ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w94 4/15 ojú ìwé 19-21
  • Olè Jíjà Ha Ni Nítòótọ́ Bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Olè Jíjà Ha Ni Nítòótọ́ Bí?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Owó Ta Ni?
  • Ẹ̀yáwó Tàbí Olè Jíjà?
  • Gbígbẹ́kẹ̀lé Ọlọrun
  • Má Ṣe Di Olè!
    Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà
  • Èrò Tó Yẹ Ká Ní Nípa Owó
    Jí!—2015
  • Ṣé Owó Ni Gbòǹgbò Ohun Búburú Gbogbo?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Owó
    Jí!—2014
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
w94 4/15 ojú ìwé 19-21

Olè Jíjà Ha Ni Nítòótọ́ Bí?

ABIỌDUN jẹ́ olórí-agbáwo ní hòtẹ́ẹ̀lì ńlá kan ní Nigeria. Nígbà tí ó ń ti ilẹ̀kùn gbọ̀ngàn ìjẹun ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kan, ó rí àpò owó tí ó ní ₦13,500 nínú. Láìjáfara, ó fi owó náà hàn, èyí tí ẹni tí ó ni ín, àlejò kan nínú hòtẹ́ẹ̀lì náà, gbà padà lẹ́yìn náà. Àwọn ọ̀gá ní hòtẹ́ẹ̀lì náà san ẹ̀san fún Abiọdun pẹ̀lú ìgbégasókè onípele méjì lẹ́nu iṣẹ́, tí wọ́n sì fún un ní ẹ̀bùn “òṣìṣẹ́ tí ó dára jùlọ ní ọdún náà.” Ẹni tí ó ni owó náà pẹ̀lú san ẹ̀san fún un.

Quality, ìwé-ìròyìn àdúgbò kan, gbé ìròyìn náà jáde, ó sì pe Abiọdun ní “Aláàánú ará Samaria.” Nígbà tí ìwé-ìròyìn Quality béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ bóyá a dán an wò láti fi owó náà pamọ́ fún araarẹ̀, Abiọdun sọ pé: ‘Èmi jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Nítorí náà bí mo bá rí ohunkóhun tí kìí ṣe tèmi, èmi yóò dá a padà fún ẹni tí ó ni ín.’

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ní àdúgbò náà ni ẹnu yà sí ẹ̀rí àìlábòsí tí Abiọdun fihàn. Inú àwọn Ẹlẹ́rìí ẹlẹgbẹ́ Abiọdun dùn sí ohun tí ó ṣẹlẹ̀, ṣùgbọ́n kò yà wọ́n lẹ́nu. Jákèjádò ayé ni a ti mọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa fún àwọn ìlànà gíga wọn. Láàárín wọn àìlábòsí kìí ṣe ohun tí a lè yọ́ sílẹ̀; ìlànà ni, apá tí ó ṣekókó nínú ìsìn Kristian.

Bí ó ti wù kí ó rí, lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àwọn ipò nǹkan lè mú kí ó ṣòro láti mọ ìyàtọ̀ láàárín ohun tí ó jẹ́ àìlábòsí àti ohun tí kìí ṣe bẹ́ẹ̀. Gbé ipò ọ̀ràn yìí yẹ̀wò. Festus, ẹni tí ń bójútó ọrẹ àti ọ̀ràn ìnáwó nínú ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa kan ní Ìwọ̀-Oòrùn Africa, nílò owó gidi gan-⁠an.a Aya rẹ̀ nílò iṣẹ́-abẹ tí ó ṣe pàtàkì kan tí àwọn oníṣègùn rẹ̀ sọ pé kò gbọdọ̀ fi falẹ̀. Ilé-ìwòsàn náà béèrè pé kí ó san ìdajì owó sílẹ̀.

Festus kò ní owó náà lọ́wọ́. Nígbà tí ó tọ àwọn bíi mélòókan lọ láti yá owó, wọn kò yá a. Nígbà náà ni ó rántí owó tí ó wà ní ìkáwọ́ rẹ̀ ó sì ronú pé, ‘Ó ha tọ́ fún mi láti fi ẹ̀mí aya mi wewu nígbà tí mo lè ṣe ohun kan láti dènà rẹ̀? Èéṣe tí n kò fi “yá” nínú owó ìjọ? Mo lè san án padà nígbà tí àwọn kan tí wọ́n jẹ mí lówó bá san án padà fún mi.’

