ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w94 4/15 ojú ìwé 26-29
  • Wọ́n Pinnu Láti Ṣiṣẹ́sin Jehofa!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wọ́n Pinnu Láti Ṣiṣẹ́sin Jehofa!
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣíṣẹ́pá Ìdánìkanwà
  • Wọ́n Dúróṣinṣin Lójú Àtakò
  • Ìtẹríba Láìfi Ìgbàgbọ́ Ẹni Dọ́rẹ̀ẹ́
  • ‘A Jèrè Wọn Ní Àìsọ̀rọ̀’
  • ‘Fi Omijé Fúrúngbìn; Kí O Sì Fi Ayọ̀ Kórè’
  • “Orí Obìnrin Ni Ọkùnrin”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2021
  • Ki Ni Itẹriba Ninu Igbeyawo Tumọsi?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ìmọ̀ràn Ọlọgbọ́n Fún Àwọn Tọkọtaya
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Ẹ̀yin Ọkọ—Ẹ Mú Kí Ilé Yín Tura
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
w94 4/15 ojú ìwé 26-29

Wọ́n Pinnu Láti Ṣiṣẹ́sin Jehofa!

“OKÒ gbọdọ̀ lọ wàásù!” “Èmi kò fẹ́ rí àwọn ènìyàn rẹ níhìn-⁠ín!” Ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin Kristian ni wọ́n ń gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí àti èyí tí ó farajọ wọ́n láti ọ̀dọ̀ àwọn ọkọ wọn alátakò. Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn ọkùnrin wọ̀nyí bá jẹ́ ológun, àwọn aya wọn ń dojú kọ àwọn ìpèníjà àrà-ọ̀tọ̀ kan sí ìgbàgbọ́ wọn. (Isaiah 2:⁠4; Johannu 17:16) Báwo, nígbà náà, ni irú àwọn Kristian aya bẹ́ẹ̀ ṣe ń gbìyànjú láti máa báa lọ ní jíjẹ́ alágbára nípa tẹ̀mí àti aláápọn nínú iṣẹ́-ìsìn Ìjọba?

Ìdúróṣinṣin sí Jehofa Ọlọrun papọ̀ pẹ̀lú ìpinnu ara-ẹni ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti forítì. “Mo rò pé ìpinnu aláìyẹhùn tèmí fúnraami ni,” ni Yvonne, aya ṣọ́jà kan ṣàlàyé. “Mo mọ̀ pé ó yẹ kí àwọn ọ̀nà wà láti gbà borí àtakò ọkọ mi.” Àwọn ọ̀nà wà nítòótọ́.

Kristian obìnrin mìíràn, tí ó fẹ́ ọ̀gá ṣọ́jà kan, ròyìn bí ìdúró aláìyẹhùn rẹ̀ ṣe mú kí ìgbésí-ayé túbọ̀ rọrùn fún ọkọ rẹ̀. “Ó mọ ìtòlẹ́sẹẹsẹ mi àti tirẹ̀ pẹ̀lú, àwọn ológun sì mọrírì èyí lọ́pọ̀lọpọ̀,” ni òun ṣàlàyé. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, bíbáalọ rẹ̀ láti ṣiṣẹ́sin Jehofa láìdáwọ́dúró kò rọrùn.

Ṣíṣẹ́pá Ìdánìkanwà

Aya àwọn ológun sábà máa ń dojúkọ ìpèníjà ṣíṣílọ ní pàjáwìrì bí wọn yóò bá bá ọkọ wọn lọ sí ibi àyè-iṣẹ́ titun wọn tí ó jìnnà sí ilé. Lẹ́yìn náà, ní fífìdíkalẹ̀ sí àyíká tí ó ṣàjòjì, ó rọrùn láti nímọ̀lára ìdánìkanwà. Ṣùgbọ́n kò yẹ kí èyí rí bẹ́ẹ̀. Àwọn tí wọ́n ń ṣiṣẹ́sin Jehofa ní àǹfààní kan. Kí ni ohun náà? Gẹ́gẹ́ bí Kristian aposteli Peteru ti wí, ó jẹ́ “gbogbo ẹgbẹ́ àwọn ará.” Àwọn tí iye wọn ti ń lọ sí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ nísinsìnyí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní 231 orílẹ̀-èdè ń ṣe gẹ́gẹ́ bí ìdílé Kristian ńlá kan, “ẹgbẹ́ ará” kan. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ níbi gbogbo ni o ti lè rí wọn.​—⁠1 Peteru 2:17, NW, àlàyé etí-ìwé.

