ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w94 3/1 ojú ìwé 24-28
  • ‘Ọwọ́ Jehofa’ Nínú Ìgbésí-Ayé Mi

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • ‘Ọwọ́ Jehofa’ Nínú Ìgbésí-Ayé Mi
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìgbòkègbodò Ìwàásù ní Ìbẹ̀rẹ̀
  • A Fòfinde Iṣẹ́ Wa ní Canada
  • Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Apá Ẹ̀ka Iṣẹ́-Ìsìn Alákòókò Kíkún
  • Títọ́ Àwọn Ọmọ Wa ní Brazil
  • Pípadà sí Canada
  • Ìpinnu Tó Tọ́ Yọrí Sí Ìbùkún Jálẹ̀ Ìgbésí Ayé Mi
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ṣíṣiṣẹ́ Sin Jèhófà Gẹ́gẹ́ Bí Ìdílé Tí Ó Wà Níṣọ̀kan
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Jèhófà Fi Inú Rere Àìlẹ́tọ̀ọ́sí Hàn sí Wa Lónírúurú Ọ̀nà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2017
  • Lilepa Gongo Kan Ti Mo Ti Gbekalẹ Ní Ọmọ Ọdun Mẹfa
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
w94 3/1 ojú ìwé 24-28

‘Ọwọ́ Jehofa’ Nínú Ìgbésí-Ayé Mi

GẸ́GẸ́ BÍ LAWRENCE THOMPSON TI SỌ Ọ́

NÍ ALẸ́ ọjọ́ kan ní ọdún 1946, èmi àti baba mi jókòó sínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tí a sì ń wo iná alẹ́ mèremère tí ń kọ mànà síwá-sẹ́yìn lójú ọ̀run. A sọ̀rọ̀ nípa ọláńlá Jehofa àti bí àwa ti kéré tó. A ṣèrántí àwọn ìrírí ọdún tí iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa wà lábẹ́ ìfòfindè ní Canada. Baba tẹ bí Jehofa ti mú àwọn ènìyàn Rẹ̀ dúró tí ó sì ṣamọ̀nà wọn la àwọn ọdún wọnnì já mọ́ mi lọ́kàn.

BÍ Ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọ ọdún 13 péré ni mí, mo lóye òtítọ́ ohun tí Baba ń sọ. Ó tún tẹ níní èrò ìjẹ́kánjúkánjú àti bí iṣẹ́ ìwàásù tí ó ṣì wà láti ṣe ti gbòòrò tó mọ́ mi lọ́kan. Baba fa ọ̀rọ̀ inú Numeri 11:23 yọ ó sì tẹnumọ́ ọn fún mi pé, níti gidi, ọwọ́ Jehofa kò kúrú rárá. Kìkì àìnígbàgbọ́ àti àìnígbẹkẹ̀lé wa nínú rẹ̀ ni ó ń dín ohun tí yóò ṣe fún wa kù. Ó jẹ́ ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ tibaba-tọmọ kan tí ó ṣeyebíye, ọ̀kan tí èmi kì yóò gbàgbé láé.

Kíkẹ́kọ̀ọ́ àwọn ìtẹ̀jáde Watch Tower, ní pàtàkì ìwé náà Salvation, tí a tẹ̀ jáde ní 1939, tún nípa lórí ìbẹ̀rẹ̀ ìgbésí-ayé mi lọ́nà títóbi jọjọ. Èmi kò jẹ́ gbàgbé àpèjúwe amúnijígìrì inú ìwé náà: “Ọkọ̀ ojú-irin ayára-⁠bí-àṣá, tí ó kún fún èrò, ń śaré lọ ní nǹkan bíi 160 kìlómítà ní wákàtí kan. Ó gbọ́dọ̀ gba orí afárá títẹ̀ wọ́rọ́kọ́ kan sọdá odò, débi pé àwọn ènìyàn tí wọ́n wà lórí pèpéle apá ẹ̀yìn ọkọ̀ náà yóò rí ẹ̀rọ ọkọ̀ náà . . . Àwọn ọkùnrin méjì tí wọ́n wà lórí pèpéle apá ẹ̀yìn . . . ríi pé afárá náà láàárín òpó kan sí ìkejì lápá ibi tí ó parí sí ní òdìkejì lọ́hùn-⁠ún ti ń jóná ó sì ń já sínú odò. Wọ́n mọ̀ pé ewu ńlá dojúkọ wọ́n. Ipò pàjáwìrì gan-⁠an nìyẹn. A ha lè dá ọkọ̀ ojú-irin náà dúró lásìkò láti gba ẹ̀mí ọ̀pọ̀ èrò tí ń bẹ nínú ọkọ̀ náà là bí?”