Festus lo owó náà tí kìí ṣe tirẹ̀ láti fi san owó ilé-ìwòsàn. Ìrònú rẹ̀ ha tọ̀nà bí? A ha dá ìgbésẹ̀ rẹ̀ láre lójú-ìwòye ipò pàjáwìrì tí ó dojúkọ bí?

Owó Ta Ni?

Ní títú àwọn ìbéèrè wọ̀nyí palẹ̀, ẹ jẹ́ kí a gbé àwọn kókó díẹ̀ yẹ̀wò nípa orísun àti ète owó bí irú èyí tí Festus mú. Owó-àkànlò náà wá nípasẹ̀ ọrẹ àtinúwá ti àwọn mẹ́ḿbà ìjọ tí wọ́n fẹ́ láti mú ìjọsìn mímọ́gaara ti Jehofa tẹ̀síwájú. (2 Korinti 9:7) A kìí lò ó láti fi san owó-oṣù, níwọ̀n bí a kò ti ń san owó fún ẹnikẹ́ni fún ohun tí wọ́n ṣe nínú ìjọ. Ní òdìkejì, owó tí a fi tọrẹ náà ni a ń lò ní pàtàkì láti fi rà kí a sì fi bójútó ibi ìpàdé kan, tí ó sábà máa ń jẹ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba. Èyí pèsè ibi tí ó wọ̀ tí ó sì dẹra níbi tí gbogbo ènìyàn​—⁠ọmọdé àti àgbà, ọlọ́rọ̀ àti tálákà​—⁠ti lè pésẹ̀ fún ìtọ́ni Bibeli.

Owó ta ni? Ó jẹ́ ti ìjọ lápapọ̀. Kò sí mẹ́ḿbà kan tí ń pinnu bí a óò ti náwó náà. Nígbà tí ó jẹ́ pé àwọn alàgbà ni wọ́n ń bójútó sísan owó ìnáwó ìjọ tí a ń ṣe déédéé, nígbà tí ìnáwó àrà-ọ̀tọ̀ kan bá dìde, àwọn alàgbà yóò gbé ọ̀rọ̀ náà kalẹ̀ níwájú gbogbo ìjọ fún ìfọwọ́sí wọn.

Ẹ̀yáwó Tàbí Olè Jíjà?

Nítorí èrò rẹ̀ láti dá owó náà padà bí ó bá ti lè tètè ṣeéṣe kí ó yá tó, Festus wo ìgbésẹ̀ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yáwó. Bí ó ti wù kí ó rí, Webster’s New Dictionary of Synonyms lo àwọn ọ̀rọ̀ mìíràn tí ó níí ṣe pẹ̀lú “mímú àti yíyọ ohun-⁠ìní ẹlòmíràn tí a sábà máa ń ṣe ní ìdákọ́ńkọ́ tàbí láìjẹ́ pé ẹni náà mọ̀ nípa rẹ̀ tí ó sì sábà máa ń jẹ́ láìsí ìfọwọ́sí rẹ̀.” Àwọn ọ̀rọ̀ náà ni “olè jíjà” àti “olè.” Láìgba àṣẹ tàbí ìyọ̀ọ̀da, Festus mú owó tí ó jẹ́ ti ìjọ. Nítorí náà, nítòótọ́, òun jẹ̀bi olè jíjà. Olè ni.

Dájúdájú, onírúurú ìwọ̀n ìbániwí ni ó wà fún ìsúnniṣe tí ó wà lẹ́yìn olè jíjà. A lè rí ìyẹn nínú àpẹẹrẹ ti Judasi Iskariotu, ẹni tí a fi owó Jesu àti ti àwọn olùṣòtítọ́ aposteli sí ìkáwọ́ rẹ̀. Bibeli sọ pé: “[Judasi jẹ́] olè, òun ni ó sì ni àpò, a sì máa gbé ohun tí a fi sínú rẹ̀.” (Johannu 12:6) Bí ọkàn-àyà búburú àti ìwọra paraku tí ń sún un ṣiṣẹ́, Judasi túbọ̀ ń burú sí i. Lẹ́yìn-ò-rẹyìn, ó rẹ araarẹ̀ sílẹ̀ dé ipò dída Ọmọkùnrin Ọlọrun​—⁠fún 30 owó fàdákà.​—⁠Matteu 26:​14-⁠16.

