ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w94 10/1 ojú ìwé 26-30
  • Iwọ Ha Ń Ran Ọmọ Rẹ Lọ́wọ́ Lati Yan Jehofa Bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Iwọ Ha Ń Ran Ọmọ Rẹ Lọ́wọ́ Lati Yan Jehofa Bí?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìdí tí Awọn Ọ̀dọ́ Kan Fi Ń Kọ Jehofa Sílẹ̀
  • Tètè Bẹ̀rẹ̀
  • Fún Awọn Ọmọ Rẹ Ní Àkókò Rẹ
  • Àpẹẹrẹ ati Ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ Rere
  • Ìdùnnú tí Ó Wà Ninu Rírí I Kí Awọn Ọmọ Yan Jehofa
  • Ẹ̀yin Òbí, Ẹ Ran Àwọn Ọmọ Yín Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2022
  • Gbígbé Ìdílé Tó Dúró Sán-ún Nípa Tẹ̀mí Ró
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Ẹ Kọ́ Àwọn Ọmọ Yín Láti Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ẹ̀yin Òbí Ẹ Jẹ́ Àpẹẹrẹ Rere Fáwọn Ọmọ Yín
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
w94 10/1 ojú ìwé 26-30

Iwọ Ha Ń Ran Ọmọ Rẹ Lọ́wọ́ Lati Yan Jehofa Bí?

Ọ̀DỌ́MỌKÙNRIN kan sọ pé, “Mo nímọ̀lára pé kíkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli jẹ́ ohun tí ń dánilágara tí ó sì ń káàárẹ̀báni níti gidi. Ní bòńkẹ́lẹ́, mo pinnu lọ́kàn araàmi pé bí mo bá dàgbà emi kì yoo jẹ́ ọ̀kan lára awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa.” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a nírètí pé èyí tí ó pọ̀ jùlọ lára awọn ọmọ tí a bí sínú ìdílé Kristian yoo yàn lati dúró níhà ọ̀dọ̀ Jehofa ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, awọn ọ̀dọ́ bíi tirẹ̀ lè la awọn àkókò tí ó nira já lati lè yan Jehofa gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun wọn.

Awọn òbí sábà máa ń nímọ̀lára àìdánilójú níti bí wọn ṣe lè darí awọn ọmọ wọn lọ́nà gbígbéṣẹ́. Wọn nírìírí awọn èrò tí ń wádìí ọkàn, bíi ti baba kan tí ń ṣàníyàn ti ó sọ nígbà kan pé: “Kí a sọ tòótọ́, awọn àkókò kan wà tí mo ń wo ojú awọn ọmọ mí lẹ́yìn tí wọn bá ti sùn, tí omijé ìjákulẹ̀ ṣì wà ní ẹ̀rẹ̀kẹ́ wọn, ti mo sì ń ṣe kàyéfì bí kò bá yẹ kí n ti túbọ̀ fi àánú hàn síi.” Awọn ọmọkùnrin rẹ̀ méjèèjì dàgbà wọn sì yàn lati ṣiṣẹ́sin Jehofa.

Síbẹ̀ a rí awọn ọ̀dọ́ tí wọn kọ Jehofa sílẹ̀ tí wọn sì dágbére fún agbo Kristian lati bá ayé Satani lọ. Nitori naa bawo tilẹ̀ ni awọn òbí ṣe lè kẹ́sẹjárí ní ríran awọn ọmọ wọn lọ́wọ́ lati yan Jehofa? Lati dáhùn ìbéèrè yẹn, ẹ jẹ́ kí a kọ́kọ́ wádìí ohun tí ó mú kí awọn ọ̀dọ́ kan kọ Jehofa sílẹ̀ nígbà tí awọn òbí wọn fẹ́ gidigidi pé kí wọn dúró tì í.

Ìdí tí Awọn Ọ̀dọ́ Kan Fi Ń Kọ Jehofa Sílẹ̀

Ọ̀kan lára awọn kókó abájọ wíwọ́pọ̀ ni pé awọn ọ̀dọ́ kan kò fi ìgbà kankan mọ Jehofa tabi awọn ọ̀nà rẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ti ń lọ sí awọn ìpàdé Kristian lati ìgbà ọmọ-ọwọ́, wọn kò fi tọkàn-tọkàn ṣe é, kò sì sí wíwá Jehofa lọ́nà kan tí ó ṣe gúnmọ́. (Isaiah 55:⁠6; Iṣe 17:27) Ọmọdékùnrin tí a mẹ́nukàn lẹ́ẹ̀kan ni agara ń dá ní awọn ìpàdé Kristian nitori pé oun kìí lóye ohun tí awọn olùbánisọ̀rọ̀ ń sọ lati orí pèpéle.

