Àwọn Olùpòkìkí Ìjọba Ròyìn
Ìfẹsẹ̀múlẹ̀ṣinṣin Ń Mú Àwọn Èrè Dídọ́ṣọ̀ Wá
JESU sọtẹ́lẹ̀ pé àwọn ọmọlẹ́yìn òun ni a ó ṣe inúnibíni sí, aposteli Paulu sì sọ bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú, gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní 2 Timoteu 3:12: “Nítòótọ́, gbogbo àwọn tí ó fẹ́ máa gbé ìgbé ìwà-bí-Ọlọrun nínú Kristi Jesu, yóò farada inúnibíni.” Ṣùgbọ́n ìfẹsẹ̀múlẹ̀ṣinṣin nínú ṣíṣiṣẹ́sin Jehofa Ọlọrun ń mú àwọn èrè dídọ́ṣọ̀ wá.
◻ Èyí jẹ́ òtítọ́ ní ìlú kan tí ó wà ní bèbè-etíkun àríwá ìlà-oòrùn Malaysia. Bí òun tilẹ̀ jẹ́ alátìlẹ́yìn gbágbágbá fún ìsìn Búdà kan tí ó sì ń kọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́nà mímúná, kò ṣeéṣe fun baba kan láti dí àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ mẹ́ta àti ọmọkùnrin rẹ̀ mẹ́ta lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Kódà aya rẹ̀ fi ọkàn-ìfẹ́ hàn nínú òtítọ́. Nígbà tí ó di ọjọ́ kan aládùúgbò rẹ̀ kan fi í ṣe ẹlẹ́yà pé: “Báwo ni apá rẹ kò ṣe ká àwọn ọmọ rẹ tí o sì jẹ́ kí wọ́n di Ẹlẹ́rìí Jehofa? Gbogbo àwọn ọmọ tèmi ni wọ́n dúró gbágbágbá ti èmi àti ìsìn Búdà ti àwọn baba-ńlá wa. Ó mà ṣe o!”
Baba náà sáré lọ sílé ó sì halẹ̀ pé òun yóò lu arábìnrin náà tí ó bá àwọn ọmọ rẹ̀ ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ọmọ náà mú ara rẹ̀ rọ̀wọ̀ọ̀ wọ́n sì ń bá kíkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa àti lílọ sí àwọn ìpàdé nìṣó pẹ̀lú ìtìlẹ́yìn ìyá wọn.
Bí ó ti wù kí ó rí, níkẹyìn, baba náà pe gbogbo ìdílé jọpọ̀. Ó fi dandangbọ̀n béèrè pé, “Ẹ ṣe yíyàn láàárín èmi àti gbígbé nínú ilé àti dídi Kristian kí ẹ sì fi ilé sílẹ̀.” Ọmọkùnrin tí ó dàgbà jù, olóhùn-jẹ́jẹ́ ènìyàn, bẹ̀rẹ̀ síí palẹ̀ ẹrù rẹ̀ mọ́ lójú-ẹsẹ̀. “Rárá!” ni baba náà kígbe. “Níwọ̀n bí gbogbo yín ti ya ọlọ̀tẹ̀ ọmọ, ó sàn fún mi láti kú.” Lẹ́yìn náà ni ó sáré jáde kúrò nínú ilé, tí ìdílé náà sì gbáyá a, tí wọ́n sì bẹ̀ẹ́ pé kí ó máṣe pa araarẹ̀. Bí ẹ̀bẹ̀ wọn ti wú u lórí, ó padà sílé.
Ọjọ́ yí gorí ọjọ́. Baba náà sì bẹ̀rẹ̀ síí ṣàkíyèsí ìyọrísí rere tí òtítọ́ Bibeli ní lórí ìwà àwọn ọmọ rẹ̀. Lọ́jọ́ kan ó pàdé ọ̀rẹ́ rẹ̀ tí ó ti fi í ṣẹlẹ́yà, ẹni tí kò láyọ̀ nísinsìnyí, tí ó wí pé: “Àwọn ọmọ mi ti já mi kulẹ̀ gidigidi. Wọ́n ń rẹ́ mi jẹ́ wọ́n sì ń jà mí lólè.” Ṣùgbọ́n baba ti àwọn ọmọ rẹ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa wí pé: “Óò, àwọn ọmọ mi yàtọ̀! Wọ́n ṣenúrere sí mi wọ́n tilẹ̀ ti ràn mí lọ́wọ́ láti san owó ọkọ̀ mi tí mo ń san díẹ̀díẹ̀ nígbà tí ń kò fi ní iṣẹ́ lọ́wọ́.”
Lónìí, àwọn ọmọbìnrin mẹ́ta àti ìyà náà ni a ti baptisi. Ọmọkùnrin kan jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe. Baba tí ó jẹ́ alátìlẹ́yìn gbágbágbá àti abínúfaraya tẹ́lẹ̀rí náà ń kọ́? Ó ti di oníwà-bí-ọ̀rẹ́ báyìí ó sì ti wá sí Ìṣe-Ìrántí.
Jehofa san èrè fún ọmọkùnrin náà àti àwọn àbúrò rẹ̀ obìnrin mẹ́ta àti ìyá wọn pẹ̀lú fún ìfẹsẹ̀múlẹ̀ṣinṣin wọn fún Un. Wọ́n jẹ́ oníwàásù Ìjọba onítara tí ń mú ọkàn-àyà Jehofa yọ̀ nísinsìnyí.—Owe 27:11.