William Whiston—Aládàámọ̀ Tàbí Ọ̀mọ̀wèé Akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ Aláìlábòsí?
ÌWỌ yóò ha fi iṣẹ́ ìgbésí-ayé rẹ rúbọ nítorí ìgbàgbọ́ rẹ bí? William Whiston ṣe bẹ́ẹ̀.
Ó di ẹni pàtàkì kan nínú àríyànjiyàn ìsìn ní apá ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún kejìdínlógún, nígbà tí ó kọ̀ láti fohùnṣọ̀kan pẹ̀lú Ṣọ́ọ̀ṣì ti England lórí àwọn ẹ̀kọ́ Bibeli. Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí, ó di ẹni tí a pè ní aládàámọ̀ ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀. Nípa báyìí ìgbésẹ̀ rẹ̀ mú ẹ̀gàn wá bá a ṣùgbọ́n ó tún mú kí ó jèrè ọ̀wọ̀.
Ta ni William Whiston? Kí ni ó sì ṣàṣeparí rẹ̀?
Ọ̀mọ̀wèé Akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ Bibeli
William Whiston jẹ́ amòye akẹ́kọ̀ọ́ ẹlẹgbẹ́ Sir Isaac Newton ní Yunifásítì Cambridge. Bí ìwọ bá lọ ṣàyẹ̀wò àwọn ìwé Flavius Josephus òpìtàn Ju ti ọ̀rúndún kìn-ín-ní ní ẹ̀dà Gẹ̀ẹ́sì, ó ṣeéṣe kí o máa ka ìtumọ̀ tí Whiston ṣe ní 1736. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìtumọ̀ mìíràn wà, àwọn ìtumọ̀ jíjinlẹ̀ rẹ̀, pẹ̀lú àwọn àkíyèsí àti àwọn àròkọ rẹ̀, kò tíì ní alábàádọ́gba àti pé a ṣì lè rí wọn lọ́dọ̀ àwọn òǹtẹ̀wé. Ọ̀pọ̀ ka àwọn ìwé wọ̀nyí sí òténté àṣeyọrí Whiston.
Bí ó ti wù kí ó rí, èyí tí a kò gbọ́dọ̀ gbójúfòdá ní ìwé Primitive New Testament, ìtumọ̀ Ìwé Mímọ́ Lédè Griki láti ọwọ́ Whiston. A tẹ̀ ẹ́ jáde ní 1745, ní ọdún kejìdínlọ́gọ́rin ọjọ́ ayé rẹ̀. Whiston túmọ̀ àwọn Ìhìnrere mẹ́rin àti Iṣe Awọn Aposteli náà láti inú ÌwéÀfọwọ́kọ-Alábala ti Bezae, àwọn lẹ́tà Paulu láti inú Ìwé-Àfọwọ́kọ-Alábala ti Clermont, àti àwọn apá tí ó ṣẹ́kù, títíkan Ìfihàn, láti inú Ìwé-Àfọwọ́kọ Alexandrine. Ó fìṣọ́ra yẹ àwọn apá tí ó jẹ́ ayédèrú nínú 1 Johannu 5:7 sílẹ̀. Whiston yan àwọn orísun ìgbàanì mẹ́ta wọ̀nyí gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó dára jùlọ nínú àwọn tí ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó ní àkókò náà.
Ìfẹ́ fún Bibeli ni ìsúnniṣe tí ó farahàn jùlọ fún ohun tí Whiston ṣe. Èyí tí ó gbilẹ̀ ní ọjọ́ rẹ̀ ni deism, ẹ̀kọ́ náà pé ìrònú nìkan ni ìpìlẹ̀ tí ó tóótun fun ìgbàgbọ́ nínú Ọlọrun. Gẹ́gẹ́ bí ìwé náà William Whiston—Honest Newtonian ti sọ, ó fi agbára gbèjà ojú-ìwòye “arinkinkin mọ́ àwọn ìlànà pé Bibeli ni orísun kanṣoṣo tí kò ní àṣìṣe nínú tí ó wà fún ọ̀rọ̀-ìtàn ìgbàanì.” Èdè náà “Newtonian” níhìn-ín jẹ́ ìtọ́ka tí a ṣe sí Isaac Newton, tí a mọ̀ dáradára jùlọ nítorí ìwé rẹ̀ náà Principia, nínú èyí tí ó ti ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa òfin òòfàmọ́lẹ̀ lágbàáyé. Ìrònú Newton ní ipa jíjinlẹ̀ lórí William Whiston. Báwo?
