Ìwọ Ha Ń Gbádùn Ìdákẹ́kọ̀ọ́ Bí?
Ọ̀PỌ̀ àwọn olótìítọ́ ọkàn ìránṣẹ́ Ọlọrun ni inú wọn yóò dùn láti ya àkókò tí ó pọ̀ tó sọ́tọ̀ fún dídákẹ́kọ̀ọ́ Bibeli. (Orin Dafidi 1:1, 2) Síbẹ̀, bí wọ́n ti lérò pé èyí ń béèrè àkókò àti okun wọn lọ́pọ̀lọpọ̀, ọ̀pọ̀ rí i pé ó ṣòro láti lo àkókò àti okun tí ó pọ̀ tó fún ìdákẹ́kọ̀ọ́ bí wọn ìbá ti fẹ́ láti ṣe.
Bí ó ti wù kí ó rí, nítorí àtilè máa báa lọ gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Ọlọrun tí ó gbéṣẹ́, àìní wà fún gbogbo wa láti sọ ayọ̀ àti okun wa dọ̀tun láti ọjọ́ dé ọjọ́ nípa wíwá àwọn apá-ìhà titun tàbí apá-ìhà jíjinlẹ̀ ti òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Àwọn òtítọ́ Bibeli tí wọ́n sún ọ ṣiṣẹ́ ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn lè má fi bẹ́ẹ̀ sún ọ ṣiṣẹ́ mọ́ nísinsìnyí. Fún ìdí yìí, ó dára, àní ó ṣekókó, pé kí a ṣe ìsapá àfitọkàntọkàn ṣe àti èyí tí ó jẹ́ lemọ́lemọ́ láti jèrè ìjìnlẹ̀ òye titun nínú òtítọ́ kí a baà lè ru ara wa sókè nípa tẹ̀mí.
Báwo ni àwọn ẹni ìgbàgbọ́ ti ìgbà ìjímìjí ṣe sọ araawọn di alágbára nípa tẹ̀mí nípasẹ̀ ìdákẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun? Báwo ni àwọn díẹ̀ lára àwọn ìránṣẹ́ Jehofa òde-òní ṣe lè mú kí ìkẹ́kọ̀ọ́ wọn túbọ̀ gbádùnmọ́ni kí ó sì tún ṣàǹfààní? Báwo ni a ti san èrè fún wọn nítorí àwọn ìsapá wọn?
Wọ́n Sọ Okun Wọn Dọ̀tun Nípasẹ̀ Ìdákẹ́kọ̀ọ́
Ọba Josiah ti Juda dáwọ́lé ìgbétásì rẹ̀ lòdìsí ìbọ̀rìṣà pẹ̀lú ìtara tí ó túbọ̀ pọ̀ síi lẹ́yìn tí ó ti mú kí a ka “ìwé òfin Oluwa tí a ti ọwọ́ Mose kọ” fún òun. Kò sí iyèméjì pé kìí ṣe ìgbà àkọ́kọ́ nìyẹn tí ó gbé apá yìí nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọrun yẹ̀wò; ṣùgbọ́n gbígbọ́ ìhìn-iṣẹ́ náà ní tààràtà láti inú ìwé àfọwọ́kọ ti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ru ú sókè nínú ogun rẹ̀ fún ìjọsìn mímọ́gaara.—2 Kronika 34:14-19.
Wòlíì Danieli fi òye mọ ‘iye ọdún tí a óò mú pé lórí ìdahoro Jerusalemu’ àti ìdánilójú rẹ̀ kìí wulẹ̀ ṣe láti inú ìwé Jeremiah ṣùgbọ́n láti inú “àwọn ìwé.” (NW) Ó ṣeéṣe jùlọ kí ìwọ̀nyí ní nínú àwọn ìwé bíi Lefitiku (26:34, 35), Isaiah (44:26-28), Hosea (14:4-7), àti Amosi (9:13-15). Ohun tí ó rí àrídájú rẹ̀ nípasẹ̀ fífi tí ó fi aápọn kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli sún ọkùnrin olùfọkànsìn yìí láti wá Ọlọrun nípasẹ̀ àdúrà onígbòóná-ọkàn. Ẹ̀bẹ̀ àtọkànwá rẹ̀ ni a dáhùn pẹ̀lú ìfihàn àti ìtúnmúdánilójú síwájú síi níti ìlú-ńlá Jerusalemu àti àwọn ènìyàn rẹ̀.—Danieli, orí 9.
