ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w94 6/1 ojú ìwé 3-4
  • Èéṣe tí Ó Fi Yẹ Kí A Lọ́kàn-Ìfẹ́ Nínú Ìsìn?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Èéṣe tí Ó Fi Yẹ Kí A Lọ́kàn-Ìfẹ́ Nínú Ìsìn?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Wọ́n Yọ̀ǹda Ara Wọn Tinútinú—Ní Alibéníà àti Kosovo
    Ìrírí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà
  • Eeṣe Ti A Fi Nilati Fọwọ́ Pataki Mu Isin?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ìwọ Ha Ti Rí Ìsì Tí Ó Tọ̀nà Bí?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Bí Ọwọ́ Rẹ Ṣe Lè Tẹ Ohun Tó O Nílò Nípa Tẹ̀mí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
w94 6/1 ojú ìwé 3-4

Èéṣe tí Ó Fi Yẹ Kí A Lọ́kàn-Ìfẹ́ Nínú Ìsìn?

ỌKÀN-ÌFẸ́ wà fún ìsìn ní gbogbo orílẹ̀-èdè tí ń bẹ lórí ilẹ̀-ayé. Ní òdìkejì ẹ̀wẹ̀, ọ̀pọ̀ ènìyàn tún wà tí wọ́n sọ ní ṣàkó pé àwọn kò lọ́kàn-ìfẹ́ nínú ìsìn. Ṣùgbọ́n ǹjẹ́ wọ́n ha ń nímọ̀lára lọ́nà bẹ́ẹ̀ nígbà gbogbo bí?

A dá ènìyàn lọ́nà tí ó fi jẹ́ pé àwọn nǹkan ti ara nìkan kò lè tẹ́ ẹnìkan lọ́rùn níti gidi. Àwọn ènìyàn ní àìní fún jíjẹ́ ẹni tẹ̀mí. Ìwàláàyè ọjọ́ dé ọjọ́ tí a kọ́ yíká níní àwọn ohun kòṣeémánìí ti ara lásán, pẹ̀lú àwọn sáà eré-ìtura lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, kìí tẹ́ àwọn àìní inú lọ́hùn-⁠ún tí ẹnìkan ní lọ́rùn lẹ́kùn-⁠ún-rẹ́rẹ́. Ní ìyàtọ̀ sí àwọn ẹranko, ènìyàn fẹ́ láti mọ̀, ‘Kí ni ète ìgbésí-ayé?’ ‘Ìgbésí-ayé kúkúrú yìí, tí ó ní ọ̀pọ̀ ohun rírẹwà nínú síbẹ̀ tí ó tún kún fún ọ̀pọ̀ ohun bíburẹ́wà, èyí ha ni gbogbo ohun tí ó wà bí?’ Ìwọ kò ha ti béèrè àwọn ìbéèrè wọ̀nyí bí?

S í b ẹ̀, ọ̀ p ọ̀ àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ènìyàn tí wọ́n wàláàyè lónìí dàgbà ní àwọn àyíká ibi tí a kò ti fojúure wo níní ọkàn-ìfẹ́ èyíkéyìí tí ó ṣe gúnmọ́ nínú ìsìn. Agbára ìdarí bẹ́ẹ̀ ti lè wá láti ọ̀dọ̀ àwọn òbí wọn, láti ọ̀dọ̀ àwọn olùkọ́, láti ọ̀dọ̀ àwọn ojúgbà, tàbí láti ọ̀dọ̀ ìjọba pàápàá.

Skalabrino, ọ̀dọ́mọkùnrin kan láti Albania, ṣàlàyé pé lábẹ́ àkóso ìjọba Kọmmunist àwọn ènìyàn ni a kọ́ pé kò sí Ọlọrun. Síwájú síi, ó léwu fún wọn láti sọ̀rọ̀ nípa ìsìn; ṣíṣe bẹ́ẹ̀ lè yọrísí ìfinisẹ́wọ̀n. Síbẹ̀, ní 1991, nígbà tí ó wà ní Switzerland gẹ́gẹ́ bí olùwá-ibi-ìsádi, a fún un ní àǹfààní láti kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli. Ó tẹ́wọ́gbà á. Èéṣe?

Ó dára, ní Albania òun ti gbọ́ pé ìwé kan wà tí ń jẹ́ Bibeli, ṣùgbọ́n níti gidi òun kò mọ ohunkóhun nípa rẹ̀. Nítorí náà, ó lè má jẹ́ ìfẹ́-ọkàn láti lóye Bibeli ni ó sún un ní ìbẹ̀rẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a sọ fún un pé òun yóò máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa ète Ọlọrun fún aráyé àti ilẹ̀-ayé, ó tún ríi gẹ́gẹ́ bí àǹfààní kan láti mú kí sísọ tí òun ń sọ èdè àdúgbò náà jágaara síi. Bí ó ti wù kí ó rí, lójú ẹsẹ̀, ó ríi pé ohun tí òun ń kọ́ tẹ́ ìyánhànhàn tẹ̀mí inú lọ́hùn-⁠ún ti òun lọ́rùn. A mú ọkàn rẹ̀ yọ̀ nípasẹ̀ ìlérí Ọlọrun fún ayé titun kan níbi tí àlàáfíà yóò ti gbilẹ̀, ayé kan nínú èyí tí àwọn ènìyàn yóò lè wàláàyè títíláé kí wọ́n sì gbádùn ọ̀pọ̀ yanturu àwọn nǹkan kòṣeémánìí fún ìgbésí-ayé. Ọkàn-ìfẹ́ rẹ̀ ní a tún mú pọ̀ síi nígbà tí ó kẹ́kọ̀ọ́ pé òun àti ìdílé òun lè nípìn-⁠ín nínú ayé titun yìí. Níwọ̀n bí kò ti lè pa ìhìnrere náà mọ́ra, ó tẹ ìdílé rẹ̀ tí ó fi sílẹ̀ ní Albania láago láti ṣàjọpín rẹ̀ pẹ̀lú wọn.

