ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w94 2/15 ojú ìwé 26-29
  • Ìgbàsókè-Ọ̀run Ìgbàgbọ́ Aláìjampata Tí Ọlọrun Ṣípayá Ha Ni Bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìgbàsókè-Ọ̀run Ìgbàgbọ́ Aláìjampata Tí Ọlọrun Ṣípayá Ha Ni Bí?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìrúyọ Ìgbàgbọ́ Aláìjampata Kan
  • Ohun tí Ìwé Mímọ́ Sọ Níti Gidi
  • Maria​—⁠Obìnrin Ìgbàgbọ́
  • “Wò Ó! Ẹrúbìnrin Jèhófà!”
    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
  • Àwọn Ohun Tá A Lè Kọ́ Lára Màríà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Ṣé Màríà Ni Ìyá Ọlọ́run?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • “Wò Ó! Ẹrúbìnrin Jèhófà!”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
w94 2/15 ojú ìwé 26-29

Ìgbàsókè-Ọ̀run Ìgbàgbọ́ Aláìjampata Tí Ọlọrun Ṣípayá Ha Ni Bí?

ÌGBÀSÓKÈ-Ọ̀RUN​—⁠ẹ̀kọ́-ìgbàgbọ́ náà pé Maria, ìyá Jesu, gòkè re ọ̀run nínú ẹran-ara​—⁠ni àràádọ́ta-ọ̀kẹ́ àwọn Roman Katoliki ṣìkẹ́. Òpìtàn náà George William Douglas sọ pé: “Ìgbàsókè-Ọ̀run, tàbí gbígbà lọ sí ọ̀run, ti Maria Wundia ni a ti ń jọ́sìn fún [ìgbà pípẹ́] gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó lókìkì jùlọ lára àwọn ayẹyẹ rẹ̀ àti ọ̀kan lára àwọn ayẹyẹ ìsìn pàtàkì Ṣọ́ọ̀ṣì náà lọ́dún.”

Ṣùgbọ́n, àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́-ìsìn Katoliki gbà pé Bibeli kò sọ̀rọ̀ nípa Maria pé ó gòkè lọ sí ọ̀run lọ́nà bẹ́ẹ̀. Nítòótọ́, ìwọ̀nba àwọn Katoliki ni wọ́n mọ̀ pé ẹ̀kọ́-ìgbàgbọ́ tí wọ́n yàn láàyò yìí ti jẹ́ ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ alárìíyànjiyàn àti èyí tí ó ń fa ìjiyàn kíkorò fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún. Nítorí náà báwo gan-⁠an ni ṣọ́ọ̀ṣì ṣe wá tẹ́wọ́gba Ìgbàsókè-Ọ̀run Maria gẹ́gẹ́ bí ìgbàgbọ́ aláìjampata?a Ìdí èyíkéyìí ha wà láti wò ó gẹ́gẹ́ bí èyí tí a ṣípayá látọ̀runwá bí? Ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí kò wulẹ̀ ní jẹ́ oréfèé lásán. Wọ́n ní ìtumọ̀ pàtàkì fún ẹni yòówù tí ó bá jẹ́ olùfẹ́ òtítọ́.

Ìrúyọ Ìgbàgbọ́ Aláìjampata Kan

Ó lè yà ọ́ lẹ́nu láti mọ̀ pé ní àwọn ọ̀rúndún àkọ́kọ́ lẹ́yìn ikú Jesu, èrò náà nípa Ìgbàsókè-Ọ̀run Maria ṣàjèjì pátápátá sí ìrònú àwọn Kristian. Ẹlẹ́kọ̀ọ́-ìsìn Katoliki náà Jean Galot kọ̀wé nínú ìwé-ìròyìn L’Osservatore Romano pé: “Ní ìpilẹ̀ṣẹ̀, ìrántí ikú Maria kò ní ìsokọ́ra kankan pẹ̀lú ẹgbẹ́ àwùjọ Kristian.”

