ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w94 6/1 ojú ìwé 5-7
  • Ìwákiri Wọn fún Ìsìn Tí Ó Tọ̀nà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìwákiri Wọn fún Ìsìn Tí Ó Tọ̀nà
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìdí Tí Àwọn Kan Fi Ní Iyèméjì Gidigidi
  • Ó Kọ́ Òtítọ́ Nípa Àwọn Òkú
  • Wọ́n Rí Ìgbésí-Ayé tí Ó Nítumọ̀
  • Akínkanjú Aṣáájú-ọ̀nà
    Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2016
  • ‘Aláyọ̀ Ni Ọkùnrin náà tí Ó Wá Ọgbọ́n Rí’
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Bí Àwọn Kan Ṣe Rí Ìdáhùn Gbà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
  • Awọn Agutan Jesu Fetisilẹ si Ohùn Rẹ̀
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
w94 6/1 ojú ìwé 5-7

Ìwákiri Wọn fún Ìsìn Tí Ó Tọ̀nà

LÁTI ìgbà ọmọdé ní àwọn kan ti ń wá ìdáhùn títẹ́nilọ́rùn sí àwọn ìbéèrè tí wọ́n ní nípa ìgbésí-ayé kiri. Nígbà tí wọ́n wà léwe, wọ́n ti lè lọ síbi àwọn ètò ìsìn. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ lára wọn ríi pé yálà àwọn ìdáhùn tí a fúnni tàbí ààtò àṣà ṣọ́ọ̀ṣì náà kò ṣèrànwọ́ níti gidi láti kojú àwọn ìṣòro ìgbésí-ayé.

Wọ́n lè sọ pé àwọn ṣì ń ṣe ìsìn àwọn òbí àwọn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀ẹ̀kanlọ́gbọ̀n ni wọ́n ń pésẹ̀ síbi àwọn ètò ìsìn. Gẹ́gẹ́ bí bíṣọ́ọ̀bù Ṣọ́ọ̀ṣì ti England ṣe sọ, tiwọn jẹ́ òfegè ìgbàgbọ́. Wọ́n ti fọwọ́ rọ́ ìsìn tì sẹ́yìn. Àwọn mìíràn, tí àgàbàgebè tí wọ́n rí nínú agbo ìsìn ti kónírìíra, ti kọ ìsìn sílẹ̀ lákọ̀tán. Síbẹ̀, àwọn ìbéèrè wọn nípa ìgbésí-ayé ṣì wà níbẹ̀.

Ìdí Tí Àwọn Kan Fi Ní Iyèméjì Gidigidi

Àwọn ènìyàn tí ó pọ̀ jùlọ mọ̀ pé ọ̀pọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì ní àwọn aṣojú láti ṣèrànwọ́ fún àwọn aláìnílé, láti pín oúnjẹ fún àwọn aláìní, àti láti ṣonígbọ̀wọ́ àwọn ayẹyẹ ìṣẹ̀dálẹ̀. Ṣùgbọ́n ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé lójoojúmọ́ ni wọ́n ń gbọ́ ìròyìn nípa ìwà-ipá àti ìtàjẹ̀sílẹ̀ tí ìsìn dásílẹ̀ kìí ṣe kìkì láàárín àwọn tí kìí ṣe Kristian ṣùgbọ́n láàárín àwọn tí wọ́n fẹnu lásán sọ pé àwọn jẹ́ Kristian. Ó ha yẹ kí ó yà wá lẹ́nu bí wọ́n bá ṣiyèméjì pé àwọn àwùjọ tí ń lọ́wọ́ nínú irú ìwà-ipá bẹ́ẹ̀ ń ṣe ìsìn tí ó tọ̀nà bí?

Ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n jẹ́ onísìn látilẹ̀ wá sábà máa ń ronú pé ilé ìtọ́jú àwọn ọmọ òrukàn tí àwọn ṣọ́ọ̀ṣì ń ṣonígbọ̀wọ́ fún jẹ́ ohun yíyẹ. Bí ó ti wù kí ó rí, ní àwọn ọdún àìpẹ́ yìí, a ti dáyà já wọn bí a ti ń fẹ̀sùnkan àwọn àlùfáà láti ibìkan sí ibòmíràn fún fífi ìbálòpọ̀ fìyà jẹ àwọn ọmọdé tí a fi síkàáwọ́ wọn. Lákọ̀ọ́kọ́ àwọn ènìyàn rò pé ìwọ̀nba àlùfáà díẹ̀ ni a lè dálẹ́bi. Ní báyìí àwọn kan lára wọn ń ṣe kàyéfì bóyá nǹkankan ti ṣẹlẹ̀ sí ṣọ́ọ̀ṣì náà fúnraarẹ̀ ní ọ̀nà ṣíṣepàtàkì kan.