Josiah, tí ó “ṣe èyí tí ó tọ́ ní ojú Oluwa,” àti Danieli, tí “íṣe àyànfẹ́ gidigidi” ní ojú Ọlọrun, ni wọn kò yàtọ̀ sí wa lọ́nà pàtàkì kan lónìí. (2 Awọn Ọba 22:2; Danieli 9:23) Àwọn ìsapá wọn lẹ́nìkọ̀ọ̀kan tí wọ́n fi jìn fún ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a fi ìtara ṣe nínú Ìwé Mímọ́ tí ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó ní ìgbà yẹn ṣamọ̀nà wọn sí ipò tẹ̀mí tí ó túbọ̀ ga síi ó sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti gbádùn ìdè tí ó túbọ̀ lágbára pẹ̀lú Ọlọrun. Ohun kan náà ni a lè sọ nípa ọ̀pọ̀ àwọn ìránṣẹ́ Jehofa ìjímìjí mìíràn, àwọn bíi Jefta, onípsalmu kan ní ìdílé Asafu, Nehemiah, àti Stefanu. Gbogbo àwọn wọ̀nyí fúnni ní ẹ̀rí ìdákẹ́kọ̀ọ́ tí a farabalẹ̀ ṣe nínú àwọn apá Bibeli tí ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó ní àkókò tiwọn.—Awọn Onidajọ 11:14-27; Orin Dafidi 79, 80; Nehemiah 1:8-10; 8:9-12; 13:29-31; Iṣe 6:15–7:53.
Ẹ Jẹ́ Kí Iṣẹ́-Òjíṣẹ́ náà Jẹ́ Ìsúnniṣe Kan
Ọ̀pọ̀ jùlọ nínú àwọn ìránṣẹ́ Jehofa lónìí tí wọ́n ti ṣiṣẹ́sìn-ín fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ní ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún ìdákẹ́kọ̀ọ́ Bibeli. Wọ́n ti rí i pé èyí ṣekókó kí wọ́n baà lè wà lójúfò kí wọ́n sì dé ojú ìwọ̀n àwọn ẹrù-iṣẹ́ Kristian ní kíkún. Síbẹ̀ náà, ọ̀pọ̀ nínú wọn gbà pé kìí fìgbà gbogbo rọrùn láti mú kí ìlò àkókò àti okun wọn wàdéédéé láàárín ìkẹ́kọ̀ọ́ àti àwọn ọ̀ràn mìíràn tí wọn kò gbọ́dọ̀ ṣàìkàsí.
Síbẹ̀, wíwà lójúfò nípa tẹ̀mí nípasẹ̀ ìdákẹ́kọ̀ọ́ aláápọn ṣekókó fún bíbójútó àwọn àìní nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ Kristian wa nínú ìpele ìtẹ̀síwájú tí ó ti lọ jìnnà yìí nínú iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba kárí ayé. Àwọn wọnnì tí a mú ọkàn wọn yọ̀ nípasẹ̀ àkọ̀tun àti òye-inú tí ó jinlẹ̀ síi nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọrun lè kojú ìpèníjà ti nínípalórí àwọn ọkàn-àyà tí ebi ń pa. Èyí jẹ́ òtítọ́ yálà a yan ẹnìkan sí ibi tí a ti lè retí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ nínú iṣẹ́ ẹja pípa nípa tẹ̀mí tàbí ẹnìkan ń lo ìforítì ní àgbègbè ìpínlẹ̀ tí a ń ṣe déédéé níbi tí ìdágunlá ní gbogbogbòò ti gbòdekan.