Susan, tí a ṣàdédé fi agbára mú láti fi agbègbè ilé rẹ̀ sílẹ̀, gúnlẹ̀ sí ibùdó àwọn ọmọ-ogun òfuurufú níbi tí a yan ọkọ rẹ̀ sí. Bí ó ti jẹ́ ẹni titun nínú ìgbàgbọ́ tí ó sì wà lábẹ́ ìkìmọ́lẹ̀ láti ọ̀dọ̀ ọkọ rẹ̀ aláìgbàgbọ́ láti dáwọ́ nínípìn-⁠ín nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ Kristian dúró, òun ròyìn pé: “Ní wéré ni mo lọ sí ìpàdé àdúgbò, tí ó sì ṣeéṣe fún mi láti jókòó kí n sì bá àwọn arábìnrin mìíràn sọ̀rọ̀ níbẹ̀. Mo lè sọ nítòótọ́ pé ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ yìí ni ó ràn mi lọ́wọ́ láti máa báa nìṣó.”

Nígbà mìíràn ìdánìkanwà máa ń fa ìsoríkọ́. Kódà ní àkókò yẹn, ìhìnrere ń pèsè ìmúlárayá tí a fẹ́. Glenys, arábìnrin kan láti England tí ó tẹ̀lé ọkọ rẹ̀ tí iṣẹ́ gbé lọ sí òké òkun, sọ pé: “Nígbà tí mo ní ìsoríkọ́, láìròtẹ́lẹ̀, ẹnìkan tí mo ti mọ̀ lọ́pọ̀ ọdún sẹ́yìn nígbà tí èmi fúnraàmi ṣì jẹ́ ṣọ́jà, kọ̀wé tí ó sì sọ pé kò pẹ́ tí òun ṣe ìrìbọmi gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Ìyẹn fún mi ní ìṣírí ní àkókò yíyẹ gan-⁠an.”

Jane, ẹni tí ó rìnrìn-àjò lọ sí Kenya pẹ̀lú ọkọ rẹ̀, ríi pé àwọn ìpàdé Kristian jẹ́ agbẹ́mìíró, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èdè tí kò lóye ni a fi darí rẹ̀. “Mo mọ̀ pé ibí ni Jehofa fẹ́ kí n wà,” ni òun sọ. “Mo wà pẹ̀lú àwọn arákùnrin mi, wọ́n sì tù mí lára nípa tẹ̀mí. Wọ́n tẹ́wọ́gbà mi, mo sì nímọ̀lára pé a jẹ́ ìdílé kan.”

Jane wulẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára ọ̀pọ̀ àwọn wọnnì tí wọ́n wà lábẹ́ ipò wọ̀nyí tí ó ṣàwárí àwọn ìbátan nípa tẹ̀mí tí òun kò tilẹ̀ mọ̀ pé òun ní!​—⁠Marku 10:​29, 30.

Wọ́n Dúróṣinṣin Lójú Àtakò

Jesu kìlọ̀ pé: “Ẹ máṣe rò pé èmi wá rán àlàáfíà sí ayé, èmí kò wá rán àlàáfíà bíkòṣe idà.” (Matteu 10:34) Kí ni òun ní lọ́kàn? Kódà láàárín ìdílé, níbi tí a ti retí pé kí àlàáfíà gbilẹ̀, “idà jíjù láìròtẹ́lẹ̀” lè ṣẹlẹ̀, ni A. T. Robertson sọ nínú Word Pictures in the New Testament. Jesu sọ pé, “Àwọn ará ilé ènìyàn sì ni ọ̀tá rẹ̀.” (Matteu 10:36) Ẹ wo bí àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ti jẹ́ òtítọ́ tó nígbà tí alábàáṣègbéyàwó kan bá ṣe àtakò sí òtítọ́!