Bí ó ti wù kí ó rí, lẹ́yìn tí ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan di ẹ̀kọ́-ìgbàgbọ́ ṣọ́ọ̀ṣì tí a fàṣẹ sí, Maria di ẹni tí a bẹ̀rẹ̀ síí fún ní ipa-iṣẹ́ pàtàkì lọ́nà tí ó túbọ̀ ń pọ̀ síi. Àwọn ọ̀rọ̀ tí ń buyìn fúnni, bíi “Ìyá Ọlọrun,” “tí ó lóyún láìní ẹ̀ṣẹ̀,” Alárinà-Obìnrin,” àti “Ọbabìnrin Ọ̀run,” ni a bẹ̀rẹ̀ sí lò fún un. Ẹlẹ́kọ̀ọ́-ìsìn náà Galot ronú pé, nígbà tí ó yá, “ẹ̀kọ́-àtọwọ́dọ́wọ́ ìgbà ìjímìjí tí a palẹ́numọ́ lórí ọ̀ràn ikú Maria kò lè tẹ́ àwọn Kristian wọnnì tí wọ́n mọ ìjẹ́pípé Maria dájú tí wọ́n sì fẹ́ láti jọ́sìn rẹ̀ lọ́rùn. Nípà báyìí, àwọn àpèjúwe Ìgbàsókè-Ọ̀run, tí ó jẹyọ láti inú ìrònúwòye gbígbajúmọ̀, fìdí múlẹ̀.”

Ní nǹkan bí ọ̀rúndún kẹrin C.E., àwọn ìwé lásán tí a fẹnu pè ní ti ìgbàsókè-ọ̀run bẹ̀rẹ̀ sí lọ káàkiri. Àwọn ìwé wọ̀nyí fúnni ní àwọn ìròyìn tí a ronúkọ nípa ohun tí a rò pé ó jẹ́ ìgòkè Maria lọ sí ọ̀run. Fún àpẹẹrẹ, ṣàgbéyẹ̀wò ẹsẹ ìwé tí a pè ní “Sísùn Ìyà Mímọ́ ti Ọlọrun.” Wọ́n ronú pé aposteli Johannu ni ó kọ ọ́, ṣùgbọ́n ó ṣeéṣe jùlọ kí a ti ronú kọ ọ́ ní nǹkan bíi 400 ọdún lẹ́yìn ikú Johannu. Gẹ́gẹ́ bí ayédèrú àkọsílẹ̀ yìí ti sọ, àwọn aposteli Kristi ni a kójọ sọ́dọ̀ Maria lọ́nà àrà, níbi tí wọ́n ti rí i tí ó wo afọ́jú, adití, àti arọ sàn. Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, gẹ́gẹ́ bí ibí yìí ti sọ, àwọn aposteli gbọ́ tí Oluwa sọ fún Maria pé: “Kíyèsí i, láti ìsinsìnyí lọ ni a óò ta ara rẹ ṣíṣeyebíye ní àtaré lọ sínú paradise, ọkàn mímọ́ rẹ yóò sì wà nínú àwọn ọ̀run nínú àwọn àpótí ìṣúra Baba mi nínú ìmọ́lẹ̀yòò tí kò láfiwé, níbi tí àlááfíà àti ìdùnnú àwọn angẹli mímọ́ wà, àti wíwà títí gbére pẹ̀lú.”

Báwo ni àwọn onígbàgbọ́ ṣe hùwàpadà sí irú àwọn ìwé bẹ́ẹ̀? Onímọ̀ nípa Maria Wúńdíá René Laurentin ṣàlàyé pé: “Àwọn ìhùwàpadà náà yàtọ̀ gan-⁠an ni. Àwọn tí wọ́n tètè máa ń gbàgbọ́ láìwádìí ni a tànjẹ nípasẹ̀ ìdángbinrin ìtàn tí ó dùn-⁠ún-⁠gbọ́ náà, láìsí ìronúsíwásẹ́yìn síwájú síi mọ́. Àwọn mìíràn tẹ́ḿbẹ́lú àwọn àkọsílẹ̀ tí kò ṣọ̀kandélẹ̀ wọ̀nyí, èyí tí ó sábà máa ń takora tí kò sì ní ọlá-àṣẹ.” Nípa báyìí ó gba ìjàkadì fún àbá-èrò-orí ti Ìgbàsókè-Ọ̀run láti di èyí tí a tẹ́wọ́gbà lọ́nà àfàṣẹtìlẹ́yìn. Èyí tí ó tún fi kún ìdàrúdàpọ̀ náà ni òtítọ́ náà pé àwọn ohun tí a tànmọ́ọ̀ pé wọ́n jẹ́ ohun-ìrántí-àtijọ́ fún ara Maria ni àwọn kan ti ń jọ́sìn ní àwọn ibìkan. Ó ṣòro láti mú èyí báramu pẹ̀lú èrò-ìgbàgbọ́ náà pé ara ìyára rẹ̀ ní a ti gba lọ sókè ọ̀run.