Máa Fi Ọ̀rọ̀ Ọlọrun Bọ́ Araàrẹ Déédéé
Ohun tí àwọn ẹlòmíràn ń ṣe lè fún ọ ní èrò nípa bí o ṣe lè túbọ̀ gbádùn ọ̀nà ìgbàkẹ́kọ̀ọ́ déédéé rẹ tàbí bí ìwọ àti ìdílé rẹ ṣe lè lo àkókò ìkẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà tí ó túbọ̀ ń mérè wá. Lára àwọn nǹkan tí ìránṣẹ́ Ọlọrun kì yóò fẹ́ láti pàdánù ni kíka Ọ̀rọ̀ Ọlọrun fúnraarẹ̀ déédéé. Ọ̀pọ̀ ti fi í ṣe góńgó wọn láti ka ó kérétán orí mẹ́ta sí mẹ́rin nínú Bibeli lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Ìwọ ha fẹ́ láti ka gbogbo Bibeli tán ní ọdún kan bí? Nígbà náà ìwọ yóò láyọ̀ láti lo àkókò púpọ̀ síi ní kíkà á, bóyá fún ọgbọ̀n ìṣẹ́jú lóòjọ́.
Ìwọ ha ti ka Bibeli jálẹ̀ ju ẹ̀ẹ̀kanṣoṣo rí lọ bí? Èéṣe tí o kò fi gbé góńgó titun kan kalẹ̀ nígbà mìíràn? Láti yí ọwọ́ padà, Kristian obìnrin kan ka àwọn ìwé Bibeli ní ọ̀nà tí a gbà kọ wọ́n tẹ̀léra. Ó jèrè ọ̀pọ̀ àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀, tí a gbékarí ipò àtilẹ̀wá níti ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọjọ́ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀, tí òun ti fòdá tẹ́lẹ̀. Kristian obìnrin mìíràn ti ka Bibeli láti páálí sí páálí nígbà márùn ún ní àwọn ọdún márùn ún tí ó ti kọjá, láti igun ìwòye tí ó yàtọ̀síra nígbà kọ̀ọ̀kan. Ní ìgbà àkọ́kọ́, ó kà á jálẹ̀ ní tààràtà. Nígbà tí ó kà á lẹ́ẹ̀kejì, ó ṣàkópọ̀ ohun tí ó wà nínú orí kọ̀ọ̀kan sí ìlà kan tàbí méjì nínú ìwé àkọsílẹ̀. Láti ọdún kẹta síwájú, ó kọjá sórí ẹ̀dà atọ́ka títóbi, ní kíkọ́kọ́ yẹ àwọn ìtọ́ka sí ẹsẹ̀ mìíràn nínú òpó ìlà àárín méjì wò lọ́nà àṣàyàn àti fífiyè kínníkínní sí àlàyé etí ìwé àti ìsọfúnni inú àkọkún. Ní ìgbà karùn ún, ó lo àwọn àwòrán ilẹ̀ inú Bibeli láti mú òye pọ̀ síi ní apá tí ó jẹ́ ti ìrísí ojú-ilẹ̀. Ó sọ pé: “Ní tèmi, Bibeli kíkà di èyí tí ó gbádùn mọ́ mi bí ìgbà tí mo ń jẹun.”
Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli kan tí wọ́n ní ìháragàgà ti rí i pé ó ṣàǹfààní láti ní ẹ̀dà Bibeli kan fún ìdákẹ́kọ̀ọ́, ní kíkọ àwọn àlàyé ṣókí fífanimọ́ra, àwọn àkàwé tí ń múnironújinlẹ̀, tàbí nọ́ḿbà ojú-ìwé àwọn ìtẹ̀jáde mìíràn tí wọ́n lè tọ́ka sí lẹ́yìn náà sí etí ìwé rẹ̀. Òjíṣẹ́ alákòókò kíkún kan kà á sí ìgbádùn ní ìparí oṣù kọ̀ọ̀kan láti kọ àwọn kókó titun tí ó ti kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ nínú oṣù náà sínú ẹ̀dà tí ó fi ń kẹ́kọ̀ọ́. Ó sọ pé, “Fífojúsọ́nà fún àwọn wákàtí mi ṣíṣeyebíye wọ̀nyí, ń ràn mi lọ́wọ́ láti tètè lé àwọn góńgó mìíràn bá nínú oṣù náà.”