Nígbà tí Diane bẹ̀rẹ̀ síí kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, ọkọ rẹ̀, ọ̀gá ológun òfuurufú, kò nífẹ̀ẹ́ sí i rárá. Ipa wo ni èyí ní lórí ìgbéyàwó wọn? “Ńṣe ni ó dàbí ẹni pé omi dídì kan bọ́ sí àárín wa,” ni Diane sọ. “Ìgbéyàwó wa ti jẹ́ aláyọ̀. Lójijì ńṣe ni a kàn wulẹ̀ ń gbé nínú ilé kan náà lásán.” Nígbà náà, báwo ni òun ṣe kojú rẹ̀? “Jíjẹ́ kí ìgbàgbọ́ ẹni dánilójú àti ìpinnu ni ohun tí ó ṣe pàtàkì, papọ̀ pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ Jehofa àti ẹ̀mí rẹ̀.” Diane fi àpẹẹrẹ wòlíì Danieli nínú Bibeli sọ́kàn.

Nígbà tí ó wà ní ìgbèkùn ní Babiloni tí a sì fi àwọn oúnjẹ tí kò ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún ìránṣẹ́ Ọlọrun lọ̀ ọ́, Danieli “pinnu rẹ̀ ní ọkàn rẹ̀ pé, òun kì yóò fi oúnjẹ àdídùn ọba, . . . ba ara òun jẹ́.” Bẹ́ẹ̀ni, Danieli ṣe ìpinnu àtọkànwá. Ó pinnu ní ọkàn rẹ̀ pé òun kì yóò ba ara òun jẹ́ nípa jíjẹ àwọn oúnjẹ yẹn. Ẹ sì wo irú ìfàyàrán tí òun ṣàṣefihàn rẹ̀ bí ó ti ń bá a lọ lati “bẹ olórí àwọn ìwẹ̀fà pé, kí òun má baà ba ara òun jẹ́”! Kí ni ìyọrísí rẹ̀? Jehofa bùkún ìdúróṣinṣin aláìyẹhùn rẹ̀.​—⁠Danieli 1:​8, 9, 17.

Bákan náà ni lónìí, ọkọ kan tí ó jẹ́ alátakò lè pàṣẹ pé kí aya òun dáwọ́ lílọ sí àwọn ìpàdé ìjọ dúró. Báwo ni ó ṣe yẹ kí ó hùwàpadà? Jane bá araarẹ̀ nínú irú ipò yìí. Ó ṣàlàyé pé: “Èmi kì yóò juwọ́sílẹ̀ láé lábẹ́ ìkìmọ́lẹ̀. Mo mọ̀ pé kò lè sí ìfìgbàgbọ́ bánidọ́rẹ̀ẹ́ èyíkéyìí. Mo níláti fi bí àwọn ìpàdé náà ti ṣe iyebíye tó fún mi hàn kedere.” Jehofa bùkún ìpinnu rẹ̀ bí ó ti ń bá a lọ láti máa pésẹ̀ sí àwọn ìpàdé.

Glenys ròyìn pé: “Ọkọ mi gbìyànjú láti dí mi lọ́wọ́ ní lílọ sí àwọn ìpàdé, ṣùgbọ́n ìyẹn kò pẹ́ rárá, mo pàpà lọ. Nígbà tí mo bá padà dé ilé, òun máa ń nà mí ní àwọn ìgbà mìíràn, tàbí kẹ̀ kí ó má tilẹ̀ sọ̀rọ̀ sí mi.” Síbẹ̀, obìnrin náà kojú rẹ̀, ní gbígbàdúrà lemọ́lemọ́. Bákan náà, méjì nínú àwọn alàgbà inú ìjọ máa ń gbàdúrà pẹ̀lú rẹ̀ déédéé, èyí tí ó fún un ní ìṣírí lọ́pọ̀lọpọ̀ láti máa báa lọ ní pípésẹ̀ sí àwọn ìpàdé.​—⁠Jakọbu 5:13-⁠15; 1 Peteru 2:⁠23.