Ní mímú àpèjúwe náà lò, ìwé náà parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Bákan náà lónìí, gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè àti àwọn ènìyàn ilẹ̀-ayé dojúkọ ipò pàjáwìrì títóbi jùlọ. A ń kìlọ̀ fún wọn gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti pa á láṣẹ, pé àjálù Armageddoni wà níwájú. . . . Lẹ́yìn gbígba ìkìlọ̀, ẹnìkọ̀ọ̀kan tí a tipa báyìí kìlọ̀ fún gbọ́dọ̀ yan ipa-ọ̀nà tí òun yóò tọ̀ nísinsìnyí.”

Ọkọ̀ ojú-irin ayára-⁠bí-àṣá náà, afárá tí ń jóná, àti ìjẹ́kánjúkánjú iṣẹ́ ìwàásù náà ni a gbìn sí mi lọ́kàn lọ́nà tí kò ṣeé parẹ́.

Ìgbòkègbodò Ìwàásù ní Ìbẹ̀rẹ̀

Mo bẹ̀rẹ̀ síí kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù náà ní ọdún 1938, nígbà tí mo jẹ́ ọmọ ọdún márùn-⁠ún. Henry àti Alice Tweed, àwọn aṣáájú-ọ̀nà méjì (àwọn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún) yóò mú kí n bá àwọn lọ, tí a ó sì lo wákàtí 10 sí 12 lóòjọ́ ní bíbá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀. Mo gbádùn àwọn odindi ọjọ́ wọ̀nyẹn dáradára nínú iṣẹ́-ìsìn Jehofa. Nítorí náà mo kún fún ayọ̀ ní ọdún tí ó tẹ̀lé e nígbà tí Baba ati Màmá yọ̀ǹda fún mi láti di akéde kí n sì máa ròyìn ìgbòkègbodò mi níti gidi.

Ní àwọn àkókò ìbẹ̀rẹ̀ wọ̀nyẹn, a lọ́wọ́ nínú gbígbé ìsọfúnni káàkiri, ní rírìn la àwọn òpópónà pàtàkì nínú àwọn ìlú já ní gbígbé àwọn pátákó ìsọfúnni tí ó ní àwọn àkọlé tí ó tú ìsìn èké fó tí ó sì ń polongo Ìjọba Ọlọrun kọ́rùn. A tún lo àwọn rẹ́kọ́ọ̀dù tí ó ṣeé gbérìn tí a sì ń gbé àwo àwọn ìhìn-iṣẹ́ Bibeli síi lẹ́nu ọ̀nà àwọn onílé gan-⁠an. Àwa yóò gbé àwọn ọ̀rọ̀ J. F. Rutherford, ààrẹ Watch Tower Society síi, mo sì kọ́ díẹ̀ lára wọn ní àkọ́sórí. Mo ṣì lè gbọ́ ọ tí ó sọ pé: “A ti sábà máa ń sọ pé, Ìsìn jẹ́ ìdẹkùn àti wàyó!”

A Fòfinde Iṣẹ́ Wa ní Canada

Nígbà ogun àgbáyé kejì, a fòfinde iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní Canada, gẹ́gẹ́ bí ó ti rí ní ilẹ̀ Germany ti ẹgbẹ́ òṣèlú Nazi ati àwọn ilẹ̀ mìíràn. Nítorí náà, a ń lo Bibeli nìkan ṣùgbọ́n a ń bá iṣẹ́ tí Ọlọrun pa láṣẹ nìṣó ní ìṣègbọràn sí àwọn ìtọ́ni Bibeli. (Matteu 28:​19, 20; Iṣe 5:29) A kẹ́kọ̀ọ́ láti kojú ìgbóguntini àwọn ọlọ́pàá sí àwọn ìpàdé àti ilé wa. A tún ní ìrírí nípa jíjẹ́rìí sí ọ̀ràn níwájú àwọn adájọ́ àti dídáhùn sí àwọn ìbéèrè tí a fi ń wádìí ọ̀ràn wò.