A gbin irúgbìn òtítọ́ sínú awọn kan, ṣugbọn wọn fàyègba ẹ̀mí-àìbìkítà, ìgbésí-ayé ọlọ́rọ̀-àlùmọ́nì tí ó farahàn gbangba ti ayé Satani lati tàn wọn jẹ. Awọn kan kò lè kojú ìfẹ́-ọkàn lílágbára gidigidi lati máa bá awọn ojúgbà wọn kẹ́gbẹ́ ati lati máa ṣàfarawé wọn.​—⁠1 Kronika 28:⁠9; Luku 8:12-⁠14; 1 Korinti 15:33.

Bí ó ti wù kí ó rí, jákèjádò ayé, ọ̀pọ̀ awọn ọmọ tí a bí sínú ilé Kristian ti yàn lati dúró síhà ọ̀dọ̀ Jehofa. A ha lè rí ohunkóhun kọ́ lati inú ìgbésẹ̀ onífojúsọ́nà-fún-rere tí awọn òbí wọn gbé bí?

Tètè Bẹ̀rẹ̀

Kọ́kọ́rọ́ kan tí ó ṣekókó fún ríran awọn ọmọ rẹ lọ́wọ́ lati yan Jehofa ni lati tètè bẹ̀rẹ̀. Ninu awọn ọ̀ràn tí ó pọ̀ jùlọ, awọn èrò àtẹ̀mọ́nilọ́kàn tí ó rí gbà ati awọn ẹ̀kọ́ tí ó kọ́ nígbà tí ọkàn-àyà rẹ̀ sì ṣeé tẹ̀síhìn-⁠ín-sọ́hùn-⁠ún tí ó sì ṣetán lati kẹ́kọ̀ọ́ yoo wà jálẹ̀ gbogbo àkókò ìgbésí-ayé. (Owe 22:6) Nitori naa tètè bẹ̀rẹ̀ lati máa sọ̀rọ̀ nipa ìwàrere-ìṣeun Jehofa, ìfẹ́ ati ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ rẹ̀ fún awọn ọmọ rẹ, kí o sì máa sakun lati gbé ìfẹ́ fún Jehofa ati ìmọrírì fún ohun tí Jehofa ti ṣe fún wọn ró ninu ọkàn wọn. Lati ṣàṣeparí èyí, ọ̀pọ̀ awọn òbí ti lo ọ̀pọ̀ jaburata ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ lórí awọn ìṣẹ̀dá Jehofa tí wọn rí ninu awọn ìtẹ̀jáde Watchtower Society lọ́nà yíyọrísírere.

Ìgbọràn ati ọ̀wọ̀ fún Jehofa ati ìjọsìn rẹ̀ wà lára awọn ànímọ́ mìíràn tí a gbọ́dọ̀ gbìn sínú wọn ní kùtùkùtù ìgbésí-ayé. Ó ń múnilọ́kànyọ̀ lati rí awọn ọmọ tí kò tíì tó bẹ̀rẹ̀ ilé-ẹ̀kọ́ tí wọn ń gbìyànjú lati ṣàkọsílẹ̀ tí ó rọrùn ní awọn ìpàdé Kristian lati yẹ awọn ẹsẹ ìwé mímọ́ wò ninu Bibeli wọn tabi kí wọn lọ sí ilé ìtura pẹlu awọn òbí wọn lati fi omi tútù bọ́jú wọn nígbà tí wọn bá ń tòògbé. Awọn nǹkan kéékèèké ni iwọnyi, ṣugbọn ẹ wo bí wọn ṣe ṣekókó tó ní títẹ̀ ẹ́ mọ́ awọn èwe lọ́kàn pé a níláti fi ọ̀wọ̀ ati ìgbọràn hàn fún Jehofa!