Ní ọ̀rúndún kẹtàlá, Thomas Aquinas, bíi ti ọ̀pọ̀ àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn mìíràn, gbàgbọ́ pé kò ṣeéṣe láti ṣàlàyé Ìgbàsókè-Ọ̀run gẹ́gẹ́ bí ìgbàgbọ́ aláìjampata kan, níwọ̀n bí “Ìwé Mímọ́ kò ti fi í kọ́ni.” Síbẹ̀, èrò-ìgbàgbọ́ náà ń báa lọ láti máa gbajúmọ̀ síi, ìyàwòrán àwọn ohun tí a tànmọ́ọ̀ pé wọ́n jẹ́ ìgbàsókè-ọ̀run Maria láti ọwọ́ àwọn ayàwòrán tí a mọ̀ bí-ẹní-mowó bíi Raphael, Correggio, Titian, Carracci, àti Rubens sì ń pọ̀ síi.

Ọ̀ràn àríyànjiyàn náà ṣì wà láìlójútùú títí di ẹnu àìpẹ́ yìí. Gẹ́gẹ́ bí onísìn Jesuit Giuseppe Filograssi ti sọ, tipẹ́tipẹ́ sẹ́yìn láti apá ìdajì àkọ́kọ́ nínú ọ̀rúndún wa, àwọn ọ̀mọ̀wé-àkẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ Katoliki ń báa lọ láti máa tẹ “àwọn ẹ̀kọ́-ìwádìí àti ìjíròrò tí kìí fìgbà gbogbo gbè sẹ́yìn” àbá-èrò-orí Ìgbàsókè-Ọ̀run jáde. Àní àwọn popu pàápàá, irú bíi Leo XIII, Pius X, àti Benedict XV, “ni wọ́n kúkú yàn láti máṣe sọ̀rọ̀ lórí kókó-ọ̀ràn náà.” Ṣùgbọ́n ní November 1, 1950, ṣọ́ọ̀ṣì mú ipò ìdúró pàtó kan nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín. Pope Pius XII kéde pé: “Àwa túmọ̀ rẹ̀ pé ó jẹ́ ìgbàgbọ́ aláìjampata kan tí Ọlọrun ṣípayá pé Ìyá Ọlọrun Aláìlẹ́ṣẹ̀, Maria tíí ṣe Wúńdíá títíláé, nígbà tí ó parí ipa-ọ̀nà ìwàláàyè rẹ̀ lórí ilẹ̀-ayé, ní a gbàsókè tara tọkàn sínú ògo ti ọ̀run.”​—⁠Munificentissimus Deus.

Ìgbàgbọ́ nínú ìrìn-àjò Maria lọ sí ọ̀run nínú ara kìí tún ṣe ọ̀ràn yàn-⁠bí-⁠o-⁠bá-⁠fẹ́ mọ́ láàárín àwọn Katoliki​—⁠ó ti di ìgbàgbọ́ aláìjampata tí Ṣọ́ọ̀ṣì ní nísinsìnyí. Pope Pius XII polongo pé “bí ẹnikẹ́ni . . . bá dán an wò láti kọ̀ tàbí fínnú-fíndọ̀ gbé ìyèméjì dìde lórí ohun tí Àwa ti túmọ̀, ó níláti mọ̀ pé òun kò kúnjú òṣùwọ̀n Ìgbàgbọ́ Àtọ̀runwá àti ti Katoliki mọ́.”