Ìyọrísí tí ìmọ̀ pípéye láti inú Bibeli lè ní lórí ìgbésí-ayé ẹnìkan ya Aleksei, tí ń gbé ní Russia, pẹ̀lú lẹ́nu. Bí àwọn ìṣòro ti wọ̀ ọ́ lọ́rùn tí kò sì ṣeéṣe fún un láti rí àlàyé títẹ́nilọ́rùn nípa ète ìgbésí-ayé, ó gbèrò láti pa ara rẹ̀. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, lákọ̀ọ́kọ́, ó lọ sí Finland láti bẹ ọ̀rẹ́ kan wò. Nínú ìrìn-àjò náà nínú ọkọ̀ rélùwéè, ó bá àwọn èrò ọkọ̀ bíi tirẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa ìṣòro rẹ̀. Nínú wọn ni ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, tí ó rọ̀ ọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli nítorí pé ó pèsè ojútùú sí irú àwọn ìṣòro bẹ́ẹ̀. Ó ṣiyèméjì. Ní àbọ̀ ìrìn-àjò náà, ó tún ní irú ìrírí kan náà. Lọ́tẹ̀ yìí Ẹlẹ́rìí mìíràn ni ó sọ èrò ọkàn rẹ̀ jáde fàlàlà tí ó sì sọ fún un pé òun náà ti ní irú ìṣòro bẹ́ẹ̀ rí ṣùgbọ́n Bibeli ti ṣèrànwọ́ fún òun láti borí wọn. Òun pẹ̀lú fún un níṣìírí láti kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli. Nígbà tí ó padà délé, ẹ̀rọ tẹlifóònù dún. Ọ̀rẹ́ rẹ mìíràn kan ni, tí ó ń kẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí tí ó sì láyọ̀ gidigidi. Ọkùnrin náà wá bẹ̀rẹ̀ sí ríi pé ó ṣeéṣe kí Bibeli lè pèsè ohun tí òun nílò níti tòótọ́, ṣùgbọ́n ó mọ̀ pé òun kò lè lóye rẹ̀ láìsí ìrànwọ́. Ó gbà láti máa ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli inú ilé déédéé pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí lọ sí àwọn ìpàdé wọn. Kò gbà á ní àkókò púpọ̀ láti lóye ìdí tí àwọn tí wọ́n kọ́ ìgbésí-ayé wọn yíká ohun tí Bibeli fi kọ́ni fi jẹ́ aláyọ̀ tóbẹ́ẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn náà ń fojú winá àwọn ìṣòro kan náà tí aráyé ń dojúkọ.

Pẹ̀lú ìjìnlẹ̀ òye nípa ọ̀nà tí a gbà dá ènìyàn, Jesu Kristi sọ pé: “Ènìyàn kò lè wàláàyè nípa búrẹ́dì nìkan.” (Matteu 4:4, The New English Bible) Ó tún sọ pé: “Aláyọ̀ ni awọn wọnnì tí àìní wọn nipa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn.” (Matteu 5:⁠3 NW) Wọ́n láyọ̀ nítorí pé wọ́n mọ àìní wọn jinlẹ̀ jinlẹ̀, wọ́n gbé ìgbésẹ̀ yíyẹ láti tẹ́ ẹ lọ́rùn, wọ́n sì nírìírí ìbùkún Ọlọrun. Bí ó ti wù kí ó rí, a kò tẹ́ àìní wa tẹ̀mí lọ́rùn nípa wíwulẹ̀ darapọ̀ mọ́ ṣọ́ọ̀ṣì kan tàbí pípésẹ̀ síbi àwọn ètò ìsìn kan. Ìsìn tí ó jẹ́ ti aláàtò àṣà lọ́pọ̀lọpọ̀ lè fanilọ́kàn mọ́ra, ṣùgbọ́n ó ha pèsè àwọn ojútùú tòótọ́ gidi sí àwọn ìṣòro ìgbésí-ayé bí? Àní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìsìn kan ṣe alágbàwí àwọn ìlànà-ìwà ṣíṣekókó tí ó bọ́gbọ́nmu kan, bí ó bá kùnà láti pèsè òye tòótọ́ nípa ète gidi fún ìgbésí-ayé, yóò ha tẹ́ àìní tẹ̀mí rẹ lọ́rùn bí? Èyí tí ó tún jẹnilógún jùlọ ni pé, ǹjẹ́ ṣíṣe irú ìsìn bẹ́ẹ̀ yóò ha yọrísí níní ìbátan dídára pẹ̀lú Ọlọrun? Láìsí ìyẹn, kì yóò sí ìtẹ́lọ́rùn tòótọ́ kankan.

Nínú ọ̀ràn yìí ọ̀pọ̀ ènìyàn ń wá ohun kan tí wọn kò tíì rí kiri.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]

A o ha tẹ àìní rẹ nípa tẹ̀mí lọ́rùn nítòótọ́ nípa dídarapọ̀ mọ́ ṣọ́ọ̀ṣì kan bí?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

Ọ̀pọ̀ ti ríi pe nígbà tí wọn lóye Bibeli, ìgbésí-ayé ní ìtumọ̀ tí ó yàtọ̀

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́