Èmi àti arákùnrin mi Jim di ọ̀jáfáfá nínú jíju àwọn ìwé kékeré láti inú ọkọ̀ sí ẹnu ọ̀nà àti gbàgede. Ní àfikún, a ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí asáréjíṣẹ́ àti, nígbà mìíràn, gẹ́gẹ́ bí adènà fún àwọn wọnnì tí wọ́n ń sọdá ibodè láti lọ sí àwọn àpéjọpọ̀ ní United States.

Ilé wa wà ní ẹ̀yìn òde ìlú Port Arthur (Thunder Bay nísinsìnyí), Ontario, lórí sarè méjì ilẹ̀ tí igi àti igbó yíká. A ní màlúù kan, ọmọ màlúù, àwọn ẹlẹ́dẹ̀, àti àwọn adìyẹ àṣẹ́sìn​—⁠gbogbo èyí tí ó ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí arúmọjẹ fún iṣẹ́ ṣíṣe ìtìlẹ́yìn fún àwọn ọ̀dọ́ Kristian ẹlẹgbẹ́ wa tí wọ́n ń dọdẹ kiri láti sọ sẹ́wọ̀n nítorí wíwàásù Ìjọba Ọlọrun.

Ní alẹ́, bí àwọn ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́, ọkọ̀ akẹ́rù, àti ọkọ̀ eléjò tí ó gbé àwọn ọ̀dọ́ Kristian ṣe ń wọlé, ni wọ́n ń jáde nínú ọgbà wa tí ó pamọ́ náà. Àwa yóò gba àwọn ọ̀dọ́ wọ̀nyí sílé, pa wọ́n mọ́, mú kí wọ́n farahàn lọ́nà tí ó yàtọ̀, a óò bọ́ wọn tí a óò sì jẹ́ kí wọn máa bá ọ̀nà wọn lọ. Baba àti màmá mi, papọ̀ pẹ̀lú àwọn alábàáṣiṣẹ́ ìgbà ìbẹ̀rẹ̀ wọnnì, jẹ́ àwọn ìránṣẹ́ olùfọkànsìn tí wọ́n mú kí ọkàn-àyà mi tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń dàgbà nífẹ̀ẹ́ láti ṣiṣẹ́sìn kí n sì nífẹ̀ẹ́ Jehofa Ọlọrun.

Ní August 1941, mo ya ìgbésí-ayé mi sí mímọ́ fún Jehofa a sì baptisi mi nínú adágún odò kékeré kan nínú ẹgàn. Àwa mélòókan ti kórajọ fún ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ní òru nínú iyàrá inú ọkọ̀ kan tí a tan iná sí. Bí ó ti farahàn pé ará fu wọ́n, àwọn ọlọ́pàá ṣe ìwọ́de, ní fífi iná wá inú adágún náà kiri, ṣùgbọ́n wọn kò rí wa.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Apá Ẹ̀ka Iṣẹ́-Ìsìn Alákòókò Kíkún

Ní 1951, mo jáde ilé-ẹ̀kọ́ gíga mo sì rìnrìn-àjò tí ó tó 1,600 kìlómítà láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà ni Cobourg, Ontario. Ìjọ náà kéré, èmi kò sì ní aṣáájú-ọ̀nà alábàáṣiṣẹ́. Ṣùgbọ́n ní rírántí pé ọwọ́ Jehofa kò kúrú, mo háyà iyàrá kan, mo sì ń gbọ́únjẹ fúnraàmi, mo sì láyọ̀ láti máa ṣiṣẹ́sin Jehofa. Ní ọdún tí ó tẹ̀lé e, a késí mi láti ṣiṣẹ́sìn ní ẹ̀ka Watch Tower Society tí ó wà ní Toronto. Níbẹ̀ ni mo ti kọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀kọ́ ṣíṣeyebíye tí ó múra mi sílẹ̀ fún iṣẹ́-ìsìn Ijọba tí ń bẹ níwájú.

