristi ní December 25 ni ọ̀pọ̀ jùlọ àwọn ṣọ́ọ̀ṣì Ìlà-Oòrùn gbàmúlò ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀. Ní Jerusalemu, àtakò sí Kérésìmesì wà fún ìgbà pípẹ́, ṣùgbọ́n a wá tẹ́wọ́gbà á lẹ́yìn náà.”

Èéṣe tí ó fi rọrùn tóbẹ́ẹ̀ fún àwọn wọnnì tí wọ́n ń pe araawọn ní Kristian ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún lẹ́yìn Kristi láti tẹ́wọ́gba àṣà náà? Ìwé agbédègbéyọ̀ The New Encyclopædia Britannica tànmọ́lẹ̀ sórí kókó-ọ̀rọ̀ náà síwájú síi pé: “Àwọn àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ tí ó sopọ̀ mọ́ Kérésìmesì ti rúyọ láti orísun mélòókan gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí ìṣèèṣì báraṣekòńgẹ́ ayẹyẹ ìbí Kristi pẹ̀lú pípa ayẹyẹ ìbọ̀rìṣà iṣẹ́-àgbẹ̀ àti oòrùn mọ́ láàárín ìgbà òtútù. Ní ayé Romu, Saturnalia (December 17) jẹ́ àkókò àríyá ṣíṣe àti ìṣepàṣípààrọ̀ àwọn ẹ̀bùn. December 25 ni a tún kà sí déètì tí a bí ọlọrun ohun-ìjìnlẹ̀ ti ilẹ̀ Iran náà Mithra, Oòrùn Òdodo.”

Ǹjẹ́ gbogbo ìwọ̀nyí ha jẹ́ “ìṣèèsì báraṣekòńgẹ́” kan níti gidi bi? Kò rí bẹ́ẹ̀ rárá! Òtítọ́ ìtàn gidi ni pé ní ọ̀rùndún kẹrin C.E., lábẹ́ Olú-Ọba Constantine, Ilẹ̀-Ọba Romu yípadà lọ́nà pàtàkì kúrò ní olùṣe inúnibíni sí ìsìn Kristian sí onígbọ̀wọ́ fún “ìsìn Kristian” gẹ́gẹ́ bí ìsìn kan tí a tẹ́wọ́gbà. Bí púpọ̀ síi àwọn ènìyàn, tí wọ́n kò ní ìsọfúnni ìpìlẹ̀ nípa ìtumọ̀ tòótọ́ fún ìsìn Kristian, ti tẹ́wọ́gba ìgbàgbọ́ titun yii, wọ́n bẹ̀rẹ̀ síí ṣayẹyẹ àwọn àjọ̀dún ìbọ̀rìṣà wọn tí wọ́n mọ̀ dunjú pẹ̀lú àwọn orúkọ oyè titun “Kristian.” Déètì wo ni ìbá tún báamu jù fún ṣíṣayẹyẹ ìbí Kristi ju December 25 lọ, èyí tí wọ́n ti sàmìsí ná gẹ́gẹ́ bí déètì ìbí “Oòrùn Òdodo”?

Ó Ha Jámọ́ Nǹkankan Bí?

Ìdí kékeré ni ó wà fún iyèméjì pé àwọn ọmọlẹ́yìn Jesu àkọ́kọ́, tí ipò-àtilẹ̀wá wọn jẹ́ ti Ju, kò ṣayẹyẹ ọjọ́-ìbí rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ìwé agbédègbẹ́yọ̀ Encyclopaedia Judaica ti sọ, “ṣíṣayẹyẹ àwọn ọjọ́-ìbí ni a kò mọ̀ nínú ààtò ìbílẹ̀ àwọn Ju.” Dájúdájú, àwọn Kristian ìjímìjí kì yóò ti gba irú ayẹyẹ bẹ́ẹ̀. Dípò ṣíṣayẹyẹ ìbí rẹ̀, wọn yoo bọ̀wọ̀ fún àṣẹ Jesu láti ṣe ìrántí ikú òun, èyí tí wọ́n ní déètì tí ó jóòótọ́ gidi kan fún, ìyẹn ni Nisan 14.—Luku 22:7, 15, 19, 20; 1 Korinti 11:23-26.

Ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún ṣáájú Kristi, àwọn ènìyàn Ju, tí wọ́n jẹ́ orílẹ̀-èdè tí Ọlọrun yàn nígbà náà, ní a fi àsọtẹ́lẹ̀ kìlọ̀ fún nípa òpin ìkólọnígbèkùn wọn sí Babiloni tí ń bọ̀ pé: “Ẹ fà ṣẹ́yìn, ẹ fà sẹ́yìn, ẹ jáde kúrò láàárín rẹ̀; ẹ má fọwọ́ kan ohun àìmọ́ kan: ẹ kúrò láàárín rẹ̀, ẹ jẹ́ mímọ́, ẹ̀yin tí ń gbé ohun-èlò Oluwa.” (Isaiah 52:11) Wọ́n níláti padà sí ilẹ̀-ìbílẹ̀ wọn láti tún fìdí ìjọsìn tòótọ́ Jehofa múlẹ̀ lẹ́ẹ̀kan síi. Yóò jẹ́ ohun tí kò yẹ fún wọn láti gba àwọn àṣà ìbọ̀rìṣà aláìmọ́ àti àwọn ọ̀nà ìjọsìn tí wọ́n ti ṣàkíyèsí ní Babiloni.

Lọ́nà tí kò yanilẹ́nu, àṣẹ kan-náà yìí ní a túnsọ fún àwọn Kristian ní 2 Korinti 6:14-18. Dípò àwọn orílẹ̀-èdè Ju tí wọ́n kọ Kristi sílẹ̀, àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ di aṣojú fún ìsìn mímọ́gaara. Wọ́n ní ẹrù-iṣẹ́ náà láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti jáde kúrò nínú òkùnkùn tẹ̀mí wá sínú ìmọ́lẹ̀ òtítọ́. (1 Peteru 2:9, 10) Báwo ni ó ṣe lè ṣeéṣe fún wọn láti ṣe èyí bí wọ́n bá da àwọn ẹ̀kọ́ Kristi pọ̀ mọ́ àwọn àṣà àti àwọn ọlidé tí wọ́n pilẹ̀ṣẹ̀ lọ́dọ̀ àwọn abọ̀rìṣà?

Bí ó ti wù kí ìgbádùn rẹ̀ fa ọ̀pọ̀lọpọ̀ mọ́ra tó, ṣíṣayẹyẹ “Kérésìmesì Olójò-Dídì” jẹ́ ‘fífí ọwọ́ kan ohun àìmọ́.’ (2 Korinti 6:17) Ẹnìkan tí ó nífẹ̀ẹ́ Ọlọrun àti Kristi nítòótọ́ gbọ́dọ̀ yẹra fún un.

Ní àfikún sí òtítọ́ náà pé ó ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ nínú àwọn ayẹyẹ abọ̀rìṣà, a tún ti ríi pé Kérésìmesì kò dúró fún òtítọ́, níwọ̀n bí a ti bí Jesu ní October. Bẹ́ẹ̀ni, láìka ìrísí-ìran tí ìwòye ẹnìkan lè gbéyọ sí, a kò ṣáà bí Jesu ní ìgbà òjò-dídì.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Fún ìjíròrò tí ó túbọ̀ kúnrẹ́rẹ́ nípa àsọtẹ́lẹ̀ yìí, wo ìwé-pẹlẹbẹ náà Will There Ever Be a World Without War? ojú-ìwé 26, tí a tẹ̀jáde láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4, 5]

Jerusalemu tí òjò-dídì bò, bí a ti ríi láti ìlà-oòrùn

[Credit Line]

Garo Nalbandian

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

Òjò-dídì ní ẹ̀gbẹ́ ògiri Jerusalemu

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Ní ìgbà ooru nìkan ni àwọn olùṣọ́-àgùtàn lè dúró ti àwọn agbo-àgùtàn wọn ní alẹ́ ní bèbè àwọn òkè olókùúta, bí a ti ríi nísàlẹ̀ yìí

[Credit Line]

Garo Nalbandian

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́