Ó tún yẹ kí ìtọ́ni ara-ẹni tí a gbékarí Bibeli tètè bẹ̀rẹ̀. Nígbà tí awọn ọmọdékùnrin wọn jẹ́ ọmọ ọdún méjì, tọkọtaya kan bẹ̀rẹ̀ sí ka ìwé naa Fifetisilẹ si Olukọ Nla na.a Lẹ́yìn naa, nígbà tí awọn ọmọdékùnrin naa bẹ̀rẹ̀ ilé-ẹ̀kọ́, wọn yoo tètè jí ní kùtùkùtù wọn yoo sì kẹ́kọ̀ọ́ pẹlu ìyá wọn lóròòwúrọ̀ ninu ìwé naa Iwe Itan Bibeli Mi ati Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye.* Ìjíròrò ẹsẹ̀ ìwé mímọ́ ti ọjọ́ naa tí baba wọn yoo darí ni yoo tẹ̀lé e ṣáájú oúnjẹ òwúrọ̀. Ìsapá awọn òbí wọn ni a bùkún jìngbìnnì nígbà tí awọn ọmọkùnrin wọn yàn lati sin Jehofa láìpẹ́ yii, ní fífi àpẹẹrẹ ìyàsímímọ́ wọn hàn nípasẹ̀ ṣíṣe ìrìbọmi ninu omi ni ọmọ ọdún 10 ati 11.

Arẹwà ọ̀dọ́mọkùnrin kan tí ń ṣiṣẹ́sìn ní ẹ̀ka ọ́fíìsí Watch Tower Society ní Japan rántí pé nígbà tí oun ṣì kéré, ìyá oun ran oun lọ́wọ́ lati mú ipò-ìbátan dàgbà pẹlu Jehofa nipa jíjókòó sẹ́gbẹ̀ẹ́ oun lóru, ní ríran oun lọ́wọ́ lati gbàdúrà. Oun kò fìgbàkanrí gbàgbé ẹ̀kọ́ tí ó kọ́​—⁠ibi yòówù kí ó lọ tabi ohun yòówù tí ó ń ṣe, Jehofa máa ń wà nítòsí nígbà gbogbo tí ó sì múratán lati ṣèrànwọ́.

Awọn òbí tí wọn ti ṣàṣeyọrí kọ́ lati mọ awọn ìsúnniṣe búburú tí ó jẹ́ nitori àìpé tí awọn ọmọ wọn ti jogún, awọn òbí naa sì tètè máa ń bẹ̀rẹ̀ lati ran awọn ọmọ wọn lọ́wọ́ lati ṣàtúnṣe ìwọ̀nyí. (Owe 22:15) Awọn ìtẹ̀sí-èrò tí ó darí síhà ìmọtara-ẹni-nìkan, agídí, ìgbéraga, ati ṣíṣòfíntótó jù nipa awọn ẹlòmíràn, ni a gbọ́dọ̀ tètè gbé ìgbésẹ̀ lòdìsí. Láìjẹ́ bẹ́ẹ̀, lẹ́yìnwá-ọ̀la irú awọn irúgbìn bẹ́ẹ̀ yoo dàgbà di ìṣọ̀tẹ̀ lòdìsí Ọlọrun ati awọn ọ̀nà rẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, awọn òbí tí wọn ní èrò rere ṣugbọn tí wọn jẹ́ akẹ́mọbàjẹ́ sábà máa ń jẹ́ kí awọn ọmọ wọn mú ìwà anìkànjọpọ́n dàgbà. Ó máa ń nira fún awọn ọmọ wọnyi lati bọ̀wọ̀ fún yálà awọn òbí wọn tabi Jehofa, ní dídi irú ‘awọn aláìlọ́pẹ́’ tí a mẹ́nukàn ninu Bibeli. (Owe 29:21, NW) Ní ọwọ́ mìíràn ẹ̀wẹ̀, awọn ọmọ tí a yan awọn iṣẹ́ ilé pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ fún tí a sì kọ́ lati máa kíyèsí àìní awọn ẹlòmíràn sábà máa ń jẹ́ olùṣọpẹ́ fún awọn òbí wọn ati fún Jehofa.

