Ìwọ Ha Rántí Bí?
Ìwọ ha ti gbádùn kíka àwọn ìtẹ̀jáde Ilé-Ìṣọ́nà ti ẹnu àìpẹ́ yìí bí? Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ìwọ yóò rí i gẹ́gẹ́ bí ohun tí ó gbádùnmọ́ni láti rántí àwọn ohun tí ó tẹ̀lé e wọ̀nyí:
▫ Èéṣe tí àwọn amí ọmọ Israeli náà fi yàn láti wọ̀ sí ilé Rahabu aṣẹ́wó?
Àwọn amí ọmọ Israeli náà fi Òfin Ọlọrun sílò, nítorí náà wọn kò wọ̀ sí ilé Rahabu fún àwọn ète oníwàpálapàla. Wọ́n ti lè ronú pé wíwá tí wọ́n wá sí ilé aṣẹ́wó kò lè tètè gbé ìfura dìde ní ìlú náà. Pé a kọ́ ilé rẹ̀ sára ògiri ìlú náà lè mú kí sísálọ rọrùn. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, Jehofa ni ó ṣamọ̀nà wọn lọ sọ́dọ̀ ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tí àwọn ìròyìn nípa àwọn ìbálò Ọlọrun pẹ̀lú àwọn ọmọ Israeli ti ní ipa dídára lórí ọkàn-àyà rẹ̀ débi pé ó ronúpìwàdà ó sì yí àwọn ọ̀nà rẹ̀ padà.—12/15, ojú-ìwé 24 sí 25.
▫ Báwo ni ìbínú ṣe ń nípa lórí ìlera wa?
Ìwádìí fihàn pé ìbínú ń mú àwọn omi ìsúnniṣe inú ara tí ń fa másùnmáwo jáde. Ìbínú rangbandan àtìgbàdégbà lè fa àìwàdéédéé láàárín irú àwọn èròjà ọlọ́ràá inú sẹ́ẹ̀lì tí ń dáàbòboni àti èyí tí ń panilára, ní fífi wá sínú ewu òkùnrùn ọkàn-àyà-òun-ihò-ẹ̀jẹ̀.—12/15, ojú-ìwé 32.
▫ Àwọn ìdámọ̀ràn wo ni yóò ràn wá lọ́wọ́ láti mú kí ìpínkiri àwọn ìwé-ìròyìn Ilé-Ìṣọ́nà ati Jí! wa pọ̀ síi?
Jẹ́ ẹni tí fífi Ilé-Ìṣọ́nà àti Jí! sóde ń jẹ lọ́kàn; mú kí ìfilọni náà rọrùn; jẹ́ olùmọwọ́ọ́yípadà nípa mímúra àwọn ìfilọni díẹ̀ sílẹ̀; gbé góńgó ti ara-ẹni kalẹ̀.—1/1, ojú-ìwé 24 sí 25.
▫ Èéṣe tí Mose fi jẹ́ àpẹẹrẹ ìṣàkóso àtọ̀runwá tí ó dára jọjọ fún wa láti tẹ̀lé?
Mose wá ìtọ́sọ́nà Jehofa lórí àwọn ọ̀ràn, kò lépa àṣeyọrí ti ara-ẹni, ṣùgbọ́n ó ṣàníyàn nípa ògo Jehofa. Ó ní ìgbàgbọ́ lílágbára; kò sì gbàgbé rí pé Jehofa ni Alákòóso tòótọ́ fún orílẹ̀-èdè Israeli.—1/15, ojú-ìwé 11.
▫ Kí ni díẹ̀ lára àwọn ọ̀nà tí ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá gbà ṣẹ́gun?
Ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá ṣẹ́gun nípa fífún àwọn ènìyàn Jehofa ní òye òtítọ́ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé. Ó ń mú àwọn ènìyàn wá sínú ìmọ́lẹ̀ tẹ̀mí, ó sì ń fi ọ̀nà tí àwọn ọlọ́kàn tútù lè gbà sin Ọlọrun “ní ẹ̀mí àti ní òtítọ́” hàn wọ́n. (Johannu 4:24) Ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá tún ṣẹ́gun àwọn àdánwò àti ayé búburú.—2/1, ojú-ìwé 10 sí 12.
▫ Kí ni kọ́kọ́rọ́ náà sí ìgbaninímọ̀ràn tí ó yọrísírere?
Kọ́kọ́rọ́ náà ni níní ọ̀wọ̀ tí ó yẹ fún ẹni kejì àti ẹ̀tọ́ rẹ̀ láti jẹ́ ẹni tí a bálò ní ọ̀nà tí ń buyì kúnni. Nítorí èyí, Kristian olùgbaninímọ̀ràn kan níláti jẹ́ onínúure àti ẹni tí ó dúró gbọnyingbọnyin, ṣùgbọ́n ó gbọ́dọ̀ fi iyì fún ẹni tí ó ń gbà nímọ̀ràn.—2/1, ojú-ìwé 28.