Ànímọ́ tí Ó Yàtọ̀síra
A bí William Whiston ní 1667, ọmọkùnrin àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì kan fún Church of England ní ṣe. Lẹ́yìn tí a ti fi í joyè ní 1693, ó padà lọ sí Yunifásítì Cambridge láti kẹ́kọ̀ọ́ ìṣirò ó sì di igbákejì Newton. Ìrẹ́pọ̀ tímọ́tímọ́ kan dàgbà láàárín wọn. Nígbà tí Newton fi ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọ̀jọ̀gbọ́n ti a fún ní oyè Lucasian Nínú Ìmọ̀ Ìṣirò sílẹ̀ ní nǹkan bí ọdún mẹ́ta lẹ́yìn náà, ó ríi dájú pé Whiston ni a yàn dípò òun. Ní lílépa iṣẹ́-ìgbésí-ayé rẹ̀, Whiston kọ́ni ní ẹ̀kọ́ ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ sánmọ̀ àti ìṣirò, ṣùgbọ́n agbára ìdarí Newton tún sún un láti mú ọkàn-ìfẹ́ tí ó túbọ̀ jinlẹ̀ dàgbà nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọjọ́ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àti ẹ̀kọ́-ìgbàgbọ́ Bibeli.
Newton jẹ́ ẹlẹ́mìí ìsìn. Gẹ́gẹ́ bí onígbàgbọ́ kan tí ó farajìn fún ìwádìí nípa Ẹgbẹ̀rúndún Bibeli, ó kọ̀wé lọ́nà gbígbòòrò lórí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Danieli àti Ìfihàn. Bí ó ti wù kí ó rí, agbára káká ni a fi tẹ èyíkéyìí nínú àwọn ìwé wọ̀nyí jáde ní àkókò ìgbésí-ayé rẹ̀. Ó ṣá ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan tì. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó kan títẹ àwọn ẹ̀rí rẹ̀ lòdìsí Mẹ́talọ́kan jáde, “Newton jáwọ́ nítorí ìbẹ̀rù pé àwọn ojú-ìwòye rẹ̀ tí ó lòdìsí Mẹ́talọ́kan yóò di mímọ̀,” ni gbédègbẹ́yọ̀ The New Encyclopædia Britannica sọ. F. E. Manuel sọ ọ́ lọ́nà yìí nínú ìwé náà Isaac Newton, Historian pé: “Bóyá ẹgbẹ́ Newton pa àwọn èrò wọn mọ́ láṣìírí tàbí wọ́n kó ìtara-ọkàn wọn níjàánu. . . . Níbi tí Newton ti fi ọ̀rọ̀ bò Whiston kìí fi ọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ.” Àwọn ọkùnrin méjèèjì tipa báyìí ní àwọn ànímọ́ yíyàtọ̀síra.
Ìtanùlẹ́gbẹ́
Ní July 1708, Whiston kọ̀wé sí àwọn bíṣọ́ọ̀bù àgbà ti Canterbury àti ti York, ní rírọ̀ wọ́n láti ṣàtúnṣe ẹ̀kọ́-ìgbàgbọ́ Church of England nítìtorí ẹ̀kọ́ èké Mẹ́talọ́kan gẹ́gẹ́ bí ó ti farahàn nínú Ìjẹ́wọ́-Ìgbàgbọ́ Athanasia. Lọ́nà tí ó ṣeélóye, wọ́n fún un nímọ̀ràn pé kí ó ṣọ́ra. Síbẹ̀ Whiston tẹpẹlẹ mọ́ ọn. Ó sọ pé: “Mo ti kẹ́kọ̀ọ́ àwọn kókó wọ̀nyí kanlẹ̀, mo sì ti gbàgbọ́dájú pátápátá pé ṣọ́ọ̀ṣì Kristian ni a ti fi àwọn kókó wọ̀nyí tànjẹ tipẹ́tipẹ́ àti lọ́nà lílékenkà; àti pé, lágbára ìbùkún Ọlọrun, bí ó bá wà ní agbára mi, a kì yóò tún tàn án jẹ mọ́.”
Newton bẹ̀rù nítorí ipò rẹ̀ láwùjọ àti níti ẹ̀kọ́-ìwé. Ní ọwọ́ mìíràn ẹ̀wẹ̀, Whiston kò bẹ̀rù. Lẹ́yìn tí ó ti gbé èrò-ìgbàgbọ́ rẹ̀ tí ó lòdì sí Mẹ́talọ́kan kalẹ̀ tán, ó kọ ìwé-ìléwọ́ kan tí ó gbé àwọn ojú-ìwòye rẹ̀ kalẹ̀. Ṣùgbọ́n ní August 1708, Yunifásítì Cambridge kọ̀ láti fún Whiston ní ìwé-àṣẹ láti tẹ àkójọpọ̀-ọ̀rọ̀ yìí, níwọ̀n bí wọ́n ti kà á sí èyí tí a kò tẹ́wọ́gbà ní gbogbogbòò.