Ohun mìíràn tí ó ṣe pàtàkì ni títètè bẹ̀rẹ̀ lati gbé awọn góńgó mímọníwọ̀n ti ìṣàkóso Ọlọrun tí ọwọ́ ọmọ kan lè tẹ̀ kalẹ̀ fún un. Bí a kò bá tètè ṣe èyí kí a sì ṣe é déédéé, awọn mìíràn lè fi awọn góńgó tí ó yàtọ̀ kún inú ati ọkàn-àyà rẹ̀. Kíka Bibeli lati páálí dé páálí, dídákẹ́kọ̀ọ́ awọn ìtẹ̀jáde Watchtower Society, dídarapọ̀ mọ́ Ilé-Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́-Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọrun, dídi olùpòkìkí ìhìnrere, ati ṣíṣe ìrìbọmi níláti wà lára awọn góńgó wọnyi.

Takafumi rántí pé ìyá oun ni ó mú kí oun mú àṣà kíka ìwé ìròyìn Ilé-Ìṣọ́nà ati Jí! dàgbà nipa ṣíṣètò awọn ìbéèrè rírọrùn ati fífi wọn sílẹ̀ sórí tábìlì ilé-ìdáná kí oun baà lè rí i nígbà tí oun bá padà dé lati ilé-ẹ̀kọ́. Yuri rántí pé wíwà papọ̀ fún awọn ọjọ́ díẹ̀ pẹlu awọn aṣáájú-ọ̀nàb tí wọn ń ṣisẹ́sìn níbi tí àìní fún awọn Kristian òjíṣẹ́ ti pọ̀ síi, jíjáde pẹlu wọn ninu iṣẹ́-òjíṣẹ́, rírí wọn bí wọn ṣe ń gbọ́únjẹ tí ó dára, ati ṣíṣàkíyèsí ìdùnnú ati ìtara wọn ní ipa ìdarí ńláǹlà lórí ìfẹ́-ọkàn rẹ̀ lati ṣiṣẹ́sin Jehofa ní ọ̀nà kan naa. Ọ̀pọ̀ awọn ọ̀dọ́ rántí pé nígbà gbogbo ni awọn òbí wọn máa ń mú wọn wá sí Beteli, bí a ṣe ń pé awọn orílé-iṣẹ́ ati ẹ̀ka ti Watch Tower Society, níbi tí wọn ti lè rí bí awọn ọ̀dọ́mọkùnrin ati ọ̀dọ́mọbìnrin mìíràn ṣe ń fayọ̀ ṣiṣẹ́sin Jehofa. Ọ̀pọ̀ lára awọn wọnnì tí wọn ti ṣèbẹ̀wò nígbà tí wọn wà ní ọmọdé ń ṣiṣẹ́sìn nísinsìnyí ní awọn Beteli káàkiri àgbáyé.

Fún Awọn Ọmọ Rẹ Ní Àkókò Rẹ

Bí àkókò tí o lò pẹlu awọn ọmọ rẹ bá ṣe pọ̀ tí wọn sì jẹ́ ojúlówó tó bẹ́ẹ̀ ni ó ṣeéṣe kí ó ní ipa ìdarí tààràtà tó lórí yálà awọn ọmọ rẹ yoo yàn lati ṣiṣẹ́sin Jehofa tabi bẹ́ẹ̀kọ́. Wọn tètè máa ń fòyemọ bí àkókò tí o ń lò fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli tí o ṣe pẹlu wọn ṣe pọ̀ tó ati bí o ṣe múrasílẹ̀ tó. Bí o kò bá lè rántí ibi tí ẹ dé dúró ninu ìkẹ́kọ̀ọ́ tí ẹ ṣe gbẹ̀yìn tabi bí o bá dá ìkẹ́kọ̀ọ́ naa dúró fún awọn ìdí tí kò tó nǹkan, ìhìn-iṣẹ́ tí o ń fi ránṣẹ́ ni pé ìkẹ́kọ̀ọ́ naa kò ṣe pàtàkì tóbẹ́ẹ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, nígbà tí wọn bá rí i pé awọn òbí ń pa awọn nǹkankan tì nitori ìkẹ́kọ̀ọ́ naa, tí wọn ń múrasílẹ̀ dáradára tí wọn sì ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ naa déédéé láìka ohunkóhun tí ó lè dé sí, ìhìn-iṣẹ́ yíyàtọ̀ pátápátá ni o ń fi ránṣẹ́. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kìí ṣe ohun-àbéèrè-fún, awọn ìyá kan máa ń múra fún awọn ọmọ wọn nitori ìkẹ́kọ̀ọ́ wọn, bí wọn ti ń ṣe gẹ́lẹ́ nígbà tí wọn bá ń lọ sí awọn ìpàdé tabi darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pẹlu aládùúgbò kan. Ohun tí wọn ń tẹ̀ mọ́ wọn lọ́kàn ni pé ìjọsìn Jehofa ṣe pàtàkì.