▫ Báwo ni Ṣọ́ọ̀ṣì Roman Katoliki ṣe wá gba Ìgbàsókè-Ọ̀run Maria gẹ́gẹ́ bí ẹ̀kọ́-ìsìn?
Ní àwọn ọ̀rúndún àkọ́kọ́ lẹ́yìn ikú Jesu, èrò náà nípa Ìgbàsókè-Ọ̀run Maria ṣàjèjì pátápátá sí ìrònú àwọn Kristian. Bí ó ti wù kí ó rí, lẹ́yìn tí ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan di ẹ̀kọ́-ìgbàgbọ́ ṣọ́ọ̀ṣì tí a fàṣẹ sí, Maria ni a fún ní ipa-iṣẹ́ pàtàkì tí ó túbọ̀ ń pọ̀ síi. Àbá-èrò-orí Ìgbàsókè-Ọ̀run náà ni a kò gbà gẹ́gẹ́ bí ìgbàgbọ́ aláìjampata títí di November 1, 1950, nígbà tí Poopu Pius XII kéde pé: “Àwa túmọ̀ rẹ̀ pé ó jẹ́ ìgbàgbọ́ aláìjampata kan tí Ọlọrun ṣípayá.”—Munificentissimus Deus.—2/15, ojú-ìwé 26 sí 27.
▫ Nínú Jeremiah orí 24, kí ni àwọn agbọ̀n èso ọ̀pọ̀tọ́ méjèèjì, èso ọ̀pọ̀tọ́ dídára àti àwọn tí kò dára, ṣàpẹẹrẹ rẹ̀?
Èso ọ̀pọ̀tọ́ dídára náà ṣàpẹẹrẹ àwọn Ju tí a kọ́kọ́ kó nígbèkùn lọ sí Babiloni, lára èyí tí àwọn àṣẹ́kù yóò padà sí Juda. Èso ọ̀pọ̀tọ́ búburú náà dúró fún Ọba Sedekiah àti àwọn tí wọ́n jọ ṣọ̀tẹ̀ lòdìsí Ọba Nebukadnessari bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ti búra ní orúkọ Ọlọrun. Ní ìfiwéra, a rí ní àkókò òde-òní àwọn àṣẹ́kù Israeli tẹ̀mí, tí wọ́n ti so èso rere nínú ìgbésí-ayé wọn, ní ìyàtọ̀ pátápátá sí àwọn àlùfáà Kristẹndọm, tí wọ́n ti so èso dídíbàjẹ́.—3/1, ojú-ìwé 14 sí 16.
▫ Àwọn wo ni àwọn Quartodeciman, èésìtiṣe tí àwọn Kristian lónìí fi lọ́kàn ìfẹ́ láti mọ̀ nípa wọn?
Lẹ́yìn àkókò àwọn aposteli, àwọn kan wà tí wọ́n ń ṣayẹyẹ Oúnjẹ Alẹ́ Oluwa ní Nisan 14 lọ́dọọdún, ní títẹ̀lé àwòkọ́ṣe àwọn aposteli. A mọ̀ wọ́n sí “Àwọn Ọlọ́jọ́ Kẹrìnlá,” tàbí àwọn Quartodeciman. Èyí jẹ wá lógún lónìí, nítorí tí ó fihàn pé, àní lẹ́yìn ikú àwọn aposteli pàápàá, àwọn kan wà tí wọ́n rọ̀ mọ́ ipa ọ̀nà tí ó tọ́ ní ṣíṣèrántí ikú Jesu lẹ́ẹ̀kan lọ́dún ní Nisan 14.—3/15, ojú-ìwé 4 sí 5.
▫ Ta ni William Whiston?
Òun jẹ́ ọ̀mọ̀wé-akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ ti ọ̀rúndún kejìdínlógún ní England, alábàákẹ́gbẹ́pọ̀ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Sir Isaac Newton. Whiston túmọ̀ Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Griki, ó tako ẹ̀kọ́-ìgbàgbọ́ Mẹ́talọ́kan ní gbangba, ó sì tún jẹ́ olùkọ́ni ní ẹ̀kọ́ ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ sánmọ̀ àti ìṣirò. Ṣùgbọ́n ohun tí ó ṣeéṣe kí a rántí rẹ̀ fún jùlọ ni ìtumọ̀ àwọn ìwé òpìtàn Ju náà, Flavius Josephus tí ó ṣe sí Gẹ̀ẹ́sì.—3/15, ojú-ìwé 26 sí 28.
▫ Báwo ni a ṣe dá ènìyàn ní àwòrán Ọlọrun? (Genesisi 1:27)
A dá ènìyàn pẹ̀lú agbára láti lo àwọn ànímọ́ Ọlọrun títayọ ti ìfẹ́, ìdájọ́-òdodo, ọgbọ́n, àti agbára—àti àwọn ànímọ́ mìíràn.—4/1, ojú-ìwé 25.