Bí ó ti wù kí ó rí, àníyàn nípa aya rẹ̀ ni ó sún Festus. Èyí ha túmọ̀ sí pé òun kò ní ẹ̀bi bí? Dájúdájú bẹ́ẹ̀kọ́. Ṣàkíyèsí ohun tí Bibeli sọ nípa olè jíjà lábẹ́ ipò mìíràn tí ó dàbí pàjáwìrì: “Wọn kìí gan olè, bí ó bá ṣe pé, ó jalè láti tẹ́ ọkàn rẹ̀ lọ́rùn, nígbà tí ebi ń pa á; ṣùgbọ́n bí a bá mú un, yóò san án padà níwọ̀n méje; gbogbo ìní ilé rẹ̀ ni yóò fi san ẹ̀san.” (Owe 6:​30, 31) Ní èdè mìíràn, bí ọwọ́ bá tẹ̀ ẹ́, olè náà gbọ́dọ̀ jìyà tí ó tọ́ lábẹ́ òfin. Ní ìbámu pẹ̀lú Òfin Mose, olè kan níláti san àsanfidípò nítorí ìwà-ọ̀daràn rẹ̀. Nítorí náà, dípò fífún olè jíjà níṣìírí tàbí dídá a láre, Bibeli kìlọ̀ pé, kódà lábẹ́ ipò pàjáwìrì, gbígbéwiri lè yọrísí àdánù níti ìṣúnná owó, ìdójútini, àti èyí tí ó burú jùlọ, ìpàdánù ìtẹ́wọ́gbà Ọlọrun.

Gẹ́gẹ́ bí àwọn Ẹlẹ́rìí fún Jehofa, gbogbo àwọn Kristian tòótọ́, pàápàá jùlọ àwọn wọnnì tí a fún ní ẹrù-iṣẹ́ nínú ìjọ, gbọ́dọ̀ jẹ́ àpẹẹrẹ rere, “aláìlẹ́gàn.” (1 Timoteu 3:10) Festus kò rí owó tí àwọn ènìyàn jẹ ẹ́ gbà padà, nípa báyìí kò ṣeéṣe fún un láti dá owó tí ó ti mú padà. Ohun tí ó ṣe wá di mímọ̀. Kí ni ó ṣẹlẹ̀ sí i? Kí a sọ pé olè aláìronúpìwàdà ni ó jẹ́ ni, à bá ti lé e kúrò nínú ìjọ Kristian mímọ́. (1 Peteru 4:15) Ṣùgbọ́n ó kábàámọ̀ gidigidi ó sì ronúpìwàdà. Nítorí èyí, ó ṣeéṣe fún un láti wà nínú ìjọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó pàdánù àǹfààní iṣẹ́-ìsìn rẹ̀.

Gbígbẹ́kẹ̀lé Ọlọrun

Aposteli Paulu kìlọ̀ pé bí ẹnìkan tí ó sọ pé òun ń sin Jehofa bá gbéwiri, èyí lè mú ẹ̀gàn wá sórí orúkọ Ọlọrun àti àwọn tí a ń fi orúkọ Rẹ̀ pè. Paulu kọ̀wé pé: “Ǹjẹ́ ìwọ tí o ń kọ́ ẹlòmíràn, ìwọ kò kọ́ araàrẹ? ìwọ tí o ń wàásù kí ènìyàn kí ó má jalè, ìwọ ń jalè? Nítorí orúkọ Ọlọrun sáà di ìsọ̀rọ̀ búburú sí nínú àwọn Keferi nítorí yín, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́.”​—⁠Romu 2:​21, 24.