Lẹ́yìn ti mo ti ṣiṣẹ́sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà fún ohun tí ó ju ọdún kan lọ ní Toronto, èmi àti Lucy Trudeau ṣègbéyàwó, ní ìgbà otútù ọdún 1954, a gba iṣẹ́ àyànfúnni aṣáájú-ọ̀nà sí Levis, Quebec. Ojú ọjọ́ tutù nini, ìhalẹ̀mọ́ni àwùjọ àwọn ènìyànkénìyàn àti àwọn ọlọ́pàá máyàjáni, ó sì jẹ́ ìpèníjà láti kọ́ èdè French. Jálẹ̀ gbogbo èyí, ọwọ́ Jehofa kò kúrú rárá, nítorí náà nígbà tí ó jẹ́ pé àwọn àkókò lílekoko wà, a ní ọ̀pọ̀ ìbùkún pẹ̀lú.

Fún àpẹẹrẹ, a sọ fún wa láti ṣàyẹ̀wò ọkọ̀ ojú-omi méjì (Arosa Star àti Arosa Kulm) tí Society wéwèé láti lò fún gbígbé àwọn àyànṣasojú lọ sí àwọn àpéjọpọ̀ ńlá Europe ti 1955. Nítorí àníyàn tí wọ́n ní fún ṣíṣojú iṣẹ́-ajé fún Society, àwọn lọ́gàálọ́gàá ní ilé-iṣẹ́ tí ń ṣòwò ọkọ̀ ojú-omi máa ń ṣe wá lálejò lẹ́kọ̀ọ̀kan, èyí tí ó jẹ́ àkókò ìtura gbígbádùnmọ́ni kúrò nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ tí ó kún fún másùnmáwo ní Quebec ní àkókò yẹn.

Ní ìgbà ìwọ́wé 1955, a késí mi láti ṣiṣẹ́sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó arìnrìn-àjò, a sì lo ìgbà otútù yẹn láti ṣèbẹ̀wò sí àwọn ìjọ àdádó ni àríwá Ontario títutù nini. Ní ọdún tí ó tẹ̀lé e a lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ Watchtower Bible School of Gilead ní United States, àti lẹ́yìn náà a yàn wá gẹ́gẹ́ bíi míṣọ́nnárì sí Brazil, ní South America.

Tọkàntara ni a fi bẹ̀rẹ̀ síí ṣiṣẹ́ níbi iṣẹ́ àyànfúnni wa titun kò sì pẹ́ rárá tí a fi lè wàásù kí a sì kọ́ni ní èdè Portuguese. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1957, a padà yàn mí láti ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí alábòójútó arìnrìn-àjò. Nísinsìnyí, dípò otútù nini ti Àríwá, a níláti kojú ooru gbígbóná janjan. Ní ọ̀pọ̀ ìgbà ni a níláti dúró kí a sì da erùpẹ̀ tí ń jóni kúrò nínú bàtà wa tàbí kí a bẹ́ ìrèké fún jíjẹrìn lati sọ okun wa dọ̀tun. Ṣùgbọ́n àwọn ìbùkún wà.

Ní ìlú Regente Feijo, mo bá ọ̀gá ọlọ́pàá sọ̀rọ̀, ó sì pàṣẹ pé kí a ti gbogbo ilé ìtajà kí gbogbo ènìyàn sì lọ sí gbàgede ìlú. Lábẹ́ ìbòji igi eléwé fẹ̀rẹ̀gẹ̀dẹ̀ kan tí ń yọ ìtàná, mo sọ ọ̀rọ̀-àsọyé Bibeli fún gbogbo àwọn ará ìlú náà. Lónìí ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí kan wà níbẹ̀.