Ohun tí Ìwé Mímọ́ Sọ Níti Gidi

Ṣùgbọ́n lórí ìpìlẹ̀ wo ni ṣọ́ọ̀ṣì mú ipò ìdúró aláìṣojo yìí? Pope Pius XII jẹ́wọ́ pé ìgbàgbọ́ aláìjampata ti Ìgbàsókè-Ọ̀run ní “ìpìlẹ̀ rẹ̀ tí ó ga jùlọ nínú Ìwé Mímọ́.” Lárá àwọn ẹsẹ-ìwé tí wọ́n sábà máa ń tọ́ka sí gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí ìdánilójú nípa ìgbàsókè Maria ni Luku 1:​28, 42. Àwọn ẹsẹ wọ̀nyí sọ nípa Maria pé: “Mo kí ọ, ìwọ ẹni tí ó kún fún oore-ọ̀fẹ́, Oluwa wà pẹ̀lú rẹ: alábùkúnfún ni ìwọ láàárín àwọn obìnrin . . . , alábùkúnfún sì ni ọmọ inú rẹ.” (Douay) Àwọn onígbàgbọ́ nínú ìgbàsókè-ọ̀run ronu pé nítorí pé Maria “kún fún oore-ọ̀fẹ́,” ikú kò gbọ́dọ̀ borí rẹ̀ láé. Níwọ̀n bí ó sì ti jẹ́ “alábùkúnfún” bíi tí “ọmọ inú rẹ̀,” òun gbọ́dọ̀ ní àwọn àǹfààní tí ó dọ́gba pẹ̀lú ti Jesu​—⁠títíkan ìgòkè-re-ọ̀run rẹ̀. Ìwọ ha ronú pé ìrònú tí ó yèkooro ni èyí jẹ́ bí?

Ohun kan ni pé, àwọn ọ̀mọ̀wé-akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ nípa èdè sọ pé gbólóhùn ọ̀rọ̀ náà “kún fún oore-ọ̀fẹ́” jẹ́ ìtumọ̀ kan tí kó ṣe pàtó àti pé gbólóhùn ọ̀rọ̀ ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà tí Luku lò ni a túmọ̀ lọ́nà tí ó túbọ̀ péye sí “ẹni tí Ọlọrun fi ojúrere-ìṣeun hàn sí.” Nípa báyìí Jerusalem Bible ti Katoliki túmọ̀ Luku 1:28 pé: “Yọ̀, ẹni tí a fojúrere-ìṣeun hàn sí lọ́nà gíga!” Kò sí ìdí kankan láti parí-èrò pé Maria ni a gbà lọ sókè ọ̀run nínú ara kìkì nítorí pé Ọlọrun ‘fojúrere-ìṣeun hàn sí i lọ́nà gíga.’ Kristian ajẹ́rìíkú àkọ́kọ́, Stefanu, ni a sọ̀rọ̀ bákan náà nípa rẹ̀ nínú Bibeli Douay ti Katoliki pé a fojúrere-ìṣeun hàn sí lọ́nà gíga, tàbí “kún fún oore-ọ̀fẹ́”​—⁠kò sì sí àjíǹde nínú ara kankan tí a tíì sọ pé ó ní.​—⁠Iṣe 6:8.

Síbẹ̀, Maria kìí ha ṣe alábùkúnfún tàbí ẹni tí a fojúrere-ìṣeun hàn sí bí? Bẹ́ẹ̀ni, ṣùgbọ́n lọ́nà tí ó gbàfiyèsí, obìnrin kan tí a pé ní Jaeli nígbà náà lọ́hùn-⁠ún ní ọjọ́ àwọn onídàájọ́ Israeli ni a kà sí “alábùkúnfún láàárín àwọn obìnrin.” (Awọn Onidajọ 5:24, Dy) Dájúdájú kò sí ẹni tí yóò jiyàn pé Jaeli pẹ̀lú ni a gbà lọ sọ́run nínú ara. Yàtọ̀ sí ìyẹn, gbogbo èrò náà nípa Ìgbàsókè-Ọ̀run ni a gbékarí èrò náà pé Jesu fúnraarẹ̀ gòkè re ọ̀run nínú ẹ̀ran-ara. Bí ó ti wù kí ó rí, Bibeli sọ pé Jesu ni a “sọdi ààyè,” tàbí jíǹde, “nínú ẹ̀mí.” (1 Peteru 3:18, Dy; fiwé 1 Korinti 15:45.) Aposteli Paulu sọ síwájú síi pé “ẹran-ara àti ẹ̀jẹ̀ kò lè ní ìjọba ti Ọlọrun ní-ìní.”​—⁠1 Korinti 15:​42-⁠50, Dy.