Àwọn Ìwéwèé Díẹ̀ Tí A Fi Ọgbọ́n Ṣe
Ìwọ ha nímọ̀lára pé ìwéwèé rẹ kún fún àwọn ohun àìgbọ́dọ̀máṣe lójoojúmọ́ àti lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ àti pé o nílò àwọn ìtanilólobó díẹ̀ fún lílo àkókò rẹ tí ó mọníwọ̀n lọ́nà dídára jù bí? Ó dára, jẹ́ kí ohun tí o nílọ́kàn láti kà wà pẹ̀lú rẹ, kí o sì lo àwọn àkókò ọwọ́dilẹ̀ rẹ. Ní ilé tàbí níbi tí o bá ti sábà máa ń kẹ́kọ̀ọ́, dé àyè tí ó bá ṣeéṣe dé lọ́nà tí ó bọ́gbọ́nmu, ṣètò àwọn ìwé àti àwọn ohun-èèlò ìkẹ́kọ̀ọ́ mìíràn kí ó baà lè rọrùn láti dé ibi tí wọ́n wà. Jẹ́ kí agbègbè ibi tí o ti ń kàwé gbádùnmọ́ni ṣùgbọ́n kìí ṣe pé kí ó tunilára ju débi pé kí ó máa fi oorun kùn ọ́. Ìwọ ha ní iṣẹ́-àyànfúnni ọ̀rọ̀ àsọyé kan bí? Yára ka àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ náà sílẹ̀ ní àkókò tí ó bá yá jùlọ fún ọ láti ṣe bẹ́ẹ̀, lẹ́yìn náà jẹ́ kí àwọn èrò náà padà wá sọ́kàn rẹ nígbà tí o bá ń sinmi tàbí tí o bá ń ṣe àwọn iṣẹ́ àfipawọ́ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́.
Àwọn mìíràn lè fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú rẹ láti lo àkókò lọ́nà rere fún àǹfààní tọ̀túntòsì. Fún àpẹẹrẹ, o lè jẹ́ kí ẹnìkan ka ọ̀rọ̀ kan tí ó rọrùn láti lóye sókè ní etíìgbọ́ rẹ nígbà tí o bá ń ṣe àwọn iṣẹ́ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ lọ́wọ́ tàbí nígbà tí o ń gbé tíì kalẹ̀ fún onínúure tí ń kàwé fún ọ. Tipé kí gbogbo àwọn tí ń bẹ nínú ilé pohùnpọ̀ sórí àkókò píparọ́rọ́ fún ìdákẹ́kọ̀ọ́ ńkọ́? “Kí ni o ti kà láìpẹ́ yìí tí ó gbádùn mọ́ ọ?” Nígbà mìíràn ó lè ṣeéṣe fún ọ láti gbọ́ nípa ohun tí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ ti kọ́ nípa bíbẹ̀rẹ̀ ìjíròrò kan pẹ̀lú wọn lọ́nà yìí.
Ìwọ ha lọ́kàn ìfẹ́ nínú mímú àwọn èrò titun kan wọnú ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ bí? Ìwọ lè gbé góńgó àkókò kalẹ̀ fún ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ ní ọ̀nà kan náà tí ọ̀pọ̀ ń gbà gbé góńgó àkókò kalẹ̀ fún sísọ̀rọ̀ fún àwọn ẹlòmíràn nípa Bibeli. Akéde (aṣáájú-ọ̀nà) alákòókò kíkún kan gbé wákàtí kíkéré jùlọ fún ìkẹ́kọ̀ọ́ kalẹ̀ inú rẹ̀ sì dùn bí ó ti rí i tí òun ń súnmọ́ lílé góńgó náà bá. Àwọn ẹlòmíràn dín àkókò tí wọ́n fi ń wo tẹlifíṣọ̀n kù wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ rí àkókò fún ìkẹ́kọ̀ọ́. Ọ̀pọ̀ yan ẹṣin-ọ̀rọ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ kan tí wọ́n lépa fún àkókò díẹ̀, bí èso tẹ̀mí, ipò àtilẹ̀wá àwọn ìwé Bibeli, tàbí ọnà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́. Àwọn kan gbádùn yíya ṣáàtì ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọjọ́ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀, bí irú àwọn tí wọ́n fi ìbátan tí ó wà láàárín àwọn ọba Israeli àti àwọn wòlíìa tàbí Iṣe Awọn Aposteli àti àwọn lẹ́tà Paulu hàn.