Títọ́ Àwọn Ọmọ Wa ní Brazil

Nígbà tí Lucy lóyún ní 1958, a fìdíkalẹ̀ sí Juiz de Fora a sì ṣiṣẹ́sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe. Láàárín ọdún méjì tí ó tẹ̀lé e, a bí àwọn ọmọbìnrin wa, Susan àti Kim. Wọ́n jásí ìbùkún gidi nínú iṣẹ́-ìsìn náà, wọn di ohun àjèjì nínú ìlú. Bí a ti ń fa kẹ̀kẹ́ ìgbọ́mọsí wọn kọjá ní àwọn òpópónà olókùúta, àwọn ènìyàn yóò jáde wá láti wò wọ́n. Níwọ̀n bí àìní ti pọ̀ fún àwọn akéde Ìjọba ni Recife, tí ó wà ní ìsàlẹ̀ agbedeméjì ìbú ayé, a ṣí lọ sí ibi gbígbóná janjan yẹn.

Ní 1961, kìí ṣe pé o ṣeéṣe fún mi láti ṣètò ọkọ̀ òfuurufú fún àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n ń lọ sí àpéjọpọ̀ ni São Paulo nìkan ni ṣùgbọ́n èmi pẹ̀lú lọ sí àpéjọpọ̀ mánigbàgbé yẹn. Ṣùgbọ́n, ní nǹkan bí 20 ìṣẹ́jú lẹ́yìn tí a ti gbéra, ọkọ̀ òfuurufú náà já dòò wálẹ̀, tí àwọn èrò tí ó kó sì fọ́n káàkiri inú rẹ̀. Inú ọkọ̀ òfuurufú náà bàjẹ́; àwọn ìjókòó fòyọ kúrò lára ìdè, àwọn èrò sì farapa. A láyọ̀ pé, ó ṣeéṣe fún awakọ̀ òfuurufú náà láti dù ú kí ọkọ̀ náà máṣe fàyà gbálẹ̀, tí a sì gúnlẹ̀ láìséwu. Kò sí èyíkéyìí nínú wa tí ó farapa débi pé a kò lè wọ ọkọ̀ òfuurufú mìíràn dé São Paulo. A gbádùn àpéjọpọ̀ àgbàyanu kan, ṣùgbọ́n mo sọ pé èmi kì yóò tún wọ ọkọ̀ òfuurufú mọ́ láé!

Bí ó ti wù kí ó rí, nígbà tí mo padà dé ilé láti àpéjọpọ̀ náà, iṣẹ́ àyànfúnni mìíràn ti ń dúró dè mí. Mo níláti bójútó àpéjọpọ̀ kan nínú igbó kìjikìji kan ní Teresina, Ìpínlẹ̀ Piauí. Mo níláti wọ ọkọ̀ òfuurufú lọ síbẹ̀. Bí ẹ̀rù ti bà mí tó, mo tẹ́wọ́gba iṣẹ́ àyànfúnni náà, ní gbígbẹ́kẹ̀lé ọwọ́ Jehofa.

Ní 1962 a bí ọmọkùnrin wa Greg, ní Recife. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò ṣeéṣe fún mi láti ṣe aṣáájú-ọ̀nà mọ́ nítorí tí mo ní ìdílé tí ń tóbi síi nísinsìnyí, o ṣeéṣe fún mi láti lo agbára ìdarí rere lórí ìjọ kékeré náà. Àwọn ọmọ náà sábà máa ń háragàgà láti darapọ̀ mọ́ wa nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ náà, níwọ̀n bí a ti mú kí ó gbádùn mọ́ wọn. O ṣeéṣe fún ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn, láti ọmọ ọdún mẹ́ta, láti gbé ọ̀rọ̀ kalẹ̀ ní ẹnu ọ̀nà. A sọ ọ́ di àṣà láti máṣe pa ìpàdé tàbí kíkópa nínú iṣẹ́-ìsìn pápá jẹ. Kódà nígbà tí ẹnìkan nínú ìdílé bá ṣàìsàn tí ẹlòmíràn sì níláti dúró tì í nílé, àwọn yòókù yóò lọ sí ìpàdé tàbí kópa nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ pápá.