Yoo béèrè fún ọ̀pọ̀ àkókò ati ìsapá lati mú kí ẹ̀kọ́ awọn ọmọ rẹ̀ nipa Bibeli jẹ́ èyí tí ń gbádùnmọ́ni, tí ń wọnú ọkàn-àyà wọn. Ó máa ń fún awọn ọmọdé níṣìírí ní pàtàkì nígbà tí wọn bá rí i pé a ń fi ohun ti a ń kọ́ wọn ṣeré akọ́nilẹ́kọ̀ọ́. Fún àpẹẹrẹ, baba kan ran awọn ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́ lati fojú yàwòrán àjíǹde nipa ṣíṣeré akọ́nilẹ́kọ̀ọ́ ti àkọsílẹ̀ inú Bibeli nipa àjíǹde Lasaru. Ó wọnú ìyẹ̀wù lọ ó sì jáde gọ́lọ́ bí i Lasaru tí a jí dìde.​—⁠Johannu 11:​17-⁠44.

Bí awọn ọmọ naa ṣe ń dàgbà, ó túbọ̀ ń gba àkókò ati aáyan pupọ síi lati lè kojú awọn ìmọ̀lára, iyèméjì, ati àníyàn rẹpẹtẹ tí wọn ń dojúkọ. Àkókò tí awọn òbí onífẹ̀ẹ́ ati olóye yà sọ́tọ̀ níbi tí ọ̀ràn dé yii ṣe pàtàkì gidigidi bí awọn ọmọ naa bá níláti mú ìgbẹ́kẹ̀lé dàgbà ninu Jehofa. Baba aláṣeyọrí kan tí ó ní awọn ọmọ mẹ́rin ṣàlàyé pé nígbà tí awọn ọmọ oun bá dojúkọ onírúurú ìṣòro, oun yoo ṣàyẹ̀wò awọn àkójọpọ̀-ọ̀rọ̀ tí ó tan mọ́ ọn ninu ìtẹ̀jáde Watchtower tí oun yoo sì jíròrò rẹ̀ pẹlu wọn lójoojúmọ́ títí di ìgbà tí wọn bá tó borí rògbòdìyàn naa.

Ìyá ọlọ́mọ méjì kan tí ó sì jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà tí ọwọ́ rẹ̀ dí ṣàkíyèsí pé ọmọbìnrin oun bẹ̀rẹ̀sí ya araarẹ̀ sọ́tọ̀ tí inú rẹ̀ kò sì dùn mọ́ ninu awọn ìgbòkègbodò ìṣàkóso Ọlọrun. Nitori naa ìyá naa pinnu lati máa wà nílé nígbà tí ọmọ naa bá padà dé lati ilé-ẹ̀kọ́ lọ́sọ̀ọ̀sán, ní jíjíròrò pẹlu ọmọbìnrin naa bí awọn méjèèjì ṣe ń mu ife tíì kọ̀ọ̀kan. Nípasẹ̀ ìjíròrò tìyá-tọmọ tímọ́tímọ́ naa, ọmọbìnrin naa rí ìrànlọ́wọ́ tí ó ń fẹ́ gbà. Nísinsìnyí, lẹ́yìn tí ó ti jáde ilé-ẹ̀kọ́ gíga, ó ti darapọ̀ mọ́ ìyá rẹ̀ ninu iṣẹ́-ìsìn aṣáájú-ọ̀nà.​—⁠Owe 20:⁠5.

Àpẹẹrẹ ati Ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ Rere

Ní àfikún sí yíyọ̀ọ̀da àkókò wọn, awọn òbí gbọ́dọ̀ pèsè ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ gbígbámúṣé fún awọn ọmọ wọn. Owe 13:20 sọ pé: “Ẹni tí ó ń bá ọlọgbọ́n rìn yoo gbọ́n; ṣugbọn ẹgbẹ́ awọn aṣiwèrè ni yoo ṣègbé.”