Ẹ̀yin ọ̀dọ́, ẹ ha ń fẹ́ ìgbàgbọ́ tí ó túbọ̀ lágbára bí? Èéṣe tí ẹ kò mú ìtẹ̀jáde kan fún ìkẹ́kọ̀ọ́ kínníkínní ní àkókò ìsinmi kúrò ní ilé-ẹ̀kọ́ yín tí yóò tẹ̀lé e? Ọmọ ilé-ẹ̀kọ́ gíga kan tí ó ti ṣèrìbọmi yan Mankind’s Search for God, ìwé náà tí a tẹ̀jáde láti ọwọ́ Watch Tower Society. Nínú orí kọ̀ọ̀kan, ó kọ àwọn àkópọ̀ ṣókí sínú ìwé nípa àwọn ohun tí ó kọ́. Ó ń gbé ìpèníjà dìde ó sì ń gba àkókò púpọ̀ síi ju bí ó ti rò lọ. Bí ó ti wù kí ó rí, nígbà tí ó parí gbogbo ìwé náà pátá, ìjótìítọ́ àwọn ìhìn-iṣẹ́ Bibeli wọ̀ ọ́ lọ́kàn ṣinṣin.
Máa Háragàgà Láti Kẹ́kọ̀ọ́ Nígbà Gbogbo
Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ nínú iye àwọn ìránṣẹ́ olùṣòtítọ́ ti Jehofa lóde òní ‘ń pọ̀ síi ní iṣẹ́ Oluwa.’ (1 Korinti 15:58) Àní pẹ̀lú ìtòlẹ́sẹẹsẹ tí a túnṣe àti ìsapá olótìítọ́ ọkàn pàápàá, ọ̀nà ìgbàṣiṣẹ́ kan tí o tẹ̀lé ní ọ̀sẹ̀ kan pàtó lè má yípadà púpọ̀. Síbẹ̀, ìháragàgà tí kìí kùnà ní ipa tìrẹ láti jèrè òye òtítọ́ tí ó túbọ̀ jinlẹ̀ àti láti mú araàrẹ wà lójúfò sí àwọn ète Jehofa tí ń ní ìmúṣẹ yóò mú ìyàtọ̀ wá.
Ó ń fúnni níṣìírí láti gbọ́ èrè àwọn wọnnì tí wọ́n ti mú ọ̀nà ìkẹ́kọ̀ọ́ wọn sunwọ̀n síi. Kristian ọkùnrin kan, ní mímọ̀ pé òun ń pàdánù ìṣarasíhùwà tí ó tọ́ nípa wíwá ìmọ̀ òtítọ́ tí ó túbọ̀ jinlẹ̀, ṣètò ìgbésí-ayé rẹ̀ kí ó baà lè yọ̀ọ̀da púpọ̀ síi nínú àwọn wákàtí tí ọwọ́ rẹ̀ kò bá dí fún ìdákẹ́kọ̀ọ́. Ó sọ pé, “Ó ti mú ìdùnnú tí n kò mọ̀ tẹ́lẹ̀ wá fún mi. Pẹ̀lú ìgbọ́kànlé tí ń ga síi ṣáá nínú ìkọ̀wé Bibeli tí ó ní orísun àtọ̀runwá, mo rí i pé mo lè bá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ nípa ìgbàgbọ́ mi pẹ̀lú ìtara-ọkàn tòótọ́. Mo nímọ̀lára pé a bọ́ mi yó dáradára, mo jípépé nípa tẹ̀mí, mo sì ń nítẹ̀ẹ́lọ́rùn ní òpin ọjọ́ kọ̀ọ̀kan.”