Jálẹ̀ gbogbo àwọn ọdún náà, a máa ń jíròrò àwọn irú ẹ̀kọ́ ìwé àti góńgó àwọn ọmọ náà nínú ìgbésí-ayé déédéé gẹ́gẹ́ bí ìdílé, ní mímúra wọn sílẹ̀ fún iṣẹ́ ìgbésí-ayé pẹ̀lú ètò-àjọ Jehofa. A kíyèsára láti máṣe ṣí wọn payá sí àwọn ipá tí ń sọnidìbàjẹ́, bíi tẹlifíṣọ̀n. A kò ní tẹlifíṣọ̀n nínú ilé wa títí di ìgbà tí àwọn ọmọ wa fi wọ ìgbà ọ̀dọ́langba wọn. Bí ó sì tilẹ̀ jẹ́ pé agbára wa gbé e, a kò fi àwọn ohun-ìní ti ara bà wọ́n jẹ́. Fún àpẹẹrẹ, a ra kẹ̀kẹ́ kanṣoṣo péré, fún àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta láti ṣàjọpín.

A ń ṣe àwọn nǹkan papọ̀ bí ó bá ti lè ṣeéṣe tó, gbígbá bọ́ọ̀lù alápẹ̀rẹ̀, lílúwẹ̀ẹ́, àti rírìnrìn-àjò ìgbafẹ́ ìdílé. Àwọn ìrìn-àjò ìgbafẹ́ wa níí ṣe pẹ̀lú lílọ sí àwọn àpéjọpọ̀ Kristian tàbí ṣíṣèbẹ̀wò sí àwọn ilé Beteli ní onírúurú orílẹ̀-èdè. Àwọn ìrìn-àjò wọ̀nyí yọ̀ọ̀da àkókò fún wa láti sọ̀rọ̀ fàlàlà kí èmi àti Lucy baà lè mọ ohun tí ó wà lọ́kàn àwọn ọmọ wa. A dúpẹ́ gidigidi lọ́wọ́ Jehofa fún àwọn ọdún gbígbádùnmọ́ni wọ̀nyẹn!

Lẹ́yìn-⁠ọ̀-rẹyìn, ọdún mẹ́wàá tí a lò ní Ilẹ̀ Olóoru nítòsí agbedeméjì ìbú ayé nípa lórí ìlera Lucy. Nítorí náà, a ṣe ìyípadà iṣẹ́ àyànfúnni síbi tí ipò ojú ọjọ́ ti wà níwọ̀n ní gúúsù, ní Curitiba, Ìpínlẹ̀ Paraná.

Pípadà sí Canada

Ní 1977, lẹ́yìn nńkan bí 20 ọdún ní Brazil, èmi àti Lucy pẹ̀lú àwọn ọmọ wa padà sí Canada láti lọ bójútó baba mi tí ń ṣòjòjò. Ẹ wo irú àṣà ìbílẹ̀ yíyàtọ̀ tí èyí jẹ́ fún ìdílé wa! Ṣùgbọ́n kò mú ìyàtọ̀ wá nípa tẹ̀mí, níwọ̀n bí a ti ń báa lọ láti tẹ̀lé ipa-ọ̀nà kan náà pẹ̀lú ẹgbẹ́ àwọn ará wa onífẹ̀ẹ́ tí wọ́n jẹ́ Kristian.

Ní Canada iṣẹ́-òjíṣẹ́ alákòókò kíkún di ohun tí gbogbo ìdílé lọ́wọ́ sí bí àwọn ọmọbìnrin wa ti ń wọnú iṣẹ́-òjíṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà alákòókò kíkún níkọ̀ọ̀kan. Gbogbo wa ṣe ìtìlẹ́yìn fún iṣẹ́ ìdílé wa. Owó èyíkéyìí tí ó bá wọlé láti inú iṣẹ́ àbọ̀ọ̀ṣẹ́ ni a ń fikún owó tí a nílò láti bójútó ilé wa àti àwọn ọkọ̀ mẹ́ta tí a nílò láti kárí àwọn ìpínlẹ̀ wa tí ó wà káàkiri. Lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, lẹ́yìn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli ti ìdílé wa, a ń jíròrò ìwéwèé ìdílé wa. Àwọn ìjíròrò wọ̀nyí ń ṣèrànwọ́ láti jẹ́ kí a mọ ibi tí ẹnìkọ̀ọ̀kan ń lọ àti ohun ti a ń fi ìgbésí-ayé wa ṣe ni kedere.