Ọ̀pọ̀ awọn òbí aláṣeyọrí mọ̀ bí òwe yii ṣe jẹ́ òtítọ́ tó. Baba ọlọ́mọ mẹ́rin kan sọ pé: “Nígbà tí mo bojú wẹ̀yìn, mo wòye pé àwùjọ awọn ọ̀rẹ́ awọn ọmọ wa tí wọn wà ninu òtítọ́ ni wọn ràn wọn lọ́wọ́ lati ṣiṣẹ́sin Jehofa. Mo fún wọn níṣìírí lati wá awọn ọ̀rẹ́ ninu awọn ìjọ mìíràn ati ninu tiwa pẹlu kí wọn sì mú irú ìbádọ́rẹ̀ẹ́ bẹ́ẹ̀ dàgbà.” Kristian alàgbà kan tí ó ti ṣiṣẹ́sìn ní Beteli fún ọ̀pọ̀ ọdún rántí pé: “Nígbà tí mo wà lọ́mọdé, a ń gbé ninu ilé kékeré kan, ṣugbọn a máa ń yọ̀ọ̀da rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ibùwọ̀ alábòójútó àyíká. Ní àfikún síi, awọn aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe tí ń bẹ ní ìjọ wa máa ń jẹ oúnjẹ alẹ́ déédéé pẹlu wa. Wọn ń wẹ̀ ní ilé wa wọn sì ń bá wa kẹ́gbẹ́pọ̀. Gbígbọ́ awọn ìrírí wọn ati rírí ìdùnnú wọn ràn mí lọ́wọ́ lati mú ìmọrírì dàgbà fún iṣẹ́-ìsìn alákòókò kíkún.”

Ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ rere máa ń ṣèrànwọ́ fún awọn wọnnì tí wọn ń là ìṣòro já. Ìyá kan tí ọmọ rẹ̀ ń la àkókò onírúgúdù kọjá jíròrò ìṣòro naa pẹlu alábòójútó arìnrìn-àjò ti awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Ó dámọ̀ràn kí ìyá naa máa bá ọmọdékùnrin naa jáde ninu iṣẹ́-ìsìn pápá. Alábòójútó naa wí pé, “Bí o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ipò tẹ̀mí rẹ̀ ati gbogbo nǹkan mìíràn yoo sunwọ̀n síi.” Ó ròyìn pé: “Ìṣètò fún ìjẹ́rìí ìrọ̀lẹ́ wà ní ìjọ wa, ọ̀pọ̀ awọn ọmọ tí wọn ti tó bẹ̀rẹ̀ ilé-ẹ̀kọ́, awọn aṣáájú-ọ̀nà mélòókan tí wọn lọ́jọ́ lórí, ati ó kéré tán alàgbà kan ń nípìn-⁠ín ninu rẹ̀. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ó jẹ́ ìjàkadì gidi kí n tó lè máa mú ọmọ mi jáde déédéé, ṣugbọn ìyẹn kò bá a lọ títí níwọ̀n bí oun ti máa ń padà wálé pẹlu ayọ̀ tí ó pọ̀ síi tí ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ gbígbámúṣé sì fún un ní ìṣírí. Nígbà tí ó ṣì jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga, ó ṣèrìbọmi ó sì ń ṣiṣẹ́sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lóṣooṣù, nígbà tí ó sì jáde ní ilé-ẹ̀kọ́, ó di aṣáájú-ọ̀nà déédéé.” Ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ gbígbámúṣé papọ̀ pẹlu ṣiṣe ìfẹ́-inú Jehofa mú ìyọrísí tí ó dára wá.