Àwọn díẹ̀, bíi Eugenia, ti ri ara wọn bọ inú ìsìn wọn bámúbámú nígbàkan rí. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́ kan ní Argentina, ó wà lára àwọn tí wọ́n rin ìrìn-àjò mímọ́ láti jọ́sìn Wúńdía ti Itatí. Fún ọdún 14 ó gbé inú ilé àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàndágbé gẹ́gẹ́ bí obìnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàndágbé. Lẹ́yìn náà ó kúrò láti di apákan ẹgbẹ́ aṣòṣèlúṣèsìn kárí ayé kan tí ó ṣalágbàwí ìyípadà tegbòtigàgá ojú ẹsẹ̀, ti ètò ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà àti ọrọ̀-ajé ti ẹgbẹ́-àwùjọ nípasẹ̀ ọ̀nà ìṣọ̀tẹ̀. Nítorí nǹkan tí ó fójúrí tí ó sì nírìírí rẹ̀, o sọ ìgbàgbọ́ àti ìgbọ́kànlé nù nínú Ọlọrun. Òun kò wá ìsìn kan tí òun lè ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ kiri níti gidi. Ohun tí òun ń fẹ́ ni ọ̀nà kan láti mú ìdájọ́ òdodo wá fún àwọn tí wọ́n tòṣì​—⁠bẹ́ẹ̀ni, àti ọ̀rẹ́ kan tí òun lè fọkàntán.

Àwọn mìíràn ti kíyèsí ohun tí ń lọ nínú àwọn ṣọ́ọ̀ṣì wọ́n sì ti fàsẹ́yìn. Aláìgbọlọ́rungbọ́ kan tí a tẹ ojú ìwòye rẹ̀ jáde ní 1991 nínú ìwé ìròyìn Sputnik fi tòótọ́ tòótọ́ sọ pé: “Èmi kò rí ìyàtọ̀ kan tí ó ṣe gúnmọ́ láàárín àwọn ànímọ́ àròsọ àtọwọ́dọ́wọ́ ti àwọn abọ̀rìṣà àti ti Kristian.” Gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ kan, òun ṣàpèjúwe ìtòlọ́wọ̀ọ̀wọ́ kan nínú èyí tí àwọn àlùfáà tí wọ́n wọ aṣọ ìgúnwà tí a fi góòlù ṣe ọnà sí ti rọra ń gbé pósí olóòkúta pẹ̀lú òkú tí a kùn lọ́ṣẹ la àárín ìgboro Moscow já. Ó jẹ́ òkú “Kristian mímọ́ onísìn Orthodox kan” tí a gbé láti ilé nǹkan ìṣẹ̀m̀báyé lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì, ó sì rán òǹkọ̀wé náà létí àwọn àlùfáà àti àwọn òkú tí a kùn lọ́ṣẹ ní Egipti ìgbàanì. Ó rántí pẹ̀lú, pé, bí àwọn tí wọ́n ń lọ́wọ́ nínú ìtòlọ́wọ̀ọ̀wọ́ náà ní Moscow ṣe gbàgbọ́ nínú “Mẹ́talọ́kan ti Kristian,” àwọn ará Egipti pẹ̀lú ti jọ́sìn àwọn ọlọrun olórí mẹ́ta​—⁠Osiris, Isis, àti Horus.