Nígbà mìíràn àwọn ọ̀gá ọkọ lè yọ ọ́ lẹ́nu láìsinmi láti dá aya rẹ̀ dúró wíwàásù ìhìnrere. Diane ríi pé òun gbọ́dọ̀ mú awọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jùlọ nínú ìgbésí-ayé òun ṣe kedere sí ọkọ òun. “Mo ti múratán,” ní òun sọ, “láti kojú àbájáde bíbáalọ mi ní wíwàásù.” Ẹ wo bí èyí ti jọ ìdúró àwọn aposteli tó! (Iṣe 4:​29, 31) Bí ó ti wù kí ó rí, òun lo ìṣọ́ra nínú ìwàásù rẹ̀. Ó ròyìn pé: “Mo máa ń ní ìkórajọpọ̀ fún kọfí mo sì máa ń fi ìwé Otitọ lọ gbogbo àwọn tí wọ́n bá pésẹ̀ síbẹ̀.”​—⁠Matteu 10:16; 24:⁠14.

Ìtẹríba Láìfi Ìgbàgbọ́ Ẹni Dọ́rẹ̀ẹ́

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pe pákáǹleke ìgbéyàwó ń kó ìdààmú bá wọn, àwọn Kristian aya ń wọ̀nà fún ọjọ́ iwájú wọ́n sì gbáralé Jehofa. Èyí ràn wọ́n lọ́wọ́ láti di ojú-ìwòye tí ó wàdéédéé mú. Wọ́n ń ṣe ìtìlẹ́yìn èyíkéyìí tí wọ́n bá lè ṣe fún àwọn ọkọ wọn láìfi ìgbàgbọ́ wọn dọ́rẹ̀ẹ́. Ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n ń tẹ̀lé ìmọ̀ràn onímìísí Peteru tí ó sọ pé: “Ẹ̀yin aya, ẹ máa tẹríba fún awọn ọkọ yín.” (1 Peteru 3:1) Nínú The Amplified New Testament, ìtọni aposteli yìí kà pé: “Ẹ rẹ araayín sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó rẹlẹ̀ tí ó sì gbáralé wọn, kí ẹ sì mú araayín bá ipò wọn mu.” Ṣàkíyèsí bí Jane ṣe tẹ̀lé ìmọ̀ràn yìí. “Ọkọ mi sọ fún mi pé òun tí mo bá fẹ́ ṣe kò gbọdọ̀ dí iṣẹ́ ìgbésí-ayé òun lọ́wọ́,” ni ó ṣàlàyé. “Nítorí náà mo wá àwọn ọ̀nà tí mo lè gbà ràn án lọ́wọ́.”

Nípa báyìí, àwọn Kristian aya kan ti gbà láti lọ sí ibi àpèjẹ ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà tí a késí àwọn ọkọ wọn sí. Ṣùgbọ́n wọ́n ṣì pinnu láti máṣe fi ìgbàgbọ́ wọn dọ́rẹ̀ẹ́ láé. Jane lo àkókò láti bá ọkọ rẹ̀ sọ̀rọ̀ lórí èyí. Ó fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ ṣàlàyé pé òun múratán láti tẹ̀lé e lọ ṣùgbọ́n òun kò fẹ́ kí wíwà níbẹ̀ òun dójú tì í. “Mo mọ̀ pé lẹ́kọ̀ọ̀kan, gbogbo àwọn tí wọ́n bá pésẹ̀ síbẹ̀ ni a óò retí pé kí wọ́n dìde kí wọn sì fi ife gbá ife. Mo ti kẹ́kọ̀ọ́ pé ìtúúbá yẹ fún Jehofa nìkanṣoṣo, fífi ife gbá ife kìí wulẹ̀ ṣe fífi ọ̀wọ̀ hàn lásán. Ọkọ mi lóye bí irú ipò bẹ́ẹ̀ ṣe lè kótìjú báni tó, nítorí náà ó wulẹ̀ sọ pé: ‘Má tẹ̀lé mi!’ Mo sì ṣègbọràn sí i.”

Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, Glenys tẹ̀lé ọkọ rẹ̀ lọ sí ibi àpèjẹ bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n ó ń ṣọ́ àwọn ọ̀gá tí wọn jókòó sí iwájú tábìlì. Nígbà tí ó ríi pé wọ́n ti ń múra àti fi ife gbá ife, ó fi ọgbọ́n dìde lọ sí ilé-ìtura! Bẹ́ẹ̀ni, àwọn obìnrin wọ̀nyí mú araawọn bá ọkọ wọn mu ṣùgbọ́n wọn kò fi ipò ìgbàgbọ́ wọn bánidọ́rẹ̀ẹ́ láé.

‘A Jèrè Wọn Ní Àìsọ̀rọ̀’

Yvonne ronú pé: “Bí mo bá fikún ìsapá mi gẹ́gẹ́ bí aya kan, ọkọ mi yóò ríi pé òtítọ́ ń yí mi padà.” Nítorí náà ó ka àkòrí náà nínú ìwé Igbesi Ayé Idile tí ó sọ pé “Aya kan Ti A Fẹran Gidigidi”a ní àkàtúnkà. “Mo fi àfiyèsí àrà-ọ̀tọ̀ sí àkójọ-ọ̀rọ̀ tí ó wà lábẹ́ ìsọ̀rí náà ‘Awọn Ẹlẹkun, Awọn Ẹlẹjọ-Wẹwẹ’! Ṣùgbọ́n mo ṣàkíyèsí pé bí mo ṣe ń tiraka láti bá ọkọ mi sọ̀rọ̀ tó, bẹ́ẹ̀ni ọ̀ran túbọ̀ ń burú síi tó.” Bí ó ti wù kí ó rí, nígbẹ̀yìngbẹ́yín ó ṣàṣeyọrí ní ríran ọkọ rẹ̀ lọ́wọ́ láti ṣiṣẹ́sin Jehofa. Báwo ni ó ṣe ṣe é? Nípa fífi ìlànà tí a là sílẹ̀ ní 1 Peteru 3:1 sílò tí ó sọ pé awọn ọkọ ni a “lè jèrè wọn ní àìsọ̀rọ̀.”

Ọ̀nà tí àwọn obìnrin Kristian ń gbà bójútó àwọn ìdílé wọn ń ṣe púpọ̀púpọ̀ láti mú kí ìsìn Kristian wu àwọn ẹlòmíràn. “Mo gbìyànjú láti mú kí òtítọ́ fanimọ́ra bí ó ti lè ṣeéṣe tó,” ni Diane ròyìn. “Nígbà tí mo bá lọ sí ìpàdé, ọkọ mi máa ń nímọ̀lára ìdánìkanwà, nítorí náà mo làkàkà láti fún àwọn ọmọ ní ìtọ́ni láti hùwà dáradára nígbà tí a bá dé ilé. Èmi pẹ̀lú gbìyànjú láti fún un ní àfiyèsí àrà-ọ̀tọ̀ nígbà tí a padà dé.” Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ ni ìṣarasíhùwà ọkọ rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ síí yípadà bí ó ti ń dáhùnpadà sí àfiyèsí onínúure ìdílé rẹ̀.

Àwọn ìránṣẹ́ Jehofa ẹlẹgbẹ́ ẹni lè ṣe ìrànlọ́wọ́ pẹ̀lú. Jane ròyìn pé ọkọ òun gbádùn ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ àwọn míṣọ́nnárì Ẹlẹ́rìí tí ó ṣalábàápàdé ní Kenya. “Wọ́n bá a dọ́rẹ̀ẹ́ wọ́n sì sọ̀rọ̀ nípa eré bọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá, wọ́n sì jẹ́ olùfẹ́ àlejò gidigidi. Ní ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n késí wa lọ sí onírúurú ilé míṣọ́nnárì láti wá jẹun.” Ọkọ rẹ̀ sọ lẹ́yìn náà pé: “Mo wá bẹ̀rẹ̀ síí rí ìgbàgbọ́ Jane láti inú ojú-ìwòye tí ó yàtọ̀ pátá. Àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ jẹ́ àwọn ènìyàn tí wọ́n gbọ́n dáradára tí wọ́n lè sọ̀rọ̀ lórí onírúurú kókó-ẹ̀kọ́.” Lọ́nà kan náà, ọkọ Diane yí ojú-ìwòye rẹ̀ nípa òtítọ́ padà. Nígbà tí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tí ó ń wà bàjẹ́, ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí kan ni ó wá ṣèrànlọ́wọ́ fún un. “Ìyẹn wú mi lórí lọ́pọ̀lọpọ̀,” ni òun sọ.