Ó lè jẹ́ pé kò sí awọn ọ̀dọ́ tí wọn lè ní ipa ìdarí tí ó dára lórí ọmọ rẹ ládùúgbò, ṣugbọn àkíyèsí tí ọ̀pọ̀ awọn ọ̀dọ́ tí wọn yàn lati ṣiṣẹ́sin Jehofa ń ṣe nííṣe pẹlu àpẹẹrẹ awọn òbí wọn. Ọ̀pọ̀ awọn èwe ni wọn mọrírì awọn òbí wọn tí wọn sì ń fẹ́ lati ṣàfarawé wọn. Yuri rántí ẹ̀mí àlejò ṣíṣe tí ìyá rẹ̀ ní ati bí ó ṣe ń bìkítà fún awọn ẹlòmíràn, ní bíbá wọn sọ̀rọ̀ lórí tẹlifoonu tí ó sì ń gbọ́únjẹ fun awọn tí ń ṣàìsàn. Tatsuo, tí ó wá lati inú ìdílé ọlọ́mọ mẹ́rin, tí gbogbo wọn ti dàgbà tí wọn sì ń ṣiṣẹ́sin Jehofa nísinsìnyí, wí pé: “Mama kò lè kẹ́kọ̀ọ́ déédéé pẹlu wa nitori Dadi jẹ́ aláìgbàgbọ́ tí mama sì ń dojúkọ àtakò pupọ lati ọ̀dọ̀ awọn ìbátan. Ṣugbọn ṣíṣàkíyèsí ìdúró rẹ̀ fún òtítọ́ ati ìdùnnú rẹ̀ ninu ṣíṣiṣẹ́sin Jehofa ní ipa ìdarí ńláǹlà lórí mi. Ó sì tún ń múratán lati dúró tì wá títí di àfẹ̀mọ́jú lati lè ràn wá lọ́wọ́ lati yanjú awọn ìṣòro wa.” Awọn ọ̀rọ̀ ọlọgbọ́n tí ń tẹnu òbí jáde ní agbára bí a bá fi iṣẹ́ òdodo tì í lẹ́yìn. Yoichiro sọ nipa awọn òbí rẹ̀ pé: “Nkò lè rántí ìgbà kankan tí wọn sọ̀rọ̀ tí ó kún fún èrò òdì nipa awọn ẹlòmíràn ninu ìjọ; bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sì fàyègbà awa ọmọ lati ṣòfófó nipa àṣìṣe awọn ẹlòmíràn.”​—⁠Luku 6:​40-⁠42.

Ìdùnnú tí Ó Wà Ninu Rírí I Kí Awọn Ọmọ Yan Jehofa

Kò sí ìlànà àwòṣiṣẹ́ pípegedé tí ó lè ran awọn ọmọ rẹ lọ́wọ́ lati yan Jehofa. Ọ̀pọ̀ awọn sáà alánìíyàn yoo wà. Ṣugbọn baba tí ìdààmú bá tí a mẹ́nukàn níṣàájú wí pé: “Gẹ́gẹ́ bí òbí a ń gbìyànjú nígbà gbogbo lati máa tẹ̀lé awọn ìdámọ̀ràn tí ètò-àjọ Jehofa tí a lè fojúrí ń pèsè. Èyí jẹ́ ìrànwọ́ ńláǹlà ní bíborí awọn ìṣòro.” Ìsapá wọn yọrísírere.

Bẹ́ẹ̀ni, nipa sísa gbogbo ipá rẹ lati tẹ̀lé awọn ìtọ́sọ́nà Bibeli, kíkọ́ awọn ọmọ rẹ ní awọn ìdí yíyèkooro lati nífẹ̀ẹ́ Jehofa, tí o sì fi àpẹẹrẹ ìṣòtítọ́ ati ìsapá àtọkànwá rẹ lati ṣèrànwọ́ tì í lẹ́yìn, iwọ naa lè rí i pé a fi àṣeyọrí dé awọn ìsapá rẹ ládé nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín. Ṣé o rántí ọmọdékùnrin tí a sọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣáájú, tí ó ti fi ìgbà kan pinnu pé oun kì yoo di ọ̀kan lára awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa? Ó dára, lẹ́yìn tí ìyá rẹ̀ ti ràn án lọ́wọ́ la awọn ọdún lílekoko rẹ̀ já lọ́nà tí ó yọrísírere, ó wí pé: “Inú mi dùn pé oun kò dáwọ́ dúró!” Iwọ lè ní àbájáde kan naa pẹlu awọn ọmọ rẹ.​—⁠Galatia 6:⁠9.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A tẹ̀ ẹ́ jáde lati ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.

b Awọn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún ti awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni a ń pè ní aṣáájú-ọ̀nà. Aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ kan ń lo ó kérétán 60 wákàtí ninu iṣẹ́-òjíṣẹ́ lóṣooṣù, aṣáájú-ọ̀nà déédéé kan ń lo 90 wákàtí, tí aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe sì ń lo 140 wákàtí.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]

Iwọ ha lè bojúwẹ̀yìn kí o sì rántí awọn ohun tí ń mọ́kàn yọ̀ nipa títọ́ awọn ọmọ dàgbà?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́