Lóòótọ́, Bibeli sọ̀rọ̀ nípa àjíǹde ti òkè ọ̀run fún àwọn Kristian olùṣòtítọ́ tí a fi ẹ̀mí mímọ́ yàn. Bí ó ti wù kí ó rí, 1 Tessalonika 4:​13-⁠17 mú kí ó ṣe kedere pé àjíǹde yìí kì yóò bẹ̀rẹ̀ títí “wíwàníhìn-⁠ín Oluwa,” ní àkókò àwọn ọjọ́ ìkẹyìn sànmánì búburú yìí. Títí di ìgbà náà, Maria yóò ṣì wá nínú oorun ikú, papọ̀ pẹ̀lú ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Kristian olùṣòtítọ́ mìíràn.​—⁠1 Korinti 15:​51, 52.

Maria​—⁠Obìnrin Ìgbàgbọ́

Ní ìdánilójú pé ní sísọ àwọn ohun tí a ti sọ lókè yìí àwa kò ní àìbọ̀wọ̀ fún Maria lọ́kàn. Láìsí iyèméjì, obìnrin àwòfiṣàpẹẹrẹ ni Maria jẹ́​—⁠ẹni náà tí ìgbàgbọ́ rẹ̀ yẹ ní fífarawé. O fí ìmúratán tẹ́wọ́gba àǹfààní ẹrù-iṣẹ́ ti dídi ìyá Jesu, papọ̀ pẹ̀lú àwọn àdánwò àti ìrúbọ tí ìyẹn yóò ní nínú. (Luku 1:38; 2:34, 35) Papọ̀ pẹ̀lú Josefu, ó tọ́ Jesu dàgbà nínú ọgbọ́n Ọlọrun. (Luku 2:​51, 52) Ó dúró ti Jesu nígbà ìjìyà rẹ̀ lórí òpó-igi. (Johannu 19:​25-⁠27) Àti gẹ́gẹ́ bí olùṣòtítọ́ ọmọ-ẹ̀yìn kan, ó fi pẹ̀lú ìgbọràn dúró sí Jerusalemu ó sì ní ìrírí ìtújáde ẹ̀mí Ọlọrun ní Pentekosti.​—⁠Iṣe 1:13, 14; 2:1-⁠4.

Ojú-ìwòye kan tí a lọ́po nípa Maria kò bọlá fún yálà Ẹlẹ́dàá tàbí Maria. Ìgbàgbọ́ aláìjampata ti Ìgbàsókè-Ọ̀run ń ṣiṣẹ́ láti túbọ̀ mú ìjẹ́wọ́ aláìnípìlẹ̀ náà pé Maria jẹ́ olùṣìpẹ̀ fúnni lọ́dọ̀ Ọlọrun lágbára síi. Ṣùgbọ́n Jesu Kristi ha fọwọ́sí irúfẹ́ ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀ rí bí? Ní ìyàtọ̀ sí ìyẹn, ó sọ pé: “Èmi ni ọ̀nà, àti òtítọ́, àti ìyè: kò sí ẹnikẹ́ni tí ó lè wá sọ́dọ̀ Baba, bíkòṣe nípasẹ̀ mi. Bí ẹ̀yin bá béèrè ohunkóhun ní orúkọ mi, èmi ó ṣe é.” (Johannu 14:​6, 14; fiwé Iṣe 4:12.) Bẹ́ẹ̀ni, Jesu Kristi nìkanṣoṣo, ni ó ń bẹ̀bẹ̀ lọ́dọ̀ Ẹlẹ́dàá, kìí ṣe Maria. Nípasẹ̀ Jesu​—⁠kìí ṣe Maria⁠—​ni a níláti tọ Olùfúnni-⁠ní-Ìyè wa lọ fún “ìrànlọ́wọ́ ní ìgbà àìní.”​—⁠Heberu 4:16, Revised Standard Version, Catholic Edition.