Òǹkọ̀wé yẹn kan náà tọ́kasí èrò àwọn Kristian nípa ìfẹ́​—⁠“ìfẹ́ ni Ọlọrun,” àti “fẹ́ ẹnìkejì rẹ”​—⁠gẹgẹ bí èyí tí kò ní ìbáradọ́gba kankan pẹ̀lú Egipti abọ̀rìṣà. Ṣùgbọ́n òun ṣàkíyèsí pé: “Ìfẹ́ ará ti kùnà láti ṣẹ́gun nínú ayé, àní ní agbègbè aye yẹn tí ó pe ara rẹ̀ ní ìhà ayé tí ó jẹ́ ti Kristian pàápàá.” Ó gbe èyíinì lẹ́sẹ̀ pẹ̀lú àwọn àlàyé nípa èso búburú tí ṣọ́ọ̀ṣì ti ní láti inú ìrinkinkin ṣọ́ọ̀ṣì mọ́ lílọ́wọ́ nínú àlámọ̀rí Ìjọba. Ohun tí ó rí kò sún un láti ronú pé àwọn ṣọ́ọ̀ṣì Kristẹndọm ń fúnni ní ohun tí òun ń wá kiri.

Ní òdìkejì ẹ̀wẹ̀, àwọn mìíràn ti rí ìdáhùn títẹ́nilọ́rùn ṣùgbọ́n kìí ṣe nínú àwọn ṣọ́ọ̀ṣì Kristẹndọm.

Ó Kọ́ Òtítọ́ Nípa Àwọn Òkú

Magdalena, ẹni tí ó jẹ́ ẹni ọdún 37 nísinsìnyí, ń gbé ní Bulgaria. Lẹ́yìn ìgbà tí bàbá ọkọ rẹ̀ kú ní 1991, ó sọ̀rètínù pátápátá. Ó ń bi araarẹ̀ léraléra pé, ‘Níbo ni àwọn òkú lọ? Níbo ni bàbá ọkọ mi wà?’ Ó lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì, ó sì gbàdúrà níwájú ère ìsìn inú ilé, síbẹ̀ kò rí ìdáhùn kankan.

Nígbà tí ó di ọjọ́ kan aládùúgbò rẹ̀ kan tẹ̀ ẹ́ láago láti pè é wá sí ilé rẹ̀. Ọ̀dọ́mọkùnrin kan tí ó ń kẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń ṣèbẹ̀wò sí ọ̀dọ̀ aláàdúgbò náà. Ó fetísílẹ̀ bí ó ṣe ń sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọrun àti ète Rẹ̀ láti sọ ilẹ̀-ayé di paradise kan níbi tí ènìyàn yóò ti lè wàláàyè títíláé nínú ayọ̀. Ìwé náà Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye wà lórí tábìlì. Ní lílò ó, ọ̀dọ́mọkùnrin náà darí àfiyèsí rẹ̀ sí ẹsẹ̀ Bibeli náà tí ó wà ní Oniwasu 9:5, èyí tí ó sọ pé: “Àwọn òkú kò mọ ohun kan.” Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ yẹn ó kà á síwájú síi. Ó kẹ́kọ̀ọ́ pé àwọn òkú kìí bá ìwàláàyè nìṣó níbòmíràn ní ọ̀run tàbí ní hẹ́ẹ̀lì; wọn kò mọ ohunkohun, àfi bí ẹní tí ó sun oorun àsùnwọra. Pẹ̀lú ayọ̀ ó tẹ́wọ́gba ìkésíni náà láti wá sí ìpàdé ìjọ àdúgbò ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Lẹ́yìn ìpàdé náà ó gbà láti ní ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli déédéé. Ní ṣíṣàkíyèsí ọ̀nà tí a gbà gbàdúrà sí Jehofa ní ìpàdé náà, òun pẹ̀lú bẹ̀rẹ̀ sí gbàdúrà sí Jehofa fún ìrànwọ́ láti lè ṣẹ́gun àìlera tí ó ti wọ̀ ọ́ lára gan-⁠an. Nígbà tí àdúrà rẹ̀ gbà, ó mọ̀ pé òun ti rí ìsìn tí ó tọ̀nà.

Wọ́n Rí Ìgbésí-Ayé tí Ó Nítumọ̀

André dàgbà nínú ìdílé kan tí ó fọwọ́ danyindanyin mú ìsìn Katoliki ní Belgium tí ó sì ti ṣiṣẹ́sìn gẹ́gẹ́ bi igbákejì àlùfáà àdúgbò náà. Bí ó ti wù kí ó rí, ní àkókò yẹn, ó rí àwọn ohun tí ó jin ọ̀wọ̀ tí ó ní fún ṣọ́ọ̀ṣì rẹ̀ lẹ́sẹ̀. Nítorí èyí, ó jẹ́ Katoliki aláfẹnujẹ́ lásán.