Aguri, ọlọ́gbọ́n ọkùnrin kan ní ìgbà àtijọ́, sọ kókó kan náà. Ó béèrè nínú àdúrà rẹ̀ pé kí òun “má baà tòṣì, kí [òun] sì jalè, kí [òun] sì ṣẹ̀ sí orúkọ Ọlọrun [rẹ̀].” (Owe 30:9) Ṣàkíyèsí pé ọlọ́gbọ́n ọkùnrin náà gbà pé òṣì lè mú àwọn ipò kan wá tí ó lè dán olódodo ènìyàn kan pàápàá wò láti gbéwiri. Bẹ́ẹ̀ni, àwọn àkókò lílekoko lè dán ìgbàgbọ́ tí Kristian kan ní nínú agbára Jehofa láti pèsè fún àìní àwọn ènìyàn rẹ̀ wò.

Síbẹ̀, àwọn Ẹlẹ́rìí adúróṣinṣin ti Jehofa, títíkan àwọn tí ó tálákà, ní ìgbàgbọ́ pé Ọlọrun “ni olùsẹ̀san fún àwọn tí ó fi ara balẹ̀ wá a.” (Heberu 11:6) Wọ́n mọ̀ pé Jehofa ń san ẹ̀san fún àwọn ènìyàn rẹ̀ olùṣòtítọ́ nípa ríràn wọ́n lọ́wọ́ láti bójútó àwọn àìní wọn. Jesu mú kí èyí ṣe kedere nínú Ìwàásù rẹ̀ Lórí Òkè, ní wíwí pé, “Ẹ máṣe ṣe àníyàn, wí pé, Kí ni a ó jẹ? tàbí, Kí ni a ó mu? tàbí, aṣọ wo ni a ó fi wọ̀ wá? . . . Nítorí Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run mọ̀ pé, ẹ̀yin kò lè ṣe aláìní gbogbo nǹkan wọ̀nyí. Ṣùgbọ́n ẹ tètè máa wá ìjọba Ọlọrun ná, àti òdodo rẹ̀; gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni a ó sì fi kún un fún yín.”​—⁠Matteu 6:​31-⁠33.

Báwo ni Ọlọrun ṣe ń pèsè fún àwọn aláìní nínú ìjọ Kristian? Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà. Ọ̀nà kan jẹ́ nípasẹ̀ àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn. Àwọn ènìyàn Ọlọrun ń fi ojúlówó ìfẹ́ hàn fún araawọn lẹ́nìkínní kejì. Wọ́n fi ọwọ́ pàtàkì mú ìṣílétí inú Bibeli náà: “Ẹni tí ó bá ní ohun ìní ayé, tí ó sì rí arákùnrin rẹ̀ tíí ṣe aláìní, tí ó sì sé ilẹ̀kùn ìyọ́nú rẹ̀ mọ́ ọn, báwo ni ìfẹ́ Ọlọrun ti ń gbé inú rẹ̀? Ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ máṣe jẹ́ kí a fi ọ̀rọ̀ tàbí ahọ́n fẹ́ràn, bíkòṣe ní ìṣe àti ní òtítọ́.”​—⁠1 Johannu 3:​17, 18.

Jákèjádò ayé, ní èyí tí ó ju 73,000 ìjọ, àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa tí wọ́n lé ní million mẹ́rin àti ààbọ̀ ń fi taápọntaápọn làkàkà láti ṣiṣẹ́sin Ọlọrun ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà òdodo rẹ̀. Wọ́n mọ̀ pé Ọlọrun kì yóò fi àwọn ènìyàn rẹ̀ adúróṣinṣin sílẹ̀ láé. Àwọn wọnnì tí wọ́n ti ṣiṣẹ́sin Jehofa fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún gbé ohùn wọn sókè ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Ọba Dafidi, tí ó kọ̀wé pé: “Èmi ti wà ní èwe, èmi sì dàgbà; èmi kò tíì rí kí a kọ olódodo sílẹ̀, tàbí kí irú-ọmọ rẹ̀ kí ó máa ṣagbe oúnjẹ.”​—⁠Orin Dafidi 37:⁠25.

Ẹ wo bí ó ti dára tó láti lo ìgbàgbọ́ nínú Ọlọrun tí ó mísí àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn, dípò jíjẹ́ kí a dán wa wò lati gbéwiri bóyá kí a sì pàdánù ojúrere Ọlọrun títíláé!​—⁠1 Korinti 6:​9, 10.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Orúkọ náà ni a ti yípadà.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́