Gbígba òtítọ́ nípa Maria lè ni àwọn kan lára. Ó kérépin, ó lè túmọ̀sí kíkọ àwọn èrò-ìgbàgbọ́ kan tí wọ́n ti dìmú tipẹ́tipẹ́ àti àwọn èròǹgbà tí wọ́n ṣìkẹ́ sílẹ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, bí ó tilẹ̀ lè nira ní àwọn ìgbà mìíràn, òtítọ́ ‘ń sọni dòmìnira’ níkẹyìn. (Johannu 8:32) Jesu sọ pé Baba òun ń wá àwọn wọnnì tí wọn yóò jọ́sìn ní “ẹ̀mí àti ní òtítọ́.” (Johannu 4:24, Dy) Sí àwọn Katoliki olótìítọ́-inú, àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí dúró gẹ́gẹ́ bí ìpèníjà kan.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Nínú ìsìn Katoliki, ìgbàgbọ́ aláìjampata kan, láìdàbí èrò-ìgbàgbọ́ kan tí ó rọrùn, ni a sọ pé ó jẹ́ òtítọ́ kan tí a fi ìrònújinlẹ̀ gbékalẹ̀ yálà nípasẹ̀ àjọ aṣojú fún gbogbo ṣọ́ọ̀ṣì àgbáyé tàbí nípasẹ̀ “ọlá-àṣẹ ìkọ́ni aláìlèṣàṣìṣe” ti popu. Lára àwọn ẹ̀kọ́-ìgbàgbọ́ tí Ṣọ́ọ̀ṣì Katoliki túmọ̀ lọ́nà bẹ́ẹ̀, Ìgbàsókè-Ọ̀run Maria ni ó jẹ́ ti lọ́ọ́lọ́ọ́ jùlọ.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 27]

MARIA HA KÚ BÍ?

Maria ha kú níti gidi ṣáájú ìgòkè re ọ̀run rẹ̀ tí a tànmọ́ọ̀ bí? Àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́-ìsìn Katoliki dojúkọ àwọn yíyàn méjì tí kò bárarẹ́ níti ẹ̀kọ́-ìsìn lórí ọ̀ràn àríyànjiyàn yìí. Ìwé Nuovo dizionario di teologia ṣàlàyé pé “yóò ṣòro láti gbà pé Maria ní àǹfààní àjẹsára kúrò lọ́wọ́ ikú, èyí tí Kristi fúnraarẹ̀ kò ní.” Ní ọwọ́ mìíràn ẹ̀wẹ̀, sísọ pé Maria kú níti gidi bákan náà gbé ọ̀ràn àríyànjiyàn lílekoko dìde. Ẹlẹ́kọ̀ọ́-ìsìn Kari Børresen ṣàlàyé pé “ikú ni ìjìyà fún ẹ̀ṣẹ̀ ìpilẹ̀ṣẹ̀, èyí tí, gẹ́gẹ́ bí [ẹ̀kọ́-ìgbàgbọ́ “Ìlóyún Mímọ́ Asọ̀yádaláìlẹ́ṣẹ̀”] ti sọ, kò kan Maria.” Nígbà náà, lórí ìpìlẹ̀ wo ni òun ti níláti kú? Kò yanilẹ́nu pé Popu Pius XII fìṣọ́ra yẹra fún gbogbo ọ̀ràn-àríyànjiyàn nípa ikú Maria pátápátá nígbà tí ó ń túmọ̀ ìgbàgbọ́ aláìjampata ti Ìgbàsókè-Ọ̀run náà.

Ó dùnmọ́ni pé ẹ̀kọ́ Bibeli kò ní irú ìdàrúdàpọ̀ bẹ́ẹ̀. Kò sí ibikíbi tí ó ti kọ́ni​—⁠tàbí tanilólobó⁠—​pé Maria jẹ́ ìmújáde “ìlóyún mímọ́ asọ̀yádaláìlẹ́ṣẹ̀,” Ní ìyàtọ̀ pátápátá, ó fihàn pé Maria jẹ́ ènìyàn aláìpé tí ó nílò ìtúnràpadà. Fún ìdí yìí, lẹ́yìn ìbí Jesu, ó lọ sínú tẹ́ḿpìlì ó sì rú ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ sí Ọlọrun. (Lefitiku 12:​1-⁠8; Luku 2:​22-⁠24) Bíi ti gbogbo àwọn ènìyàn aláìpé yòókù, Maria kú ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀.​—⁠Romu 3:23; 6:⁠23.

Òtítọ́ tí kò lọ́júpọ̀ yìí yàtọ́ gédégédé sí àwọn ìbéèrè aládììtú tí ìgbàgbọ́ aláìjampata nípa Ìgbàsókè-Ọ̀run gbé dìde.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

‘Ìgbàsókè-Ọ̀run Wúńdíá,’ tí Titian (nǹkan bíi 1488-1576) fi ọ̀dà yàwòrán rẹ̀

[Credit Line]

Giraudon/Art Resource, N.Y.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]

Nípa mímú ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ wá sí tẹ́ḿpìlì lẹ́yìn ìbí Jesu, Maria polongo araarẹ̀ ní ẹlẹ́ṣẹ̀ tí ó nílò ìtúnràpadà

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́