Fún ọdún 15 ó ti fi bọ́ọ̀lù gbígbá ṣiṣẹ́ṣe. Nígbà kan tí ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù rẹ̀ nípìn-⁠ín nínú eré ìdíje kan ní Italy, a pè wọ́n fún ìpàdé kan pẹ̀lú póòpù. Kò sí ohunkohun tí ń gbéniró nípa tẹ̀mí nípa ìbẹ̀wò yẹn, àwọn ọrọ̀ ayé tí ó yí póòpù náà ká sì kó ìdààmú bá André. Iyèméjì rẹ̀ nípa ṣọ́ọ̀ṣì náà túbọ̀ jinlẹ̀ síi. Ìgbésí-ayé òun fúnraarẹ̀ di aláìláyọ̀ nítorí ìgbéyàwó méjì tí ó foríṣánpọ́n. Ipò ayé já a kulẹ̀. Ní 1989 ó kọ ọ́ sínú ìwé àkọsílẹ̀ ìgbòkègbodò ojoojúmọ́ rẹ̀ pé: ‘Kí ni ìtumọ̀ gbogbo nǹkan rẹ́dẹrẹ̀dẹ tí ń ṣẹlẹ̀ ní àyíká wa yìí?’ Kò rí ìdáhùn kankan láti inú ìsìn rẹ̀.

Ní 1990, nígbà tí André ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí adánilẹ́kọ̀ọ́ eré bọ́ọ̀lù ní Iceland, Iiris, míṣọ́nnárì àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa kan, kàn sí i. Ó tẹ́wọ́gba ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ ó si rọ míṣọ́nnárì náà láti padà wá. Ó padà lọ pẹ̀lú ọkọ rẹ̀, Kjell. Nígbà tí ó ṣeéṣe fún wọn níkẹyìn láti jókòó kí wọ́n sì bá André sọ̀rọ̀, ó hàn gbangba pé ó ní ọkàn-ìfẹ́ jíjinlẹ̀ láti lóye Bibeli. Aya rẹ̀, Ásta, ní ọkàn-ìfẹ́ bíi tirẹ̀. Ní ọ̀sán ọjọ́ kọ̀ọ̀kan, ó máa ń ní wákàtí mẹ́ta láàárín àkókò ìdánilẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀, wọ́n sì pinnu láti lo àkókò yẹn fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli. Ó sọ pé: “Ó tù mí lára láti máa kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli ju sísinmi lásán lọ.” Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ Bibeli dáhùn àwọn ìbéèrè wọn. Kò pẹ́ kò jìnnà ìgbàgbọ́ wọn nínu Jehofa àti Ìjọba rẹ̀ gbèrú síi. Ìlérí ológo inú Bibeli ti ayé titun alálàáfíà, ayé kan tí ó bọ́ lọ́wọ́ “gbogbo nǹkan rẹ́dẹrẹ̀dẹ tí ń ṣẹlẹ̀,” di òtítọ́ gidi sí wọn. André àti Ásta ń jùmọ̀ ṣàjọpín ìgbàgbọ́ àṣẹ̀ṣẹ̀rí wọn pẹ̀lú àwọn mìíràn nísinsìnyí.

Magdalena, André, àti Ásta ní ìfọkànbalẹ̀ pé àwọn ti rí ìsìn tí ó tọ̀nà nígbẹ̀yìn gbẹ́yín. Eugenia pẹ̀lú, lẹ́yìn gbígbìyànjú láti yanjú àwọn ìṣòro ayé nípasẹ̀ ọ̀nà òṣèlú, rí ìsìn tí ó jọ bí ẹni pé ó tọ̀nà láàárín àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀. Ṣùgbọ́n kí ni ohun náà gan-⁠an tí ń pinnu bóyá ìsìn kan ni èyí tí ó tọ̀nà? Jọ̀wọ́ wo àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ tí ó tẹ̀lé e.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli déédéé pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń ṣèrànwọ́ fún àwọn ènìyàn tí iye wọn lé ní million márùn-⁠ún nínú ìwákiri wọn fún ìdáhùn títẹ́nilọ́rùn

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́