Alábòójútó arìnrìn-àjò kan ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, tí ń ṣèbẹ̀wò sí ọ̀pọ̀ àwọn ìjọ, ṣàpèjúwe àwọn àǹfààní mìíràn ní ọ̀nà yìí: “Ọ̀rọ̀ àwọn wọnnì tí wọ́n jẹ́ aláápọn nínú ìdákẹ́kọ̀ọ́ sábà máa ń dùnmọ́ni ó sì máa ń yéni yékéyéké. Wọn túbọ̀ máa ń wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, ọ̀rọ̀ kòbákùngbé láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹlòmíràn kìí sìí tètè dà wọ́n ríborìbo. Nígbà tí wọ́n bá wà nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ pápá, wọ́n máa ń yíwọ́padà wọ́n sì tún máa ń wà lójúfò sí àìní àwọn ènìyàn tí wọ́n ń bá pàdé.”
Ó fi kókó kan kún un tí àwọn kan lè fẹ́ láti fi sọ́kàn nígbà tí wọ́n bá ń ṣe àyẹ̀wò ọ̀nà ìgbàkẹ́kọ̀ọ́ tiwọn. “Ní àwọn ìpàdé fún ìjíròrò Ìwé Mímọ́, ọ̀pọ̀ máa ń nítẹ̀sí láti ka àlàyé wọn ní tààràtà láti inú ìwé. Wọn yóò jàǹfààní púpọ̀ síi bí wọn yóò bá ṣàṣàrò lórí bí àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ náà ṣe tanmọ́ ohun tí wọ́n ti kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ tẹ́lẹ̀ tàbí mọ́ ìgbésí-ayé tiwọn.” Ìwọ ha ronú pé o lè sunwọ̀n síi ní ìhà yìí bí?
Wòlíì Danieli, lẹ́yìn iye tí ó ju 90 ọdún ìgbésí-ayé lọ, kò nímọ̀lára pé òun lóye àwọn ọ̀nà Jehofa tó. Ní àwọn ọdún rẹ̀ tí ó kẹ́yìn, ó béèrè nípa ọ̀rọ̀ kan tí òun kò lóye rẹ̀ ní kíkún: “Oluwa mi, kí ni yóò ṣe ìkẹyìn [ì]wọ̀nyí?” (Danieli 12:8) Kò sí iyèméjì pé ìháragàgà tí kìí yípadà yìí láti kẹ́kọ̀ọ́ púpọ̀ síi nípa òtítọ́ Ọlọrun jẹ́ kọ́kọ́rọ́ kan sí ìpàwàtítọ́mọ́ rẹ̀ gígalọ́lá jálẹ̀ gbogbo ipa-ọ̀nà ìgbésí-ayé rẹ̀ tí ó kún fún àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì.—Danieli 7:8, 16, 19, 20.
Ẹrù-iṣẹ́ kan náà ni ẹnìkọ̀ọ̀kan nínú àwọn ìránṣẹ́ Jehofa ní láti dúró gbọnyingbọnyin gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Rẹ̀. Máa báa nìṣó pẹ̀lú ìtara láti pa araàrẹ mọ́ ní alágbára nípa tẹ̀mí. Gbìyànjú láti fi àwọn apá-ẹ̀ka titun kan tàbí méjì kún ìwéwèé ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀, oṣooṣù, tàbí ti ọdọọdún. Wo bí Ọlọrun yóò ṣe bùkún ìsapá kékeré èyíkéyìí tí o bá ṣe. Bẹ́ẹ̀ni, gbádùn ìdákẹ́kọ̀ọ́ Bibeli rẹ àti àwọn ìyọrísí tí ń mú wá.—Orin Dafidi 107:43.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Gẹ́gẹ́ bí ìpìlẹ̀ fún ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ tí a mú gbòòrò síi, ìwọ lè fẹ́ láti lo ṣáàtì náà tí a rí nínú Insight on the Scriptures, tí a tẹ̀jáde láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., Ìdìpọ̀ 1, ojú-ìwé 464 sí 466.