Dájúdájú, kìí ṣe gbogbo àwọn alábàáṣègbéyàwó ẹni ni a ń jèrè sínú òtítọ́. Kí ni a lè ṣe nígbà náà? Jehofa ń pèsè ìrànlọ́wọ́ láti mú kí ó ṣeéṣe fún àwọn adúróṣinṣin láti forítì í. (1 Korinti 10:13) Ronú nípa ọ̀rọ̀ ìṣírí Glenys sí àwọn tí wọ́n wà ní irú ipò rẹ̀: “Máṣe ṣiyèméjì láé pé Jehofa ni Ẹni tí ó dá ètò ìgbéyàwó sílẹ̀ àti pé òun ń fẹ́ kí àwọn tọkọtaya wà papọ̀. Nítorí náà láìka ohun tí ọkọ rẹ lè ṣe sí tàbí irú àtakò tí ìwọ lè dojúkọ láti ọ̀dọ̀ àwọn wọnnì tí ó yí ọ ká, Jehofa kì yóò jẹ́ kí ẹsẹ̀ rẹ̀ kí ó yẹ̀ láé.” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọkọ rẹ̀ kò tíì sin Jehofa, ìṣarasíhùwà rẹ̀ sí i àti sí òtítọ́ ti di ti oníwà-⁠bí-ọ̀rẹ́.

‘Fi Omijé Fúrúngbìn; Kí O Sì Fi Ayọ̀ Kórè’

Nítòótọ́, àwọn obìnrin Kristian wọ̀nyí pinnu láti ṣiṣẹ́sin Jehofa. Bí ìwọ bá wà nínú ipò kan náà, sọ èyí di ìpinnu rẹ pẹ̀lú. Rántí ọ̀rọ̀ ìyànjú náà: “Kí ìwọ kí ó máa bẹ̀rù Oluwa Ọlọrun rẹ; òun ni kí ìwọ kí ó máa sìn, òun ni kí ìwọ kí ó sì faramọ́.”​—⁠Deuteronomi 10:⁠20.

“Ẹni tí ń fi ẹkún rìn lọ, tí ó sì gbé irúgbìn lọ́wọ́, lóòótọ́, yóò fi ayọ̀ padà wá, yóò sì ru ìtí rẹ̀,” ni olórin náà sọ. (Orin Dafidi 126:6) Ẹlẹ́rìí kan gbà pé: “Ìwọ ń sun ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹkún bí o ti ń gbìyànjú láti fi òtítọ́ han alábàáṣègbéyàwó rẹ, bóyá nípa ìwà tàbí ọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n ní òpin rẹ̀, ìwọ fi ayọ̀ kígbe jáde nítorí pé bí òun kò bá tilẹ̀ tẹ́wọ́gba òtítọ́, Jehofa yóò máa bùkún fún ọ fún ìsapá tí o ṣe.”

Gbogbo àwọn wọnnì tí wọ́n ń fi pẹ̀lú ìṣòtítọ́ ṣiṣẹ́sin Jehofa láìka àtakò nínú ilé sí yẹ fún ìgbóríyìn gidi. Wọ́n lẹ́tọ̀ọ́sí ìtìlẹ́yìn àti ìfẹ́ wa. Ǹjẹ́ kí wọ́n máa bá ìdúró aláìjuwọ́sílẹ̀ nínú ìgbàgbọ́ wọn lọ, pẹ̀lú ìpinnu aláìyẹhùn láti ṣiṣẹ́sin Jehofa!

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Mimu Ki Igbesi Ayé Idile Rẹ Jẹ Alayọ ni a tẹ̀ láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc. (1981).

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]

Ìkẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú àdúrà ń fún ìpinnu Kristian lókun

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́