Àwọn Olùpòkìkí Ìjọba Ròyìn
Òtítọ́ Bibeli So Ìdílé kan Pọ̀ Ṣọ̀kan
LÓNÌÍ, ní apá ibi púpọ̀ lórí ilẹ̀-ayé, ìṣọ̀kan ìdílé ti fẹ́rẹ̀ẹ́ di àwátì. Bí ó ti wù kí ó rí, Bibeli ṣí àṣírí ìṣọ̀kan ìdílé payá. Gbé ọ̀rọ̀ Jesu yẹ̀wò: “Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbọ́ ọ̀rọ̀ tèmi wọ̀nyí, tí ó bá sì ṣe wọ́n, èmi óò fi wé ọlọ́gbọ́n ènìyàn kan, tí ó kọ́ ilé rẹ̀ sí orí àpáta.” (Matteu 7:24) Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ìdílé láàárín àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti ní ìṣọ̀kan nípa fífi àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sílò àti nípa lílo Bibeli gẹ́gẹ́ bí ìpìlẹ̀ fún gbígbé ìdílé tí ó ṣọ̀kan ró. Ọwọ́ àwọn mìíràn pẹ̀lú ń tẹ ìṣọ̀kan bẹ́ẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìrírí tí ó tẹ̀lé e yìí ti fihàn.
Nígbà tí Daniel ń ṣiṣẹ́ nínú ẹgbẹ́ ọmọ-ogun ní France, àlùfáà fún ẹgbẹ́ ọmọ-ogun dábàá pé kí Daniel ra Bibeli kan, ó ṣe bẹ́ẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ síí kà á déédéé. Níkẹyìn a gbé e lọ sí Tahiti. Mélòókan lára àwọn ṣọ́jà ẹlẹgbẹ́ Daniel jẹ onísìn Adventist, tí àwọn mìíràn sì jẹ́ onísìn Mormon. Àwọn ìjíròrò wọn sábà máa ń yídà sí ọ̀ràn ìsìn. Ní ọjọ́ kan sájẹ́ǹtì àgbà fi Daniel han ìyàwó rẹ̀, tí ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Ó lo gbogbo ọ̀sán kan ní dídáhùn ọ̀pọ̀ jaburata ìbéèrè tí Daniel ní tí ó sì júwe ọ̀kan lára àwọn ìjọ àdúgbò àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní Tahiti fún un. Láìpẹ́ ó bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli déédéé.
Àwọn òbí Daniel tí wọ́n wà ní France jẹ́ Katoliki olótìítọ́-inú. Baba rẹ̀ jẹ́ olùgba àwọn ọmọ ilé-ẹ̀kọ́ nímọ̀ràn tí ó sì tún ń bójútó ìtọ́ni ìsìn ní ilé-ẹ̀kọ́ Katoliki kan. Ní fífẹ́ láti ṣàjọpín ìjìnlẹ̀ òye tẹ̀mí ṣíṣeyebíye tí òun ń kọ́ pẹ̀lú àwọn òbí rẹ̀, Daniel bẹ̀rẹ̀ síí fi àwọn ọ̀rọ̀ Bibeli díẹ̀díẹ̀ sínú lẹ́tà rẹ̀ sí wọn.
Ní ìbẹ̀rẹ̀, inú mama Daniel dùn, ṣùgbọ́n lẹ́yìn náà jìnnìjìnnì bò ó láti rí orúkọ náà Jehofa nínú ọ̀kan lára àwọn lẹ́tà ọmọ rẹ̀. Ní ọjọ́ díẹ̀ lẹ́yìn náà, ó gbọ́ ìtòlẹ́sẹẹsẹ orí rédíò kan tí ó fi àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa hàn gẹ́gẹ́ bí “ẹ̀yà ìsìn líléwu.” Ó kọ̀wé sí Daniel, ní sísọ fún un pé kí ó jáwọ́ gbogbo àjọṣepọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, Daniel ń báa lọ láti ní ìtẹ̀síwájú nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli rẹ̀ tí ó sì ṣètò láìpẹ́ láti fi iṣẹ́ ológun sílẹ̀ kí ó sì padà sí France.
Gbàrà tí ó ti padà dé ilé, Daniel ń lo alaalẹ́—nígbà mìíràn títí di ààjìn òru—nínú ìjíròrò Bibeli gígùn pẹ̀lú mama rẹ̀. Níkẹyìn ó gbà láti bá Daniel lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba kan. Nígbà tí ó pésẹ̀ sí ìpàdé rẹ̀ alákọ̀ọ́kọ́, orí rẹ̀ wú tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli tirẹ̀. Ó ní ìtẹ̀síwájú tí ó yára kánkán ó sí ṣèrìbọmi láìpẹ́.
Baba Daniel jẹ́ ọkùnrin tí ó fún ènìyàn láyè láti ṣe ohun tí ó fẹ́ ṣùgbọ́n iṣẹ́ àkọ́mọ̀ọ́ṣe àti ìgbòkègbodò ìsìn rẹ̀ gbà á lọ́kàn. Síbẹ̀, ní àkókò kan ó gbé ìyàwó rẹ̀ àti Daniel lọ sí àpéjọpọ̀ àgbègbè kan. Ó jẹ́ ní July 14, ó sì wà lọ́kàn rẹ̀ láti wo ètò yíyan-bí-ológun ní ìlú náà fún Àyájọ́ Bastille. Nígbà tí ó ń dúró, nítorí ojúmìító ó pinnu láti wo inú gbọ̀ngàn àpéjọpọ̀ náà. Ètò àti àlàáfíà tí ó rí láàárín àwọn ènìyàn Jehofa wú u lórí, bí ó sì ti ń rin yíká onírúurú àwọn ẹ̀ka àpéjọpọ̀ náà léraléra ni gbogbo ènìyàn ń pè é ní “arákùnrin.” Ó gbàgbé pátápátá nípa ètò yíyan-bí-ológun fún Àyájọ́ Bastille tí ó sì dúró títí di ẹ̀yìn àpéjọpọ̀ náà. Ó béèrè fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli ó sì ní ìtẹ̀síwájú tí ó yára kánkán nínú kíkẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Bí ó ti wù kí ó rí, bí ó ti ń kọ́ púpọ̀ síi, bẹ́ẹ̀ ni ipò tí ó yí iṣẹ́ rẹ̀ ká kò mú kí ó nímọ̀lára ìdẹ̀ra, nítorí náà ní ẹni ọdún 58, ó fi iṣẹ́ rẹ̀ sílẹ̀. Ní báyìí àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta nínú ìdílé náà ti ṣèyàsímímọ́ àti ìrìbọmi tí wọ́n sì ń ṣiṣẹ́sin Jehofa lápapọ̀ ní ìṣọ̀kan.
Òtítọ́ Bibeli ni ó so ìdílé Daniel pọ̀ ṣọ̀kan. Ó lè so àwọn ìdílé mìíràn pọ̀ ṣọ̀kan bí wọ́n bá kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ tí wọ́n sì fi í sílò tọkàntọkàn.