Ọmọkùnrin wa, Greg, bíi ti àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ obìnrin pẹ̀lú ní iṣẹ́-òjíṣẹ́ alákòókò kíkún gẹ́gẹ́ bíi góńgó rẹ̀. Láti ìgbà tí ó ti wà ní ọmọ ọdún márùn-⁠ún, ó ti fi ìfẹ́-ọkàn rẹ̀ hàn láti ṣiṣẹ́sìn ní ẹ̀ka ọ́fíìsì Society, tí a ń pè ní Beteli. Kò gbàgbé góńgó yẹn, lẹ́yìn tí ó sì jáde ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga, ó béèrè lọ́wọ́ èmi àti ìyá rẹ̀ pé: “Ẹ ha lérò pé mo níláti kọ̀wé béèrè fún iṣẹ́ ní Beteli bí?”

Nígbà tí ó jẹ́ pé ó gún ọkàn wa ní kẹ́ṣẹ́ láti jẹ́ kí ọmọ wa lọ, a dáhùn láìlọ́tìkọ̀ pé: “Ìwọ kì yóò mọ ọwọ́ Jehofa lára lọ́pọ̀lọpọ̀ tó bí ìwọ yóò ti ṣe ní Beteli​—⁠ọ̀gangan ìdarí ètò-àjọ Jehofa.” Láàárín oṣù méjì ó lọ sí Beteli ti Canada. Ìyẹn jẹ́ ní 1980, òun sì ti ń ṣiṣẹ́sìn níbẹ̀ láti ìgbà náà wá.

Àwọn ọdún 1980 mú àwọn ìpèníjà títun wá fún èmí àti Lucy. A padà sí ibi tí a ti bẹ̀rẹ̀​—⁠àwa méjì péré. Nígbà yẹn Susan ti relé ọkọ ó sì ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà pẹ̀lú ọkọ rẹ̀, Kim àti Greg sì ń ṣiṣẹ́sìn ní Beteli. Kí ni àwa yóò ṣe? Ìbéèrè yẹn ni a dáhùn kíákíá ni 1981 nígbà tí a késí wa láti ṣiṣẹ́sin àyíká Portuguese kan, èyí tí ó gbòòrò tó 2,000 kìlómítà yíká Canada. A ṣì ń gbádùn iṣẹ́ arìnrìn-àjò náà.

Kim ti relé ọkọ láti ìgbà yìí wá ti ó sì ti lọ sí Gileadi, ó sì ń ṣiṣẹ́sìn nísinsìnyí pẹ̀lú ọkọ rẹ̀ nínú iṣẹ́ àyíká ní Brazil. Susan àti ọkọ rẹ̀ ṣì wà ní Canada, wọ́n ń tọ́ àwọn ọmọ wọn méjì, ọkọ Susan sì ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìdílé wa pínyà nípa ti ara ní àwọn ọdún àìpẹ́ yìí nítorí onírúurú iṣẹ́ àyànfúnni nínú iṣẹ́-ìsìn alákòókò kíkún, a ṣì wà tímọ́tímọ́ papọ̀ nípa tẹ̀mí àti níti èrò-ìmọ̀lára.

Èmi àti Lucy ń fojúsọ́nà fún ọjọ́-ọ̀la aláyọ̀ pẹ̀lú ìdílé wa lórí ilẹ̀-ayé tí a fọ̀ mọ́ náà. (2 Peteru 3:13) Gẹ́gẹ́ bíi ti Mose ìgbà àtijọ́, a ti nírìírí ìjótìítọ́ ìdáhùn sí ìbéèrè mọ̀ọ́nú náà tí ó wà ní Numeri 11:23 ní tààràtà: ‘Ọwọ́ Jehofa ha kúrú bí? Ìwọ ó rí i nísinsìnyí bí ọ̀rọ̀ mi yóò ṣẹ sí ọ, tàbí bí kì yóò ṣẹ.’ Níti tòótọ́, kò sí ohun tí o lè dí Jehofa lọ́wọ́ láti bùkún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ fún iṣẹ́-ìsìn wọn àfitọkàntọkàn ṣe.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Pẹ̀lú aya mi, Lucy

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́