Ní 1710, wọ́n fi ẹ̀sùn kan Whiston pé ó ń kọ́ni ní ẹ̀kọ́ tí ó yàtọ̀ sí èrò-ìgbàgbọ́ Church of England. Wọ́n dẹ́bi fún un, wọ́n gba oyè ọ̀jọ̀gbọ́n rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ rẹ̀, wọ́n sì lé e kúrò ní Cambridge. Bí ó ti wù kí ó rí, lójú àwọn ìgbésẹ̀ òfin tí wọ́n gbé lòdìsí i, tí ń báa lọ fún nǹkan bí ọdún márùn-ún mìíràn síi, wọn kò rí Whiston gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó jẹ̀bi àdámọ̀.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ojú-ìwòye rẹ̀ tí ó lòdìsí Mẹ́talọ́kan jọra pẹ̀lú tí Whiston, Newton kò sọ̀rọ̀ gbe ọ̀rẹ́ rẹ̀ ó sì ta á nù ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀. Ní 1754, àkójọ ìwé ìmọ̀ Newton lórí Bibeli tí ó tú Mẹ́talọ́kan fó ni a tẹ̀ jáde nígbẹ̀yìn—ọdún 27 lẹ́yìn ikú rẹ̀. Ṣùgbọ́n ìyẹn ti pẹ́ jù láti ṣèrànwọ́ èyíkéyìí fún Whiston, tí ó ti kú ní ọdún méjì ṣáájú.
Newton ni a tún sọ pé ó ṣèdíwọ́ fún Whiston láti di apákan ẹgbẹ́ Royal Society. Ṣùgbọ́n a kò mú Whiston rẹ̀wẹ̀sì. Òun àti ìdílè rẹ̀ ṣí lọ sí London, níbi tí ó ti ṣe ìdásílẹ̀ Ẹgbẹ́ Tí Ń Ṣagbátẹrù Ìsìn Kristian Ìjímìjí. Ó fi gbogbo okun rẹ̀ kọ̀wé, ìwé rẹ̀ tí ó ṣe pàtàkì jùlọ títí di ìgbà yẹn ni àwọn ìdìpọ̀ mẹ́rin náà Primitive Christianity Revived.
Ó Jiyàn Títí Dópin
Gẹ́gẹ́ bí onímọ̀-ìjìnlẹ̀ kan, Whiston ṣiṣẹ́ lórí onírúurú ọ̀nà tí àwọn atukọ̀-òkun lè gbà pinnu ìwọ̀-oòrùn àti ìlà-oòrùn lójú òkun. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kò tẹ́wọ́gba èrò rẹ̀, àìyéérinkinkin rẹ̀ wá jálẹ̀ sí ìmújáde ẹ̀rọ adíwọ̀n-àkókò ti àwọn awakọ̀-òkun. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ nínú àwọn ojú-ìwòye Whiston nípa àsọtẹ́lẹ̀ Bibeli, bíi ti àwọn alájọgbáyé rẹ̀, ti jásí èyí tí kò péye, kò sí ohun tí kò ṣe tán nínú ìwákiri rẹ̀ fún òtítọ́. Àwọn ìwé-àṣàrò-kúkúrú rẹ̀ lórí ìlọyíká àwọn ìràwọ̀ onírù àti àwọn ìjẹ́wọ́ rẹ̀ níti àwọn ipa tí Ìkún-Omi ọjọ́ Noa ní wà lára ọ̀pọ̀ àwọn ohun tí ó kọ láti gbèjà òtítọ́ ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ àti ti Bibeli. Bí ó ti wù kí ó rí, èyí tí ó borí jùlọ nínú àwọn ìwé rẹ̀ ni ìwọ̀nyí tí ó tú ẹ̀kọ́-ìgbàgbọ́ Mẹ́talọ́kan fó gẹ́gẹ́ bí èyí tí kò bá ìwé mímọ́ mu.
Ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀nà tí ó ń gbà hùwà, Whiston fi Ṣọ́ọ̀ṣì ti England sílẹ̀ ní 1747. Ó ṣe bẹ́ẹ̀, níti gidi àti lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, nígbà tí ó rìn jáde kúrò nínú ṣọ́ọ̀ṣì bí àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì kan ti bẹ̀rẹ̀ síí ka Ìjẹ́wọ́-Ìgbàgbọ́ Athanasia. Ìwé náà A Religious Encyclopædia sọ nípa Whiston pé: “Ẹnìkan gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́-ọkàn sí àìfọ̀rọ̀sábẹ́-ahọ́n sọ àti ìjótìítọ́ ìwà akin rẹ̀, ìṣedéédéé ìgbésí-ayé rẹ̀, àti ìṣarasíhùwà rẹ̀ tí kò ní màgòmágó nínú.”
Níti William Whiston, òtítọ́ ni a kò lè fi bánidọ́rẹ̀ẹ́, àwọn ohun tí ẹnìkan sì gbàgbọ́ dájú fúnraarẹ̀ ṣeyebíye púpọ̀ ju ìyìn àti ẹ̀yẹ ènìyàn lọ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ òjiyàn, Whiston jẹ́ ọ̀mọ̀wèé àkẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ aláìlábòsí tí ó fi àìbẹ̀rù gbèjà Bibeli gẹ́gẹ́ bí Ọ̀rọ̀ Ọlọrun.—2 Timoteu 3:16, 17.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 26]
Ẹ̀tọ́-àdàkọ British Museum